diff --git a/BBC/bbc-sport-yoruba.csv b/BBC/bbc-sport-yoruba.csv new file mode 100644 index 000000000..80bac9c54 --- /dev/null +++ b/BBC/bbc-sport-yoruba.csv @@ -0,0 +1,369 @@ +Mo yá $50k fún ìgbáradì ìdíje 2022 World Championships – Tobi Amusan," Oríṣun àwòrán, oluwatobiloba_amusan/Instagram Tobi Amusan to gba ami ẹyẹ idije ere sisa ọlọgọrun mita (Women 100m hurdles) ti sọ iriri rẹ ati bo ṣe di alami ẹyẹ naa. Amusan, to sọrọ yii lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ, ni oun gba ẹyawo to le ni ẹgbẹrun lọna aadọta Dọla ($50,000) lati ṣe igbaradi fun igbaradi idije ere sisa lagbaye (World Athletics Championship). Ọjọ Iṣẹgun ni wọn ṣe atunṣe si iye akoko to lo lati fi sare nigba akọkọ to lọ sare. Dipo iṣẹju aaya 12s. 06ms ti wọn kọ silẹ fun pe o lo nigba to kọkọ sare naa lati gba ami ẹyẹ, 12s.12ms ni wọn kọ silẹ fun bayii pe o lo lati fi sare naa, lati pari idije agbaye naa. Amusan lo di ọmọ Naijiria akọkọ yoo gba ami ẹyẹ lanti lanti naa, ti aarẹ Buhari si ti fun ni ami ẹyẹ idanimọ. Lasiko to n sọrọ nigba igbaradi rẹ, o ni oun ṣiṣẹ takun takun saaju idije naa. Amusan to fakọ yọ ni Oregon lo ni, oun saba ma n farapa nitori ere idaraya ti oun yan laayo. O ni nitori naa ni oun se gba ẹyawo lati ri pe ara oun duro kampe lati wa ni ipo to yẹ fun idije naa. ""Bẹẹ ni mo n ṣèṣe ni ọpọlọpọ igba, ti mo si mọ pe ilera mi ku diẹ kaato. Ati wa loke tente ninu iṣẹ ti mo yan laayo nilo owo, nitori naa, ni mo se ya owo lati ri pe ilera mi wa nibamu, ki idije to bẹrẹ."" Ọṣẹ to kọja ni aarẹ Buhari fun Tobi Amusan ni ami ẹyẹ Officer of the Order of the Niger (OON) ti orilẹede Naijiria. Ninu ọrọ rẹ, Amusan ni idunnu ati ayọ lo jẹ fun oun lati ri pe Aarẹ Buhari fun oun ni ami ẹyẹ naa ati pe oun gbe orukọ orilẹede Naijiria ga.",22 Owewe 2022 +Wo ọ̀pọ́ àwòrán ìgbà tí Ọbabìnrin Elizabeth ti kópa nínú eré ìdárayá," BBC ṣe akọjọpọ awọn akoko ti ỌbabinrinElizabeth kopa ninu ere idaraya. Oríṣun àwòrán, Getty Images Ẹṣin akọkọ ti wọn fun ỌbabinrinElizabeth ree, orukọ ẹṣin naa ni Peggy, to jẹ ẹranko ọdun mẹri. Igba akọkọ ti yoo so gun ẹṣin naa ree lọdun 1952. Oríṣun àwòrán, Getty Images Ọbabinrin Elizabeth fẹran ẹṣin pupọ nigba aye rẹ, o si maa n yọju sibi awọn ayẹyẹ. Asiko to yọju sibi idije ere ẹṣin kan ree pẹlu aburo rẹ, Princess Margaret. Oríṣun àwòrán, Getty Images Ni 1957, Ọbabinrin Elizabeth gbe ami ami ẹyẹ Wimbledon fun Althea Gibson, to jẹ ọkunrin alawọmdudu tii yoo ami ẹyẹ SW19. Oríṣun àwòrán, Getty Images Ọdun meji lẹyin naa, Ọbabinrin Elizabeth yọju sibi aṣekagba ifẹsẹwọnsẹ FA Cup nibi ti Nottinham Forest ti din dundu iya fun Luton pẹlu ami ayo 2-1, to si gbe ami ẹyẹ fun Jack Burkitt. Papa iṣere Wembly ni 1966, Elizabeth fun agbabọọlu Bobby Moore ni ami ẹyẹ ife ẹyẹ agbaye lẹyin ti wọn na West Germany ni ami ayo 4-2 Oríṣun àwòrán, Getty Images Ọbabinrin Elizabeth ṣe ayẹyẹ 'Silver Jubilee"" rẹ ni Wimbledon lasiko ifẹsẹwọnsẹ awọn obinrin ninu eyii ti Virginia Wade ti jawe olubori Oríṣun àwòrán, Getty Images Ọbabinrin Elizabeth wa nibi aṣekagba idije Euro 96 ni papa iṣere Wmbly laarin Germany ati Czech Republic, Germany lo bori idije naa Oríṣun àwòrán, Getty Images Ayẹyẹ iṣide Commonwealth to waye ni manchester ree lọdun 2002 pẹlu David Beckham ati Kirsty Howard Oríṣun àwòrán, Getty Images Ọbabinrin Elizabeth lo ṣi idije hockey ni Slovenia lọdun 2008 nibi ti Guildford Flames ati Aquacity Poprad ti koju ara wọn Oríṣun àwòrán, Getty Images Elizabeth tun kopa nibi iṣide ayẹyẹ Olympic nibi to ti farahan ninu fiimu kan pẹlu James Bond (Daniel Craig) Oríṣun àwòrán, Getty Images Kraliça 2012-ci ildə paralimpiya oyunlarının da rəsmi açılışını etdi və 11 dəfə paralimpiya çempiyonu olmuş Baroness Tanni Grey-Thompson-la görüşdü. Oríṣun àwòrán, Getty Images Ọbabinrin Elizabeth naa lo ṣide eto 2012 Paralympics nibi to ti pade ẹni to gab ife ẹyẹ eto nigba mọkanla, iyẹn Baroness Tanni Grey-Thompson Oríṣun àwòrán, Getty Images Ẹṣin Ọbabinrin Elizabeth, Estimate, kopa ninu idije ere sisa fun awọn lọdun 2013, o si jẹ igab akọkọ ti ẹṣin ọba to wa lori oye yoo gba ife ẹyẹ idije naa lati ọdun mẹ́tàdínláàdọ́fà sẹyin Oríṣun àwòrán, Getty Images Ọbabinrin Elizabeth ba Bryan Habana lati South Africa ati Henry Speight sọrọ ṣaaju idije ife ẹyẹ agbaye Rugby lọdun 2015 Oríṣun àwòrán, Getty Images Ryan Moore ba Queen Elizabeth sọrọ lọdun 2016 Oríṣun àwòrán, Getty Images Aafin Burkinham ni Queen Elizabeth ti gbalejo awọn to gba anmi ẹyẹ Rio Olympics and Paralympics lọdun 2016 kan naa, ara awọn to wa nibẹ ni Nicola Adams Oríṣun àwòrán, Getty Images Ni 2017, Queen Elizabeth yọju sibi idije Royal Ascot Oríṣun àwòrán, Getty Images Queen Elizabeth yọju si Royal Ascot to waye lọdun 2021 Oríṣun àwòrán, Getty Images Ninu oṣu Kẹwaa, ọdun 2021, Queen Elizabeth wa ayẹyẹ iṣide to ṣaaaju Commonwealth Games ti Birmingham lọdun yii",9 Owewe 2022 +"Adigunjalè wọ ilé Aubameyang, wọ́n lùú, wọ́n tún kó dúkìá rẹ̀"," Oríṣun àwòrán, Getty Images Awọn adigunjale ji awọn nkan olowo iyebiye ko lọ nile agbabọọlu Barcelona, Pierre-Emerick Aubameyang, ni owurọ ọjọ Aje. Awọn alaṣẹ ẹgbẹ agbabọọlu naa sọ pe ọkunrin mẹrin to di ihamọra nkan ija oloro lo wọ ile agbabọọlu naa, ti wọn si fi ipa mu lati ṣi ilẹkun ibi to n ko awọn nkan olowo iyebiye pamọ si. Nibẹ ni wọn ti ko awọn ẹṣọ ara to ko sibẹ lọ. Iroyin sọ pe awọn adigunjale naa dunkooko mọ Aubameyang ati iyawo rẹ. Bakan naa ni iroyin naa sọ pe wọn lu u lasiko ikọlu naa. Igba akọkọ kọ niyii ti adigunjale wọ ile awọn agbabọọlu ni orilẹ-ede Spain. Eyi to ṣẹlẹ yii si ni igba keji ti wọn wọ ile Aubameyang ni Castelldefels laarin oṣu meji pere. Ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe igba akọkọ waye nigba ti agbabọọlu naa ati idile rẹ ko si nile. Awọn agbabọọlu Barcelona miran ti ole ti wọ ile wọn ni Gerard Pique, Ansu Fati, Jordi Alba, Samuel Umtiti ati Coutinho.",29 Ògún 2022 +Ta ni Bournemouth ṣẹ̀ tí Liverpool fi di ẹrù ìyà 9-0 rù wọ́n?," Oríṣun àwòrán, Getty Images Ẹgbẹ agbabọọlu Liverpool tayọ ni ifẹsẹwọnsẹ wọn pẹlu Bournemouth pẹlu goolu mẹsan si odo. Ifẹwọnsẹ akọkọ ti Liverpool yoo bori ni saa liigi 2022/2023 niyi lẹyin ti wọn ti gba ifẹsẹwọnsẹ mẹta ṣiwaju. Goolu mẹsan si odo ni goolu to pọju ninu ifẹsẹwọnsẹ kan ṣoṣo lati igba ti liigi premiership ilẹ Gẹẹsi ti bẹrẹ lọgbọn ọdun sẹyin. Bi o tilẹ jẹ wi pe ṣaju ifẹsẹwọnsẹ naa, akọnimọọgba Liverpool, Jurgen Klopp ṣalaye pe ibẹrẹ wọn ko tii ri bi awọn ṣe fẹ lẹyin ti wọn gbe ta ọmi meji ki Manchester United to na wọn lọjọ Aje ni papa iṣire Old Trafford. Oríṣun àwòrán, Getty Images Manchester United lo kọkọ na ikọ agbabọọlu miran pẹlu goolu mẹsan an si odo nigba ti wọn koju Ipswich lọdun 1995 ati Southampton lọdun to kọja. Bakan naa ni Leicester city na Southampton ni mẹsan si odo lọdun 2019. Oríṣun àwòrán, Getty Images Diaz gba meji wọle ni iṣẹju kẹta ati ikarundinlaadọrun, firmino pẹlu gba meji wọle nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa wọ iṣẹju kọkanlelọgbọn ati ikejilelọgọta. Elliot (Iṣẹju kẹfa), Alexander-Arnold (Iṣẹju kejidinlọgbọn), Van Dijk (iṣẹju karundinlaadọta), Freitas Gouveia Carvalho (iṣẹju ọgọrin). Bakan naa ni aṣiṣe de ba Mepham, agbabọọlu Bournemouth to gba bọọlu si ile ara rẹ.",27 Ògún 2022 +Omijé gbojú Anthony Joshua lẹ́yìn tó lulẹ̀ níwájú Oleksandr Usyk lẹ́ẹ̀kejì," Oríṣun àwòrán, Getty Images Niṣe lomije n bọ loju gbajumọ akanṣẹgbayi ọmọ orilẹede England, Anthony Joshua lẹyin to padanu ifẹsẹwọnsẹ ẹṣẹ kikan laarin oun ati Oleksandr Usyk lọjọ Satide mọ Ọjọ Aiku. Bo tilẹ jẹ pe onka awọn alamojuto ifẹsẹwọnsẹ ẹṣẹ kikan naa lo fun Usyk ni bẹliti igbanu ẹyẹ olubori nilu Jeddah lorilẹede Saudi Arabia, Joshua ṣalaye nigba ti wọn bii lere ọrọ pe, “inu n bimi gidi gan an ni, o dun mi de isalẹ ọkan mi” Lẹyin to sọ eyi tan, Joshua fọwọ boju rẹ o si mi kanlẹ. O ni awọn, “ipenija kan ti mo n koju n ni ipa lara mi ṣugbọn n ko ni jẹ ki ijakulẹ ija naa gbe mi ṣubu bi o tilẹ jẹ pe yoo nira diẹ” Joshua ti gba ami ẹyẹ goolu ẹṣẹ kikan ni idije Olympics lọdun 2012 nilu London. Lẹyin eyi lo bori awọn ija nejilelogun to kọkọ ja gẹgẹ bi akanṣẹjẹun. Anthony Joshua ti padanu mẹta ninu awọn ija marun to ja gbẹyin bayii, igba keji si niyi ni tẹlentẹle ti yoo lulẹ niwaju Usyk ọmọ orilẹede Ukraine. Kamaru Usman pẹlu lilẹ ni idije ijakadi igbalode UFC 278. Kamaru Usman padanu idije ijakadi igbalode UFC 278 ni ipele Welterweight to wa.",21 Ògún 2022 +"Arsenal da àlejò ọ̀ràn fún Bournemouth, 3:0 ni wọ́n fi dá bàntẹ́ ìyà fún wọn"," Oríṣun àwòrán, Getty Images Ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal ti fagba han ẹgbẹ agbabọọlu Bournemouth ninu ifẹsẹwọnsẹ Premier League to waye lọjọ Abamẹta. Ami ayo mẹta ọtọtọ ni Arsenal fi da bantẹ fun Bournemouth eyii to mu ki orin ọpẹ gba ẹnu awọn ololufẹ ikọ naa. Igba ti ifẹsẹwọnsẹ ọhun wọ iṣẹju marun un ni Martin Ødegaard kọkọ ṣi oju awọn Bournemouth wo. Nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa gbẹnule iṣẹju mọkanla gerege lo tun dan ẹnu awọn Bournemouth wo lẹẹkansi, ti bọọlu naa si ri ẹyin awọn naa. Ẹwẹ, nigba ti yoo fi di iṣẹju marunlelaadọta ti ifẹwọnsẹ ọhun bẹrẹ ni William Saliba sọ pe aisinibẹ ni ai ba wọn da si, eyii to mu ko ṣọ ami ayo Arsenal do aro mẹta ti ko gbọdọ da omi ọbẹ nu. Wayi, bo tilẹ jẹ awọn ọmọ ẹgbẹ agbabọọlu Bournemouth naa gbiyanju lati ṣe bii ọkunrin, amọ o jọ bi ẹni pe diẹ ọmọkunrin wọn ko to. Ẹwẹ, ninu ifẹsẹwọnsẹ to kọkọ waye, Tottenham ja fitafita ki wọn to ri goolu kan fi ṣagba Wolves. Nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa wọ iṣẹju kẹrinlelọgọta ni Harry Kane sọ ami kan sọsọ wọle. Pẹlu goolu naa, Harry Kane ti lewaju bayii gẹgẹbii agbabọọlu to gba goolu sinu awọn julọ ninu ẹgbẹ agbabọọlu kan naa lati igba ti Premier league ilẹ Gẹẹsi ti bẹrẹ ni nnkan bii ọgbọn ọdun sẹyin. Goolu marundinlaadọwa, (185 goals) ni Harry kane ti gba sinu awọn bayii.    ",20 Ògún 2022 +"Tobi ní òun kò ní jẹ́ asáré ojú títì lásán, mo sì ń tì í lẹ́yìn - Alàgbà Amusan"," Oríṣun àwòrán, Getty Images Awọn obi Oluwatobiloba Amusan, to jẹ elere ori ọdan ọmọ Naijiria, ti n jo yagini yojo pẹlu bi ọmọ wọn ṣe gbegba oroke ninu idije igi fifo 100m hurdles. Nibi idije Commonwealth Games ni akikanju obinrin yii ti fi itan lelẹ gẹgẹ bi ẹni to yara sa ere naa julọ ni isọri awọn obinrin. O fi akoko tuntun 12.30 lelẹ lati fi gba ami ẹyẹ wura lorukọ Naijiria lowurọ ọjọ Aiku. Ṣaaju lo ti kọkọ gba ami ẹyẹ rẹ akọkọ nibi abala to kangun si aṣekagba idije elere igi fifo 100 metres hurdles lọjọ Aiku. Awọn obi rẹ, arakunrin ati arabirin Amusan sọ fun BBC pe awọn ko ti gbagbe ayọ ati idunnu tawọn mọ nigba ti Tobi gba ami ẹyẹ wura. Bakan naa lo si tun fi itan lelẹ nibi idije World Athletics Championships to waye ni Eugen USA. Nibẹ lo ti fi itan lelẹ gẹgẹ bi ọmọ Naijria akọkọ ti yoo gba ami ẹyẹ wura nibi idije naa. Baba Tobi sọ iriri rẹ lalẹ ọjọ ti Tobi gba ami ẹyẹ nibi idije World Chamìonship. O sọ fun BBC pe oun ko sun daada lalẹ naa nitori pe oun fẹ wo Tobi lasiko ti yoo sare lori amohunmaworan. Baba Amusan tẹsiwaju pe ''Nigba ti Tobi kopa nibi idije World Championship, mo sọ pe mo gbọdọ darun mọju lati wo isesi rẹ lori ọdan. Oorun diẹ bẹrẹ si ni kun mi nitori akoko wa yatọ si ti ilu to ti n kopa nibi idije naa. Gẹgẹ bi obi, bi ọmọ rẹ ba ṣe oriire, idunnu rẹ ko ni lopin, a kọrin, a jo, a fọpẹ fun Ọlọrun. Inu wa dun pupọ'' Kii se ọjọ ti eeyan ba gun, lo n kan ọrun, lẹyin igbesẹ akọkọ, mo ti n sọ fun awn ohun to yẹ ko se atawọn ohun ti ko yẹ ko se. Koda, Tobi sọ fun mi pe laelae, oun ko ni jẹ asare oju titi lasan, lati igba naa ni mo ti n se atilẹyin fun. Mo si nigbagbọ ninu rẹ pe lọjọ kan, yoo di ohun eelo to se iyebiye lagbo ere idaraya. Lootọ ni ala mi pada wa sẹ lori rẹ, eyi to dun mọ mi ninu, ogo si ni fun Oluwa nitori kii se mimọọse wa.  O fikun pe oun ko mọ pe iru ọjọ bayii yoo waye, ti ogo Tobi yoo tan bi ti irawọ. Baba Tobi sọ pe kii ṣe mimọ ṣe awọn bi kii ṣe pe Ọlọrun lo gbogo fun ọmọ awọn.",8 Ògún 2022 +NFF kò ti san owó tó jẹ Super Falcons ní Morocco títí di àsìkò yìí," Oríṣun àwòrán, Super Falcons Ẹgbẹ agbabọọlu obinrin orilẹ-ede Naijiria ko tii ri owo ti ajọ bọọlu alafẹsẹgba ni Naijiria, ati ileeṣẹ ere idayara, jẹ wọn fun idije ife awọn obinrin ni Africa, WAFCON, to waye loṣu to kọja. Ẹgbẹ agbabọọlu Super Falcons kọ lati lọ si papa iṣere fun igbaradi wọn fun ifẹsẹwọnsẹ ti wọn fi koju Zambia lọjọ kejilelogun, oṣu Keje, nitori pe wọn jẹ wọn ni owo ajẹmọnu. Ifẹsẹwọnsẹ naa lo sọ ẹni to ṣe ipo kẹta. Owo to le ni ẹgbẹrun mẹwaa Dọla, ni wọn jẹ ẹnikọọkan awọn agbabọọlu naa, lara eyi ti ajẹmọnu wọn fun bibori ninu ifẹsẹwọnsẹ mẹta to mu wọn wọ ipele semi finals ni idije WAFCON. Botilẹ jẹ pe ajọ NFF sọ pe oun yoo san owo naa laipẹ, ẹnikan lara awọn agbabọọlu naa sọ fun BBC Sport Africa pe oriṣiriṣi irọ̀ ni wọn n pa fun awọn. “Wọn kọkọ sọ fun wa lọjọ ti a da iṣẹ silẹ ṣaaju ọjọ ti a koju Zambia pe, wọn ti buwọlu owo naa, ti awọn yoo si san laipẹ.” O ni lati igba naa ni wọn ti pa irọ bii pe awọn nọmba apo asunwọn ti awọn agbabọọlu fun ko pe, ati bẹẹ bẹẹ lọ. BBC Sport Africa kan si ajọ NFF ati ileeṣẹ ere idaraya lori ẹsun naa. Ẹnikan lara awọn olori ajọ naa sọ fun BBC lọjọru pe o yẹ ki awọn agbabọọlu naa ri owo wọn gba lọsẹ yii, nitori pe awọn ti ṣiṣẹ lori rẹ. Wọn ti san apapọ $2,800 ni owo ti awọn agbabọọlu naa n na lojoojumọ ati ajẹmọnu fun awọn nkan mii ṣaaju idije WAFCON fun wọn. Awọn owo ti wọn ko tii ri gba ni awọn ajẹmọnu wọn fun WAFCON, ati fun awọn irinajo wọn si Austria ati Canada, to fi mọ eyi ti wọn fi lu Ivory Coast ṣaaju idije WAFCON. Igba akọkọ kọ re e ti ẹgbẹ agbabọọlu Super Falcons fẹhonu han lori owo ti ijọba jẹ wọn. Wọn ti ṣe bẹẹ ri ni idije WAFCON meji to ti waye ri, ni South Africa lọdun 2004, ati ni Abuja lọdun 2016.",5 Ògún 2022 +Arsenal fọ́ Sevilla lẹ́nu pẹ̀lú góòlù 6-0," Oríṣun àwòrán, Getty Images Goolu mẹta ṣangiliti ni atamatase tuntun ti ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal ṣẹṣẹ ra, Gabriel Jesus gba wọle sawọn lasiko ti Arsenal fi na Sevilla ni goolu mẹfa si odo ni idije ife ẹyẹ Emirates Cup to waye lọjọ. Bukayọ Saka naa gba bọọlu wọle sawọn ni igba meji. Ki ifẹsẹwọnsẹ naa to wọ iṣẹju mọkandinlogun ni Arsenal goke pẹlu goolu mẹrin si odo. Eddie Nketia lo wa fọba lee lori. Emirate Cup jẹ idije igbaradi fun saa bọọlu to n bọ lọna eyi ti awọn ẹgbẹ agbabọọlu kan ti ileeṣẹ Emirates n ṣe agbatẹru fun maa n gba lọdọọdun ki ipenija ajakalẹ arun COVID-19 to de ba a lọdun 2020 ati ọdun 2021. Oríṣun àwòrán, Getty Images Awọn ifẹsẹwọnsẹ miran to tun waye lọjọ abamẹta Ni ilu Oslo lorilẹede Norway ni ifẹsẹwọnsẹ ọlọrẹsọrẹ laarin Manchester United ati Athletico Madrid ti waye. Amọṣa nnkan ko fi gbogbo ara ṣe ẹnuure fun Manchester United. Joao Felix lo bu omi pa ireti wọn ninu ifẹsẹwọnsẹ naa nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa ti n rebi ati danu duro. Amọṣa, alamojuto ifẹsẹwọnsẹ naa, iyẹn rẹfiri fun agbabọọlu Manchester United lọwọ aaringbungbun papa, Fred ni kaadi pupa fun aṣemaṣe lẹyin ti goolu naa waye. Oríṣun àwòrán, Getty Images Ni ifẹsẹwnsẹ to waye laarin Chelsea ati Udinese ni papa iṣire Dancia arena nilu Udine lorilẹede Italy. Goolu meji lati ẹsẹ Ruben Loftus -Cheek ati Hakim Ziyech lo fun Chelsea ni igara olubori.",30 Agẹmo 2022 +"Ẹ má bú ọkọ́ mi mọ́, Bàbá Tobi kò jẹ́bí bó ṣé dáná sún aṣọ èrè ṣíṣá ọmọ rẹ - Ìyá Amusan"," Oríṣun àwòrán, Tobi Amusan Iya to bi Tobi Amusan ti o di ilumọọka lagbaye ati akọni ori ọdan ti ko si ẹlẹgbẹ rẹ, Iyafin Amusan ti sọrọ lori ọrọ kan ti ọmọ rẹ sọ. Tobi lo sọ fun ẹka ere idaraya BBC pe baba oun maa n dana sun asọ ere idaraya oun ni lasiko ti oun n gbaradi, nitori iwe lo fẹ ki oun gbajumọ. Amọ nigba ti oun naa n ba BBC Yoruba sọrọ, iya Tobi Amusan ni ki awọn ọmọ Naijiria maṣe bu ẹnu atẹlu baba ọmọ oun. O ni awọn eeyan n bu ọkọ oun lẹyin ti Tobi ni baba oun maa n dana sun asọ ati bata oun nitori pe oun fẹ maa sare ori ọdan.  Tobi Amusan lẹyin ti o gba ami ẹyẹ agbaye nidi ere sisa onimita ọgọrun, salaye pe ọpọlọpọ igba ni mama oun ma parọ fun baba oun pe oun lọ sí ṣọọṣì. Amọ to si jẹ pe oun lọ se igbaradi fun ere sísa ni. Iyafin Amusan wa sọ fun BBC Yoruba pe ara ọmọ lo ta baba Tobi nitori fura Tobi lo ni oun fẹ di dokita. Mama Tobi ni ojuse awọn si ni lati tọ Tobi sọna, ko le kọkọ moju to ẹkọ rẹ, ko si yago fun ere sisa. “Agbabọọlu ni Baba Tobi, ẹmi iya rẹ gan mo ma n sa ere, fun idi eyi, Baba Tobi fẹ ko gba jumọ eto ẹko rẹ lo fi gbe igbesẹ naa. Sugbọn o ni ibi ti Ọlọrun ba ni eeyan yoo de, yoo de ibẹ lasẹ Eledumare.” Iyafin Amusan ni lati ile iwe alakọbẹrẹ ni Tobi Amusan ti bẹrẹ si n ma sare, ki o to lọ si oke okun. O tẹsiwaju pe, bi ọrọ Naijiria ṣe ba ni lẹru wa lara idi ti baba Tobi fi gbe igbesẹ naa, ti o si rọ awọn eeyan lati mase bu ẹnu atẹ lu igbese wọn. “Ile iwe jẹ ọkan googi to sọ ọmọ mi di ilu mọka.” “Lati ile ẹkọ alakọbẹrẹ ni ọmọ mi ti n sare, titi ti o fi lọ ka iwe ni oke okun, to fi wa ri anfani lati sare fun Naijiria. Iyafin Amusan wa rọ awọn obi ati alagbatọ lati maṣe dẹkun nidi sise atilẹyin fun awọn ọmọ wọn, gẹgẹ bi o ṣe ṣe fun Tobi. Sugbọn o ni ki wọn ri daju pe wọn ran awọn ọmọ naa lọ si ile iwe fun ẹkọ to peye.” “Pẹlu Ọlọrun, awọn ọmọ le de ibi ti wọn fẹ, a gbọdọ gbaruku ti wọn pẹlu adura, a gbọdọ ran wọn lọ si ile iwe.” Oríṣun àwòrán, Getty Images Tobi Amusan ti di ilumọọka lagbaye ati akọni ori ọdan ti ko si ẹlẹgbẹ rẹ nidi ere sisa onimita ọgọrun. Laipẹ yii si ni okiki rẹ kan pe o ti laluyọ nidi ere sisa, to si ti gba ami ẹyẹ agbaye nidi ere idaraya naa. Ọmọ Naijiria ni Tobi Amusan, o wa lati iran Yoruba, to si gbe ogo orilẹede yii ga. Nigba to n ba ẹka ere idaraya BBC sọrọ, Tobi Amusan salaye awọn akoko to lo ni Naijiria ati ibasepọ pẹlu ẹbi rẹ. Tobi, tii se ẹni ọdun mẹẹdọgbọn lo salaye pe ọpọ ipenija lo dide si oun nitori ere sisa ti oun yan laayo naa. Tobi sọ fun BBC pe awọn obi oun ko gba gbẹrẹ rara, ti wọn si mu iwa ọmọluabi lọkunkundun. O ni ẹkọ iwe nikan ni wọn fẹ ki awọn ọmọ wọn dojukọ, ati pe gẹgẹ bii obinrin, wọn ro pe oun ti n si ẹsẹ gbe, ti oun ko si ni afojusun to dara. Oríṣun àwòrán, Getty Images Nigba to n salaye iru atilẹyin to ri gba lati ọdọ iya rẹ, Tobi Amusan ni iya oun ni oju inu, to si ti ri awn ohun ti oun ko ri nipa ọjọ ọla oun. “Mama mi ro pe o yẹ ki awọn fun mi ni aaye lati se oun to wu ọkan mi, to si maa n fa mi leti lati mase ja oun kulẹ ninu igbẹkẹle ti oun ni ninu mi. Mama mi yoo sọ fun baba mi pe ipade ẹgbẹ akọrin ni mo lọ ni sọọsi wa nigba kiigba ti mo ba yọ jade nile, tabi ko sọ fun pe mo lọ sibi eto ariyanjiyan akẹkọọ ta n pe ni Debate. Gbogbo asiko yii, mo ti lọ sibi idije ere sisani awn ipinlẹ miran.  Bi gbogbo rẹ si se bẹrẹ ree. Ni ọjọ kan, baba mi yari, to si koro oju si mi nigba ti asiri tu pe mo n lọ sa ere ori ọdan ni. O jo gbogbo awọn asọ ere sisa mi. O wa sọ fun mama mi pe iyẹn ni ko jẹigba ikẹyin ti oun yoo foju kan mi ni ibudo ere idaraya.” Amọ bi o tilẹ jẹ pe baba rẹ ko ni igbẹkẹle tabi igbagbọ ninu ere sisa to yan laayo, sibẹ Tobi Amusan ni igbagbọ pupọ ati igbẹkẹle ninu ara rẹ, eyi to mu ko moke ninu ere sisa. Oríṣun àwòrán, Getty Images Oríṣun àwòrán, Twitter Aarẹ Muhammadu Buhari ti darapọ mọ ẹgbẹẹgbẹrun awọn ọmọ Naijiria lagbaye lati ki arabinrin Tobi Amusan ku oriire. Iyen lẹyin to gba Ami ẹyẹ wura fun Naijiria ninu idije World Athletics Championships ti ọdun 2022. Amusan to jẹ ẹni ọdun marunlelogun naa lo ṣe ohun ti enikan o ṣeri lasiko to di ọmọ Naijiria akọkọ lati gba Wura ni idije Championship Ninu ọrọ Aarẹ Buhari, o kii pe o ku oriire to si mu iwuri ba orin orilẹede Naijiria , ti wọn kọ lati sami si Ami ẹyẹ wura to gba naa. Aarẹ Buhari ni iṣẹtakuntakun to ṣe naa mu ayọ ati idunnu ba awọn ọmọ Naijiria, eleyii to mu wọn gbagbọ wi pe ko si ohun to ṣoro lati ṣe pẹlu igbagbọ. O fikun un pe aseyori re yoo jẹ moriya fun awọn ọmọde to n bọ ni ẹyin rẹ lati mọ daju pe ẹni to ba ṣiṣẹ takuntakun yoo ri ere rẹ. Bakan naa ni gomina ipinlẹ Eko, Bajide Sanwo-Olu ni itan Amusan jẹ itan Naijiria, eleyii to fi daju pe ti awọn ọmọ Naijiria ba gbagbọ ninu ara wọn, ko si ohunkohun to lee ṣoro ṣe fun wọn. O ni arabinrin naa kọ awọn ọmọ Naijiria lati ṣiṣẹ ki wọn si mọ pe ere n bẹ fun oniṣẹ. Ninu ọrọ tirẹ, gomina ipinlẹ Ogun to pe arabinrin naa ni ọmọ oun ti oun yan ni nkan bii osu diẹ ṣẹyin lati ṣe moriya fun iṣẹ to yan laayo. Amusan to jẹ ọmọ ipinlẹ Ogun ni gomina Abiodun ba yọ ayọ to si ni gbogbo awọn ọmọ ipinlẹ Ogun wa ni ẹyin rẹ. Gbajugbaja elere idaraya, Usain Bolt naa ki ku oriire to si ni aṣeyọri rẹ lamilaaka, to si wu ni lori. Ninu ọrọ idupẹ rẹ, Amusan ni ohun ni awọn eniyan ma n lo ọrọ o ku diẹ fun nitori igba mẹta ọtọọtọ ni ohun ti ṣe ipo kẹrin, ki o to di pe oun gba ade wura naa. Amusan lo kọkọ fakọyọ ninu idije to kangun si aṣekagba (Semi-Finals) lẹyin to gba jawe olubori ni iṣeju aaya (12:12 SECONDS) Lẹyin eyi lo wa fọbale ni aṣekagba idije naa nibi to ti wa jawe olubori to si da ẹni akọkọ lati orilẹede Naijiria ti yoo gbegba oroke ni idije Championships ni agbaye. Lẹyin to pegede tan, o gba okẹ marun un dọla owo ilẹ okeere ati ẹgbẹrun aadọrin dọla fun jija we olubori to si gba ami ẹyẹ wura. Apapọ owo to gba ti wọn ba yii si owo orilẹede Naijiria yoo le ni aadọrin miliọnu Naira. Oríṣun àwòrán, AFP Ṣaaju asiko yi, ọpọ le ma mọ nipa elere ori ọdan Tobilola Amusan ṣugbọn pẹlu ara to da nibi idije C0mmonwealth to n lọ lọwọ, ọpọ lo n kan sara si arabinrin ọmọ Naijiria yi. Ninu idije elere sisare fo igi taa mọ si hurdles lo ti fi ounjẹ fẹgbẹ to si gbawo bọ nigba to kopa ninu abala to kangun si aṣekagba. Ko fi mọ ni eleyi nikan nigba to tẹsiwaju ni abala aṣekagba to si gba ami ẹyẹ wura ninu idije naa. Pẹlu itu to pa, oun ni ẹni to sa are lasiko to kere julọ ni isọri awọn obinrin. Ni onka iṣẹju, iṣẹju mejila ati iṣẹju aaya mejila(12.12  secs) lo fi gba ife ẹyẹ naa. Ẹni ọdun marundinlọgbọn yi fi itan lelẹ nipa pe o la akoko ti ọmọ orileede Amẹrika nii Kendra Harrison ti ṣaaju fi lelẹ gẹgẹ bi ẹni to sare julọ ni isọri ere hurles 100m fawọn obinrin. Akoko ti Harrison jẹ 12.20 lọdun 2016 lo si fi lelẹ. Ninu aṣekagba idije ti wn sa lorileede Amẹrika yi, Harrison ṣe ipo keji lẹyin Amusan ninu abala to kangun si aṣekagba. Wakati meji lẹyin igba to fi ẹyin Harrison lulẹ ni Amusan tẹsiwaju lọ gba ami ẹyẹ goolu ninu aṣekagbga idije naa. Koda o tun sare ju ti 12.12 to sa ni abala to kangun si aṣekagba ṣugbọn nitori atẹgun to pọ lasiko ere naa, wọn ko kọ 12.06s toi sa silẹ fun. Fọnran fidio ibi ti omije ti n jabọ loju arabinrin Tobilola jẹ nkan ti ọpọ ti n sọrọ rẹ ni Naijiria loju opo ayelujara. Niṣe ni Tobi n yọ omi loju nigba ti wọn n kọrin orileede Naijiria fun Tobi gẹgẹ bi ẹni to jaweolubori. Eyi mu ki ọpọ ọmọ Naijiria kan saara si ki wn si ni akikanju lo jẹ to si tun gbe ogo Naijiria ga. Wọn bi Tobilola Amusan ni ilu Ijẹbu Ode lọdun 1997 to si kẹkọ jade nileẹkọ girama Our Lady of Apostles Secondary School, Ijebu-Ode. Ọmọ Yoruba atata yi tẹsiwaju lọ si fasiti University of Texas, El Paso. Ninu awọn ami ẹyẹ to ti gba sẹyin tẹlẹ ni eyi to gba lọdun 2018 ni ilẹ Afrika ati nibi idije Commonwealth. Bakan naa lo tun jaweolubori nibi idije Diamond League ni Zurich lọdun 2021 nibi idije elere ori ọdan ni abala 100 metres hurdles. ",25 Agẹmo 2022 +Àṣìṣe gba adé ipò kẹta lọ́wọ́ Naijiria lópin WAFCON 2022," Ẹgbẹ agbabọọlu obìnrin ti orile-ede Naijiria, Super Falcons, ko ri ami ẹyẹ kankan gba pada sile ni idije bọọlu àwọn obìnrin ni Africa, wafcon to waye ni Morocco. Eyi waye lẹyin ti orile-ede Zambia na wọn ni ami ayo kan si odo níbi ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ to waye lọjọ Ẹti fun ipo kẹta idije naa. Papa ìṣeré Mohammed V n'ilu Casablanca lo ti waye. Ọmi odo ni wọn kọ́kọ́ ta, sugbọn ọmọ ẹgbẹ́ agbabọọlu Super Falcons, Nnadozie Chiamaka, ṣeeṣi gba bọọlu si àwọ̀n wọn, eyi to di goolu ọ̀fẹ́ fun Zambia, ni isẹju kọkandinlọgbọn. Ko si ẹni to pada gba bọọlu si àwọ̀n ara wọn titi ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ fi pari. Ninu ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ mẹfa ti Naijiria gbá ni wafcon 2022, mẹta pere ni wọn bori. Wọn lu Botswana ati Burundi ni ipele akọkọ. Wọn lu Cameroun ni ipele quarter final. Sugbọn South Africa lu wọn ní ipele akọkọ, Morocco lu wọn ni ipele semi final. Zambia lu wọn ni aṣekagba, to si gba ipo kẹta mọ wọn lọwọ. Igba kẹta rèé ti Naijiria padanu ife ẹyẹ ni wafcon lati igba tó ti bẹ̀rẹ̀. Amọ o gba a nigba mẹsan-an ninu mejla. Bi o tilẹ jẹ pe Super Falcons ko ṣe àṣeyọrí ni wafcon ọdun yii, yoo lanfaani lati kopa ni idije ife agbaye lọdun 2023, ni Australia ati New Zealand. Nigba to ba awọn akọroyin sọ̀rọ̀ lẹyin ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ third place, olukọni Super Falcons, Randy Waldrum sọ pe lootọ ni awọn ko ri ipo kankan mu ni idije naa, botilẹ jẹ pe awọn gbiyanju. O ni sugbọn idunnu to wa nibẹ ni pe àwọn lanfaani lati ri tikẹẹti idije fun ife agbaye gba. Ati pe gbogbo aṣiṣe ti awọn ṣe ni awọn yoo ṣe àtúnṣe si ṣáájú idije to n bọ. Ọdun to kọja ni Waldrum gba iṣakoso gẹgẹ bi olukọni Super Falcons. Oríṣun àwòrán, cafonline Orile-ede Naijiria ati Zambia yoo koju ara wọn lónìí lati jà fun àmì ẹyẹ bàbà (ipo kẹta) ninu idije bọọlu àwọn obìnrin ni Africa to n lọ lọwọ ni Morocco. Orile-ede mejeeji padanu ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ ti wọn gbá ni ipele semi final lọjọ Aje. Naijiria padanu 5-4 ninu pẹnariti ti wọn gba lẹyin ti ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ wọn pẹlu Morocco yọrí si 1-1 lẹyin wakati meji. Ami ayo 1-0 ni Zambia gba pẹlu South Africa. Aago mẹsan-an alẹ oni ni ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ naa yoo waye, ni papa ìṣeré Mohammed V, n'ilu Casablanca. Oríṣun àwòrán, cafonline Naijiria ti gba ife idije WAFCON fun igba mẹsan-an, ninu mọkanla to ti waye sẹ́yìn. Ọdun 2018 ni wọn gba a kẹhin. Ẹni ti yoo gba eyi to n lọ lọwọ wà laarin South Africa ati Morocco. Ko si ẹni to gba a ri ninu orile-ede mejeeji.",22 Agẹmo 2022 +"Bí NFF kò bá sanwó tó jẹ wá, a kò ní gbaradì fún ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ pẹ̀lú Zambia - Super Falcons"," Oríṣun àwòrán, super falcons Ajọ bọọlu alafẹsẹgba ni Naijiria, NFF, ti sọ pe iṣoro ọ̀wọ́n gogo owo ilẹ̀ okeere ni ko jẹ ki oun ti san owo oṣù fun àwọn agbabọọlu Super Falcons. Owurọ Ọjọ́ru ni àwọn agbabọọlu obìnrin orile-ede Naijiria, Super Falcons, kọ̀ lati lọ si pápá igbaradi wọn ṣáájú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ pẹlu agbabọọlu orile-ede Zambia. Eyi ko sẹ́yìn owo ti ìjọba Naijiria jẹ wọn. Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ naa ni yoo sọ ẹni ti yoo gba àmì ẹyẹ fun ipo kẹta ninu idije WAFCON 2022 to n lọ lọwọ ni Morocco. Sugbọn ninu fidio kan ti ajọ NFF fi sita, aṣoju aarẹ NFF, Amaju Pinnick, Alhaji Ibrahim Gusau sọ pe aitete ri owo àwọn agbabọọlu naa san, jẹ ibanujẹ fun 'gbogbo wa'. 'Inu gbogbo eeyan nile ati nilẹ okeere lo dun si bi àwọn agbabọọlu naa ṣe ṣe ni idije yìí. Oríṣun àwòrán, super falcons/ twitter ' Gbogbo ipa wa la sì n ṣa, lati ri paṣipaarọ owo ilẹ̀ okeere ṣe."" O ṣàlàyé pe àwọn ti n ṣiṣẹ pẹlu gbogbo awọn ti ọ̀rọ̀ kan lati mu ki owo wọ inu apo àsùnwọ̀n àwọn agbabọọlu obìnrin naa laipẹ. Alhaji Gusau sọ pe oun ti ṣe ipade pẹlu awọn agbabọọlu naa ni ile ìtura ti wọn wà, lori ọrọ naa. O ni ibinu wọn si ti rọlẹ̀ lẹyin àrọwà ati àlàyé ti awọn ṣe fun wọn. Ẹgbẹ́ agbabọọlu obìnrin orile-ede Naijiria, Super Falcons, ti kọ̀ lati lọ fun igbaradi wọn ṣáájú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ pẹlu agbabọọlu orile-ede Zambia.  Ọjọ Ẹti ni ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ naa yoo waye, nibi ti ẹgbẹ́ agbabọọlu mejeeji yoo ti koju ara wọn lati jà fun ipo kẹta ninu idije WAFCON 2022 to n lọ lọwọ ni Morocco.  Sugbọn iroyin to jade ni owurọ Ọjọ́ru ni pe, awọn agbabọọlu naa kọ lati jade kuro ni ile itura wọn, nigba ti asiko to o lati lọ si papa igbaradi.  Bo tilẹ jẹ pe BBC ko tii le fìdí nkan to fa igbeṣẹ naa mulẹ lati ọdọ awọn agbabọọlu, Iroyin sọ pe wọn ṣe bẹ́ẹ̀ nitori owo oṣù ati ajẹmọnu ti ajọ to n sakoso bọọlu ni Naijiria, NFF, jẹ wọn. Gbogbo igbiyanju ikọ iroyin BBC Yoruba to wa ni Morocco lati ba awọn alaṣẹ ẹgbẹ́ agbabọọlu Super Falcons naa sọ̀rọ̀, ni ko tii so eso rere.  A o ma a fun yin ni ẹkunrẹrẹ iroyin naa, to ba ṣe n jáde. Oríṣun àwòrán, others Ẹgbẹ́ agbábọ̀ọ́lù Morocco ṣí adé akọni ìdíje WAFCON kúrò lórí Naijiria Àlá ẹgbẹ́ agbabọọlu obìnrin ti orile-ede Naijiria, Super Falcons, lati tun gba ife ẹyẹ idije bọọlu àwọn obìnrin ni Africa, lọdun yii ti já si òfo.  Eyi waye lẹyin ti ẹgbẹ́ agbabọọlu orile-ede Morocco lu wọn ninu ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ to kangun si aṣekagba, semi final to waye lọjọ Aje.  Papa ìṣeré Moulay Abdellah n'ilu Rabat, Morocco ni ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ naa ti waye.  Igba mẹsan-an ni Naijiria ti gba ife ninu igba mejila ti WAFCON ti waye.  Ọdún 2018 ni wọn gba a kẹhin, amọ ti 2022 ti ko bá jẹ ikẹwa bọ mọ wọn lọwọ.  Ni bayii, ipo kẹta ni Super Falcons yoo jà fun nigba ti wọn ba koju orile-ede Zambia. Oríṣun àwòrán, CAF Bi ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ naa ṣe lọ  Aago mẹsan-an alẹ ni ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ naa bẹ̀rẹ̀.  Lati ibẹrẹ lo si ti gbóná janjan.  Titi abala akọkọ fi parí, ọ̀mì odo ni Super Falcons ati Atlas Lionesses ti Morocco gbá.  Sugbọn nigba ti ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ wọ abala kejì, ní iṣẹju, Uchenna Kanu gbá bọọlu si awọn Morocco.  Amọ ko ju iṣẹju meji lọ, ti Morocco fi da a pada fun wọn. Oríṣun àwòrán, CAF Agbabọọlu gbòógì meji ninu ikọ̀ Super Falcons lo gba 'red card' ni abala keji. Halimatu Ayinde ati Rasheedat Ajibade.  Eyi to mu ki ọmọ ikọ̀ wọn ku mẹsan-an.  Àwọn mẹsan-an lo si pari ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ naa, lati koju mọkanla ti Morocco ní.  Ọ̀mì ayo kan ni wọn ta titi ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ fi pari lẹyin aadọrun iṣẹju.  Sugbọn àwọn adari ayo fun wọn ni ọgbọn iṣẹju si i.  Ko si ayipada kankan, eyi to mu ki wọn o gba pẹnariti.  Ninu maarun-un ti ẹgbẹ́ agbabọọlu kọọkan gbá, Naijiria padanu ẹyọkan.  Ohun si lo mu ki Morocco bori. Oríṣun àwòrán, CAF",19 Agẹmo 2022 +"Kò rọrùn rárá láti dàgbà ní agbègbè bíi Mushin, àànú Ọlọ́hun ló sọ mi di agbábọ́ọ̀lù Super Falcons - Rasheedat Ajibade"," Rasheedat Ajibade WAFCON 2022: Tí m bá wo bí mo ṣe bẹ̀rẹ̀ ní Mushin táwọn ẹgbẹ́ mi ń máà m Ṣaaaju ifsẹwọnsẹ ti yoo waye laarin awọn agbabọọlu obinrin orilẹede Naijiria ati Cameroon lonii ni papa isere Stade Mohamed V Stadium ni Casablanca lẹyin ti wọn lu awọn agbabọọlu Burundi lalubami lọjọ Aiku to kọja, BBC Yoruba mu iroyin nipa igbaradi awọn ẹgbẹ agbabọọlu ti Naijiria wa. Ọkan lara wọn to jẹ agbabọọlu aarin to si jẹ ọmọ Yoruba, Rasheedat Ajibade kẹnu bọ ọrọ nipa ibẹrẹpẹpẹ rẹ ni agbegbe Mushi ni ipinlẹ Eko, Naijiria.",14 Agẹmo 2022 +"Ọmọ ọ̀dọ̀ ni wọ́n gbé mi lọ ṣe ní London, wọ́n yí orúkọ mi padà, mo dí olókìkí kí ń tó lè lẹ́nu ọ̀rọ̀ - Mo Farah"," Ko to di gbajugbaja tẹẹ mọ lonii, hummmmn.. ikun imu ti bọ si tosi ti ko si lee pariwo titi to fi dagba. Gbajúgbajà eléré ìdárayá Sir Mo Farah ti tú àṣírí bí ó ṣe wọ orílẹ̀ èdè United Kingdom ní kékeré.   Farah ní ọ̀nà àìtọ́ ni wọ́n gbà gbé òun wọ UK láti ṣe ọmọ ọ̀dọ̀.   Ó ní àwọn tó gbé òun wọ orílẹ̀ èdè United Kingdom ló sọ òun ni Mohammed Farah àti pé Hussein Abdi Kahin gan-an ni orúkọ tí ìyá àti bàbá sọ òun.   Ó ní obìnrin kan ló mú òun kúrò ní orílẹ̀ èdè Somalia tó jẹ́ orílẹ̀ èdè bàbá òun nígbà tí òun wà ní ọmọ ọdún mẹ́sàn-án láti wá máa ṣe ìtọ́jú àwọn ọmọ kan ní orílẹ̀ èdè UK. Oríṣun àwòrán, others Farah ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé nǹkan tí òun máa ń sọ tẹ́lẹ̀ ni wí pé òun àti àwọn òbí òun ṣe àtìpó wọ UK tẹ̀lé ni, ó ní òótọ́ ibẹ̀ ni pé àwọn òbí òun kò fi ìgbà kankan dé United Kingdom rí.   Ó ṣàlàyé fún BBC pé oko àwọn ní òun àti àwọn ẹbí òun ń gbé kí òun tó di èrò UK.   Ó ní ọmọ ọdún mẹ́rin ni òun wà tí bàbá òun fi jáde láyé lẹ́yìn tí ìbọn bà á nínú ogun abẹ́lé tó wáyé ní orílẹ̀ èdè Somalia ní ọdún náà lọ́hùn-ún.   Ó fi kun pé bí ọmọ ọdún mẹ́jọ sí mẹ́sàn-án ni òun wà tí wọ́n fi wá mú òun kúrò ní ilé àwọn láti lọ máa gbé ọ̀dọ̀ mọ̀lẹ́bí kan ní Djibouti. ""Obìnrin kan tí mi ò mọ̀ rí ló mú mi wọ orílẹ̀ èdè United Kingdom"".   ""Inú mi dùn gidi nígbà náà nítorí mi ò wọ ọkọ̀ òfurufú rí""   ""Obìnrin náà ló ní kí n sọ pé Mohammed ni orúkọ mi, ìwé ìrìnnà kan sì wà lọ́wọ́ rẹ̀ èyí tó ṣàfihàn àwòrán mi pẹ̀lú orúkọ Mohammed Farah""   Farah tẹ̀síwájú pé nígbà tí àwọn dé UK, obìnrin náà mú òun lọ sí ilé rẹ̀ ní Hounslow, ẹkùn ìwọ̀ oòrùn London tó sì gba ìwé ìrìnnà ọwọ́ òun.   ""Níwájú mi ló fa gbogbo ìwé náà ya tó sì dà á sí ilé-ilẹ̀, ìgbà yẹn gan ni mo mọ̀ wí pé mo ti wọ gàù""   Ó ní láti ìgbà náà ni òun ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ọmọ ọ̀dọ̀ tí obìnrin náà sì ṣe ìkìlọ̀ fún òun wí pé tí òun bá ṣì fẹ́ rí àwọn ẹbí òun láyé òun ò gbọdọ̀ la ẹnu òun sọ ohunkóhun fún ẹnìkankan.   Ó ṣàlàyé pé òun tó ọmọ ọdún méjìlá kí wọ́n tó fi òun sí ilé ẹ̀kọ́ ní Feltham Community college.   Ó ní òun ti wọ́n sọ ní ilé ẹ̀kọ́ náà ni wí pé òun wá ṣe àtìpó ní UK láti Somalia ni.     Oríṣun àwòrán, others Ọ̀kan lára àwọn olùkọ́ Mo Farah tó bá BBC sọ̀rọ̀ ni nígbà tó bẹ̀rẹ̀ ilé ẹ̀kọ́ kìí múra dada àti pé kò le sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì tó bẹ́ẹ̀.   Bákan náà ni àwọn kò rí kí àwọn òbí rẹ̀ máa wá fún ẹ̀kọ́ àgbà.   Olùkọ́ Farah tó kọ eré ìdárayá, Alan Watkinson ní òun máa ń rí ìyàtọ̀ lára Farah tó bá ti wọ aṣọ eré ìdárayá.   Watkinson ní ó dàbí wí pé eré ìdárayá nìkan ni èdè tí Farah gbọ́.   Mo Farah ni eré ìdárayá dàbí òun tó mú ìgbé ayé tuntun bá òun, tí òun sì rò ó wí pé tí òun bá fẹ́ bọ́ nínú ìgbé ayé tí òun ń gbé lọ́wọ́ òun ní láti mu ni ọ̀kúnkúndùn   Ó ní èyí ló mú òun jẹ́wọ́ ẹni tí òun jẹ́ gan fún olùkọ́ Watkinson tí òun sì ṣàlàyé iṣẹ́ tí òun ń ṣe fún àwọn mọ̀lẹ́bí náà fun.   Ó fi kun pé Watkinson ló so òun papọ̀ mọ́ àwọn ẹbí mìíràn tí wọ́n wá láti Somalia bí tòun àti pé láti ìgbà náà ni inú ti máa ń dùn.   Láti ọmọ ọdún mẹ́rìnlá ló ti bẹ̀rẹ̀ sí ní pa òkìkí nínú eré sísá tí wọ́n sì pè é láti wá díje ni Latvia àmọ́ ìwé ìrìnnà tí kò ní ṣe ìdíwọ́ fún un.   Ó ní lọ́dún 2000 ni Watkinson bá òun gba ìwé ọmọ ìlú British pẹ̀lú orúkọ Mohammed Farah.   Farah ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ló kojú irú ìṣòro tí òun ní yìí, eré sísá ló gba òun là.   Iléeṣẹ́ BBC gbìyànjú láti kàn sí obìnrin tí Farah fẹ̀sùn kàn pé òun ló mú òun wọ London àmọ́ ó kọ̀ láti sọ ohunkóhun lórí ọ̀rọ̀ náà.",14 Agẹmo 2022 +Ṣé Nigeria yóò fìyà jẹ Morocco bí ti àtẹ̀yìnwá láti dé àṣekágba WAFCON 2022?," Ẹgbẹ agbaboolu obinrin Naijiria, Super Falcons yoo wako pẹlu ikọ Atlas Lionesses ti orlẹede Morocco. Loni, ọjọ Aje, ọjọ kejidinlogun, oṣu Keje, ọdun 2022, ni ifigagbaga naa yoo waye fun ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ to kangun si asekagba idije WAFCON 2022. Papa ìṣeré Prince Moulay Abdellah ni ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ naa yoo tì waye laago mẹsan-an alẹ n'ilu Rabat.  Iko Super Falcons lo gbọdọ bori ifẹsẹwọnsẹ yii lati wọ ipele aṣekagba idije naa. Lionesses of Atlas ile Morocco ni o bori ninu gbogbo ifẹsẹwọnsẹ ti wọn ti kopa ninu idije naa, ti iko Super Falcons si padanu ẹyọ kan ninu ifẹsẹwọnsẹ wọn ti wọn gba pẹlu iko Bayana Bayana ti ile South Africa. Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ yii ni yoo gbe ẹgbẹ́ agbabọọlu Super Falcons de ipele aṣekagba idije naa, ti wọn ba fi borí Morocco.  Bakan naa ni yoo jẹ fun Morocco, to ba jẹ pe awọn lo bori.  Ki wọn o to koju ẹlòmíì ni aṣekagba idije.  Orile-ede Naijiria n ja lati gba ife idije bọọlu àwọn obìnrin ni Africa, WAFCON, fun igba kẹwaa, ninu ìgbà mejila to ti waye.  Morocco n jà lati gba a fun igba akọkọ.  Botilẹ jẹ pe Super Falcons ni ọpọ n fi ojú si lara gẹgẹ bi akọni, ẹgbẹ́ agbabọọlu Atlas Lionesses naa kò ṣe e fi ọwọ rọ́ sẹyin.  Idi ni pe lati igba ti idije WAFCON 2022 ti bẹ̀rẹ̀, ni wọn ti n fakọyọ.  Wọn ò si tíì padanu ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ kankan.   Yatọ si eyi, Morocco lo gbalejo idije naa, wọn o si ni fẹ ki ife ẹyẹ bọ wọn lọwọ.  Nitori naa ẹgbẹ́ agbabọọlu Super Falcons nilo lati fi ọkàn si nkan ti wọn n ṣe lori papa lati ìbẹ̀rẹ̀ ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ naa.  Iye igba ti Morocco ati Super Falcons ti pade lori papa  Ọdun 1998 ni ẹgbẹ́ agbabọọlu mejeeji kọkọ pade ni WAFCON 1998.  Iya kekere kọ ni Super Falcons fi jẹ Atlas Lionesses ni ilẹ baba wọn.  Ami ayo mẹjọ si odo ni wọn fun wọn.  Ọdun 2000 ni wọn tun pade ni WAFCON 2022 to waye ni South Africa.  Ami ayo mẹfa si odo ni Naijiria tun fi lù wọ́n ni aludojubolẹ.  Sugbọn laarin ìgbà naa si asiko yii, ẹgbẹ́ agbabọọlu Morocco fihan pe nkan ti yatọ, paapaa lati igba ti WAFCON 2022 ti bẹ̀rẹ̀. Nigba ti o gba ni yanju, Aarẹ, ajọ to risi kokari ere bọọlu nile wa, NFF, Amaju Pinnick ni gbogbo nkan ni iko Super Falcons ni lati ṣe lati gba ifẹyẹ ijide naa gba kẹwa. Amaju ni oun kọkọ ki awọn agba bọọlu naa fun bi wọn ṣe fakọyọ ninu awọn ifẹsẹwọnsẹ ti ko pa ninu, ti wọn si bori awon akẹẹgbẹ wọn. “Mo kọkọ ki awọn agbabọọlu naa fun bi wọn fakọyọ ninu ifẹsẹọnsẹ pẹlu awọn akẹẹgbẹ wọn.” “Wọn ti fi ran wa pe orilẹede Naijiria ni oga ti a ba sọrọ ere bọọlu obinrin ni ile adulawọ, bi wọn ṣe fakọyọ ninu awọn ifesewọn wọn,” “Ifẹsẹweọnsẹ pẹlu ikọ Morocco ko le yipada sugbọn yoo lagbara pupọ gan nitori ikọ Morocco naa jẹ ẹgbẹ agbabọọlu ti muṣemuṣe wọn da muṣe.” “Mo ni igbagbọ pe a bori wọn, mo ti sọ fun awọn agbabọọlu naa lati ranti ibi ti wọn wa, ki wọn si fi ọkan gbe orilẹede Naijiria larug\]e nibi ijide WAFCON.”  “Ninu mi dun si awọn agbabọọlu pupọ.” Oríṣun àwòrán, others Aarẹ, ajọ to risi kokari ere bọọlu nile wa, NFF, Amaju Pinnick ni oun ni igbagbọ ninu iko Super Falcons lati bori orilẹede Morocco to ba di ago mẹsan oni ni papa iṣerẹ Prince Moulay Abdellah Stadium, Rabat lorilẹede Morocco.  Amaju ni awọn agbabọọlu Naijiria ti sẹtan lati jẹ orilẹede Naijiria bọ si oke nibi ti o ko wa. O ni o ti ṣeṣe fun Ikọ agbabọọlu Super Facons lati kopa ninu ifẹsẹwọmsẹ aṣe kagba to ba di ọjọ aiku ọse to bo yi Oríṣun àwòrán, others Bi ẹgbẹ́ agbabọọlu Super Falcons ti Naijiria ṣe n gbaradi lati koju Swallow ti Burundi lonii, ẹ jẹ ka ṣe agbeyẹwo ipa ti ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ naa ni. Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ naa ni eyi to kẹhin ni abala akọkọ fun awọn orile-ede to the wa ni ipin C ninu idije WAFCON 2022 to n lọ lọwọ ni Morocco. Ẹgbẹ agbabọọlu to ṣe ipo kinni, ikeji, ati ikẹta ni ipin C, yoo bọ si ipele quarter finals. Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ pẹlu Burundi si ni yoo sọ ibi ti ori n gbe Super Falcons lọ, ti Burundi ba fi lu wọn. South Africa ati Botswana lo na Burundi. Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ ti ọjọ́ Aiku, ti yoo waye ni papa ìṣeré Prince Moulay El Hassan, Rabat, ni igba àkọ́kọ́ ti orile-ede mejeeji koju ara wọn nilẹ okeere. Orile-ede Burundi ti padanu ninu ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ wọn meji akọkọ, Naijiria padanu ẹyọkan sọwọ South Africa. Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ laarin orile-ede mejeeji la le fi we ija laarin Dafidi ati Golayaati. Igba àkọ́kọ́ re e ti Burundi n kopa ni idije WAFCON, àmọ́ Naijiria ti kopa ninu mọkanla, o si ti gba ife ni igba mẹsan-an. Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ mẹta ni orile-ede kọọkan to n kopa ni idije bọọlu àwọn obìnrin ni Africa to n lọ lọwọ ni Morocco, WAFCON 2022, gbá ni abala akọkọ. Ninu meji to ti kọkọ gbá, Naijiria padanu ẹyọkan sọwọ South Africa, o bori ikeji nigba to na Botswana ni ami ayo méjìlá si odo. Lọwọlọwọ, Naijiria lo wa ni ipo keji ni ipin kẹta (C), pẹlu ami mẹta. Orile-ede Burundi lo wa ni ipo to kẹhin, ko ni ami kankan lẹyin ti South Africa ati Botswana lu u. Botilẹ jẹ pe ami mẹta ni Naijiria àti Botswana ni lori tabili igbelewọn, wọn fi Naijiria si ipo kejì, nitori 'iru' goolu ti wọn gbá wọ awọn. Sugbọn o, dandan ni fun wọn lati bori Burundi, ki wọn o le bọ si ipele quarter final. Olukọni ẹgbẹ́ agbabọọlu obìnrin Naijiria, Randy Waldrum, sọ fun awọn akọroyin n'ilu Rabat, lọjọ Abamẹta pe, àwọn ko le foju kere Burundi. O ni ""ao le foju di ẹgbẹ́ agbabọọlu Burundi."" A n gbaradi lati tun ṣe daadaa ju bi a ṣe ṣe lọ ní ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ wa to kọja. Erongba wa si ni lati wọ ipele quarter finals lọjọ Aiku."" +",10 Agẹmo 2022 +Àjọ bọ́ọ̀lù Sierra Leone yóò wádìí Àràmàǹdà ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ líìgì níbi tí àwọn agbábọ́ọ̀lù ti gbá góòlù 91-1 àti 95-0 wọlé," Oríṣun àwòrán, sierra leone football association Ajọ elere bọọlu lorilẹede Sierra leone ti gbe iwadi kalẹ lori ifẹsẹwọnsẹ bọọlu meji kan to waye ni liigi ilẹ naa. Awọn ẹgbẹ agbabọọlu mejeeji to bori ninu ifẹsẹwọnsẹ naa n lepa ati ni agbega si liigi to ga julọ lorilẹede naa. Ajọ ere bọọlu lorilẹede naa ni oun yoo ṣe iwadii awọn alamojuto ifẹsẹwọnsẹ naa atawọn agbabọọlu to kopa pẹlu. Ami kan naa lawọn ẹgbẹ agbabọọlu mejeeji wa, ifẹsẹwọnsẹ to jẹ aṣekagba saa bọọlu naa awọn ikọ mejeeji yii nlepa ẹni ti iye goolu rẹ yoo pọju ni. Nigba ti ifẹsẹwọnsẹ mejeeji yoo si fi pari, ẹgbẹ agbabọọlu Gulf FC na Koquima Lebanon ni goolu mọkanlelaadọrun si ẹyọkan, 91-1 Bakan naa ni Lumbenbu United si jiya goolu marundinlaọgọrun si odo, 95-0 lọwọ Kahula Rangers Oríṣun àwòrán, Ajọ bọọlu orilẹede Sierra Leone Fọran fidio lati ibudo ifẹsẹwọnsẹ tio waye ni Kenema city fihan bi awọn agbabọọlu ṣe n mọọmọ gba bọọlu fun awọn agbabọọlu alatako lati gba bọọlu sinu awọn. Fun pẹnariti to waye, nṣe ni aṣọle fo lọ si ọna to yatọ gedegbe si ibi ti bọọlu lọ, to si lulẹ bii apo ẹwa nibẹ. Ajọ ere bọọlu lorilẹede Sierra Leone ti sọ pe ẹnikẹni ti aje iwa ibajẹ ba ṣi mọ lori pe o ṣe idunadura nipasẹ ifẹsẹwọnsẹ naa  yoo ba ajọ to n gbogun ti iwa ijẹkujẹ lorilẹede naa lalejo fun igbesẹ to ba yẹ.  ",5 Agẹmo 2022 +Àlàyé bí ẹyẹ Super Falcons gbé kìnnìún Cameroon mì ní quarter final ìdíje WAFCON 2022," And we'll keep you signed in. Sign in or Register You need one to watch live TV on any channel or device, and BBC programmes on iPlayer. It’s the law. Nípasẹ̀ Adedayo Owolabi, Olubusola Afolayan, Olubayode Alebiosu àti Busayo James-Olufade Gbogbo àkókò tí a kọ jẹ́ ti UK Ẹgbẹ agbabọọlu obìnrin orile-ede Naijiria, Super Falcons, ti +bọ si ipele to kangun si aṣekagba, semi finals idije bọọlu àwọn obìnrin ni +Africa to n lọ lọwọ ni Morocco. Eyi waye lẹyin ti wọn lu ẹgbẹ́ agbabọọlu Indomitable +Lionesses ti orile-ede Cameroon ni ami ayo kan si odo. Ọjọbọ ni ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ naa waye ni papa ìṣeré Mohammed V +n'ilu Casablanca. Ọmi odo ni ẹgbẹ́ agbabọọlu mejeeji ta ní abala àkọ́kọ́ ifẹsẹ̀wọnsẹ̀ +naa. Sugbọn nigba ti ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ wọ isẹju mẹrindinlọgọfa, +Rasheedat Ajibade, pẹlu iranlọwọ Onumonu Chukwufunmnaya gba bọọlu si àwọ̀n +Cameroon. Titi ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ naa fi pari, ko si ẹgbẹ́ agbabọọlu to gba +bọọlu si àwọ̀n. Orile-ede Cameroon ti já kuro ni WAFCON 2022, bákan náà ni wọn +o ni le kopa ni idije bọọlu àwọn obìnrin ni agbaye lọdun to n bọ. Naijiria yoo koju orile-ede Morocco ni ipele +semi final ni ọjọ Aje, ọjọ kejidinlogun. Ẹgbẹ agbabọọlu orile-ede Senegal ati Botswana ti ko ẹrù wọn +kuro ninu idije bọọlu àwọn obìnrin ni Africa to n lọ lọwọ ni Morocco. Eyi waye lẹyin ti orile-ede Zambia na Senegal ni ami ayo mẹta +si meji. Ọmi ayo kọọkan ni wọn ta ni abala akọkọ àti ikeji ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ +naa. Eyi to mu ki wọn o gba pẹnariti. Bakan naa lo ri ni ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ Morocco ati Botswana. Ami +ayo 2-1 ni Morocco na Botswana. Ni bayii, Zambia ti bọ si ipele to kangun si àṣekágbá +idije WAFCON 2022. Yàtọ̀ si eyi, wọn tun ti koju osunwọn lati kopa ni idije ife +agbaye (World Cup) ti àwọn obìnrin ti yoo waye ni orile-ede Australia ati New +Zealand, lọdun 2023. Igba ọtun gba a ni eyi jẹ fun Zambia, nitori pe igba àkọ́kọ́ +niyii ti wọn n lọ fun idije ife ẹyẹ agbaye. Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ abala quarter final n tẹsiwaju lonii, pẹlu +orile-ede Naijiria ati Cameroon laago mẹfa irọlẹ, South Africa ati Tunisia +laago mẹsan-an alẹ. Àwọn meji to ba tun fidirẹmi ninu ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ mejeeji, yoo +já kuro ninu idije naa lọdun yii. Wọn ko sì ni le kopa ni World Cup lọdun 2023. Ẹni to ba bori ninu Naijiria ati Cameroon yoo +koju Morocco ni semi final. WAFCON 2022 quarter finals : Wo bí ìdíje quarter finals yóò ṣe lọ Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ fun ipele quarter finals ni idije bọọlu +àwọn obìnrin ni Africa to n lọ lọwọ ni Morocco, WAFCON 2022, yoo bẹrẹ ni Ọjọru, +ọjọ kẹtàlá, oṣu Keje, yoo si pari ni Ọjọbọ. Eyi n waye lẹyin ti orile-ede mẹrin (Burundi, Togo, +Uganda ati Burkina Faso), ti ja kuro ninu idije naa ni opin ọ̀sẹ̀ to kọja. Àwọn orile-ede to kù ni Naijiria, South Africa, +Botswana, Zambia, Tunisia, Senegal, Morocco ati Cameroon. Bayii ni ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ quarter final yoo ṣe lọ: Nkan to yẹ ki o mọ̀ nipa orile-ede kọọkan ti yoo gbá quarter final; Copper Queens ti Zambia ati Teranga Lionesses ti +Senegal Igba akọkọ niyii ti ẹgbẹ agbabọọlu orile-ede mejeeji +tayọ kọjá ipele akọkọ idije WAFCON, group stage. Ipele yii ni wọn ti má n pin +orile-ede kọọkan si isọri. Nitori naa, o +nira diẹ lati sọ àsọtẹ́lẹ̀ nipa ẹni ti yoo bori ni ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ wọn lọjọru. Atlas Lionesses ti The Mares ti Morocco ati Botswana Lootọ lo jẹ pe igba akọkọ niyii ti Botswana n kopa ni +idije Wafcon, amọ wọn ko ṣe e fi ọwọ rọ sẹyin. Ẹwẹ, orile-ede Morocco naa to gbalejo idije ti ọdún +yii naa ko kẹ̀rẹ̀. Wọn ko padanu ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ kankan lati igba ti idije +naa ti bẹ̀rẹ̀ ni isọri A ti wọn wa. Ayo marun-un ni wọn ti gba wọlé. Eyi tó mu ki wọn ṣe +ipo kinni ni isọri wọn. Super Falcons ti Naijiria ati Indomitable Lionesses ti +Cameroon Igba mẹsan-an ni ẹgbẹ́ agbabọọlu obìnrin Naijiria, +Super Falcons, ti gba ife idije WAFCON, ninu igba mọkanla to ti waye. Lọwọ lọwọ, +ọwọ wọn ni ife naa wa lẹyin ti wọn bori lọdun 2018. Ninu idije ti ọdun yii, Super Falcons fidirẹmi ni ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ +wọn àkọ́kọ́, pẹlubi South Africa ṣe lù +wọn ni 2-1. Wọn padà bori ni ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ wọn keji, nigba ti wọn +lu Botswana ni 2-0. Bakan naa ni ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ wọn kẹta, àmì ayo 4-0 ni wọn +lu Burundi. Cameroon ni wọn o koju ni ipele quarter final. Ẹgbẹ́ +agbabọọlu mejeeji kii ṣe àjòjì si ara wọn. Ipade wọn lori pápá ma n dà bi ti +erin meji ni. Àwọn mejeeji lo koju ara wọn ni ipele quarter final lọdun +2016, n'ilu Yaounde lorilẹ èdè Cameroon. Ẹgbẹ agbabọọlu Indomitable Lionesses naa ko ṣe fi ọwọ +yẹpẹrẹ mu lagbo bọọlu obìnrin ni Africa, sugbọn wọn ko ti laafaani lati gba ife +WAFCON ri lati igba ti wọn ti n kopa. Banfana Banfana ti South Africa ati Carthage Eagles ti +Tunisia Ẹgbẹ agbabọọlu Banfana Banfana ti South Africa, lo ṣe +ipo keji ni aṣekagba idije WAFCON lọdun 2018. Lati ibẹrẹ idije ti ọdun yii si ni wọn ti n tayọ. Wọn ko kuna idije kankan ní isọri C ti wọn wa. Àwọn lo +si wa ni ipo kinni pẹlu àmì mẹsan-án. Ni iwoye eeyan, Banfana Banfana lágbára jù Chartage +Eagles ti Tunisia lọ l'ori pápá. Amọ ohunkóhun lo le sẹlẹ ninu idije bọọlu. Àwọn ẹgbẹ́ agbabọọlu to ba yege ni ipele quarter +finals, ni yoo lanfaani lati kopa ni idije bọọlu àwọn obìnrin ni agbaye, ti yoo +waye lọdun 2023 ni orile-ede Australia ati New Zealand. Ẹgbẹ agbabọọlu Super Falcons ti Naijiria ti wọ ipele quarter +finals, ni idije WAFCON 2022 to n lọ lọwọ ni Morocco. Eyi waye lẹyin ti wọn na Burundi ni ami ayo mẹrin si odo lọjọ +Aiku Abala akọkọ, Group stage, idije bọọlu àwọn obìnrin ni Africa +fun ọdún 2022, WAFCON 2022, ti pari bayii lẹyin awọn ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ to waye lọjọ +Aiku. Super Falcons ti Naijiria na Swallow ti Burundi, South +Africa na Botswana ni ami ayo kan si odo. Ni ìpín C ti Naijiria wa, awọn lo wa ni ipo keji ni ori +tabili igbelewọn pẹlu ami mẹfa. South Africa lo wa ni ipo kinni pẹlu ami mẹsan-an. + Super Falcons ti bọ si ipele quarter finals bayii. Ipo ti orile-ede kọọkan wa niyii lori tabili +igbelewọn: Morocco vs Botswana Zambia vs Senegal South Africa vs Tunisia Cameroon vs Nigeria Àwọn ẹgbẹ́ agbabọọlu to ti já kuro ninu idije naa ni: Burundi, Uganda, Togo ati Burkina Faso. Onumonu Chukwufunmnaya lo kọ́kọ́ gba bọọlu sinu awọn Botswana nigba ti ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ naa wọ iṣẹju mọkanlelogun ni abala akọkọ. Ko pẹ ti wọn wọle fun abala keji, ni Christy Ucheibe fi ọba le ni iṣẹju kẹtadinlaadọta. Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ naa yatọ pupọ si ti ọjọ Aje, paapaa nipa bi awọn agbabọọlu naa ṣe jara mọ isẹ tọkàntọkàn, ati awọn igbeṣẹ ti olukọni wọn, Randy Waldrum gbe nipa awọn agbabọọlu to fi bẹ̀rẹ, ati awọn to pada rọpo. Bo tilẹ jẹ pe Super Falcons bori, wọn ṣi nilo ki wọn o na ẹgbẹ́ agbabọọlu orile-ede Burundi ninu ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ wọn lọjọ Aiku, ki wọn to o le bọ si ipele quarter finals. Ko tii daju pe Botswana naa yoo bọ si ipele naa, botilẹ jẹ pe wọn na Burundi ni ami ayo mẹrin si meji, ninu ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ wọn àkọ́kọ́. Ẹgbẹ agbabọọlu orile-ede Naijiria yoo gba ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ wọn keji lonii ninu idije wafcon 2022 to n waye ni Morocco. Àwọn agbabọọlu to yoo kopa niyii: Ẹgbẹ agbabọọlu Banfana Banfana ti orile-ede South Africa, ti tayọ si ipele quarter finals, ninu idije WAFCON 2022 to n lọ lọwọ ni Morocco. Eyi waye lẹyin ti wọn bori ni ifẹsẹwọnsẹ meji akọkọ ni ipin C. Orile-ede Naijiria ni wọn kọ́kọ́ lù ni ami ayo meji si ẹyọkan lọjọ Aje. Wọn tun lu Burundi ni ami ayo mẹta si ẹyọkan lọjọbọ. + +Igba akọkọ niyii ti awọn agbabọọlu obìnrin ti orile-ede Burundi n kopa ni idije WAFCON. WAFCON: CAF kéde àfikún ẹ̀bùn owó fún àwọn orílẹ̀èdè tó ń kópa ní ìdíje WAFCON ọdún yìí Ajọ bọọlu nilẹ Afirica ti fi kun iye owo ti awọn +agbabọọ̀lu obinrin to n kopa nibi idije ife ẹyẹ WAFCON lorilẹede Morocco yoo +gba. Aarẹ ajọ ere bọọlu nilẹ Afirika,Ọmọwe Patrice Motsepe lo kede afikun naa eyi +ti yoo to ida aadọjọ ninu ọgọrun (150%). Idije naa bẹrẹ ni ilu Rabat lọjọ Satide, ọdọ +keji oṣu keje ọdun 2022 lorilẹede Morocco. Pẹlu afikun yii, iye owo tawọn orilẹede to +kopa yoo gba ti kuro ni ẹgbẹrun lọna ọrinlelẹẹdẹgbẹrun o din mẹwaa dọla +(USD975, 000) si miliọnu meji o le ẹgbẹrun lọna irinwo dọla (USD 2, 400,000) Aarẹ ajọ bọọlu nilẹ Afirika, CAF ati igbimọ iṣakoso +ajọ naa ni asiko fifi ọwọ gbẹfẹ mu ọrọ bọọlu awọn obinrin ati idagbasoke rẹ ni +Afirika ti di ọrọ itan. Orilẹede to ba gba ife ẹyẹ idijẹ WAFCON tọdun +yii yoo gba ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta dọla (USD 500, 000) dipo ẹgbẹrun lọna igba +ti wọn n gba tẹlẹ. Orilẹede to ba gba ipo keji yoo gba ẹgbẹrun lọna +ọọdunrun dọla (USD 300, 000). Gbogbo awọn orilẹede to ba wọ ipele to kangun +si aṣekagba yoo gba ẹbun owo ẹgbẹrun lọna igba ati marundinlọgbọn dọla (USD +225, 000) dipo ẹgbẹrun marundinlaadoje dọla (USD 125, 000) ti wọn n gba tẹlẹ. Nigeria vs Botswana: Ṣé Super Falcons yóò le fi Botswana tí kò kópa rí ní wafcon ra iyì padà? Ẹgbẹ agbabọọlu Super Falcons ti Naijiria, yoo tẹsiwaju lonii, ninu idije bọọlu àwọn obìnrin ni Africa, wafcon 2022, to n lọ lọwọ ni Morocco. Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ naa ti yoo waye pẹlu orile-ede Botswana, ni anfaani kan ṣoṣo ti Naijiria ni, lati ṣe atunṣe kikuna ti wọn kùnà lọjọ Aje. Ọjọ Aje ni wọn gba ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ wọn akọkọ pẹlu Banfana Banfana ti South Africa, ti wọn si na wọn ni ami ayo kan si ẹyọkan. Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ pẹlu ẹgbẹ́ agbabọọlu Mares ti Botswana, si ni yoo sọ boya Naijiria yoo lọ si ipele quarter finals, tabi boya wọn n pada sile. Aṣeyọri nla ni Botswana fi bẹ̀rẹ idije wọn ni wafcon 2022, botilẹ jẹ wi pe igba akọkọ niyii ti wọn n kopa ninu idije naa. + +Ami ayo mẹrin si meji ni wọn lu Burundi. Àwọn si lo n leke lori tabili igbelewọn idije wafcon 2022, ni ìpín C. Ti wọn ba si tun lu Naijiria, a jẹ pe wọn o ni anfaani lati wa lara orile-ede mẹjọ ti yoo tayọ si ipele quater finals. Papa iṣere Prince Moulay El Hassan, n'ilu Rabat, ni ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ naa yoo ti waye laago mẹsan alẹ. Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ yii kan naa ni igba akọkọ ti Super Falcons ati Mares yoo koju ara wọn. Ọjọru ni awọn alaṣẹ ẹgbẹ́ agbabọọlu Super Falcons kede pe Ogbontarigi agbabọọlu, Asisat Oshoala, ko ni le kopa mọ ni wafcon 2022. Eyi ko ṣẹyin ifarapa to ni lasiko ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ pẹlu South Africa lọjọ Aje. Sugbọn, olukọni wọn, Randy Waldrum ti sọ pe eyi ko nii di aṣeyọri Falcons lọwọ. O sọ nibi ipade akọroyin lọjọru pe 'atunto ati atunṣe ti wa lẹyin ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ pẹlu South Africa'. Wọn ti juwe ọna +ile fun agbabọọlu orilẹede Zambia, Barbra Banda nibi idije WAFCON 2022 to n lọ +lọwọ lorilẹede Morocco. Awọn alaṣẹ ajọ +ere bọọlu ni Zambia ṣalaye pe lile ti wọn le agbabọọlu naa ko ṣẹyin bi +ariyanjiyan ṣe n waye lori iru ẹya eeyan to jẹ boya akọ ni tabi abo. Idije WAFCON jẹ +idije bọọlu fun awọn agbabọọlu obinrin ni Afirika ṣugbọn ariyanjiyan n lọ lori +boya ki wọn kaa mọ ẹya abo tabi akọ. Aarẹ ajọ bọọlu +Zambia, Andrew Kamanga fi idi iroyin naa mulẹ. Ajọ ere bọọlu lorilẹede NAijiria, NFF sọ pe grade 2 medical collateral ligament strain ni ohun to n yọ ọ lẹnu ti ko fi nii lee gba bọọlu ninu idije WAFCON ọdun yii mọ. Igba meji ni Oshoala farapa lasiko ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ wọn, ko to di pe ko ba wọn parí. Àjọ NFF sọ loju opo Twitter rẹ lọ san Ọjọ́ru pe Ọjọbọ ni yoo pada si orile-ede Spain. Nibẹ lo tí n gba bọọlu fun ẹgbẹ́ agbabọọlu Barcelona. + +Sugbọn ṣa, olukọni ẹgbẹ́ agbabọọlu Super Falcons, Randy Waldrum, sọ fun awọn akọroyin pe àìsí Oshoala, ko nii mu idiwọ tabi ifasẹyin ba wọn ni WAFCON 2022. WAFCON 2022: Asisat Oshoala, atamátàsé agbábọ́ọ̀lù Nàìjíríà ti já kúrò ní ìdíje WAFCON 2022 tó ń lọ lọ́wọ́ ní Morocco Ogbontarigi agbabọọlu obìnrin, to tun jẹ atamatase, Asisat Oshoala ti ja kuro ni idije bọọlu àwọn obìnrin ni Africa to n lọ lọwọ ni Morocco. Gẹ́gẹ́ bi ikede ti ajọ bọọlu Naijiria fi sita, eyi ko sẹ́yìn ifarapa to ni lasiko ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ Super Falcons pẹlu Banfana Banfana ti South Africa lọjọ Aje. Ẹgbẹ agbabọọlu Senegal na akẹẹgbẹ rẹ lati Burkina Faso ni ami ayo kan si odo níbi ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ wọn àkọ́kọ́ to waye ni papa ìṣeré Prince Moulay Abdellah, n'ilu Rabat. Ọmi odo ni wọn ta ni abala akọkọ ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ naa, sugbọn nigba ti idije naa wọ isẹju mẹrinlelọgọrin, agbabọọlu Korkal Fall gba bọọlu si àwọ̀n Burkina Babes, eyi to mu ki o jẹ 1-0. Saaju ni ẹgbẹ́ agbabọọlu Morocco to n gbalejo idije WAFCON 2022, na Burkina Faso ni ami ayo kan si odo níbi ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ akọkọ to ṣíde idije tọdun yii lọjọ Satide. Igba kejì re e ti Burkina Faso n kopa ni idije bọọlu awọn obinrin ni Afrika, lẹyin ọdún mejilelogun sẹ́yìn ti wọn kọkọ kopa. Ọjọ Ẹti ni wọn o koju Uganda ni ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ wọn to kẹhin ni abala akọkọ idije yii. + +Àwọn ẹgbẹ́ agbabọọlu ti ami wọn ba pọju ni yoo tayọ bọ si ipele quater finals. Senegal si ni orile-ede àkọ́kọ́ to ti bọ si ipele naa bayii. ami ayo meji si ẹyọkan ti ẹgbẹ́ agbabọọlu Banyana Banyana ti South Africa, fi lu agbabọọlu Naijiria, Super Falcons, nibi ifẹsẹ̀wọnsẹ̀ wọn to waye ni ọjọ́ Aje. Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ naa ni àkọ́kọ́ ti ẹgbẹ́ agbabọọlu mejeeji gbá, ninu idije bọọlu alafẹsẹgba ti awọn obinrin, to ni waye lorile-ede Morocco. + +Agbabọọlu South Africa, Jermaine Seopsenwe, lo gba bọọlu si àwọn Super Falcons, nigba ti idije naa wọ isẹju mọkanlelọgọta. Ko ju isẹju meji lọ nigba ti Hildah Tholakele Magaia tun gba bọọlu miran si àwọ̀n Super Falcons. + +Sugbọn nigba ti ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ wọ isẹju mọkanlelaadọrun, agbabọọlu Super Falcons, Rasheedat Ajibade, gba bọọlu sinu awọn South Africa. Àwọn nkan mii to sẹlẹ nibi ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ naa + +Igba méjì ni Asisat Oshoala farapa nibi ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ naa + +Agbabọọlu Naijiria, Alozie Michele Chinwen, gba kaadi alawọ ofefe (yellow) nigba ti idije wọ iṣẹju mẹrinlelogoji. Àmì ayò 2-0 ni South Africa fi ṣíde ìyà fún Naijiria ní wafcon 2022 + +Ko din ni ami ayo meji ti ẹgbẹ́ agbabọọlu Banyana Banyana ti South Africa, fi lu agbabọọlu Naijiria, Super Falcons, nibi ifẹsẹ̀wọnsẹ̀ wọn to waye ni ọjọ́ Aje. Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ naa ni àkọ́kọ́ ti ẹgbẹ́ agbabọọlu mejeeji gbá, ninu idije bọọlu alafẹsẹgba ti awọn obinrin, to ni waye lorile-ede Morocco. Agbabọọlu South Africa, Jermaine Seopsenwe, lo gba bọọlu si àwọn Super Falcons, nigba ti idije naa wọ isẹju mọkanlelọgọta. + +Ko ju isẹju meji lọ nigba ti Hildah Tholakele Magaia tun gba bọọlu miran si àwọ̀n Super Falcons. Àwọn nkan mii to sẹlẹ nibi ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ naa + +Igba méjì ni Asisat Oshoala farapa nibi ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ naa + +Agbabọọlu Naijiria, Alozie Michele Chinwen, gba kaadi alawọ ofefe (yellow) nigba ti idije wọ iṣẹju mẹrinlelogoji. Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ akọkọ fun ẹgbẹ́ agbabọọlu Super Falcons ti Naijiria ni idije WAFCON 2022 ti n waye ni papa ìṣeré Prince Heritier Maulay El Hassan, n'ilu Rabat, lorile-ede Morocco. Ni deede agogo mẹfa irọlẹ ni ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ naa bẹ̀rẹ̀. + +Lati ìbẹ̀rẹ̀ ni idije naa ti n gbóná, pẹlu bí ẹgbẹ́ agbabọọlu mejeeji ṣe ń gbiyanju lati gba bọọlu sinu awọn. ",4 Agẹmo 2022 +"Ìgbà méjìlá tí Super Falcons kojú South Africa ní WAFCON, tí wọn sì dáṣọ ìyà sí wọn lọ́rùn"," Oríṣun àwòrán, nff Ninu idije bọọlu afẹsẹgba to jẹ ti awọn obinrin ilẹ̀ Afrika tó n waye lọwọ ni orile-ede Morocco, ọjọ Aje, ọjọ́ kẹrin, oṣu Keje, ni ẹgbẹ́ agbabọọlu Super Falcons yoo gba ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ wọn àkọ́kọ́ pẹlu orile-ede South Africa. Papa ìṣeré Prince Heritier Moulay El Hassan, n'ilu Rabat, ni ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ naa yoo ti waye laago mẹfa irọlẹ. Igba àkọ́kọ́ kọ re e ti awọn mejeeeji n koju ara wọn. Ni gbogbo igba ti wọn ba pade lori papa, lo ma n gbona janjan bi ẹ̀kọ. Eyi ko sẹ́yìn bo ṣe jẹ́ pe ẹgbẹ́ agbabòọlu mejeeji, Super Falcons ati Bayana Bayana, lo jẹ ogbontarigi ninu bọọlu gbigba. Àmọ́ o, agba lẹtù, ọmọde lawó. Ninu igba mọkanla tí idije WAFCON ti waye, igba mẹsan-an ni Naijiria gba ife ẹyẹ. Ẹ jẹ ka ṣe agbeyẹwo iye igba ti South Africa ati Naijiria ti koju ara wọn: Oríṣun àwòrán, other Ọdún naa ni igba akọkọ ti ẹgbẹ́ agbabọọlu mejeeji koju ara wọn ninu idije bọọlu awọn obinrin ni Africa. Ewuro ayo mẹrin si odo ni Naijiria gbo si South Africa lẹ́nu, ni papa ìṣeré n'ilu Ibadan. Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ naa ni abala akọkọ ni ipele aṣekagba idije WAFCON lọdun 1995. Ọdún naa paapaa ni igba àkọ́kọ́ ti Bayana Bayana kopa ninu idije naa. Boya nitori naa ni Naijiria fi lu wọn lalu bolẹ. Naijiria ko fi mọ nibẹ, nigba ti wọn tun jọ pade n'ilu Johannesburg lorile-ede South Africa, ami ayo meje si ẹyọkan ni Naijiria fi fọ́ South Africa mọ ilé baba wọn. Oríṣun àwòrán, caf A fi bi ẹni pe wọn fi ẹgba iya le Super Falcons Naijiria lọwọ lati ma a fi lu South Africa ni. Ninu idije wafcon to tun waye lọdun 2000, wọn tun jọ pade. South Africa gbiyanju, wọn faraya bii ki wọn o gba ẹsan ìyà meji àkọ́kọ́, àmọ́ Naijiria tun rún wọn mọ́lẹ̀ nilẹ baba wọn, nibi ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ to waye n'ilu Boksburg. Àwọn agbabọọlu Naijiria méjì,Olaitan Yusuf and Stella Mbachu lo rọ̀jò iya le Bayana Bayana lori.   Oríṣun àwòrán, other Naijiria ati South Africa pade fun igba kẹrin lọjọ kejidinlogun, oṣu Kejila, ọdun 2002, ni idije wafcon. Ipele semi-final ni wọn ti pade, lẹyin ti Bayana Bayana borí ni ìpín B, nibi ti wọn wa pẹlu Cameroon, Angola, ati Zimbabwe. Papa ìṣeré to wa n'ilu Warri, nipinlẹ Delta, ní Super Falcons ti lọ wọn mọlẹ bi ata irẹsi eléwé. Oríṣun àwòrán, other Fun igba akọkọ, ẹgbẹ́ agbabọọlu mejeeji pade ni ibẹrẹ pẹpẹ idije WAFCON lọdun naa. Naijiria lo bori. Wọn tun jọ pade fun igba kejì ninu idije naa ni ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ to kẹhin ni ìpín tí wọn pin wọn si, group stage. Ami ayo meji si odo ni Naijiria tun fi bori wọn. Oríṣun àwòrán, nff Ọdún yii ni igba àkọ́kọ́ ti Naijiria ko gba ife ẹyẹ WAFCON. Orile-ede Equatorial Guinea nì idije naa ti waye lọdun 2008.  Ipo kẹta ni Naijiria ṣe. Àmọ́ ibẹrẹ pẹpẹ idije naa ni àwọn ati South Africa ti pade ni papa ìṣeré Estadio La Libertad, Bata. Ami ayo kan si odo ni wọn gbá. Oríṣun àwòrán, nff Àgbò to tàdí mẹ́yìn, agbara lo lọ mu wa ni ọrọ Naijiria ni WAFCON 2010.  South Africa wa lara awọn ti wọn fi iya jẹ, ti wọn tun fi rí ife ẹyẹ idije naa gba lẹẹkan si i.  Wọn dáná ami ayo meji si ẹyọkan si wọn lara nilẹ baba wọn ni papa ìṣeré Sinaba Stadium.​ Oríṣun àwòrán, nff Fun igba àkọ́kọ́, ninu itan wafcon, South Africa fi ẹyin Naijiria janlẹ pẹlu ami kan si odo.  Lílù ti Bayana Bayana naa wọn, ja wọn danu ṣáájú ki idije to wọ semi-final.  Equatorial Guinea lo tun gba ife ẹyẹ fun igba keji lọdun naa. Ṣe ẹ o gbagbe pe South Africa lo ja Naijiria kuro ninu idije naa, pẹlu ami ayo kan si odo. Wọn o de ipele semi-final. Ikanra ni Asisat Oshoala fi gbẹsan lara South Africa nigba ti wọn pade ni Windhoek, nigba ti wọn jọ pade. Ipele aṣekagba idije naa ni wọn tun ti pade, lẹyin naa. Ami ayo méjì si odo ni Naijiria fun wọn ni papa ìṣeré Sam Nujoma, ti wọn tun fi gba ife ẹyẹ. Wọn tun jọ pade ni ipele semi-final ni wafcon to waye ni Cameroon lọdun 2016. Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ naa gbona pupọ, ṣùgbọ́n Naijiria pada bori pẹlu ami kan si odo nigba ti ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ wọ isẹju mẹrinlelaadọta. Oríṣun àwòrán, caf Lọtẹ yii, àwọn agbabọọlu obìnrin South Africa ko ṣeré rara. Àwọn pẹlu Naijiria lo jọ koju ara wọn ni ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ àkọ́kọ́, nibi idije WAFCON to waye ni Ghana, Ghana 2018. Ami ayo kan si odo ni South Africa fun Naijiria. Igbẹyin ni alayo n ta ni Super Falcons fi ọ̀rọ̀ ṣe nigba ti wọn jọ tun pade ni idije aṣekagba.   Ọmi òdo ni wọn jọ kọ́kọ́ ta. Ṣugbọn Naijiria bori pẹlu ami mẹrin si mẹta nigba ti wọn gba pẹnariti. Ọdún naa ni igba kẹsàn-án ti Naijiria gba ife ẹyẹ WAFCON.  Taa ni yoo bori ni ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ wọn àkọ́kọ́ ni Morocco?",3 Agẹmo 2022 +"Ìdíje bọ̀ọ́lù àwọn obìnrin, WAFCON 2022 gbérasọ ní Morocco"," Oríṣun àwòrán, cafonline Ọjọ keji, oṣu Keje, ọdun 2022, ni idije fun ife ẹyẹ bọọlu awọn obinrin ni Afrika, Women's Africa Cup of Nations, yoo bẹ̀rẹ̀ ni orile-ede Morocco. Ti ọdun yii si ni igba akọkọ ti orile-ede mejila n kopa ninu idije naa. Saaju asiko yii, orile-ede mẹ́jọ lo ma ń kopa. Bakan naa lo jẹ pe igba àkọ́kọ́ re e ti Morocco gbalejo idije naa. Papa ìṣeré mẹta ni yoo ti waye, n'ilu Rabat olu ilu Morocco, ati ilu Casablanca laarin ọjọ keji oṣu Keje, si ọjọ kẹtalelogun, oṣu Keje. Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ akọkọ lati ṣide yoo waye laarin Morocco ati Burkina Faso ni papa isere Prince Moulay Abdellah n'ilu Rabat. Oríṣun àwòrán, caf Ẹgbẹ agbabọọlu Naijiria, Super Falcons, lo gba ife naa ni idije mẹta to kọja, wọn si ti gba a nígbà mẹsan-an, ninu igba mọkanla ti idije naa ti waye. Ipin C ni Naijiria wa ninu idije ti ọdun yii. Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ wọn àkọ́kọ́ yoo waye lọjọ Aje pẹlu orile-ede South Africa. Lẹyin naa ni wọn o koju Botswana ati Burundi. Ohun kan to jẹ mímọ̀ ni pe lati ìbẹ̀rẹ̀ ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ wọn àkọ́kọ́, ni Super Falcons ti ma n gba jọba idije. Àwọn agbabọọlu Naijiria to n sisẹ nilẹ okeere, pọ laarin àwọn ọmọ ikọ Super Falcons. Lara wọn ni Asisat Oshoala, ọmọ ẹgbẹ́ agbabọọlu Spain. Oun naa ni balogun ikọ Super Falcons. Ni opin idije WAFCON 2022 yii, ẹgbẹ́ agbabọọlu orile-ede to ba bori yoo ni anfaani lati kopa ni idije ife agbaye lọdun to n bọ. Bakan naa, orile-ede mẹrin to ba de ipele to kangun si aṣekagba, semi-final, yoo ni anfaani lati lọ si Australia ati New Zealand. Ẹgbẹrun lọ́nà ẹẹdẹgbẹta Dọla ni ẹ̀bùn owo ti orile-ede to ba borí ni WAFCON 2022 yoo gba.",2 Agẹmo 2022 +Ìjọba Nàìjíríà yí ìpinnu rẹ̀ padà lórí àjọ eré ìdárayá bọ́ọ̀lù alápẹ̀rẹ̀ tó bẹ́gilé tẹ́lẹ̀," Oríṣun àwòrán, D'tigers/nigeria basketball Ijọba orile-ede Naijiria ti yi ìpinnu pada lori ere idaraya gbigbabọọlu sáwọn lẹyin ti wọn yoo ọwọ ninu ifieyẹ agbaye losu to lọ. + + Ajọ to rí sì ere idaraya ati oun to jọ mọ awọn ọdọ lorile-ede Naijiria ni awọn o ni kopa ninu ifesewonse kankan latari iṣẹlẹ kan to waye ni apa guusu ilẹ adulawo. + + Ajọ naa ni ìpinnu awọn ni aṣẹ aarẹ Muhammad Buhari latari igbinyanju ijọba lati ṣe amujuto ere idaraya naa lati ẹsẹ kuku ati lati ṣe àtúnṣe si. + Iyiyi ìpinnu naa pada waye lẹyin Ipadẹ laarin àjọ agbaye ere gbigbabọọlu sáwọ, FIBA ati minisita ajọ to rí sì ere idaraya ati oun to jọ mọ awọn ọdọ lorile-ede Naijiria, Sunday Dare. + + Yiyi ìpinnu naa pada túmọ̀ si orile-ede Naijiria yoo ni anfani lati kopa ninu ere idaraya gbigbabọọlu sáwọn ti Ile adulawo ti yoo waye ni orile-ede Rwanda losu to bo, nibi ti wọn ti koju Mali, Uganda ati orile-ede Cape Verde. + + +Iko D'Tigers ni o le tente tabili lẹyin ifesewonse akoko ninu oṣu November",23 Òkùdu 2022 +Òṣìṣẹ́ ètò ìlèra yóò jẹ́jọ́ lórí ikú Maradona," Oríṣun àwòrán, real Madrid Òṣìṣẹ eto Ilera mẹjọ ni wọn yoo ma jẹjọ lori iku atamatase ọmọ orile-ede Argentina, Diego Maradona latari bi wọn o ṣe kọbiara si eto Ilera rẹ + + +Adajọ lọ pàṣẹ jẹjọ naa lẹyin ti awọn igbimo eto Ilera ni itọju Maradona ni awọn ko lofin ninu. + + Maradona, ẹni ogota ọdun ni osaliasi ni oṣu kokanla ọdun 2022 lẹyin niluu Buenos Aires. + iwadi fihan pe Maradona tí n ri iwosan ni ile lẹyin ti wọn ṣe iṣẹ́ abẹ fun ninu oṣu naa. + Lẹyin ọjo diẹ tí Maradona ku ni awọn agbejoro rẹ gbe igbimo kalẹ lati ṣe iwadi nipa awọn dokita ati nusi to wa ni ìṣàkóso itọju rẹ. +Mario Baudry, Agbejoro fun ọkan lara awọn ọmọ ologbe naa, ni pe ""ni asiko ti +olojọ dẹ, ko ri iranlowo ẹnikẹ́ni."" + ""Kete ti mo rí nkan to fa okunfa ikú naa, ni mo ti ni ó ní ọwọ ko lofin ninu."" + +Ọdún to lọ ní gbimo ẹlẹni ogún níye láti woo irúfé ikú to pa Maradona, ti iwadi si fihan pe Maradona, ti o ba ri itọju to pe ye gba, ko ba iku. + +Ọjọ ti ijẹjọ naa ni o ti mo ṣùgbọ́n ti awọn òṣìṣẹ eto Ilera ba jẹbi ẹsun naa, wọn yoo fi ẹwon ọdun medogbon gbara",23 Òkùdu 2022 +"'Wọ́n sọ fún ìyà mi kó jù mi nù nígbà tí mò ń fi àyà fà bí ejò àmọ́ mo di àrídunú pẹ̀lú gbígbé ""weight"""," Ami ẹyẹ ti Bose Omolayo ti gba gẹgẹ bi elere idaraya to n gbe irin kii ṣe kekere koda o ti rinrinajo lọ si ọpọ orilẹede kaakiri agbaye bayii. Nigba kekere rẹ gẹgẹ bo ṣe sọ iriri to ni ni awọn kan ti sọ fun iya rẹ pe ko lọ ju u nu tori pe ""ọmọ to n fi aya fa ko lee di nkankan laye"". Arabinrin Bose Omolayo sọ fun BBC Yoruba bi o ṣe padanu ẹsẹ rẹ ni kekere ni nkan bii ọdun mejila amọ ko jẹ ki eyi dii lọwọ lati sọ ala rẹ di mimu ṣẹ gẹgẹ bi elere idaraya. Ni bayii, inu rẹ dun pe o ti n gbe igbe aye to wu u bayii ti inu rẹ si dun si iṣẹ to yan laayo. Ẹ wo tọkọ-taya tó ní ìpèníjà ẹsẹ̀ àmọ́ tí wọn kọ̀ láti ṣe agbe jẹun 'Dokita ilé ìwòsàn ló gba ẹsẹ̀ lọ́wọ́ mi' Wo àṣírí nkan tó gba ẹsẹ̀ kan lọ́wọ́ Jigan Baba Oja Bakan naa ni o dupẹ pe o pada ri ọkọ fẹ to tun jẹ Ojiṣẹ Ọlọrun. Bakan naa lo bi ọmọ. ""Inu mi kan maa n dun ti mo ba ri awọn ọmọ ti mo bi toripe wọn ti kọkọ ni mi o ni le bimọ"". Bose mu iranti wa ni igba to bẹrẹ gbigbe irin gẹgẹ bi iṣẹ lẹyin to ti foju ri oniruuru ipenija laye rẹ bo ṣe n dagba. 'Àwa ni ""Zama Zama""! À ń gbé labẹ́ ilẹ̀ láti wa góòlù jáde àmọ́ bí ikú ṣe ma ń mú wa lọ rèé' Ṣé lóòtọ́ ni Jonathan ti gbẹ̀yìn darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ APC? Nkan tí PDP àti APC sọ rèé O ranti awọn to gba iya rẹ nimọran lati lọ ju oun sori akitan tori wọn ni oun ko le da nkankan laye amọ iya rẹ kọ eti ikun si wọn to si tii lẹyin titi to fi di eeyan. Bakan naa lo ranti ẹni to fi gbigbe irin lọ ọ ti ko si lee gbagbe laye laye tori oun naa ti di ẹni to n rinrin ajo lọ soke okun lẹnu iṣẹ yii ti o si ti gba ami ẹyẹ pupọ.",3 Òkùdu 2022 +"Buhari yọ ikọ̀ D'Tiger, D'Tigress kúrò nídíje bọ́ọ̀lù alápẹ̀rẹ̀ lágbáyé fún ọdún méjì, ohun tó fàá nìyí"," Oríṣun àwòrán, D' Tigers/Nigeria Basketball Ijọba apapọ Naijiria ti pinnu lati yọ ikọ agbabọọlu alapẹrẹ, (Basket ball) Naijiria ko gbọdọ kopa ni idije agbaye kankan fun ọdun meji Bakan naa nijọba tun fẹ tu ajọ bọọlu alapẹrẹ NBBF ka nitori wahala adari to n suyọ nibẹ. Ileeṣẹ ere idaraya ati idagbasoke awọn ọdọ lorilẹede Naijiria lo paṣẹ yii ti aarẹ Muhaamadu Buhari si buwọlu u. Lẹta kan ti ileeṣẹ ere idaraya ijọba apapọ Naijiria kọ ṣalaye ohun top ṣokunfa igbesẹ naa. O ni pe wọn yọ ọwọ awọn ikọ ọkunrin ati obinrin agbabọọlu apẹrẹ naa kuro lawọn idije bọọlu alapẹrẹ lagbaye nitori""oniruuru wahala ati awuyewuye to n waye eyi to ti ""fẹrẹ sọ ere idaraya bọọlu alapẹrẹ di ẹdunarinlẹ"" ni Naijiria. ""Eyi yoo fun Naijiria laaye lati tun ile rẹ to lẹka bọọlu alapẹrẹ bẹrẹ lati ẹsẹ kuku titi kan awọn liigi abẹle rẹ gbogbo. Alaafin stool: Wo ẹni tó ṣeẹṣe pé kí Aláàfin kàn lẹ́yìn ìpapòdà Oba Lamidi Adeyemi Ohun to han si BBC ni pe wọn gbe igbesẹ yii lati dena ipinnu awọn agbabọọlu apẹrẹ Naijiria lati wọde lawọn idije agbaye kan tako ajọ naa ati ijọba. Bakan naa ni inu awọn alakoso ileeṣẹ ere idaraya ni Naijiria ko dun si bi awọn agbabọọlu alapẹrẹ ṣe n da siedeaiyede to n waye laarin awọn adari lajọ ere bọọlu alapẹrẹ Naijiria ti wọn si n gbe lẹyin igun kan ninu edeaiyede naa. Oríṣun àwòrán, D' Tigers/ Nigeria Basketball Labẹ ofin ajọ ere bọọlu alapẹrẹ lagbaye, FIBA, ajọ naa koro a maa koro oju si awọn orilẹede yoowu ti ijọba ba ti n da si ọrọ iṣakoso awọn ikọ agbabọọlu alapẹrẹ nibẹ. Mathew Okotie, Driver who returned laptop: Ṣé àwọn awakọ̀ olóòtọ́ ṣi kù ní Nàìjírípa? Igbesẹ ti ijọba orilẹede Naijiria gbe yii lee mu ki ajọ FIBA gbegile orilẹede Naijiria lagbo ere idaraya bọọlu alapẹrẹ lagbaye- eyi si lee tumọ̀ si pe aikọ agbabọọlu alapẹrẹ orilẹede Naijiria, awọn ẹgbẹ agbabọọ̀lu alapẹrẹ gbogbo atawọn oṣiṣẹ rẹ gbogbo ko ni lanfani si awọn idije agbaye gbogbo ati ipade wọn. BBC ti kan si ajọ FIBA fun alaye lori eyi. Oríṣun àwòrán, D' Tigers/ Nigeria Basketball Itumọ eyi ni pe ikọ agbabọọlu alapẹrẹ obinrin Naijiria ko ni lee kopa nibi idije ife ẹyẹ agbaye fawọn obinrin agbabọọlu alapẹrẹ ti yoo waye lorilẹede Australia loṣu kẹsan an ọdun 2022. Iyabo Anisulowo:Ẹ̀yin ọ̀dọ́ Nàìjíríà, ẹ má bínú, kò rọrùn fún ọ̀dọ́ láti dìde nínú ìṣèlú Kan lara awọn agbabọọlu alapẹrẹ Naijiria, Upe Atosu ni ibanujẹ ọkan nla ni igbesẹ naa jẹ fun wọn ati pe o yẹ ki ijọba atawọn alaṣẹ ere idaraya ni Naijiria o mọ pe ere idaraya kii ṣe ayo ọlọpọn ti eeyan a daaru ki o to tun un to. ""Ọna to dara julọ lati yanju ọrọ yii kọ niyi."" Oríṣun àwòrán, D' Tigers/Nigeria Basketball Awuyewuye eto idibo sipo awọn alakoso ajọ ere bọọlu alapẹrẹ orilẹede Naijiria, NBBF to waye lọdun mẹfa sẹyin lo ṣokunfa wahala laarin awọn alakoso nibẹ. Lọpọ igba si ni wahala ti fẹrẹ da igbaradi awọn agbabọọlu alapẹrẹ naa fun awọn idje agbaye gbogbo ati liigi rẹ labẹle ru. Ó yẹ kí a wádìí ikú tó pa Oba Lamidi Adeyemi, Baba gbọ́dọ̀ padà- Sat Guru Maharaj-ji Wahala naa tun ṣe akoba fun owo oṣu akọnimọọgba ikọ obinrin agbabọọlu alapẹrẹ Naijiria, Otis Hugley to ko ikọ naa lọ kopa fun ati pegede fun ere idaraya agbaye Tokyo 2020, ife ẹyẹ ilẹ adulawọ fawọn ikọ agbabọọlu alapẹrẹ ati ife ẹyẹ agbaye ti ọdun 2022 titi kan bibori France pẹlu. Osun spider man: Mo ń ṣe ìtanijí láti gbógunti ìdọ̀tí láwùjọ ló sún mi dé ìdí 'Spider man' Bakan naa lawọn agbabọọlu alapẹrẹ lobinrin pẹlu n waako pẹlu ajọ to n ṣakoso ere bọọlu alapẹrẹ ni Naijiria, NBBF ati ileeṣẹ ere idaraya lori kikuna lati san owo ajẹmọnu wọn tawọn wahala to nii ṣe pẹlu iṣakoso ikọ naa lasiko ti wọn lọ kopa ni idije Olimpiiki lorilẹede Japan. Ó gbé owó fún mi, ó tún ra fóònù ńlá fún mi - Bàbá Onílù Ibadan sọ bó ṣe pàde Àgùnbánirọ̀ tó dáa lọ́lá",13 Èbibi 2022 +Jurgen Klopp tọwọ́ bọ̀wé àdéhùn tuntun pẹ̀lú Liverpool di 2026," Oríṣun àwòrán, Getty Images Akọnimọọgba ẹgbẹ agbabọọlu Liverpool, ti buwọlu adehun afikun ọlọọdun meji kun adehun rẹ to wa nilẹ tẹlẹ pẹlu ẹgbẹ agbabọọlu naa. Lọdun 2024 lo yẹ ki adehun rẹ to wa nilẹ tẹlẹ pari, ṣugbọn adehun tuntun to fọwọsi bayii ti sun un di ọdun 2026 bayii. Ni ọdun 2015 ni Klopp darapọ mọ Liverpool ki o to sọ ọ bi ẹna loṣu kẹta ọdun 2022 pe o ṣeeṣe ki oun gba isinmi kuro lẹnu iṣẹ akọnimọọgba lasiko ti saa adehun oun ba pari lọdun 2024. Ife ẹyẹ marun ni Klopp ti gba pẹlu Liverpool lati igba to ti dara pọ mọ wọn. Nigba to darapọ mọ ẹgbẹ agbabọọlu naa lọdun 2015, Klopp ṣeleri ati mu idunnu wa fawọn ololufẹ agbabọọlu naa lati mu wọn di ẹni to ni igbagbọ to jinlẹ ninu ilepa ikọ agbabọọlu naa lati ṣe aṣeyọri. Nigba naa, Liverpool ko tii gba ife ẹyẹ liigi ilẹ Gẹẹsi lati ọdun 1990. Klopp ko ikọ naa sodi gba ife ẹyẹ Champions League Yuroopu ni saa liigi ọdun 2018 si 2019 ki o to ko wọn sodi gba ife ẹyẹ liigi lọdun 2020. Oríṣun àwòrán, Getty Images Nigba to n buwọlu adehun tuntun naa, Klopp ni ""inu oun dun, ayọ oun kun, oun si rii gẹgẹ bi anfani nlanla"" Klopp fi kun un pe "" Nigba tawọn to ni ẹgbẹ agbabọọlu naa mu aba adehun tuntun tọ mi wa, mo bi ara mi leere ibeere ti mo maa n beere ni gbangba lọpọ igba. Ṣe mo ni agbara ati okun lati ṣiṣẹ naa lẹẹkansi lati ṣe awọn ohun ti ẹgbẹ agbabọọlu to dara yii nilo latọdọ ẹni to di ipo akọnimọọgba mu?"" ""Ko gba mi lọpọ akoko lati ri idahun sii..ifẹ ibi yii ti gba ọkan mi."" Bakan naa lawọn amugbalẹgbẹ rẹ, Pep Lijnders ati Peter Krawietz naa ti tọwọ bọ iwe adehun tuntun pẹlu.",28 Ìgbé 2022 +"Láì tíì pé ọ̀sẹ̀ kan tó kéde akọ́nimọ̀ọ́gbá tuntun, Man U tún jẹ àjẹranjú ìyà lọ́wọ́ Arsenal pẹ̀lú góòlù Mẹ́ta sí ẹyọkan"," Oríṣun àwòrán, Premierleague.com Ọsẹ yii ṣẹnuure fun ikọ agbabọọlu Arsenal atawọn ololufẹ rẹ pẹlu bi wọn tun ṣe digbolu Manchester United lọsan ọjọ Abamẹta pẹlu goolu mẹta si ẹyọkan. Iṣẹgun ti Arsenal ri lori Manchester United yii lo gbe wọn lọ si ipo kẹrin ṣaaju Totteham to ṣi ni ifẹsẹwọnsẹ tiwọn lọsan ọjọ Abamẹta kan naa. Nuno Tavares lo kọkọ ṣide ojo goolu to rọ fun Arsenal nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa wọ iṣẹju naa wọ iṣẹju kẹta. Laipẹ rẹ nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa wọ iṣẹju kejilelọgbọn ni Busayọ Saka ba tun fọba lee pẹlu pẹnariti lẹyin ti wọn gbe e ṣubu loju ile Manchester United. Christiano Ronaldo, to ṣẹṣẹ pada sori papa lẹyin to padanu ọmọ rẹ ọkunrin laipẹ yii, da ẹyọ kan pada ki Bruno Fernades to sọ pẹnariti nu fun Manchester United lẹyin ti Tavares fi ọwọ gbe bọọlu loju ile Arsenal. goolu ti Christiano Ronaldo gba wọ awn Arsenal yii ni yoo di goolu ọgọrun ti gbajumọ agbabọọlu naa yoo maa gba wọ awọn ni idije Premier league. Ni ọjọ kini oṣu kọkanla ọdun 2003, tii ṣe ọdun marundinlogun sẹyin ni C. Ronaldo kọkọ gba goolu si awọn ni idije Premier League ninu ifẹsẹwọnsẹ Manchester United pẹlu Portsmouth ni gbede Old Trafford Oríṣun àwòrán, Getty Images Granit Xhaka lo pa oju goolu de pẹlu bọọlu to gba sawọn eyi ti ọwọ gooli manchester United, David De Gea ko to. Ten Hag ni yoo maa ṣakoso ikọ naa ni saa to n bọ. Esi ifẹsẹwọnsẹ Manchester united pẹlu Arsenal yoo si wa lara awọn ohun ti yoo maa gbe yẹwo lati mọ pe omi n bẹ laamu fun oun lasiko to ba bẹrẹ iṣẹ pẹlu wọn.",23 Ìgbé 2022 +Kílódé tí wọ́n ti ìlẹ̀kùn mọ́ Super Falcons ni pápákọ̀ òfurufú l'Abuja?," Oríṣun àwòrán, Credit/Nigeria Super Falcons/Instagram Ẹgbẹ agbabọọlu obinrin fun Orile-ede Naijiria, Super Falcons pada si Naijiria ni Ọjọbọ Eyi waye lẹyin ti wọn lu ẹgbẹ agbabọọlu Ivory Coast pẹlu ami ayo mẹta sodo lati pegede fun idije ere bọọlu awọn obinrin nilẹ Afirika, AWCON. Ṣugbọn oju wọn ri to nigba ti baalu to gbe wọn pada si Naijiria balẹ ní papakọ ofurufu ilu Abuja. Fidio kan to lu ayelujara pa ṣàfihàn bi wọn ko ṣe ri ọna kọja kuro ni papakọ ofurufu naa. Wakati melo ni won fi da awon agbabọólu wa duro? Iroyin sọ pe wakati mẹta ni wọn fi wa ni papakọ ofurufu naa lai raye jade. Agbabọọlu kan lara wọn, Uchenna Kalu tiẹ sun silẹ ninu irora to sí dabi ẹni pe o ni k'awọn oṣiṣẹ eleto tọju rẹ. Awọn agbabọọlu n fi ibinu sọrọ ninu fidio ọhún lori ohun ti oju wọn ri papakọ ofurufu. Ohun ti a gbọ pe o ṣẹlẹ ni pe eto lori ilana covid 19 lo fa idaduro naa fun ni papakọ ofurufu Abuja. Diabetes Ulcer -Ajọ FAAN sọrọ lori idaduro Super Falcons ni papakọ ofurufu Abuja Oludari ajọ FAAN to n ri si ọrọ papakọ ofurufu ni Naijiria, Henrietta Yakubu, ajọ NCDC to n gbogun ti ajakalẹ arun ati ajọ eleto abo, AVSEC lo dena mọ Super Falcons lẹyin ti wọn tako ilana ati dẹkun covid 19. Arabinrin Yakubu ni ẹgbẹ agbabọọlu Super Falcons kọ lati san owo to yẹ ki wọn san fun NCDC lori ọrọ coronavirus nigba ti wọn de sí Abuja lati Ivory Coast. O ṣalaye pe awọn agbabọọlu naa ni wọn fẹ gb'owo ẹyin lọwọ awọn ni. Akàwégboyè alákàrà Kini Minista tun sọ? Yakubu ni ""awọn mii rin lọ si ibi to wu wọn, ṣugbọn wọn ni lati pada wa san owo naa lẹyin ti ilẹkun wa ni titi. Bukola Odufuwa: Mo ń ta oúnjẹ fáwọn akẹ́kọ̀ọ́, gbálẹ̀, fọ aṣọ, pọnmi láì tọrọ agbe jẹun Ẹwẹ, minisita ere idaraya, Sunday Dare ati aarẹ ajọ elere bọọlu NFF, Amaju Pinnick ti bu ẹnu atẹ lu iṣẹlẹ naa. Ajọ NFF ni ohun gbogbo to yẹ ki Super Falcons ṣe ní wọn ṣe nigba ti wọn de si papakọ ofurufu ilu Abuja. Minisita ti wa sọ pe ajọ NCDC ni lati ṣe iwadii iṣẹlẹ naa ni kiakia.",25 Èrèlè 2022 +Wọ́n ti fi orúkọ Sadio MAne sọ pápá ìṣeré kan ní Senegal," Olootu ijọba ni ẹkun Sedhiou, lorilẹ-ede Senegal, ti ṣetan lati fi orukọ ongbatarigi agbabọọlu ẹgbẹ Liverpool, Sadio Mane, sọ papa isẹre to wa ni ẹkun naa. Agbabọọlu naa lo gba goolu pẹnraiti sinu awọn lasiko ti Senegal koju Egypt ni aṣekagba idije AFCON 2022 to sẹṣẹ pari, eyi to mu ki wọn o jawe olubori. Ami ayo mẹrin si meji ni Terenga Lions ti Senegal fun Egypt. Igba akọkọ si re e ti orilẹ-ede naa gba ife idije AFCON. Olooru ijọba ni Sedhiou, Adboulaye Diop, sọ pe oun pinnu lati fi orukọ Mane sọ papa iṣere Sate de Sédhiou, lati fi ẹmi imoore awọn ọmọ bibi agbegbe naa han si ""ọkunrin to n fi igbe aye rẹ sin ọmọniyan"". ""Sadio Mane tọ si pe ka bu ọla fun un"". OAU student's death: O dun OAU pé Heritage kú, agbìyànjú láti gbé e délé ìwòsàn ṣùgbọ́n... Asiko diẹ sẹyin ni Mane di aayo lọkan ọpọ miliọnu eeyan ni ilu abinbibi, nigba to jẹjẹ owo lati fi kọ ileewosan ati ile ẹkọ fun wọn. O tun da owo si kikọ awọn mọṣalaaṣi, to si tun fun ijọba lowo lati gbogun ti ajakalẹ aarun Covid-19. Yatọ si eyi, Mane tun pin aṣọ ẹgbẹ agbabọọlu Liverpool fun awọn ara ilu abinibi rẹ, Bambali, ki wọn o ri nkan wọ lasiko aṣekagba idije Champions League ni oṣu Karun-un, ọdun 2018. 'Ìyá Tíṣà lòdì sí kí n mutí, fagbó tàbí sìgá' Lẹyin ti ikọ ẹgbẹ agbabọọlu Senegal bori ni Afcon lorilẹ-ede Cameroon, Mane sọ pe bi oun ṣe gba akọkọ ife ẹyẹ idije naa fun Senegal, jẹ aṣeyọri to tobi ju ninu irinajo oun gẹgẹ bi agbabọọlu. Plights of Widows in Nigeria: Abosede Ilori ní N16,000 ni òun ń gbà fi tọ́jú ọmọ méjì",14 Èrèlè 2022 +Ta ni yoo gba ife ẹyẹ AFCON laarin Mane ati Salah?," Oríṣun àwòrán, John Powell/Getty Image Ifẹsẹwọnsẹ aṣekagba jẹ eleyi ti ọpọ maa n foju sọna fun ninu idije Afcon to maa n waye nilẹ Afrika. Ti ọdun yii ko yatọ si tatẹyinwa. Koda oju awọn ololufẹ ere bọọlu n bẹ lọna nitori awọn ikọ meji to rapala de aṣekagba yii, ina piti ni wọn. Egypt ati Senegal ni yoo dijọ waako lọjọ Aiku lati mọ ẹni ti wọn yoo de lade Ọba ere bọọlu ni Afrika. Ni bayi, wọn ti gba ifẹsẹwọnsẹ mọkanlelaadọta ninu idije Afcon Cameroon 2021, ti papa iṣere Paul Biya to wa ni Olembe yoo si gbalejo asekagba naa. Ẹ jẹ ki a se agbeyẹwo awọn ikọ mejeeji ati iru aṣeyọri ti wọn ti ni ṣẹyin ṣaaju ifẹsẹwọnsẹ yii. Oríṣun àwòrán, Shaun Botterill/Getty Image Odu ni Egypt nibi ka maa gba ife ẹyẹ Afcon: Ni meni meji, ba ba ni ka maa ka, Egypt ti gba ife ẹyẹ Afcon ni igba meje ọtọọtọ. Ninu akọsilẹ, ko si orileede miran ni Afrika to sunmọ wọn tabi to gba ife ẹyẹ yii ju wọn lọ. Ọdun 2010 ni wọn gba ife ẹyẹ naa kẹyin pẹlu bi wọn ti ṣe fagba han Black Stars Ghana pẹlu goolu kan sodo ninu aṣekagba. Ninu ifẹsẹwọnsẹ ti wọn gba lati le fi kopa ninu idije Afcon, ta mọ si ''qualifiers'' ami ayo mejila ni wọn ko jọ ninu ifẹsẹwọnsẹ mẹfaa. Wọn lewaju isọri Keje lati le fi kopa ninu idije Afcon 2021. Nigba ti wọn de idije naa, Naijiria da wọn lagbo sina pẹlu goolu kan sodo ninu ifẹsẹwọnsẹ akọkọ isọri kẹrin. Ifidirẹmi yii dabi ẹni pe wọn ko ni tẹsiwaju ṣugbọn wọn gbọnra nu, ti wọn si gbiyanju titi ti wọn fi de aṣekagba. Senegal naa ko kẹrẹ, o ni atamátàsé ati adẹ̀yìnmú gidi: Orileede Senegal le ma gborukọ lori bi ti Egypt ṣugbọn awọn naa kii se aimọ lawujọ awọn orilẹede agbabọọlu ni Afrika. Ninu ifẹsẹwọnsẹ mejila ti wọn gba lera wọn, wọn ko fidi rẹmi ninu wọn. Wọn jawe olubori ninu mẹsan, wọn si gba ọmi ninu mẹta. Goolu mẹrinlelogun ni wọn ti jẹ lati oṣu Keje ọdun to kọja ninu awọn ifẹsẹwọnsẹ ti wọn kopa ninu rẹ, ti goolu mẹfa pere si wọle si awọn wọn. Bi a ba ni ka sọ nipa ikọ to ni atamatase ati awọn adẹyinmu ti ko kẹrẹ rara, Senegal jẹ ikọ to duro wamu wamu. Lọdun yii ohun to wa lọkan wọn ni bi wọn yoo se ṣaseyọri ninu aṣekagba. 'Ìgbà mẹẹ̀dógún ni mo ti ṣẹ́ oyún' Lọdun 2002, Cameroon lo fidi wọn rẹmi ninu aṣekagba nipa pẹnariti, ti Algeria naa si gbewuro soju wọn ni Egypt pẹlu goolu kan sodo. Ninu irinajo wọn de aṣekagba lọdun yii, wọn ko jẹ goolu pupọ ni ipele kini ṣugbọn wọn tẹsiwajulati leke isọri keji. Igba ti wọn de abala komẹsẹoyọ ni wọn bẹrẹ si ni pitu. Goolu meji ni wọn fi da bantẹ iya fun Cape Verde lati ọwọ Sadio Mane ati Ahmadou Bamba Dieng. Equitorial Guinea naa gba igbaju ati igbamu lọwọ wọn pẹlu goolu mẹta sookan. Nigba ti Burkina Faso koju wọn ni abala to kangun si aṣekagba, goolu mẹta sookan lawọn naa fi gbara. Nkan to ku bayi ni ki wọn koju Egypt ni aṣekagba. Boya wọn yoo gba ife yẹ Afcon ni igba akọkọ ninu itan orileede wọn. Bo ti lẹ jẹ wi pe orileede meji ni yoo koju ara wọn, orukọ awọn agbabọọlu mejeeji yii, Sadio Mane ati Mo Salah lawọn eeyan n ran lẹnu. Idi ni pe awọn mejeeji jijọ n ṣe ọrọ aje pẹlu ẹgbẹ agbagbọọlu Liverpool nilẹ Gẹẹsi ni. Atamatase lawọn mejeeji, ti wọn si ti jijọ gba ami ẹyẹ agbabọọlu to pegede julọ ni Afrika. Ti Senegal yoo ba bori Egypt, Sadio Mane yoo ni ipa ribiribi lati ko nipa didoju ija kọ awọn adilemu Egypt. Amọ Salah naa ko ni gbẹni wa nitori pe oun naa yoo ja fita fita lati se bii ọkunrin. Ipade wa di ori papa nirọlẹ oni lati mọ irin ti yoo tẹ fun ekeji laarin ikọ Egypt ati Senegal, Sadio Mane ati Mo Salah, ẹ ku oju lọna. Jejere",6 Èrèlè 2022 +Senegal àti Egypt yóò wáàkò fún tíkẹ́ẹ̀tì ife ẹ̀yẹ àgbáyé Qatar 2022," Oríṣun àwòrán, Senegal football Ẹgbẹ agbabọọlu Senegal ati Egypt ni yoo koju ara awọn ninu ifẹsẹwọnsẹ ati pegede fun idije ife ẹyẹ agbaye ni Qatar lọdun 2022 yii. Eyi tumọ si pe Mohamed Salah ati Sadio Mane ti wọn jọ jẹ ọmọ agbabọọlu Livrepool yoo koju ara wọn. Ikọ Super Eagles Naijiria yoo koju Black Stars Ghana ninu ifẹsẹwọnsẹ ati pegede fun idije ife ẹyẹ agbaye ti yoo waye ni Qatar lọdun 2022 yii. Lonii ọjọ Abamẹta niluu Douala ni Cameroon wọn kede bi awọn ifẹsẹwọnsẹ naa yoo ṣe lọ nilẹ Afirika. Laarin ọjọ kọkanlelogun si ọjọ kọkandinlọgbọn ni ifẹsẹwọnsẹ mejeeji gbọdọ waye laarin Naijiria ati Ghana. Ninu awọn ifẹsẹwọnsẹ mii, Mohamed Salah ati Sadio Mane yoo koju ara wọn nigba ti Egypt ati Senegal yoo maa waako. Cameroon to n gbalejo idije AFCON lọwọ yoo maa na tan bi owo pẹlu Algeria. Oríṣun àwòrán, FIFA Mali ati Tunisia yoo jọ maa ṣalaye fun ara wọn ẹni ti yoo lọ si idije ife ẹyẹ agbaye bi Qatar. Ikọ agbabọọlu DR Congo ati Morocco yoo jọ waako bakan naa.",22 Sẹ́rẹ́ 2022 +"Wo ohun tí o lè má mọ̀ nípa Maduka Okoye, aṣọ́lé Nàìjíríà tó ń dá àwọn obìnrin lọ́rùn"," Oríṣun àwòrán, Instagram/Maduka Okoye Orukọ aṣọle Super Eagles Naijiria, Maduka Okoye lo wa lẹnu ọpọ obinrin Naijiria bayii. Ibeere ti eeyan le beere ni pe, ṣe nitori idije ere bọọlu AFCON 2021 ti Naijiria n kopa lọwọ ninu rẹ ni Cameroon ni Okoye fi n dawọn lọrun? Iyalẹnu lo jẹ nitori ẹwa ti Eledua fi jinki Maduka ọmọ Okoye lawọn obninrin fi n sọ nipa rẹ papaa julọ lori itakun agbọrọkaye Twitter. Okoye ti inagijẹ rẹ n jẹ ''Madu'' ti di ilumọọka lati igba ti idije AFCON ti bẹrẹ ni Cameroon. Okoye gba bọọlu fun ikọ Super Eagles Naijiria fun igba akọkọ ninu ifẹsẹwọnsẹ ti Naijiria ti koju Brazil lọdun 2019. Ẹgbẹ agbabọọlu Fortuna Dusseldorf ni Germany lo n gba bọọlu fun nigba naa. Okoye ṣoju ikọ agbabọọlu ọdọ Bayer Leverkusen ati Fortuna Düsseldorf ti o to darapọ mọ Sparta Rotterdam loṣu keje ọdun 2020. Tọktaya afọju ti Eledua tun fi ibeji ta lọrẹ Wọnyii ni awọn koko kan ti o le ma mọ nipa Maduka Okoye: 1. Ọjọ kejidinlọgbọn oṣu kẹjọ ọdun 1999 ni wọn bi Maduka Okoye ni Dusseldorf lorilẹede Germany. Ọmọ Naijiria ni baba rẹ, amọ ọmọbibi orilẹede Germany iya to bi i lọmọ. Buga Jesse 2. Okoye fi Naijria silẹ lọ si Germany lọmọ ọdun mẹfa, ko si pada wale fun ọdun mẹrinla. 3. Ọmọ Enugu ni baba rẹ, Okoye gbe niluu Enugu, Abuja ati ilu Eko fun igba diẹ ki o to morile Germany nibi to ti dagba to si ti di agbabọọlu. Eba 4. Wọn pe Okoye si ikọ agbabọọlu U23 Naijiria lọdun 2019, ṣugbọn ko le wa nitori ikọ to n gbabọọlu fun ko fi i silẹ. 5. Ọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu keje ọdun 2019, akọnimọọgba Super Eagles tẹlẹ ri, Gernot Rohr ni oun fẹ pe Maduka lati wa darapọ mọ Super Eagles lẹyin ti aisan Carl Ikeme bẹrẹ. Ẹlẹ́wọ̀n: Ọgbà ẹ̀wọ̀n ni mo ti kàwé yege ní ìdánwò Jamb",22 Sẹ́rẹ́ 2022 +Ìgbẹ́ àá féwé! Ivory Coast já ìràwọ̀ Algeria lulẹ̀ nínú ìdije AFCON ní Cameroon," Oríṣun àwòrán, Instagram/Algeria Team Ṣe afojudu ni ki a pe e ni abi o kan wa bẹẹ naa ni? Ohun ti a n sọ ni ijakulẹ ẹgbẹ agbabọọlu Algeria ti ife idije ere bọọlu ilẹ Afirika, AFCON wa lọwọ ninu idije ọhun to n lọ lọwọ ni Cameroon. Ivory Coast tutọ soke foju gba a nigba ti wọn koju Algeria ni Ọjọru, igbaju igbamu ni wọn fi ṣe fun Algeria. Eni, eji, ẹta, bi Ivory Coast ṣe ko goolu le Algeria lọwọ niyii ninu ifẹsẹwọnsẹ ọhun eleyii to ya ọpọ ololufẹ ere bọọlu lẹnu. Amọ, Algeria naa ta putu da ẹyọkan pada bo tilẹ jẹpe aṣọ ko ba Ọmọyẹ mọ nitori Ọmọyẹ wọn ti rin ni ihoho wọ ọja. Iya o to ya, a fi ada pa ikun, ikun lọ, ada tun sọ nun. Algeria tun ri pẹnariti ninu ere bọọlu ọhun, amọ ẹlẹsẹ ayo wọn, Riyad Mahrez to gba pẹnariti naa tun padanu rẹ. Ninu ifẹsẹwọnsẹ mẹta ti Algeria gba ninu idije AFCON 2021 yii, wọn fidi rẹmi ninu meji nigba ti wọn ta ọmi ninu ọkan to ku. Koda, goolu kan ṣoṣo ni wọn le ri gba sawọn eleyii to jẹ ki wọn jẹ gbese goolu mẹta bayii. Ivory Coast to ran wọn lọ sile lo wa loke tente tabili isọri karun un ti wọn wa pẹlu ami ayo meje. Equatorial Guinea to fagba han Sierra Leone ninu ifẹsẹwọnsẹ keji to waye l'Ọjọbọ ni isọri karun un idije AFCON lo ṣipo keji pẹlu ami ayo mẹfa. Si iyalẹnu ọpọlọpọ, Algeria lo wa ni isalẹ patapata pẹlu ami ayo kan ṣoṣo. Algeria lo gba ife ẹyẹ AFCON lọdun 2019 lẹyin ti wọn lu ẹgbẹ agbabọọlu Senegal ninu ifẹsẹwọnsẹ aṣekagba idije naa.",20 Sẹ́rẹ́ 2022 +Super Eagles Nàìjíríà gún Guinea Bissau ní kẹ́ṣẹ́ pẹ̀lú 2-0," Oríṣun àwòrán, CAF online Ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles Naijiria gbo ewuro soju Guinea Bissau ninu ere bọọlu kẹta ti wọn gba ninu idije AFCON 2021. Ẹlẹsẹ ayo Umar Sadiq to kọkọ sọ goolu to yẹ ko gba s'awọn Guinea Bissau lo pada gba goolu s'awọn fun Naijiria. Naijiria ti kọkọ lu Egypt ati Sudan ninu Ifesewonse meji ti wọn kọkọ gba nibi idije naa. Adiẹyin mu to tun jẹ balogun Super Eagles lori papa, William Troost-Ekong fọba lee fun Naijiria lẹyin to gba goolu keji sawọn fun Naijiria. Naijiria yóò fórí gbárí pẹ̀lu Guinea Bissau lálẹ́ òní, ohun tí a mọ̀ nípa ìfẹsẹwọ̀nsẹ̀ náà rèé Lonii ni ikọ agbabọọlu Naijiria yoo koju ikọ ẹgbẹ agbabọọlu Wild Dogs ti orilẹ-ede Guinea Bissau ninu idije Afcon to n lọwọ laago mẹjọ alẹ. Ikọ Super Eagles lo n leke tente ninu ẹgbẹ ti wọn wa lẹyin ti wọn ti kọkọ na ikọ Egypt ni ami ayo 1-0, lẹyin naa ni wọn tun din dundu iya fun ikọ agbabọolu Sudan pẹlu ami ayo 3-1. Ti Super Eagles ba bori lalẹ oni, awọn ni yoo jẹ ikọ akọkọ ti yoo ni ojuami mẹsan an ninu ifeọsẹwọnsẹ ẹlẹgbẹjẹgbẹ ninu idije Afcon naa. Amọ, to ba jẹ pe ikọ Guinea Bissau lo jaweolubori, wọn ni anfaanin lati tẹsiwaju si ipele to kan ninu idije Afcon fun igba akọkọ ninu itan, amọ iyẹn da le esi ifẹsẹwọnsẹ laarin Egypt ati Sudan. Ohun to yẹ ki o mọ nipa ifẹsẹwọnṣẹ laarin Naijiria ati Guinea Bissau Ikọ mejeji ko tii dojukọ ara wọn ri, eyii ni igba akọkọ. Ipo kẹ́rìndínláàdọ́fà ni Guinea Bissau wa lagbaye, ti wọn si wa ni ipo kẹrinlelogun nilẹ Afrika. Nigba ti Super Eagles wa ni ipo kẹrindinlogoji lagbaye, ti wọn wa ni ipo karun un nilẹ Afrika. Ninu idije Afon to n lọ lọwọ yii, Guinea Bissau ko tii sọ bọlu kankan sinu awọn bo tilẹ jẹ pe wọn ni ojuami kan ninu ifẹsẹwọnsẹ wọn pẹlu Sudan. Igba kẹta ree ti Guinea Bissau yoo kopa ninu idije Afcon bo tilẹ jẹ pe wọn ko kọja ipele ẹlẹgbẹjẹgbẹ ri ninu idije ọhun. Super Eagles ẹwẹ ti gba ife ẹyẹ Afcon ni igba mẹta ọtọtọ.",19 Sẹ́rẹ́ 2022 +"Ṣé lóòtọ́ ni abẹ́ Venus Williams ẹni ọdún 41 ṣì dí pa, tí kò tíì bá ọkùnrin kankan lájọṣepọ̀ rí?"," Oríṣun àwòrán, Venus Williams Ọrọ nla ni ọrọ jija abale ọdọbinrin laye ọjọun. Nitori naa, ọpọ obinrin ni wọn kii ti ni ibalopọ ri pẹlu ọkunrin ki wọn to lọ si ile ọkọ. Iyi nla lo si maa n jẹ fun wọn ati ẹbi wọn ti ọkọ wọn ba le ba wọn nile lasiko orun akọkọ ti wọn ba jọ sun. Bakan naa, itiju nla lawọn ti ọkọ wọn ko ba bawọn nile maa n ba bọ nibẹ atawọn ẹbi wọn. Amọ, gbogbo nkan ti yatọ laye ode oni, ọpọ ọmọdebinrin lo ti n mọ ọkunrin ki wọn to mura lati lọ si ile ọkọ rara. Awọn obinrin kan si tun wa laye ode oni ti wọn ko tii mọ ọkunrin bo tilẹ jẹ pe ọjọ ori wọn ko kere. Iru obinrin bẹẹ ni agbabọọlu tẹniisi ọmọ orilẹede Amẹrika, Venus Williams eleyii ti iroyin sọ pe ko tii mọ ọkunrin di akoko yii. Oríṣun àwòrán, Venus Williams Iroyin ti a gbọ ni pe, Venus ko tii mọ ọkunrin bo tilẹ jẹ pe o ti pe ọmọ ọdun mọkanlelogoji bayii. Koda, ọjọ kẹtadinlogun oṣu kẹfa ọdun 2022 yii ni Venus yoo pe ọdun mejilelelogoji. Sibẹ naa, ohun ti a gbọ ni pe ko tii ni nibalopọ pẹlu ọkunrin kankan ri lati igba to ti gbọnju. Venus ti maa n sọ fawọn akọroyin pe oun ko ni igbagbọ ninu ibalopọ pẹlu ọkunrin afẹsọna ṣaaju igbeyawo.",17 Sẹ́rẹ́ 2022 +Nàìjíríà ló dáńtọ́ láti gba ife ẹ̀yẹ AFCON 2021 ní Cameroon- Asamoah Gyan," Oríṣun àwòrán, Twitter/Super Eagles Ẹlẹsẹ ayo ẹgbẹ agbabọọlu orilẹede Ghana tẹlẹ ri, Asamoah Gyan ti sọ pe ikọ Super Eagles Naijiria lo dantọ julọ lati gba ife ẹyẹ idije AFCON to n lọ lọwọ ni Cameroon. Gyan fọrọ yii lede lori ẹrọ amohunmaworan Supersports nigba to jẹ ọna lara awọn alejo lori eto. Ẹlẹsẹ ayo orilẹede Ghana tẹlẹ ni awọn agbabọọlu Naijiria fi ara wọn han nigba ti wọn gbo ewuro soju Egypt pẹlu ami ayo kan sodo pe awọn lawọn to lati gbade idije AFCON ni Cameroon. ''Lai ṣe ani ani, ikọ agbabọọlu Naijiria lo gbounjẹ fẹgbẹ to si gbawo bọ ninu gbogbo ẹgbẹ agbabọọlu to n kopa ninu idije AFCON lọwọ yii. Ko si ikọ agbabọọlu ti Super Eagles ko le ṣẹgun pẹlu ohun ti wọn gba ninu ifẹṣẹwọnsẹ wọn pẹlu Egypt. Gbogbo awọn ikọ agbabọọlu mii to tun le gba ife ẹyẹ AFCON ko fi tara tara si idije to n lọ lọwọ. Amọ ti a ba wo ikọ Super Eagle Naijiria, wọn n gba bọọlu bi ikọ to le bori gba ife ẹyẹ naa. O yẹ ki Naijiria gba ju goolu kan lọ sawọn Egypt ṣugbọn nkan naa n ṣe taṣe taṣe mọ wọn lọwọ ni. Ti ikọ Super Eagles ba le tẹsiwaju lati maa gbabọọlu bi wọn ṣe n gba a lọwọ yii, awọn ni yoo gba ife ẹyẹ AFCON to n lọwọ yii,'' Gyan lo sọ bẹẹ. Lọjọ Abamẹta ni Naijiria tun jawe olubori ninu ifẹsẹwọnsẹ keji ti wọn gba pẹlu Sudan. Ami ayo mẹta si ẹyọkan ni wọn jawe olubori eleyii to mu wọn pegede fun ipele ẹlẹni mẹrindinlogun ninu idije AFCON to n lọ lọwọ.",16 Sẹ́rẹ́ 2022 +"Kò sí eré ní 'Moscow', Super Eagles fi pàṣán 3-1 lu Sudan ní ìdíje Afcon"," Oríṣun àwòrán, Super eagles Nipa irinṣe ajumọlo wa,yan ikọ ti o wu ọ lọkan ninu awọn ti a ṣe aṣayan wọn ki o ṣi ṣe alabapin rẹ pẹlu awọn ọrẹ rẹ. Ikọ agbabọọlu Super Eagles Naijiria ko ṣere rara ninu ifẹsẹwọnsẹ wọn pẹlu orilẹ-ede Sudan to waye ni papa iṣire Stade Roumdé Adijia to wa nilu Garoua lorilẹede Cameroun. Wọn ko ti i lo to iṣẹju mẹwaa lori papa, ti Samuel Chukwueze fi kọkọ gba bọọlu kan sinu awọn Sudan. Ka to o tun ṣẹju pẹ́, bọọlu miran lati ọdọ Awoniyi tun ti yí sinu ile Sudan, eyi to mu ki ifẹsẹwọnsẹ naa jẹ ami ayo meji si odo ni abala akọkọ. A fi bi ẹni pe orilẹ-ede Sudan sin wọn wa sori papa ni ọrọ ri nigba ti abala keji idije naa tun bẹrẹ. Laarin iṣẹju kan ti wọn wọ ori papa ni ọmọ orilẹ-ede Naijiria, Moses Simon tun ju goolu kan sinu awọn Sudan. Eyi to mu ki o di ami ayo mẹta si odo. Awọn agbabọọlu Naijiria ti kọkọ lu ikọ Pharaohs ti orilẹede Egypt lọjọ Iṣẹgun to kọja. Orilẹede Sudan jẹ ọkan lara awọn ikọ agbabọọlu to ti pẹ julọ ni ilẹ Afirika. Sudan jẹ ọkan lara awọn orilẹede mẹta to kopa ni idije ife ẹyẹ bọọlu afẹsẹgba ilẹ adulawọ akọkọ, pẹlu Egypt ati Ethipia lọdun 1957. Ọdun 1970 ni Sudan gba ife ẹyẹ naa nigba to gbalejo idije ọhun. Oríṣun àwòrán, cafonline Orilẹede Naijiria lo n le tente loke ipin D pẹlu ami mẹta lẹyin ti Sudan ati Guinea Bissau ta ọmi olodo ti wọn si ni ami kọọkan. Bi Sudan ba lee bori ifẹsẹwọnsẹ naa, yoo mu wọn duro digbi lati kogoja fun ipele to kan. Amọṣa bi o ba jẹ Super Eagles Naijiria lo ba bori, ipele ẹlẹni mẹrindinlogun to kan di dandan fun wọn niyẹn. Awọn odu ẹlẹsẹ ayo ti aye yoo maa fẹ ri lasiko ifẹsẹwọnsẹnaa Kelechi Iheanacho ati Moses Simon- Nigeria Oríṣun àwòrán, cafonline Bi o tilẹ jẹ pe Iheanacho lo gba goolu wọle si awọn orilẹede Egypt ninu ifẹsẹwọnsẹ wọn akọkọ to si gba ami ẹyẹ agbabọlu to pegede julọ ninu ifẹsẹwọnsẹ naa, MVP, amọṣa Moses Simon lo mu ọpọ awọn oluworan bọọlu lọkan ju pẹlu ipa ribiribi to ko ni ifẹsẹwọnsẹ naa. Kí ni Saheed Balogun àti Shina Peters wá lọ sí ilé Ààrẹ Buhari l'Àbuja Ìdá àádọ́rùn ún àwọn tó ṣe ìdánwò ọlọ́pàá ló fìdí rẹmi - Àjọ ọlọ́pàá A ò jẹ́ Ọba mọ́ o! A ṣetán láti padà sí ipò Olóyè tí a wà tẹ́lẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ Olubadan - Lekan Balogun BIAFRA at 50: Ìhàlẹ̀ ológun ni Gowon ni ká kọ́kọ́ fi bẹ̀rẹ̀- Aladejẹbi Oríṣun àwòrán, cafonline Abu Ashren ni goli amule fun orilẹede Sudan, O si mu pẹnariti kan ninu ifẹsẹwọnsẹ wọn pẹlu Guinea-Bissau nibi to ti gba ami ẹyẹ agbabọlu to pegede julọ ninu ifẹsẹwọnsẹ naa, MVP. Oju rẹ lọpọ yoo tun maa wo lasiko ifẹsẹwọnsẹ wọn. Yasin Hamed naa wa lara awọn agbabọọlu Sudan to n gba bọọlu jẹun nilẹ Yuroopu. Atamatase ti wọn yoo si maa wo oju rẹ niyi. Oríṣun àwòrán, cafonline Akọnimọọgba orilẹede Naijiria, Augustine Eguavoen ni oun ko ro pe ifẹsẹwọnsẹ naa yoo rọrun bi awọn eeyan kan ṣe n ro. ""Gbogbo wa la mọ pataki bibori ifẹsẹwọnsẹ to kan yii. A mọ pe ko ni rọgbọ rara, mo si lero pe bi a ba tete yi ero yii pada ni yoo dara fun gbogbo wa. Gẹgẹ bi ana, orilẹede Cameroun yege, wọn bori lati wọ ipele oloju mẹrindinlogun. ""Awa naa yoo gbiyanju lati ṣe bẹẹ pẹlu. Ko lee rọrun gẹgẹ bi mo ṣe sọ, ṣugbọn afojusun wa niyi."" Oríṣun àwòrán, cafonline Amọṣa ni tirẹ, akọnimọọgba orilẹede Sudan Burhan Tia ṣalaye pe awọn mọ pe Naijiria kii ṣe ẹran rirọ, ṣugbọn awọn ko ni fi eyi ṣe o, awọn yoo ṣe ẹtọ gbogbo to ba yẹ gẹgẹ bi ikọ to fẹ gbẹyẹ mọ Naijiria lọwọ. ""Lootọ ni pe a ṣe awọn aṣiṣe kan ninu ifẹsẹwọnsẹ wa pẹlu Guinea-Bissau, ṣugbọn a lee ṣe ohun gbogbo to ba tọ. ""A mọ pe ikọ to gbayi ni Naijiria, wọn ma maa lepa lati bori ni. Ikọ nla ni ṣugbọn olukuluku lo ni agbara rẹ.""",15 Sẹ́rẹ́ 2022 +Títí ìdíje AFCON 2021 yóò fi parí ní wọ́n ó lo VAR - CAF," Oríṣun àwòrán, Getty Images Igba akọkọ niyii ti wọn o lo VAR fun gbogbo ifẹsẹwọnsẹ ni idije Africa Cup of Nations Àjọ tó ń mójútó eré bọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá nílẹ̀ Adúláwọ̀ (CAF) ti ní ẹ̀rọ ayàwòrán tí àwọn alamojuto idije ma n lo lati tọpinpin ifẹsẹwọnsẹ (VAR) ni yóò jẹ́ lílò ní gbogbo ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ méjìléláàdọ́ta tí wọn yóò gbà á níbi ìdíje AFCON 2021. Ó kú ìpele méjì tí ìdìje yóò parí ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ síní ṣàmúlò ìmọ̀ ẹ̀rọ yìí níbi ìdíje AFCON 2019 tó wáyé ní orílẹ̀ èdè Egypt. Àtẹ̀jáde kan látọwọ́ CAF ní ṣíṣàmúlò ìmọ̀ ẹ̀rọ yìí yóò jẹ́ ọ̀nà láti mú kí àwọn olùdárí ìdíje bọ̀ọ̀lù ní Afrika bẹ́gbẹ́ pé ní àgbáyé. Adárí ayò mẹ́rìnlélógún, igbákejì mọ́kànlélọ́gbọ̀n àti ẹ̀rọ VAR mẹ́jọ láti orílẹ̀ èdè mẹ́rìndínlógójì. Obìnrin mẹ́rin ló wà lára awọn adárí ayò nàá. Àwọn òṣìṣẹ́ méjì láti àjọ Caribbean àti Àríwá àti Ààrin gbùngùn Amẹ́ríkà yóò kópa. Ẹni tó bá gba ipò kìíní nínú ìdíje yìí yóò gba mílíọ̀nù márùn-ún Dọ́là èyí tó fi ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta lé sí ti ọdún 2019. Orílẹ̀-èdè tó bá ṣe ipò kejì àti ìkẹta yóò gba mílíọ̀nù méjì lé ẹ̀gbẹ̀rún lọ́nà ọ̀tàdínlẹ́gbẹ̀rinDọ́là. Àwọn tó dé ipele sẹ̀mí fainà àti kúọ́tà fainà yóò gba mílíọ̀nù méjì lé ẹgbẹ̀rún lọ́nà igba Dọ́là àti mílíọ̀nù kan lé ẹ̀gbẹ̀rún lọ́nà ọ̀tàdínlẹ́gbẹ̀rin. Ọjọ́ Àìkú ní ìdíje náà yóò bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ láàárín Cameroon àti Burkina Faso ní aago márùn-ún ìrọ̀lẹ́. Aṣọle ẹgbẹ agbabọọlu obinrin Super Falcons orilẹede Naijiria tẹlẹ, Rachael Aladi Ayegba ti di awakọ bọọsi nla lorilẹ ede bayii.",8 Sẹ́rẹ́ 2022 +Golí Super Falcons Nàìjíríà tẹ́lẹ̀ Rachael Ayegba di awakọ̀ bọ́ọ̀sì ní UK," Oríṣun àwòrán, Evening Standard Ọna ọfun, ọna ọrun, bayii ni awọn Yoruba maa n wi.Aṣọle ẹgbẹ agbabọọlu obinrin Super Falcons orilẹede Naijiria tẹlẹ, Rachael Aladi Ayegba ti di awakọ bọọsi nla lorilẹ ede bayii.Ayegba ṣoju Naijiria ninu idije ere bọọlu agbaye lọdun 2007 lorilẹ ede China. Bakan naa ni Ayegba ṣoju Naijiria ninu idije ere bọọlu awọn obinrin ilẹ Afirika lọdun 2006 ati 2008.Ọdun mọkanla ni o fi gba bọọlu jẹun lorilẹ ede Finland ki o to lọ fun ẹkọ olukọni ere bọọlu.Iwe iroyin UK's Evening Standard sọ pe o kere tan awon awakọ bọọsi n N14m lowo oṣu ni UK.Ayegba to jẹ ẹni ọdun marundinlogoji tiẹ sọ fun iwe iroyin Evening Standard pe bi oun ṣe jẹ agbabọọlu tẹlẹ ri n ran oun lọwọ lati ṣiṣẹ dẹrẹba dara dara.Ayegba ni oun ti maa lọ UK fun họlude tẹlẹ nigba ti oun fi gbabọọlu ni orilẹ ede Finland.Lati agbegbe Victoria si Lewisham bọọsi ti Ayegbe n wa n na lẹyin ọdun mẹta ti o ti n gbe orilẹ ede UK bayii.",11 Ọ̀pẹ̀̀ 2021 +"Ọkùnrin kan pokùn so lẹ́yìn tó pàdánù N150,000 owó iléèṣẹ́ sórí tẹ́tẹ́"," Oríṣun àwòrán, Getty Images Ọkunrin kan ti gbẹmi ara rẹ nilu Abuja, lẹyin to padanu ẹgbẹrun lọna aadọjọ Naira sori tẹtẹ. Iroyin sọ pe ni agbegbe Pegi, nijọba ibilẹ Kuje ni Arakunrin Adegbite ti pa ara rẹ. A gbọ pe ọga rẹ nibi to ti n ṣiṣẹ lo ko owo naa fun lati san fun awọn oṣiṣẹ akẹẹgbẹ rẹ, ṣugbọn o fi owo naa ta tẹtẹ nireti pe oun yoo jere rẹpẹtẹ, ko to o fi owo ṣe nkan ti wọn ran. Amọ, o padanu gbogbo owo naa sinu tẹtẹ to ta. Sport Betting: Idí rèé tí àwọn ọ̀dọ́ kan fi n ta tẹ́tẹ́... Ọrẹ oloogbe to ba iwe iroyin Punch sọ pe iyalẹnu lo jẹ fun oun lati gbọ pe Adegbite pa ara rẹ. O ni lootọ, ọga rẹ lo ko owo naa fun, amọ o fi ta tẹtẹ ni ṣọọbu kan ti wsn ti n ta tẹtẹ lori bọọlu. Ìdí tí Tòmátò ẹ̀sà kò ṣe dára fún ìlera yín; wo àwọn kókó márùn-ún yìí ""Awọn ifẹsẹwọnsẹ to ta tẹtẹ le lori ko lọ bo sẹ lero."" ""Ni owurọ ọjọ keji, awọn alajọgbele rẹ ko ri ko jade. Wọn ṣakiyesi pe o wa ninu ile. Eyi si lo mu ki wọn o ja ilẹkun rẹ, ti wọn fi ba to ti pokunso lara faanu."" Teslim Thunder Balogun: Àwọn oní-Tomato, aláta, oníṣu á máa kó ọjà wọn lọ́fẹ̀ẹ́ sínú ọkọ̀ ",10 Ọ̀pẹ̀̀ 2021 +BBC kéde àwọn tó pegedé láti gba àmì ẹ̀yẹ èrè ìdárayá ọdún 2021," Ileeṣẹ iroyin BBC ti kede orukọ awọn eeyan to fa kalẹ fun ami ẹye ẹni to pegede julọ ninu ere idaraya lọdun 2021. Igbimọ awọn akọroyin lati ilẹ Afrika ati ilẹ Gẹẹsi lo ṣe akojọpọ orukọ awọn eeyan mẹfa naa. Wọn yan awọn eeyan ọhun gẹgẹ bii aṣeyọri wọn ninu awọn ifẹsẹwọnsẹ ti wọn ti kopa kaakiri agbaye laarin oṣu Kiini si oṣu Kẹsan an, ọdun 2021. Bakan naa ni wọn tun yan awọn eeyan naa lori awọn aṣeyọri wọn yatọ si ipa ti wọn n ko ninu ere idaraya. Awọn eeyan naa ree: Oríṣun àwòrán, Getty Images Orilẹ-ede: Kenya Ọjọ ori: 37 Ere: Ere-ije gigun Eliud Kipchoge di gbajumọ lẹyin to jawe olubori ninu ere ije oni maili mẹrindinlogun ninu idije Olympic. Lẹyin naa ni igbimọ Olympic naa kede orukọ rẹ gẹgẹ bii okunrin to tayọ julọ ninu idijẹ ọhun. Okunrin ọhun jawe olubori ninu idije mẹtala ninu marundinlogun to ti kopa ninu rẹ. Lẹni ọdun mẹrindinlogoji, Eliud Kipchoge ni okunrin to dagba julọ ti yoo bori ninu ere-ije gigun ninu idije Olympic lẹyin Calos Lopes, lati Portugal lọdun 1984. Oríṣun àwòrán, Getty Images Orilẹ-ede: Kenya Ọjọ ori: 27 Ere: Ere-ije gigun Faith Kipyegon bori ninu ere 1,500 mita lẹyin to ti kọkọ bori ninu ere ije naa ni Rio de Janeiro lọdun 2016. Lẹyin to bori tan lo fi aṣeyọri naa sọ ori ọmọ rẹ obinrin to jẹ ọmọ ọdun mẹta, eyii to ni oun lo fun oun ni iwuri lati ṣe aṣeyọri. Bo ṣe fi ami ẹyẹ naa sọri ọmọ rẹ ṣe pataki nitori oun ni elere ije kẹta ti yoo bi ọmọ, ti yoo si tun jawe olubori ninu idije lẹyin to bimọ tan. Awọn meji akọkọ ni Shirley Strickland latri Australia ati Francoise Mbango lati Cameroon. Oríṣun àwòrán, Getty Images Orilẹ-ede: Kenya Ọjọ ori: 27 Ere: Ere-ije 200m Ntando Mahlangu jawe olubori ninu ere idaraya awọn akandan ẹda fun igba akọkọ lasiko to wa ni ọmọ ọdun mẹrinla lọdun 2016. Lọdun yii, o tun jawe olubori ninu ifẹwọnsẹ long jump ninu idije Olympic ni Tokyo. Igba to wa ni ọmọ ọdun mẹwaa ni wọn ge ẹsẹ rẹ mejeji nitori ẹsẹ naa kọ lati dagbe bi awọn ẹya ara rẹ to ku ṣe n dagba. Oríṣun àwòrán, Getty Images Orilẹ-ede: Namibia Ọjọ ori: 18 Ere: Ere-ije Igba to wa lẹni ọdun marundinlogun lo kọkọ gba goolu fun orilẹ-ede rẹ ninu idije Tokyo Olympic 2020. Oríṣun àwòrán, Getty Images Orilẹ-ede: Senegal Ọjọ ori: 29 Ere: Adele bọọlu alafẹsẹgba Edouard Mendy ti ṣe bẹbẹ lati igba to ti darapọ mọ ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea lati Rennes. Orukọ rẹ wọ inu iwe itan gẹgẹ bii adele ẹgbẹ agbabọọlu akọkọ lati ilẹ Afrika ti yoo kopa ninu idije Champions League. Oríṣun àwòrán, Getty Images Orilẹ-ede: South Africa Ọjọ ori: 24 Ere: Breaststroke Tatjana Schoenmaker ni obinrinn akọkọ ti yoo gba ife ẹyẹ Olympic fun South Africa lati ọdun 2000. Nigba to ba awọn akọroyin sọrọ lẹyin to gba ami ẹyẹ naa tan, o ni afojusun oun lọwọ yii ni ki oun bẹrẹ si n ṣe daadaa ju ti tẹlẹ lọ.",6 Ọ̀pẹ̀̀ 2021 +"Ṣé lóòtọ́ ní pé ìlúmọ̀ọ́ká agbábọ́ọ̀lù ayé àtijọ́ Teslim Thunder Balogun gbá ṣọ́ọ̀tì gbígbóná fi pa ""Goal keeper""?"," ""Ó wù ẹ̀, kò wù ẹ́, tí wọ́n bá ti gbọ́ pé ọmọ bíbí Thunder Balogun ni ẹ́, dandan ni wàá gbá bọ́ọ̀lù fún School ẹ"". Ajibola Hakeem Balogun ọmọ gbajugbaja ati ilumọọka agbabọọlu fun orilẹede Naijiria ni ọpọlọpọ ọdun sẹyin nigba ti aye ṣi wa lorokun, Teslim Balogun gba BBC Yoruba lalejo. Teslim Balogun ti ọpọlọpọ mọ kaakiri agbaye si Thunder Balogun kẹnu bọ ọrọ lori iyatọ to wa laarin igbe aye baba rẹ gẹgẹ bi irawọ agbabọọlu aye atijọ ati bi awọn ti aye ode oni ṣe n ṣe. O ni lati kekere ni awọn ọmọ Thunder Balogun ti n gbadun iyi to wa ninu orukọ ati iṣẹ ti baba awọn nṣe. Bi ileewe kan ba ti fẹ gba wọn fun ẹkọ lati kekere gẹgẹ bo ṣe sọ, “bi wọn ba ti rii pe ọmọ Thunder Balogun ni ẹ, yala o wu ẹ tabi ko wu ẹ o, oo niṣẹ meji, wọn a ni koo niṣo lori ọdan na, afi dandan koo gba bọọlu fun ileewe yẹn”. “Orúkọ bàbá mi Thunder Balogun máa ń dẹ́rù ba àwọn ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù tí àwa ọmọ rẹ̀ bá kojú”. O ni awọn imọran ti Baba oun Teslim Balogun maa n fun awọn tayọ gbigbe orukọ rẹ ti gbogbo agbaye n wari fun lọ. ""Taa ba ni ka lọ si ọja lọ ra nkan lasiko ti iya mi ba loyun ti emi ati baba mi lọ, àwọn oní-Tomato, aláta, oníṣu á máa kó ọjà wọn lọ́fẹ̀ẹ́ sínú ọkọ̀ bàbá mi"". O ni iyi ti baba oun ati awọn tawọn jẹ ọmọ maa n ri kii ṣe kekere. Agbaọjẹ akọroyin aye atijọ kan, Segun Adenuga ti BBC Yoruba bá sọ̀rọ̀, ṣalaye iru agbabọọlu ti Thunder jẹ lori ọdan. O ni ko si ootọ kankan to jọ pe Thunder Balogun fi ṣọ́ọ̀tì pa aṣọ ojule kankan. Ege lo maa n ge ju koda o fẹẹ le bi aṣọle pe ibo lo fẹ ki oun gba bọọlu wọle si lawọn rẹ sibẹ yoo ṣi tayọ”. “Laye atijọ, tọkan tara ni wọn fi n gba bọọlu, pe wọn mu wọn lasan pe ki wọn wa gba bọọlu fun orilẹede wọn, iyi nla ni, ko si si ẹni to maa n beere owo, tọrọ kọbọ ni wọn maa n fun wọn”. Ọmọ Thunder Balogun ṣe afiwe bi awọn gbajumọ irawọ aye ode oni ṣe maa n takete si awọn ololufẹ wọn tabi le wọn danu ti wọn ba ri wọn lawujọ. “Baba mi maa n sọ nigba taa wa ni kekere pe bọọlu tawọn n gba yii ati bawọn eeyan ṣe fẹran awọn si, kii ṣe bọọlu ori papa nikan o tori gbogbo awọn taa ba fẹ lọ ra nkan lọja lo ma maa pariwo Thunder Thunder ti wọn a maa yọ mọ mi”. Bakan naa ni ọmọ eekan agbabọọlu gba awọn ọdọ asiko yii to yan bọọlu gbigba gẹgẹ bi iṣẹ layo nimọran. Akoroyin BBC to ṣe ifọrọwanilẹnuwo yi, Adedayo Ehinmitan lo ya aworan naa pẹlu ọpọlọ",3 Ọ̀pẹ̀̀ 2021 +"Ó di gbéré, Ole lọ! Manchester United yọ Ole bí ẹni yọ jìgá gẹ́gẹ́ bí akọ́nimọ̀ọ́gbá wọn"," Oríṣun àwòrán, Manchester United Lẹyin ọ rẹyin, ẹgbẹ agbabọọlu Manchester United ti le akọnimọọgba wọn, Ole Gunnar Solskjaer, lọ lẹyin ti Watford lu wọn ni alubami pẹlu ami ayo mẹrin si ẹyọkan ninu idije Premier League. Man U fi ikede yii lede loju opo Facebook rẹ lọjọ Aiku. Ẹgbẹ agbabọọlu naa ni o nira fun awọn lati le Ole danu amọ, awọn ni lati ṣe bẹẹ nitori nkan ko ṣẹnu 're fun Man U mọ. Michael Carrick ni yoo maa ṣe akoso Man United bayii titi ti wọn yoo fi yan akọnimọọgba fidihẹ.",21 Bélú 2021 +"Liverpool faṣọ iyì ya mọ́ Man U lára, ó wọ Ole àti Ronaldo láṣọ ẹ̀tẹ́"," Oríṣun àwòrán, Getty Images Liverpool ṣe ẹgbẹ agbaboolu Manchester United risa-risa ninu Ifẹsẹwọnsẹ idije Premier League to waye ni papa isere Old Trafford lọjọ Aiku. Àmì ayo marun ùn sodo ni Liverpool gba si awọn Man U nile wọn eleyii ti United ko sí lee ta putu. Ẹlẹsẹ ayo n ni, Mohammed Salah lo gbayo mẹta ọtẹtọ wọlé fun Liverpool ninu ere bọọlu ọhún. Naby Keita lo kökọ ṣide ayo nigba ti o gba góòlù akọkọ s'awọn Man United. Diogo Jota lo fi ọba lee fun Liverpool ni Old Trafford. Lẹyin naa ni agbaojẹ Salah gba góòlù mẹta lera s'awọn",24 Ọ̀wàrà 2021 +Bimbo Oshin ṣàlàyé ọ̀rọ̀ ìkẹyìn tí ọkọ rẹ̀ sọ fun un kó tó kú," Mo ti sun ẹkun ti mi o sun laarin ọdun marindinlọgbọn mi gẹgẹ bi oṣere tiata, sibẹ, bi ala lo ṣi ri loju mi. Pẹlu omije loju ni mo n kọ ọrọ ikẹdun yii. Eyi ni ọrọ ti gbajumọ oṣere, Bimbọ Ọshin fi bẹrẹ ọrs idagbere to ka nibi isinku ọkọ rẹ, oloogbe Ibironkẹ ti gbogbo eeyan mọ si Dudu Heritage. ""Mo ni anfani nla ti ko lẹlẹgbẹ lati jẹ iyawo fun ọkunrin to bẹru Ọlọrun to si tun nifẹ ati alaafia julọ ti obinrin kobinrin lee fi tọrọ. Ko si bi aye mi ṣe tun lee ladun laisi rẹ."" Ifẹ aye mi ni to ṣe ohun gbogbo to yẹ lati daabo bo mi lainaani oniruuru ikoju ati ariwisi. Oun ni eeyan kan ṣoṣo to mọ ohun ti a n pe ni ifẹ. Mo dupẹ pe mo lanfani lati baa rin irinajo ala rere to ni, ireti, ifẹ, ibanidọrẹ to yii ka."" Bimbọ Ọshin ni bi oun ba ti n ranti ọjọ kejila oṣu kẹsan ọdun 2021, inu oun kii dun. O ni ọrọ to sọ kẹyin fun oun naa ni pe nigba ti oun fẹ lọ gbe ọmọ awọn ni ibudo iṣire Golf course ṣi n wa si iranti lọkan oun. ""Mo ṣi pe ẹ ni nnkan bii agogo meje ku iṣẹju diẹ lalẹ ọjọ naa nigba ti mo wa gbe ọmọ wa ni Golf Club gẹgẹ bi o ṣe sọ fun mi pe ki n ṣe. Ọkan mi ọ fun mi pe ki n pe ẹ lati yọju si mi ni ita nibi ti wọn n gbe ọkọ si. Mo pe ẹ o si ṣe nlẹ o iyawo ẹ, maa binu, mo wa ni ipade kan."" Ọrọ ajọsọ wọn to gbẹyin niyi. O ni ọmọbinrin wọn a maa beere lọwọ oun pe nibo ni baba awọn wa ṣugbọn esi ti oun maa n fun un ni pe Baba rẹ ti ls darapọ ms awọn angẹli. Gbajumọ oṣere naa ṣe apejuwe ọkọ rẹ Dudu Heritage gẹgẹ bi ọkunrin to ni itẹlọrun ati oruks rere nitori o gbagbọ pe orukọ rere san ju wura ati Fadaka. O ni Ọkọ to fun oun iyawo rẹ atawọn ọmọ ni ifọkanbalẹ ni. Ẹrin rẹ a si maa ran ka gbogbo ile. Eto isinkun gbajugbaja oniṣowo, to tun jẹ ọkọ gbajumọ oṣere tiata Yoruba, Bimbo Oshin, iyẹn Ola Ibiropnke ti ọpọ eeyan mọ si Dudu Heritage ti waye nilu Ibadan. Ori papa ti wọn ti n gba ẹyin orilẹ ilẹ pẹlu igi sinu iho, Ibadan Golf Club ni eto naa ti kọkọ bẹrẹ. Wọn bẹrẹ eto ọhun pẹlu gbingbin igi kan ni gbagede ti wọn ti n gba gọọfu naa lati ṣe iranti rẹ, ati lati ṣe apẹrẹ pe bo tilẹ jẹ pe o ti jade laye, yoo si wa laaye sibẹ. Ọpọ awọn oṣere tiata Yoruba lo peju sibi eto itiju naa. Lara awọn agba oṣere to wa nibẹ ni, Adewale Adeoye, ti ọpọ eeyan mọ mọ si Adewale Elesho ẹnu n ja waya. Elesho sọ fun BBC Yoruba pe Dudu Herigate jẹ ẹnikan to lawọ gidi to si maa n fẹ ki itẹsiwaju ba ẹlomiran. ""Akokoro eyín lè ṣe ìpalára fún àtọ̀ ọkùnrin, ó sì lè yọrí sí ṣàkóbá fún ọkàn èèyàn"" Bakan naa lo ni Dudu Hertiage kii ṣe ẹni to ni ahun, o si maa lawọ lati ṣe ore fun ọpọ eeyan. Ẹwẹ, ọrẹ timọ-timọ si oloogbe ọhun, to tun jẹ mbalogun ẹgbẹ awọn to n gab gọọfu, amofin Idowu Salami sọ fun BBC pe ẹgbẹ awọn to n gba gọọfu naa n ṣedaro oloogbe. O fi kun pe inu ọgba Ibadan Golf Club naa gangan ni Dudu wa nigba ti ọlọjọ de.",15 Ọ̀wàrà 2021 +"Buhari gbà mí, wá ṣe onígbọ̀wọ́ ìjà ẹ̀ṣẹ́ kíkàn mi, kó tó bọ́ mọ́ mi lọ́wọ́ - Ridwan Oyekola"," Ridwan Scorpion Oyekola tun ti ba BBC Yoruba sọrọ lori ohun to jẹ ẹdun kan rẹ lọwọ lọwọ bayii, eyi to si le se akoba fun ẹsẹ kikan to yan laayo. Oyekola ni lẹyin osu mẹfa ti oun gba ami ẹyẹ bẹliti agbaye, lo yẹ ki oun tun ija miran ja lati tun bẹliti naa gba. O ni osu kẹfa ọdun 2021 lo yẹ ki ija keji naa ti waye, amọ ko si onigbọwọ fun oun eyi ti ko tii jẹ ki ija naa waye. Akansẹ agbaye naa ni ajọ to n se kokari idije naa ti n yọ oun lẹnu, ti wọn si ti fi ọjọ ija naa si ọgbọnjọ osu Kẹwa taa wa yii. Amọ o ni titi di akoko yii, onigbọwọ kankan ko tii si fun oun lati ja ija naa, to si n ke si aarẹ mMuhammadu Buhari atawọn ọlọrọ lorilẹede yii, lati wa se iranwọ fun lori ika oun. Oyekola ni lai si onigbọwọ, wọn le gba bẹliti agbaye naa lọwọ oun, eyi to le se akoba fun ẹsẹ kikan to yan laayo, ti yoo si da omi tutu si lọkan.",13 Ọ̀wàrà 2021 +"""Mo gba àmì ẹ́yẹ wúrà fún Nàíjíríà ní Tokyo 2020 àmọ́ ìgbé ayé mi ń burú si ni"""," Latifat Tijani jẹ akọni to n gbe irin fun orilẹede Naijiria ninu awọn idije fawọn agba ọjẹ elere idaraya lagbaye. Ilu Abeokuta nipinlẹ Ogun ni Latifat ti wa, oun nikan soso si ni elere idaraya to mu ami ẹyẹ goolu wale laarin awn elere idaraya to jẹ akanda ẹda to soju orilẹede wa ninu idije ere idaraya Olympics fawọn akanda ẹda to waye ni Tokyo lọdun 2020. Saaju ni Latifat ti kọkọ gba ami ẹyẹ fadaka fun orilẹede Naijiria lọdun 2016 ti inu awọn alasẹ ilẹ wa si dunnu si awọn igbesẹ akin ti akọni obinrin to jẹ akanda ẹda naa n gbe. Amọ bo ti se bẹbẹ to yii, Latifat ko ri ohun rere kankan tọkasi lati safihan iyi ati ẹyẹ to n mu ba ilẹ baba rẹ. Koda, inu ile ti Latifat n gbe ko wu oju ri rara, eyi to n mu ki ibinu awọn ọmọ Naijiria maa ru soke si ijọba pe se o yẹ ki iya maa jẹ iru eeyan bayii. BBC Yoruba ba Latifat fọrọ jomitoro ọrọ, to si salaye pe ijọba ko tii se amusẹ gbogbo ileri ti wọn se fun oun lati ọdun 2016 titi di akoko yii bi o tilẹ jẹ pe wọn n se ileri pe awọn yoo se e. O ni igbe aye oun lo n fi ojoojumọ buru si lojoojumọ, iwọnba ohun ti oun ri gba lọwọ gomina Amosun lọdun 2016 si ni oun fi sare se ile ti oun n gbe. Amọ sibẹ sibẹ Latifat ni ifẹ nla ti oun ni si ere idaraya ko yinjẹ rara, ti oun si setan lati se bẹbẹ siwaju niwọn igba ti ijọba ba fun ohun lawọn ohun eelo to yẹ fun igbaradi awọn elere idaraya bii ti oun.",12 Ọ̀wàrà 2021 +"Ọ̀pẹ́lọpẹ́ Seyi Makinde lára mi, ẹbí tó yẹ kó ràn mí lọ́wọ́ ní mo lówó mi fi mọ ẹbí - Ridwan-Scorpion Abẹ̀ṣẹ́kùbíòjò"," Scorpion ti di gbajugbaja abẹṣẹkubiojo pẹlu ami ẹyẹ kan to tun ṣẹṣẹ gba gẹgẹ bi ajawe olubori agbaye fun International Super Featherwight Champion. Ridwan Oyekola ni orukọ rẹ amọ ọpọlọpọ mọ ọ si ""Scorpion"". O ni ki okiki to de fun oun gan ni awọn eeyan ti n pe oun ni olowo to si jẹ pe oun ko tii jẹ nkankan asan okiki orukọ loun kan ni. O ṣalaye pe ko si ni to n ṣe iru iṣẹ yii ninu idile oun amọ ẹgbin kan ti oun koju lo jẹ ki oun bẹrẹ ẹṣẹ jija tori o pade obinrin kan to fẹ baa ja lai mọ pe ogbontarigi abẹṣẹkubiojo gan ni obinrin hun to si luu bii bara. ""Mo ti gba sọwedowo miliọnu mẹwaa ri to jẹ pe kinkini ninu rẹ lo pada tẹ mi lọwọ"". 'Kàǹkàn ìbílẹ̀, òògùn, àwọ̀tẹ́lẹ̀ àti fóònù lá bá lẹ́gbẹ̀ẹ́ òkú obìnrin tí wọ́n dédé jù sí àdúgbò wa l'Akure' Ṣé o tí gbọ́ nípa eNaira, owó àìrí tuntun tí CBN ṣe ìfilọ́lẹ̀ rẹ̀? Nkan tí ó ní láti mọ̀ rèé Mo sún ìgbẹ́jọ́ yìí láàrin Princess àti Baba Ijesha síwájú di 21/10/2021 torípé ...- Adájọ́ Ayé ò! Báyìí ní ọwọ́ FBI ṣé tún tẹ àwọn gbájúẹ̀ ọmọ Nàìjíríà 11 ní Texas Mọ̀ nípa àìsàn tó ń mú ǹkan ọmọkùnrin lè gìdìgbà láì rọlẹ̀ Ridwan ni ẹbun owo miliọnu mẹwaa ti oun ri gba lọwọ Gomina ipinlẹ Oyo lo gbe oun jade gẹgẹ bi ilumọọka. ""Tori eyi, lai tilẹ tii gba owo, awọn ẹbi ati ọrẹ ti n ro pe mo ti di olowo ti wọn si n sọ pe mo lowo mi o fi ran awọn lọwọ. Mi o ni ọkọ ayọkẹlẹ ara mi ti mo fi n rin koda mi o ni N100,000 ni asuwọn owo mi, ọla Ọlọrun ati Gomina Seyi Makinde nikan ni mo n jẹ"". Ridwan ni ẹ́un ọkọ ti wọn ṣeleri gan ko tii tẹ oun lọwọ koda o ni awọn adigunjale tun da oun lọna tori ikede miliọnu mẹwa naira ti oun jẹ. Sorpion Ridwan kẹnu bọ ọrọ lori bi didi eeyan olokiki ṣe ko ijiya baa. Iṣẹ́ abẹ tí Bola Tinubu ṣe ló fa àbẹ̀wò ọ̀pọ̀ èèyàn sọ́dọ̀ rẹ̀ - Fayemi Sotitobire pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn lórí ẹ̀wọ̀n gbére Kíláàsì wó lé ọmọ ilé ẹkọ́ mẹ́ta lórí, ọ̀kan ti kú, ẹ wo ohun tó ṣe méjì tó kù",28 Owewe 2021 +Ẹ̀rù ò b'odò! Mo ṣetán láti dojú ìjà kọ Tyson Fury báyìí- Anthony Joshua," Oríṣun àwòrán, Getty Images Abẹṣẹkubiojo ọmọ Naijiria to fi orilẹede UK ṣe ibuje, Anthony Joshua ti sọ pe oun ti ṣetan lati ba Tyson Fury ja. Bo tilẹ jẹ pe ọmo ilẹ Ukraine, Oleksandr Usyk ti gba bẹniti rẹ mẹtẹẹta lẹyin to lu u lalubami, AJ ni oun si le ja lai si awọn bẹniti yii. Usyk ya agbado ha sawọn eeyan lẹni lalẹ ọjọ Abamẹta lẹyin to fi ẹṣẹ gbade ori Joshua. Ṣugbọn ohun ti Joshua n sọ bayii ni pe oun kọkọ fẹ gba bẹniti oun pada lọwọ Usyk. O ni lẹyin naa ni oun le rona ati ba Fury ja. Ó bà ni kò bàjẹ́, ẹ wo ọ̀rọ̀ tí Anthony Joshua sọ lẹ́yin tí Usyk fẹ̀ṣẹ̀ gbadé orí rẹ̀ láìròtẹ́lẹ̀ Iku ogun nii pa akinkanju, iku odo nii pa omuwẹ, odo ti a ba foju di nigba mii maa n le gbe ni lọ. Abẹṣẹkubiojo Anthony Joshua ti sọrọ soke lẹyin ti akẹṣẹ jẹun ọmo ilẹ Ukraine, Oleksandr Usyk fẹṣẹ gbade lọwọ rẹ niluu London lalẹ ọjọ Abamẹta. Iyalẹnu lo jẹ fun ọpọlọpọ awọn ololufẹ AJ nigba ti Usyk bẹrẹ si ni rọ ojo ẹṣẹ le e lori ti ko si lee ta putu. Oríṣun àwòrán, Getty Images Gbogbo awọn oludajọ ija lo ni Usyk lo bori AJ pẹlu ayo 117-112, 116-112, 115-113 ni papa iṣere ẹgbẹ agbabọọlu Tottenham niluu London. Ọpọ lo ti ro pe Joshua yoo fi ẹṣẹ dabira si Usyk lara ṣaaju ija wọn, ọrọ bẹyin yọ nigba ti wọn bẹrẹ si ni lewọ sira wọn. Ẹwẹ, Joshua ti fi ọrọ ranṣẹ sawọn ololufẹ rẹ lẹyin to fidi rẹmi tan niluu London. AJ ni o ba ni, ko bajẹ, ''ọmọ akin, maṣe ba ọkan jẹ, koda gbogbo aye le maa wo lulẹ niwaju rẹ. Ẹyin araalu London mo nifẹ yin gan an, ẹ ṣe mo dupẹ gbogbo eeyan, ẹ ku gbogbo igba ti ẹ n gbaruku ti mi.'' 'Eniola Badmus wọ pátá lọ sí ààfin Oba Elegushi, ""ọ̀ín"" kí ló burú níbẹ̀?' Ọmọ ẹgbẹ́ PDP Oyo tí inú bá ń bí, ẹ kó ""mo kó - mo rò"" yín wá ká yanjú ẹ̀ - Makinde Ọkùnrin kan tó jẹ gbèsè N4.6m ni wọ́n so mọ́lẹ̀ bíi ewúrẹ́ Onigbọwọ Joshua naa, Eddie Hearn ti sọ ero rẹ lori bi Joshua ṣe fidi rẹmi ninu ija oun ati Usyk. Hearn ni o ṣeeṣe ki Joshua ti fi oju ṣeṣe tori ko le riran daadaa mọ nigba ti ija naa de ipele kẹsan an. Usyk ti di abẹṣẹkubiojo lagbaaye bayii lẹyin to gba bẹniiti mẹta lọwọ Joshua. Romeo and Juliet padà di ìwé Akinola àti Arike ní èdè Yorùbá",26 Owewe 2021 +"Omi lórí pápá ìṣeré Lekan Salami kìí ṣe tuntun, ó lè ṣẹlẹ níbikíbi - Ìjọba Oyo"," Omi lórí pápá ìṣeré Adamasingba kìí ṣe tuntun, ó lè ṣẹlẹ níbi kíbi- Ìjọba OyoSeyi Makinde ṣí pàpá ìṣeré tó fi N5.3bn tún ṣe àmọ́ òjo bàá jẹ́ lọ́jọ́ ayẹyẹ ìṣíde Ijọba ipinlẹ ti fesi lori iroyin to gba ori ayelujara nipa bi omi ṣe dagun si ori papa iṣere Adamasingba ti Gomina Seyi Makinde ipinlẹ Oyo ṣi ni Ọjọ́rú. Nigba ti o n ba BBC Yoruba sọrọ, akọwe iroyin fún Gomina Makinde, Taiwo Adisa sọ pe omi to dagun lori papa iṣere naa kii ṣe ohun ti oju ko riri. Ọgbẹni Adisa ni ""iru nkan bayii naa n ṣẹlẹ ní òkè òkun to fi mọ ninu idije Premier League gan an. Ọpọ ìgbà ni a máa n ri bi yinyin ṣe maa n jabọ, ti o si máa n ṣakoba fun papa iṣere ti wọn ti n gbabọọlu. Oríṣun àwòrán, OYSG Igba miiran gan an, wọn máa wọgile ere bọọlu ti yinyin ba ti pọju lori papa. Bakan naa lo fikun pe iṣẹ atunse papa ere idaraya naa ṣi n lọ lọwọ, ti isẹ ko si tii pari patapata nibẹ. ""Agbaṣẹse to n se atunse papa isere idaraya naa ṣẹṣẹ gbin koriko sori papa ere bọọlu ọhún, ni nkan bi oṣu meji sẹyin. Gomina Makinde si lo pinnu lati ṣi papa iṣere naa ki ẹgbẹ agbabọọlu Shooting Stars le lanfaani lati máa lo o fún igbaradi idije Super 8 wọn ni. Ijebu Ode ni Shooting Stars ti n lọ gbabọọlu lati ọjọ yii wa, eleyii ti ko si bojumu to."" O wa fikun pe o buru jai ki odidi ilu Ibadan, to jẹ olu ìlú ijọba iwọ oorun guusu Naijiria tẹlẹ má ni papa iṣere ti ẹgbẹ agbabọọlu ipinlẹ Oyo le maa lo. Idi niyii, ti ijọba fi tètè ṣi papa iṣere naa nigba ti agbaṣẹṣe ko ti pari iṣẹ lori papa iṣere naa. Seyi Makinde: Ẹ̀yin tẹ́ fẹ́ fi ọ̀rọ̀ ẹ̀sin ba Oyo jẹ́, ẹ ṣọ́ra ṣe Fún àwọn tí wọn n sọ pé ijọba na biliọnu marun o le diẹ naira (N5bn) lori papa iṣere lasan, Taiwo Adisa ni kii ṣe ori papa Adamasingba nikan ni owo wà fún o. ""Ipele mẹta ni iṣẹ lori papa iṣere Adamasingba yìí pin sí, agbaṣẹṣe ṣẹṣẹ n pari iṣẹ lọ lori ipele kinni ni iṣẹ papa iṣere naa ni. Agbaṣẹṣe sọ fún ijọba pe o kere tan, o máa to oṣu mẹta ki ori papa iṣere Adamasingba tó ṣee lo daadaa. Lara N5bn yìí naa ni agbaṣẹṣe yoo ti kọ oríṣìíríṣìí gbọngan ere idaraya pẹlu awọn ohun elo igbalode. Bakan naa, agbaṣẹṣe yóò tún kọ ile itura sí papa iṣere yìí láti lè maa ri owo ṣe àtúnṣe papa iṣere yìí,"" Adisa lo sọ bẹẹ. Amọ agbaṣẹṣe to n ṣiṣẹ atunse papa isere idaraya naa kọ láti bá BBC Yoruba sọrọ nigba ti a kàn sí lati gbọ tẹnu rẹ lori isẹlẹ to waye lana ọhun . Nnkan ayọ ati itura ni wẹliwẹli ojo maa n jẹ lọpọlọpọ igba ti o ba rọ si ori ilẹ fun gbogbo ẹda alaye. Ṣugbọn awuyewuye ni ojo to rọ l'Ọjọru nibi ayẹyẹ atunṣe papa iṣẹre Lekan Salami, to n bẹ ni Adamasingba mu lọwọ. Saaju ni gomina Seyi Makinde ti kede pe biliọnu marun ati miliọnu lọna ọọdunrun naira (N5.3bn) ni oun naa lati se atunse papa isere idaraya naa. Ọwọ eeyan si lo n foju soju sode lati pe wo papa isere awodamiẹnu naa, ti wọn lo ba tawọn ilẹ okeere mu, nigba to ba di sisi. Lara awọn eto ti wọn si la kalẹ fun ayẹyẹ sisi papa isere idaraya naa ni ifẹsẹwọnsẹ ere bọọlu laarin ẹgbẹ agbabọọlu 3SC ati NK Tabor Sezana lati orilẹede Slovenia. Ayẹyẹ iside naa bẹrẹ ni pẹrẹu ni nnkan bi i aago marun un irọlẹ, ohun gbogbo lo si n lọ leto-leto, ko to di wi pe ojo bẹrẹ ni papa iṣere naa. Lati ibẹ si ni ọpọplọpọ awọn eeyan ti o lọ wo iran ifẹsẹwọnsẹ ere bọọlu naa, ti bọ si ori itakun ayelujara lati fi aidun inu wọn han lori awọn kudiẹ-kudiẹ ti wẹliwẹli ojo naa tu sita lasiko ti ifẹsẹwọnsẹ n lọ lọwọ. Lori opo ikansiraẹni Facebook, ẹnikan ti orukọ rẹ n jẹ Morufu Smith kọọ sibẹ pe, ""Mo kọ iwe lati gbe oriyin fun Ṣeyi Makinde lori atunṣe papa iṣere Lekan Salami saaju ọjọ ayẹyẹ naa. Mo si fi kun ọrọ mi pe laipẹ laijina a o mọ boya ojulowo ni awọn nnkan ti wọn tun se nibẹ. O si ṣẹlẹ bẹẹ lasiko ti ifẹwọnsẹ n lọ lọwọ nitori ọpọlọpọ omi lo rogun si ori papa ti wọn ti n gba bọọlu, nitori ko si ibomii ti agbara ojo le ṣan si. Femi Branch: Gbogbo dúkìá mi àti ti ìyá mi ni mo tà láti tọ́jú ẹsẹ̀ mi fún ọdún méjì Sé sàgbèlójúyòyò ni ‘renovations’ tí Sèyí se ni?"". Ẹlomii to tun fi ọrọ lede, Adebisi Adeniyi ni ""ọta ẹni ki i pa odu ọya"", ti ariwo si sọ lórí omi tó kún pápá ìṣeré Lekan Salami, O fi kun ọrọ rẹ pe awọn ọta ilọsiwaju lo n binu Ṣeyi Makinde nitori ojo to rọ nibi ayẹyẹ naa. Ninu ọrọ ti ẹ, Godwin Onoghokere ni ""Gomina Makinde(Ọyọ) na N5.3BN lati ṣe atunṣe papa iṣere ṣugbọn ojo tuna aṣiri iṣẹ to ni ọwọ oṣelu ninu"". Awọn ọkanọjọkan fọnran lo ti lu ori ayelujara pa, ninu eyii ti awọn eeyan ti n ṣe afihan ibi ti omi ti n jo labẹ orule papa iṣere naa. Ọpọ araalu ti wa n beere pe ta lo jẹbi aṣiṣẹ naa laarin ijọba ipinlẹ Ọyọ ati kọngila ti wọn gbe isẹ naa fun?",2 Owewe 2021 +"Ọ̀pọ̀ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ́lù mójú lọ sọ́jà, bí kátàkárà agbábọ́ọ́lù ṣe dópin"," Oríṣun àwòrán, Getty Images Ọja kata kara ati pasipaarọ awọn agbabọọlu ti saa bọọlu yii wa sopin lọjọ kọkanlelọgbọn oṣu kẹjọ. Ọpọ ẹgbẹ agbabọọlu lo moju lọ si ọja, ti wọn si ri agbabọọlu gidi ra. Manchester United wa lara iru ikọ agbabọọlu bẹẹ lẹyin ti wọn ẹlẹsẹ ayo, Cristiano Ronaldo pada. Lati Man U yii naa ni Ronaldo ti darapọ mọ Real Madrid ko to lọ ṣoju ikọ Juventus naa lati ibi to ti pada wale. Pẹlu ọrọ aje Barcelona ti n ṣojojo, ikọ agbabọọlu ni lati da Antoine Griezmann pada si Atletico Madrid lati ya a lo fun saa bọọlu kan. Ọdun meji sẹyin ni Barcelona ra Griezmann fun £103m. Barca fi sinu adehun pẹlu Atletico pe wọn ni anfaani lati Griezmann pada ni ipari saa bọọlu yìí. Kola Tubosun: Ọ̀pọ̀ ọmọ òyìnbó ló ń kọ́ èdè Yorùbá, ẹ̀yin ọ̀dọ́ ẹ gbé èdè abínibí lárugẹ Àmọ́, Atletico ni awọn tun máa ya Griezmann lo ni ti saa bọọlu yìí bá gberasọ. Ẹgbẹ agbaọọlu Chelsea naa mójú lọ sí ọjà, koda agbabọọlu gidi ni wọn rí mu wale. Chelsea ya Saul Niguez ra lati Atletico Madrid fun saa bọọlu kan fún £3.4m. Chelsea lanfaani lati ra Niguez patapata ni ipari saa bọọlu yìí fún £30m. Niguez wa lára àwọn agbabọọlu ife ẹyẹ La Liga ni saa bọọlu tó lọ. Arsenal naa ko gbẹyin, Takehiro Tomiyasu ni wọn ra lati Bologna fún £19.8m. Arsenal ati orogun wọn, Tottenham ni wọn jọ n du Tomiyasu ki o to ja mọ Arsenal lọwọ. Awọn agbabọọlu ti Arsenal ti ra ni ọja awọn agbabọọlu ni saa bọọlu yìí jẹ £150m. Eegunjobi Omotanbaje Ajobiewe- Èébú ní wọ́n kọ́kọ́ ń bù mí nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ ẹ̀ṣà pípé ní",1 Owewe 2021 +Ṣé lóòtọ́ọ́ ni Lionel Messi lè gba ife ẹ̀yẹ Champions League fún PSG lẹ́ni ọdún 34?," Oríṣun àwòrán, Facebook/PSG Ọpọ ololufẹ ere bọọlu lo ti sọrọ nipa igbesẹ Lionel Messi lati darapọ mọ ẹgbẹ agbabọọlu PSG lati Barcelona. Awọn kan ni asiko ti to fun ẹgbẹ agbabọọlu PSG lati gba ife ẹyẹ UEFA Champions League eleyii ti wọn ko tii gba ri ninu itan wọn. Agbaọjẹ agbabọọlu orilẹede Brazil to ti fẹyin ti naa sọ pe oun n gbọ oorun Champiọns League ni PSG bayii lẹyin ti Messi darapọ mọ wọn tan. Ronadinho to ti figba kan ri gbabọọlu fun PSG ati Barcelona sọ pe ohun iwuri lo jẹ foun pe oun ti gba bọọlu fun ikọ agbabọọlu mejeeji. O ni ife ẹyẹ UEFA Champions League ko jina mọ si PSG pẹlu Messi atawọn agbabọọlu mii bi Sergio Ramos ti wọn ṣẹṣẹ ra. Messi mi ilẹ titi nigba to darapọ mọ PSG tan. Niṣe lero pejọ biba si papa isẹre Parc des Princes nibi ti ẹgbẹ agbabọọlu PSG ti fi Messi han fun gbogbo aye. Ọlatunji, akẹ́kọ̀ọ́gboyè 'graduate' tó ń ta àkàrà 'Ó ta lẹ́nu' nílùú Osogbo Nọmba 30 lo wa lara jẹsi ti Messi yoo maa wọ ni ẹgbẹ agbabọọlu naa. Ẹwẹ, gbajugbaja oniroyin to tun jẹ ololufẹ ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal, Piers Morgan ni PSG ko le padanu lori owo oṣu gọbọi ti Messi yoo maa gba. Morgan ni PSG yoo ri owo wọn pada laarin oṣu diẹ lati ara jẹsi rẹ ti wọn ba ta. Oniroyin Morgan ni witi witi lawọn ololufẹ ere bọọlu n ra aṣọ Messi, eleyii ti yoo si tẹsiwaju bẹẹ.",21 Ògún 2021 +Wo tábìlì ìṣirò Olympic tó kọjá àtàwọn orílẹ̀èdè tó ti gba àmì ẹ̀yẹ láti ọdún 2000," Oríṣun àwòrán, Olympics.Com Ere idaraya Olympic to waye nilu Tokyo lorilẹede Japan bẹrẹ ni ọjọ Ẹti, ọjọ Kẹtalelogun osu Keje ọdun 2021, to si pari ni ọjọ Aiku, ọjọ Kẹjọ osu kẹjọ ọdun 2021. Ọpọ orilẹede lo gba oniruuru ami ẹyẹ Wura Fadaka ati Baba ninu idije naa. Koda, orilẹede wa Naijiria gan gba ami ẹyẹ fadaka meji ati Baba kan ninu idije Olympic kan, ta si gbe ipo kẹrinlelaadọta. Awọn akojọpọ ree nipa awọn koko ohun to waye ninu idije naa, to fi mọ awọn orilẹede to gba ami ẹyẹ ati awọn oludije wọn. Bi ikọ kan ti se daadaa si Bi ikọ kan ti se daadaa si Bi ikọ kan ti se daadaa si",12 Ògún 2021 +Ààrẹ NFF tẹ́lẹ̀ri Oneya jáde láyé lẹ́ni ọdún 73," Oríṣun àwòrán, Google Ààrẹ ajo ere boolu NFF tẹ́lẹ̀ri Oneya ti ku lẹni ọdún mẹ́tàléláàdọ́rin. Ààrẹ ajọ ere bọọlu nigba kan ri ogagun feyinti Dominic Oneya ti jẹ Olorun nipe bi gbogbo iroyin se n gbe e jade. Oneya ti a bi ni ọjọ kẹrindilọgbọn, oṣu karun ọdun 1948, a bii ni ilu Agbarho ni Ughellli ni iroyin kan pe o ku ni owurọ ọjọbọ ni ile rẹ ni Effurun nijọba ibilẹ Uvwie nipinlẹ Delta. Aarẹ NFF lọwọ bayii Amaju Pinnick fi idi rẹ mulẹ fun awọn oniroyin pe lootọ ni Oneya ku. ""Lootọ ni o ti ku"" idahun rẹ ree fun awọn oniroyin. Ọ̀rẹ́bìnrin kó sí gbaga ọlọ́pàá lórí ẹ̀sùn pé ó gún ""Sugar daddy"" rẹ̀ pa Ẹran Akíka(Pangolin) àti ìwo Erin d'ẹ́rù b'olẹ̀, ìjọba f'òfin gba bílíọ́nù 22 ẹran ara wọn Ìjọba Eko jáwọ́ nínú ẹ̀sùn tó fi kan Ọba Ogboni pé ó pààyàn ní ìwọ́de Yoruba Nation ní Ojota Oba Gbolahan Timson shomolu: Obasanjo ti jẹ́wọ́ pé 'Mistake' ni Buhari ṣùgbọ́n... Odun 1999 si 2002 ni Oneya fi jẹ aare NFF. O ṣíṣẹ́ ni oniruuru aaye ninu igbimọ tẹẹkoto fun CAF ti o si je olori igbimọ ka ti minisita fi lọlẹ lati tun ere bọọlu ṣe ni Naijiria Bakan naa lo jẹ́ Gomina ologun ipinlẹ Kano laarin ọdun 1996 si 1998. Igi Ọ̀pẹ abàmì tó dá ní orí 42 l'Ekiti rèé o, 'bí mo ṣe ríi l'orí mi ń dìde fììì' Tunde Bakare journey in life: Bàbá bàbá mi ni Lèmọ́mù àkọ́kọ́ ní Sodeke Abeokuta ṣùgbọ́n..",5 Ògún 2021 +"Ṣàǹgbá fọ́! Ìrètí Nàìjíríà fún góòlú, Adekuroye pòfo nínú ìjànkadì ní Tokyo 2020"," Oríṣun àwòrán, @Daniel Igali facebook Gbajugbaja ajijakandi, Odunayo Adekuroye ti ọpọ eeyan ti ni ireti pe oun ni yoo gba goolu fun Naijiria ninu idije Olympiki Tokyo 2020 fidi rẹmi lairo tẹlẹ. Anastasia Nichita ọmọ orilẹ-ede Moldova lo fi iya jẹ Adekuroye niluu Tokyo. Adekuroye lo kuku n kọkọ n ṣiwaju ninu ijankadi ọhun, koda ami ayo mẹjọ si meji ni Adekuroye fi n ṣagba Nichita. Ṣadeedee kan ni nkan yi biri, ti Odunayo ṣubu loju ija. Iṣubu yii gan an lo mu ki Nichita bori ninu ija ipele ẹlẹni mẹrindilogun ọhun. Esabod, Sunday Igboho: Kò burú bí Igboho ṣe wà lẹ́wọ̀n báyìí,ọ̀rọ̀ rẹ̀ dàbí i ti aláboyún Amọ, ireti diẹ sí wa fun Adekuroye lati gba ami ẹyẹ baba tawọn oloyinbo n pe ni ""bronze."" Ṣugbọn to wà nibẹ ni pe Nichita to fẹyin Odunayo gbalẹ gbọdọ wọ Ipele aṣekagba ni Tokyo. Tunde Bakare journey in life: Bàbá bàbá mi ni Lèmọ́mù àkọ́kọ́ ní Sodeke Abeokuta ṣùgbọ́n.. Ẹwẹ, Blessing Oborududu gbarada ninu ijankadi ti ẹ. Koda, ami ẹyẹ fadaka ni Oborududu gba nigba ti ọmọ ilẹ Amẹrika, Tamyra Marianna Mensah fẹyin rẹ gbalẹ pẹlu ami ayo mẹrin sí ẹyọkan ninu ijankadi 68kg. Ọ̀pẹlọpẹ́ Ajá tí Ifa ní kí a fi ṣètùtù ní Ekiti ní 1942 ni kò jẹ́ kí ìjàmbá náà pọ̀ jù- Ol",4 Ògún 2021 +"Pàá lẹ́ẹ̀kínní, pàá lẹ́ẹ̀kejì, Germany d'áṣọ ìyà fún D'Tigers Nàìjíríà lẹ́yìn ìkọlù Australia ní Olympics"," Oríṣun àwòrán, D'Tigers/Nigerian Basketball Ẹgbẹ agbabọọlu alapẹrẹ Naijiria, D'Tigers tun ti fidi rẹmi ninu ifẹsẹwọnsẹ keji ti wọn gba ninu idije Olympics to n lọ lọwọ niluu Tokyo lorilẹede Japan. Ẹgbẹ agbabọọlu alapẹrẹ orilẹede Australia lo kọkọ fiya jẹ D'Tigers Naijiria ninu ere bọọlu ti wọn kọkọ. Ṣugbọn Germany fi ọba lee fun wọn nigba ti wọn ṣe iya airo tẹlẹ fun Naijiria pẹlu ami ayo 99-92. Germany lo kọkọ ṣiwaju ni ipele akọkọ pẹlu ami ayo 21-24 ki D'Tigers to gbafuja lọwọ wọn ni ipele keji pẹlu ami ayo 29-26. Ọmi ni awọn mejeeji jọ ta ni ipele keji, ṣugbọn Naijiria fidirẹmi ni ipele kẹrin ere bọọlu alapẹrẹ naa. D'Tigers ti n lewaju pẹlu ami ayo mọkanla ni ipele kẹta ki wọn to padanu ipo aṣiwaju wọn eyi to mu wọn fidi rẹmi. Naijiria ati Germany lo fẹyin gbalẹ ninu ere bọọlu alapẹrẹ ti wọn kọkọ kopa ninu rẹ ni idije Tokyo 2020. Oríṣun àwòrán, D'Tigers/Nigerian Basketball Nigba ti Austalia fiya jẹ Naijiria, Italy lo pokọ iya fun Germany. D'Tigers gbọdọ jawe olubori bayii ninu ere bọọlu alapẹrẹ wọn to kẹyin lọjọ Abamẹta ki to le ni ireti lati tẹsiwaju ninu idije Olympics. Ẹwẹ, agbabọọlu tẹniisi ori tabili, Aruna Quadri naa fidi rẹmi ninu ere ọwọ lori tabili to ṣe pẹlu ninu idije ọlọdanni ni Tokyo 2020. Ọmọ Brazil, Gustavo Tsuboi lo di ẹru iya le Quadri lori pẹlu ami ayo 4-2 (15-13, 9-11, 6-11, 11-7, 7-11, 6-11). Ohun to jẹ iyalẹnu ni pe ọga ni Quadri jẹ fun Tsuboi lagbo tẹniisi ori tabili lagbaaye. Amọ Quadri ni lootọọ ni Tsuboi jẹ si oun ṣugbọn o pegede ju oun lọ ninu ere ọwọ ti awọn jọ ṣe. Nibayii, orilẹede Naijiria ko tii ri ami ẹyẹ kankan gba ninu idije Toyo 2020 to n lọ lọwọ.",28 Agẹmo 2021 +Àwọn eléré ìdárayá ilẹ̀ Afrika tó yẹ kí o wò," Odun 2020 lo yẹ ki idije ere idaraya Olimpiki Tokyo 2020 ko waye, sugbọn wọn sun siwaju nitori aarun coronavirus si 2021. Gẹgẹ bi awọn ere idaraya Olimpiki Tokyo yii yoo ṣe bẹrẹ ni ọjọ kẹtalelogun (23) oṣu keje, 2021, a n fi asiko yii wo awọn elere idaraya ilẹ Afrika to yẹ ko wo ninu idije yii. Awọn elere idaraya wọnyi ni a yan lati orisirisi ere idaraya leyi ti wọn kò ṣe awọn miran ni apa ilẹ Afrika ati wipe ara awọn olukopa yii leti ni iriri olimpiki tẹlẹ ri tabi kò jẹ fun igba akọkọ wọn.ii. Taoufik Makhloufi jẹ asare aarin (awọn ere 800m ati awọn mita mita 1,500). O bẹrẹ si ni kopa ni Olimpiki odun 2012 to waye nilu London ti o si gba goolu kan nibi idije ere 1,500m ati ami fadaka meji ni Olimpiiki Rio 2016. Wali Bidani jẹ ọmọ Algeria to ma n gbe nkan to wuwo. O kopa ni Olympics fun igba akọkọ ni London 2012 Olympics, to si kopa fun igba keji ni Rio 2016 Olympics. Azenaide Carlos jẹ agbabọọlu ọlọwọ ati ọmọ ẹgbẹ agbabọọlu ọlọwọ obinrin orilẹ-ede Angola ti ọpọ mọ si 'The Pearls' Idije Olympics mẹta lo ti kopa lati ọdun 2008. Ọmọ orilẹ-ede Botswana ni Nijel Amos, to jẹ elere sisa, to si ti ami ẹyẹ fadaka fun idije 880m ti awọn ọkunrin ni London 2012 Olympic Games. Tokyo 2020 ni yoo jẹ igba kẹta rẹ. Ọmọ orilẹ-ede Burkina Faso ni Hugues Fabrice, o jẹ ọmọ ikọ Burkinabe, to si ma n fo nkan. O ti gba ami ẹy idẹ ni 2019 World Athletics Championships. Elere sisa ni Francine Niyonsaba lati orilẹ-ede Burundi. O gba ami ẹyẹ fadaka ni Rio 2016 ati 2017 World Championships ninu ere sisa 800m ti awọn obinrin. Cheick Cisse fi itan lelẹ nigba to gba ami ẹyẹ Goolu akọkọ fun Ivory Coast ni idije Rio 2016 Olympics. Oun si ni ọmọ ilẹ Afica akọkọ to gba ami ẹyẹ goolu ninu ere idaraya Taekwondo. Marie-Josée jẹ elere idaray nkan jiju lati orilẹ-ede Ivory Coast, to si ma n sa ere 100m ati 200m. O ti gba ami ẹyẹ idẹ ninu idije 100m ti awọn obinrin ni World Athletics Championships, o si tun ṣe ipo kẹrin ni Rio 2016 Olympics ninu idije 100m ati 200m. Haydy Morsy jẹ elere idaraya Pentathlon igbalode, to ma n luwẹ, to si ma n gun ẹṣin. Idije Tokyo 2020 ni igba keji ti yoo kopa ni idije Olympics ni Azmy Mehelba jẹ ẹni to ma n yinbọn, lati Egypt. Idije Tokyo 2020 Olympics games si ni igba kẹta ti yoo kopa ni idije Olympics. O gba ami ẹyẹ goolu ni idije ISSF World Cup Shotgun to waye ni oṣu Karun-un, ọdun 2021. Giana Farouk wa lati Egypt, to si ma n kopa ni ere idaray Karate. Tokyo 2020 games ni idije Olympics akọkọ ti yoo ti kopa. Ọ gba ami ẹyẹ goolu ni idije World Karate Championships lọdun 2016, ati ami ẹyẹ idẹ lọdun 2018. Merhawi Kudus, ẹni ọdun 27 jẹ ọmọ orilẹ-ede Eritrea, to ma n gun kẹẹkẹ. O ṣe ipo kẹta ni idje Turkey 2019 Cycling Tour. O bori ni idije Individual Time Trial ni 2021 Eritrean Championships. Tokyo 2020 ni idije Olympics akọkọ ti yoo lọ. Amanuel Gebreigzabhier n kopa fun igba akọkọ ni idije Olympics lọdun yii. Oun lo ṣe ipo kinni ni idje 2018 African Road Championships. Mosana Debesay jẹ elere idaraya kẹẹkẹ gigun lati Eritrea. O bori ni idije 2019 African Road Championships, ati 2018 African Road Championships individual time trial. Tẹgbọn-taburo ni oun ati elere idaraya kẹẹkẹ gigun, Mekseb Debesay Letesenbet Gidey jẹ ọmọ orilẹ-ede Ethiopia to ma n sa maratọọni, o si ti gba ami ẹyẹ ni agbaye. Gidey ni orukọ rẹ wa ninu iwe akọsilẹ lagbaye fun bo ṣe bori ni idije 5000m ti awn obinrin, to si tun bori ni 10,000m laipẹ yi. O gba ami ẹyẹ fadaka ni idije awọn obirin fun 10,000m nibi idije 2019 World Athletics Championships. Selemon Barega wa lati Ethiopia, p su ma n sa ere ọna jijin. O gba ami ẹyẹ fadaka ni idije awọn ọkunrin fun 5000m ni idije 2019 World Athletics Championships. Tokyo 2020 ni idije Olympics akọkọ ti yoo yi kopa. Yomif Kejelcha jẹ elere sisa lati Ethiopia, ti yoo kopa ni Olympics fun igba akọkọ ni Tokyo Games. Kejelcha ti gba ami ẹyẹ goolu ri ni idije 3000m ti awọn ọkunrin, ni 2018 World Indoor Championships. O tun gba ami ẹyẹ fadaka ni 10,000m ti awọn ọkunrin ni 2019 World Athletics Championships. Lelisa Desisa wa lati Ethiopia, o jẹ elere sisa maratọọnu, o si ti gba ami ẹyẹ goolu ni 2019 World Athletics Championships. Shura Kitata jẹ elere idaraya maratọọnu lati Ethiopia O gba ami ẹyẹ goolu ni 2020 London Marathon, o si tun lu ọmọ Kenya, Eliud Kipchoge to bori rẹ ni 2018. Gudaf Tsegay jẹ aṣare agbedemeji ara Ethopia to lamilaka ami-ẹyẹ awọn obinrin 1,500 mita ni agbaye ni ilu Liévin, France ni oṣu keji odun 2021. Arabinrin naa si tun gba idẹ ni idije ọdun 2019 Gina Bass jẹ elere sisa Gambia to gba ami-ẹyẹ ni idije200m tí àwọn obinrin ni Rabat 2019. Awọn idije Tokyo ni yoo jẹ ẹlẹkeji rẹ ni Olimpiki Julius Yego jẹ olujunkan Kenyan to gba ami ẹyẹ fadaka ni Olimpiki to waye ni Rio lọdun 2016 Wọn fun ni inagije 'Mr Youtube' nitori bo ṣe mọ iṣẹ ọhun latara wiwo fọran lori Youtube Brigid Kosgei jẹ asare Kenya to lamilaaka ni odun 2018 ati 2019 nibi idije Chicago marathon ati ilu London 2019 ati 2020 Kosgei jẹ ẹni to di ami ẹyẹ agbaye lọwọ + pẹlu akoko 2:14:04 to gba ni Chicago marathon ọdun 2019. Idije Tokyo ni akoko ti yoo kopa. Eliud Kipchoge jẹ ẹni ti ere jẹ iṣẹ rẹ Ọmọ Kenya ọhun jẹ ẹni to di ami ẹyẹ agbaye mu pẹlu igba 2:01:39 ni ọjọ kẹrindinlogun oṣu kẹsan ọdun 2018 nibi Berlin Marathon. Otungba ami ẹyẹ goolu ni olimpiki Rio lọdun 2016 Beatrice Chepkoech lo jẹ ẹni ti ami ẹyẹ agbaye si wa lọwọ rẹ fun ere Steeplechase Asare orilẹede Kenya to ni goolu fun 3,000 SSteplechase ni idije odun 2019. Faith Kipyegon jẹ asare orilẹede Kenya to gba ami ẹyẹ goolu fun 1500m ni idije Rio Olimpiki lọdun 2016 O tun gba fadaka nibi idije agbaye lọdun 2017 ati omiran ni odun 2019. Khadija Mardi jẹ afẹṣẹja ọmọ ilu Morocco. O kopa ninu Awọn ere Olimpiiki Rio 2016 ṣugbọn o padanu ni agbedemeji obinrin (69-75kg) nibi ipele quarter finals O tun gba ami-idẹ kan níbi ere ẹlẹṣẹ obinrin ni odun 2019 Rababe Arafi jẹ aṣare Moroccan kan ti o gba goolu ni 1500m 2019 IAAF Diamond League ti awọn obinrin. Idije Tokyo 2020 ni yoo ẹlekeji rẹ ti yoo kopa Ramzi Boukhiam jẹ yan iṣẹ ere sisa oju omi laayo Idije Olimpiki yii ni yoo jẹ akọkọ rẹ ati wipe ohun si ni yoo koko soju orilẹede Morocco nibi ere sisa ori omi. Soufiane El Bakkali wa lati orilẹ-ede Morocco. O gba ami ẹyẹ fadaka ni idije awọn ọkunrin fun 3,000m steeplechase ni 2017 IAAF World Championships. Rio 2016 Olympics ni Olympics akọkọ to ti kopa. Maria Machav jẹ awakọ oju omi to wa lati Mozambique, yoo si kopa ni idije Olympic Games fun igba akọkọ ni Tokyo 2020. Ọmọ orilẹ-ede Mozambique ni Deisy Nhaquile. O jẹ awakọ ori omi ti yoo kopa ni idije Olympic Games fun igba akọkọ ni Tokyo 2020. o bori ni idije 2019 Afican Sailing Championships ni 420 Radial Laser class. Tokyo 2020 ni idije Olympics akọkọ ti Denise Parruque, ọmọ orilẹ-ede Mozambique to jẹ awakọ oju omi, yoo ti kopa. Oun ati akẹẹgbẹ rẹ, Maria, to bori ni idije 2019 Africa class 470 regatta. Maike Diekmann jẹ ọmọ orilẹ-ede Namibia, o ma n tukọ oju omi, yoo si ṣoju Namibia fun igba akọkọ ninu idije yii ni Olympic Games. Beatrice Masilingi jẹ elere sisa lati Namibia. Oun si ni elere sisa 400m to jẹ ẹnikẹta ti ọjọ ori rẹ ko to 20,to yára julọ l'agbaye. Amọ o, wọn ko ni i jẹ ko sare ni idije Olympics nitori eroja testosterone to pọju lara rẹ. Ṣugbọn, yoo kopa ni idije 200m. Christine Mboma jẹelere sisa lati Namibia, o si ṣe nkan ti ko ṣẹlẹ ri lagbaye ni ọdun 2021 ni abala awọn ti ọjọ ori wọn wa ni abẹogun ọdun to sa idije 400m. Amọ o, wọn ko ni i jẹ ko sare ni idije Olympics nitori eroja testosterone to pọju lara rẹ. Ṣugbọn, yoo kopa ni idije 200m. Ọmọ orilẹ-ede Niger ni Aminatou Seyni, elere sisa to kopa ni idije 2019 World Championships. Elere sisa ati ẹni to ma n fo nkan ni Blessing Okagbare, ọmọ orilẹ-ede Naijiria. O ni akọsilẹ nipa rẹ ti ẹnikẹni ko ni iru rẹ, fun bo ṣe pari ere sisa 100m laarin iṣẹju aaya 10.75, to si tun ṣe ju bẹẹ lọ ni oṣu Kẹfa, ọdun 2021 pẹlu 10.63. Oun lo yara julọ ni Naijiria ati Africa.Oun ati ọmọ orilẹ-ede Jamaica, Shelly-Ann, to bori ni idije Fraser-Pryce lọdun 2021 lo wa ni ipo kan naa Elizabeth Anyanacho ni obinrin, ọmọ orilẹ-ede Naijiria keji ati ẹni akọkọ lati ọdun 16 sẹyin, to ni anfaani lati kopa ni idije Olympics fun ere idaraya Taekwondo. Idije Rio 2016 Olympics ni Divine Oduduru ti kopa fun igba akọkọ Oun nikan ni elere sisa lati Naijiria to de ipele 'semifinal' laarin awọn ọkunrin to n sare. Tobi Amusan jẹ elere sisa, to tun ma n fo nkan, lati Naijiria, O gba ami ẹyẹ goolu ni idije 100m ti awọn obinrin nibi Gold Coast 2018 Commonwealth Games ni Australia. 2016 Rio Olympics ni Olympics akọkọ to ti kopa, o si de ipele 'semifinal', ṣugbọn ko de ipelel to kẹhin, nitori pe o sẹ ipo kẹta. Ese Brume jẹ ẹnikan lara obinrin ilẹ Africa mẹta to ma n fo, to si tiu tayọ &m Rio 2016 Games ni idije Olympics akọkọ to ti kopa. O si ṣe ipo karun-un. O gba ami ẹyẹ idẹ ni 2019 World Athletics Championships. Ọmọ orilẹ-ede Naijiria ni Chukwuebuka Enekwechi. O ma n sẹ ere idaraya Shot Put, o si gba ami ẹyẹ fadaka ni idije 2018 Commonwealth Games. O tun ṣe ipo kẹjọ ni 2019 World Championships, eyi to mu ko jẹ elere idaraya ọkunrin, ọmọ Naijria kan ṣoṣo to de ipele to kẹhin Usheoritse Itsekiri jẹ elere sisa lati Naijiria to ti gba ami ẹyẹ idẹ, to tun gba ami ẹyẹ rẹ lati ilẹ okeere fun igba akọkọ ninu ere sisa 100m ti awọn ọkunrin ni African Games ni Rabat. Esther Toko jẹ atukọ oju omi lati Naijiria, to ti gba ami ẹyẹ idẹ ati fadaka ni Cape Verde 2019 African Beach Games. Tokyo ni idije Olympics akọkọ to n lọ. Eyi to mu ko jẹ atukọ oju omito n gbe ni Naijiria ti yoo kọkọ ṣoju Naijiria ni Olympics. Ayomide Emmanuel Bello yoo kopa fun igba akọkọ ni Olympics, gẹgẹ bi obinrin akọkọ to n wa ọkọ oju omi 'canoe' lati Naijiria ti yoo kopa ni idije naa. Bello gba ami ẹyẹ goolu mẹrin ni idije Rabat 2019 African Games ni C-1 200m, C-1 500m, C-2, 200m ati C2 500m. Rodney Govinden yoo ṣoju Seychelles ni Tokyo 2020 Olympics Games. Idije Olympics keji ti yoo ti kopa re e , lẹyin Rio 2016. O bori ni idije 2019 Seychellois of the Year Award. Wayde Van Nierkerk jẹ ọmọ orilẹ-ede South Afirca, to jẹ elere sisa to ti gba mi ẹyẹ goolu ni Rio 2016 Olympics, ni idije ere sisa 400m. O di ipilẹ tuntun iṣẹju aaya 43.03 lelẹ ni agbaye, eyi to fi gba a mọ ẹni to yara ju tẹlẹ, Michael Johnson, ọmọ orilẹ-ede America. Chad le Clos jẹ omuwẹ lati orilẹ-ede South Africa, to ti gba ami ẹyẹ lọpọlọpọ. Lara wọn ni goolu kan ni London 2012 Olympics, ati fadaka meji ni Rio 2016 Olympics. Asare ori ọdan ni Akani Simbine to jẹ ọmọ orilẹ-ede South Africa ni ipele 100m ni idije Commonwealth to waye lọdun 2018. O ṣe ipo kẹrin ni 2019 World Championships. Caitlin Rooskrantz ti ṣetan lati kopa fun igba akọkọ ni 2020 Tokyo Olympics Ọmọ orilẹ-ede South Afirca naa bori ni idije 2018 African Artistic Gymnastics Championships ati Hungary 2019 Artistic Gymnastics World Cup Challenge Yoo kopa fun igba akọkọ ni idije Olympics, ni Tokyo 2020 Olympics Erin Sterkenburg jẹ ọmọ orilẹ-ede South Africa, to ma n gun nkan. oun si ni ọmọ Africa akọkọ to ti yoo kopa ni idije oke gigun ni idije Tokyo 2020 Olympic Games. O bori ni idije 2020 IFSC Africa Championships Ọmọ orilẹ-ede South Africa ni Henri Schoeman. O jẹ elere idara Triathon, to gba ami ẹyẹ goolu lasiko idije Gold Coast 2018 Commonwealth Games. O gba ami ẹyẹ idẹ ni idije triathlon,awọn ọkunrin ni Rio 2016 Olympics Boipelo Awuah ni elere idaraya 'skateboard' akọkọ lati south Africa to kopa ni Olympics. Oun naa ni elere idaraya ti ọjọ ori rẹ kere ju nu idije naa. Ikọ Rugby South Africa Sevens, to tun n jẹ́ Blitzboks gba ami ẹyẹ idẹ, ni Rio Olympics 2016. Ipo keji ni wọn ṣe ni idije Rugby Sevens World Cup ni 1997. Oussama Mellouli, jẹ omuwẹ lati orilẹ-ede Tunisia, to gba ami ẹyẹ goolu fun idije mita 1500, ti awọn ọkunrin ni Beijing 2008 Olympics, ati idije liluwẹ, maratọọnu o ni kilomita 10 ni London 2012 Olympics. Marwa Amri jẹ ọmọ orilẹ-ede Tunisia, to ma n ja ijakadi. O gba ami ẹyẹ idẹ ni Rio 2016 Olympics. Eyi to mu ko jẹ obinrin Africa akọkọ to gba ami ẹyẹ ninu ijakadi ni idje Olympics. Ọmọ orilẹ-ede Tunisia ni Ines Boubakri. O ma n fo odi. O si gba ami ẹyẹ idẹ ni idije awọn obinrin ni Rio 2016 Olympics. Jacob Kiplimo jẹ ọmọ orilẹ-ede Uganda, to pari ere sisa mita 3000, ni idije awọn ọkunrin ni 2020 IAAF Diamond Golden Gala. Tokyo 2020 ni yoo jẹ idije keji to ti kopa lẹyin Rio 2016. Roland Musagala jẹ ọmọ Uganda to kopa ninu idije Olympic ninu ere sisa fun igba akọkọ lọdun 2016. O gb a goolu ni liigi Diamond ati ni Paris pẹlu Ọmọ orilẹ-ede Uganda ni Joshua Chep tegei. O ti gba ami ẹyẹ goolu ni idije ere sisa oni mita 10,000 ni idije World Athletics Championships lọdun 2019, o tun ṣe nkan ti ko ṣẹlẹ ri nigba to bori ere sisa mita 5,000 ni idije Monaco 2020 Diamond League. Elere idaraya 'steeplechase' ni Peruth Chemutai. O pari ere ije steeplechase o ni mita 3,000 ni Rio 2016 Olympics. Bakan naa lo ṣe ipo karun-un, ni idije 'steeplechase' o ni mita 3,000 ti awọn obirin lọdun 2019 lasiko World Athletics Championships. Ẹgbẹ agbabọọlu awọn obinrin ni Zambia, Cpper Queens tabi She-Polopolo, yoo kopa fun igba akọkọ ni idije Olympics ni Tokyo 2020 lọdun yii Ọdun yii ni igba akọkọ niyii, ti Scott Vincent yoo kopa ni Olympics. Lọdun 2019, ipo kẹrin ni ọmọ orilẹ-ede Zimbabwe ọhun ṣe ni idije Japan Open Golf Championships. Ẹgbẹ agbabọọlu Alapẹrẹ ti Naijira, D'Tigers, lo gba tikẹẹti kan ṣoṣo to bọ si Africa fun idije Tokyo 2020 olympics, nibi idije 2019 FIBA Basketball World Cup. Ẹgbẹ agbabọọlu Alapẹrẹ ti Naijira, D'Tigers, lo gba tikẹẹti kan ṣoṣo to bọ si Africa fun idije Tokyo 2020 olympics, nibi idije 2019 FIBA Basketball World Cup. Awọn akọni ilẹ Africa ọhun, tun na Australia ati USA ni oṣu Keje, ọdun 2021, lasiko idije ọlọrẹ-sọrẹ meji ọtọọtọ to waye ṣaaju Olympics Ẹgbẹ agbabọọlu ọlọwọ, ti awọn obinrin ni orilẹ-ede Angola, The Pearls, lo gba ife 2021 African Women's Handball Champions. Wọn ṣe ipo kẹjọ ni Rio 2016 Olympics, lẹyin ti wọn ja ni ipele 'Quarter finals'. Ilana ta lo: Awọn elere idaraya Afirika wọnyi ṣe aṣoju awọn oriṣiriṣi awọn agbegbe nílẹ Afrika. Wọn yan wọn lori iriri wọn ní Olimpiki, awọn ami ẹyẹ ti wọn gba ati iyasọtọ ti iṣẹlẹ ere idaraya wọn. Igboriyin: Olootu atẹjade Nkechi Ogbonna, Princess Abumere pẹlu Muthoni Muchiri. Ayaworan Olaniyi Adebimpe àti Millicent Wachira. Iṣẹ ayelujara: Purity Birir. Atilẹyin afikun: Sally Morales and Celestine Karoney. Aworan: Getty Images, The International Basketball Federation, AFP, Nigerian News, Nigerian Rowing Canoeing and Sailing Federation, Nigerianews, Mekseb Debesay, Sailing Club of Mozambique, Giana Farouk, EPA, Press Focus/News Pix via PA, Erwythereyet via Twitter, Bruce Viaene via Olympics, ClimbZA, DW via Club of Mozambique.",22 Agẹmo 2021 +Ǹjẹ́ àsìkò ti tó fún England báyìí láti gba ife ẹ̀yẹ EURO?," Oríṣun àwòrán, Getty Images Bi ẹgbẹ agbabọọlu England ṣe gbajugbaja to, wọn ko tii gba ife ẹyẹ EURO ri ninu itan wọn. O ti pe ọdun marundinlọgọta ti England ti de ipele aṣekagba idije bọọlu afẹsẹgba to gbojigan kẹyin lẹyin ti wọn gba ife ẹyẹ agbaaye lọdun 1966. Eyi túmọ si pe England ko tii de ipele aṣekagba idije EURO ri. Akọnimọọgba ẹgbẹ agbabọọlu England, Gareth Southgate ko ṣai mọ eleyii, idi ree ti o fi kepe awọn agbabọọlu rẹ lati fakọyọ nigba ti wọn ba koju Denmark ninu ifẹsẹwọnsẹ to kangun sí aṣekagba alẹ Ọjọru. Southgate ni lootọọ ni England ko tii de ipele aṣekagba idije EURO ri, ṣugbọn o ni awọn agbabọọlu oun ti ṣetan lati ṣe iwuri fun orilẹ-ede wọn. O ni awọn agbabọọlu to n ṣoju England lọwọ yii le jẹ ikọ agbabọọlu akọkọ ti yoo gbe England wọ ipele aṣekagba idije EURO. Southgate fikun ọrọ rẹ pe nkan idunnu ati iwuri lo jẹ pe gbogbo eeyan ilẹ Gẹẹsi lo wa lẹyin awọn. ""A ti wa ni igbaradi fun ifẹsẹwọnsẹ pẹlu Denmark ti yoo waye ni papa iṣere Wembley. Awọn agbabọọlu wa ti ni iriri ipele yii ri lẹyin ti a de ipele to kangun sí aṣekagba ninu idije ife ẹyẹ agbaaye ọdun 2018 ni Russia. A mọ pe ko le rọrun pẹlu Denmark ṣugbọn ere bọọlu ti gbogbo eeyan yoo gbadun ni,"" Southgate lo sọ bẹẹ. Akọnimọọgba ilẹ Gẹẹsi ni ko si ewu loko fún ikọ England afi giri aparo lasan. Southgate ni Denmark lo le maa kọminu nitori awọn ni wọn ti gba ife naa lọdun 1992.",7 Agẹmo 2021 +Tábìlì àmì ẹ̀yẹ Olympic Tokyo 2020," Idije mẹtalelogun ọtọọtọ ati ifigagbaga ojilelọọdunrun o din ẹyọ kan ni yoo waye ninu idije ere idaraya Olympic fọdun 2020. Ibudo mejilelogoji kaakiri orilẹede Japan ni awọn idije naa yoo ti maa waye. Oju opo yii ni yoo maa se afihan tabili ami ẹyẹ ti wọn gba, bẹẹ ni yoo maa gbe esi bi idije naa se n lọ si funra ara rẹ lati se afihan iye ami ẹyẹ Wura, baba ati Idẹ ti ikọ elere idaraya kọọkan gba ninu idije naa. Ami ẹyẹ akọkọ nireti wa pe wọn yoo fun ẹni to jawe olubori lọjọ Kẹrinlelogun osu Keje ọdun 2021. Bi ikọ kan ti se daadaa si",1 Agẹmo 2021 +Israel Adesanya dúró sókè ténté nínú ìjàkadì UFC lẹ́yìn tó fẹ̀ṣẹ́ fọ́ Vettori lẹ́nu," Oríṣun àwòrán, Getty Images Ajijakadi ọmọ Naijiria, Israel Adesanya ti jẹwọ ara rẹ bii ọmọ Akin lẹyin to fọ Marvin Vettori lẹnu ninu ija UFC 263 to waye lalẹ ọjọ Abamẹta ni gbagede Gila River. Aṣeyọri naa ti mu ki Adesanya si wa lori itẹ gẹgẹ bii ajijakadi to lamilaaka julọ ni ipele ""middleweight"" ni UFC. Lẹyin ti ijakadi naa de ipele karun ni awọn to n dari rẹ sọ pe o to gẹ, ti wọn si kede maaki 50-45, 50-45, 50-45 gẹgẹ bii esi ijakadi ọhun, eyii fi han pe Adesanya lo gbegba oroke. Eyii ni igba keji ti Adesanya yoo fagba han Vettori ninu idije UFC. Igba akọkọ ti awọn mejeji kọkọ wọya ija ni oṣu Kẹrin ọdun 2018, eyii to jẹ ijakadi keji ti Asdesanya yoo kopa ninu rẹ ni UFC. Oríṣun àwòrán, Getty Images Bo tilẹ jẹ pe Vittori halẹ ni abala akọkọ ijakadi ọhun, ṣugbọn Adesanya fagba han an pẹlu ọpọlọpọ ẹṣẹ ati ikuku. Adesanya lo bori ija ọhun bo tilẹ jẹ pe Vittori ti kọkọ n lẹnu ṣaaju pe oun yoo fi ọpalamba ija jẹ Adesanya. Aṣeyọsri yii ni igba kẹta ti Adesanya yoo ṣe jaweolubori gẹgẹ bii ajijakadi to milẹ julọ ni ipele middlewweight ni UFC.",13 Òkùdu 2021 +Wo ìdí tó fi rọrùn fún Chelsea láti bu ìfọ́jú lu Manchester City lẹ́ẹ̀mẹẹ̀ta léra wọn," Oríṣun àwòrán, Getty Images Yoruba bọ, wọn ni paa lẹẹkinni, paa lẹẹkeji, paa lẹẹkẹta. Bi oju ọhun ko ba fọ, yoo di bai bai. Bayii ni Chelsea ṣe dijgbaju olooyi ru Manchester City nini ifẹsẹwọnsẹ aṣekagba UEFA Champions to waye lalẹ ọjọ Abamẹta ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu karun ọdun 2021. Ninu idije Premier League ni Chelsea ti kọkọ fagba han Man City lẹyin ti Thomas Tuchel di akọnimọọgba Chelsea. Kẹrẹ kẹrẹ, Man City ati Chelsea tun pade nini ipele to kangun si aṣekagba idije FA Cup, iya naa lo tun bade fun Man City lọwọ Chelsea. Ọpọ lo ti ro pe ina eṣi ko le jo Man City nigba mẹta lere wọn, amọ ina yii jo wọn raurau nio. Aṣeju Pep Guardiola ṣakoba fun Manchester City Ọpọ onimọ nipa ere bọọlu ni wọn ti di ẹbi ru olukọni Man City, Pep Guardiola fun aṣeju nipa bi o ṣe maa n to awọn agbabọọlu to maa n lo fun awọn ifẹsẹwọnsẹ to lamilaaka. Iru iṣẹlẹ yii ti ṣẹlẹ fun igba meji ninu idije Champions League nigba ti ẹgbẹ agbabọọlu Lyon ati Monaco lo City jade ninu idije naa lai ro tẹlẹ. Oríṣun àwòrán, Getty Images This is Chelsea's second Champions League win after winning the title in 2012 Ohun to ya gbogbo eeyan lẹnu to fi mọ olukọni Chelsea fun ra rẹ, Tuchel ni pe Guardiola ko fi agbaọjẹ agbabọọlu arin gbungbun rẹ Fernandinho sara awọn to bẹrẹ ifẹsẹwọnsẹ aṣekagba Champions League ọjọ Abamẹta. Ohun to tumọ si nipe ko si agbabọọlu to le di aarin mu fun City ni wọn igba ti o jẹ pe Rodri tabi Fernandinho ko si nibẹ. Eyi lo ṣakoba fun City nitori ti wọn ba ti lọ siwaju bayii ni Chelsea ri ọna lọ si ile wọn lati ṣe wọn ni suta. Apa keji ere bọọlu naa ni Guardiola gbe Fernadinho wọle, ṣugbọn ẹpa ko boro mọ.",30 Èbibi 2021 +"Chelsea pòfo nínú ìdíje FA Cup, báwo ni Champions League yóò ṣe rí pẹ̀lú Man City?"," Oríṣun àwòrán, Getty Images Gbangba yoo dẹkun, kedere yoo si bẹẹ wo lalẹ ọjọ Abamẹta nigba ti ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea ati Manchester City ba waako ninu ifẹsẹwọnsẹ aṣekagba idije UEFA Champions League ti saa bọọlu 2020-2021. Papa iṣere Estadio do Dragao ni Porto lorilẹede Portugal ni ifẹsẹwọnsẹ to lamilaaka ọhun yoo ti waye ni deedee ago mẹjọ alẹ. Gbogbo eto lo ti to fun ifẹsẹwọnsẹ naa lati gberasọ lalẹ ọjọ Satide. Awọn ohun to yẹ ki ẹ mọ niyii nipa ifẹsẹwọnsẹ Champions League alẹ ọjọ Abamẹta ni Porto. Akọkọ ni pe, ẹgbẹ agbabọọlu ilẹ Gẹeṣi ni Chelsea ati Man City ti wọn yoo jọ ta kangbọn ninu aṣekagba idije UEFA Champions League. Man City ko tii gba ife ẹyẹ Champions League ri, koda igba akọkọ ree ti wọn n kopa ninu aṣekagba idije naa. Chelsea ni ti wọn ti gba idije naa lẹẹkan nigba ti wọn lu Bayern Munich lọdun 2012. Oríṣun àwòrán, EPA Chelsea ti fagba han Man City lẹẹmeji laipẹ yii ninu idije FA Cup ati idije Premier League. Ẹgbẹrun mẹrindinlogun abọ oloworan ni yoo lanfaani lati wo ere bọọlu naa ni Porto. Oríṣun àwòrán, Getty Images Awọn ikọ mejeeji lawọn agbabọọlu dantọ lati kopa ninu idije alẹ ọjọ Satide ayafi Ilkay Gundogan Man City to kọlu Fernandinho nigba ti wọn n gbaradi. Akọnimọọgba Man City, Pep Guardiola ti gba ife ẹyẹ Champions League nigba meji lasiko to fi jẹ olukọni Barcelona. OLukọni Chelsea ni tiẹ, Thomas Tuchel ko ti gba ife naa ri gẹgẹ bi akọnimọọgba. Amọ, oun lo gbe ẹgbẹ agbabọọlu PSG wọ aṣekagba idije ọhun ni saa bọọlu to lọ, ṣugbọn Bayern Munich fagba han wọn lati gba ife naa.",29 Èbibi 2021 +"Aston Villa fọ́ Chelsea lẹ́nu, àmọ́ Tottenham daṣọ àṣírí bò wọ́n"," Oríṣun àwòrán, Getty Images Ẹgbẹ agbabọọlu ti pegede lati kopa ninu idije Champions league ti saa to n bọ lẹyin ti wọn ṣe ipo kẹrin, bi o tilẹ jẹ pe Astọn Villa san bantẹ iya fun wọn jẹ. Pẹlu ọpọlọpọ idunnu ni ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea fi side eto lori papaa, amọ ẹgbẹ agbabọọlu Astọn Villa na fihan pe awọn ko wa sere. Oríṣun àwòrán, Reuters Agbabọọlu mẹwaa lo pari ifẹṣẹwọnṣẹ naa lori papa lẹyin ti Balogun ikọ Chelsea, Cesar Azpilicueta gba Red Card nitori aṣemaṣe. Amọ, adura gba fun ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea nitori ikọ Leicester City to fidi rẹmi nile nigba ti wọn koju ẹgbẹ agbabọọlu Tothemham. Eyi tumọ si wipe Chelsea pari pẹlu ami ayo 67 lori tabili nigba ti Leicester City pari pẹlu ami ayo 66. Team P GD Pts Man City 38 51 86 Man Utd 38 29 74 Liverpool 38 26 69 Chelsea 38 22 67 Leicester 38 18 66 Oríṣun àwòrán, Getty Images",23 Èbibi 2021 +Òjò àrọ̀rọ̀dá gbẹ̀mí àwọn ènìyàn 25 tó ń ṣeré ìdárayá," Oríṣun àwòrán, STR/AFP via Getty Images Awọn elere idaraya ori papa mọkanlelogun ti ku lorilẹede China lẹyin ti iji lile deede bẹrẹ lasiko ti wọn sare oni ọna gigun ni iha ariwa orilẹede naa. Iji lile naa to mu ojo arọrọda dani to to iwọn kilo mita ọgọrun un 100km (60-mile), in agbegbe Gansu ni opin oṣẹ. Pẹlu ayọ ati idunnu ni awọn elere idaraya naa fi tu yaya-tu yaya jade ni ọjọ Satide, ti wọn si wọ aṣọ penpe pẹlu asia idije ere idaraya naa. Amọ, ko i tii ju wakati mẹta ti idije naa bẹrẹ ni iji lile bẹ silẹ, ti ojo lile si tẹre, eleyii to fi mu ki oju ọjọ tutu ju bo ṣe yẹ lọ. Oríṣun àwòrán, STR/AFP via Getty Images Amọ awọn elere idaraya to kopa ninu idije naa ni lọwọ aarọ ni oju ọjọ ti fihan pe ojo diẹ le rọ, amọ ko sẹni to sọ fun wa pe ojo naa yoo pọ to bẹẹ. Awọn alakoso ere naa da a duro nigba ti awọn eniyan to le ni mejilelaadọsan ninu awọn elere naa di awati, ti wọn si bẹrẹ si ni wa wọn. Oríṣun àwòrán, CCTV via Reuters Lara awọn ti wọn ri ninu awọn to sọnu naa ni otutu aya pẹlu aisan ti dede kọlu wọn lasiko ti wọn n wa wọn. Awọn olotu eto ilera lorilẹede naa ni eniyan mọkanlelaadọjọ ni wọn ti wa ni alaafia bayii, ti mẹjọ ninu wọn si farapa. Ọkan lara awọn to jajabọ ninu iṣẹlẹ naa ni bi oun ṣe ri pe ojo naa n pọsi, ni oun ti yipada lọ si inu ile itura ohun, to si jawọ ninu idije naa. Bi iṣẹlẹ naa ṣe waye ni awọn oṣiṣẹ pajawiri ti bẹrẹ si ni wa awọn eniyan to ṣọnu sinu iji lile naa pẹlu ohun elo igbalode ti wọn fi wa wọn. Amọ, awọn araalu koju oro si iṣẹlẹ yii ti wọn si dẹbi ru ijọba wi pe ko bojuto ere idaraya naa nipa pipese ohun idaabobo fun awọn to n kopa ti ohunkohun ba sẹlẹ.",23 Èbibi 2021 +"Leicester ṣẹ́ṣó ìyà fún Man United, Man City gba ife ẹ̀yẹ Premier League ti sáà yìí"," Oríṣun àwòrán, Twitter/Kevin de Bruyne Ẹgbẹ agbabọọlu Manchester City ti gba ife ẹyẹ Premier League fun saa bọọlu yii. Man City gba ife naa lẹyin ti Leicestrer City lu Man U mọle pẹlu ami ayo meji sẹyọkan lọjọ Iṣẹgun. Ami ayo mẹwaa ni Man City fi n ṣiwaju United ninu eyi ti wọn si ni ifẹsẹwọnsẹ mẹta pere to ku ti wọn yoo gba ti saa yii yoo fi pari. Igba kẹta ti Man City yoo gba ife ẹyẹ Premier League ree laarin ọdun mẹrin ti Pep Guardiola ti di akọnimọọgba wọn.",11 Èbibi 2021 +Chelsea fi ogun ẹ̀yìn ja Manchester City ṣáájú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ àṣekágbá Champions League," Oríṣun àwòrán, Getty Images Lọjọ Abamẹta ni ẹgbẹ agbabọọlu Manchester City ko ba gba ife ẹyẹ idije Premier League ti saa bọọlu yii to ba jẹ pe wọn lu Chelsea ni papa iṣere Etihad. Ṣugbọn Man City ni lati duro di ọjọ mii ki wọn to le gba ami ẹyẹ naa nitori Chelsea ti ẹyin gbe ru wọn. Raheem Sterling lo kọkọ gba goolu sawọn Chelsea ni abala akọkọ ifẹsẹwọnsẹ naa. Lẹyin naa ni Manchester City tun ri pẹnariti eyi ti wọn gbe fun Sergio Aguero wi pe ko gba. Ṣugbọn akọ ni Aguero fi gba pẹnariti ọhun eyi ti golu Chelsea mu lai laagun rara. Abala keji ere bọọlu naa ni Chelsea ni sọji mọ Man City lọwọ. Hakim Ziyech lo kọkọ da goolu ti Sterling gba wọle pada, ki Marcos Alonso to fi ọba le. Ni bayii, Man City ṣi le gba ife ẹyẹ EPL lọjọ Aiku ti Aston Villa ba lu Manchester United ni Villa Park. Lọjọ kọkandinlọgbọn oṣu karun un lawọn mejeeji yoo jọ pade ninu ifẹsẹwọnsẹ aṣekagba idije Champions League.",8 Èbibi 2021 +Ìwọ́de àwọn olólùfẹ́ Man U fọwọ́ ago sẹ́yìn fún Man City láti gba ife ẹ̀yẹ Premier League," Oríṣun àwòrán, Reuters Manchester United lo wa ni ipo keji ninu idije Premier League Lẹyin tawọn ololufẹ ẹgbẹ agbabọọlu Manchester City ati Liverpool ti wa ni ikalẹ kaakiri agbaaye lati wo ifẹsẹwọnsẹ wọn to yẹ ko waye lọjọ keji oṣu karun un ọdun 2021, lawọn alaṣẹ idije Premier League kede pe wọn ti sun ifẹsẹwọnsẹ naa siwaju. Idi abajọ ni pe ọgọọrọ awọn ololufẹ Man U yabo papa iṣere Old Trafford nibi ti wọn ṣe iwọde tako ẹbi Glazer to ra ẹgbẹ agbabọọlu naa lori bi Man U ṣe wa lara awọn ikọ agbabọọlu mẹfa to buwọlu iwe lati yapa lọ da idije European Super League ti ko kẹsẹ jari. Bakan naa ni wọn lo ifẹhonuhan ti wọn ṣe lati sọ fun ẹbi Glazer pe ki wọn yọwọ lọrọ Man United pe ki wọn ta ikọ agbabọọlu naa ni kiakia. Awọn alaṣẹ idije Premier League yoo ṣepade pẹlu Man U ati Liverpool bayii lati sọ ọjọ ti ifẹsẹwọnsẹ naa yoo waye. Niiṣe ni ero kun ita papa iṣere Old Trafford biba, nigba tawọn kan ninu wọn rapala wọle ti wọn si duro sori papa iṣere naa. Awọn alaṣẹ idije liigi naa sọ pe abo awọn eeyan to wa ni papa iṣere Old Trafford lọjọ Aiku lo ṣe koko. Oríṣun àwòrán, Getty Images Police said groups of protestors began to gather at Old Trafford and separately at the Lowry Hotel, where the Manchester United players were staying Iroyin tiẹ sọ pe ọlọpaa kan ṣeeṣe nibi to ti n dari awọn ololufẹ Man U to yabo papa isẹre Old Trafford. Manchester United lo wa ni ipo keji lọwọ yii lori tabili idije Premier League, nigba ti orogun wọn, Manchester City wa loke tente. Manchester City ko ba gba ife ẹyẹ Premier League lọjọ Aiku to ba jẹ pe Man U fidi rẹmi ti Liverpool ti ere bọọlu naa ba waye. Bi ọrọ ṣe ri bayii, City ni lati jawe olubori ninu ifẹsẹwọnsẹ kan sii lati gba ife ẹyẹ Premier League ti saa bọọlu yii.",2 Èbibi 2021 +"Ìjọba Nàíjíríà, ẹ gbé eré ìdárayá míràn lárugẹ yàtọ̀ sí bọ́ọ̀lù - Dele Oladejo"," Dokita Oludele Oladejo tii se ololufẹ ere idaraya Squash ti parọwa si ijọba apapọ pe ko se agbelarugẹ awọn ere idaraya miran yatọ si ere bọọlu nikan to gbaju mọ. Oladejo, ẹni to se agbatẹru idije ere idaraya Squash laipẹ yii fun awọn ọjẹ wẹwẹ akẹkọọ to nifẹ si ere idaraya yii, wa fọwọ gbaya pe owo nla wa nidi ere idaraya naa. Lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ nibi asekagba idije Squash fawọn ọjẹ wẹwẹ elere idaraya naa, Oladejo ni awọn akọni ati olowo lo n se ere idaraya Squash. Bakan naa lo fi ọwọ gbaya fun ijọba pe yoo maa ri owo ori gba nidi agbega ere idaraya Squash, ti awọn araalu yoo si tun ri isẹ oojọ se nidi ere idaraya yii. Onimọ nipa ilera ẹda naa tun ni ere idaraya Squash maa n jẹ ki ounjẹ tete da, ti yoo si tun fun awọn ọmọ ni okun.",25 Ìgbé 2021 +Kamaru Usman fi ẹ̀ṣẹ́ da orí Jorge Masvidal rú láti gba ife ẹ̀yẹ," Oríṣun àwòrán, Getty Images Ija ọhun waye ni Florida ti awọn ololufẹ awọn afẹṣẹkubiojo ọhun to le ni ẹgbẹrun lọna marundinlogun. Ajẹkun iya ni Jorge Masvidal jẹ lọwọ Kamaru Usman to jẹ ọmọ Naijiria lasiko ifẹṣẹkubiojo to waye ni aarin awọn mejeeji ni Florida. Awọn mejeeji jijakadi lati figagbaga lori ẹni ti yio gba Ami Ẹyẹ UFC welterweight. Ijakadi naa to waye ni Jacksonville ni Florida ni Kamaru ti ṣe bẹbẹ laarin awọn ololufẹ rẹ to le ni ẹgbẹrun lọna marundinlogun, 15,000 to wa wo iran. Ijakadi naa waye lati fi idi rẹ mulẹ ẹni gan an to kujuwọn lati gba UFC welterweight laarin awọn mejeeji. Ni saa akọkọ idije naa, round one, awọn mejeeji lo ṣe daradara ti wọn si sa ipa wọn lati fi agba han ẹnikẹji. Amọ ni saa keji idije naa, round two, Kamaru to ti rẹkẹ Masvidal fi akọ han to si lu u ni alubami. Oríṣun àwòrán, Getty Images Eleyii ti mu ki Usman lamilaaka ju ti tẹlẹ lọ, ti o si ti di igba mọkandinlogun si ẹyọkan, 19-1 ti o ti fakọyọ ninu idije ifẹṣẹkubiojo. Ninu ọrọ rẹ, Kamaru ni ohun ti sọ fun awọn eniyan pe oun ṣẹṣẹ mu ẹyẹ bọ lapo ni, nitori naa ki ẹ farabalẹ ma a wo iran oun. Bakan naa ni Kamaru ni o da oun loju wi pe laipẹ gbogbo eniyan ni yoo ri wi pe oun lo darajulọ gẹgẹ bi afẹsẹkubiojo ni agbaye.",25 Ìgbé 2021 +Wo ọ̀pọ̀ àǹfààní tó wà nínú eré ìdárayá Squash fún àgbéga ìlera àti ọrọ̀ ajé rẹ," Ni orilẹede Naijiria, ọpọ eeyan ni ko mọ nipa ere idaraya miran mọ yatọ si ere bọọlu, eyi to lokiki yika aye. Ọpọ eeyan ni ko si mọ pe ere idaraya ẹlẹyin ti wọn n gba mọ iganna, ""Squash"", jẹ ọkan gboogi lara awọn ọna ti awọn orilẹede to ti goke agba l'agbaye fi n se agbega eto ilera ati ọrọ aje wọn. Bo tilẹ jẹ wi pe ere idaraya naa ko ti i fi bẹẹ wọ pọ ni orilẹede Naijiria, amọ awọn akọṣẹmọṣẹ nipa ere idaraya Squash kan ti ṣe alaye fun BBC Yoruba wi pe, orisun ọrọ ati ilera pipe ni ere idaraya naa, ti a ba le kọ ibi ara si i. Agba ọjẹ ninu ere idaraya naa, Dokita Oludele Oladejo ṣe alaye wi pe ijọba gbọdọ wa ọna lati gbe ere idaraya naa larugẹ nitori pe o le ṣe anfani to pọ fun ọrọ aje aladani ati fun orilẹede l'apapọ. Dele Ọladejo si lo se agbatẹru idije Squash nilu Ibadan laipẹ yii fawọn ọjẹ wẹwẹ elere idaraya naa ti ọjọ ori wọn wa laarin ọdun mẹtala si mẹtadinlogun. Dokita onisegun oyinbo naa ni, ""Ere idaraya Squash jẹ eto ọrọ aje lọna tiẹ nitori pe fun awọn to n gba a, iṣẹ aṣejere ati aṣelowo ni. Awọn ti yoo ma a mojuto akoso ere idaraya naa, iṣẹ lo jẹ fun awọn yẹn pẹlu. Ijọba gan yoo maa gba owo ori lọwọ awọn oṣiṣẹ tabi lọwọ awọn to n gba Squash, to ba di ere idaraya nla"". Oladejo ni ere bọọlu ti wọn n gba mọ iganna yii, iyẹn ""Squash"" ki i ṣe ere idaraya lasan nitori ojulowo iṣẹ oojọ to n fun ni lokun, to si tun le mu ọpọlọpọ owo wọle ni. O parọwa si awọn obi ati ijọba lati fun awọn ọmọ lanfani kikopa ninu ere idaraya naa nitori pupọ ọmọde ni yoo fakọyọ, ti wọn ba fun wọn ni anfani lati se ere idaraya naa. O fi kun ọrọ rẹ pe ""ijọba ni lati wa ọna to fi jẹ pe gbogbo awọn ere idaraya wọnyii ni yoo jẹ gboogi ohun ti wọn n na owo le. Bakan naa ni ki wọn fi anfani silẹ fun awọn akọṣẹmọṣẹ to n kọ ọmọ nipa awọn ere yii lati lọ kọọ nibi ti o yẹ, nitori pe ere ti o wa nibẹ kọja nnkan ti a ro"". Lẹyin idije ere idaraya Squash to waye ni ibudo igbafẹ Recreation Club nilu Ibadan naa ni wọn ti pin oniruuru ẹbun fawọn ọmọ to fakọyọ lọkunrin ati lobinrin, ninu idije naa. Female Car Painter: Èmi ní obìnrin àkọ́kọ́ tí yóò máa ṣiṣẹ́ akunmọ́tò ní Ibadan Bakan naa ni ọmọkunrin meji, ti wọn jẹ ọmọ iya kan naa gba ẹbun ẹkọ ọfẹ titi de ile ẹkọ giga fasiti eyi ti apapọ awọn elere idaraya Squash to wa nibudo igbafẹ Recreation Club nilu Ibadan se agbatẹru rẹ.",12 Ìgbé 2021 +Ìjọba àpapọ̀ ní ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀; LOC Sports Festival l'Edo ní ìdíje náà kò ní tẹ̀síwájú torí àísówó," Oríṣun àwòrán, Twitter/National Sports Festival Ijọba apapọ ti sọ pe idije oriṣiiriṣii ere idaraya, National Sports Festival to n lọ lọwọ nipinlẹ Edo ko ni wa sopin lojiji lonii Ọjọbọ mọ. Ọrọ yii jade lẹyin ti igbimọ abẹnu lori idije naa, LOC ti kọkọ kede pe idije naa yoo pari lọsan Ọjọbọ nitori aisowo. Ṣugbọn igbakeji oludari ọrọ iroyin ni ileeṣẹ ijọba to n ri si ọrọ ere idaraya ati idagbasoke awọn ọdọ, Ramon Balogun lo fidi ọrọ naa mulẹ ninu atẹjade to fi sita l'Ọjọbọ. O ṣalaye ninu atẹjade ọhun pe ẹka ijọba to n ṣakoso ere idaraya ati ajọ MOC to n ṣiṣẹ lori agbekalẹ idije naa ko gbọ ohun kan nipa ọrọ ti igbimọ LOC ipinlẹ Edo sọ pe idije naa ko ni le tẹsiwaju mọ. Atẹjade naa ṣalaye pe ko si ipade kankan tabi apero kan lori ati da idije naa duro. Ọgbẹni Balogun sọ pe Minisita ere idaraya, Sunday Dare, akọwe agba ileeṣẹ to n ri si ọrọ ere idaraya atawọn lọgalọga lo wa ni Benin fun idije National Sports Festival. O ṣalaye pe ojuṣe ipinlẹ Edo tabi igbimọ LOC ni lati fi to wọn leti ti ipenija kan tabi omiran ba wa lori idije to n lọ lọwọ. Igbakeji oludari ọrọ iroyin ni ileeṣẹ ijọba to n ri si ọrọ ere idaraya ati idagbasoke awọn ọdọ tun sọ pe ipinlẹ Edo tiẹ beere iranwọ owo lori ati gbalejo idije ọhun lẹyin ti ijọba sun un siwaju nitori ajakalẹ arun covid-19. Ọgbẹni Balogun ni ileeṣẹ ijọba to n ri si ere idaraya ti gbe ọrọ naa de iwaju ijọba apapọ, o si yẹ ki owo iranwọ naa jade laipẹ. Ẹwẹ, alakoso ọrọ iroyin lori idije National Sports Festival to n lọ lọwọ nipinlẹ Edo, Ebomhiana Musa lo sọ lalẹ Ọjọru pe igbesẹ lati da idije naa duro waye nibi ipade ti igbimọ LOC ṣe eleyii ti igbakeji gomina ipinlẹ Edo, Philip Shaibu wa nibẹ. O sọ pe igbimọ LOC gbe igbesẹ yii nitori ijọba apapọ ko tii mu ileri iranwọ owo to ṣe fun ipinlẹ Edo ṣẹ lẹyin ti wọn ti kọkọ sun idije naa siwaju tẹlẹ. O kere tan ẹgbẹrun mẹjọ awọn elere idaraya lo n kopa ninu idije National Sports Festival to n lọ lọwọ nipinlẹ Edo.",8 Ìgbé 2021 +Haaland báwo? Mbappe ló dáná sun Bayern Munich ráúráú mọ́lé!," Oríṣun àwòrán, Getty Images Bi ọmọ ẹni ba dara, ẹ jẹ ka wi nitori a o ni fi ṣe aya. Orukọ Kylian Mbappe lo gbẹnu awọn ololufẹ ere bọọlu lalẹ Ọjọru lẹyin to gbarada ninu ifẹsẹwọnsẹ UEFA Champions League ti Paris St-Germain gba pẹlu Bayern Munich. Goolu meji ọtọtọ ni Mbappe gba sawọn ninu ere bọọlu ti PSG ti da ṣeria fun Bayern pẹlu ami ayo mẹta si meji nile wọn. Ifẹsẹwọnsẹ naa jẹ bi ẹsan fun PSG nitori awọn ni Bayern lu ninu ifẹsẹwọnsẹ aṣekagba idije Champions League ti saa to lọ ti wọn fi gba ife ẹfẹ naa. Lẹyin iṣẹju mẹta pere ti wọn bẹrẹ ere bọọlu ọhun ni Mbappe gbayo akọkọ sawọn. Balogun ẹgbẹ agbabọọlu PSG, Marquinhos lo gba goolu keji wọle fun ikọ naa. Amọ, ẹgbẹ agbabọọlu Bayern ja rabu rabu, Eric Maxim Choupo-Moting ati Thomas Mueller da goolu mejeeji pada. Oríṣun àwòrán, Getty Images Ṣugbọn Mbappe kan Bayern ni eyi ọọkan lẹyin to gba goolu mi sawọn nigba ti ere bọọlu ọhun ku iṣẹju mejilelogun ko pari. Ipele keji ifẹsẹwọnsẹ yii yoo waye nile PSG laipẹ yoi lati mọ ẹni ti yoo pegede fun ipele to kangun si aṣekagba. Ti ẹ o ba gbagbe, Mbappe gba goolu mẹta sawọn nigba ti PSG koju Barcelona ni ipele ti wọn gba sẹyin. Ẹwẹ, ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea naa fiya jẹ FC Port o mọ ile wọn ninu ere bọọlu UEFA Champions League keji to waye lalẹ Ọjọru. Mason Mount ati Ben Chilwell lo gbayo mejeeji sawọn ninu eyi ti Chelsea ti fihan gbangba pe awọn kii ṣẹgbẹ Porto.",8 Ìgbé 2021 +Èèmọ̀! West Brom fi omi àbùkù wẹ̀ fún Chelsea lọ́sàn án gangan nílé wọn," Oríṣun àwòrán, Getty Images Ajẹkun iya ni ikọ agbabọọlu Chelsea jẹ lọwọ West Brom lọsan ọjọ Abamẹta. Ami ayo marun un si meji ni West Brom fi ṣagba fun Chelsea ninu ifẹwọnsẹ idije Premier League naa to waye ni papa iṣere Stamford Bridge. Ni ṣe lo da bi ẹni pe Chelsea yoo rọwọ mu ṣaaju nigba ti ifẹsẹwọnsẹ ọhun kọkọ bẹrẹ lẹyin ti Christian Pulisic sọ goolu sinu awọn West Brom. Ṣugbọn nigba to ku diẹ ki abala akọkọ ifẹsẹwọnsẹ naa wa sopin ni Fellipe Matheus Pereira da pada lera lera, lai fọta pe. Ninu abala keji ifẹsẹwọnsẹ naa ni Callum Robinson ti ṣe bii ọmọkunrin, toun naa tun sọ goolu kan sinu awọn Chelsea. Oríṣun àwòrán, Getty Images Iṣeju marun un si asiko naa ni Mbaye Diagne naa tun fi ẹyọ kan le. Bo tilẹ jẹ pe Mason Mount gbiyanju lati da ami ayo kan pada, lati fun Chelasea ni ami ayo meji ninu ifẹsẹwọnsẹ naa, goolu ti Callum Robinson tun sọ wọle nigba to ku iṣẹju aaya diẹ ki ifẹsẹwọnsẹ naa pari lo fi ọba le. Lẹyinorẹyin, Chelsea fi agbọn ru goolu marun lọle nigba ti wọn da meji pere pada fun West Brom.",3 Ìgbé 2021 +"Naijiria sán bàntẹ́ ìyà fún Benin, ó tún kójú òsùnwọ̀n fún Nations Cup"," Oríṣun àwòrán, Other Ẹgbẹ agbabọọlu agba Naijiria, Super Eagles ti na Squirrels ti Benin Republic. Bi wọn ṣe bori ninu idije naa to waye ni papa iṣere Stade Charles de Gaulle ni Poto Novo, Benin, ti mu ki wọn o koju oṣuwọn lati kopa ni nations cup. Ami ayo kan si odo ni Super Eagles fi fẹyin Squirrels janlẹ. Asiko ti ifẹsẹwọnsẹ naa wọ iṣẹju mẹtalelaadọrun ni Paul Onuacha gba bọọlu sinu awọn, lẹyin ti ẹgbẹ agbabọọlu mejeeji ti ta ọmi odo. Ṣaaju asiko yii, ami kan pere ni Naijiria nilo lati koju osuwọn fun Nations Cup, ti yoo waye ni ọdun to n bọ ni Cameroon. Super Eagles gunlẹ si Benin Republic lọjọ Ẹti fun ifẹsẹwọnsẹ ati pegede fun idije ere bọọlu ilẹ Afirika, AFCON 2021.",27 Ẹrẹ̀nà 2021 +"Super Eagles, ẹ lọ lu Benin Republic mọ́lé, ọmọ Nàìjíríà wà lẹ́yìn yín- Mínísítà"," Oríṣun àwòrán, Twitter/Super Eagles Minisita ere idaraya ati ọrọ idagbasoke awọn ọdọ, Sunday Dare ti rọ ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles Naijiria pe ki wọn lọ lu alatako wọn wọn, Benin Republic mọle. Super Eagles gunlẹ si Benin Republic lọjọ Ẹti fun ifẹsẹwọnsẹ ati pegede fun idije ere bọọlu ilẹ Afirika, AFCON 2021. Ninu ọrọ iyanju rẹ sawọn agbabọọlu Naijiria, minisita só fun wọn pe ''aileja lojude ile baba mi o de bi, ẹ bẹrẹ daadaa, ṣugbọn ni bayii, ẹ gbọdọ pari daadaa bakan naa. Ko si ere bọọlu to rọrun, nitori naa, ẹ maa foju di awọn agbabọọlu Benin Republic tori pe ko si ọbọ kan ni dere mọ lagbo ere bọọlu afẹsẹgba,'' minisita lo sọ bẹẹ. Ọgbẹni Dare sọ fawọn agbabọọlu Naijiria pe ki wọn sa gbogbo ipa wọn lati fo bi ẹyẹ idi ti orukọ inagijẹ wọn n jẹ. Naijiria lo si wa loke tente lori isọri kejila awọn orilẹede to n gba ifẹsẹwọnsẹ ati pegede fun idije AFCON 2021. Ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles ti jawe olubori ni meji ninu ifẹsẹwọnsẹ mẹrin ti wọn ti gba nigba ti wọn ta ọmi meji bakan naa. Orilẹede Benin lo wa ni ipo keji lẹyin tawọn naa jawe olubori ninu ere bọọlu meji ṣugbọn wọn fidi rẹmi ninu ọkan nigba ti wọn ta ọmi ninu omiran. Ẹwẹ, ajọ to n ri si ere bọọlu afẹsẹgba ni Naijiria, NFF ti sọ pe awọn ọmọ Naijiria yoo ri ifẹsẹwọnsẹ naa wo loju opo Twitter rẹ.",27 Ẹrẹ̀nà 2021 +Iheanacho lu Manchester United bí aṣọ òfi kúrò nínú ìdíje FA Cup," Oríṣun àwòrán, BBC Sport Yoruba lo maa n gbadura pe, iya aarọ tabi ti alẹ pe ki Eleduwa maa jẹ ki a jẹ ọkan kan ninu rẹ. Amọ, ọrọ ko ri bẹ fun ẹgbẹ agbabọọlu Manchester United lẹyin ti ẹlẹsẹ ayo, ọmọ Naijiria, Kelechi Iheanacho fi iya aṣaalẹ jẹ wọn ninu idije FA Cup ilẹ Gẹẹsi. Ami ayo meji ọtọtọ ni Iheanacho gba sawọn Man United ninu ifẹsẹwọnsẹ ti Leicester City ti digbaju ru Man U. Youri Tielemans naa gbayo wọle Man U fun Leicester ti Man U si fidi rémi rẹmi pẹlu ami ayo mẹta sẹyọkan. Mason Greenwood lo ja rabu rabu lati dayo kan pada fun Man U amọ ẹpa ẹpa ko boro mọ tori ọmi pọ ju ọka lọ. Nibayii, Manchester United ti ja lulẹ ninu idije FA Cup nigba ti Leicester pegede fun abala to kangun si aṣekagba ninu idije naa.",21 Ẹrẹ̀nà 2021 +Anthony Joshua bẹ̀rẹ̀ ìgbáradì láti kojú Tyson Fury nínú ìjà tí yóò yeruku lálá," Oríṣun àwòrán, Instagram/Anthony Joshua Ohun to ba ti ya kan, kii tun pẹ mọ, abẹṣẹ ku bi ojo, Anthony Joshua ti bẹrẹ igbaradi fun ija rẹ pẹlu Tyson Fury. Olukọni Joshua, Joby Clayton ṣalaye pe AJ ti n gbiyanju oriṣiiriṣii ọna lati gbaradi fun ija naa. Onigbọwọ Joshua, Eddie Hearn lo kede laipẹ yii pe AJ ti buwọlu ija meji pẹlu Fury lati le mọ ẹni to le ja ju ni ipele awọn akẹṣẹ to lagbara ju. Clayton sọ pe ati okeere ni olujinjin ti maa n mẹkun sun ni ọrọ igbaradi Joshua fun ija rẹ pẹlu Fury. Olukọni Joshua to n ṣiṣẹ pọ pẹlu Rob McCracken ṣalaye pe iṣẹ oun ni lati rii pe Joshua wa ni igbaradi lati koju Fury. ''Fury kii ṣe ẹran rirọ, o ṣoro lati mọ oriṣiiriṣii ọgbọn ti o maa n lo ti o ba n ja,'' Clayton lo sọ bẹẹ. Clayton ni Joshua n ṣe daadaa ninu igbaradi rẹ nitori oun gan an mọ pe ija pẹlu Fury yoo nipa to lagbara lori rẹ gẹgẹ bi akẹṣẹ. ''A maa n ri pe AJ simin lasiko to ba yẹ ki o sinmin nitori gbogbo igba kọ ni o gbọdọ fi maa ṣe igbaradi,'' Clayton ṣalaye. Laipẹ yii ni onigbọwọ Joshua, Hearn kede ibi ti ija naa yoo ti waye. Hearn sọ pe AJ ko beṣu bẹgba lori igbaradi rẹ fun Fury nitori o mọ iru akẹṣẹ ti Fury jẹ. Amọ, Hearn ni gbogbo ohun ti Joshua n ro ni ọna lati jawe olubori ninu ija naa.",17 Ẹrẹ̀nà 2021 +"Mo sọ fún Azeez pé tó bá ti já ẹ̀ṣẹ́ níta láì ṣe lórí ìtàgé ìjà, ó máa kú ni - Bàba"," Ọmọ ọdun mẹrinla abẹṣẹkubiojo ni Tijani Azeez to si jẹ akẹkọọ ni ile iwe ati ni ile ẹk to ti n kọ ẹṣẹ jija. ""Ti mo ba lọ ileewe laarọ, ti mo de ni ago mẹrin, maa tun bẹrẹ si ni kọ ẹkọ ẹṣẹ di ago meje alẹ"". Lati ọmọ ọdun meji ni ọmọ ọdun mẹrinla yii ni oun ti bẹrẹ ẹṣẹ jija toripe baba rẹ gan lo si ọna yii. Gbogbo igba ni inu Tijani maa n dun si ohun to fẹran lati maa ṣe yii to bẹẹ to jẹ wipe iye ọjọ ati wakati to fi n kọ ẹṣẹ jija laarin ọsẹ kan ko lonka rara. Olukọni to n kọ tijani bo ṣe n ja ẹṣẹ jẹ onimọ to ti n kọ ẹṣẹ lati ọdun 2003 koda o wu oun gan ki ọmọ to bi funrarẹ maa ja ẹṣẹ. Ọpọlọpọ ọrọ iwuri lo sọ nipa Tijani azeez.",12 Ẹrẹ̀nà 2021 +"Ayé àkámarà! Liverpool laná ní Anfield, Chelsea pa òkúta sí gaàrí wọn"," Oríṣun àwòrán, Getty Images Ogun laye, ọmọ araye le! Ijamba mii tun ṣe ẹgbẹ agbabọọlu Liverpool lalẹ Ọjọbọ lẹyin ti Chelsea lu wọn mọle. Eyi ni igba ifẹsẹwọnsẹ karun un ti Liverpool yoo fidi rẹmi ninu rẹ ni papa iṣere wọn ni Anfield. Kete ti wọn bẹrẹ ere bọọlu naa ni Chelsea ti bẹrẹ si ni gbiyanju lati gba bọọlu sawọn Liverpool nigba ti Liverpool ko si le ta putu. Ẹlẹsẹ ayo, Timo Werner lo kọkọ gba goolu sawọn Liverpool nigba ti ifẹsẹwọnsẹ ọhun de iṣẹju mẹrinlelogun. Amọ, ẹrọ oloju aṣa VAR wọgile goolu naa pe o ti wọ ''off side'' ko to gba bọọlu sawọn. Oríṣun àwòrán, Getty Images Ṣugbọn agbabọọlu aarin gbungbun, Mason Mount gba goolu miran wọle nigba ti ipele akọkọ ku iṣẹju mẹta ko pari. Liverpool gbiyanju titi lati da ayo naa pada ṣugbọn omi pọ ju ọka lọ fun wọn. Ni bayii, ipo keje ni ẹgbẹ agbabọọlu Liverpool wa lori tabili idije Premier League. Chelsea ti wa ni ipo kẹrin lẹyin ti wọn ko fidi rẹmi ninu ere bọọlu mẹwaa ti wọn ti gba lati igba ti Thomas Tuchel ti di akọnimọọgba wọn. Ẹwẹ, agbabọọlu Liverpool tẹlẹ ri, Jamie Carragher ti rọ ẹgbẹ agbabọọlu naa lati ra awọn agbabọọlu tuntun to dantọ. Carragher ni Liverpool nilo awọn agbabọọlu tuntun lati sọji pada.",5 Ẹrẹ̀nà 2021 +"Man United kò bá lu Chelsea mọ́lé, àmọ́ rẹfirí jà wá lólè pẹnárítì- Ole yarí"," Oríṣun àwòrán, Getty Images Man United kò bá lu Chelsea mọ́lé, àmọ́ rẹfirí jà wá lólè pẹnárítì- Ole yarí. Akọnimọọgba Manchester United, Ole Gunnar Solskjaer ti fi aidunnu rẹ han lórí bi rẹfiri ṣe kọ lati fun Man U ni pẹnariti ninu ifẹsẹwọnsẹ idije Premier League ọjọ Aiku. Ole ni agbabọọlu Chelsea, Callum Hudson-Odoi fi ọwọ gbe bọọlu eyi to tumọ si pẹnariti. Ṣugbọn rẹfiri Stuart Atwell ko fun Man United ni pẹnariti lẹyin to tun iṣẹlẹ laarin Hudson-Odoi ati Mason Greenwood wo eyi to fihan pe bọọlu kọkọ kan oke ọwọ Greenwood ko to ba agbabọọlu Chelsea lọwọ. Amọ, Solskjaer ni ariwo tawọn alatako ẹgbẹ agbabọọlu n pa wi pe Man United ni awọn rẹfiri n fun ni pẹnariti julọ ni ko jẹ ki rẹfiri Attwell fun United ni pẹnariti. Francis Olusola Alao: Wọ́n ti ti ọ̀rọ̀ òṣèlú bọ ọ̀rs Sunday Igboho, ṣùgbọ́n..- Oba Olugbọn Ẹgbẹ agbabọọlu Man United ti ni pẹnariti mejilelogun ninu idije Premier League lati ibẹrẹ saa bọọlu to lọ titi di akoko yii. Eyi lo mu ki olukọni Liverpool, Jurgen Klopp ati akọnimọọgba Chelsea tẹlẹ, Frank Lampard sọrọ pe awọn rẹfiri n ṣegbe lẹyin Man United lori ọrọ pẹnariti. Ole ni eyi gan an ni ko jẹ ki awọn rẹfiri fẹ maa fun Man United ni pẹnariti mọ. Solskjaer ni ko gba ibikan ye oun idi ti rẹfiri ṣe kọ lati fun Man U ni pẹnariti. Solskjaer ṣalaye pe lai ṣe ani-ani, tẹlifisan VAR fihan pe o yẹ ki rẹfiri fun United ni pẹnariti ṣugbọn ""ariwo tawọn Chelsea n pa ni pe Greenwood lo kọkọ fi apa gbe bọọlu."" Badagry Historical Wells: Omi inú kànga Wawú ló ń kó ọpọlọ àwọn ẹrú lọ Àmọ́, akọnimọọgba Chelsea, Thomas Tuchel ti fesi si ọrọ Solskjaer. Tuchel ni ko si ohun to jọ pẹnariti rara ninu ohun to ṣẹlẹ laarin Hudson-Odoi ati Greenwood. Tuchel ni o ya oun lẹnu pe rẹfiri tiẹ lọ ṣ'ayẹwo iṣẹlẹ naa tẹlifísàn VAR nitori agbabọọlu Man United lo kọkọ fọwọ́ gbe bọọlu. Regent Ondo: Láti 1978 tí Bàbá mi ti jẹ Oba ni mo ti ms pé máà jẹ adelé- Magaret Omonije I Ami ayo mejila ni Manchester City to wa ni ipo kinni fi n ṣiwaju Man United bayii lori tabili EPL. Ipo karun un si ni Chelsea wa bayii lori tabili idije Premier League.",1 Ẹrẹ̀nà 2021 +"Arsenal gbàlejò ọ̀ràn, Manchester City tẹ̀ wọ́n mẹ́rẹ̀ ní Emirates"," Oríṣun àwòrán, Getty Images Manchester City di alejo ọran mọ ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal lọwọ ni papa iṣere Emirates lẹyin ti City lu wọn mọlẹ bi aṣọ ofi ninu idije Premier League lọjọ Aiku. Ko pẹ ti wọn bẹrẹ ifẹsẹwọnsẹ naa ti Raheem Sterling gbayo sawọn Arsenal eyi to mu ki City lewaju ninu ere bọọlu ọhun. Arsenal sọji nigba to ku diẹ ki ipele akọkọ ifẹsẹwọnsẹ naa pari, ṣugbọn gbogbo igbiyanju lati da ayo naa pada, pabo lo jasi. Ipele keji ifẹsẹwọnsẹ ọhún naa gbona giri giri pẹlu bi Arsenal ti doju ija kọ City. Nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa de iṣeju marundinlọgọrin ni akọmọọgba Arsenal, Mikel Arteta yọ Pepe ati Odegaard, to si fi Alexandre Lacazette ati Smith Rowe rọpo wọn boya wọn le gbiyan lati ta biọbiọ, ṣugbọn lori ofo naa ni. Pẹlun gbogbo igbiyanju Arsenal ninu ifẹsẹwọnsẹ naa, Manchester City papa ya aṣo iyi mọ wọn lara. Lọwọ yii, Man City lo n leke tabili idije Premier League ọhun, nigba ti Arsenal wa lọwọ isalẹ ni ipo kẹwaa. Lori iro: Ká ni àwọn Òbí mi gbà fún mí, èmi àti Sunny Ade á jọ máa 'Compete- Baba Lórí ir",21 Èrèlè 2021 +Ṣàngbá fọ́! Mbappe pòkọ ìyà fún Messi àti Barcelona mu ní Nou Camp," Oríṣun àwòrán, Getty Images Igba laa ni, ẹnikan o lo ile aye gbo. Ohun lo difa fun ọdọmọde agbabọọlu PSG, Kylian Mbappe to rọ agbaọjẹ agbabọọlu Barcelona, Lionel Messi loye. Goolu mẹta ọtọtọ ni Mbappe gba sawọn Barcelona nigba ti PSG pokọ iya fun Barcelona nile wọn ni ipele ẹlẹni-mẹrindinlogun idije UEFA Champions League lalẹ ọjọ Iṣẹgun. Ṣe ẹ mọ pe akọda oro ko da bi adagbẹyin. Messi lo kọkọ gba pẹnariti wọle PSG lai mọ pe o kọ lẹta si iya ni. Ṣugbọn goolu mẹrin ni Mbappe ati Moise Kean fi da pada lẹyin ti wọn lu Barca mọlẹ bi aṣọ ofi pẹlu ami ayo mẹrin sí ẹyọkan. Lori iro: Ká ni àwọn Òbí mi gbà fún mí, èmi àti Sunny Ade á jọ máa 'Compete- Baba Lórí ir Iti ọgẹdẹ ti ko to ohun ti a n yọ ada si ni PSG fi ọrọ Barcelona ṣe ni Nou Camp tori elege ara PSG, Neymar gan an ko lanfaani lati kopa ninu ifẹsẹwọnsẹ ọhún lẹyin to ti fi ẹsẹ ṣeṣe tẹlẹ. O ṣeeṣe ki Neymar kopa ninu ipele keji ifẹsẹwọnṣẹ ọhun ti yoo waye logunjo, oṣu kẹta ọdun yìí niluu Paris. Akomolede ati Asa lori BBC: Olùkọ́ Bolanle Adekanmi kọ́ wa nípa oríṣíi Àròkọ Yorùbá tó wà",17 Èrèlè 2021 +"Bàyìí ni Yisa Sofoluwe, agbábọ́ọ̀lù Super Eagles tẹ́lẹ̀ ṣe jà jà lórí àìsàn kó tó dágbéré fáyé"," Oríṣun àwòrán, NAtion A bí Yisa Sofoluwe ni ọjọ́ kejìlélógún, oṣù kejílá, ọdún 1967 to si gbá bọ́ọ̀lù fún orílẹ̀-èdè Nàìjíríà gẹ́gẹ́ bi a dile ẹyin mú. Ẹyìn ni apá òsì ni ìròyìn sọ pé ó máa ń gbá láàrin ọdún 1983 si ọdun 1988, bákan náà ló gbá Nation's Cup ọdún 1984 àti ti 1988 Sofoluwe jẹ góòlù kan fún orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lásìkò náà. Ó farahàn nínú idíje bọ́ọ̀lù Nàìjíríà fún ìgbà ogójì lásìkò tó n gbá bọ́ọ̀lù Bákan náà ni Sofoluwe ti fi igba kan jẹ́ agbábọ́ọ̀lù Abiola Babes nílùú Abeokuta, IICC ti Ibadan àti Gatew+ay Abeokuta. Ṣááju ni ìròyìn kàn pé, àgbà ọ̀jẹ̀ agbábọ́ọ̀lù náà ṣe àìsàn to sì gba ìtọ́jú nílé ìwòsàn LUTH. Ọ̀kan ninu àwọn ọrẹ́ rẹ̀ Waidi Akanni sàlàyé pé, àwọn ń gbìyànJÚ láti wá owó tí yóò fi ṣe iṣẹ́ abẹ̀ tó nílò, ṣùgbọ́n ẹpa kò bóró mọ́. Ìròyin sọ pé mínísítà fún eré ìdárayá àti ọ̀rọ̀ ọ̀dọ́ lọ́sàn ọjọ́ Iṣẹgun gbé ìgbésẹ̀ láti ran Sofoluwe lọ́wọ́ láti bá gómìnà ìpínlẹ̀ rẹ̀ sọ̀rọ̀ kí wọ́n lé ràn an lọ́wọ́ lórí ọ̀rọ̀ iṣẹ́ abẹ náà. Mínísítà fí owó ránṣẹ́ pẹ̀lú láti fi ran ìtọ́jú rẹ̀ lọ́wọ́ sùgbọ́n kò dúró ṣe iṣẹ́ abẹ náà tó fi gbekuru jẹ lọ́wọ́ ẹbọra. Agbábọ́ọ̀lù ikọ̀ Super Eagles tẹ́lẹ̀rí Yisa Sofoluwe jáde láyé Oríṣun àwòrán, Google Agbabọọlu ikọ Super Eagles tẹlẹri, Yisa Sofoluwe ti jade laye ni ẹni ọdun mẹrinlelaadọta, lẹyin to ṣe aisan. Opin ọsẹ yii ni iroyin jade nipa aisan rẹ lẹyin ti wọn lo ni aisan ninu agbari, cerebral atrophy to niiṣe pẹlu ọpọlọ. Aisan yii ma n jẹ ki gbogbo sẹẹli ọpọlọ ni ifasẹyin, ti ọpọlọ ko si ni lee ṣiṣẹ mọ bi o ṣeyẹ. Sofoluwe ni agbabọọlu ẹyin to n dile mu nigba aye rẹ, ti gbogbo aye si mọ ọ si ""Dean of Defence"". Ọjọ Kejidinlọgbọn, Oṣu Kejila, ọdun 1967 ni wọn bi akọni naa to si gba bọọlu si awọn lẹẹkan fun orilẹede Naijiria. O gba bọọlu pẹlu ikọ to de aṣekagba idije AFCON ni ọdun 1984 ati ọdun 1988. Awọn akẹgbẹ rẹ ati awọn ololufẹ rẹ ni wọn ti n ṣe idaro rẹ lẹyin to papoda pe ki Edua de ilẹ fun ẹni ire to lọ. Ṣé o mọ oríkì ìlú ara rẹ tó olùkọ́ yìí tó dántọ́ lẹ́nu rẹ̀ bíi ọmọ ìlú rẹ?",10 Èrèlè 2021 +"Ìgbà ọ̀tun! Lampard kó ìyà lọ, Tuchel kó ire de Chelsea"," Oríṣun àwòrán, Getty Images Igba kan n lọ, igba kan n bọ, aye duro titi lae. Eyi lo difa akọnimọọgba Chelsea tẹlẹri, Frank Lampard ti o ti idi itan bayii ni ẹgbẹ agbabọọlu naa. Olori ẹgbẹ agbabọọlu naa, Roman Abramovich jawe gbẹle ẹ fun Lampard lẹyin ti nkan ko ṣẹnu 're mọ fun Chelsea ninu awọn ifẹsẹwọnsẹ ti wọn n kopa ninu rẹ. Ṣugbọn ni bayii, omi tuntun ti ru, ẹja tuntun si ti wọ lẹgbẹ agbabọọlu Chelsea lẹyin ti Tomas Tuchel di akọnimọọgba tuntun fun Chelsea. Ọmi ni Chelsea gba pẹlu Wolves ninu ifẹsẹwọnsẹ akọkọ ti Chelsea ti gba lẹyin ti Tuchel de. Amọ, ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea fakọyọ lọjọ Aiku, lẹyin ti bo Burnley mọlẹ nile wọn pẹlu ami ayo meji sodo. Balogun ikọ Chelsea, Cesar Azpilicueta lo gbayo akọkọ sawọn fun Chelsea ki Marcos Alonso to fọba lee nigba to ku diẹ ki ifẹsẹwọnsẹ naa pari. Ipo kẹsan ni Chelsea wa bayii lori tabili idije English Premier League.",31 Sẹ́rẹ́ 2021 +Ọba àwọn góòlù! Aubameyang àti Saka ṣá Newcastle pa lálẹ́ ọjọ́ Ajé," Oríṣun àwòrán, Reuters Ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal rọ bajinatu fun Newcastle ni papa iṣere Emirates lalẹ ọjọ Aje ninu idije Premier League. Balogun ikọ Arsenal, Pierre-Emerick Aubameyang gba goolu meji sawọn nigba ti Bukayo Saka naa gba goolu kan si awọn lẹyin Arsenal lu Newcastle pẹlu ayo mẹta sodo. Aubameyang lo kọkọ gbayo sawọn ni iṣẹju marun un lẹyin ti ipele keji ifẹsẹwọnsẹ naa bẹrẹ. Saka gba goolu keji sawọn nigba ti ere bọọlu naa pe ọgọta iṣẹju ọgọta. Aubameyang fi ọba lee nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa ku iṣẹju mẹtala ti yoo pari. Nibayii, Arsenal ti goke lọ si ipo kẹwaa lori tabili idjije Premier League. Akọnimọọgba Arsenal, Mikel Arteta ko ṣai fi idunnu rẹ han si Aubameyang to gba goolu meji sawọn lẹyin to n tiraka lati fakọyọ lawọn ifẹsẹwọnsẹ ti Arsenal ti sẹyin. Bakan naa lo gboṣuba fawọn ọjẹwẹwẹ agbabọọlu bii Bukayo Saka ati Emile Smith-Rowe ti wọn fakọyọ bakan naa.",19 Sẹ́rẹ́ 2021 +Ẹ wo àwọn èèkàn eléré ìdárayá tó bá ọdún 2020 lọ," Oríṣun àwòrán, Facebook/BBC Ọdun 2020 lamilaka, to si jẹ ọdun manigbagbe paapa julọ pẹlu ajakalẹ arun Covid-19 to ṣọṣẹ jakejado agbaye. Lorilede wa Naijiria, a mọ riri ajakalẹ yii lara pẹlu awọn eeyan ti iku mu ẹmi wọn lọ nitori ajakalẹ arun Coronavirus naa, eyi to tun mu ki idenukọlẹ ba eto ọrọ aje titi di akoko yii. Bi a ba wo agbo osere ere idaraya, awọn tó ba ọdún yi lọ yala lati ipasẹ Covid-19 tabi nnkan mii, pọ yanturu. Oríṣun àwòrán, Facebook/Ajibade Babalade Lọjọ kẹrin oṣu Kẹsan ni agbẹyin fun ìkọ Super Eagles dagbere faye ni Ibadan . Babalade, to jẹ ẹni ọdun mejidinlaadọta ṣe aarẹ diẹ, ti won sì gbé lọ sí ilé ìwòsan agba fasiti Ibadan, UCH níbi to padà ku si. Ajibade jẹ ogbontarigi agbẹ́yìn to soju Naijiria ninu ikọ Super Eagles, to si ba wọn gba ife ẹyẹ bàbà lọdun 1992 ninu idije AFCON to waye ni Senegal. Chineme Martins: Oríṣun àwòrán, Facebook/Martins Chineme Ikú agbabọọlu ẹni ọdun mẹtalelogun yii dun ọpọ eeyan nitori igbagbọ wọn ni pé ti Naijiria ba ni eto ilera tó péye lori papa iṣere Lafia ni, ko bà maa ku. Lọjọ Kẹjọ oṣù Kẹta ni Martins dagbere faye lasiko Ifẹsẹwọnsẹ ẹgbẹ agbabọọlu rẹ, Nassarawa United ninu liigi bọọlu Naijiria, NPFL. Sadede ni Chineme daku lori papa ni abala keji ifẹsẹwọnsẹ naa nigba ti Nassarawa United n koju Katsina United. Oríṣun àwòrán, Facebook/John Felagha Ọgbọnjọ oṣu Kẹjọ ni aṣọle nigba kan ri fún ìkọ U17 ati U20 Naijiria kú ní Senegal. Felagha jẹ ọkan lára ìkọ Golden Eaglets nigba ti won gba baba ni Switzerland lọdun 2009, bo ti le jẹ wipe ko ribi dé ojú ile lasiko idije naa. Oríṣun àwòrán, @ExtraSportsNG Okedeyi jẹ ọkan lára àwọn adari idije bọọlu alapẹrẹ basket ball ni Naijiria ki ọlọjọ to dé. Bẹẹ lo tun jẹ oguna gbongbo ọmọ ẹgbẹ àwọn rẹfiri bọọlu alapẹrẹ ni Naijiria. Lasiko idije ti Total sagbatẹru rẹ nibẹrẹ ọdun yii lawọn eeyan ri Okedeyi kẹyin. Okedeyi jẹ alukoro ẹgbẹ awọn to n gba bọọlu alapẹrẹ nilu Eko ṣaaju ikú rẹ. Oríṣun àwòrán, @nbbfonline Ikú ọmọdebinrin yii jẹ eyi ti a ko ba ti kéde ka ni wọn tete mọ nkan to n ṣe pato. Ìdí ni pé ọtọ ní nkan t'awon onimọ ilera n tọju rẹ fún amọ nigba ti wọn yóò fi mọ nkan to se gangan, ẹpa ko boro mọ. Oríṣun àwòrán, @titansbasket Gbajumọ ababọọ̀lu alapẹrẹ ni ọmọ ọdun mẹrindiinlogun naa, to si sẹsẹ fẹ joko kọ idanwo asejade ile ẹkọ girama agba ni, ki iku to pa oju rẹ de. Ọjọ kejidinlogun osu Kẹrin lo dagbere faye pe o digbose. Michael Ojo: Oríṣun àwòrán, @odds_12 Ọmọ Naijiria ati ilẹ Amẹrika yii ku nitori ọkan rẹ to sọsẹ silẹ lasiko igbaradi lori papa ere bọọlu alapẹrẹ. Ni papa isere idaraya Partizan ti ìkọ Crvena Zvezda, lorileede Serbia ti n gbaradi lo ti daku. Nígbà tí wọn yoo fi gbé dé ilé iwosan kan lagbegbe naa, o ti dakẹ. Aremu Adu: Oríṣun àwòrán, @LASG Olukọni ere idaraya naa jẹ ilumọọka nibi ka maa ṣatọna awọn ọjẹ wẹwẹ ere idaraya nipinlẹ Eko. Ọjọ Kẹwa oṣù Kaarun ọdun 2020 lo ki ayé pe o digba. Ọpọ lawọn elere idaraya ni Naijiria ti wọn ti tipasẹ Coach Adu gun oke agba nidi ere idaraya. Ninu awọn to kọ la ti awọn to ti wa nilẹ Amẹrika nibi ti wọn ti n tẹsiwaju pẹlu ẹkọ wọn. Oríṣun àwòrán, @thenff Ninu awọn ti ajọ ere bọọlu Naijiria NFF padanu lọdun 2020 ni Emmanuel Ibah wa. O jẹ alakoso NFF lagbegbe Guusu Naijiria, to sì tun jẹ alaga ẹgbẹ ere bọọlu ni Akwa-Ibom titi di igba to fi faye silẹ. Ẹni ọdun mọkanlelọgọta lo jẹ lasiko ti ọlọjọ dé.",28 Ọ̀pẹ̀̀ 2020 +Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ ayédèrú Ahmed Musa tó ń lu àwọn èèyàn ní jìbìtì," Oríṣun àwòrán, Kano Police Command Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kano ti tẹ ọkunrin kan to n pe ara rẹ ni balogun ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles, Ahmed Musa. Wọn ni ọkunrin ọhun ti orukọ rẹ n jẹ Gambo Yakubu ti gba owo ti iye rẹ to ₦700,000 lọwọ awọn eeyan, lẹyin to fi da wọn loju pe oun yoo ba wọn ṣeto ati gba bọọlu loke okun. Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, DSP Abdullahi Haruna lo fidi iroyin naa mulẹ fun akọroyin. O ni ""ootọ ni pe afurasi ọhun n ṣiṣe pẹlu ileeṣẹ Ahmed Musa tẹlẹ ki wọn to le danu, lẹyin naa lo lọ ṣe ayederu iwe lati maa fi lu awọn eeyan ni jibiti."" Ṣaaju ni oludari ileeṣẹ ti Ahmed Musa da silẹ ọhun ti kọkọ ta ọlọpaa lolobo nipa afurasi naa nitori bi ọpọ ero ṣe maa n wa sile iṣẹ wọn lati bere owo to gba lọwọ wọn. Gẹgẹ bi ọrọ ti alukoro ọlọpaa naa sọ, nnkan bii eeyan marundinlogun ni afurasi naa ti lu jibiti lẹyin ti wọn ti fun ni ẹgbẹrun marun un owo fọọmu lati lọ gba bọọlu niluu oyinbo. Haruna sọ pe ""apapọ iye owo to ti gba lọwọ awọn eeyan jẹ ₦ 700,000 to si sọ pe oun ti na owo naa fun awọn ọrẹbinrin oun."" 'Ọ̀lọ́pàá shátà mi láti Mowe dé Magboro dé Shagamu, wọ́n ní ṣé mi ò mọ̀ pé ìjọ́ba ni mo ṣiṣẹ́ fún'",23 Ọ̀pẹ̀̀ 2020 +Kí ló kàn fún Arsenal báyìí lẹ́yìn tí Burnley yẹ̀yẹ́ wọn mọ́lé ní Emirates?," Oríṣun àwòrán, Reuters Ọkan lara adilemu fun ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal, Kieran Tierney ti sọ pe o yẹ kawọn ololufẹ ikọ agbabọọlu naa yẹyẹ wọn gẹgẹ bi wọn ti ṣe lẹyin ti Burnley lu wọn mọle pẹlu ami ayo kan sodo ninu idije Premier League lọjọ Aiku. O buru debi wi pe balogun Arsenal, Pierre-Emerick Aubameyang gan an lo ṣeeṣi gba goolu kan ṣoṣo tiu Burnley fi bori wọlẹ Arsenal. Ni bayii, Arsenal ti fidi rẹmi ninu meje ninu ifẹsẹwọnsẹ mẹwaa ti wọn ti gba bayii. Ẹgbẹrun meji ololufẹ ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal to wo ere bọọlu naa lo fi aidunnu wọn han sawọn agbabọọlu ati akọnimọọgba wọn, Mikel Arteta lẹyin ifẹsẹwọnsẹ naa. Tierney sọ lẹyin ifẹsẹwọnsẹ naa pe igbiyanju awọn agbabọọlu Arsenal lori papa kudiẹ kaato. Igba akọkọ ree ti Arsenal yoo fidi rẹmi ninu ifẹsẹwọnsẹ mẹrin lera lera nile wọn lati bii ọdun mọkanlelọgọta. Pẹlu bi wọn ti bori ninu ifẹsẹwọnsẹ mẹrin ninu mejila ti wọn ti gba a, o ti pe ọdun marunlelogoji bayii ti ibẹrẹ saa bọọlu tuntun ti buru jai fun Arsenal bayii. Oríṣun àwòrán, EPA Goolu mẹwaa ti wọn gba sawọn ninu ifẹsẹwọnsẹ mejila ti wọn ti gba ni saa bọọlu yii lo kere julọ fun Arsenal lati ọdun 1982. Lati oṣu kejila ọdun 2019 ti Arteta ti di akọnimọọgba Arsenal, awọn agbabọọlu rẹ ti kaadi pupa mẹfa. Iwa aibikita bẹẹ naa lo mi ki Granit Xhaka gba kaadi pupa ti wọn fi le danu ninu ifẹsẹwọnsẹ ọjọ Aiku lẹyin to fẹ fun agbabọọlu Burnley, Ashley Westwood lọrun.",14 Ọ̀pẹ̀̀ 2020 +Àṣeyọrí Anthony Joshua fi hàn pé owó tí à ń ná lórí eré ìdarayá kò lọ lásán - Dapo Abiodun," Oríṣun àwòrán, Getty Images Gomina ipinlẹ Ogun, Dapo Abiodun ti ki abẹṣẹkubiojo,Anthony Joshua ku oriire lẹyin to bori ojugab rẹ lati orilẹ-ede Bulgaria, Kubrat Pulev ni gbagede SSE Arena ni ilu London lalẹ ọjọ Abamẹta. Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ rẹ, Kunle Somorin fi lede, Abiodun ni Johsua gbe ogo ipinlẹ Ogun ga. Gẹgẹ bi ohun ti gomina naa sọ, o ni ẹbun nla ni aṣeyọri naa jẹ, ati pe yoo tun jẹ ohun iwuri fun awọn elomiran lati tẹpa mọ ohunkohun ti wọn ba yan laayo. Atẹjade naa ni ""gbogbo wa ni ipinlẹ yii ni a gbadura fun aṣeyọri rẹ lai wo ti ẹsin."" ""Mo le ka aṣeyọri nla to waye lalẹ ana ni London gẹgẹ bi ẹbun ọdun Keresimesi lati ọdọ Ọlọrun ati Anthony Joshua fun gbogbo wa ni ipinlẹ Ogun."" Oríṣun àwòrán, Getty Images Abiodun ṣalaye pe Anthony Joshua, to tun jẹ ọmọ bibi ipinlẹ Ogun ti gbe ogo Naijiria ga, o si tun fi han awọn eeyan pe orilẹ-ede Naijiria ṣi maa bori gbogbo idojukjọ to n la kọja. Gomina naa sọ pe adura awọn eeyan lo n gba lori abẹṣekubiojo naa ti ade IBF, WBA ati WBO ko tii fi bọ mọ lọwọ. Nigba to n sọrọ loju opo Twitter rẹ, Abiodun fi kun pe aṣeyọri naa ti fi han pe gbogbo owo ti ijọba ipinlẹ Ogun ati akitiyan rẹ lori ere idaraya ko lọ lasan. Ọgbà ẹ̀wọ̀n ni wọ́n ti já àbálé Esra lábẹ́ àwáwí àyẹ̀wò wúndíá Alẹ ọjọ Satide, ọjọ kejila, oṣu kejila ọdun 2020, ni ija naa waye ni gbagede SSE Arena, ni ilu London, nibi ti Joshua ti fi ẹṣe ja Pulev bọ bi apo irẹsi. Yatọ si Abidoun, Aarẹ Muhammadu Buhari naa ti ki Joshua ku orrire aṣeyọri ọhun.",13 Ọ̀pẹ̀̀ 2020 +Wo bí Joshua ṣe fẹ̀ṣẹ́ dá Pulev lẹ́kun àńṣekándúkándú," Oríṣun àwòrán, Reuters Nnkan yan lalẹ ọjọ Satide, ọjọ kejila oṣu kejila ọdun 2020 nigba ti awọn akanṣẹjẹun meji, Anthony Joshua ti ilẹ Gẹẹsi ati Kubrat Pulev ọmọ Bulgaria. Lẹyin o rẹyin Anthony Joshua lo bori nigba to fi ẹṣẹ ja Pulev bs bi apo irẹsi nigba ti ija wọn wọ ipele kẹsan. Oríṣun àwòrán, EPA Pẹlu abajade ija ẹṣẹ kikan naa, Anthony Joshua ṣi ni agba ọjọ akanṣẹ to di bẹliti ẹyẹ WBO, WBA ati IBF mu bayii. Oríṣun àwòrán, PA Media Ija naa ti wọn ja lati aṣalẹ ọjọ Satide wọ kuutkutu owurọ ọjọ Aiku ni igba kejilelogun ti Joshua yoo fi ẹṣẹ ja akanṣẹjẹun miran bọ ni apo irẹsi, iyẹn Knockout lati igba to ti bẹrẹ si ni kan ẹṣẹ jẹun, eyi si ni igba keji ti Pulev yoo kuna lati igba to ti n ja ẹṣẹ jẹun. Oríṣun àwòrán, Reuters",13 Ọ̀pẹ̀̀ 2020 +Kí ni abẹ̀ṣẹ́kùbíòjò Anthony Joshua fi n wu àwọn ọmọ Naijiria tí gbogbo wọn fẹ́ tan mọ́ ọ?," Oríṣun àwòrán, Getty Images Ibẹrẹ Anthony Joshua Wọn mọ ẹbi Joshua daadaa ni ilu Sagamu, ti wọn si mọ itan awọn baba nla rẹ daadaa. Baba-baba-baba rẹ ni Daniel Adebambo Joshua, ọlọrọ onilẹ ati oniṣowo ti wọn gbagbọ pe o yan orukọ kẹta rẹ nigba to di ọmọlẹyin Kristi. Daniel ran ọmọ rẹ kan nileewe nilẹ Britain, nibẹ lo ti fẹ obinrin Irish kan to ba a wale pada si Naijiria nibi ti wọn ti tọ ọmọ meje. Ọkan lara awọn meje ọhun ni Robert to fẹ Yeta Odusanya lati ilu Sagamu kan naa, ohun si ni baba Anthony ati aburo rẹ, Janet. Orukọ mii ti Anthony n jẹ ni Olaseni. Awọn aṣeyọri rẹ ninu jija ẹṣẹ fihan pe idile rẹ gbajumọ tayọ ilu wọn nikan de gbogbo orilẹede Naijiria. Pẹlu iyi lo fi maa n pọn orilẹede rẹ le nibikibi to ba wa, asia Naijiria ko le ma fẹ lẹlẹ nibi to ba ti n ja, koda aworan Afirika wa gbagada lapa rẹ. Oríṣun àwòrán, Getty Images O maa n fihan pe oun fẹran awọn ounjẹ ibilẹ Naijiria gan Bi o ṣe fẹran Naijiria to, o ko ounjẹ ranṣẹ sile fun awọn idile ti Coronavirus ṣakoba fun. O jẹ ẹni to lẹkọ ile pẹlu ọrọ pẹlẹ lẹnu ati ẹrin musẹ to maa n di ẹrin keekee. O nira ki Anthony ma bori to ba ja ẹṣẹ tori naa irawọ to tan jade wa lati Naijiria ni ọpọ ka a si, eyii si mu ki ọpọlọpọ ololufẹ rẹ lati Naijiria fẹran rẹ gan. Ero maa n wọ ni nibi iworan ti wọn ti maa n wo ija Anthony Joshua ni Sagamu, koda Joshua tun ni ẹgbẹ awọn alatilẹyi n tirẹ ni Sagamu. O to ẹgbẹrun mẹwa ololufẹ rẹ to wo ija kan, koda awọn kan rinrinajo lọ wo o. Bi Joshua ko tilẹ ṣe raye ri ipade ṣe pẹlu awọn ololufẹ rẹ nigba to wale ninu oṣu keji, ko sẹni to binu si i, ṣugbọn o ri ọba ati awọn ijoye ko to pada. Oríṣun àwòrán, Getty Images ""Ko si iyọnu, ọmọ wa naa ṣi ni, aṣoju wa si ni,"" ọkan lara wọn, Okunore lo sọ bẹẹ. ""Mo mọ pe o tan mọ Watford amọ ọmọ ilu wa ni baba ati baba baba rẹ ati babaa babaa babaa rẹ"". Iwuri ni Joshua Ọpọ ọdọ ni ẹkun Guusu-Ila Oorun lo ti n fi Joshua ṣe awokọṣe pẹlu bi wọn ṣe n wo o ti wọn si n farabalẹ kọ bo ṣe n goke. Ẹni ọdun mọkanlelogun kan, 'Lekan the Engine' Muibi to jẹ mọkaliiki ni Ooṣa ni Joshua jẹ si oun. ""Mike Tyson gangan lo mu mi fẹran jija ẹṣẹ amọ Joshua lo n ti mi soke pe mo lee moke tori ọmọ Naijiria bii emi loun"".",11 Ọ̀pẹ̀̀ 2020 +Tottenham sọ ọjọ́ ìsinmi olóyin di ''Black Sunday'' mọ́ Arsenal lọ́wọ́ pẹ̀lú ìgbájú-ìgbámú," Oríṣun àwòrán, Getty Images Ti eleyi kii ba ṣe ijamba nla? Ẹ jọwọ kinni ka ti pe eyi naa? Igbaju igbamu ni kẹri kẹri n ba rode ni ẹgbẹ agbabọọlu Tottenham fi ṣe fun Arsenal ninu ifẹsẹwọnsẹ wọn ọjọ Aiku ninu idije Premier League. Afi bi ala ni ọrọ naa ri nigba tawọn ẹgbẹ agbabọọlu olorogun mejeeji ti wọn fi apa ariwa ilu London ṣe ibujoko kọju ija si ara wọn. Ki a to wi, ki a to fọ, ẹlẹsẹ ayo, Heung-Min Son ṣi gbada lori Eṣu lẹyin to gba goolu goolu aramọnda kan wọle Arsenal ni bii iṣẹju mẹtala. Arsenal gbiyanju lati da goolu naa pada, ṣugbọn pabo ni gbogbo igbiyanju ja si. Amọ eruku tun sọ lala nigba to ku diẹ ki ipele akọkọ ifẹsẹwọnsẹ naa pari lẹyin ti Harry Kane gbayo mii wọle Arsenal. Oríṣun àwòrán, Getty Images Gbogbo igbiyanju Arsenal lati gbayo wọle Tottenham ni ipele keji ifẹsẹwọnsẹ ọhun, pabo lo ja si. Arsenal ti wa ni ipo kẹẹdogun bayii lori tabili idije Premier League. Ifẹsẹwọnsẹ mẹfa ọtọtọ ni wọn ti fidi rẹmi rẹmi bayii bayii ninu mọkanla ti wọn ti gba ni saa bọọlu tuntun yii. Ẹgbẹ agbabọọlu Tottenham ti Jose Mourinho jẹ akọnimọọgba wọn lo si wa loke tente bayii lori tabili idije EPL.",6 Ọ̀pẹ̀̀ 2020 +Ọlọ́pàá 200 ni yóò máa ṣọ́ ibojì Diego Maradona torí àwọn olè," Oríṣun àwòrán, Casa Rosada Yoruba bọ wọn ni ohun ti a ba fi silẹ, ni ewurẹ n gbe.Eyi lo mu ki ijọba orile-ede Argentina ṣeto fun igba ọlọpaa ti yoo maa ṣọ iboji agbaọjẹ agbabọọlu tó lọ, Diego Armando Maradona.Ijọba ni ohun gbe igbesẹ yii lati dena mọ awọn ole to lee fẹ ji nkan ninu ibojì naa. Awọn alaṣẹ ilẹ naa bẹru pe awọn janduku le lọ ji awọn ohun mere mere to wa ni iboji naa ti ko ba si eto abo to mọyan lori níbẹ. 'Ọkọ mi wa ọkọ̀ tẹ ""Poly Bag"" lásán, àfi gbùùàà! Àdó okoró búrẹ́kẹ' Ẹka ileeṣẹ ijọba to n ri si eto aabo sọ pe awọn ẹṣọ yoo duro wamu wamu lati ṣọ ibi isinku síi Bella Vista lẹyin olu ilu Argentina, Buenos Aires fun o kere tan fun ọsẹ kan.Ijọba ko fẹ ki ohun to ṣẹlẹ lọdun 1987 nigba ti awọn janduku ji ohun mere mere ko ninu ibojì Aarẹ Argentina tẹlẹ ri, Juan Peron lọ.Maradona to ṣagbatẹru bi Argentina ṣe gba ife ẹyẹ agbaye ọdun 1986, dagbere faye lẹni ọgọta ọdun.Aisan ikọlu ọkan lo ṣekupa Maradona lẹyin to ṣiṣẹ abẹ ọpọlọ tan tori ẹjẹ to da si i lọpọlọ.Bi awọn ọmọ ilẹ Argentina ti fẹran Aarẹ Peron bi oju, ni wọn ṣe fẹran akọni agbabọọlu Maradona naa.",2 Ọ̀pẹ̀̀ 2020 +"Pàá lẹ́ẹ̀kíní, pàá lẹ́ẹ̀kejì, nígbà wo gan ni Madrid fẹ́ jẹ àǹfàní £150m tí wọ́n kó lè Eden Hazard?"," Oríṣun àwòrán, Getty Images Eden Hazard agbabọọlu ọmọ Belgium to n ṣoju ẹgbẹ Real Madrid ti tun farapa lori papa iṣere. Iṣẹlẹ yi waye lasiko ti Real Madrid n koju Alaves eyi ti wọn ti fidi rẹmi pẹlu goolu meji sookan. Hazard to ṣe wi pe o ṣẹṣẹ kopa ninu ifẹwọnsẹ mẹta pere lati igba ti saa bọọlu ọdun yi ti bẹrẹ ko lo ju iṣẹju mejidinlọgbọn lọ lori papa ki wọn to gbe e jade. A ko ti le sọ ni pato ẹya ara to da wahala tuntun yi silẹ fun botilẹ jẹ pe awọn kan ni kokosẹ rẹ ni. ""Mi o le ṣalaye nkan to ṣẹlẹ lalẹ oni. Tibi tire ni nkan to ṣẹlẹ si wa'' ''Nipa Eden mo lero pe, mo si ni igbagbọ pe kii ṣe nkankan to lagbara pupọ. O sọ fun mi pe ki ṣe nkan to le. Mo lero pe ko ni ju bẹẹ lọ'' Ọrọ ti akọnimọọgba Madrid Zinedine Zidane sọ re lẹyin ifẹsẹwọnsẹ wọn. Oríṣun àwòrán, Reuters Goolu ti Lucas Perez jẹ nipa gbe e silẹ gba a sile ni iṣẹju karun abala kini ni ikọ Alaves fi lewaju ninu ifẹsẹwọnsẹ naa. Joselu naa da kun iya fun Real Madrid lẹyin aṣiṣe asọle Madrid Thibaut Courtois. Casemiro lo pada wa jẹ goolu dondo fun Madrid ni nkan bii iṣẹju diẹ ti ifẹsẹwọnsẹ naa yoo fi pari. Kini ka ti pe ifarapa gbogbo igba yii? Ọdun 2019 ni Real Madrid na owo to le ni aadọjọ miliọnu poun lati ra Eden Hazard lọdọ Chelsea. Lati igba to ti de si ẹgbẹ agbabọọlu naa igba mẹtadinlọgbọn pere lo ṣeṣe gba bọọlu fun ikọ Zinedine Zidane. Nibẹrẹ saa bọọlu yi, ko ribi kopa nitori pe o farapa lori ẹsẹ ọtun rẹ ti o si fagidi gba nigba mẹta pere ki o to ko arun Covid-19 nibẹrẹ oṣu Kọkanla",29 Bélú 2020 +Báyìí ni àgbàọ̀jẹ̀ agbábọ́ọ̀lù Diego Maradona ṣe wọ káà ilẹ̀ lọ lólú ìlú Argentina," Oríṣun àwòrán, Casa Rosada Ba a ku laa dere eeyan o sunwọn laaye. Agbaọjẹ agbabọọlu Argentina yẹlẹ ri, Diego Maradona ti wọ kaa ilẹ lọlẹyin to papoda lẹni ọgọta ọdun. Olu ilu orilẹede Argentina, Buenos Aires ni wọn sin Maradona si nibi ti ọpọ ti pejọ lati ṣe ẹyẹ ikẹyin fun elege ara to filẹ ṣaṣọ bora. Awọn ẹbi ti ko ju mẹrinlelogun lọ pẹlu awọn ọrẹ rẹ lo wa nibi ayẹyẹ isinku Maradona l'Ọjọbọ. Amọ, ọgọọrọ eeyan lo lanfaani lati ṣe ẹyẹ ikẹyin fun un, ọpọ lo n sunkun, nigba ti awọn mii n ṣe sadakanta lẹgbẹ posi Maradona. Iku Maradona ti mu ki gbogbo eeyan lagbaaye papaa julọ awọn ololufẹ ere bọọlu ṣe idaro ẹni 're to lọ papaa julọ nilẹ abinibi rẹ, Argentina. Koda asia orilẹede Argentina ati jẹsi rẹ pẹlu nọmba ''10'' ti o maa n wọ wa lori posi Maradona fun awọn eeyan lati ri lolu ileeṣẹ ijọba ilẹ naa. Oríṣun àwòrán, Reuters Maradona was regarded as a national hero in Argentina Awọn agbofinro tiẹ ni ikọlu pẹlu awọn oludaro to n gbiyanju lati suu mọ olu ileeṣẹ ijọba nibi ti wọn gbe posi Maradona si. Iroyin kan tiẹ tun sọ pe awọn ọlọpaa yin tajutaju lati dari awọn ero nibi eto isinku naa. Ọkọ igboku si lo gbe posi Maradona lo si ilẹ isinku si Bella Vista ni bi ti o ti sun. Ọ̀rọ̀ àsọkẹ́yìn Diego Maradona ìlúmọọká agbábọ́ọ̀lù rèé kó tó dágbére f'áyé Ohun mẹta ti ẹda kan ko mọ laye ti a wa yii ni pe ko si ẹni to mọ iru iku ti yoo pa a. Ekeji ni pe ko si ẹni to mọ igba ati akoko ti ọlọjọ yoo de ati pe ko si ẹda ẹni to mọ ibi ti o maa ku sii. Awọn ọmọ orilẹede Argentina ati gbogbo agbaye si n ṣe idaro gbajugbaja agbabọọlu elege ara, Diego Maradona ti filẹ ṣaṣọ bora lẹni ọgọta ọdun l'Ọjọru. Amọ kinni ọrọ ti ogbontarigi agbabọọlu naa sọ kẹyin ki o to jẹ Eleduwa ni pe. Oríṣun àwòrán, Getty Images Gẹgẹ bi iroyin to tẹ wa lọwọ lati orilẹede Argentina, Maradona sọ fun ọmọkunrin to wa pẹlu rẹ ni ede ilu rẹ pe ''Me siento mal,'' eyi to tumọ si ''o n rẹ mi.'' Ara Maradona ko le daadaa nigba to lọ jẹ ounjẹ aarọ Ọjọru, o ṣaroye pe otutu n mu oun. Oríṣun àwòrán, Getty Images Lẹyin naa lo sọ fun ẹbi rẹ kan pe o n rẹ oun ki o to pada sori ibusun rẹ ki ẹlẹmi to gba a. Ayẹwo oku fihan pe arun ikọlu ọkan to ṣekupa Maradona lẹyin ọsẹ meji to ṣe iṣẹ abẹ ọpọlọ lati ko ẹjọ to da sii lọpọlọ kuro. Ẹwẹ, aarẹ orilẹede Argentina, Alberto Fernandez ti kede ọjọ mẹta lati kẹdun Maradona. Oba Adedokun Abolarin ti Oke Ila: Ó ya ọ̀pọ̀ tó súnmọ́ mi lẹ́nu bí mo ṣe ń kọ́ Diego Maradona ìlúmọọká agbábọ́ọ̀lù dágbére f'áyé Iroyin to n tẹ wa lọwọ ni yajoyajo sọ pe gbajugbaja agbabọọlu ni ọmọ Argentina Diego Maradona ti dagbere faye. Ikede yi ta ri ka loju opo awọn ileesẹ iroyin sọ pe o faye silẹ laipẹ ọjọ ti o ṣe isẹ abẹ ọpọlọ. Oríṣun àwòrán, Getty Images Ẹni ọgọta aọdun ni Maradona ko to fi aye silẹ. Maradona je okan lara agbabọọlu to lamilaka julọ lagbaye. O tun jẹ agbabọọlu ọmọ Argentina tó gbà ife ẹyẹ agbaye gẹgẹ bi Balogun ikọ ọmọ agbabọọlu Argentina. Ọpọ ni yoo maa ṣe iranti Maradona fun goolu rẹ to fọwọ jẹ ninu idije agbaye eyi ti Argentina fi gbewuro soju ilẹ Gẹẹsi ni Mexico 86. Oríṣun àwòrán, AFP Tolori tẹlẹmu ni ko ni gbagbe ilumọọka agbabọọlu elege ara yi to ṣe pe o ko ipa ribi ribi ninu ere bọọlu lagbaye. Nigba aye rẹ, o gba bọọlu fún ẹgbẹ agbabọọlu Barcelona àti Napoli ó si gba ife ẹyẹ pelu lẹẹmeji ni Serie A.",25 Bélú 2020 +Ohun mẹ́wàá pàtàkì nípa Maradona àti ìbáṣepọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú ẹlẹ́sẹ̀ ayò Diego Costa rèé," Oríṣun àwòrán, Getty Images Erin wo, ajanaku sun bi oke! Gbogbo agbaye papaa julọ awọn ogbontarigi agbabọọlu atawọn ololufẹ ere bọọlu lo n ṣe idaro Diego Amando Maradona to jade laye l'Ọjọru lẹni ọgọta ọdun. Ilumọọka elege ara ni agbabọọlu ọmọbibi orilẹede Argentina, Maradona jẹ, koda awọn eeyan kan gbagbọ pe oun ni agbabọọlu to dantọ julọ ninu iwe itan. Maradona wa lati idile ti wọn ko ṣaaba rọwọ fi họri, o si goke agba di agbaọjẹ agbabọọlu kaakiri agbaaye. Maradona gba ami ẹyẹ pẹlu oriṣiiriṣii ẹgbẹ agbabọọlu lorilẹede Argentina, Italy ati Spain. Eyi ti ọpọ eeyan ko le gbagbe laelae ni idije ife ẹyẹ agbaye eyi ti Maradona gba pẹlu orilẹede rẹ lọdun 1986. Lara awọn abawọn ti awọn eeyan ṣaaba maa n tọka si ni mimu oogun oloro ati ọti lile nigba to n gbabọọlu. Oba Adedokun Abolarin ti Oke Ila: Ó ya ọ̀pọ̀ tó súnmọ́ mi lẹ́nu bí mo ṣe ń kọ́ Ohun mẹwaa pataki to yẹ ki o mọ ree nipa Diego Maradona 1. Maradona gbarada nigba to gba ami ẹyẹ liigi ọjẹwẹwẹ Argentina pẹlu ẹgbẹ agbabọọlu Boca Juniors lọdun 1982. 2. Lọdun 1984, Maradona fi ikọ agbabọọlu Boca Juniors silẹ lọ si Napoli lorilẹede Italy. Oun lo ṣagbatẹru bi Napoli ṣe gba ami ẹyẹ Serie A ti wọn gba lọdun 1987 ati 1990, ami ẹyẹ Serie A meji pere ti wọn gba ninu itan wọn. Oríṣun àwòrán, Getty Images Diego Maradona gba ife ẹyẹ agbaye ọdun 1986 3. Maradona nikan ni balogun ẹgbẹ agbabọọlu to ṣoju orilẹede rẹ fun akoko to pọ julọ. Igba mẹrindinlogun ọtọtọ ni Maradona ṣoju Argentina ninu idije ife ẹyẹ agbaye. 4. Ọmọ ọdun mẹẹdogun ni Maradona wa nigba to bẹrẹ si ni maa gbabọọlu lẹyin to darapọ mọ ẹgbẹ agbabọọlu Boca Juniors logunjọ oṣu kẹwaa ọdun 1979. 5. Ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu keji ọdun 1977 ni Maradona bẹrẹ si ni ṣoju orilẹede Argentina. Oríṣun àwòrán, Rex Features Maradona lagbabọọlu ti o pegede julọ nidije agbaye ọdun 1986 Ọmọ ọdun mẹrindinlogun lo wa nigba naa, orilẹede Hungary ni Argentina koju lọjọ naa. 6. Ẹgbẹ agbabọọlu Argentinos Juniors ti fi orukọ Maradona sọ papa iṣere wọn, Estadio Diego Armando Maradona ni papa isẹre naa n jẹ bayii. 7. Lọdun 1996, Maradona sọ pe ''mo ti loogun oloro, mo si n loogun oloro, mo si maa loogun lọ laelae.'' Kí lo mọ̀ nípa ìbẹta kan ṣoṣo tí Alaafin Oyo bí? Wọ́n pé ọdún méjìlá báyìí Kílódé tí Ọọni Ife, Oba Ogunwusi kò fi gbọdọ̀ rí ọmọ rẹ̀ tuntun ti Olorì Naomi bí títí di bíi ẹ̀yìn oṣù mẹ́fà? Ilé ẹjọ́ dájọ́ ẹgba mẹ́ẹ̀dóògún fún ọ̀daràn tó jí Iphone ní Kaduna Wo dókítà ọmọ Nàìjíríà tí àgbáyé ń wárí fún nítorí abẹ́rẹ́ àjẹsára COVID-19 Wo ọkùnrin ẹni ọdún 55 tí wọ́n ká agbárí èèyàn mẹ́rin, àti àwọn ẹ̀yà ara mìí mọ́ lọ́wọ́ ní Ogun Ìyàwó wọ sòkòtò fún ayẹyẹ ìgbéyéwò rẹ̀, ní wáhálà bá bẹ́ sílẹ̀ 8. Lọdun 2000, ajọ to n ṣagbatẹru ere bọọlu lagbaaye, FIFA fi ẹbun agbabọọlu to dantọ julọ ninu iwe itan fun Maradona ati Pele orilẹede Brazil. 9. Maradona sọ fun ra rẹ pe Dalma ati Giannina ni ojulowo ọmọ oun nigba ti awọn yoku jẹ aṣiṣe atipe tori owo oun loun fi bi awọn ọmọ yoku. 10. Wọn sọ ẹlẹsẹ ayo Diego Costa to jẹ ọmọbibi orilẹede Brazil to n ṣoju Spain lorukọ Maradona. Akọ́mọlédè àti Àṣà lórí BBC Yorùbá: Kọ̀ síi nípa iṣẹ́ tí oúnjẹ ń ṣe lára níbí",26 Bélú 2020 +"Wọ́n ti fòfin ọdún márùn ún de Aàrẹ̀ CAF, Ahmad Ahmad"," Oríṣun àwòrán, Getty Images Ajọ to n mojuto ọrọ ere bọọlu ni agbaye ti fofin ọdun marun un de aarẹ ajọ to n ri si ọrọ ere bọọlu nilẹ Adulawọ. FIFA fẹsun kan Ahmad Ahmad lẹyin ọpọlọpọ iwadii lori ṣiṣe magomago owo ati titẹ oju awọn ofin ajọ naa molẹ nilẹ Afrika. Wọn tun ni ko ṣe e fi ọkan tan ati pe o tun gba owo ati ẹbun lọna aitọ yatọ si aṣilo ipo ati agbara. FIFA ni lati ọdun 2017 ni wọn ti n ṣe iwadii naa titi di ọdun 2019. Wọn tun ni ẹsun riran awọn eeyan lọ fun Umrah ni Mecca fun irinajo ẹsin naa tun jẹyọ. Oríṣun àwòrán, Getty Images Ogbeni Ahmad ni FIFA kede fifi ofin ọlọdun marun un de yii ni wọn tun ni ko san owo itanran $200, 000 to jẹ ẹgbẹrun lọna igba owo dọla ilẹ okeere. O seese fun aarẹ CAF naa lati pe ẹjọ kotẹmilọrun si idajọ yii nile ẹjọ to wa fun igbẹjọ awọn elere bọọlu ati ere idaraya iyẹn: Court of Arbitration for Sport (CAS) laarin ọgọta ọjọ si asiko yii. Loṣu to kọja ni aarẹ Madagascar naa ni oun fẹ lọ lẹẹkeji ninu idibo to yẹ ko waye ni oṣu kẹta ọdun to m bọ. Lọdun 2017 ni Ahmad di aarẹ CAF.",23 Bélú 2020 +Taribo West wọ gàu lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà lẹ́yìn tó sọtẹ́lẹ̀ pé Trump yóò wọlé ìbò ààrẹ Amerika," Oríṣun àwòrán, Taribo/twitter Taribo West wọ gàu lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà lẹ́yìn tó sọtẹ́lẹ̀ pé Trump yóò wọlé ìbò ààrẹ Amerika. Ọrọ agbabọọlu Naijiria tẹlẹ ri, Taribo West lọpọ n gba bi ẹni n gba igba ọti lori ayelujara lẹyin to sọ asọtẹlẹ pe Aarẹ Donald Trump ni yoo wọle ibo aarẹ orilẹ-ede Amẹrika. Ọpọ lo bẹrẹ si ni fi West to jẹ adilemu ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles ṣe lẹyin ti oludije ẹgbẹ oṣelu Democrat, Joe Biden wọle ibo ọhun tan. Fidio asọtẹlẹ naa ti wa lori ayelujara ṣaaju ibo aarẹ Amẹrika, amọ awọn eeyan bẹrẹ si ni sọ nipa rẹ lẹyin ti Trump fidi rẹmi tan. West to jẹ pasitọ sọ ninu fidio naa pe oun sọtẹlẹlẹ ṣaaju pe Godwin Obaseki ni yóò wọlẹ ibo gomina ipinlẹ Edo. Oríṣun àwòrán, Taribo/ twitter O tun sọ ninu fọ́nrán naa pe asọtẹlẹ jade lẹnu oun pe Rotimi Akeredolu ni yoo wọle ibo gomina Ondo, ṣugbọn ko si ẹni to sọ nipa awọn asọtẹlẹ yii lori ayelujara. O rọ eeyan lati pin fidio naa nitori pe o da oun loju pe ibo diẹ ni Trump yoo fi la Biden mọlẹ ninu ibo aarẹ Amẹrika. Amọ, awọn kan sọ pe asọtẹlẹ Ọgbẹni West si le wa si imuṣẹ nitori Trump ti gbọrọ idibo naa lọ si ileẹjọ. Akomolede ati Aṣa lori BBC:Wo ìrúfẹ́ ìgbeyàwó méje tó wà nílẹ̀ Yorùbá àti ojúṣe Alárinà",10 Bélú 2020 +Diego Maradona ṣiṣẹ́ abẹ lórí ẹ̀jẹ̀ tó dì sí i lọ́pọlọ lẹ́yìn ọjọ́ ìbí ọgọ́ta ọdún," Oríṣun àwòrán, Getty Images Agbaọjẹ agbabọọlu orilẹede Argentina nigba kan ri, Diego Maradona ti ṣiṣẹ abẹ lori ọpọlọ rẹ, iṣẹ abẹ naa si kẹsẹ jari. Dokita gbajugbaja agbabọọlu naa, Leopoldo Luque lo ṣi aṣọ loju eegun ọrọ yii fawọn akọroyin. Lọjọ Aje ni wọn gbe Maradona lọ si ile iwosan Ipensa to wa niluu Buenos Aires. Dokita Luque sọ pe Maradona si wa labẹ ayẹwo bi ara rẹ ti n ya bọ diẹdiẹ lẹyin to ṣiṣẹ abẹ tan. lati ile iwosan Ipensa ni wọn ti gbe Maradona lọ si ile iwosan Olivos Clinic to wa ni La Plata nibi to ti ṣiṣẹ abẹ naa. Wakati kan ati ogun iṣẹju ni wọn fi ṣiṣẹ abẹ ọhun fun Maradona. Oríṣun àwòrán, Getty Images Maradona, ẹni ọgọta ọdun ni akọnimọọgba ẹgbẹ agbabọọlu Gimnasia y Esgrima to n dije ninu liigi orilẹede Argentina. Koda Maradona wa nibi ifẹsẹwọnsẹ Gimnasia y Esgrima pẹlu Patronato to waye lọjọ Ẹti tii ṣe ọjọ ibi ọgọta ọdun rẹ. Ọpọ awọn ololufẹ ẹgbẹ agbabọọlu Gimnasia y Esgrima lo wa nita ile iwosan ti wọn ti ṣiṣẹ abẹ fun Maradona lati fihan pe gbọin-gbọin lawọn wa lẹyin rẹ. Ọpọ ninu lo bẹrẹ si ni fi orukọ rẹ kọrin, kete ti wọn gbọ pe iṣẹ abẹ naa ti pari. Ẹgbẹ agbabọọlu Napoli ti Maradona ran lọwọ lati gba liigi Serie A lẹẹmeji naa ranṣẹ si i loju opo Twitter wọn.",4 Bélú 2020 +Aàbò tó péye yóò wà fún àwọn tí yóò kópa nínú ìfẹsẹwọ̀nsẹ̀ Naijiria àti Sierra Leone ní Benin - Obaseki," Oríṣun àwòrán, @daily_trust Gomina ipinlẹ Edo, Godwin Obaseki ti sọ pe abo to peye yoo wa fun gbogbo awọn agbabọọlu atawọn ero iworan ti yoo wa nibi ifẹṣewọn laarin ikọ Super Eagles ati Leone Stars ti orilẹ-ede Sierra Leone lọsẹ to n bọ. Ifẹsẹwọnsẹ naa to jẹ igabradi idije ife ẹyẹ ilẹ Afrika, AFCON, ti yoo waye lọdun 2021 ni yoo waye ni papa iṣẹre Samuel Ogbemudia ni ilu Benin. Bakan naa ni ifẹsẹwọnjsẹ to lamilaaka akọkọ ti yoo waye ni papa iṣẹre naa lati igba ti wọn ti ṣatunṣe rẹ. O tun jẹ ifẹsẹwọnsẹ to lamilaaka ti ikọ Super Eagles yoo gba lati igba ti ajakalẹ arun Coronavirus ti bẹrẹ. Oríṣun àwòrán, @NGSuperEagles Ifẹsẹwọnsẹ naa yoo waye lọjọ kẹtala, oṣu kọkanla, ọdun 2020, lẹyin ọjọ ti iburawọle gomina Obaseki fun saa keji gẹgẹ bii gomina. Olubadamọran pataki fun gomina ọhun lori ọrọ to n lọ, Crusoe Osagie sọ pe ijọba ipinlẹ naa ti ṣetan lati dabo bo gbogbo eeyan ti yoo peju sibi ifẹsẹwọnsẹ ọhun. Gẹgẹ bo ṣe sọ, o ni ""idunnu wa ni lati ṣagbatẹru igbaradi idije AFCON 2021 laarin ikọ Super Eagles ati Leone Stars ni papa iṣẹre Ogbemudia."" John Amanam: Ìfẹ́ tí mo ní sí àbúrò mi ló sọ mi dí ẹni tó ń ṣe 'Prosthetic' báyìí",1 Bélú 2020 +"₦147m la rí kójọ fún ìwọ́de, a kò fẹ́ owó mọ́, ìwọ́de ti parí - Feminist Coalition"," Ẹgbẹ kan to n lewaju ninu eto akoso iwọde EndSARS ni Nigeria, The Feminist Coalition, ti kede pe oun ti yọwọ yọsẹ kuro ninu iwọde naa. Bakan naa lo kede pe oun ti se alaye lori owo ti wọn ri ko jọ fun iwọde naa, ti apapọ rẹ jẹ miliọnu mẹtadinlaadọjọ naira. Ọjọbọ ni ẹgbẹ Feminist Coalition kede pe oun ko ni ni ohunkohun se pẹlu iwọde kankan mọ. O salaye pe asẹ ti aarẹ Muhammadu Buhari pa ninu ọrọ to ba awọn ọmọ Naijiria sọ, pe ki wọn fi opin si iwọde wọn, lo mu ki oun se ipinnu ọhun. O wa rọ awọn alatilẹyin ẹgbẹ naa nilẹ yii ati loke okun, lati dẹkun fifi owo sọwọ sinu apo asunwọn ẹgbẹ naa ti wọn fi n ko owo jọ, eyi towo inu rẹ bayii jẹ miliọnu lọna mẹtadinlaadọjọ naira. Oríṣun àwòrán, @feminist_co Bakan naa ni ẹgbẹ Feminist Coalition tun rawọ ẹbẹ sawọn ọdọ pe ki wọn dẹkun iwọde naa, niwọn igba ti aarẹ ti ba araalu sọrọ, ti ko si mẹnuba ohunkohun to nii se pẹlu ibọn yinyin to waye ni Lekki. O ni dipo bẹẹ, se ni aarẹ Buhari se atilẹyin fun ikede konile o gbele to wa lawọn ipinlẹ kan lorilẹede yii, to si rọ awọn eeyan lati dẹkun iwọde fun aabo ẹmi wọn. Ko tan sibẹ, ẹgbẹ Feminisit Coalition tun pẹlu alaafia ni awọn oluwọde EndSARS fi n se iwọde wọn yika Naijiria, ti wọn si safihan iwa ọlọgbọn. Oríṣun àwòrán, @feminist_co ""Amọ nibi ti ọrọ de bayii, a gbọdọ daabo bo ẹmi ara wa ati tawọn ọmọ ẹgbẹ wa pẹlu."" Nipa ti owo ti wọn ri kojọ, tii se miliọnu lọna mẹtadinlaadọjọ naira fun iwọde naa, o ni awọn ti na miliọnu lsna ọgọta ninu rẹ laarin ssẹ meji, gẹgẹ bi alaye to wa lori ayelujara wọn. Oríṣun àwòrán, @VillaUpdates1 Atamatase ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles, John Ogu ti ke si awọn akẹgbẹ rẹ, lati maṣe kopa ninu ifẹsẹwọnsẹ Naijiria to n bọ lọjọ iwaju. O ni oun n pe ipe naa nitori iha ti ijọba apapọ kọ si iwọde End SARS. Agbabọọlu naa, to ti gba bọọlu fun Naijiria ni igba mẹrindinlọgbọn sọ pe, ṣiṣe bẹẹ yoo jẹ ki ijọba apapọ mọ bi ọrọ ṣe gbona si lara wọn. O ni kawọn oloselu kesi awọ̀n ọmọ wọn lati maa lọ soju Naijiria ninu ifẹsẹwọnsẹ Super Eagles to n bọ Kii ṣe Ogu nikan ni ọmọ Naijiria to jẹ agbabọọlu to bu ẹnu atẹ lu ọwọ ti ijọba fi mu iwọde naa, paapaa lẹyin ifẹmiṣofo to waye ni Lekki. Ṣaaju ni Odion Ighalo, to n gba bọọlu fun Manchester United nilẹ Gẹẹsi, ti kọkọ sọ pe ""itiju nla gbaa"" ni ijọba Naijiria jẹ lẹyin ikọlu Lekki. Ajọ ajafẹtọ ọmọniyan lagbaye, Amnesty International sọ pe ko din ni eeyan mejila to ku nibi iṣẹlẹ naa. Ṣugbọn ileeṣẹ ologun ti sẹ pe ohun ko mọ ohun nipa iṣẹlẹ to waye ni Lekki, bẹẹ na ni ijọba ipinlẹ Eko naa ni oun ko mọ ohunkohun nipa rẹ, ti Aarẹ Muhammadu Buhari naa ko si sọrọ. Iwọde End SARS bẹrẹ lati pe fun opin si ẹka ileeṣẹ ọlọpa to n ri si iwa idigunjale, SARS, lori iwa aṣemaṣe ti wọn n wu ati bi wọn ṣe n tẹ oju ẹtọ awọn eeyan mọlẹ. #EndSARS : Àwọn ọ̀dọ́ dáná sun tírélà akẹ́rù tẹrùtẹrù ní Ekiti",23 Ọ̀wàrà 2020 +"Àfikún owó epo, owó iná àti owó orí VAT ló jẹ́ ká fowó kún tàríìfù DSTV- Ọ̀gá MultiChoice"," Oríṣun àwòrán, Twitter/Super Sport Ti ko ba nidi, obinrin kii jẹ ikumolu. Ileeṣẹ MultiChoice Group to ni ileeṣẹ amohunmaworan DSTV ti ṣalaye fawọn ọmọ Naijiria ohun to ṣe okunfa bi wọn ti gbowo le tariifu ẹrọ amohunmaworan naa. Ileeṣẹ MultiChoice Group bi ijọba apapọ ti ṣe afikun owo ori VAT, epo rọbi ati ina mọnamọna lo jẹ kawọn naa gbowo le DSTV. Oludari ileeṣẹ MultiChoice Group, John Ugbe lo sọrọ yii niwaju igbimọ ile aṣoju-ṣofin to ṣe iwadii afikun owo tariifu DSTV. O tun fesi lori bi awọn eeyan kan ti n sọ pe ileeṣẹ naa ko ṣe eto iranwọ fawọn ọmọ Naijiria lasiko coronavirus, MultiChoice Group ni ohun ti gbe biliọnu kan naira fun ijọba apapọ gẹgẹ bi owo iranwọ. Ileeṣẹ MultiChoice Group ṣalaye siwaju si pe bi ọrọ aje to dẹnu kọlẹ ṣe n ṣakoba fawọn ọmọ Naijiria lo n ṣe akoba fun ileeṣẹ ọhun naa. Lọjọ kẹtadinlogun oṣu kẹta 2020 yii ni ile igbimọ aṣoju-ṣoju gbe igbimọ kan kalẹ lati ṣe iwadii afikun owo tariifu DSTV ni Naijiria. coronavirus prevention badge update: Wo òótọ́ àti irọ́ tó wà nínú báàjì àyà náà Bakan naa ni ile tun pinnu lọjọ keji oṣu kẹfa pe ki ileeṣẹ DSTV wa wi tẹnu rẹ lori ọrọ tariifu naa. Ninu ọrọ rẹ, alaga igbimọ to n ṣe iwadii ileeṣẹ DSTV, Unyime Idem sọ pe ile bẹrẹ iwadii lẹyin tawọn ọmọ fi ẹhonu han lori afikun owo tariifu DSTV. Ile ti sun ijoko lori ọrọ naa siwaju lai lọjọ lẹyin ijoko ọjọ Aje. Abayọmi Aranmọlatẹ, Dr Laser: Vagino Plasty àti iṣẹ́ abẹ ẹwà Obìnrin ló jẹ mí lógún",13 Ọ̀wàrà 2020 +Mo sì ń gba ìtọ́jú lọ́wọ́ lẹ́yìn tí Fury fẹ̀ṣẹ́ já iṣan ọwọ́ mi loṣù mẹ́jọ sẹ́yìn- Deontay Wilder," Oríṣun àwòrán, Reuters Iya ko to iya ni ọmọde maa sọ pe ko ni dara fun ẹni to lu oun. Agbaọjẹ abẹṣẹ ku bi ojo, Deontay Wilder lo sọ pe oun si n gba itọju lẹyin oṣu mẹjọ ti Tyson Fury ti fẹṣẹ dara si oun lara. Wilder oun ko lanfaani lati ṣe igbaradi kankan bayii nitori oun ni lati ṣe iṣẹ abẹ nitori ipalara ti oun ni lori iṣan ọwọ oun nigba ti o koju Fury. Wilder to jẹ abẹṣẹ ku bi ojo ọmọbibi ilẹ Amẹrika fidi rẹmi ninu ija fun igba akọkọ nigba ti oun ati Futy waako loṣu keji ọdun 2020 yii niluu Las Vegas l'Amẹrika. O yẹ kawọn mejeeji tun jọ koju ara wọn lẹẹkan si lọjọ kẹẹdọgbọn oṣu keje ṣugbọn iṣede ajakalẹ aarun coronavirus ko jẹ ki ija naa waye. ''Mo ti n gbadun bọ diẹ diẹ, ohun kan ti mo n ro lasiko yii ni lati gbadun pada,'' Wilder lo sọ bẹẹ. Wilder ti inagijẹ rẹ n jẹ Bronze Bomber sọ pe oun yoo bẹrẹ igbaradi kete ti oun ba ti gbadun tan. Nigba naa ni mo maa raye lati bẹrẹ si ni ṣe ohun ti mo fẹran lati maa ṣe. Oríṣun àwòrán, Getty Images Wilder ni oriṣiiriṣii ounjẹ loun n jẹ lọwọ yii pẹlu afẹsọna atawọn ọmọde to rọgba yi oun ka. O ni oun ko le ṣe aroye nipa ohun ti oun n la kọja lasiko yii, nitori gbogbo agbaye lo n la oriṣiiriṣii nkan kọja bayii fun igba akọkọ. Ṣugbọn Wilder si gbagbọ pe oun si le ba Fury ja ki ọdun 2020 to pari bo tilẹ jẹ pe ko tii gbadun ọwọ rẹ tan.",11 Ọ̀wàrà 2020 +Olivier Giroud fi àràmọ̀ndà góòlù méjì ṣayẹyẹ ìfẹsẹ́wọnsẹ̀ ọgọ́rùn ún tó gbá fún France," Oríṣun àwòrán, Instagram/giroud918 Ọpọ olololufẹ ere boolu lo bu ẹnu ẹtẹ lu ẹlẹsẹ ayo, Olivier Giroud lẹyin to kuna lati gba goolu kankan sawọn fun ẹgbẹ agbabọọlu orilẹede Faranse ninu idije ife ẹyẹ agbaye lọdun 2018. Ṣugbọn Giroud ya agbado ha si awọn to maa n tako o lẹnu lalẹ Ọjọru nigba to gba goolu aramọnda meji ọtọtọ sawọn ninu ifẹsẹwọnsẹ ọlọrẹsọọrẹ to waye laarin ilẹ Faranse ati Ukraine. Ọjọ manigbagbe ni alẹ Ọjọru ọjọ keje oṣu kẹwaa, ọdun 2020 jẹ fun Giroud nitori ifẹsẹwọnsẹ to fakọyọ ninu rẹ yii lọ jẹ ifẹsẹwọnsẹ ọgọrun un ti yoo kopa ninu rẹ fun ilu baba rẹ, Faranse. Alabami ni ilẹ Faranse lu Ukraine ninu ere bọọlu naa lẹyin ti wọn gba goolu meje ọtọtọ wọle ti Ukraine si rapala da ẹyọkan ṣoṣo pada. Amọ ara ọtọ ni goolu meji ti Giroud ẹni ọdun mẹtalelọgbọn gba wọle ninu rẹ jẹ. Giroud ko si lara awọn ẹlẹsẹ ayo meji akọkọ lẹgbẹ agbabọọlu Chelsea to ti gbabọọlu jẹun, bakan naa ọpọ ni ko nigbagbọ ninu rẹ nigba to fi wa pẹlu ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal. Ṣugbọn ọrọ Giroud ti di okuta tawọn ọmọle kọ silẹ to ti wa di pataki igun ile bayii pẹlu ara to fi bọọlu da nigba ti orilẹede Faranse waako pẹlu Ukraine. Lapapọ, Giroud ti gba goolu mejilelogoji sawọn bayii fun orilẹede Faranse ninu ọgọrun un bọọlu to ti ṣoju ilẹ naa. Oun ni ẹleṣẹ ayo keji to gbabọọlu sawọn julọ fun orilẹede Faranse, agbaọjẹ agbabọọlu Arsenal tẹlẹ ri, Thierry Henry lo wa ni ipo kinni. Goolu mẹsan an ni Henry fi ju Giroud lọ eyi ti o si lanfaani lati ba a ati lati ju u lọ.",8 Ọ̀wàrà 2020 +"Cavani dèrò Man United, Arsenal bínú ra Partey ní £45m, Walcott padà sí ẹsẹ àárọ̀"," Oríṣun àwòrán, Getty Images Ẹni to ba foju ana wo oku, ẹbọra ni yoo bọ oluwa rẹ laṣọ. Ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal ya agbado ha sawọn ololufẹ ere bọọlu lẹnu lẹyin ti wọn ra agbabọọlu aaringbungbun Thomas Partey lati Atletico Madrid. Lọjọ karun un oṣu kẹwaa ọdun 2020 ti ọja kata-kara kasẹ nlẹ ni Arsenal ra Partey ni miliọnu marundinlaadọta owo pọun. Partey to jẹ ọmọ ọdun mẹtadinlọgbọn kopa ninu ifẹsẹwọnsẹ liigi La Liga marun din logoji, o si gba goolu mẹta sawọn fun Atletico ni saa bọọlu to lọ. Partey to jẹ ọmọbibi orilẹede Ghana gba ife ẹyẹ Europa League ati Super Cup ọdun 2018 pẹlu Atletico nigba to wa nibẹ. Ẹwẹ, agbabọọlu Arsenal, Lucas Torreira lo rọpo Partey ni Atletico Madrid lẹyin to darapọ mọ wọn fun ọdun kan. Torreira lanfaani lati pada si ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal lẹyin ọdun kan. Edinson Cavani dero Manchester United Oríṣun àwòrán, Getty Images Yoruba bọ, wọn ni bi a ko ba ri adan, a mọ fi obẹ ṣe ẹbọ. Bayii gan an ni ọrọ ṣe ri pẹlu ẹgbẹ agbabọọlu Manchester United ninu ọja kata-kara awọn agbabọọlu to kasẹ nlẹ lọjọ Aje ọjọ karun un oṣu kẹwaa ọdun 2020. Agbabọọlu Borusia Dortmund Jadon Sancho ni Man United kọkọ le lati ra ṣugbọ ko ri ra nitori owo gọbọi ni Dortmund gbe le lori. Eyi lo jẹ ki man U lọ fun ẹleṣẹ ayo ẹgbẹ agbabọọlu PSG tẹlẹ, Edinson Cavani, ẹni ọdun mẹtalelọgbọn. Ọta le lugba o din mẹwaa ẹgbẹrun owo pọun(£250,000) ni Cavani yoo maa gba ni Manchester United. Aṣọ gbajugbaja Nọmba 7 tawọn agbaọjẹ agbabọọlu to ti ṣoju Man United tẹlẹ ri ni Cavani yoo maa wọ. Theo Walcott pada si Southampton Oríṣun àwòrán, Getty Images Ẹlẹsẹ ayo Theo Walcott ti pada si ẹgbẹ agbabọọlu Southampton lati Everton fun ọdun kan. Walcott pada si Southampton lẹyin ọdun mẹẹdogun to fi ẹgbẹ agbabọọlu silẹ darapọ mọ Arsenal. Ọdun 2018 ni Walcott fi Arsenal silẹ lọ Everton lẹyin ti wọn ta a ni ogun miliọnu pọun. Walcott ọmọ ọdun mọkanlelọgbọn ṣalaye pe awọn ẹgbẹ agbabọọlu mii fẹ ra oun amọ oun pinnu lati pada si ẹsẹ aarọ ni Southampton. Oríṣun àwòrán, Getty Images Lọdun 2005 ni Walcott bẹrẹ si ni ṣoju Southampton nigba to pe ọmọ ọdun mẹrindinlogun.",6 Ọ̀wàrà 2020 +Ayé má níkà o! Tottenham ya aṣọ iyì mọ́ Manchester United lára nírọ̀lẹ́ ọ̀jọ́ ìsinmi," Oríṣun àwòrán, EPA Ọjọ buruku Eṣu gbomi mu lọjọ isinmi ọjọ kẹrin oṣu kẹwaa ọdun 2020 jẹ fun ẹgbẹ agbabọọlu Manchester United. Ijamba ṣe Man United nile wọn lẹyin ti Tottenham wọ wọn ni aṣọ ẹtẹ pẹlu ami ayo mẹfa si ẹyọkan. Egungun to kọkọ jo iran ni yoo wo gbẹyin ni Tottenham fi ṣe fún Man United lẹyin ti Bruno Fernandez gba goolu akọkọ ninu ifẹsẹwọnsẹ ọhun ṣawọn. Góòlu mẹfa ọtọtọ ni United fi gba pada lọwọ Tottenham. Eyi ni igba keji ti Man United yoo fidi rẹmi ni papa isere Old Trafford ni saa bọọlu tuntun yii. Crystal Palace lo kọkọ lu wọn lalubolẹ mọle tẹlẹ.",4 Ọ̀wàrà 2020 +Dákúdájí Chelsea bínú já òrùlé Stamford Bridge lé Crystal Palace lórí," Oríṣun àwòrán, Getty Images Akọnimọọgba ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea, Frank Lampard ti fi idunnu rẹ han pẹlu bi wọn ṣe na Crystal Palace lalubami pẹlu ami ayo mẹrin si odo. Lampard ni aṣeyọri awọn ko ṣẹyin agbabọọlu tuntun, Ben Chilwell ti wọn ra fun miliọnu marundinlaadọta pọun. Chilwell to jẹ ẹni ọdun mẹtalelogun lo gba bọọlu wọ inu awọn, nigba ti Zouma ṣe iranwọ fun goolu keji, Jorginho gba penariti wọ inu awọn ni igba kẹta ati ikẹrin. Amọ, Frank Lampard ti rọ awọn agbabọọlu rẹ lati farabalẹ nitori ere ṣẹṣẹ bẹrẹ ni. Laipẹ yii ni Liverpool lu Chelsea ni alubami, ko to di wi pe wọn gberasọ pada. Bakan naa naa ni Everton naa Brighton ni ami ayo mẹrin si meji , nibi ti Rodriguez ti gba ami ayo meji wọ ni awọn, ti CalverLewin ati Mina naa gba bọọlu wọ inu awọn.",3 Ọ̀wàrà 2020 +"Nínú akànṣẹ́ mẹ́ta ọmọ Nàìjíríà tó dáńtọ́ lágbàáyé, Yorùbá méjì wà nínu wọn"," Oríṣun àwòrán, Instagram Bi ọmọ ẹni ba daa, ẹ jẹ ki a wi, kii se pe a kuku fẹ fi ṣe aya ni. Awọn ọmọ Naijiria to n ṣe bẹbẹ lagbo eṣẹ kikan lagbaaye lo bi ọrọ yii. Mẹta ni wọn, awọn naa si ni, Anthony Joshua, Israel Adesanya ati Kamaru Usman. Lootọọ oke okun ni awọn mẹtẹẹta fi ṣe ibugbe, amọ ko si ẹni to gbagbe orilẹede Naijiria gẹgẹ bi orirun wọn, ninu awọn mẹtẹẹta. Ẹ jẹ ki a wo bẹbẹ tawọn ọmọluabi mẹtẹẹta ọmọ Naijiria yii ṣe lagbaaye: Israel Adesanya - Igba ogun lo ti figa gbaga, ti ko si fidi rẹ́mi ninu ikankan Oríṣun àwòrán, Getty Images Ko si ẹni to le kọ iyan Israel Adesanya kere lagbo ẹṣẹ kikan ti UFC, ti wọn tun maa n pe ni MMA. Ilu Auckland lorilẹede New Zealand lo fi ṣe ibugbe, amọ ilu Eko ni wọn bi Israel si lọjọ kejilelogun oṣu keje ọdun 1989. Igba ogun ni Adesanya ti fija pẹẹta pẹlu oriṣiiriṣii awọn alatako, ṣugbọn gbogbo wọn lo la lalubolẹ bi ilu bẹmbẹ. Koda, o tun ṣẹṣẹ fakọyọ ninu ija to ja kẹyin ni, nibi to ti ṣe Paulo Costa bi ọsẹ ti n ṣe oju, ninu ija to waye niluu Abu Dhabi lorilẹede UAE laarọ lọjọ Aiku. Yemen Water Child: Ọmọdé 44 ni Sọ́jà pa, tí 100 míì sì kú látọwọ́ ohun ìjà olóró Ipele keje ni wọn ṣẹṣẹ de nigba ti Israel ti lu Costa, ti ori rẹ si bẹjẹ eyi to mu ki alakoso ija gbọwọ rẹ soke pe, o ti jawe olubori. Lọwọ yii, Israel ni igbanu ''UFC Middleweight'' wa lọwọ rẹ lagbaaye. Kamaru Usman - Ninu ija mẹtadinlogun, o fidi rẹmi ninu ẹyọ kan Oríṣun àwòrán, Instagram/kamaru Usman Kamaru Usman naa, tii ṣe ọmọbibi orilẹede Naijiria, jẹ akọni abẹṣẹ ku bi ojo lagbo ija MMA. Orilẹede Amẹrika lo fi ṣe ibugbe, amọ ilu Auchi nipinlẹ Edo ni wọn ti bi Usman, lọjọ kọkanla oṣu karun un ọdun 1987. Igba mejidinlogun ni Usman ti ja, mẹtadinlogun lo ti jawe olubori, ti o si fidi rẹmi ninu ọkan ṣoṣo ninu wọn. SS3 ní mo wà báyìí, mo sì ti gba àmì ẹ̀yẹ̀ púpò nílé-lóko gẹ́gẹ́ bí onílù - Ayansike Ọjọ kejila oṣu keje ọdun 2020 ni ija to kopa ninu rẹ kẹyin waye, ninu eyi to ti lu Jorge Masvidal niluu Abu Dhabi. Usman ni igbanu ''UFC Welterweight'' wa lọwọ rẹ bayii. Oríṣun àwòrán, Instagram/anthonyjoshua Ti a ba n sọrọ awọn afi ẹṣẹ ku bi ojo lagbaaye, ọrọ ko tii tan ti a ko ba darukọ Anthony Oluwafemi Joshua. Niluu Watford lorilẹede England, ni wọn ti bi Joshua lọjọ kẹẹdogun oṣu kẹwaa ọdun 1989, amọ bi iṣu lo maa jẹ orilẹede Naijiria lẹnu. Koda, o ti figba kan gbe ilu Eko ri nigba to n dagba. Joshua ti gba oriṣiiriṣii ami ẹyẹ ninu ẹṣẹ kikan lagbaaye, to fi mọ ami ẹyẹ wura ninu idije ''Olympics'' ọdun 2012. Bolaji Faleke ni Olùkọ́ tó ń kọ́ wa ní àṣà oge ṣiṣe lórí BBC Yorùbá Joshua ti fẹṣẹ yanju awọn ilumọọka akanṣẹ bi Wladimir Klitschko, Charles Martin, Joseph Parker, Alexander Povetkin ati Andy Ruiz Jr. Igbanu mẹta lẹka ẹṣẹ kikan to lami laaka lo wa lo lọwọ AJ nikan. Oun ni igbanu IBF, IBO, WBA ati WBO ''heavyweight'' wa lọwọ rẹ bayii. Káre akọni ọmọ Yoruba! Israel Adesanya fi ẹ̀ṣẹ́ fọ́ Paulo Costa lójú 'Misita Alagidi, emi leleyi!' ni gbolohun ti Israel Adesanya fi da awọn alatako rẹ lohun lẹyin to da bantẹ iya fun Paulo Costa ninu ija wọn to waye ni Dubai. Isọri keji ija naa ni Adesanyta ti rọjo ẹsẹ lu Costa ti adari ija naa si bọ si aarin wọn lati pari rẹ ni kiakia. Ni bayi, Adesanya ṣi ni o jẹ olubori Middle Weight Champion of the World. Loju opo Twitter awọn ọmọ Naijiria to fi mọ Minisita feto ọdọ ati idaraya Sunday Dare ti n ki ku orire ija naa Oríṣun àwòrán, Getty Images Ọjọ nii pẹ, ipade kii jian. Ọjọ Aiku tii ṣe ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu kẹsan an ọdun 2020 ni ajijakandi ọmọbibi orilẹede Naijiria to jẹ aṣaaju ninu ija UFC, Israel Adesanya to yoo koju Paulo Costa ọmọ ilẹ Brazil. Faabada! Ẹyin ologinni ko gbọdọ balẹ. Adesanya ko ti fidi rẹmi ri lati igba to ti di agbaọjẹ lagbo UFC. Ija MMA mọkandinlogun ni Adesanya ti kopa ninu rẹ ti o si jawe olubori ninu gbogbo wọn, nigba ti alako rẹ, Costa ko tii fidi rẹmi ninu ija MMA mẹtala to ti ja. Ilu Abu Dhabi, United Arab Emirates lawọn mejeeji yoo ti waako lọjọ Aiku. Nigba ti wọn n tahun si ara ṣaaju ija ọjọ Aiku, Costa oun yoo gbe Israel tọrọ ba doju rẹ tan nitori ko lara. Amọ ile lo kuku ba Adesanya naa, oun naa sọ pe oorun ti ko si Costa loju ohun lo si n ṣakoba fun un. Adesanya ni ti oun ba le ki Costa lọrun mọlẹ pẹrẹ, o ni ọrun naa ko tun jẹ tirẹ mọ. Israel sọ pe o ṣe oun bi ki ija naa ti bẹrẹ nitori oun ko le duro mọ lati da ẹṣẹ bo Costa lori. Igba mẹrinla ni Adesanya ti lu alatako rẹ lalubami ti wọn maa n pe ni TKO ninu ija mọkandinlogun to ti ja. SS3 ní mo wà báyìí, mo sì ti gba àmì ẹ̀yẹ̀ púpò nílé-lóko gẹ́gẹ́ bí onílù - Ayansike",26 Owewe 2020 +"Alámì ẹ̀yẹ Scrabble Paul Sodje àti ọ̀rẹ́ rẹ́ kú lásìkò tó fẹ́ lọ́ sanwó ìdóòlà ẹ̀mí àbúrò rẹ̀, tí afurasí darandaran jí gbé"," Oríṣun àwòrán, Others Adari ikọ ere idaraya Scrabble ni Naijiria tẹlẹri, Paul Sodje ti ku lẹyin ti awọn afurasi darandaran ji gbe. Agbẹnusọ fun ẹgbẹ Nigerian Scrabble Federation, Akintunde Akinsemola, to fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ fun BBC Yoruba ni, wọn ri oku rẹ ni agbegbe Idoani ni ijọba ibilẹ Ọṣẹ nipinlẹ Ondo. Akinṣemọla ni ọjọru to jẹ Ọjọ Kẹsan, Oṣu Kẹsan, ọdun 2020 ni o yẹ ki Paul Sodje pe ẹni ọdun marundinlọgọta. Awọn ikọ Nigerian Scrabble Federation naa pejọ pọ lati ranti ọ̀jọ ibi rẹ lori ẹrọ ayelujara ni ọjọ naa. Paul Sodje lo dari ikọ Naijiria lọ si idije Alawọ dudu ilẹ Afrika to waye ni orilẹede Zambia ni ọdun 2012. Nigba to n salaye bi iṣẹlẹ naa ṣe bẹrẹ ni bi ọsẹ meji sẹyin, Akinsemola ni lasiko ti wọn fẹ lọ sin mọlẹbi rẹ to ku ni ipinlẹ Delta, ni wahala naa bẹrẹ. Mayowa Omoniyi: Kò sí orin Obey, Sunny Ade abí tàkasúfèé tí ń kò le ta gìtá sí '' Ibi isinku mọlẹbi rẹ, ni wọn wa ti wọn ti gba ipe wi pe Chris, tii se aburo Paul Sodje, wa ni panpẹ awọn ajinigbe, ti wọn si ni ki wọn mu ọgọrun miliọnu wa lati tu silẹ.'' ''Awọn ẹbi ati iyawo Chris Sodje bẹ awọn agbebọn naa lati jọwọ gba miliọnu kan Naira, ti awọn ni agbara lati san.'' ''Alami ẹyẹ Scrabble ni Naijiria naa wa gbera pẹlu ọrẹ rẹ, lati lọ san owo ẹmi ti awọn ajinigbe naa beere fun ni agbegbe ti wọn ti ji gbe.'' Alaga ẹgbẹ Nigerian Scrabble Federation ni, lati igba ti wọn ti lọ san owo ẹmi naa ni wọn ko ti gburo Paul Sodje, Chris Sodje ati ọrẹ rẹ to tẹle Paul, lati lọ san owo fun awọn ajinigbe naa. Baby abandoned on dunmpsite: Mo ti bímọ mẹ́rin tẹ́lẹ̀ fún bàbá méjì nínú òṣí- Dupe Ogbomos Akinsemola ni titi di asiko yii, ko si ẹni to le e sọ pato ohun to ṣẹlẹ laarin awọn ajinigbe naa ati awọn ti wọn lọ san owo naa. O fikun pe, ni ọjọ diẹ lẹyin iṣẹlẹ yii ni awọn darandaran naa tun ṣẹ ikọlu si Idoani, nibi ti wọn ti gbe Adari ileewosan ijọba nibẹ pẹlu awọn eniyan miran lagbegbe naa. ''Lasiko ti wọn n wa awọn eniyan ti awọn darandaran naa jigbe lọ si ileewosan to wa ni ilu Ọwọ, ni wọn ri oku Paul Sodje ati ọrẹ rẹ ni ile igbokusi to wa ni Ọwọ.'' Awọn adari ni ilu Idoani ti Otunba Oladele Olapeju ṣe adari fun ni, wọn ri oku Paul Sodje ati ọrẹ rẹ ni ilu Ajagbale, ti ko jina si ilu Ifọn.'' Oríṣun àwòrán, Others ''Awọn lo gbe e oku rẹ lọ si ileewosan ijọba apapọ to wa ni ilu ọwọ titi di asiko yii.'' Nibayii, inu ibanujẹ ni ẹbi ati ara Paul Sodje wa lọwọlọwọ, paapaa iyawo Chris Sodje, Flora, ti ko tilẹ mọ boya ọkọ rẹ wa laye abi o ti ku. Flora, lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ ni oun ti sa gbogbo ipa oun lati wa ibi ti ọkọ rẹ wa, ti o si fi to gbogbo awọn ẹsọ alaabo to wa ni Naijiria leti. O ni lati igba ti wọn ti lọ fun awọn ajinigbe naa ni owo, ni awọn darandaran naa ti kọ lati ba awọn sọrọ mọ, ti awọn ko si gburo Chris Sodje to jẹ ẹni ọdun mọkanlelogoji titi di asiko yii. Gbogbo igbiyanju BBC Yoruba lati ba ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ondo sọrọ lori isẹlẹ yii, si lo ja si pabo.",10 Owewe 2020 +Mo ṣetán láti fi ẹ̀ṣẹ́ dín dòdò ìyà fún Anthony Joshua- Efe Ajagba," Oríṣun àwòrán, Instagram Yoruba bọ, wọn ni o di oni karangida, adiẹ n jẹ ifun ara wọn. Bayii lọrọ ri abẹṣẹ ku bi ojo ọmọ Naijiria, Efe Ajagba to ni oun ṣetan lati fi ẹṣẹ din dodo iya fun ogbontarigi akẹṣẹ Anthony Joshua. Ilẹ Amẹrika ni Ajagba to ti ṣoju orilẹede Naijiria ri ninu idije ''Olympics'' fi ṣe ibugbe bayii lẹyin to ti wa niluu Eko fun ọpọlọpọ ọdun. Ọrọ naa da bi ẹni to maa ku pade ẹni to maa pa, nirori Joshua gan an funra rẹ ti sọ tẹlẹ pe o wu oun lati fija pẹta pẹlu akẹṣẹ to jẹ ọmọbibi ilẹ Afirika bi t'oun naa. Ajagba tiẹ ti bẹrẹ si ni sọ ọna ti o fi le fẹyin AJ gbalẹ ti wọn ba koju ara wọn. Ajagba sọ fawọn akọroyin pe ko ba wu oun ki Joshua gba lati ba oun ja lorilẹede Naijiria tawọn mejeeji ti wa. Abẹsẹ ku bi ojo ọmọ Naijiria ṣalaye pe lootọọ ni pe Joshua lagbara, amọ ọgban inu loun maa fi ṣẹ AJ leegun ẹyin tawọn koju ara awọn. O ni ati oun ati Joshua lawọn jọ lagbara ṣugbọn o ni ọgbọn ju ọgbọn lọ. Ajagba ni otitọ ni pe Joshua ti gba ami ẹyẹ goolu ninu idije ''Olympics'' ri, oun si tun ni abẹṣẹ ku bi ojo to lami lahaka taye ti aye n fẹ lọwọ bayii. Oun oun naa gboṣuba fun AJ fun awọn aṣeyọri rẹ lagbo ẹṣẹ kikan, amọ oun mọ awọn ibi ti Joshua ku si ninu ẹṣẹ kikan. Joshua gba awọn igbanu rẹ mẹtẹẹta, IBF, WBA ati WBO pada lọwọ Andy Ruiz Jr pada lẹyin ti Ruiz ti kọkọ lu u bi aṣọ ofi nigba ti wọn kọkọ koju ara wọn. Joshua naa fẹ ṣe bi agbọjẹ ninu ẹṣẹ kikan, oloogbe Muhammad Ali to ba George Foreman ja ni Zaire lọdun 1974. Amọ Ajagba ti kepe Joshua pe ko jẹ ki awọn ṣe ere ọwọ papọ ni Naijiria, o ni ti o ba ti ya eegun Joshua, o ti ya ọlọrẹ t'oun naa.",3 Owewe 2020 +"Awo lọ? Messi ò lè dúró mọ́, aṣojú Manchester City ti balẹ̀ sí Barcelona láti dú ìná dúrà"," Oríṣun àwòrán, Getty Images Bi gbogbo nnkan ti n lọ yii, afaimọ ki agbaọjẹ agbabọọlu Barcelona, Lionel Messi ma fi ikọ agbabọọlu naa silẹ ni kopẹ kopẹ. Ileeṣẹ redio kan, Cadena Ser lorilẹede Spain ti sọ pe adehun ọdun meji ni Manchester City fẹ ṣe pẹlu Messi ti wọn ba ti ra a tan lati Barcelona. Oludari kata-kara awọn agbabọọlu ni Barcelona, Txiki Begiristain ti de si ilu Barcelona lati duna dura lori ati ra Messi lọ si Man City. Bakan naa ni a gbọ pe baba Messi, Jorge yoo ṣe ipade pẹlu awọn alaṣẹ Barcelona lọsẹ yii lati sọrọ lori bi Messi yoo ti fi ẹgbẹ agbabọọlu silẹ. Ọpọ lo gbagbọ pe Messi lo le ran Man City lọwọ lati gba ife ẹyẹ UEFA Champions League eyi ti wọn ko tii gba ri ninu itan wọn. Oríṣun àwòrán, Getty Images Messi kọ lati ṣe ayẹwo coronavirus lọsẹ to kọja lẹyin ti Barca ni ki gbogbo agbabọọlu lọ fun ayẹwo ki wọn le bẹrẹ igbaradi fun saa bọọlu tuntun. Koda akọnimọọgba tuntun Ronald Koeman ti ṣe igbaradi akọkọ pẹlu awọn agbabọọlu Barca ṣugbọn Messi ko si nibẹ. Ẹwẹ, oludije fun ipo aarẹ ẹgbẹ agbabọọlu Barcelona, Toni Freixa ti sọ pe ko si ṣiṣe ko si aiṣe, Messi o le duro mọ ni Barca. Freixa ni ko si iru adehun ti Barcelona le fẹ fun Messi to le mu duro si Barcelona, o ni aṣọ ko ba ọmọyẹ Messi mọ. Freixa ni ''ọdun 2015 ti Barcelona ti gba ife ẹyẹ Champions League kẹyin, eyi si lo n kọ Messi lominu nitori o tun fẹ gbade Champions League sii.'' Oludije fun ipo aarẹ ẹgbẹ Barcelona sọ pe o ti han gbangba bayii pe Messi fẹ lọ ba akọnimọọgba rẹ tẹlẹ, Pep Guardiola ni Man City. Níbo ni Messi fẹ́ mórí lé báyìí lẹ́yìn tó jáwée ó tó gẹ́ fún Barcelona? Ko si ohun to ni ibẹrẹ ti ko l'opin, lo difa fun gudugbẹ to ja lọjọ Iṣẹgun nigba ti iroyin jade pe elegee ara, Lionel Messi ti kọwe si ẹgbẹ agbabọọlu Barcelona pe oun ṣetan lati dagbere fun ẹgbẹ agbabọọlu naa pe o digba o ṣe. Ipinnu Messi ko ṣẹyin rukerudo to n ṣẹlẹ lọwọ ni Barcelona papaajulọ lati igba ti Bayern Munich ti lu wọn laluki pẹlu ami ayo mẹjọ si meji ninu idije UEFA Champions League. Iṣẹ ti bọ lọwọ akọnimọọgba Quique Setien lẹyin abuku nla naa, koda wọn ti le Eric Abidal naa to n ri sí katakara ati pasiparọ awọn agbabọọlu fun Barca lọ. Lẹyin ti Ronald Koeman di akọnimọọgba tuntun fun Barcelona, ẹgbẹ agbabọọlu naa ti bẹrẹ awọn atunto kan lati tẹ ikọ naa siwaju. Oríṣun àwòrán, Getty Images Lara awọn awọn igbesẹ ọhun ni pe ẹlẹsẹ ayo Luis Suarez at'awọn mii yoo ni lati fi ẹgbẹ agbabọọlu naa silẹ. Lẹyin naa ni Messi sọ fun Barca pe asiko ti to lati fi ikọ Barca silẹ. Awọn ẹgbẹ agbabọọlu bii Manchester City, Manchester United, PSG ati Inter Milan lawọn kan n sọ pe o ṣeeṣe ki Messi mori le. Iroyin kan tiẹ sọ pe Messi ti kan si akọnimọọgba rẹ tẹle, Pep Guardiola to wa ni Man City bayii. Ohun to wa ninu adehun ti Messi ṣe pẹlu Barca ni pe oun le fi ẹgbẹ agbabọọlu naa silẹ lọfẹẹ, ṣugbọn Barca ni o gbọdọ jẹ ipari oṣu karun ti saa bọọlu yoo pari. Awọn alaṣẹ Barcelona ni Messi ko le lọ bayii nitori oṣu karun ti kọja, amọ Messi ni ajakalẹ arun coronavirus ni ko jẹki oun sọrọ lati igba yii wa. 'ìjà ṣẹlẹ̀ láàrín èmi àti ọ̀gá mi ní Lebanon tórí mi ò lè dá N300K padà'",26 Ògún 2020 +Ronald Koeman di akọ́nimọ̀ọ́gbá Barcelona tuntun lẹ́yìn ìjàmbá Champions League," Oríṣun àwòrán, PA Media Omi tuntun ti ru lẹgbẹ agbabọọlu Barcelona, Ronald Koeman ti di akọnimọọgba tuntun ikọ naa. Oun lo rọpo Quique Setien ti wọn ṣẹṣẹ fọwọ osi juwe ile fun un ni kopẹ kopẹ. Koeman ẹni ọdun mẹtadinlọgọta fi iṣẹ rẹ gẹgẹ bi akọnimọọgba ẹgbẹ agbabọọlu orilẹede Netherlands silẹ nibi ti adehun to fọwọ si ti ku ọdun meji lati gba iṣẹ Barcelona. Koeman gbabọọlu fun ikọ Barcelona laarin ọdun 1989 si 1995, o si gba ami ẹyẹ La Liga mẹrin ati ife ẹyẹ kan ni Yuropu. Oríṣun àwòrán, Getty Images Ronald Koeman gbami ẹyẹ Yuropu pẹlu Barca lọdun 1992 Ipo keji ni Barcelona gba ni saa bọọlu to ṣẹṣẹ pari ninu eyi ti wọn ko si ri ife kankan gba fun igba akọkọ lati ọdun 2008. Oríṣun àwòrán, Getty Images Barcelona to yan Ramon Planes gẹgẹ bi oludarieto kata-kara agbọọlu eleyi ti Eric Abidal di mu tẹlẹ ki wọn to ni ko maa lọ lọjọ Iṣẹgun. Akitiyan lati yan akọnimọọgba mii bẹrẹ lẹyin ti Bayern Munich lu Barca lalu bolẹ ninu idije UEFA Champions League pẹlu ami ayo mẹjọ si meji. Ìjàmbá ṣe wá ní Barcelona, aṣọ ò bá Ọmọ́ye wa mọ́- Gerard Pique Paa lẹẹkinni, paa lẹẹkeji, paa lẹẹkẹta, bi oju ọhun ko ba fọ tan, yoo pada di bai bai. Bayii lọrọ ṣe ri fun ẹgbẹ agbabọọlu Barcelona ti Bayern Munich lu lalubami. Ami ayo mẹjọ si meji ni Bayern fi ṣagba Barcelona ninu ifẹsẹwọnsẹ to waye lorilẹede Portugal lalẹ ọjọ Ẹti, ọjọ kẹrinla oṣu kẹjọ ọdun 2020. Ọkan lara awọn gbajugbaja agbabọọlu Barcelona, adilemu, Gerard Pique ke gbajari pe abuku nla kan Barca, o ni omi ti tẹyin wọ igbin lẹnu. Pique ni kii ṣe igba akọkọ, tabi ekeji tabi ẹkẹta ti irufẹ abuku yii yoo kan Barcelona. Adilemu naa sọ pe asiko ti to fun gbogbo agbabọọlu Barcelona lati ati awọn alaṣẹ lati wa nnkan ṣe si ina ẹgbẹ agbbọọlu naa to n jo ajo rẹyin bayii. Amọ akọnimọọgba Barca fun ra rẹ, Quique Setien ni oun ko tii le sọ bo ya oun yoo fi ẹgbẹ agbabọọlu naa silẹ laipẹ. Oríṣun àwòrán, Getty Images O ni otitọ ni pe ijamba ṣe Barca lọwọ Bayern, ṣugbọn ọrọ naa gba ki onikaluluku ronu ọna lati tẹ agbabọọlu Barca siwaju. Ẹwẹ, agbabọọlu Manchester United nigba kan ri, Rio Ferdinand sọ pe asiko ti to fun ẹlẹsẹ ayo Lionel Messi lati ronu lori ibaṣepọ rẹ pẹlu Barcelona. Ferdinand sọ pe pẹlu bi gbogbo nnkan ṣe polukurumusu ni Barcelona bayii, o dabi wi pe asiko ti to fun Lionel Messi lati fi Barca silẹ. Ohun ti Ferdinand n sọ ni pe bi a ba pẹ lori imi, eṣin keṣinṣin lo n ba ni nibẹ.",15 Ògún 2020 +Àwọn afẹ̀hónúhàn bọ́ra sí ìhòhò lórí pápá lòdì sí sísọ eré bọ́ọ̀lù di jẹunjẹun," Awọn eeyan kan lorilẹ-ede Germany ti lọ sori papa ni ihoho ọmọluabi lọna ati ṣefẹhonuhan lodi si sisọ ere bọọlu di jẹunjẹun. Ifẹhonuhan naa lo waye nipasẹ ifẹsẹwọnsẹ kan ti ayaworan Gerrit Starczewski gbe kalẹ ni papa iṣere Stimberg ni Ruhr. Awọn eeyan naa lọ sori papa lai wọ aṣọ kankan, yatọ si ibọsẹ ati bata ti wọn fi n gba bọọlu, bẹẹ ni wọn tun kọ nọmba agbabọọlu si ẹyin wọn. Starczewski ni igbesẹ naa waye lọna ati fi ẹhonu han lodi si ohun ti wọn sọ ere bọọlu da laye ode oni pẹlu ihoho awọn eeyan naa. O ni ""Ere bọọlu ti da idakuda laye ode oni, idi niyii ti a fi wa ni ihoho."" Blind DJ: Etu Omotayo kò ríran àmọ́ ó le to irinṣẹ́ eléré pọ̀ láti kọrin láì sí ìrànwọ́",17 Ògún 2020 +Wọ́n ti sún ọjọ́ ìjà Mike Tyson pẹ̀lú Roy Jones Jr síwájú," Oríṣun àwòrán, Instagram/miketyson Ija laarin abẹṣẹ ku bi ojo to ti fẹyin ti, Mike Tyson ati Roy Jones ti di siso rọ bayii. Ọjọ kẹjọ, oṣu kẹsan an, ọdun 2020 yii lo yẹ ki ija naa waye tẹlẹ, ṣugbọn ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu kọkanla ni ija ọhun yoo waye bayii. Ileeṣẹ The Ring sọ ninu iroyin kan to gbe jade pe awọn onigbọwọ sun ija naa siwaju lati le fi ija naa pa owo daadaa. Igba akọkọ ree ti gbajugbaja abẹṣẹ ku bi ojo, Tyson yoo maa lewọ ninu ẹṣẹ kikan lẹyin to ti fẹyinti ni bii ọdun mẹẹdogun sẹyin. Ni Carson ni California ni ija naa yoo ti ṣẹlẹ. Adari ajọ to n ri si ere idaraya nipinlẹ California, Andy Foster ti sọ tẹlẹ pe ija laarin Tyson ẹni ọdun mẹtalalaadọta ati Jones, ẹni ọdun mọkanlelaadọta da bii eremọde tabi igbaradi fun ija. Ṣugbọn Jones sọ pe oun ṣetan lati na tan bi powo pelu Tyson nitori oun ko wo ija gẹgẹ bi eremọde rara. Ọdun 2005 ni Tyson ja kẹyin nigba ti Kevin McBride lu u lalubami. Oríṣun àwòrán, Instagram/miketyson Ọdun 2018 ni alatako rẹ, Jones kẹyin, oun lo si bori alatako rẹ, Scott Sigmon lọdun naa. BBC Africa Eye: ìwádìí ìkọ̀ks BBC fihàn pé àwọn kan ń jí ohun èèlò ìdáàbòbò ìjọba tà nígbo",10 Ògún 2020 +Lampard laná! Arsenal fa Chelsea ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ gba ife FA Cup," Oríṣun àwòrán, @Arsenal/twitter Ami ayo meji si odo ni ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal fi ja ife idije FA Cup mọ Chelsea lọwọ. Nkan gbona janjan bi amala gbigbona lasiko ti ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea ati Arsenal koju ara wọn ni aṣekagba idije FA Cup. Papa iṣere Wembley to jẹ ti Chelsea ni idije na ti waye. Nigba ti yoo fi di ọgbọn iṣẹju ti idije naa bẹrẹ, Chelsea ati Arsenal ti ku eruku ami ayo kọọkan si ara wọn l'oju. Mama Arsenal: Màmá àgbà yìí máa ń lọ sí ìbùdó tí wọ́n ti ń wo bọ́ọ́lù láti wòran Ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea lo kọkọ gba bọọlu wọle, lati ọwọ ọmọ ilẹ America, Christian Pulisic. Oun si ni ọmọ ilẹ America akọkọ to gba bọọlu sinu àwọn ni aṣekagba idije FA Cup. Ṣugbọn Cesar Azpilicueta ṣe aṣiṣe, eyi to mu ki Arsenal o gba pẹnariti. Pierre-Emerick Aubameyang lo gba bọọlu wọle fun Arsenal, niṣe lo fi bọọlu ju goli si ibi ti ẹgbẹ kan. Oun naa lo si tun gba bọọlu keji wọle fun wọn ni abala keji ifẹsẹwọnsẹ naa. Chelsea ti kọkọ gba kaadi yẹlo ni abala akọkọ, ti wọn si tun gba omiran laipẹ ti abala keji bẹrẹ. Ni bayii, ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal ti yege lati kopa ni idije Europa.",1 Ògún 2020 +Ọmọ Nàìjíríà di agbábọ́ọ̀lù Áfíríkà tí iye owó tí wọ́n rà à ga jù nínú ìtàn!," Oríṣun àwòrán, @ZachLowy Ẹgbẹ agbabọọlu Napoli ti tọwọ bọ iwe adehun lati ra ọmọ Naijiria to n gba bọọlu fun ikọ Lille, Victor Osimhen. Gẹgẹ bi iroyin ti ileeṣẹ L'Equipe gbe jade, iye owo ti wọn ra agbabọọlu naa lati ilẹ France lọ si iha 'Italian Serie A' le ni miliọnu mọkanlelọgọrin pọun. Eyii to n tumọ si pe Victor ni agbabọọlu lati ilẹ Afrika ti iye owo ti wọn ra a pọ julọ. Iye owo ti Napoli san lori Osimhen pọ ju iye owo ti Arsenal san fun Lille lati ra ọmọ orilẹ-ede Ivory Coast, Nicolas Pepe ni nkan bii ọdun kan sẹyin. Lẹyin ti ẹgbẹ agbabọọlu Lille ta Pepe ni Osimhen darapọ mọ ikọ ọhun lati ikọ Charleroi, to wa lorilẹ-ede Belgium. Oríṣun àwòrán, @BBCSport Lẹyin to sọ goolu mejidinlogun ṣawọn fu ikọ Lille ni saa to kọja ni oju ti wa lara rẹ pe o ṣeeṣe ko tẹkọ leti lọ si Napoli laipẹ. Lẹyin ti idunadura naa pari ni Osimhen sọ loju opo Twitter rẹ pe inu oun dun lati darapọ mọ Napoli, koda o ni niṣe lo dabi pe ki oun ti wa lori papa. Justice for Richard: Òbí àkẹ́kọ̀ọ́ tó kú síléeṣẹ́ ọṣẹ ń bèèrè fún ìdájọ́ lórí ikú ọmọ wọn",31 Agẹmo 2020 +"Mama Arsenal ṣeé débi èrè, ẹgbẹ́ kan ti fún màmá l'ẹ̀bùn owó"," Bi a ba ku, iṣe o tan ni Yoruba maa n wi. Bẹẹ gẹlẹ ni ọrọ ri pẹlu mama agba ololufẹ ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal, Nosimatu Hassan. Mama to jẹ ẹni ọdun mẹtadinlọgọrin di ẹni ti ọgọọrọ eeyan n sọ nipa rẹ lori ayelujara lẹyin ti sọ ọpọ ọrọ nipa ẹgbẹ agbabọọlu to yan laayo. Lati igba naa ọpọ ẹlẹyinju aanu ọmọ Naijiria ti n ṣeleri lati fun mama ni ẹbun kan tabi omiiran. Ṣugbọn ni bayii, ẹgbẹ ololufẹ awọn ikọ agbabọọlu Naijiria, Authentic Nigeria Supporters' Club ti fun mama ni ẹbun owo rọgun rọgun. Oríṣun àwòrán, Facebook/ANFASC Owo ti ẹgbẹ ololufẹ agbabọọlu Naijiria naa fun mama Arsenal ni ṣe ẹgbẹrun un lọna ọta le lugba o din mẹwaa. Ọlọ́run ló yàn mí ti Arsenal, mi ò lè fi wọ́n sílẹ̀ láéláé- Mama Arsenal yarí Ara meriri , mo ri ori ologbo lori atẹ ni ọrọ mama agba kan, Nosimatu Hazzan, ti ọpọ eeyan mọ si mama Arsenal. Mama agba yii, to nifẹ ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal bii oju, ti ọjọ ori rẹ yoo si to aadọrin ọdun, lo nifẹ ere bọọlu ju ọmọde tabi awọn ọkunrin miran lọ. Lasiko ti BBC se abẹwo si ọdọ mama naa, ti ọpọ eeyan mọ si Mama Arsenal nitori bo se nifẹ si ẹgbẹ agbabọslu Arsenal, ẹnu ko gba iroyin. Ko fẹẹ si agbabọọlu Arsenal tẹlẹ abi lọwọlọwọ bayii ti mama naa ko lee darukọ, to si ni oun maa n wo bọọlu ninu ile oun tabi lọ sawọn ibudo ti wọn ti n wo bọọlu. Bakan naa lo ni oun maa n lọ sawọn papa isere idaraya nilu Eko lati wo ere bọọlu, ti oun si nifẹ ere sisa, awọn ere idaraya miran lorisirisi, paapaa ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal.",6 Agẹmo 2020 +"Real Madrid gbadé ògo La Liga, Messi ní Barcelona ò lè ta pútú mọ́"," Oríṣun àwòrán, Getty Images Nibi ti ẹlẹkun ti n sunkun lalayọ ti n yọ. Bayii lọrọ ri pẹlu ẹgbẹ agbabọọlu Real Madrid ati Barcelona. Bi idunnu ti ṣubu layọ fun Madrid lẹyin ti wọn fagba han Villareal eyi to mu wọn gba ife ẹyẹ La Liga fun igba kẹrinlelọgbọn, nnkan ko ṣẹnu ire fun Barca ni ti wọn. Ẹgbẹ agbabọọlu Osasuna to bawọn lalejo lo dẹru iya le wọn lori eleyi lo mu Lionel Messi koro oju ti o si fi ibinu sọrọ. Messi ti juwe ẹgbẹ agbabọọlu Barcelona gẹgẹ bi ikọ ti ko lagbara lẹyin ti ikọ Osasuna gbo ewuro si wọn loju pẹlu ami ayo meji si ọkan ni Nou Camp. Ibanujẹ dori agba Messi kodo lẹyin ti ijakulẹ Barcelona pẹlu Osasuna gba ife ẹyẹ La Liga mọ Barcelona lọwọ lalẹ Ọjọbọ. Ajẹkun iya ti Barcelona jẹ lọwọ Osasuna yii n tumọ si pe ẹgbẹ agbabọọlu Real Madrid ni yoo gba ife ẹyẹ naa lai wo ohun ti ifẹsẹwọnsẹ rẹ pẹlu Villarreal yoo ba jade. Mama Arsenal: Màmá àgbà yìí máa ń lọ sí ìbùdó tí wọ́n ti ń wo bọ́ọ́lù láti wòran Nigba to n ba ileeṣẹ iroyin Spanish TV sọrọ lẹyin ifẹṣwọnsẹ ọhun, Messi sọ pe ""Esi ti a ri kọ la lero pe a o ri, ẹgbẹ agbabọọlu wa ko lagbara to."" O tẹsiwaju pe ""Awa gangan ni wọn n pe ni Barcelona, o si yẹ ki a maa bori ninu gbogbo ifẹsẹwọnsẹ wa ni, ṣugbọn bẹẹ kọ lọrọ ri bayii."" Oríṣun àwòrán, Getty Images José Arnaiz Diaz lo kọkọ sọ bọọlu sinu awọn Barcelona lẹyin iṣeju marundinlogun ti ifẹsẹwọnsẹ naa bẹrẹ, ṣugbọn Messi da pada ni abala keji ifẹsẹwọnsẹ ọhun. Laarin iṣẹju diẹ ti ifẹsẹwọnsẹ naa yoo pari ni Roberto Torres tun ri ẹyin awọn Barcelona nigba kan sii, eyi to mu ki goolu Osasuna di meji. Oṣu Kẹfa ọdun 2020 ni idije La Liga gberasọ pada lẹyin ti wọn ti kọkọ da a duro nitori ajakalẹ arun Covid-19.",17 Agẹmo 2020 +"Ó fipá bámi lòpọ̀, ó lù mí, ó tún gba gbogbo owó mi- Funke Oshonaike"," Oríṣun àwòrán, Facebook/Funke Oshonaike ''Ni gbogbo igba ti mo ba ti gbọ iroyin nipa ifipabanilopọ, o maa n mu mi ranti ohun to ṣẹlẹ si mi sẹyin ni. 'Wọn fipa bami lopọ, wọn si tun huwa ipa si mi, ọrọ igbe aye mi ree.'' Gbajugbaja agbabọọlu tẹniisi ori tabili to jẹ ọmọ Naijiria, Funke Oshonaike lo si aṣọ loju eegun ọrọ ri. Orilẹede Naijiria ti bẹrẹ si ni wa ọna lati dẹkun iwa ifipabanilopọ to ti gogo bayii lawujọ, Funke wa lara awọn ilumọọka ọmọ Naijiria to n sọ iriri wọn lori ifipabanilopọ fun igba akọkọ. Funke to ti ṣoju orilẹede Naijiria ninu idije ''Olympics'' ni igba mẹfa ọtọtọ pinnu lati sọ iriri rẹ lẹyin ti awọn kan fipa ba ọdọbinrin ọmọ ọdun mejilelogun, Uwa Omozua lopọ ti wọn si tun pa a niluu Benin. Ihoho ni wọn ba oku Uwa ninu ile ijọsin kan ni Benin eyi to mu ki ọpọ bẹrẹ si ni ṣe iwọde kaakiri Naijiria. Oshonaike ṣalaye pe bi wọn ti fipa ba Omozua lopọ ran ohun leti bi ọkunrin kan to fi ọdun mẹwaa ju oun lọ ṣe fipa ba oun lopọ nigba t'oun wa lọmọ ọdun mọkandinlogun. ''Ọkunrin naa da bi ọrẹ si mi, o lu mi, o si fi ika atanpako rẹ meji bọ mi loju, lẹyin naa lo fipa bami lopọ ti ẹjẹ si bo mi. Ko si ẹni to le ran mi lọwọ, mi o tiẹ mọ orukọ ti wọn n pe iru nnkan bayẹn,'' Oshonaike lo sọ bẹẹ. Oríṣun àwòrán, Funke Oshonaike Ni ọmọ ọdun mẹrinla ni Oshonaike ti bẹrẹ si ni gba tẹniisi ori tabili, lẹyin ọdun meji si igba naa ni o lọ ṣoju Naijiria ninu idije All Africa Games lọdun 1991. Ṣugbọn Atlanta 1996 ni o ti ṣoju Naijiria ninu idije ''Olympics'' fun igba akọkọ- nigba naa gan ni ọkunrin yii bẹrẹ si ni huwa ipa si i. Ọkunrin naa ko laya jẹ debi pe oun lo n ṣakoṣo owo rẹ ati ohun gbogbo to ni, bẹẹ si ni ko le yi ẹnu pada. ''O maa n lu mu lalubami nigba kuu gba ti o ba beere owo mi wi pe mo fẹ fi i silẹ,'' Oshonaike lo sọ bẹẹ. Oríṣun àwòrán, Getty Images Funkẹ ni oun ''padanu gbogbo ohun ini oun si ọwọ ọkunrin yii ṣugbọn mo pinnu lati tẹsiwaju pẹlu gbigba tẹniisi ori tabili.'' Oshonaike sọ pe ''iriri naa ṣakoba fun igbeyawo mi, o si pami lara nipa nini ibalopọ, ṣugbọn mo ti n bori rẹ diẹdiẹ bayii.'' Oríṣun àwòrán, Facebook/Funke Oshinaike Amọ Funke Oshonaike sọ pe iriri naa ko buru jai ni tootọọ ṣugbọn o ti ran oun lọwọ lati gba ọpọ obinrin ti wọn n la iru rẹ kọja niyanju. O rọ awọn obinrin ti wọn ti ni iru iriri bayii lati sọ sita ki awọn eeyan mii le kọgbọn lara wọn.",14 Agẹmo 2020 +Ayé le! Sheffield faṣọ iyì ya mọ́ Chelsea lára lọ́nà ìrìnàjò sí Champions League," Oríṣun àwòrán, Getty Images Aye ma le o, ẹgbẹ agbabọọlu Sheffield United fi oju Chelsea ri mọ bo lọjọ Satide ninu idije Premier League. Afi bi awada bi ere ni ifẹsẹwọnsẹ naa bẹrẹ ti Sheffield ba gbayo akọkọ wọle Chelsea. Kẹrẹkẹrẹ ti ere bọọlu naa n tẹsiwaju ni Sheffield ba tun fọba lee lẹyin ti wọn gbayo ẹlẹẹkeji sawọn. Aṣe ẹgbẹ agbabọọlu Sheffield n ṣẹṣẹ mu ẹyẹ bọ lapo ni, ni wọn ba tun gbayo kẹta sinu awọn Chelsea. Koda ohun ti a n wi yii kọ ni a o ba maa wi to ba jẹ pe ayo kẹrin ti Sheffield fẹ gba sawọn wọle Chelsea ni. Sheffield ti wa ni ipo kẹfa lori tabili idije Premier League bayii, nigba ti Chelsea si wa ni ipo kẹta.",11 Agẹmo 2020 +Wo agbábọ́ọ̀lù Super Eagles Nàìjíríà àkọ́kọ́ tó lùgbàdì coronavirus," Oríṣun àwòrán, @Paul Paul Onuachu ni agbábọ́ọ̀lù Super Eagles Nàìjíríà àkọ́kọ́ tó lùgbàdì Covid 19 Ẹlẹsẹ ayo, ọmọ Naijiria to n gbabọọbu jẹun fun ìkọ Genk lorilẹ-ede Belgium, Paul Onuachu ti ko aarun coronavirus. Ni Ọjọru ni ayẹwo fihan pe Onuachu nikan lo ni arun covid-19 ninu gbogbo awon agbabọọlu Genk ti wọn ṣe ayẹwo coronavirus. Amọ, ayẹwo naa tun fihan pe awọn akẹgbẹ rẹ ọmọ Naijiria ti wọn jọ wa ni Genk, Stephen Odey ati Cyrul Dessers ko ni arun ọhun. Nigba ti Ẹgbẹ agbabọọlu Genk pinnu lati ṣe ayẹwo fun gbogbo agbabọọlu wọn ṣaaju ifẹsẹwọnsẹ ọlọrẹsọọrẹẹ kan ni ayẹwo naa ti fihan pe Onuachu ti farakasa. Oríṣun àwòrán, @Paul Paul Onuachu ni agbábọ́ọ̀lù Super Eagles Nàìjíríà àkọ́kọ́ tó lùgbàdì Covid 19 Lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu karun un ni Onuachu rinrin ajo lati Belgium lọ si Naijiria. Ọjọ kejidinlọgbon, oṣu kẹfa lo lanfaani lati pada si Belgium lẹyin ti o ha si ilu Eko fun ọsẹ kan ti ko ri baalu wọ nitori ajakalẹ arun coronavirus. Kemi Dairo: Iṣẹ́ abẹ nínú ọpọlọ àti ẹ̀rọ ni mo fi ń gbọ́ ọ̀rọ̀ báyìí",9 Agẹmo 2020 +Nàíjíríà já mi kulẹ̀ - Oladapo Adu," Yoruba ni bi eegun ẹni ba joo re, ori a maa ya atọkun amọ eyi ko ri bẹẹ fun Oladapo Adu, to lọ soju Naijiria ninu idije Chess ni Sierra-Leone. Adu, ẹni to jẹ ọmọ Naijiria to n gbe ni orilẹede Amẹrika salaye pe Naijiria lo mu awọn mẹrin lati soju rẹ ninu idije Chess lai gbe owo kalẹ fi se agbatẹru wọn. O ni funra oun ni oun ra tikẹẹti alọ ati abọ lati lọ si Sierra Leone, amọ nigba ti idije naa pari logunjọ osu kẹta, arun Coronavirus ti bẹ silẹ. Coronavirus yii si lo mu ki ọkọ ofurufu oun wọgile eto irinna rẹ, ọkada si ni oun gun lati Freetown lọ si Abidjan ni ọjọ kẹrinlelogun osu kẹta ọdun yii. Adu ni awọn orilẹede yoku ni iwọ oorun Afirika wa ọna lati gbe awọn asoju wọn nibi idije naa amọ Naijria ko tiẹ ranti oun, tawọn mẹta yoku ti wọn jọ soju Naijiria si ti pada sile.",8 Agẹmo 2020 +"West Ham fi omi àbùkù wẹ Chelsea láwọlé sùn, Arsenal yìnbọn pa Norwich"," Oríṣun àwòrán, Twitter/Chelsea FC Abuku oloronbo ni ẹgbẹ agbabọọlu West Ham United fi kan Chelsea lalẹ Ọjọru ninu idije Premier League. Tomas Soucek lo kọkọ gba bọọlu sawọn fun West Ham nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa di iṣẹju mẹrinlelọgbọn, ṣugbọn ẹrọ VAR wọgile goolu ọhun. O kudiẹ ki ipele akọkọ ere bọọlu naa pari ni Willian gba pẹnariti wọle fun Chelsea eyi to mu wọn ṣiwaju ninu ifẹsẹwọnsẹ naa. Amọ West Ham ko bẹṣu bẹgba nipele keji ere bọọlu ọhun, lẹyin iṣẹju mẹfa ti ipele keji gberasọ ni Michail Antonio dayo ti Chelsea gba wọle pada. Gẹgẹ bi ẹ ti mọ pe Chelsea kii ṣe ẹran rirọ, Willian gba goolu mii wọle fun Chelsea, ni ere bọọlu ọhun ba di ọmi alayo mejimeji. Ṣugbọn gudugbẹ ja nigba ti Andriy Yarmolenko gba goolu ẹlẹkẹta sawọn fun West Ham, nigba ti o ki iṣẹju kan pere ki ifẹsẹwọnsẹ naa pari, lọrọ ba di wo mi n wo ọ. Esi ifeṣẹwọnsẹ yii ti jẹ ki Manchester United sun mọ Chelsea ni kaṣan ọrun ninu ereje fun ati kopa ninu idije UEFA Champions League ni saa bọọlu to n bọ. Ẹwẹ, ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal gbarada lẹyin ti wọn run Norwich mọlẹ jegejege ni papa isẹre Emirates pẹlu ayo mẹrin ọtọtọ sodo. Ẹlẹsẹ ayo, Pierre-Emerick Aubameyang lo kọkọ ṣide goolu fun Arsenal ni bii iṣẹju mẹtalelọgbọn ti ere bọọlu naa gberasọ. Lẹyin iṣẹju mẹrin ni agbabọọlu aringbungbun Granit Xhaka gba goolu keji sawọn fun awọn Gunners. Aubameyang tun gba yo mii sawọn, ki Cedric Soares to fi ẹlẹẹkẹrin le. Arsenal ti wa ni ipo kẹfa bayii lori tabili idije Premier League. Koda gbajugbaja olorin, Florence Ifeoluwa Otedola ti ọpọ mọ si DJ Cuppy ti banujẹ pe nigba ti oun fi Arsenal silẹ darapọ mọ Man United ni Arsenal bẹrẹ si ni ṣe daadaa. Niṣe lo n beere bo ya oun gan an lounṣe okunfa bi Arsenal ṣe n daku daji tẹlẹ. Africa Eye: Ọwọ́ tẹ ayédèrú dókítà Abdallah tó ń tà oògùn Coronavirus",2 Agẹmo 2020 +Ògbóǹtarìgì agbábọ́ọ̀lù tẹníísìì Novak Djokovic ti lùgbàdì coronavirus," Oríṣun àwòrán, Instagram/djokernole Gbajugbaja agbabọọlu tẹnisii, Novak Djokovic ti lugbadi aarun coronavirus. Oun ni agbabọọlu tẹnisii to ṣẹṣẹ ko aarun covid-19 lẹyin ti Grigor Dimitrov, Borna Coric ati Viktor Troicki sọ pe awọn ni coronavirus lẹyin ti wọn koju Djokovic ninu idije Adria Tour. Troicki ti oun naa jẹ ọmọ orilẹede Serbia ni Djokovic kọkọ koju ki o to koju Dimitrov ati Borna Coric. Ẹwẹ, gbajugbaja agbabọọlu tẹniisi ọmọ ilẹ Gẹẹsi, Andy Murray ni ẹkọ nla ni awọn agbabọọlu tẹniisi to lugbadi coronavirus jẹ fawọn yoku. Ọmọ ilẹ Australia, Nick Kyrgios ni tiẹ sọ pe igbesẹ lati maa kopa ninu idije tẹniisii lasiko ajakalẹ aarun covid-19 yii. Oríṣun àwòrán, Instagram/djokernole Lati oṣu keji ọdun 2020 ni ajọ to n ri si ere idaraya tẹniisii, ATP ti fote le tẹniisii gbigba nitori ajakalẹ aarun coronavirus. Idije Adria Tour wa lara awọn idije tẹniisii to ṣẹṣẹ bẹrẹ laipẹ yii.",23 Òkùdu 2020 +"Ọmọọba 'The Buzz' Larbie rèé, ọmọ ọdún méje tí wọ́n ń pè ní Messi lágbo ẹ̀ṣẹ́ kíkàn"," Awọn agba bọ wọn ni ọmọ to ba maa jẹ aṣamu, kekere lo ti n ṣẹnu ṣamuṣamu; eyi ni itan Ọmọọba 'The Buzz' Larbie to n ti kekere ṣe ohun ti agba ko lee ṣe lagbo ẹṣẹ kikan.",23 Òkùdu 2020 +Chelsea dun DJ Cuppy nínú lẹ̀yìn tí Arsenal gba omijé lójú rẹ̀," Oríṣun àwòrán, Getty Images Akọda oro koda bi bi ada gbẹyin ni Yoruba maa n wi. Bẹẹ gan an lọrọ ri fun ẹgbẹ agbabọọlu Aston Villa to kọ lẹta si iya lọwọ Chelsea. Aston Villa lo kọkọ gba goolu sawọn Chelsea ninu ifẹsẹwọnsẹ ọhun. Ṣugbọn Chelsea fi ye wọn pe agbo to tadi mẹyin, agbara lo lọ mu wa ni abala keji ere bọọlu naa. Christian Pulisic lo kọkọ dayo naa pada nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa di wakati kan. Lẹyin iṣẹju meji pere si igba naa ni ẹlẹsẹ ayo Olivier Giroud fi ọba le fun Chelsea eyi ti o mu Chelsea siwaju pẹlu ayo meji sodo. Awọn kan tiẹ sọ pe ẹbun ayẹyẹ ọjọ ibi ni awọn agbabọọlu Chelsea fi ijaweolubori ninu ere bọọlu naa ṣe fun akọnimọọgba wọn Frank lampard to pe ọdun mejilelogoji lọjọ Abaméta. Ẹwẹ, lẹyin ti Florence Otedola ti ọpọ mọ si Chelsea DJ kọ Arsenal silẹ pẹlu omije loju, o ti kede loju opo Twitter rẹ pe oun fẹran ohun ti oun ri lara ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea. Amọ o ṣalaye pe oun si ni lati wo awọn ẹgbẹ agbabọọlu mi ki oun to pinu eyi ti oun maa darapọ mọ.",21 Òkùdu 2020 +Cuppy kọ Arsenal sílẹ̀! Ọmọ Otedola bú sẹ́kún lẹ́yìn tí Brighton tún d'ẹrù ìyà lé Arsenal lórí," Oríṣun àwòrán, Instagram/cuppymusic Ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal ti ba ọpọlọpọ ololufẹ wọn ninu jẹ lẹyin ti Brighton ti ẹyin gbe ru wọn ninu idije liigi Premier League ti wọn gba lọjọ Abamẹta. L'Ọjọru ni Arsenal kọkọ fi iya ṣide idije naa lẹyin ti Premier League bẹrẹ lẹyin isinmi ọlọjọ gbọọrọ nitori coronavirus. Manchester City lo kọkọ ki bẹbdẹ si Arsenal ninu, ami ayo mẹta si odo ni wọn fi lu wọn bi aṣọ ofi. Ọpọ awọn ololufẹ wọn lo ti n sọ pe o yẹ ki Arsenal le na Brighton nigba ti wọn ba pade. Ṣugbọn ọrọ bẹyin yọ nigba ti Brighton fi pọnmọ kun pọnmọ pọnmọ ete awọn Gunners pẹlu ayo meji si ẹyọkan. Koda aifakọyọ naa ti gbomi loju ọkan lara awọn ololufẹ Arsenal Florence Otedola ti ọpọ mọ si DJ Cuppy. Cuppy fi sori oju opo Twitter ati Instagram rẹ pe oun ti jawee fun Arsenal lẹyin ọdun mẹfa to ti n tẹle ikọ agbabọọlu naa. O ni oun ko tii mọ ẹgbẹ agbabọọlu tuntun ti oun yoo maa tẹ le bayii, ṣugbọn o ti tan laarin oun ati Arsenal. Brighton vs Arsenal: Dákúdájí Arsenal tún paná pii lẹ́ẹ̀kan síi nílé Brighton Ajẹkun iya ni ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal tun jẹ ninu idije Premier League lẹyin ti Brighton din dodo iya fun wọn ninu ifẹsẹwọnsẹ keji ti wọn gba lati igba ti Premier League ti bẹrẹ pada. Manchester City lo kọkọ lu Gunners ni alubami lẹyin ti wọn lu wọn pẹlu goolu mẹta eyi ti Arsenal ko si lee ta putu. Oríṣun àwòrán, Getty Images Ọpọ lo ti kọkọ ro pe Arsenal yoo jẹri ara wọn lọjọ Abamẹta nigba ti wọn ba koju Brighton, ṣugbọn ọrọ bẹyin yọ ninu ere bọọlu ọhun. Manchester city kọ lẹ́tà ìyà, Arsenal ló tẹ́wọ́ gbàá ní Etihad Iya o to 'ya afada pakun, ikun salọ ada tun sọnu ni ọrọ jẹ fun ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal laṣalẹ ọjọru nigba ti wọn pada sori papa ni itẹsiwaju idije liigi premiership ilẹ Gẹẹsi ti wọn so rọ fun nnkan bii ọgọrun ọjọ nitori ajakalẹ arun coronavirus lagbaye. Ikọ Manchester city ni Arsenal koju, goolu mẹta ti ko ṣee bomi la ni wọn si fi bori Arsenal. Esi ifẹsẹwọnsẹ yii ko jẹ iyalẹnu fun ọpọ onwoye ere bọọẹu lagbaye, paapaa idije liigi Premiership. Oríṣun àwòrán, Getty Images Amọṣa, ọrọ agbabọọlu ọwọ ẹyin fun Arsenal, iyẹn David Luiz ni ọpọlọpọ mu bs ẹnu lẹyin ifẹsẹwọnsẹ naa. Yatọ si pe oun lo ṣokunfa meji ninu goolu mẹta ti Manchester city fi gbẹyẹ mọ Arsenal lọwọ, oun naa ni agbabọọlu Arsenal to gba kaadi pupa eyi to tums si pe rẹfiri ni ko wabigba kuro lori papa. Ni ipele kini ifẹsẹwọnsẹ naa ni aṣiṣe David Luiz ti kọkọ ṣakoba fun Arsena nigba to fara gbe bọọlu to yẹ ko gba danu sọwọ Raheem Sterling agbabọọlu Manchester city ti tọun si kanra gba bọọlu naa sawọn. Ni abala keji ifẹsẹwọnsẹ naa lo tun ti fa aṣọ Riyadh Mahrez to jẹ agbabọọlu Mancity ti rẹfiri si fọn fere fun pẹnariti ti o si tun fun un ni kaadi pupa pe ko jade kuro lori papa. Luiz kii ṣe ajeji si irufẹ awsn aṣiṣẹ epo n biyọ bayii to si ti mu ki ọpọlọpọ onwoye bọọlu o maa pe fun ori rẹ. Pẹlu jijawe olubori yii, O tunmọ si pe ami mẹfa lo n dabu ẹgbẹ agbabọọẹu Liverpool bayii lojuna ati gba ife ẹyẹ Premiership ti saa yii.",18 Òkùdu 2020 +"Mò ń ronú láti padà sí ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Nàìjíríà, Super Eagles láìpẹ́- Odion Ighalo"," Oríṣun àwòrán, Getty Images Ẹlẹsẹ ayo ọmọ Naijiria to n gbabọọlu fun ikọ Manchester United, Odion Ighalo ti sọ pe oun n roo lọwọ lati pada si ẹgbẹ agbabọọlu Naijiria, Super Eagles. Ighalo sọrọ yii nigba to n kopa ninu ifọrọwanilẹnuwo kan lori ileeṣẹ redio Brila FM. Ighalo kede ifẹyinti ninu ere bọọlu fun Super Eagles lẹyin idije 2019 AFCON to waye lorilẹ-ede Egypt. Ẹlẹsẹ ayo Ighalo ni oun kede ifẹyinti tẹlẹ nitori Naijiria jina si China nibi ti oun ti n gbabọọlu fun ikọ Shanghai Shenshua. Amọ, o sọ pe oun le pada bayii nitori ilẹ Gẹẹsi ni ẹgbẹ agbabọọlu Manchester United ti oun n ṣoju wa. Ṣugbọn o ni oun si fẹ gbaju mọ ẹgbẹ agbabọọlu Manchester United ti oun wa bayii. Oríṣun àwòrán, Getty Images Lasiko ti ọja rira agbabọọlu ṣi silẹ ninu oṣu kinni ọdun 2020 ni Ighalo darapọ mọ Manchester United lati ikọ agbabọọlu China, Shanghai Shenhua. Ighalo ti gba goolu mẹrin sawọn lẹẹmẹrin ninu ifẹsẹwọnsẹ mẹjọ to lanfaani lati ṣoju Man U ninu rẹ ki o to di wi pe wọn so ere bọọlu rọ nilẹ Gẹẹsi nitori ajakalẹ aarun coronavirus. Ẹwẹ, ẹgbẹ agbabọọlu Man U ti sọ loju opo Twitter pe ohun to jẹ kawọn ṣe adehun tuntun pẹlu Ighalo ni pe o farajin ṣiṣẹ atawọn goolu to ti gba sawọn. Victor Osimhen lo ti n siwaju ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles lati igba ti Ighalo ti fẹyinti.",5 Òkùdu 2020 +Mo fẹ́ kí Ighalo gba ife pẹ̀lú Manchester United kó tó kúrò lọ́dún 2021- Solskjaer," Oríṣun àwòrán, Twitter/Man U Ẹgbẹ agbabọọlu Manchester United ti sọ idi ti wọn fi ṣe adehun tuntun pẹlu ẹlẹsẹ ayo, Odion Ighalo eyi ti yoo mu un di oṣu ọdun 2021 pẹlu ikọ naa. Lori opo ayelujara ikansiraẹni Twitter ni Man U ti fidi ọrọ naa mulẹ lọjọ Aje. Lasiko ti ọja rira agbabọọlu ṣi silẹ ninu oṣu kinni ọdun 2020 ni Ighalo darapọ mọ Manchester United lati ikọ agbabọọlu China, Shanghai Shenhua. Ighalo ti gba goolu mẹrin sawọn lẹẹmẹrin ninu ifẹsẹwọnsẹ mẹjọ to lanfaani lati ṣoju Man U ninu rẹ ki o to di wi pe wọn so ere bọọlu rọ nilẹ Gẹẹsi nitori ajakalẹ aarun coronavirus. Ẹwẹ, ẹgbẹ agbabọọlu Man U ti sọ loju opo Twitter pe ohun to jẹ kawọn ṣe adehun tuntun pẹlu Ighalo ni pe o farajin ṣiṣẹ atawọn goolu to ti gba sawọn. Ti ẹ ko ba gbagbe, Ighalo gan an fun ra rẹ ṣalaye laipẹ yii bi o ti fi owo ounjẹ ọsan rẹ lọ wo ere bọọlu Man U. Oríṣun àwòrán, Twitter/Man U O ni oun atawọn ẹgbọn ati aburo oun maa n ya owo sọtọ ninu owo ounjẹ lati le lanfaani wo Manchester United. Akọnimọọgba ẹgbẹ agbabọọlu Man U, Ole Gunnar Solskjaer sọ pe oun fẹ ki Ighalo gba ife ẹyẹ pẹlu Man U ko to fi ẹgbẹ agbabọọlu naa silẹ.",2 Òkùdu 2020 +Anthony Joshua ni ìwúrí ọmọ ọdún méje tó ń kàn'ṣẹ́ yìí," ''O wun mi ki n di Naijiria 'Champion' bi Anthony Joshua '' Erongba Sekinat Quadri abẹṣẹkubiojo ọmọbirin ọmọ ọdun mẹjẹ re e nilu Eko. Papa iṣere Oworo Sports Centre ni a ti ṣe alabapade re e nibi ti oun ati awọn ajẹsẹ miran ti n gbaradi. Nigba ti Sekinat wa ni ọmọ ọdun maarun ni oun ati Baba rẹ jijọ nasẹ lọ si papa iṣere naa ti o si ri awọn to n ja ẹṣẹ. Sekinat Quadri ''Mo sọ fun Mummy mi wi pe mo fẹ́ ma ja ẹṣẹ ṣugbọn wọn sọ wi pe rara. Daddy mi lo sọ wi pe ko buru'' Laarin awọn akẹgbẹ rẹ, Sekinat jẹ ọmọ to fi ọkan si ẹṣẹ jija ti ọrọ rẹ a si ma ya olukọni rẹ lẹnu. ''Mi o lero wi pe yoo ṣe daada nidi ẹṣẹ jija yi nitori ko lara pupọ.Sugbọn lati igba ti o ti bẹrẹ niṣe ni o n jọ mi loju.''",27 Ọ̀pẹ̀̀ 2018 +"Michael Jordan: $560,000 ni wọn lu gbàǹjo bàtà ìlúmọ̀ọ́ká agbábọ́ọ́lùù àlápẹ̀rẹ̀ náà fún ẹ̀ṣọ́ ilé"," Oríṣun àwòrán, Sotheby's Bata ti ilumọọka agbabọọlu alapẹrẹ, Michael Jordan lo ni ọdun 1985, ni wọn ti lu gbanjo rẹ ni ẹgbẹrun lọna ọtalelẹẹdẹgbẹta dọla ($560,000). Bata olokun buutu naa, ti Ileesẹ Nike ṣe sita, eyi ti Jordan wọ lasiko saa bọọlu alapẹrẹ to fi dojukọ ikọ Chicago Bulls, nireti wa tẹlẹ pe owo tita rẹ yoo wa laarin ẹgbẹrun lọna ọgọrun si ẹgbẹrun lọna aadọjọ dọla nilu Sotheby. Akọsilẹ to wa nilẹ salaye pe, ojilenirinwo o din meji ati aabọ dọla ($437,500) ni wọn ta ẹsẹ bata Nike yii lọdun 1972. Awọn ẹsẹ bata buutu ti ko bara dọgba ni Jordan n wọ, ẹsẹ osi rẹ n wọ iwọn bata mẹtala nigba ti ẹsẹ ọtun rẹ n wọ iwọn ẹsẹ bata mẹtala ati aabọ. Jordan Geller, to da ibudo iṣe nkan iṣẹnbaye lọjọ si silẹ nilu Las Vegas, lo ta bata ti Michael Jordan lo pati lọdun 1985 naa. Oríṣun àwòrán, Getty Images Igbesẹ tita bata naa si lo bọ si akoko ti Ileesẹ Netflix gbe akanse ẹkunrẹrẹ fọnran aworan iroyin kan sita, to pe akori rẹ ni - The Last Dance. Afihan ifiga-gbaga fun idije ami ẹyẹ agbabọọlu alapẹrẹ to fakọyọ julọ, ikẹfa iru rẹ to waye laarin saa idije bọọlu alapẹrẹ fọdun 1997 si 1998 si wa ninu fọnran akojọ aworan fun akanse eto naa.",22 Èbibi 2020 +"Ronaldo Brazil làgbà gbogbo agbábọ́ọ̀lù, kì í ṣẹgbẹ́ ẹ Messi àti Ronaldo- Roberto Carlos"," Oríṣun àwòrán, Getty Images Ronaldo Delima gba gbajugbaja ami ẹyẹ Ballon d'Or lẹẹmeji, o si tun gba ife ẹyẹ agbaye lọdun 1994 ati 2002. Agbabọọlu Real Madrid tẹlẹ ri, Roberto Carlos ti sọ pe ẹlẹsẹ ayo, Ronaldo Nazario Delima pegede ju Lionel Messi ati Cristiano Ronaldo lọ nigba to si fi n gba bọọlu. Ronaldo Delima gba gbajugbaja ami ẹyẹ Ballon d'Or lẹẹmeji, o si tun gba ife ẹyẹ agbaye lọdun 1994 ati 2002. Ṣugbọn ifarapa leralera lori ookun rẹ ko jẹ ko le gba bọọlu pẹ. Coronavirus symptoms in Nigeria: Pẹ̀lú èròjà olùgbèjà ara 'Antibodies' Amọ, o pitu meje tawọn ọdẹ n pa ninu igbo nigba to fi n ṣoju ẹgbẹ agbabọọlu Real Madrid ati Barcelona lorilẹ-ede Spain. Carlos ni lootọọ ni Messi ati Ronaldo n tii fi bọọlu dara, fun bi ọdun mẹẹdogun bayii, o ni Ronaldo Delima si ni baba wọn. Carlos to jẹ akẹgbẹ rẹ ni Real Madrid ati Brazil jẹri wi pe o nira fawọn ẹlẹsẹ ayo lati gba bọọlu sawọn nigba naa ju akoko yii lọ nitori iyatọ ti ba ofin ere bọọlu nisin yii. Coronavirus tips: Kìí ṣe gbogbo ìbòmù ló ń dá coronavirus dúró",21 Èbibi 2020 +Àwọn jẹsí tó gbajúmọ̀ nínú ìtàn ìdíje bọ́ọ́lù," Asiko yii lọ́dọọdún ni awọn ẹgbẹ́ agbabọọlu maa n mura lati safihan àwọn aṣọ agbabọọlu wọn fun saa to n bọ.O si seese ki o pẹ lasiko yii nitori coronavirus. Nitori naa, ẹ jẹ ka ṣe agbeyẹwo diẹ lara awọn aṣọ to ti logba ri. Nigeria (2018)Iyalẹnu lo jẹ fun ọpọ eniyan nigba ti ẹgbẹ́ agbabọọlu orilẹ-ede Naijiria kede jẹsi tuntun fun idije ife agbaye lọdun 2018. Ọpọlọpọ wakati ni awọn ololufẹ Super Eagles fi to ni ile itaja Nike nilu London lati ra jẹsi naa. Miliọnu mẹta eniyan si lo ti sanwo silẹ ki aṣọ naa to jade fun tita. Cameroon (2002) Ko ṣẹlẹ ri ni Cameroon fi ọrọ jẹsi rẹ to gbe sita lọdun 2002.Aṣọ naa jẹ eyi ti ko ni apá. Gbogbo eniyan ni ko si f'oju ire wo o. Koda ajọ FIFA fi ofin de wiwọ rẹ ni idije ife agbaye ọdun 2002 to waye ni Japan, nitori pe ""ki i ṣe ṣaati, bikose awọtẹlẹ"". Celtic (1967) Ẹgbẹ́ agbabọọlu Celtic 'Lisbon Lions' lọ wọ gbajugbaja jẹsi naa, lasiko ti wọn fi kọ orúkọ wọn sinu iwe ìtàn nipa lilu ẹgbẹ́ agbabọọlu Inter Milan pẹlu ami ayo meji sẹyọkan Eyi to si sọ wọn di ẹgbẹ́ agbabọọlu Britain akọkọ to gba ife European Cup. Brazil (1970) Lootọ lo jọ ọpọ jẹsi ti Brazil ti maa n lo, sugbọn eyi tun peleke. Ohun ni ẹgbẹ́ agbabọọlu naa wọ lọdun 1970 ti wọn gba ife idije agbaye. Bakan naa lo jẹ pe ohun ni ogbontagi agbabọọlu, Pele, wọ gbẹyin ko to o fẹyinti lẹ́nu bọọlu gbigba. Chelsea (1970)Ki aṣọ o ma ba a tako ara wọn, ni ẹgbẹ́ agbabọọlu Chelsea ṣe pa ààwọ̀ ibọsẹ ati awọn nkan miran to jẹ aawọ funfun, si ààwọ̀ ofeefe (yellow),ni asiko ifẹsẹwọnsẹ asekagba pẹlu Leeds.Ọdun naa gan-an si ni igba akọkọ ti wọn gba ife ẹyẹ FA Cup.Lati saami aadọta ọdun àṣeyọrí náà, Chelsea wọ jẹsi to jọ ọ idije kan pẹlu Nottingham Forest lọdun 2020. libya Ajax (1971) Isẹ ara rẹ ko pọ rara, sugbọn o rẹwa pupọ. Inu aṣọ yii ni Ajax wa to fi na Panathinaikos ni Wembley pẹlu ami meji soodo. To si tun jẹ igba akọkọ ti wọn bori ninu idije European Cup final. Denmark (1986)Ara ni ẹgbẹ́ agbabọọlu orilẹ-ede Denmark fi aṣọ wọn da ni igba akọkọ ti wọn kopa ninu idije ife agbaye. Bo tilej jẹ pe 'jẹsi' naa fa àríyànjiyàn nigba naa, Southampton ati Coventry wa lara awọn ẹgbẹ́ agbabọọlu to pada wọ nkan to jọ aṣọ naa. Afeez Agoro: O ṣòro fún mi láti wọ Danfo jáde Netherlands (1988) Aṣọ naa jẹ ọkan lara eyi ti awọn eniyan n wárí fún ni gbogbo igba. Aṣọ naa dùn ún wo lọrun wọn pẹlu bi wọn ṣe bori ninu idije European Championship fun igba akọkọ. Manchester United (1990) Lootọ ni ẹgbẹ́ agbabọọlu Man U ti maa n wọ aṣọ ti ko ṣe fọwọ́rọsẹyin, sugbọn eyi tun peleke. Isẹ̀ ọnà 'Aztec-style' ti wọn se si ara aṣọ naa mu ko rẹwa pupọ. Àwọn ololufẹ wọn si gba ti ẹ titi di òní. 'Èmi gan máa ń béèrè lọ́wọ́ ara mi pé ta ni Wole Soyinka gangan' Arsenal (1991) Aṣọ aláwọ̀ ofeefe yii jẹ ọkan lara awọn aṣọ manigbagbe ni nkan bi ọdun 1990. Ó si gbajumọ lasiko náà.",17 Ìgbé 2020 +"Arsenal rántí ""Invincibles,"" ó pé ọdún mẹ́rìndínlógún tí Arsenal gba ife Premier League"," Oríṣun àwòrán, @GilbertoSilva Ifẹsẹwọnsẹ mọkandinlaadọta ni Arsenal gba lai padanu ọkankan ninu wọn. O ti pe ọdun mẹrindinlogun bayii ti ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal gba ife ẹyẹ Premier League lai fidi rẹmi ninu ifẹsẹwọnsẹ kankan ni saa bọọlu ọdun 2003/2004. Nigba naa si ni Arsenal gba ife ẹyẹ idije Premier League kẹyin. Arsene Wenger ni akọnimọọgba ikọ Arsenal nigba naa. Oríṣun àwòrán, @AFTVMedia Patrick Vieira ni balogun ẹgbẹ agbabọọlu ikọ naa ninu eyi tawọn agbaọjẹ agbabọọlu bi Thierry Henry, Robert Pires, Dennis Beckamp, Sol Campbell, Arshley Cole ati Kanu Nwankwo wa. Ifẹsẹwọnsẹ mọkandinlaadọta ni Arsenal gba lai padanu ọkankan ninu wọn. Lori ifẹsẹwọnsẹ aadọta ni wọn de ki ẹgbẹ agbabọọlu Manchester United to fẹyin wọn gbolẹ ti wọn si da wọn duro. Oríṣun àwòrán, Mikel Coronavirus: Arsenal padà sórí pápá, Premier League lè bẹ̀rẹ́ padà lóṣù kẹfa O ṣeeṣe ki idije Premier League bẹrẹ pada laipẹ, lẹyin ti o ti wa ni idaduro lati inu oṣu kẹta nitori ajakalẹ aarun coronavirus. Ajọ UEFA ti fawọn alaṣẹ idije naa atawọn idije liigi bọọlu mii kaakiri ilẹ Yuropu di ọjọ kẹẹdọgbọn oṣu karun un lati ṣeto igba ti wọn fẹ bẹrẹ saa bọọlu yii pada. Kini Yoruba ""international passport""? Awọn alaṣẹ Premier League fẹ bẹrẹ liigi ọhun pada lọjọ kẹjọ oṣu kẹfa, eyi ti wọn fẹ ko pari ninu oṣu keje ọdun yii.Ẹwẹ, ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal, Tottenham, West Ham ati Brighton ti ṣi papa iṣere wọn fawọn agbabọọlu wọ lati ma ṣe igbaradi ọlọdanni.",28 Ìgbé 2020 +"Àràmọ̀ndà agbábọ́ọ̀lù tó ń jẹ Messi, ó ju Ronaldo lọ lórí pápá- Jurgen Klopp"," Oríṣun àwòrán, Getty Images Akọnimọọgba ẹgbẹ agbabọọlu Liverpool, Jurgen Klopp naa ti da si arayinjiyan ""ta lo dara ju"" laarin Lionel Messi ati Cristiano Ronaldo.Ko tii si opin si ariyanjuyan yii lẹyin tawọn mejeeji ti tayọ ju awọn akẹgbẹ wọn lagbaaye lọ fun bi ọdun mẹwaa sẹyin bayii.Ronaldo ati Messi jọ dabira ninu idije La Liga nibi ti wọn ti jọ gba ami ẹyẹ loriṣiiriṣii fun ẹgbẹ agbabọọlu wọn, Real Madrid ati Barcelona ki Ronaldo to darapọ ikọ Juventus.",14 Èbibi 2020 +Ṣé ẹ lè kí Liverpool kú oríire báyìí? Premier League yóò bẹ̀rẹ̀ padà lóṣù kẹfà," Oríṣun àwòrán, Twitter/Liverpool FC Gbogbo eto ti to bayii lati bẹrẹ idije Premier League lọjọ kinni oṣu kẹfa ọdun yii lẹyin to ti wa nin idaduro nitori ajakalẹ aarun coronavirus. Ohun ti awọn alaṣẹ idije naa n gbero ni lati gba gbogbo ifẹsẹwọnsẹ to ku tan laarin ọsẹ mẹfa ni kete ti idije naa ba ti bẹrẹ pada. Inu ọpọlọ awọn ololufẹ idije Premier lo dun pe idije naa yoo pada laipẹ ọjọ. Ijọba ilẹ Gẹẹsi rọ awọn ẹgbẹ agbabọọlu ogun to wa ninu idije naa lati gba awọn ifẹsẹwọnsẹ to ku lawọn papa iṣere mii yatọ si ti wọn. Ṣugbọn awọn ikọ agbabọọlu kọ jalẹ, wọn ni o wu awọn lati gba awọn ifẹsẹwọnsẹ to ku nile awọn. Liverpool lo wa loke tente tabili EPL, nigba ti ifẹsẹwọnsẹ to ku si jẹ mọkanla.",11 Èbibi 2020 +Ẹ̀rù n ba àwọn agbábọ́ọ̀lù Premier League láti padà sórí pápá nítorí coronavirus," Oríṣun àwòrán, Getty Images Ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹfa, ọdun 2020, ni ireti wa pe idije Premier League yoo tẹsiwaju Atamatase fun ẹgbẹ́ agbabọọlu Manchester City, Sergio Aguero ti sọ pe ẹru a ti pada sori papa n ba awọn agbabọọlu pẹlu bi aarun coronavirus ṣe n tankalẹ.Ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹfa ni ireti wa pe idije Premier League yoo tẹsiwaju, eyi to tumọ si pe awọn agbabọọlu gbọdọ pada si papa igbaradi lọjọ kejidinlogun, oṣu Karun. Awọn ẹgbẹ́ agbabọọlu to ṣe koko yoo si ṣe ipade lọjọ Ẹti lati jiroro lori ọna ti wọn yoo gbe e gba.Aguero sọ pe"" ẹru n ba pupọ ninu awọn agbabọọlu nitori pe wọn ni ọmọ ati ẹbí."" Lasiko to n ba ileesẹ amohunmaworan El Chiringhito sọrọ, ọmọ orilẹ-ede Argentina ọhun sọ pe: ""Ẹru n ba mi, sugbọn emi ati ọrẹbinrin mi lajọ wa nibi, mi o si ni i ifarakanra pẹlu awọn eeyan miran. Inu ile mi ni mo wa, ọrẹbinrin mi si nikan ni mo le ko o ran.""Wọn sọ pe awọn kan wà to ni Covid-19, sugbọn ti ko fi àpẹẹrẹ kankan han, tí wọn si le ko ran elomiran. Nitori naa ni mo ṣe duro sile, tori boya mo ni aarun naa ti mi o mọ.""Ọjọ kẹtala, oṣu Kẹta ni wọn so idije Premier League rọ nitori coronavirus, sugbọn gbogbo awọn ẹgbẹ́ agbabọọlu lo ṣetan lati gba ifẹsẹwọnsẹ mejilelaadọrun to ṣẹku.Wọn yoo si gba gbogbo ifẹsẹwọnsẹ naa lai si eero iworan. Bakanna ni wọn n gbeero lati fi awọn idije kan han lori amohunmaworan lọfẹ. Megabite: Ilé-ìwé ni mo ti bẹ̀rẹ̀ orin kíkọ Ẹwẹ, àwọn oludari eto ilera yoo sepade lọjọ Ẹti lati jiroro lori ilana ti wọn yoo gbe nkan gba.BBC Sport ri i gbọ wi pe wọn yoo ṣe ayẹwo aarun coronavirus fun awọn agbabọọlu lẹẹmeji lọsẹ, ti igbaradi ba bẹrẹ saaju ki ofin konile o gbele to kasẹ nilẹ. Bakan naa ni awọn agbabọọlu gbọdọ maa lo í ọmú ni gbogbo igba ti wọn ba wa ni papa. Wọn ko si gbọdọ si oúnjẹ jíjẹ tabi iwẹ ni ibudo naa.Awọn eleto ilera to ṣe koko nìkan si ni anfaani yoo wa fun lati wọle, wọn si gbọdọ wọ aṣọ idaabo bo. Se lootọ ni pe eniyan le ko Coronavirus lara ẹni to ti kú? Gbogbo ipade ati ijiroro gbọdọ maa waye lori ayelujara. Sugbọn sa, atamatase ẹgbẹ́ agbabọọlu Brighton, Glenn Murray sọ pe awọn ilana kan ti wọn la kalẹ le ma a ṣíṣẹ, paapa ibomu lilo nitori pe ""awọn agbabọọlu yoo ma a yọ sọnu lasiko ti wọn ba n gba bọọlu"". Oríṣun àwòrán, Getty Images O sọ pe ""idi ti awọn eeyan fi fẹ́ ẹ pada sori papa ye mi, sugbọn wọn gbọdọ ṣe e ni ọna to mu ọgbọ́n dani, ati ni asiko to tọ́, ni ọna ti aabo yoo fi wa fun gbogbo eniyan, nitori pe kaakiri agbaye ni awọn agbabọọlu yoo ti wa, ko si si ẹni to mọ àwọn to ni i"".""Mo ni awọn ọmọ nilẹ, mi o si ni i fẹ́ fi wọn sinu ewu. Awọn agbabọọlu kan ni ọmọ tuntun nile, bẹ ẹ làwọn kan si n gbé pẹlu arugbo wọn. Nitori naa, igbesẹ ti ko bojumu ni bi wọn ṣe sọ pe ki idije o bẹrẹ pada. Ẹgbẹ́ agbabọọlu Arsenal, Brighton ati West Ham ti si ibudo igbaradi wọn silẹ fun awọn agbabọọlu lati ma a da ṣe igbaradi.",2 Èbibi 2020 +Bí ilumọọka agbabọọlu Drogba ṣe dáwọ ogun dúró ní Ivory Coast," Oríṣun àwòrán, others Ni papa isere Al-Merrikh Stadium ní orile-ede Sudan ní iṣẹlẹ kan to mí agbo ere bọọlu n'ilẹ Afrika ti waye. Ọjọ kẹjọ, oṣù Kẹwaa, ọdún 2005 ni ọjọ ta n wí yi. Orile-ede méjì Cameroon àti Ivory Coast jó n du aye ẹni tí yóò tẹsiwaju ninu ìsòrí wọn láti kópa níbi ìdíje ife ẹyẹ bọọlu agbaye ni odun 3006. Lara awọn to lewaju iko Ivory Coast ni akinkanju agbaboolu kan ti orukọ rẹ n jẹ Didier Drogba. Yatọ si Drogba awọn ilumọọka agbabọọlu miran bi Yahya Touré, Kolo Touré ati Emmanueli Eboue wa lori papa ti ireti sí wa pé wọn yóò jáwé oluborí. Tohun ti bi awọn wonyi ṣe n gbero pé ki wọn fi itan lelẹ, paapaa bi ohun tó n ṣẹlẹ ni orile-ede wọn kò ṣe fararọ nitori ogun abẹ́lé to n gbegi dina alaafia ara ilu. Oríṣun àwòrán, others Ààrẹ Laurent Gbagbo ati awọn ọmọ ogun rẹ ni wọn n se akoso guusu ile naa ti awọn ọmọ ogun ọlọtẹ Guilamme Soro si di agbára mú ni ariwa ilẹ náà. È tẹti kí ẹ ma bawa kalọ. Nínú Ifesewonse to waye ní Sudan, ni ikọ agbabọọlu Ivory Coast ti da bantẹ iya góòlù mẹta si ọkan fún wọn. Inu gbogbo ọmọ Ivory n dun ṣugbọn ki won to lè mọ bóyá wọn yóò tẹsiwaju tabi bẹẹkọ; wọn nilati kópa nínú ìdíje ife ẹyẹ agbaye ní ọdún 2006, Cameroon ti awọn náà n gba bọọlu lọwọ pẹlu Egypt ni lati gba ọmi. Gbogbo ile Ivory Coast lo n se ádùrá kikan-kikan kí Cameroon fidiremi. Oríṣun àwòrán, others Aseyin wa aseyinbọ, Ivory Coast lo tẹsiwaju lọ ìdíje agbaye. Idunnu ṣubu lù ayo fún gbogbo ilẹ náà tí kò sì sí ìyàtọ̀ kánkan láàrin àwọn tó n dojú ìjà kọ ara wọn mọ ;asiko ajọyọ ọhun. Parental Guidance: Ọdún méjì ni kí ẹ ti bẹ̀rẹ̀ kíkọ́ ọmọ nípa ìbálòpọ̀ Níwájú àwọn akọroyin lágbayé, ni Didier Drogba ti sọrọ ti o si parowa sí àwọn tó n já pe ki won dẹkun ija wọn. 'Ẹ jọwọ ẹ da ibọn yin silẹ; ki ẹ si kópa nínú eto idibo, Ati ọkunrin ati obinrin ilẹ wa, lóni a fihan pe gbogbo wa le jijọ gbe pọ ti a ko ro boya èèyàn kan wà lati goosu tabi Ariwa Ọkan ní gbogbo wa. Ori ijinle lémi ati awọn akẹgbẹ mí wa, è gbà alaafia láàyè n'ilẹ wa."" Coronavirus: Ǹjẹ́ fífi omi àti iyọ̀ yọnu leè dènà àrùn Coronavirus? Aworan bí Drogba ati awọn akẹgbẹ rẹ tí ṣe kunlẹ bẹ awọn ologun láti gba alaafia laaye jẹ nkan ti awọn Ileese amohunmaworan kaakiri fi n hàn n'ilẹ wọn. Ko pe kò jìnà sí ọjọ yí, àwọn tó n já gba lati joko forojomitooro ọrọ tí wọn sì dà ọwọ ija duro. Bi o ba se wí pe ere fiimu ni ọrọ ti a n so yí jé ní, enit to kọọ yóò ti ni eleyii to lati fi pari ere idinnut yi, ṣugbọn kò tan sibe. Leyin ti Ivory Coast dari pada nibi idije Ife ẹyẹ agbaye ta n wí yi lọdun 2006 ni Drogba kéde lasiko to n se àbẹwò sí àgbègbè ilu rẹ ni Bouake láwọn yóò tí gba Ifesewonse to n bọ lọnà pẹlu Madagascar. Ṣẹ́ lóòtọ́ ní ginger àti garlic lè pa àrun Coronavirus? Iyalẹnu ni ọrọ yii jẹ nitori Bouake ta n wí yii dàbí ilé agbára àwọn ọmọ ogun ọlọtẹ. Kò dájú pé Drogba gba iyọnda lọdọ ààrẹ ko tó kede ọrọ yí ṣugbọn nitori ifẹ tàwọn èèyàn ni ṣi ìdíje bọọlu, sibẹo ṣi wáyé níbẹ. Ọjọ nla ni ọjọ ti a n wí yi ti orile-ede Ivory Coast si borí Madagascar pẹlu ami ayo márún ún sí odo. Oríṣun àwòrán, others Kete ti ìdíje yí parí ni gbogbo èèyàn rọ si ori papa ti won ko si fi ti ẹyà ṣe nínú idawọ ìdùnnú lọjọ ta n wí yi. Gbogbo Ivory Coast lo duro gẹgẹ y ọkan ti iṣẹlẹ yí sì tún so gbogbo ilẹ náà papo gege bí ọkan. Ṣugbọn ìdùnnú yi ko pẹ to fi tun di ìbànújẹ nitori awọn ọmọ ogun ko dawọ ija duro. Ọdún marun un lẹyìn ogun tun waye nitori ija to tẹlẹ esi ìdìbò. Èèyàn tó tó egberun mẹta ló bá ija yi lọ. Oríṣun àwòrán, others Ọwọ tẹ ààrẹ Gbagbo ti ọ sí dero ile-ejo agbaye níbi tí wọn ti fesuny kan pe o da ẹsẹ nla to fako ijẹ ọmọnìyàn. Ni oṣù kínní ọdún 2019 won tu sile pe kò jẹbi amọ ọ di wa ni àhámọ́ láti jejo ko-te-mi-lorun Nínú inu fo àyà fò ni ilẹ Ivory Coast wa lo in I ṣugbọn awọn èèyàn ilẹ náà kò ní gbàgbé ipá ribiribi tí Didier Drogba àti àwọn akẹgbẹ rey ko lati mu alaafia ba ile won. Oríṣun àwòrán, others Bo tile je pe wọn ko ribi gba àmì ẹ̀yẹ láwọn ìdíje agbaye ti won ti kopa, orukọ wọn kò ní parẹ nínú ìtàn ilẹ wọn. Awọn ìkọ yí fihàn pé bí a bá gbaruku ti ara wa kò sí bí a kò ṣe ni jo gbe ní àlàáfíà. Coronavirus in Nigeria: Ẹ wo àǹfààní tó wà nínú àrùn Coronavirus Odun 2018 ní Didier Drogba feyinti nìdí eré bọọlu. Akínkanjú agbaboolu ti awọn ololufẹ rẹ lọri pápá àti lorile-ede rẹ kò ní gbàgbé láyè láyé ni.",2 Ìgbé 2020 +Wo àwọn ọ̀nà tí o le fi mú ara rẹ gbá yágí-yágí lásìkò ìgbélé yìí," Ọpọlọpọ orilẹ-ede ati ilu ni ọrọ igbele tipa-tipa kan, nitori itankalẹ aarun coronavirus. Ọpọ eniyan si ni ko ba lara mu, nitori pe ọmọ ṣiṣẹ́-ṣiṣẹ́ ni wọn, tabi ẹni ti igbeaye oju kan ko mọ lara. Fidio yii n se atọka si oriṣiriṣi ọna ti awọn eniyan fi n dun ara wọn ninu lasiko iporuru ọkan ti coronavirus mu ba ọpọ eniyan. Kaakiri agbaye si ni wọn ti fi awọn fidio naa ranṣẹ si wa.",19 Ìgbé 2020 +Ebi àṣeyọrí ló n pa mí báyìí lẹ́yìn àkókò mi tó ti ṣòfò - Paul Pogba," Oríṣun àwòrán, Getty Images Agbabọọlu fun Manchester United, Paul Pogba sọ pe ebi àṣeyọrí lo n pa oun ju bayii lẹyin ti oun padanu ọpọlọpọ ọjọ ninu idije saa yii nitori ifarapa.Ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kejila, ọdun 2019, ni Pogba ti gba bọọlu kẹhin, lẹyin to ni ọgbẹ́ ni ẹsẹ̀ ni ibẹrẹ ṣaa.Pogba sọ pe ""airikan ṣe kan ti su oun tipẹ"", ati pe oun yoo pada sori pápá igbaradi nikete ti aarun coronavirus ba tan nilẹ. Ogundiya: Àṣìṣe Dókítà ló sọ mi di aláàbọ̀ ara lórí kẹ̀kẹ́ Oṣu Kinni ọdun ni wọn ṣe iṣẹ abẹ fún gbajugbaja agbabọọlu naa.Pọgba sọ fun ikọ̀ agbohunsafẹfẹ Manchester United pe oun ko ti i la iru nkan bẹẹ kọja ri lati igba ti oun ti n gba bọọlu jẹun, sugbọn oun gba kadara.O ni: ""Mi o ro pe awọn eniyan mọ nkan to ṣẹlẹ si mi gan-an."" Pogba ṣalaye pe: ""Mo fi ẹsẹ mi ṣẹṣẹ lasiko ti a n gba bọọlu pẹlu Southampton ni ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kẹjọ. Eyi jẹ ibẹrẹ ṣaa, mo si mu u mọra fun igba pipẹ; mo n lọ fun igbaradi, mo si tun n gbiyanju lati fi gba bọọlu. Lẹyin ti mo dawọ gbogbo eyi duro ni mo sakiyesi pe egungun mi ti yẹ̀. Ogbontarigi agbabọọlu naa tẹsiwaju pe: ""Wọn ba mi fi nkan we e nileewosan. Sugbọn lẹyin asiko diẹ, egungun naa tobi si i, ni mo ba tun pada ṣenu isẹ. Ifẹsẹwọnsẹ pẹlu Watford ati Newcastle ni mo gba kẹyin ninu oṣu Kejila, ti mo tun fi n ni inira."" Ṣugbọn lẹyin isẹ abẹ ti wọn ṣe fun mi, ara mi ti ya. Mo si ti ṣetan lati pada ṣenu isẹ.""Ọjọ kẹta, oṣu Kẹrin ni wọn kọkọ sun idije Premier league siwaju, lẹyin naa ni wọn tun sun un ni ọgbọnjọ, oṣu Kẹrin, nitori ajakalẹ arun coronavirus to n gba ẹbọ lọwọ gbogbo agbaye yiii. Yoruba Culture: ọjọ́ méje ni wọ́n fí n rẹ ẹ̀kú Danafojura kó tó jáde",16 Ìgbé 2020 +''Ronaldo ṣì lè padà sí ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Real Madrid''," Oríṣun àwòrán, Instagram/Cristiano Ronaldo Ko le ja iyalẹnu ti agbabọjẹ agbabọọlu, Cristiano Ronaldo ba pada si ẹgbẹ agbabọọlu Real Madrid. Akẹgbẹ Ronaldo ninu ẹgbẹ agbabọọlu orilẹede Portugal, Jose Fonte lo sọrọ yii nipa ẹlẹsẹ ayo, Ronaldo to wa pẹlu ikọ Juventus bayii. O ni Ronaldo ma fi n fi aye a ti dagbere silẹ nibi kibi to ba wa lati pada si ẹgbẹ agbabọọlu to wa tẹlẹ. Ronaldo fi Real Madrid silẹ lọ si Juventus lọdun 2018 lẹyin to ti ṣoju ẹgbẹ agbabọọlu naa lorilẹede Spain fun ọdun mẹsan an gbako. Ọgọrun un miliọnu pọn-un(£100million) ni Juve san fun Madrid ki Ronaldo to darapọ mọ wọn. Lati igba ti Ronaldo ti wa ni Manchester United lo ti bẹrẹ si ni gba oniruuru ami ẹyẹ, ṣugbọn nigba to darapọ mọ Real Madrid lo gba oriṣiiriṣii ami ẹyẹ. Cristiano Ronaldo ti gba gbajugbaja ami ẹyẹ Ballon d'Or fun igba marun un ọtọtọ, Lionel Messi nikan lo gba a juu lọ pẹlu mẹfa to gba. Fonte ni Ronaldo si Madrid nitori o fẹran ẹgbẹ agbabọọlu Real Madrid pupọ, o ni bakan naa lo fi ọpọ awọn ọrẹ sibẹ. Ronaldo si ni ọdun meji ṣii ninu iwe adehun to buwọlu pẹlu Juventus.",9 Ìgbé 2020 +"Agbábọ́ọ̀lù Brazil tẹ́lẹ̀, Ronaldinho gba ìtúsílẹ̀ kúrò lọ́gbà ẹwọ̀n, àmọ́..."," Oríṣun àwòrán, EPA Agbabọọlu Brazil tẹlẹ, Ronaldinho ti gba itusilẹ lọgba ẹwọn lorilẹede Paraguay. Amọ, ijọba ilẹ Paraguay si fi ofin de e wi pe ko gbọdọ jade nile. Lọjọ kẹfa oṣu kẹta to lọ ni wọn mu Ronaldinho ati arakunrin rẹ, Roberto Assis lori ẹsun pe wọn lo ayederu iwe irina wọn orilẹede Paraguay. Awọn mejeeji gbọdọ wa ni igbele bayii titi di igba ti igbẹjọ wọn yoo fi bẹrẹ. Ṣugbọn Ronaldinho ati arakunrin rẹ sọ pe awọn ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan awọn. Agbẹjọro wọn tiẹ ṣapejuwe igbesẹ ijọba naa lati fi wọn si ahamọ iwa ta ni yoo mu mi eleyi to lodi si ofin. Oríṣun àwòrán, Reuters Adajọ Gustavo Amarilla ara gbedeke to wa ninu beeli awọn mejeeji ni pe wọn ko gbọdọ sa lọ. Ronaldinho rinrin ajo lọ si orilẹede Paraguay tẹlẹ lati ṣe ifilọlẹ iwe rẹ ati ipolongo fawọn ọmọ ti obi wọn ko ri ọwọ họri. Ronaldinho to gba ife ẹyẹ agbaye pẹlu Brazil lọdun 2002 gba bọọlu fun Paris St-Germain, Barcelona ati AC Milan ilẹ Yuropu ko to fẹhinti lẹyin to ṣoju Fluminense fun igba diẹ ni Brazil.",8 Ìgbé 2020 +Màmá Guardiola d'olóògbé lẹ́yìn tó lùgbàdì Coronavirus," Oríṣun àwòrán, Instagram/Per Guardiola Afẹfẹ aarun coronavirus to n fẹ kaakiri ti fẹ de idile akọnimọọgba ẹgbẹ agbabọọlu Manchester City,Pep Guardiola. Iya Guardiola, Dolors Sala Carrió ti di oloogbe lẹni ọdun mejilelọgọrin lẹyin to lugbadi aarun covid-19. Sala Carrió ku si Manresa, niluu Barcelona lorilẹede Spain. Ẹgbẹ agbabọọlu Manchester City lo fọrọ naa lede loju opo Twitter wọn nibi ti wọn ti kẹdun pẹlu Guardiola lori iku mama rẹ. Loṣu to lọ ni Guardiola gbe owo to le ni miliọnu kan owo dọla kalẹ lorilẹede Spain lati gbogun ti itankalẹ aarun coronavirus. Oríṣun àwòrán, Getty Images Bakan naa lo ṣe fido ninu eyi to ti gbawọn eeyan lamọran lati joko sile, ki wọn si tẹle awọn ilana tawọn oṣiṣẹ eto ilera la kalẹ lasiko yii.",6 Ìgbé 2020 +Àwọn jàndùkú jí agbábọ́ọ̀lù Nàìjíríà méjì gbé lópòpónà Owo sí Benin," Oríṣun àwòrán, Eniymba FC Awọn janduku ti ji agbabọọlu ọmọ Naijiria meji, Dayo Ojo ati Benjamin Iluyomade gbe. Ojo to ti gba bọọlu ri fun ẹgbẹ agbabọọlu Naijiria, Super Eagles n rinrin ajo pẹlu Iluyomade to n gba bọọlu fun ẹgbẹ agbabọọlu Abia Comets lati ilu Akurẹ ki wọn to ko sọwọ awọn ajinigbe lọna ilu Benin. Akẹgbẹ Ojo ti wọn jọ n gba bọọlu fun Enyimba, Emmanuel James naa wa ninu ọkọ naa ṣugbọn oun mori bọ ni tiẹ. Ojo ṣoju ẹgbẹ agbabọọlu Sunshine ilu Akure fun igba pipẹ ko to darapọ mọ Enyimba lọdun 2019. Ojo tun ṣoju Naijiria ninu idije awọn ọjẹwẹwẹ ti ọjọ ori wọn ko ju ọdun mẹtadinlogun lọdun 2010. Laipẹ yii ni ajọ LMC so idije liigi Naijiria NPFL rọ nitori ajakalẹ arun coronavirus. Ìbànújẹ́ ńlá ni ikú agbábọ́ọ̀lù Rangers, Ifeanyi George jẹ́ fún wa- Mínísítà àti NFF Iku agbabọọlu ikọ Rangers International ti ilu Enugu Ifeanyi George ṣe ni laanu gan na, bayii ni minisita fun ere idaraya ati ọrọ ọdọ, Sunday Dare ṣe n kẹdun Ifeanyi di oloogbe lẹni ọdun mẹrindinlọgbọn pẹlu awọn akẹgbẹ rẹ meji, Emmanuel Ogbu ati Eteka Gabrielinu ijamba ọkọ to ṣẹlẹ lanaa ọjọ Aiku. Iroyin ti a gbọ ni pe ọkọ ayọkẹlẹ ti wọn wa ninu rẹ lo lọ fori sọ ọkọ nla akẹru kan nibi ti o duro si . Lopopona Agbor ni ipinlẹ Edo ni ijamba ọkọ ọhun ti ṣẹlẹ nigba ti George ati awọn akẹgbẹ rẹ n rinrin ajo ni opopona ilu Onitsha si Eko. Alukoro ẹgbẹ agbabọọlu Rangers ṣalaye pe awọn agbabọọlu naa rinrin ajo lọ si ilu Eko lẹyin ti idije liigi Naijiria(NPFL) ti di siso rọ ki ijamba naa to ṣẹlẹ. Oríṣun àwòrán, Twitter/NFF Ajọ ẹṣọ oju popo FRSC sọ pe awọn mẹtẹẹta lo ja laisi lojuna ti ijamba ọkọ naa ṣẹlẹ tan. Minisita ni o ṣeni laanu pe pe awọn mejeeji ṣagbako iku ojiji lai le jẹ ohun ti wọn fẹ jẹ laye. Minisita gbadura si Eleduwa pe ko tu awọn ẹbi awọn agbabọọlu mejeeji ninu, o ni oun naa kẹdun awọn agbabọọlu mejeeji. Ẹwẹ, ajọ to n ri si ere bọọlu afẹsẹgba ni Naijiria, NFF sọ loju opo Twitter rẹ pe ibanujẹ nla ni iku awọn agbabọọlu mejeeji jẹ. Oríṣun àwòrán, Twitter/NFF NFF kẹdun pẹlu ẹbi awọn oloogbe naa ati ẹgbẹ agbabọọlu Rangers Intl, ajọ naa gbadura pe ki Eleduwa tẹ wọn si afẹfẹ rere.",23 Ẹrẹ̀nà 2020 +"Agbábọ́ọ̀lù Manchester United tẹ́lẹ̀, Marouane Fellaini lùgbàdì àrun coronavirus"," Oríṣun àwòrán, Getty Images Agbabọọlu ikọ Manchester United tẹlẹ, Marouane Fellaini ti ko arun coronavirus. Ẹgbẹ agbabọọlu rẹ, lorilẹede China, Shandong Luneng lo kede ọrọ naa laarọ ọjọ Aiku. Fellaini to darapọ mọ ẹgbẹ agbabọọlu Shandong Luneng ninu oṣu kinni lati Manchester United pada si China lọjọ Ẹti to kọja lọ ko to di pe ayẹwo fihan pe o ti lugbadi arun covid-19. Ẹgbẹ agbabọọlu rẹ sọ pe Fellaini ko ṣe ojojo tabi iba, bẹẹ ni ko si apẹẹrẹ arun coronavirus kankan lara rẹ nigba to pada de. Ṣugbọn o ti wa ni iyasọtọ bayii fun itọju, Fellaini ni agbabọọlu akọkọ ni idije liigi ilẹ China to gbajugbaja julọ ti yoo kọkọ ko arun naa. Ajakalẹ arun coronavirus lo jẹ ki wọn sun ibẹrẹ idije liigi bọọlu orilẹede China siwaju lai lọjọ. Oríṣun àwòrán, Getty Images Ọjọ kejilelogun oṣu keji ọdun yii ni idije naa ko ba bẹrẹ tẹlẹ ki ajakalẹ arun covid-19 to bẹrẹ. Ẹwẹ, gbajugbaja agbabọọlu AC Milan tẹlẹ, Paolo Maldini ati ọmọ rẹ Daniel naa ti ko coronavirus. Bakan naa, ẹlẹsẹ ayo ẹgbẹ agbabọọlu Juventus, Paulo Dybala naa ti lugbadi arun ọhun. Dybala kede loju opo Instagram rẹ pe oun ati ọrẹbunrin oun, Sabatini ti ko arun ko arun covid-19. Amọ, o ni ko ṣi ewu fawọn mejeeji nitori ara awọn ti n ya bọ diẹdiẹ. Dybala ni agbabọọlu Juventus kẹta ti yoo larun naa lẹyin Daniele Rugani ati Blaise Matuidi ti kọkọ lufgbadi arun ọhun.",22 Ẹrẹ̀nà 2020 +Wọ́n ti wọ́gilé ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ Arsenal àti Brighton lẹ́yìn tí Mikel Arteta lùgbàdì àrùn Coronavirus," Oríṣun àwòrán, @Sporf Awọn alakoso idije Premier League ti wọgile ifẹsẹwọnsẹ to yẹ ko waye laarin ikọ naa ati Brighton lọjọ Abamẹta lẹyin ti akọnimọgba ikọ Arsenal, Mikel Arteta lugbadi arun Coronavirus, Iṣẹlẹ yi ti mu ki ikọ ọhun gbe kọkọrọ ṣẹnu ilẹkun papa iṣere ti wọn ti n ṣe igbaradi, lẹyin naa ni wọn ya awọn eeyan to ṣalabapade akọnimọgba naa sọtọ fun ayẹwo ati itọju. Ni bayii, awọn alakoso idije Premier League yoo ṣepade pajawiri lọjọ Ẹti lati jiroro lori ọjọ iwaju idije naa ni saa yi. Nigba ti esi ayẹwo rẹ fihan pe o ti Lugbadi arun ọhun, ẹni ọdunn ọdun mẹtadinlọgbọn naa ni ""O ṣeni laanu."" Arteta sọ pe oun lọ ṣayẹwo lẹyin ara oun rẹwẹsi, leyi to fi han pe Coronavirus lo n ba finra. Ṣugbọn o ti wa ni oun yoo fẹ lati pada sẹnu iṣe laipe ni kete ti awọn dokita ba ti fun ni aye ati ṣe bẹ. Oríṣun àwòrán, @BleacherReport Ọkan lara awọn adari ikọ Arsenal, Vinai Venkatesham sọ fun awọn akọroyin pe ilera awọn oṣiṣẹ ẹgbẹ agbabọọlu naa ati awọn ololufẹ wọn lo jẹ ikọ naa logun. Ikọ ọhun ti wa ni pupọ awọn ọmọ ẹgbẹ agbabọọlu naa ni wọn yoo fi si apapmọ fun ayẹwo.",13 Ẹrẹ̀nà 2020 +Ighalo d'àràbà! Góòlù àrámọ̀ndà ló fi gbẹyẹ lọ́wọ́ LASK fún Manchester United ní ìdíje Europa," Oríṣun àwòrán, Getty Images Bi ọmọ ẹni dara, ẹ jẹki a wi. Ẹlẹgan an nikan ni yoo sọ pe ẹlẹsẹ ayo Odion Ighalo n fakọyọ lọwọlọwọ fun ẹgbẹ agbabọọlu rẹ, Manchester United. Lẹyin awọn goolu to kọkọ gba sawọn ni kete to darapọ ẹgbẹ agbabọọlu Man U, Ighalo lo gba goolu akọkọ wọle fun Man U ninu abala kinni ''round of 16'' idije Europa ti wọn gba pẹlu ẹgbẹ agbabọọlu LASK. Aramọnda goolu ni goolu ọhun ti Ighalo fi ṣẹ awọn alatako leegun ẹyin lalẹ Ọjọbọ Ayo marun un sodo ni Man fi ṣagba LASK, Daniel James lo gba goolu keji sawọn nigba ti Juan Mata lo gbayo ẹlẹẹkẹta wọle ki Mason Greenwood ati Pereira to fi ọba lee Oríṣun àwòrán, Getty Images Ẹwẹ, ajọ UEFA ko gba ki awọn ololufẹ awọn ẹgbẹ agbabọọlu meejeji wọlẹ lati wo wọn nitori aarun coronavirus to n tan kalẹ kaakiri agbaye. UEFA wọ́gilé ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ Real Madrid àti Manchester City nítorí coronavirus Bi awada bi ere aarun coronavirus ti di ajakalẹ aarun kaakiri agbaye bayii, eyi to si ti mu ki awọn eeyan maa so ọpọ apejọpọ ati idije ere idaraya rọ. Ẹru atu itankalẹ aarun yii kan naa lo ti mu ki ajọ UEFA so abala keji ifẹsẹwọnsẹ idije Champions League laarin Real Madrid ati Manchester City rọ bayii. Ọjọ Iṣẹgun ọsẹ to n bọ lo yẹ ki Man City gbalejo ifẹsẹwọnsẹ ọhun tẹlẹ ki ajọ UEFA to wọgilee. UEFA wọgile le ere bọọlu lẹyin iyatọ gbogbo awọn agbabọọlu Real Madrid fun ayẹwo ki wọn le mọ bo ya wọn ti lugbadi aarun coronavirus. Ẹgbẹ agbabọọlu Man City lo jawe olubori ninu abala akọkọ ere bọọlu ọhun ni papa iṣere Santiago Bernabeu. Ami ayo meji si ẹyọkan ni Manchester City fi ṣagba Real Madrid ninu ifẹsẹwọnsẹ naa. Abala keji ifẹsẹwọnsẹ laarin Juventus ati Lyon naa to yẹ ko waye lọjọ kan naa ko ni waye mọ. Ìbòòsí o! Ìṣọwọ́ gbá bọ́ọ́lù Atletico kò tọ̀nà àmọ́ a gba ìjákulẹ̀ wa - Liverpool Alakoso fun ikọ agbabọọlu Liverpool, Jurgen Klopp ti n kawọ leri lori ilu bara ti alatako wọn, Atletico Madrid na wọn, to si ni nkan ko jọ ara wọn nipa ilana isọwọ gba bọọlu naa. Ninu ifẹsẹwọnsẹ naa to waye lọjọru, ni Atletico ti fakọyọ pẹlu ami ayo mẹta si meji, ti ireti ikọ Liverpool lati raga bo ipo asaaju rẹ ninu idije awọn akọni agbaabọọlu nilẹ Yuroopu, si fori sanpọn. Oríṣun àwòrán, Getty Images Ikọ Liverpool lo ti wọ asekagba idije naa lawọn saa meji ere bọọlu to kọja, ti Klopp si n figbe ta bayii pe isọwọ gba bọọlu Diego Simeon ti ikọ Atletico ko tọna. ""Inu mi ko dun rara si isesi wa, o nira lati kopa ninu iru ifẹsẹwọnfẹ yii, mo tiẹ n wa iru ọrọ ti maa fi se apejuwe rẹ. Wọn ko gba bọọlu bo se yẹ amọ wọn koju wa bo se yẹ."" Oríṣun àwòrán, Getty Images ""A ti gba kadara wa ati abajade ifẹsẹwọnsẹ ọhun amọ ko dun mọ wa ninu. Mo mọ pe n ko mọ baa se n gba ijakulẹ mọra, paapa nigba ti awọn ọmọ ikọ agbabọọlu mi saayan to pegede lati koju agba ọjẹ agbabọọlu meji lagbaye"". Waste to Wealth: Ẹ̀gbin tìrẹ ni èròjà táwọn èèyàn míràn fi n ṣiṣẹ́ ajé, okoòwò ńlá ni Ijakulẹ yii ni igba kẹrin ti ikọ agbabọọlu Livepool yoo fidi rẹmi ninu ifẹsẹwọnsẹ mẹfa ọtọọtọ amọ wọn si ni pọnti mẹẹdọgbọn lati wa loke idije liigi premier. Oríṣun àwòrán, Getty Images",12 Ẹrẹ̀nà 2020 +Coronavirus ti di àjàkálẹ̀ àrùn káàkiri àgbáyé- WHO," Oríṣun àwòrán, Getty Images Ajọ eleto ilera ni Agbaye, WHO ti pe arun Coronavirus ni ajakalẹ arun to n ja kaakiri agbaye. Alaga ajọ WHO, Dokita Tedros Adhanom Ghebreyesus ni iye awọn eniyan to ti lugbadi awọn arun naa ni awọn orilẹede miran yatọ si China ti peleke si ni ida mẹtala laarin ọsẹ meji. Tedros Adhanom Ghebreyesus ni oun ṣe oun laanu pe awọn eniyan ko i tii kọ ibi ara si ajakalẹ arun naa Oríṣun àwòrán, EPA . Ajakalẹ aarun tun mọ si pe arun naa n kaakiri orilẹede pupọ ni ẹẹkan naa. Amọ Tedros Adhanom Ghebreyesus ni pipe arun naa ni ajakalẹ aarun ko tu mọ si pe ko ni si ọna abayọ lati kapa aarun naa. Lati igba ti arun Coronavirus ti bẹ silẹ ni ilu Wuhan, lorilẹ-ede China lọdun 2019, ọpọloọpọ awọn eeyan lo ti lugbadi arun naa kaakiri agbaye. Bi arun naa ṣe n da ẹmi awọn eeyan legbodo na lo n fa idaduro si oriṣiriṣi awọn ayẹye, eto, ipade, ere idaraya atawọn nkan mii to yẹ ko waye. Iwọnyi ni awọn ohun to yẹ ko waye, ṣugbọn ti awọn ti ọrọ kan gbegile, tabi ṣe atunto rẹ nitori arun ọhun. Làá hàn mí: Ètò yìí ló ń kìlọ̀ fún wa láti mú ìmọ́tótó ní pàtàkì láti dènà Coronavirus Ọpọ ifẹṣewọnsẹ ere bọọlu ajọ Yuroopu, EPL, to yẹ ko waye ni wọn ti wọgile laipẹ yii, ti awọn alaboju ifẹsẹwọnsẹ naa pinnu pe ki diẹ lara ifẹsẹwọnsẹ naa waye lai si ero iworan. Fun apẹrẹ, wọn sun ifẹsẹwọnsẹ laarin ikọ Arsenal ati Manchester City to yẹ ko waye lọjọ kọkanla Oṣu Kẹta ọdun yii siwaju. Ni orillẹ-ede Italy, awọn alakoso ere bọọlu nibẹ, Italian Football Federation (FIGC) sọ lẹyin ipade kan pe, o ṣeṣe ki idije Serie A saa yii ma pari nitori arun naa. Ko tan sibẹ, ajọ to n ri si ere bọọlu lagbaye, FIFA sọ pe, o ṣeṣe ko sun awọn igbaradi fun idije bọọlu agabye, Qatar 2022 siwaju. Ni ti idije Olimpiiki to yẹ ko bẹrẹ loṣu keje ọdun 2020, awọn igbimọ to n risi eto na ti ni kaka ki wọn wọgile, niṣe ni wọn yoo jẹ ko waye laisi ero iworan, ṣugbọn ko ṣeni to mọ ohun ti le ṣelẹ. Oríṣun àwòrán, @habsonfloww Laarin ọsẹ yii ni ijọba Yuroopu wọgile gbogbo ohun to jẹ mọ ipade ita gbangba lati le dẹkun itankalẹ arun naa, koda, wọn gbẹsẹ le lilọ si ile ijọsin. Stolen phone: Fóònù mi ni mo lọ́ tún ṣe lọlọ́pàá bá he mí pé mo jí fóònù Lọjọ Aje, ọjọ kẹsan an oṣu yii ni ijọba Ireland wọgile iwọde ayajọ ọjọ St. Patrick to waye ni Dublin. Ọpọ ibi ni Germany, paapaa ni Berlin ni wọn ti wọgile awọn ohun to le mu ki awọn eeyan korajọ pọ soju kan naa, bi ile iworan tiata, ati bẹbẹ lọ. Oríṣun àwòrán, Getty Images Afihan ọkọ ayọkẹle ita gbangba to yẹ ko waye ni New York, lorilẹ-ede Amẹrika lọṣu Kẹrin ọdun 2020 naa ni wọn tun ti sun siwaju. Nilẹ Amẹrika, Sẹnatọ Bernie Sanders ati igbakeji aarẹ tẹlẹ, Jospeh Biden naa sun ipolongo idibo sipo aarẹ to yẹ ko waye lọjọ Kẹwa Oṣu Kẹta ọdun yii ni Ohio siwaju latari ibẹru arun Coronavirus. Ipade ajọ banki agabye ọlọdọdun to yẹ ko waye ni Washington ni wọn ti ṣatunto rẹ bayii. Awọn ti ọrọ kan ti wa wọrọko fi ṣada ni bi wọn ṣe gbe igbesẹ lati ṣe ipade naa lori itakun agbaye dipo ki wọn ṣe loju koju. Awọn ẹlesin Musulumi ti wọn ti n gbaradi lati goke Arafa lọdun yii ko le ni anfani ati ṣe bẹ nitori ọwọja arun Coronavirus yii kan naa. Laipẹ yii ni ijọba Saudi kede pe, wọn gbẹsẹle gbogbo irinajo okere si orilẹ-ede wọn fun igba diẹ titi ti arun ọhun yoo fi kasẹ nile. Fiimu James Bond kan ti awọn olotu rẹ lero pe yoo waye loṣu Kẹrin ọdun yii ni wọn ti sun siwaju. Sinima naa ti akọle rẹ n jẹ ""No time to Die"" ni wọn sun si Oṣu Kọkanla ọdun 2020 dipo Oṣu Kẹrin. Facebook love: Ọla àti Folashade ṣègbéyàwó lẹ́yìn ọjọ́ mọ́kànlá tí wọ́n ríra ni Facebook",11 Ẹrẹ̀nà 2020 +Àyẹ̀wò gbogbo irinṣẹ́ ètò ìlera ti di dandan báyìí lẹ́yìn ikú Chineme Martins- NFF," Ajọ to n ri si ere bọọlu ni Naijiriia, NFF ti sọ pe dandan ni ṣiṣayẹwo gbogbo irinṣẹ eto ilera awọn ẹgbẹ agbabọọlu bayi ki ifẹsẹwọnsẹ kankan to le bẹrẹ. Eyi waye lẹyin iku agbabọọlu Nasarawa United, Chineme Martins to di oloogbe nigba ti ifẹsẹwọnsẹ NPFL n lọ lọwọ pẹlu ẹgbẹ agbabọọlu Katsina United lọjọ Aiku. Ikọ agbabọọlu Nasarawa ko tii sọrọ lori iku ojiji adilemu wọn to ti ṣoju ikọ agbabọọlu naa nigba mẹrin ọtọtọ ni saa bọọlu yii. Minisita fun ere idaraya ati ọrọ ọdọ, Sunday Dare fi aidunnnu rẹ han loju opo Twitter rẹ nibi to ti sọ pe o ṣeeṣe ki Martins maa ku tawọn irinṣẹ eto ilera gidi ba wa ni papa iṣere ti iṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ. Minisita ranṣẹ ibanikẹdun si ẹbi agbabọọlu Martins to di oloogbe. Igba keji ree ti agbabọọlu yoo gbẹmi mi ni papa isẹre Nasarawa United niluu Lafia. Oríṣun àwòrán, others NFF, LMC Kwara United bá Nasarawa United kẹdun ikú Martins Agbabọọlu Kano Pillars, Dominic Dukudod subu ni papa isere kan naa ninu osu kejila odun 2018. Àwọn ọmọ Naijiria to ti kú lóri pápá lásìkò ìfẹsẹwọ́nsẹ Kòsi àniàni, eré ìdáraya bọọlù jẹ́ èyi tó gbàjúmọ jùlọ ni orílẹ-èdè Naijiria àti ní gbogbo àgbàyé, ọ̀pọ́ àwọn ènìyàn lo si máa n lọ wòràn. Sùgbọ́n o, bi àwọn ènìyàn ṣe n lọ wo bọọlu yìí ọjọ miran wà ti wọ́n maa n ri ohun ti kò dùn mọni nínú. Ìrú ìṣẹ̀lẹ̀ abaní nínú jẹ yìí lo wáye lána nígbà ti ọmọ agbábọọlu pẹlu Nasarawa United dédé súbú lulẹ to si gba ibẹ lọ si ọrun alákeji. Èyí ju ọ̀pọ̀ ọmọ Naijiria , àjọ NFF, LMC, ẹbi, ọ̀rẹ àti àwọn ọmọ ẹgbẹ àgbá bọọlu jákejádo Naijira sínú ọ̀fọ̀. Ẹ̀wẹ̀, èyí kìí ṣe ìgbà àkọkọ láàrin àwọn agbábọọlu Nàìjíríà ti agbá bọọlu yóò dédé kú lóri pápá. Àwọn agbábọ́ọ̀lù Naijiria to ti kú sórí pápá Samuel Okwaraji: Samuel Okwaraji kú lórí pápá lásìkò to n gbá bọọlu láti fun pegede ife àgbáye pẹlu Angola. Okwaraji kú ni ọjọ́ kejila, oṣù kẹjọ ọ́dun 1989. Ọ̀pọ̀ lo si n dáro Okwaraji titi di àsìkò yìí nítori o jẹ olókìkí to si mọ ere orí pápá náà gbá dáadaa. Oríṣun àwòrán, others Àwọn ọmọ Naijiria to ti kú lóri pápá lásìkò ìfẹsẹwọ́nsẹ Michael Umanika: Agbábọọlu Naijiria fún Zagatala PFK lo dójubolẹ lori pápá lásìkò ti wọ́n ṣe ìgbáradi láti lọ fun idíje. Wọ́n fún ra pe àìsàn ọkan lo pàá, òun náà kú ni ọjọ kẹẹdogun ọdun 2016 Oríṣun àwòrán, other Àwọn ọmọ Naijiria to ti kú lóri pápá lásìkò ìfẹsẹwọ́nsẹ Amir Angwe: Agbábọọlu Julus Berger náà kú lóri pápa lọ́dun 1995. Iròyìn ni pé, àisan ọkàn náà lo pa òun náà. Orí pápá ló ti subu ti oun náà si gba ibẹ̀ lọ, ọmọ ọdun mọkandinlọgbọ̀n ni lásìkò náà. Orobosan Adun: Kí wọ́n to lọ fún ìfẹsẹwọ́nsẹ pẹlú Enugu Ranger, àwọn ọmọta kan ti wọ́n fúra si pe o jẹ oloufẹ àwọn ẹgbẹ́ agbábọọlu ti wọ́n fẹ́ lọ bá gbá ti kọkọ ṣe ìkọlu si asọle ẹgbẹ́ agbábọọlu Warri Wolves (Adun). Asikò ìgbáradi lóri pápá ni Adun kú lẹ́yin ọjọ mẹta ìṣẹ̀lẹ̀ náà. O kú ni ẹni ọdun méjidinlọgbọ̀n, lọdun 2009. Azeez Saka: Lọ́dun 2017, okiki irú èyi náà tún kan nígbà ti ọmọ akọnimọọgba bọọlu ori tabili Kasali Lasisi ku. Saka jẹ ọmọ ẹgbẹ́ agbábọọlu Kwara United, o kú ni ori papa lásìkò ìgbáradi pẹlu àwọn akẹgbẹ́ rẹ ní ilú ìlọrin tii ṣe oluulu ipinlẹ Kwara. Oríṣun àwòrán, Other Àwọn ọmọ Naijiria to ti kú lóri pápá lásìkò ìfẹsẹwọ́nsẹ Emmanuel Ogoli: Ọmọ ẹgbẹ́ agbábọọlu Ocean Boys kan náà kú lori pápá, lásiko idije league, o si pada jẹ di oloogbe ni ilé iwosan. O ku ni ọjọ kejila osu kejila ọdub 2010 NFF, LMC Kwara United bá Nasarawa United kẹ́dùn ikú Martins Oríṣun àwòrán, others NFF, LMC Kwara United bá Nasarawa United kẹdun ikú Martins Àjọ NFF àti LMC ṣì n sọ̀fá ìkú adilé mú ọmọ ẹgbẹ́ agbabọolu Nasarawa United Chineme Martins. Alaga àjọ LMC, Shehu Dikko, nínú àtẹjáde kan to fi ba Nasarawa United àti ẹbi olóògbé náà kẹ́dun. Ọgá àgbà èré bọọlu òun ni àwọn yóò ṣe àyẹwò okú náà láti mọ irú ikú to pa Martins ni pàtó. Oríṣun àwòrán, Others NFF, LMC Kwara United bá Nasarawa United kẹdun ikú Martins ""A ní ìgbàgbọ́ pé tí a ba mọ irú ikú to pa a, ni yóòjẹ ki a lé mọ irú igbésẹ̀ ti a o gbé láti dẹkun irú ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀."" Ẹ̀wẹ̀, àjọ LMC ń wá ọ̀nà láti ni ìbáṣepọ ẹgbẹ́ agbábọọlù olóògbé àti àwọn ẹbi rẹ̀, láti le mọ ọ̀nà ti wọ́n yóò gbà ṣe ìrànwọ́ níru àsìkò aburu yìí Bákan náà ni àjọ NFF fi ẹdun ọkan rẹ̀ han fún ọmọ agbabọọlu ọ̀un lóri àtẹjiṣẹ́ twitter rẹ. Bakan náà ni àwọn ẹgbẹ́ agbábọọlu Kwara United náà ti kẹdun pẹlú Nasarawa United lori ikú Martins.",9 Ẹrẹ̀nà 2020 +Ó ṣe f'ọ́mọ tó n jeérú! Man U f'aṣọ iyì ya mọ́ Man City lára pẹ̀lú àmì ayò 2-0," Oríṣun àwòrán, Twitter/manchester united O ti di igba mẹta ọtọtọ ni saa yii ti Man U ti n digbaju ru Man City. Manchester City bẹrẹ idije naa daada, ṣugbọn wọn ko fi bẹ ẹ halẹ lawọn asiko ti bọọlu ba wa ni ikawọ wọn, ṣugbọn Manchester United ni tiẹ gboro pupọ. Agbabọọlu Man U, Anthony Martial lo kọkọ fi goolu sina iya fun Man City nigba ti idije naa wọ iṣẹju mọkandinlọgbọn. Man U tete gba ara wọn silẹ ninu ina ogun ti Man City kọkọ da ni ibẹẹrẹ idije naa, lati igba naa ni wọn si ti n ṣe daada nigba ti idije naa wa laarin iṣẹju mẹẹdogun si ogun isẹju abala akọkọ. Man U fi bọọlu kilọ fun Man City ni ẹẹmelo kan, ki wọn o to fi titete ronu gba bọọlu kan si awọn Man City. Lati igba ti Martial si ti gba bọọlu sinu awọn ni nkan ti n gbona janjan. Oríṣun àwòrán, Getty Images Botilẹjẹ pe Manchester City ja fita-fita, Manchester United papa tun gba bọọlu miran wọle lati ọwọ Scott McTominay, nigba ti idije naa wọ iṣẹju mẹrindinlọgọrun. Ni aṣọ iyi ba bọ patapata lara Man City, nitori igba kẹta niyii ti Man U na wọn ni saa yii. Oríṣun àwòrán, Getty Images/premier league Ode iya ni Everton lọ pẹlu bi Chelsea ṣe fi iya ajẹbolori ṣe wọn lalejo ni Stamford Bridge. Idije naa rọrun pupọ ju fun ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea. Everton ti faaye gba wọn ju. Abala akọkọ idije naa ko ti i de ibi kan to ti da bi i pe ode ko ni dara fun Carlo Ancelotti. Niṣe ni Chelsea fi ọ̀bẹ̀ goolu ge Everton wẹlẹwẹlẹ. Adilemu fun ẹgbẹ agbabọọlu, Jordan Pickford gọ ara rẹ, ko yara rara bi Mason Mount ọmọ ẹgbẹ agbọọlu Chelsea ṣe ya bara, to si gba bọọlu sinu awọn . Lo ba di ookan soodo nigba ti idije wọ iṣẹju mẹrinla. International Womens day: Àwọn obìrintọ́kasí pàtàkì ìbáraẹnidọ́gba láárin ọmọnìyàn Ha, adilemu Everton, Jordan Pickford ko tun ri nkankan 'piiki' o. Ṣe ni Pedro rọrọ pẹ 'omi Jordan' silẹ, to si gba bọọlu sinu awọn. Lo ba di meji soodo ni abala akọkọ idije naa. Oríṣun àwòrán, Getty Images Igba akọkọ ti Pedro yoo gba bọọlu sinu awọn niyẹn ni saa Premier League yii. Nkan i ba tun ṣẹnu're fun Chelsea nigba ti idije naa wọ iṣẹju mejidinlọgbọn. Kini Kurt Zouma n ro naa? O fi bọọlu silẹ fun Richarlison, to gba siwaju, to si paasi rẹ si Dominic Calvert-Lewin, ṣugbọn niṣe ni oun yi bọọlu roborobo lati ọna jijin. Lo ba ja sofo! Ode iya ni Everton lọ pẹlu bi Chelsea ṣe fi iya ajẹbolori ṣe wọn lalejo ni Stamford Bridge. Ko pẹ ti abala keji idije naa bẹrẹ ni William tun fi kun omije oju ẹgbẹ agbabọọlu Everton nigba to gba bọọlu sinu awọn. Oríṣun àwòrán, Getty Images Carlo Ancelotti ti fi igba kan jẹ olukọni Chelsea, ko da o gba ife ẹyẹ liigi naa pẹlu wọn Lọrọ Everton ba di ajẹkun iya ni o jẹ..., bi orin ẹnikan oke ọhun. Ko pe iṣẹju maarun ti William pa wọn lẹkun, ni Giroud tun bu iyọ si oju egbo adaa'jina wọn, ni Chelsea ba ni ami ayo mẹẹrin, ti odo si dagbada iya bọ Everton l'ọrun. Fẹran jẹkọ gbaa ni idije naa jẹ fun Chelsea.",8 Ẹrẹ̀nà 2020 +Israel Adesanya ti fi ẹ̀ṣẹ́ yanjú Romero," Oríṣun àwòrán, Getty Images Abẹṣẹkubiojo ọmọ Naijiria ni, Iṣrael Adesanya ṣi ni ẹṣin iwaju ti gbogbo tẹyin n wo sare ni ere idaraya ẹṣẹ ati ipa kikan, iyẹn UFC248 ni ipele middlewight. Israel Adesanya to jẹ ọmọ bibi ipinlẹ Ogun lorilẹede Naijiria fi agba han Yoel Romero ninu idajọ gbogbo awọn adajọ to mojuto ija naa. Ìròyin so pé láti igbà ti Yoel Romero ti n kopa nínú eré ìdaáraya abẹsẹ́ kù bi ojo, ko si ẹni to fi ojú rẹ̀ gbòlẹ̀ rìí, Sugbọ́n ní báyìí Isreal Adesanya fẹ́ tún ìtàn náà kọ. Bi o tilẹ jẹ wi pe ọpọ awọn onworan lo fẹhonu han pe ija naa ko dun bi awọn ṣe lero, sibẹ gbogbo awọn onidajs mẹtẹẹta to wa nikalẹ fun ija naa ni wọn gbe idajs kalẹ pe ọwọ Adesanya lo dun Romero julọ lasiko ija naa. Ninu ọrs to sọ lẹyin ija naa, Adesanya ṣalaye pe ija naa ko rọgbọ, ṣugbọn gbogbo ohun to yẹ ki oun ṣe lati bori ni oun ṣe. Oríṣun àwòrán, Getty Images Pẹlu ija yii, Adesanya ti ja ija mọkandinlogun, o si ti bori gbogbo rẹ. Nibayii, ti Romero ti kuro, ọna la fun ija laarin Adesanya to wa loke tente atẹ igbelewọn awọn akanṣẹ ni ipele Middlewieght, ija ẹṣẹ ati ipa kikan UFC248 lati koju Paulo Costa to wa ni ipo keji lori atẹ naa. Omidan jáde láyé lẹ́yìn tí ìlú lù ú, jáa sí ìhòhò lórí ẹ̀ṣẹ̀ tí kò ṣẹ̀ Pẹlu abajade ija naa, Romero ti padanu marun ninu ija mejidinlogun to ti ja, mẹtala ninu rẹ lo bori. O si tun yọju sita pe mẹrin ninu ija marun to ja sẹyin ni ṣisẹ-n-tẹle lo ti padanu bayii. Romero ni, ""nṣe lo kan n sare kaakiri oju agbo ija"" o fi kun un pe ija ajakuorogbo lawọn eeyan wa wo, ohun si ni wọn sanwo fun lati wo kaakiri agbaye.",8 Ẹrẹ̀nà 2020 +Israel Adesanya fẹ́ gbéná wojú Romero," Oríṣun àwòrán, Getty Images ǸJẹ́ ẹ̀yín mọ Adesanya tó ní òun yóò dá bàntẹ́ ìyà fún Romero? Sebi wọ́n ni ti òògun ẹni ba dáni loju, a maa fi n gbári ni, ọmọ yoruba míràn tún rèé nínú ere idara abẹsẹ kù bi ojo. Bẹẹ ni ọ̀rọ̀ ṣe ri bi Isreal Adesanya ṣe n sele ri pe ajẹku iya ni Yoel Romero yoo jẹ ninu idájukọ ti yóò wáye lola ode yiì. Ìròyin so pé láti igbà ti Yoel Romero ti n kopa nínú eré ìdaáraya abẹsẹ́ kù bi ojo, ko si ẹni to fi ojú rẹ̀ gbòlẹ̀ rìí, Sugbọ́n ní báyìí Isreal Adesanya fẹ́ tún ìtàn náà kọ. Obasanjọ: Ọbasanjọ ní òhun yóò fi ìyókù ayé òun san oore Ọlọrun ni Fadeyi Oloro: Ọfọ̀, àyájọ́ kò ràn án lọ́jọ́ tí 'ṣó o láyà' bá a lálejò Abẹsẹkubiojo Kiwi Middleweight fun UFC yoo koju Romero nínú ija oni pele marun ni Las Vegas ní ọla ode yìi, eyi ti yoo jẹ ijà akọkọ láti igba ti o ti doju Robert Whittaker boleẹ̀ninu oṣu kẹwàá ọdun to kọja, eyi túnmọ si pe ìpo Middleweight náà tọ si ti o ba na Romero Romero máà n fi ara rẹ han bi ẹni to le koko ti ko si si ẹni to le bori rẹ lati igba to ti yan iṣẹ́ náà láàyò. Ẹni ọdun méjilelogoji ọmọ Cuba oun kuna ri ni ẹ̀ẹ̀mẹta láti ọjọ to ti n dije, ẹ̀ẹ̀mta náà si rèé, igbimọ jòkó ni láti mọ ẹni ti wọ́n yoo gbe ade fún. Gbogbo èniyan lo mọ Romero fún bi o ṣe maa n ja ija tirẹ pẹlu ìwà ipa àti wáranwanran sise ""Kìí ṣe ẹni ti ẹnikẹni máà n fẹ́ bá ja"" Adesanya lo sọ eyi. "" Ìdí? ìdí ni pe mo ti ri ti wọ́n ti lùú, mo ri ti wọ́n daa dúro, mo ti ri bi ẹjẹ̀ ṣe bòo', mo ri nibi to ti n sunkún, ẹmi gan náà yóò mu sunkun, èèyan ẹlẹran ara bi ti gbogbo aye ni. "" mo fẹ́ lùú ni marun si odo, mo fẹ wẹ ki n yan kankan, ki n náà ni alubolẹ, bo ba le ku ko kú, ìyẹn kii ṣe isoro temi"" Adesanya pe Romero nija láti báa ja, nigbati àwọn alaṣẹ fori ko wọ́n ko fààye gba Paulo Coasta lati koju rẹ bákan náà nitori o farapa ni ọdun to kọja. Tani Isreal Adesanya? Isreal Mobolaji Temitayo, Odunayo, Oluwafemi Owolabi, Adesanya jẹ́ ọmọ Naijiria ti o n gbe Newzealand, ni Auckland, O jẹ́ abẹsẹku bi ojo, lọ́wọ́lọ́wọ́ àbẹ́ àdéhun Utimate Fighting Championship ló wà to si jẹ Middleweight Champions. A bi ni ọdun 1989 ni ìpínlẹ̀ Eko ni Naijiria, o si ni ẹgbọn ati aburo mẹrin Femi ni orukọ baba rẹ osi jẹ olusiro owo nígba ti iya rẹ Taiwo jẹ Nọoṣi, Isreal lo si ile iwe Chrisland School ni Opebi to si n kọ ẹkọ Takwando to ba kuro ni ile iwe, ọdun 2001 lo lọ si orilẹ̀-èdè Ghana pẹlu ẹbi rẹ ki wọ́n to lọ si Newzealand. O yà si idi iṣẹ́ to yàn láàyo nítori bi awọn akẹgbẹ rẹ se máà n dẹyẹ si ni kékére, o ti ja ni Honkong, Australia, àti China o si ti de ipele ti o gba 11-0 O wọ adéhun pẹ̀lú Utimate Fighting Championship ni ọdun 2017.",7 Ẹrẹ̀nà 2020 +"Àgunlá! Ohun tó bá wù yín ni kẹ sọ, iṣẹ́ ló ká mi lára - Ighalo"," Oríṣun àwòrán, @AfricaFactsZone Ohun ti ẹnikẹni ba sọ ko kan oun, bi ko ṣe ki oun gbaju mọ iṣẹ Atamatase ikọ Manchester United, Odion Ighalo ti ni, ọrọ ti awọn kan n sọ kiri lori igbeṣẹ oun lati darapọ mọ Manchester United ko tu irun kankan lara oun. Ighalo sọ pe ohun to ṣe pataki ni ki awọn ojugba oun gbagbọ ninu oun, gẹgẹ bi agbabọọlu to pegede. O ni ""Niwọn igba ti awọn akẹgbẹ mi, akọnimọọgba mi ati awọn ololufẹ mi ba lee gbagbọ ninu ipa ti mo le ko lori papa, temi ni lati maa ṣe ohun ti mo mọọ ṣe."" Ighalo tẹsiwaju pe ""Ohun ti ẹnikẹni ba sọ ko kan mi, afojusun wa ni Man United ni lati tẹsiwaju ninu saa bọọlu yii."" Ami ayo mẹta si odo ni Manchester United fi ṣeya fun Derby County ninu ifẹsẹwọnsẹ wọn to waye lọjọ Ọjọbọ, leyii ti Ighalo ti sọ bọọlu meji wọle ninu rẹ. Ọpọ awọn ololufẹ Manchester United kaakiri agbaye lo ti bẹrẹ si n jẹ ọrọ Ighalo lẹnu bi ẹni jẹ iṣu lẹyin aṣeyọri Manchester United ninu ifẹsẹwọnsẹ naa, papa julọ fun ipa to ko. Oríṣun àwòrán, @AfricaFactsZone Ighalo ni aṣẹyọri oun ni Manchester United ti fi han pe, oun kun oju oṣuwọn lati darapọ mọ ẹgbẹ agbabọọlu naa. Ni bayii, Ighalo ti sọ goolu mẹta sinu awọn ninu ifẹsẹwọnsẹ meji to ti kopa ninu rẹ lati igba to ti darapọ mọ ikọ ọhun ni Oṣu Kini, ọdun 2020. Ẹwẹ, akọnimọgba Manchester United, Ole Gunnar Solskjaer ti gboṣuba kare fun Odion Ighalo fun iṣe akin to ṣe lati sọ bọọlu sinu awọn Derby County nigba meji ọtọtọ ninu ifẹsẹwọnsẹ FA Cup ọhun. Aremu: Eré ìtàn nípa ìbí, àti jéèyàn pẹ̀lú ìpèníjà Olusegun Aremu Obasanjo",6 Ẹrẹ̀nà 2020 +''Kazeem ṣèlérí pé oun máa mú mi lọ ìlú òyìnbó k'àwọn SARS tó pá á''," Oríṣun àwòrán, @dabiodunMFR O ṣalaye pe ọmọ ọhun kii ṣe onijọgbọn, bẹẹ ni ki i ṣe ọmọ "" Yahoo."" Iya Tiamiyu Kazeem ti oṣiṣẹ ileeṣẹ SARS fa ṣababi iku rẹ nilu Sagamu ti sọ pe ogo ọjọ iwaju idile wọn ni ọmọ naa jẹ ko to di pe awọn ọlọpaa dẹmi rẹ legbodo. Arabinrin naa sọ fun ik iroyin BBC Yoruba to ṣebẹwo si ile wọn ni ilu Sagamu pe ọmọ rẹ ọhun ti ṣeleri oke okun fun oun ki iṣẹlẹ iku ojiji to de ba a. O ni ""Kazeem ti sọ fun mi pe ti oun ba ti ri ṣe daadaa nidi iṣẹ bọọlu pe oun maa mu mi lọ si oke okun."" 'Mo fẹ́ ìdájọ́ òtítọ́ àti òdodo lóríi ikú àìmọ̀dí tí wọ́n fi pa ọmọ mi' Iyaafin Tiamiyu sọ fun BBC pe ibanujẹ nla ati iṣẹlẹ manigbagbe ni iku ọmọ naa jẹ fun gbogbo ẹbi wọn lapapọ. O ṣalaye pe ọmọ ọhun kii ṣe onijọgbọn, kii ba eeyan ja ati pe kii ṣe oni jibiti ori ẹrọ ayelujara ti ọpọ mọ si ""Yahoo boy gẹgẹ bi awọn Ọlọpaa ọhun ṣe fi ẹsun kan an."" Oríṣun àwòrán, @Official3SC Iya ọmọ naa sọ siwaju sii pe Kazeem ni afojusun lati di araba nidi iṣẹ bọọlu gbigba to n ṣe ki awọn oṣiṣẹ SARS ọhun to ge ẹmi rẹ kuru. Mi ò kí ń ṣèèyàn burúkú tàbí Babalawo bí ẹ ṣe mọ̀ mí nínú eré - Fadeyi Oloro O ni ""ti Kazeem ba n wo ifẹsẹwọnsẹ bọọlu lori tẹlifisan, o ma n woye ọjọ iwaju rẹ, to si ma n sọ pe ibi giga ti oun n lọ niyẹn."" Iya Kazeem tẹsiwaju pe ""Gbogbo igba ti ọmọ mi ba lọ gba bọọlu ni mo ma n lọ wo ti papa iṣere naa ko ba jina ju, nitori o ma n jẹ iwuri funmi ti mo ba n wo o, ṣugbọn wọn ti gba ọmọ naa lọwọ mi."" Tiamiyu Kazeem ni ọkọ oju popo kọlu, leyi to yọri si iku rẹ lẹyin ti iroyin ni awọn ọlọpaa SARS ti i jabọ kuro ninu ọkọ wọn ni ọna Abeokuta-Sagamu lọjọ Satide. Ko to di oloogbe, Kazeem ni igbakeji balogun ikọ agbabọọlu Remo Stars to wa nipinlẹ Ogun.",26 Èrèlè 2020 +Ó lòdì s'òfin kí ọlọ́páà fìyà jẹ ẹnikẹ́ni tó bá wọ aṣọ ológun - Amofin," Oríṣun àwòrán, @others Amofin kan, Banjo Ayenakin ti sọ pe ọlọpaa ko lẹtọ labẹ ofin lati fiya jẹ ẹnikẹni ti wọn ba gbamu pe o wọ aṣọ ologun ti kii si n ṣẹ ọmọ ologun. Ayenakin lo sọ ọrọ naa fun BBC Yoruba lẹyin iku Tiamiyu Kazeem to ṣagbako iku lati ọwọ ẹka ileeṣẹ ọlọpaa SARS, ti wọn ni wọn fofin mu latari pe o wọ aṣọ ologun lai jẹ ọmọ ogun. O ni ""Ti ọlọpaa ba mu ẹnikẹni pẹlu aṣọ ologun, wọn ko laṣẹ lati fi iya jẹ iru ẹni bẹẹ tabi ki wọn lu."" Amofin ọhun tẹsiwaju pe o yẹ ki wọn fi pampẹ ofin mu ọlọpaa to ba lu eeyan nitori pe o wọ aṣọ ologun. Ṣugbọn amofin naa ṣalaye pe , gẹgẹ bi ofin ṣe gbe kalẹ, ẹni ti kii ba n ṣe ọmọ ologun ko ni aṣẹ lati wọ asọ ologun lorilẹ-ede Naijiria. O ni ""O lodi si ofin ati pe ijiya n bẹ fun ẹnikẹni ti ọwọ ofin ba tẹ pe o wọ aṣọ ologun ti ko si jẹ ọkan lara ọmọ ogun Naijiria. Ayenakin ṣalaye fun BBC Yoruba, ẹsẹ ofin to ni ṣe pẹlu iwa ọdaran, iyẹn ""Criminal code"" to sọ ijiya to wa fun ẹni to ba wọ aṣọ ologun. O ni ijiya to wa fun ẹni to ba wọ aṣọ ọmọ ogun laarin igboro ni pe yoo san owo itanran ẹgbẹrun meji tabi ko ṣewọn oṣu kan. Ṣugbọn ẹni to ba wọ aṣọ ọmọ ogun lati fi tan ara ilu jẹ pe ologunn ni oun ti ko si ri bẹẹ, yoo lọ si ẹwọn oṣu mẹfa. Fire Eater: Azonto ní àfojúṣùn òun ni láti lọ fi idán iná yìí pa owó lókè òkun Ẹwẹ, amofin naa sọ siwaju sii pe ẹni to ba wọ aṣọ ologun lati fi ṣe ere ori itage, tabi ẹni ti gomina tabi aarẹ ba fun ni aṣẹ lati wọ aṣọ naa ko lẹtọ si ijiya kankan labẹ ofin. Ayenakin pari ọrọ rẹ pe ofin ko faye gba ọlọpaa kankan lati fiya jẹ ara ilu nitori pe o wuwa ọdaran. O ni ofin faye gba ara ilu lati foju ba ile ẹjọ, ko si sọ tẹnu rẹ lori ohun ti wọn ba ka mọ lọwọ kaka ki ọlọpaa fi iya jẹ iru ẹni bẹẹ. Oríṣun àwòrán, @Official3SC Gomina ipinlẹ Ogun, Dapo Abiodun ti sọ pe gbogbo awọn to lọwọ ninu iku Tiamiyu Kazeem, to jẹ ọmọ ẹgbẹ agbabọọlu Remo Stars ti ipinlẹ Ogun ko ni lọ lai foju wina ofin. Kazeem di oloogbe lopin ọsẹ to kọja yii, lẹyin ti wọn ni awọn ọtẹlẹmuyẹ Special Anti-Robbery Squad, SARS lo fa ṣababi iku rẹ lopopona Sagamu si Abeokuta. Bo tilẹ jẹ pe ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe wọn ko lọwọ ninu iku arakunrin ọhun, ṣugbọn wọn ni wọn fi pampẹ ofin mu u nitori o wọ aṣọ ologun, ti kii sii ṣẹ ọmọ ogun Naijiria. Ṣugbọn ẹni ti ọrọ ọhun ṣoju rẹ sọ pe, awọn SARS mu Kazeem lẹyin ti wọn fẹsun jibiti ori ayelujara kan an, to si sọ fun wọn pe iṣẹ bọọlu gbigba ni oun n ṣe, ṣugbọn awọn ọlọpaa kọti ikun si aroye rẹ. Wọn ni igba ti wọn n gbe e lọ ninu ọkọ wọn ni wọn ti ti i lati inu ọkọ naa, to si ko sẹnu ọkọ mii to n bọ, leyi to mu ko jẹ Ọlọrun nipe. Oríṣun àwòrán, @dabiodunMFR Gomina Abiodun ti wa parọwa si awọn awọn ọmọ ikọ Remo Stars atawọn ọmọ ipinlẹ Ogun lati ma tẹ oju ofin mọlẹ nitori wọn n fẹ idajọ ododo fun arakunrin wọn to d'ologbe. Ninu atẹjade kan lati ọwọ agbẹnusọ rẹ, Kunle Somorin, Abidoun sọ pe ẹnikẹni lara awọn agbofinro ti aje ọrọ ọhun ba ṣi mọ lori yoo jẹ iyan rẹ niṣu. Gomina ọhun sọ pe ijọba yoo ṣe iwaadi finifini lori ọrọ naa lati mọ pato ọhun to ṣẹlẹ gan latari bi ọrọ ẹni ti ọrọ naa ṣoju rẹ ati ọrọ awọn ọlọpaa ṣe yatọ. Abiodun wa kẹdun iku ologbe naa, to si sọ pe ijọba rẹ ko ni fọwọ yẹpẹrẹ mu eto abo ẹmi ati dukia awọn eeyan ipinlẹ Ogun. Mother Language Day: Bàbá míì ní àìkọ́ ọmọ òun ní Yorùbá ló mú kò pàdánù iṣẹ́ olówó ńlá",24 Èrèlè 2020 +"Ẹ̀ṣẹ́ ju ẹ̀ṣẹ́ lọ! Tyson Fury d'ẹ̀ṣẹ́ bo Deontay Wilder lórí, ó gbadé WBC mọ́ ọ lọ́wọ́"," Oríṣun àwòrán, @peluu_lovers Tyson Fury ti fagba han Deontay Wilder lẹyin to na jati-jati ninu idije ẹṣẹ kikan to waye laarọ ọjọ Aiku, ni gbọgan MGM, to wa ni Las Vegas. Alubami ni Fury, to jẹ ọmọ orilẹ-ede Gẹẹsi lu Deontay, to jẹ ọmọ ilẹ Amẹrika ninu idije ife agabaye ọhun. Fury ni ẹni ti ọwọ rẹ moke ju ninu ija naa, igba keji si ree ti wọn yoo pade lori papa, ṣugbọn ninu abala keje ija ọhun lo ti fọ Wilder lẹnu tan patapata, ti onitọun ko si lee ta putu. Nnkan bi ọdun kan o le diẹ sẹyin ni wọn kọkọ pade, ṣugbọn awọn to n ri si ija naa ni ọmi ni wọn ta lọjọ naa lọhun. Eyi si mu ki wọn mu ọjọ ija mii, ti awọn afẹṣẹku bi ojo mejeji si ti n leri tantan mọra wọn lọpọ igba ti wọn ba pade. Lẹyin ija ọhun, ti wọn si kede Fury bi ẹni to moke julọ, lo gba igbanu gẹgẹ bi ẹni to le ja ẹṣẹ ju ninu idije WBC lagbaye, eyi ni WBC World Heavyweight. Oríṣun àwòrán, Getty Images Ibanujẹ ni Wilder fi kuro ni gbọgan MGM ti ija naa ti waye nigba to sọ pe ""Ẹni to lee ja ju lo bori, jagunjagun ni mi, ṣugbọn ko si awawi."" Ni ti Fury ni tirẹ, o sọ fun awọn oniroyin lẹyin ija naa pe ""Ọba ti pada bọ sori itẹ,"" lẹyin naa lo gboriyin fun Wilder pe iṣe lo ṣe. Cerebral Palsy: Ìyá Najeebah ní oyún oṣù mẹ́rin ààbọ ni wọn gbe jáde kúrò nínú òun O ni ""Mo fẹ gboriyin fun Deontay Wilder fun iṣe takuntakun to ṣe, o ja fitafita titi di abala keje ija ọhun, ṣugbọn ọba ti pada sori itẹ rẹ."" Ọpọlọpọ awọn ololufẹ ẹṣẹ jija ti bẹrẹ si ni fi erongba wọn lede lori ija naa, ti wọn si ti n ki Tyson Fury ku ori ire.",23 Èrèlè 2020 +Lampard àtàwọn agbábọ́ọ̀lù Chelsea dọ́wọ́jọ di ẹrù wíwo lé Mourinho àti Tottenham lórí," Oríṣun àwòrán, Getty Images Agbaọjẹ agbabọọlu Chelsea tẹlẹ, to ti di akọnimọọgba ẹgbẹ agbabọọlu naa bayii, Frank Lampard lo moke ninu ija oun ati ọga rẹ, Jose Mourinho ni papa iṣere Stamford Bridge lọsan ọjọ Satide. Atamọtaṣe, Olivier Giroud lo gbayo alakọọkọ wọle fun Chelsea nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa di iṣẹju mẹẹdogun. Lẹyin iṣẹju mẹta ti wọn bẹrẹ abala keji ere bọọlu ọhun ni adilemu, Marcos Alonso gba ayo keji sawọn Tottenham Chelsea. Nisẹ ni akọnimọọgba Tottenha, Jose Mourinho dori kodo lẹyin ti ọwọ iya ba ikọ agbabọọlu rẹ Tottenham Hotspurs. Ti ẹ ko ba gbagbe, Mourinho ti ṣe akọnimọọgba ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea fun igba meji ọtọọtọ. Amọ Eric Lamela to wọle da ayo kan pada eyi to jẹ ki ere bọọlu pari si ayọ meji si ẹyọkan.",22 Èrèlè 2020 +"Kò síbi tó dàbí ilé, tìlù-tìfọn ni wọ́n fi kí Anthony Joshua tó bẹ ìlú rẹ̀, Ṣágámù wò káàbọ̀"," Oríṣun àwòrán, CockFM Radio Ṣe awọn agba bọ wọn ni ọmọ ale ni fi ọwọ osi juwe ile baba rẹ. Gbajugbaja akanṣẹ lagbaye, Anthony Joshua bẹ ile wo lọjọru. Taara ta ilu rẹ ni Ṣagamu lo mori le, nibẹ lo si ti ṣe baba kẹẹ pẹ sawọn ọbalaye ati oriade gbogbo to wa nilu naa. Eyi ni igba akọkọ ti Anthony Joshua yoo maa yọju si orilẹede Naijiria lẹyin to gba igbanu ẹyẹ agbaye rẹ, WBA, WBO, IBF ati IBO pada lọwọ Andy Ruiz. Ọmọ orilẹede Mexico naa si lo gba ami ẹyẹ ọhun dani fun bi oṣu diẹ, nibi ija wọn to waye ni gbagede Diriyah Arena lorilẹede Saudi Arabia. Oríṣun àwòrán, CockFM Radio Ọkẹ aimoye awọn ololufẹ rẹ ni wọn rọgba yii ka lasiko to fi lọ ki Alafin Ẹlẹpẹ ati Akarigbo ti ilẹ Rẹmọ ni aafin wọn. Lẹyin to foribalẹ fawọn ọba alade naa tan, ni Anthony Joshua wa ya fọto pẹlu awọn ololufẹ rẹ ti wọn wa foju gaanni rẹ. Oríṣun àwòrán, CockFM Radio Ariwo 'ibi ni ile rẹ kii ṣe ilẹ Gẹẹsi' ni ọpọlọpọ awọn eeyan to tu sita wa wo agba ọjẹ akanṣẹ naa n pa, bi gbogbo wọn ṣe n da giiri lati baa ya fọto, ti wọn si tun wọ tọọ lẹyin lati aafin Elepe lọ si aafin Kabiyesi Akarigbo ti ilu Rẹmọ.",20 Èrèlè 2020 +"Barmasai ọmọ Kenya ṣe ipò kínní nínú eré ìje-gígùn ìlú Eko, ipò wo ni Sanwo-Olu gbà?"," Oríṣun àwòrán, Twitter/Lagos State Govt. Ọmọ orilẹede Kenya, David Barmasai lo gba ami ẹyẹ ipo kinni ninu ere eje-gigun ti ilu Eko ti ọdun 2020. Barmasai pari ere to le ni kilomita mejilelogoji laarin wakati meji ati iṣẹju mẹwaa. Ẹbun owo to le ni miliọnu mejidinlogun naira ni Barmasai yoo mu re 'le fun ipo kinni to gba ninu ere ọhun. Ọna ara ọtọ ni Barmasai ọmọ ilẹ Kenya gba jawe olubori ninu ere eje-gigun ọhun. Ẹwẹ, Gomina Babajide Sanwo-Olu naa wa lara awọn to kopa ninu ere eje-gigun naa to waye niluu Eko lọjọ Abamẹta, ọjọ kẹjọ oṣu keji ọdun 2020. Ninu isọri tawọn obinrin, Sharon Cherop ti oun naa jẹ ọmọ bibi ilẹ Kenya lo jawe olubori. Iye owo kan naa ni ọkunrin ọkunrin ati obinrin to jawe olubori ninu ere eje-gigun naa jọ gba. Eyi ni igba karun un ti ere eje-gigun yii yoo waye niluu Eko lẹyin ti alakọkọ iru rẹ waye lọdun 2016.",8 Èrèlè 2020 +"Odion Ighalo darapọ mọ́ ikọ̀ Manchester United, òjijì ló bá àwọn olólùfẹ́ rẹ̀"," Oríṣun àwòrán, Getty Images Ẹgbẹ agbabọọlu Manchester United ti fi ọrọ lede pe Odion Ighalo ti darapọ mọ ikọ ọhun. Eyii to tumọ si pe Ighalo ni ọmọ Naijiria akọkọ ti yoo gba bọọlu fun ikọ Manchester United. Ẹlẹsẹ ayo naa ni ikọ Man United n yalo lati ikọ rẹ tẹlẹ, Shanghai Greenland Shenhua to wa lorilẹ-ede China. Akẹgbẹ rẹ tẹlẹ ninu ikọ Supper Eagles, Mikel Obi ni ọmọ Naijiria akọkọ ti yoo tọwọ bọwe adehun pẹlu ikọ Man United, ṣugbọn ko gba bọọlu fun ikọ ọhun. Igahlo to ti jẹ olofẹ ikọ Manchester United tẹlẹ ni awọn adari ikọ naa lero pe yoo kopa ribiribi ninu awọn idije saa yii to n lọ lọwọ. Ṣaaju ni Igahlo ti n kopa ninu igbaradi pẹlu ikọ Shenshua fun saa tuntun, ṣugbọn saa naa ni idaduro nitori arun Corona to bẹ silẹ lorilẹ-ede China. Gẹgẹ bi iroyin ti Sky Sports fi lede, ikọ Tottenham naa ti gbiynaju lati fa ọmọ ọgbọn ọdun ọhun mọra, ṣugbọn o kuna. Ighalo bẹrẹ si ni di gbajumọ nidi iṣẹ bọọlu nigba to wa ni ẹgbẹ agbabọọlu Julius Berger ni Naijiria, ko to lọ si ikọ Udinese lorilẹ-ede Italy. Ki Ighalo to kuro ni ikọ Supper Eagles, oun ni ẹni to gba bọọlu to pọju sinu awọn ninu idije AFCON to waye lọdun 2019 pẹlu bọọlu meje. Nigeria's Under-19:Ẹ wo bí Ikọ̀ Cricket Naijiria ṣe mi àgbáyé titi Ọpọlọpọ awọn ololufẹ Ighalo lo ya lẹnu pe ""Red Devils"" buwọlu igbesẹ Ighalo yii pẹlu bi Man U ṣe jẹ ọkan lara awọn ẹgbẹ agbabọọlu to gbajumọ gan lorilẹede Naijiria. Kete ti wn gbọ ni wn fọn sori ayelujara lati da si ọr naa.",1 Èrèlè 2020 +Akànṣẹ́ àti alákòso Aṣẹ́wó, Ikọ ọtẹlẹmuyẹ Africa Eye tun de orilẹede Congo nibi to ti finmu finlẹ nipa igbe aye awọn ọdọbinrin ti wọn dagba soju popo. Fidio naa ree: Africa Eye: Ìrírí àwọn ọ̀dọ́bìnrin tó dágbà sójú pópó àti ìrètí wọn fún ọjọ́ ọ̀la,29 Sẹ́rẹ́ 2020 +Akànṣẹ́ àti alákòso Aṣẹ́wó, Ikọ ọtẹlẹmuyẹ Africa Eye tun de orilẹede Congo nibi to ti finmu finlẹ nipa igbe aye awọn ọdọbinrin ti wọn dagba soju popo.,29 Sẹ́rẹ́ 2020 +Ife ẹ̀yẹ kẹrìnlélógùn d'ète fún Serena Williams," Oríṣun àwòrán, Getty Images Ọrọ Serena Williams, agbabọọlu ẹlẹyin ori papa ati ilepa rẹ lati gba ife ẹyẹ idije lawn tennis Grandslam fun igba kẹrinlelogun tun ti dete. Wang Qiang, ọmọ orilẹede China lo bomi pana ala yii lẹẹkan sii nibi idije Australian Open to n lọ lọwọ. Serena Williams jẹ ọkan lara awọn odu elere idaraya Lawn Tennis ti itan agbaye ko lee gbagbe laye lẹyin awọn bẹbẹ loriṣiriṣi to ti gbe ṣe lere idaraya naa. Kí lo tíì rí nípa Amotekun? Ẹ sùnmọ́bí, ẹ wo gbankọgbì! Ẹ̀yin obìnrin tẹ́ẹ fẹ́ wá bímọ ní America, ọ̀nà ti tì pa látònì! - Trump Amọṣa, lẹyin to gba idije Australian open ni ọdun 2017, eyi to mu ki iye ife ẹyẹ grandslam to ti gba o jẹ mẹtalelogun lo ti n lepa ati gba ẹyọkan sii ko lee jẹ mẹrinlelogun ti yoo si sọ ọ di elere idaraya Lawn tennis to da gba ami ẹyẹ Lawn tennis to pọ julọ ninu itan lagbaye. Amọṣa, lati igba yii wa ni o ti n ba ijakulẹ pade. Lẹni ọdun mejidinlogoji, ireti ọpọ nigba ti idije Australian open ti ọdun 2020 bẹrẹ ni pe ilakaka Serena Williams yoo so eso rere ki o to di pe o pade Wang Qiang ọmọ orilẹede China ni ipele kẹta idije naa. Wang gbo ewuro soju Serena eleyi to jẹ ipele to ya ju ti Serena ti jabọ ni idije Lawn Tennis lati ọdun mẹrinla sẹyin ti o ti ja kulẹ ni ipele yii kan naa nigba to koju Daniela Hantuchova. Williams ti kọkọ fẹyin Wang gbolẹ ni idije US open ni osu kẹsan ọdun to kọja ki Wang to wa gba ẹsan rẹ bayii",24 Sẹ́rẹ́ 2020 +"Láì rọ lápa rọ lẹ́sẹ̀, ẹ wo ọmọ ọdún mọ́kànlá tó ń lọ́ ara lóríṣi ọ̀nà"," Ọmọde ni ara rẹ rọ to yii. Ọmọ ọdun mọkanla ni Fopefoluwa Ayo-Oyalowo to tete mọ iru ẹbun ti Ọlọrun fun un to si n mu u lo lati majesin. Latigba to ti wa ni ọmọ ọdun marun lo ti mọ pe oun ni ẹbun naa. ""Bí mo bá ti jí, tí mo pàrọ̀ aṣọ, máà gbé orin sí i, iṣẹ́ lílọ ara bẹ̀rẹ̀ nìyẹn"". Ọmọ to n ko ọmọ alainile kuro lori titi Ọmọdé mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n gbòmìnira nílé ayédèrú ọmọ òrukàn tíjọba tì pa 'Ọjọ́ mẹ́fà lọ́sẹ̀ ni mo fi ń gbáradì láti tayọ àwọn ẹlẹgbẹ́ mi táá jọ ń wẹ odò' 'Àwón òbí míì n fi ọmọ wọn ṣe òwò ní Naijiria’ Fayemi fojú Alufa to fipa bá ọmọde lòpọ̀ síta l'Ekiti Fopefoluwa ni nigba ti oun lọ wo ori ayelujara fun fọnran awọn to ti di gbajugbaja ninu iru ohun to yan laayo yii, o pinu lọkan ara rẹ pe oun le ṣe ohun ti wọn n ṣe daadaa. O ni ""Soffie Dossie, gbajugbaja to n lọ ara ni awokọṣe mi"". Lori awọn obi to maa n pa ina ẹbun amutọrunwa mọ awọn ọmọ wọn lara, Fopefoluwa sọ ọrọ iṣiti fun wọ.",23 Sẹ́rẹ́ 2020 +Ẹ wo bí Ikọ̀ Cricket Naijiria ṣé mí àgbáyé titi, Ikọ agbabọọlu ere alafigigba ta mọ si Cricket lọrilẹede Naijiria ti ni o da bi ala loju awọn pẹlu bi awọn ṣe pegede lati kopa ninu idije Ife Agbaye Cricket fun igba akọkọ. Lorileede South Africa ni idije fawọn ọjẹwẹwẹ ti ọjọ ori wọn ko ju ọdun mọkandilogun lọ naa ti o ti gbera sọ lọjọ kọkanlelogun oṣu kini ti n waye. Balogun Ikọ naa lasiko to n ba BBC sọrọ ni idunnu ati ayọ lọ jẹ fun awọn pe awọn ṣe aṣeyọri latyi kopa ninu idije naa bi o tilẹ je pe awọn eniyan ko fi taratara gba ti ere idaraya ọhun. Naijiria yoo ma a koju ikọ Australia ninu ipele akọkọ fun idije agbaye naa. Peter Aho to ṣẹṣẹ pe ẹni ọdun mẹrindinlogun lo gba bọọlu wọnu awọn ti wọn fi bori ifẹsẹwọnsẹ ti wọn fi jawe olubori patapata. Awọn ọmọ ikọ Agbabọọlu Cricket Naijiria ni awọn sa ipa awọn ki awọn le jẹ iwuri fun ikọ ojẹwẹwẹ to n bọ lọna. Wọn fi kun pe awọn ni igbagbọ pe awọn eniyan yoo bẹrẹ si ni fẹran lati ma a wo ẹrẹ bọọlu Cricket naa bi wọn ti ṣẹ fẹran ẹrẹ bọọlu afẹsẹgba.,21 Sẹ́rẹ́ 2020 +Ọ̀pọ̀ èrò ló máa ń bẹ̀ mí pé kí ń má lọ pa ara mi- Ọmọtọshọ, Ọpọ igba ni mo ti ṣubu sẹyin- Omotosho Samson Samson Omotosho ti ọpọ maa n pe ni Super Touch Roller Blader ṣalaye fun BBC pe iṣubu oun maa n kọ oun lẹkọọ sii nipa ere idaraya ti oun yan laayo ni. Ati tọmọde-tagba ni oun maa n da lẹkọ lori ere idaraya naa ni Naijiria. Samson Ọmọtọṣọ mẹnuba oriṣi ẹka ere idaraya 'Skating' to wa lasiko yii ati awọn igbesẹ inu ṣiṣe wón. Bakan naa lo sọrọ lori bi Baba ati Iya rẹ ṣe gba kamu lori ọrọ naa ti wọn si n pese atilẹyin to yẹ fun oun. Produced by: Joshua Akinyemi,19 Sẹ́rẹ́ 2020 +Màá ra Arsenal ní 2021 tí mo bá kọ́ iléeṣẹ́ ìfọ́po rọ̀bì tán - Dangote," Oríṣun àwòrán, Twitter/Arsenal Ọrọ gbajugbaja oniṣowo, Aliko Dangote ati rira ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal ti wa di igbin tẹnu mọ igi bayii. Dangote to jẹ ẹni to lọrọ julọ nilẹ Afirika ti n sọ tipẹ pe oun nifẹ lati ra ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal. Gẹgẹ bi ololufẹ ikọ Arsenal fun ọjọ pipẹ, Dangote soju abẹ niko loni lori eto kan pe ọdun 2021 loun yoo ra Arsenal bayii. Dangote ni kete ti oun ba ti kọ ile iṣẹ ifọ epo rọbi to tobi julọ lagbaaye ti oun n kọ lọwọ tan loun yoo ra Arsenal lọdun 2021. Nnkan ko fara rọ laarin awọn ololufẹ Arsenal ati alaṣẹ ikọ agbabọọlu naa, Stan Kroenke lọwọlọwọ. Tipẹ tipẹ lawọn ololufẹ Arsenal ti n sọ pe ki Ọgbẹni Kroenke ta ikọ agbabọọlu naa fun ẹlomiiran nitori wọn ko fẹran bi o ṣe n dari rẹ. Ipo kẹwaa ni Arsenal wa lori tabili idije liigi ilẹ Gẹẹsi(Premier League), lẹyin ti Mikel Arteta di akọnimọọgba tuntun lẹyin ti Unai Emery kuro tan. Ẹwẹ, ọpọ awọn ololufẹ Arsenal ni iroyin yii dun mọ, niṣe ni wọn n sọ loju opo ayelujara Twitter pe ki Dangote tete wa ra ẹgbẹ agbabọọlu naa.",13 Sẹ́rẹ́ 2020 +Serena Williams gba ife ẹ̀yẹ àkọ́kọ́ láàrin ọdún mẹ́ta sẹ́yìn," Oríṣun àwòrán, Getty Images Serena Williams na Jessica Pegula ni Auckland pẹlu 6-3; 6-4 Ife ẹyẹ akọkọ ni yii ti Serena Williams maa gba laarin ọdun mẹta. O na Jessica Pegula ninu idije to waye ni Auckland pẹlu ami ayo Mẹfa si mẹta ati mẹfa si mẹrin. Lati ọdun 2017 ti Serena Williams ti bi ọmọbinrin rẹ Alexis Olympia ni o ṣẹṣẹ gba ife ẹyẹ rẹ akọkọ. Eyi ni ife ẹyẹ nla miran to tun gba lẹyin Grand Slam to gba ni Rome ni 2016 ati Australian Open to gba ni 2017 ko too bimọ. Lẹyin idije yii ni oun ati ọrẹ rẹ Caroline Wozniacki ajọ dije ẹlẹni meji nibi ti wọn ti le jawe olubori ninu idije Auckland Tennis Center. Trump picture: ọjọ́ tí Trump kí mi kú iṣẹ́ lórí 'twitter' ní inú mi dùn jù- Oyedele Awọn mejeeji a koju Asia Muhammed ati Taylor Townsend ninu idije naa lọjọ Aiku. Oju Serena Williams to jẹ ẹni ọdun mejidinlogoji naa wa lara gbigba ife ẹyẹ Margaret Court 24 ti Australia to jẹ Grand Slam ẹlẹni kan ṣoṣo. Eduardo: Mo ń jí mọ́tò pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ mi nítorí pé mo fẹ́ di 'Big boy'",12 Sẹ́rẹ́ 2020 +"Akẹgbẹ́ mi méjì kú, ọ̀pọ̀ farapa lọ́wọ́ agbébọn, orí ló yọ mi - Adebayor"," Oríṣun àwòrán, Getty Images Ọjọ buruku eṣu gbomi mu, oni ọjọ kẹjọ oṣu kinni ọdun 2020 lo pe ọdun mẹwaa tawọn agbebọn kan kọlu awọn agbabọọlu ilẹ Afirika lorilẹede Angola. Awọn ti ori ko yọ ninu iṣẹlẹ naa, ninu eyi tawọn kan ti di ero ọrun, ṣe iranti bi iṣẹlẹ ọhun ti ṣẹlẹ lapa ẹkun Cabinda lorilẹede Angola. Akọroyin BBC, Matthew Kenyon naa ṣe iranti bi ikọlu naa ṣe mu ẹmi awọn agbabọọlu orilẹede Togo meji lọ. Kenyon ni lẹyin tawọn agbebọn kọlu ọkọ tawọn ẹgbẹ agbabọọlu Togo wa ninu rẹ, loun ṣe ifọrọwanilẹnuwo pẹlu agbẹnusọ ikọ naa, tii ṣe Emmanuel Adebayor, to n ṣoju ikọ agbabọọlu Manchester City nigba naa. O ṣalaye pe, ti ibẹru-bojo ni Adebayor fi n sọ ohun to sẹlẹ ṣawọn agbabọọlu Togo, koda Adebayor sọ ninu ifọrọwanilẹnuwo naa pe, ẹru ṣi n ba oun lẹyin tawọn akẹgbẹ rẹ meji ṣagbako iku ninu ikọlu naa. Oríṣun àwòrán, Other Junior Senaya to jẹ ọkan lara awọn agbabọọlu fikun ọrọ Adebayor pe, ninu ọkọ lawọn wa tawọn n gbọ orin, ṣadeedee lawọn bẹrẹ si ni gbọ iro ibọn ninu igbo. ''Ka to wi, ka to fọ, wọn yinbọn pawọn akẹgbẹ wa ti a jọ wa ninu ọkọ, nibi ti gbogbo wa ti mọ pe ewu n bẹ loko longẹ niyẹn,'' Senaya lo woye bẹẹ. Kodjovi Obilale, to jẹ aṣọle nigba naa kan ṣadeedee ri pe oun ti fara gbọta, loju ẹsẹ lo rii pe ẹjẹ bẹrẹ si ni da lati ikun ati ẹsẹ oun mejeeji. Obiulale ni lẹsẹkẹsẹ loun bẹrẹ si ni ke pe ''ẹ gbami, ẹ gbami, ọta ibọn ti ba mi, mo fẹ ri ọmọbinrin ati ọmọkunrin mi, mi o fẹ ku sibi.'' Igbakeji akọnimọọgba fẹgbẹ agbabọọlu Togo, Amelete Abalo naa figbe ta pe ọta ibọn ba oun, Amelete pada ku lẹyin ti ọta ibọn ba a tan. Adebayor ranti pe, fun bi ọgbọn iṣẹju lawọn janduku naa fi n dabọn bo ọkọ tawọn wa ninu rẹ, lai le kuro loju kan naa. Adebayor ni iṣẹlẹ naa jẹ ọkan lara awọn manigbagbe iṣẹlẹ to buru ju to ṣẹlẹ s'oun laye.",8 Sẹ́rẹ́ 2020 +Siasia bẹ̀bẹ̀ ìrànwọ́ N100m lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà láti ṣejọ́ jìbìtì tí FIFA fi kàn án," Oríṣun àwòrán, Twitter/Samson Siasia Ẹ rànmí ìrànwọ́ pẹ̀lú N100m láti ṣejọ́ jìbìtì tí FIFA fi kàn mi Akọnimọọgba ẹgbẹ agbabọọlu Naijiria, Super Eagles, Samson Siasia ti bẹ bẹ iranwo to to ọgọrun un miliọnu naira lati fi ṣe ẹjọ lori ẹsun riba ti ajọ FIFA fi kan an. Loṣu kẹwaa, ọdun 2019 ni ajọ FIFA fẹsun kan Siasia pe o gba lati tẹwọ gba riba lati ṣe eeru ninu awọn ifẹsẹwọnsẹ kan to ti waye sẹyin. Siasia ni oun ti gbiyanju agbara oun lati wa owo ti yoo fi ṣe ẹjọ naa nile ẹjọ to n ri si awuyewuye to ba jẹyọ nibi ere bọọlu afẹsẹgba lagbaaye. Ṣugbọn awọ ko tii ka oju ilu nitori ọgọrun un miliọnu kii ṣe owo ọmọde owo. Siasia tun ti wa kepe ijọba apapọ atawọn ẹlẹyinju aanu ọmọ Naijiria pe ki wọn ran oun lọwọ pẹlu owo ki oun le yọ orukọ oun ninu ẹsun jibiti ti wọn fi kan oun. Ajọ FIFA fofin de Siasia pe ko gbọdọ ni ohun kankan ṣe mọ pẹlu ere bọọlu, amọ o ni oun ko mọwọ, bẹẹ ni oun ko mẹsẹ lori ọrọ naa. Trump picture: ọjọ́ tí Trump kí mi kú iṣẹ́ lórí 'twitter' ní inú mi dùn jù- Oyedele Siasia to wa lara awọn agbabọọlu Naijiria to gba ife ẹyẹ ilẹ Afirika lọdun 1994 lorilẹ-ede Tunisia, sọ pe lori ayelujara loun naa ti gbọ ẹsun ti ajọ FIFA fi kan oun gẹgẹ bi ọpọ ọmọ Naijiria naa ṣe rii. LASU Ritual: Àwọn akẹẹgbẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ LASU tí wọn fi ṣowó sọ̀rọ̀ lórí ìgbé ayé olóògbé Siasia ni: Mo kan ṣadeedee gba ipe lati ọdọ ọwọ aarẹ ajọ NFF to n dari ere bọọlu ni Naijiria ninu eyi to ti bi mi leere boya mo ti ri lẹta lati ọdọ FIFA, Oríṣun àwòrán, Twitter/Samson Siasia O ni lẹyin naa loun ri lẹta ọhun ninu ẹrọ agbọrọkaye oun ṣugbọn Siasia sọ pe oun ko mọ nnkankan lori ẹsun ti wọn fi kan oun. Yatọ si pe ajọ FIFA fofin de Siasia, ajọ naa tun ni ko san owo itanran bi miliọnu mejidinlogun naira. Igbẹjọ naa yoo waye lọjọ kọkandinlogun oṣu kẹta ọdun yii niluu Lausanne, lorilẹede Switzerland. Dambe fight: ìdíje ìjà láàrin àwọn akóni tó n ja ẹ̀ṣẹ̀",8 Sẹ́rẹ́ 2020 +C. Ronaldo fi góòlù mẹ́ta bẹ̀rẹ̀ ọdún 2020," Oríṣun àwòrán, Getty Images Ogbontagi agbabọọlu ọmọ orilẹede Portugal, Christiano Ronaldo ti fi goolu mẹta ṣẹwọ ninu ọdun tuntun. Ronaldo tun rọjo goolu gẹgẹ bi iṣe rẹ pẹlu goolu mẹta nibi ifẹsẹwọnsẹ ẹgbẹ agbabọọlu Juventus pẹlu Cagliari ni liigi Serie A. Igba akọkọ niyi ti Ronaldo yoo gba goolu mẹta wọle ni ifẹsẹwọnsẹ kan naa lati igba to ti dara pọ mọ Juventus lọdun 2018. Oun ni agbabọọlu akọkọ ti yoo gba goolu mẹta wọle ninu ifẹsẹwọnsẹ kan ṣoṣo ni liigi mẹta ọtọọtọ lagbaye, iyẹn liigi ilẹ Gẹẹsi (Premier league), liigi orilẹede Spain (la liga) ati liigi ilẹ Aguda, orilẹede Italy (Serie A). oun yii kan naa si tun ni agbabọọlu to gba goolu mẹta wọle ninu ifẹsẹwọnsẹ kan naa julọ lagbaye. ifẹsẹwọnsẹ mẹrindinlọgọta ọtọtọ ni Ronaldo ti gba goolu mẹta wọle, eleyii ti ko si agbabọọlu miran to tii dan iru bẹbẹ bẹ wo. Oríṣun àwòrán, Getty Images Kii ṣe tuntun mọ pe ifigagbaga wa laarin Ronaldo ati Messi toun pẹlu jẹ odu agbabọọlu lagbaye. Ni kete ti ifẹsẹwọnsẹ naa pari si ni awọn ololufẹ awọn mejeeji ti n waako lori ikanni ayelujara gbogbo. Bi awọn ti Ronaldo ko ṣe fẹ wọn ọn kun, lawọn ti Messi naa ko fẹ gba a laabọ.",6 Sẹ́rẹ́ 2020 +Van Persie gbàgà lẹ́nu rẹ! Solskjaer fárígá lẹ́yìn tí Van Persie ló ń rẹ́rìn-ín," Oríṣun àwòrán, Other Bi oju akata ba lewo, ẹnu adiẹ kọ la o ti gbọ. Bayii ni akọnimọọgba Manchester United, Ole Gunnar Solskjaer ṣe fesi si ọrọ ti ẹleṣẹ ayo tẹlẹ ri fun ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal ati Man U, Robin van Persie. Van Persie lo bu ẹnu atẹ lu bi Solskjaer ṣe n rẹrin lasiko ti o n dahun ibeere awọn akọroyin lẹyin ti Arsenal ṣina iya fun Man U tan. Van Persie kii ṣe asiko ti ẹgbẹ agbabọọlu Man U ṣẹṣẹ fidi rẹmi tan lo yẹ ki Ole maa rẹrin nigba to n dahun ibeere awọn akoroyin. Amọ ọrọ yii ko bọ si ibi to dara lara Ole, nisẹ lo tutọ soke to si fi oju gba a. ''Mi o mọ Van Persie ri, oun naa ko si mọ mi, nitorinaa Van Persie ko lẹtọọ lati ma tako ọna ti mo n gba dari ikọ Man U,'' Solskjaer lo sọ bẹẹ. Solskjaer tun tẹsiwaju, o ni ''Van Persie gba aṣo igbabọọlu oun to ni nọmba ''20'', ohun kan to maa ri gba lọwọ mi niyẹn.'' Ọrọ yii ti di iṣu ata yan-an yan-an loju opo Twitter nibi ti ọpọ ti bẹrẹ si ni fi Ole ati Van Persie we ara wọn nigba ti wọn gba bọọlu fun ikọ Man U. Awọn ni Van Persie dantọ ju Ole lọ nigba to fi ṣoju ẹgbẹ agbabọọlu Man bo tilẹ jẹ pe akoko to lo ko to ti Ole. Ọbẹ Ẹgusi sise ati jijẹ #Queen Dihya: Obinrin tó gbógun tàwọn agbésùnmọ̀mí ni Algeria Amọ, awọn mii fi aake kọri, wọn ni Ole kii ṣẹgbẹ Van Persie ni gbogbo ọna pẹlu ohun nla to gbe ṣe nigba to wa ni Man U. 2020: Ọdun 2020 yii ko nìí nira fún àwọn tó bá bẹ̀rù Olorun",4 Sẹ́rẹ́ 2020 +"Marlian, òfégè ìgbéyàwó Buhari, Fatoyinbo àtàwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ńlá tó mi ìgboro tìtì ní 2019"," Oríṣun àwòrán, OTHER Oriṣiriṣi iṣẹlẹ apanilẹrin, arikọgbọn, ibẹru, ati bẹẹbẹ lọ lo ṣẹlẹ ni orilẹede Naijiria ni ọdun 2019. Eyi ni akojọpọ diẹ lara awọn iṣẹlẹ naa. Gbajugbaja ayaworan, to tun jẹ iyawo gbajugbaja akọrin, Timi Dakolo, Busola Dakolo, fi ẹsun kan pasitọ ijọ Commonwealth of Zion Assembly, Biodun Fatoyinbo, ninu ifọrọwanilẹnuwo kan pe o fi ipa ba oun lopọ lọdun diẹ sẹyin. Lẹyin awuyewuye tó tẹle ifòròwanilẹnuwo naa, pasitọ ọhun ti ni oun yoo gba ile ẹjọ lọ lori ọrọ naa. Fatoyinbo ni, irọ pọnbele ni ẹsun Busola Dakolo, ati wi pe yatọ si iṣẹ oun gẹgẹ bii pasitọ, oun ko ba arabinrin naa ni nkankan pọ ni ikọkọ oun ko si fi ipa ba obinrin kankan lo pọ ri. Ẹsun naa gba gbogbo ori ayelujara kan, ṣugbọn Fatoyinbo ni oun ko fipa ba obinrin kankan lo pọ ri. Awọn ọmọ Naijiria kan sẹ iwọde lọ si ile ijọsin COZA ni Abuja, Eko, ati Port Harcourt Ninu fidio ifọrọwanilẹnuwo naa, Busola ni igba ti oun wa ni ileewe girama, ni oun kọkọ pade Fatoyinbo ni Ilorin, Ipinlẹ Kwara, nigba to ṣẹṣẹ bẹrẹ ijọ COZA. O sọ ninu ẹsun rẹ ti fidio Y! NaijaTV gbe sita wi pe, igba meji ọtọọtọ ni pasitọ naa fipa ba oun lo pọ. Niṣe ni awọn ọmọ Naijiria kan tu jade ti wọn si fi ẹhonu han lọ si awọn ẹka ijọ COZA ni Eko ati Port-Harcourt. to fi mọ ti Abuja. Wọn pe fun ifipo silẹ Fatoyinbo. AWỌN IROYIN TẸẸ LE NIFẸ SI NIPA RẸ Ìlú tí ọ̀daràn bá tí dẹ́ṣẹ̀ ló yẹ kí wọn tí gbẹjọ́ rẹ̀ -Agbẹjọ́rò Ọkọ mi kò le f'ipá bá ẹnikẹ́ni lò pọ̀ láíláí - Modele Fatoyinbo COZA: Mi ò fípá bá obìrin lò pọ̀ rí láyé mi - Pásítọ̀ Fatoyinbo ‘Ilé ẹjọ́ kò gbé ẹ̀sùn ìfipánílòpọ̀ yẹ̀wò, à ń lọ sí ilé ẹjọ́ - Busola Dakolo Agbẹjọro fun Busola Dakolo ti ni awọn n gbe Biodun Fatoyinbo lọ si ile ọjọ kotẹmilọrun lẹyin ti ile ẹjọ da ẹjọ ifipanilopọ to pe naa danu. ------------------------------------------------------------ Igbeyawo ofege laarin Aarẹ Muhammadu Buhari ati Hajiya Sadiya Umar Farouq Oriṣiiriṣi aworan ati akọle to pani lẹrin lo kun ori ayelujara ni eyi ti awọn eniyan fi n ṣeto ipalẹmọ igbeyawo ofege ti wọn ni o yẹ ko waye laarin Aarẹ Muhammadu Buhari ati Hajiya Sadiya Umar Farouq. Oríṣun àwòrán, @others Lẹyin to ti hande pe iroyin ẹlẹjẹ ni igbeyawo aarẹ Buhari ti awọn eeyan n pariwo lori ayelujara; sibẹ ọpọ aworan to panilẹrin fun ipalẹmọ lo kun ayelujara bayii Ṣaaju ni iroyin ẹlẹjẹ ti gba ori ayelujara pe eto igbeyawo naa yoo waye laarin minista tuntun fun Abojuto lori ọrọ Ijamba ati Igbayegbadun ọmọniyan lorilẹ-ede ati aarẹ Naijiria. AWỌN IROYIN TẸẸ LE NIFẸ SI NIPA RẸ Taló ya fídíò ibi tí Aisha Buhari ti ń bínú ní Aso Rock? Ìròyìn nípa ìyàwó túntún fún ọkọ mi kò mì mí lọ́kàn rárá-Aisha Buhari Èrò yapa ní mọ́ṣáláṣí Jimọ̀h láti wá fójú lóúnjẹ lórí ìgbéyàwó òfegè Buhari. Koda, wọn ṣe idasilẹ 'hashtag #BUSA2019' fun eto igbeyawo irọ naa. Ti ọpọlọpọ aworan apanilẹrin nipa 'igbeyawo naa' si kun ori ayelujara. Ninu gbogbo iṣẹlẹ iroyin igbeyawo ofege Aarẹ Buhari yii ni fidio kan ti n tan kalẹ pe wọn ti ti Aisha Buhari mọle ninu ile ijọba ni Abuja. Ṣugbọn ileeṣẹ aarẹ sọ wi pe irọ ni iroyin igbeyawo naa. --------------------------------------------------------------------------------------------------------------- Naira Marley rẹwọn he, o gba ipo kinni lori Google Trend Afeez Fashola ti ọpọ mọ si Naira Marley jẹ gbajugbaja akọrin takasufe lorilẹede Naijiria. Lọwọ ti a wa yii, Naira Marley ti fẹẹ di oriṣa akunlẹbọ fun ọpọlọpọ awọn ọdọ. Wo àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó mú Naira Marley di òrìṣà àkúnlẹ̀bọ ní 2019 Oríṣun àwòrán, Naira Marley/twitter Iroyin ti o jadi laipẹ yii sọ pe oun ni ọmọ Naijiria ti awọn eeyan ṣe afẹri rẹ ju lọ loju opo Google lọdun 2019. AWỌN IROYIN TẸẸ LE NIFẸ SI NIPA RẸ Ta ni Naira Marley jẹ́ gan? Ìgbẹ́jọ́ Naira Marley sún síwájú bí àwọn agbẹjọ́rò ṣe ń jà sí àga ìjókòó Kí ló dé tí Ilé ẹjọ́ sún ìgbẹ́jọ́ Naira Marley sí ọ̀la? 'Soapy', àwo orin tuntun Naira Marley tó ń milẹ̀ tìtì Ọgbà ẹ̀wọ̀n ni Naira Marley yóò ti wo ìbúra Buhari ní May 29 Naira Marley gba ipò mọ́ Atiku lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí èèyàn tí wọ́n ń wá jùlọ ní Google lọ́dún 2019 Ni oṣu karun ọdun 2019 ni akọrin ara, Simi pariwo sita lori ikanni ayelujara lati koro oju si bi awọn ọdọ ṣe n kan si agbami iwa jibiti ori ayelujara. Eyi si fa itahunsira laarin oun ati Naira Marley. Naira Marley koju ija si Ruggedman Kii ṣe Simi nikan ni Naira Marley ba wọ iya ija lori ọrọ boya jibiti ori ayelujara, yahoo-yahoo tọna paapaa julọ lẹyin orin 'Am I a yahoo boy?' to gbe sita. Ọkan lara awọn odu asọrọdorin lorilẹede Naijiria, Ruggedman pẹlu sọ si ọrọ naa ninu eyi to ti ni ko dara ki awọn olorin, gẹgẹ bi awokọṣe lawujọ o maa gbe lẹyin awọn oni yahooyahoo. Eyi ko dun mọ Naira Marley ninu, o si fi esi ọrọ kobakungbe ranṣẹ sii lori ayelujara. Koda awọn ololufẹ Naira Marley kan tilẹ kọlu Ruggedman ni ilu Gẹẹsi lori ọrọ yii gẹgẹ bi iroyin ṣe sọ. Ni ọjọ kẹwa oṣu karun un ọdun 2019 lawọn oṣiṣẹ ajọ EFCC mu Naira Marley niluu Eko. Ẹsun mọkanla ni wọn fi kan an eyi to da lori gbigbimọ pọ lati huwa ibi, ninu ayederu kaadi igbawo lọwọ pẹlu iwa jibiti. Lẹyin to lo ọpọlọpọ ọsẹ ni ọdọ awọn ajọ EFCC ni ile ẹjọ gba oniduro rẹ. Lati igba ti ọrọ igbẹjọ rẹ naa ti bẹrẹ lo si ti di gbajugbaja ni aarin awọn ọdọ, paapaa julọ awọn to rii gẹgẹ bii ẹni to n ja fun awọn ọdọ nitori aarin awọn ọdọ ni yahoo-yahoo pọ si julọ. Ariwo Marlian! Marlian !! lo gbode kan bayii. ------------------------------------------------------------------------------------------------------------------ Oríṣun àwòrán, @trafficwaka Laipẹ yii ni ija bẹ silẹ laarin oṣerebinrin meji naa, Toyin ati Liz. Ija ọhun bẹrẹ ni igba ti Lizzy Anjorin fi fidio kan sita l'oju opo instagram rẹ, nibi ti o ti fi ọpọlọpọ eebu ranṣẹ si Toyin. Ọrọ naa da awuyewuye silẹ ti Toyin si sọ pe oun fi ọrọ yii lọ agbejẹro rẹ, Legal House Solicitors. AWỌN IROYIN TẸẸ LE NIFẸ SI NIPA RẸ Niṣe ni awọn ololufẹ awọn oṣere mejeeji ọhun gbe ọrọ ija naa ru sori. Lẹyin eyi ni awọn agba ọjẹ ninu iṣẹ oṣere nilẹ Yoruba bii Mr Latin, Jide Kosọkọ àti Mama Rainbow sọrọ lori ija naa, wọn si gbiyanju lati dasi i. ---------------------------------------------------------------------------------- Erongba abẹṣẹ ku bi ojo ọmọ ile Gẹẹsi ati Naijiria, Anthony Joshua, lati fi irawọ kun irawọ rẹ nilẹ Amẹrika ja si pabo ni ibẹrẹ ọdun 2019. Oríṣun àwòrán, Getty Images Joshua to ti gba ami ẹyẹ to ga ju lagbo ere idaraya ẹṣẹ kikan lagbaye lẹẹmẹta ọtọọtọ fidirẹmi, to si jẹ iya ajẹbolori lọwọ ẹni ti ko to o, Andy Ruiz lasiko ti wọn koju ara wọn ni Madison Square Garden. AWỌN IROYIN TẸẸ LE NIFẸ SI NIPA RẸ Ẹẹmẹrin ọtọọtọ ni Ruiz fi ẹsẹ kan Joshua mọlẹ lai le dide. Eyi lo si mu ko gba ami ẹyẹ nla mẹta, World Boxing Association, International Boxing Federation and World Boxing Organization. Ṣugbọn nigba ti wọn tun jọ pada ja ninu oṣu Kejila, Anthony Joshua gba igbanu ogo rẹ pada lẹyin to bori Andy Ruiz ninu idije ẹṣẹ kikan to waye ni lu Riyadh ni Saudi Arabi. Ka ma gbagbe, iṣẹlẹ kan wa to ti bẹrẹ si ni gbode lati bii oṣu melo sẹyin ni ilu Akurẹ ipinlẹ Ondo ni ijọ Sotitobire Miracle Centre nibi ti ọmọ ọdun kan, Gold ti dede poora titi di akoko yii. Lẹyin ọpọlọpọ iṣẹlẹ alatamọ to ti rọ mọ eyi, Pasitọ ijọ naa ṣaa ti wa latimọle titi di dun to mbọ bayii. AWỌN IROYIN TẸẸ LE NIFẸ SI NIPA RẸ Sotitobire church: Àwọn ọ̀dọ́ ilu dáná sun ilé ìjọsìn Akure Kidnap: E túbọ̀ ní sùúrù, a máa wá ọmọ náà rí- Alukoro ọlọ́pàá Sotitobire church: Àwọn ọ̀dọ́ ilu dáná sun ilé ìjọsìn ---------------------------------------------------------------------------------------------------------------- Iṣẹlẹ miran to tun mi igboro Naijiria ni ti fidio iwadii ikọkọ kan ti BBC Africa Eye ṣe lori awọn olukọ fasiti to maa n beere fun ibalopọ lọwọ awọn akẹkọọ obinrin, ki wn o to o fun wọn ni maaki gidi. Africa Eye: Olùkọ́ méjì ní fásitì Eko àti Ghana lùgbàdì ọ̀fíntótó BBC lórí ìwà ìbàjẹ́",29 Ọ̀pẹ̀̀ 2019 +Orí yọ èèyàn mẹ́ta nínú ilé tí ọkọ̀ bàálù dédé já wọ̀," Àfi kí elédúwà máa kó wa yọ lọ́wọ́ bí ọkọ bàálù ṣe máa ń já káàkiri àwọn orílẹ̀èdè. Baalu ere idaraya ni, o ti sun mọ papakọ ofurufu Danbury Municipal to fẹ balẹ si ni Connecticut, USA. Ni batiiri ọkọ baalu ba kọ iṣẹ to si doju kọ orule ile kan lẹba ibi to n lọ. Ile naa ko jina si papakọ ofurufu to fẹ ba si rara. Nigba ti batiiri ọkọ baalu bẹrẹ iṣẹ kiṣẹ lo ba ya si inu ile naa. Lara awọn to wa ninu ile naa, eeyan kan fara pa. Iroyin si sọ pe awakọ baalu naa ko fara pa pupọ. Ìdí tí mo fi gún olólùfẹ́ mi tẹ́lẹ̀ pa - Jacinta Igboke Ìjọba korò ojú sí bí Islamic State ṣe bẹ́ àwọn Kristiẹni mẹ́wàá lórí ní Bornu Ṣé ẹ ti gbọ́ ọ̀rọ̀ lẹ́nu Wolii Sọtitobire fúnra rẹ̀? ọ̀rọ̀ rèé lẹ́nu ọlọ́rọ̀!",28 Ọ̀pẹ̀̀ 2019 +Chelsea kò rọ́wọ̀ mú lẹ́yìn tí Southampton dáná sun Stamford Bridge," Oríṣun àwòrán, Getty Images Southampton dáná sun Stamford Bridge pẹ̀lú àmì ayò 2-0 Ikọ Southampton fẹyin Chelsea gbolẹ nile wọn ninu idije Premier League to waye lonii. Iya ti Chelsea jẹ lonii ko ṣẹyin akitiyan Micheal Obafemi ati Nathan Redmond ninu ifẹsẹwọnsẹ naa to waye ni papa iṣere Stamford Bridge. Micheal Obafemi lo kọkọ dana sile Chelsea ninu abala kini ifẹsẹwọnsẹ naa. Ninu abala keji ifẹsẹwọnsẹ ọhun ni Redmond naa sọ goolu tirẹ sinu awọn. Bo tilẹ jẹ pe Chelsea ṣe bi okunrin, to si gbiyanju lati ri ẹyin awọn Southampton, ṣugbọn ko lee ta putu. Christmas & Border Closure: ìrẹsì dí góòlù fún Kérésì 2019 Ni bayii, ikọ Chelsea ti wa ni ipo kẹrin lori tabili lẹyin to n tẹle Manchester City lẹyin. Police Brutality: Ojú mi rí tó lọ́wọ́ ọlapàá nítorí Múrí màrùn ún- Adebayo Olaide",26 Ọ̀pẹ̀̀ 2019 +Inú mi dùn láti darapọ mọ́ ikọ̀ Arsenal -Mikel Arteta," Oríṣun àwòrán, Getty Images Arteta ti sẹṣẹ gẹgẹ bi adari labẹ Pep Guardiola ni Manchester City Ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal ti kede Mikel Arteta gẹgẹ bi akọnimọgba rẹ tuntun. Ninu adehun iṣẹ naa, Arteta yoo dari ikọ Arsenal fun ọdun mẹta ati aabọ. Idunu ati ayọ ni Arteta fi gba iṣẹ naa to si sọ pe ""O jẹ iyi nla fun mi lati dara pọ mọ ikọ Arsenal."" O tẹ siwaju pe ""Inu mi dun nitori Arsenal jẹ ọkan lara awọn ẹgbẹ agbabọọlu to tobi ju lagbaye."" Arteta ti n ṣe iṣẹ tẹlẹ gẹgẹ bi adari labẹ Pep Guardiola ni Manchester City lẹyin to darapọ mọ ikọ ọhun lọdun 2016. Ọmọ ọdun mẹtadinlogoji naa ti fi igba kan ṣe iṣẹ ni ikọ Arsenal yii ati ikọ Everton ri. Awọn adari ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal ko tii kede awọn ti yoo ba Arteta ṣeṣẹ. Ankara Design: Ai ri oníbara ló jẹ́ kí n wá ọ̀gbọ́n àtinúdá tèmi.",20 Ọ̀pẹ̀̀ 2019 +"Kamaru Usman, Ọmọ Naijiria f'ẹ̀ṣẹ́ gba ìgbànú ẹ̀yẹ mọ́ Covington lọ́wọ́ ní ìdíje UFC"," Oríṣun àwòrán, Getty Images Bii bara ni abẹṣẹkubiojo ọmọ orilẹede Naijiria, kamaru Usman lu Colby Covington ti wọn jọ koju ija lowurọ ọjọ aiku lati ṣi wa nipo to ni akọle rẹ, welterwwight ni idje UFC 245. Ija naa waye ni gbagede T-Mobile Arena ni Las Vegas, orilẹede Amẹrika. Laarin idije ija naa, bi Colby ṣe n ta a ni Kamaru n gbakuru mọ ọ koda o tun fi ẹṣẹ fọ Colby leyin isalẹ ti gbogbo oju rẹ si kun fun ẹjẹ. Sekinat Quadri ọmọ ọdun meje ajẹsẹ to fẹ dabi Anthony Joshua Lati idaji ni gbogbo eniyan lori ayelujara ti n reti ohun ti ija yii yoo bi. Ni bayii, Kamaru náà ni yóò tún jẹ́ ọmọ Afíríkà àkọ́kọ́ tó fẹ̀ṣẹ́kùbíòjò gbaigbanu ẹyẹ idije Ultimate Fighting Championship. Ni kete ti Covington could barely stand to listen to Usman's victory speech, charging out of the Octagon to the back as soon as the Nigerian's hand was raised. But even in defeat, ""Chaos"" established himself as one of the greatest fighters on the planet with an excellent display that will surely still see his stock rise. It was an extremely close fight that could have gone either way had it gone the distance, as both men met in the middle of the Octagon and traded blows from start to finish, eschewing their world-class wrestling abilities in favour of an all-out brawl. But Covington's fortunes changed when Usman broke his jaw at the end of the third round with a hard right.",15 Ọ̀pẹ̀̀ 2019 +"Láéláé! Messi kọ́ ni agbábọ́ọ̀lù tó dára jùlọ nínú ìtàn, Ronaldinho yarí"," Oríṣun àwòrán, Instagram/Ronaldinho Ọrọ yii dabi ẹni pe ko ni tan nilẹ bọrọ. Ọpọ lo ti n sọ pe aramọnda agbabọọlu Barcelona ati Argentina, Lionel Messi ni agbabọọlu to dara julọ ninu itan. Bakan naa, ọpọ ni wọn ko gba pe Messi ni agbabọọlu to dantọ julọ lagbaaye. Agbabọọlu Brazil tẹlẹ ri orilẹede Brazil to jẹ akẹgbẹ Messi ni ikọ Barcelona, Ronaldinho wa lara awọn to gbagbọ pe Messi kọ ni agbabọọlu to dantọ julọ ninu ere bọọlu. Laipẹ yii ni Messi gbami ẹyẹ Ballon D'or nilẹ Faranse fun igba kẹfa, amọ Ronaldinho t'oun naa gbami ẹyẹ Ballon d'or lọdun 2005 sọ pe oun ko le pe Messi ni agbabọọlu to dara julọ lagbaaye ninu itan. Ronaldinho ni idunnu lo jẹ fun oun pe Messi gbami ẹyẹ Ballon fun igba kẹfa loṣu yii amọ agbabọọlu bi Pele, Maradona, ati Ronaldo ko le jẹ ki sọ wi pe Messi lo dara julọ ninu itan. ""Ohun ti mo le sọ ni pe Messi lo dantọ julọ laarin gbogbo awọn agbabọọlu to wa lasiki tirẹ,'' Ronaldinho lo woye bayii. Cristiano Ronaldo lo ṣi keji lẹyin ti oun naa ti gba ami ẹyẹ Ballon d'or fun igba marun un.",13 Ọ̀pẹ̀̀ 2019 +Òkété ti bórù! Manchester United fọ́ Manchester City lẹ́nu pẹ́tẹpẹ̀tẹ mọ́lé," Oríṣun àwòrán, Getty Images Igba la a ni ẹnikan ko le lo ile aye gbo, bayii lọrọ ri fun ẹgbẹ agbabọọlu Manchester City ti ife ẹyẹ idije Premier League wa lọwọ wọn. Orogun wọn ti wọn jọ wa niluu kan naa, Manchester United lo fiya ajẹtun iya jẹwọn lairo tẹlẹ nile wọn. Marcus Rashford lo gbayo alakọkọ wọle fun Man United nigba ti ẹrọ VAR fun wọn ni pẹnariti. Ere bọọlu mọ Man City loju nigba ti Anthony Martial gba goolu keji sawọn Man City, lo ba ayo meji sodo ti wọn fi n siwaju wọn. Oríṣun àwòrán, Getty Images Nicolas Otamendi dayo kan pada, amọ ẹpa ko boro mọ fun Man City. Esi ifẹsẹwọnsẹ yii jẹ iyalẹnu fun ọpọlọpọ awọn ololufẹ ere bọọlu nitori ko si ẹni to le pe Man U le na Man City mọ le. Àkọ́já ewé akọ́nimọ̀ọ́gbá fìdíhẹẹ́ Everton, ìyà ló bádé fún Chelsea Ilẹ n yọ gbe Chelsea ṣubu yakata ni Goodison Park ti ṣe papa iṣere Everton Ẹgbẹ agbabọọlu Everton ṣẹṣẹ le akọnimọọgba wọn Marco Silva lọ ni, ki wọn to yan Duncan Ferguson gẹgẹ bi akọnimọọgba fidihẹ. Oríṣun àwòrán, Getty Images Iyalẹnu lo jẹ pe iṣẹju marun un ti wọn bẹrẹ ifẹsẹwọnsẹ naa ni Richarlison gbayo kan wọle Chelsea lairo tẹlẹ. Ka to wi, ka to fọ, Dominic Calvert-Lewin gbayo keji sawọn Chelsea lẹyin iṣẹju mẹrin ti ipele keji ere bọọlu naa bẹrẹ. Mateo Kovacic dayo kan pada fun Chelsea, amọ Calvert-Lewin gbayo kẹta wọle fun Everton, ni okote ba bo niru fun Chelsea. Lẹyin ọ rẹyin, ami ayo mẹta sẹyọkan ni Everton fi gbo ewuro soju Chelsea",7 Ọ̀pẹ̀̀ 2019 +DJ Cuppy gbóṣùbà ràbàndẹ̀ fún Anthony Joshua ṣáájú ìjà rẹ̀ pẹ̀lú Andy Ruiz," Oríṣun àwòrán, Instagram/Cuppy Oni lonii jẹ, ẹni a bẹ lọwẹ. Lalẹ oni ni abẹṣẹ ku bi ojo ọmọ bibi orilẹede Naijiria to n ṣoju ilẹ Gẹeṣi yoo maa ta kaungbọn pẹlu alatako rẹ, Andy Ruiz Jr niluu Riyadh lorilẹede Saudi Arabia. Awọn mejeeji ti n leri leka lati ọjọ yii wa, koda awọn alatilẹyin wọn naa ko gbẹyin nipa lileri ṣaaju ọjọ oni. Ọkan lara awọn ololufẹ AJ ni olorin takasufe, ọmọ Naijiria, DJ Cuppy. Cuppy sọrọ loju opo Instagram rẹ, ẹrẹ pe ni gbogbo igba ni lawọn ọkan mimọ maa n bori, iyẹn ni pe Joshua lọka mimọ. Niluu Riyadh ti ija naa yoo ti waye nilẹ Larubawa ni Cuppy ti fọrọ yii lede loju opo Instagram rẹ. Mo ṣetán láti kojú Andy Ruiz ni Saudi lọ́jọ́ Sátidé- Anthony Joshua Ọjọ nii pẹ, ipade kii jina. Ọla ọjọ keje oṣu kejila ọdun 2019 ni atunja ija laarin Anthony Joshua ati Andy Ruiz Jr yoo waye lorilẹede Saudi Arabia. Ṣaaju ija ọhun, gbajugbaja, abẹṣẹ ku bi ojo, Joshua ti sọ pe oun ti gbaradi fun ija ọjọ Abamẹta. Joshua tun ni ilumọọka abẹṣẹ ku bi ojo to ti fẹyin ti, Wladimir Klitschko tiẹ gba oun ni imọran pe k'oun ma ṣe lo ẹrọ ibanisọrọ rara ti ija naa yoo fi waye. Oríṣun àwòrán, Instagram/Anthony Joshua Ẹ o ranti pe Ruiz Jr ya agbado ha si ọpọlọpọ lẹnu nigba to lu Joshua bi ẹni n lu bara nigba ti wọn kọkọ koju ara wọn niluu New York, lorilẹede Amẹrika. Nigba naa ni Joshua padanu bẹniti rẹ mẹtẹẹta to ko kalẹ nibi ija naa. Amọ Joshua to gba ami ẹyẹ wura fun ilẹ Gẹẹsi ninu idije Olympics lọdun 2012 ti n ṣe igbaradi pẹlu awọn abẹṣẹ ku bi ojo miiran ṣaaju ija rẹ pẹlu Ruiz Jr. Koda Joshua sọ pe oun ko ni dunnu ti oun ba jawe olubori ninu ija ọjọ Abamẹta. Mike Tyson ti oun naa ti fẹyin ti kilọ pe afaimọ ki ẹru ijakulẹ ninu ija akọkọ maa mu Joshua padanu lẹẹkan si ni Saudi. Bi Joshua ti n leri leka naa ni Ruiz Jr ko dakẹ, O ni digbi loun n duro de Joshua ninu ija ọjọ Satide.",7 Ọ̀pẹ̀̀ 2019 +Mo ṣetán láti kojú Andy Ruiz ni Saudi lọ́jọ́ Sátidé- Anthony Joshua," Oríṣun àwòrán, Instagram/Anthony Joshua Ọjọ nii pẹ, ipade kii jina. Ọla ọjọ keje oṣu kejila ọdun 2019 ni atunja ija laarin Anthony Joshua ati Andy Ruiz Jr yoo waye lorilẹede Saudi Arabia. Ṣaaju ija ọhun, gbajugbaja, abẹṣẹ ku bi ojo, Joshua ti sọ pe oun ti gbaradi fun ija ọjọ Abamẹta. Joshua tun ni ilumọọka abẹṣẹ ku bi ojo to ti fẹyin ti, Wladimir Klitschko tiẹ gba oun ni imọran pe k'oun ma ṣe lo ẹrọ ibanisọrọ rara ti ija naa yoo fi waye. Oríṣun àwòrán, Instagram/Anthony Joshua Ẹ o ranti pe Ruiz Jr ya agbado ha si ọpọlọpọ lẹnu nigba to lu Joshua bi ẹni n lu bara nigba ti wọn kọkọ koju ara wọn niluu New York, lorilẹede Amẹrika. Nigba naa ni Joshua padanu bẹniti rẹ mẹtẹẹta to ko kalẹ nibi ija naa. Amọ Joshua to gba ami ẹyẹ wura fun ilẹ Gẹẹsi ninu idije Olympics lọdun 2012 ti n ṣe igbaradi pẹlu awọn abẹṣẹ ku bi ojo miiran ṣaaju ija rẹ pẹlu Ruiz Jr. Koda Joshua sọ pe oun ko ni dunnu ti oun ba jawe olubori ninu ija ọjọ Abamẹta. Mike Tyson ti oun naa ti fẹyin ti kilọ pe afaimọ ki ẹru ijakulẹ ninu ija akọkọ maa mu Joshua padanu lẹẹkan si ni Saudi. Bi Joshua ti n leri leka naa ni Ruiz Jr ko dakẹ, O ni digbi loun n duro de Joshua ninu ija ọjọ Satide.",6 Ọ̀pẹ̀̀ 2019 +Manchester United ré Mourinho àti Tottenham lẹ́pa lórí pápá Old Trafford," Oríṣun àwòrán, Getty Images Papa iṣere Old Trafford yeruku lala lẹyin ti Tottenham ati manchester United tutọ sira wọn loju ninu ifẹsẹwọnsẹ Premier League to waye lalẹ Ọjọru. Manchester United rii wi pe ipadabọ wa Jose Mourinho si papa iṣere Old Trafford, iya lo ba de. Lẹyin iṣẹju mẹfa ti ere bọọlu ọhun bẹrẹ ni Marcus Rashford gbayo alakọkọ sawọn fun Manchester United eleyi to mu Man U wa niwaju. Man U gbiyanju lati gbayo keji wọle, amọ Deli Alli sọ ere bọọlu ọhun di ọmi alayo kọkọkan. Ẹlẹsẹ ayo Rashford tun fakọyọ kete ti wọn bẹrẹ ipele keji ifẹsẹwọnsẹ naa lẹyin to gba pẹnariti wọle Tottenham eleyi to mu ki Man U pada maa siwaju. Ológìnní t'àjò dé...Mourinho padà sí Manchester United lónìí! Oni lonii jẹ ẹni a bẹ lọwẹ. Lalẹ Ọjọru ni gbajugbaja akọnimọọgba Jose Mourinho yoo pada si papa iṣere ẹgbẹ agbabọọlu Manchester United nibi to ti ṣiṣẹ ki wọn to fọwọ oṣi juwe ile fun un lọdun 2018. Amọ ikọ agbabọọlu Tottenham ni Mourinho n ko o lọ koju Man United lọtẹ yii lẹyin to gbaṣẹ akọnimọọgba ẹgbẹ agbabọọlu naa ni kopẹ kopẹ yii. Oríṣun àwòrán, Getty Images Ẹgbẹ agbabọọlu Tottenham ti jawe olubori ninu ifẹsẹwọnsẹ mẹta ti wọn gba ninu idije Premier League lati igba ti Mourinho ti rọ pe Mauricio Pochettino gẹgẹ bi akọnimọọgba Spurs. Koda ipo Tottenham ti gberu si lori tabili idije Premier League, ipo kẹfa ni wọn wa bayii lẹyin ti wọn fakọyọ ninu ifẹsẹwọnsẹ mẹta ti wọn gba sẹyin. Awọn agbabọọlu Tottenham gan an ti mọ pe igba ọtun ti de, agbabọọlu bi Dele Alli ti ina ere bọọlu rẹ ti n jo ajo rẹyin tẹlẹ ti sọji bayii. Ipo kẹfa ni Man U wa ki wọn to da Mourinho duro lẹnu iṣẹ, ṣugbọn ipo kẹwaa ni wọn wa bayii labẹ aṣẹ akọnimọọgba tuntun, Ole Gunnar Solskjaer. Ọmi alayo meji meji ni Manchester United ta pẹlu Aston Villa ninu ere bọọlu ti wọn gba kẹyin lọjọ Aiku.",4 Ọ̀pẹ̀̀ 2019 +"Messi ló gb'àmì ẹ̀yẹ Ballon D'or lóòtọ́ọ́, àmọ́ Ronaldo ló dára jùlọ (GOAT)- Mendes"," Oríṣun àwòrán, Instagram/cristiano Lootọọ ni aramọnda agbabọọlu Lionel Messi gba ami ẹyẹ Ballon D'or fun igba kẹfa bayii, ṣugbọn aṣoju orogun rẹ, Jorge Mendes faake kọri. O ni Cristiano Ronaldo lagbabọọlu to dantọ julọ laye ninu itan. Ronaldo kọ lati lọ si ibi ayẹyẹ naa to waye lalẹ ọjọ Aje niluu Paris lorilẹ-ede Faranse, koda oun lo gba ipo kẹta nigba ti adẹyinmu ẹgbẹ agbabọọlu Liverpool, Virgil van Dijk ṣe ipo keji mọ Ronaldo lọwọ. Ko si agbabọọlu to tii gba ami ẹyẹ naa to Messi, ẹni to ti gba a fun igba kẹfa bayii, lati igba ti wọn ti bẹrẹ fifi ami ẹyẹ naa dawọn agbabọọlu to fakọyọ julọ lọla. Ronaldo lo tun tẹle Messi lẹyin t'oun naa ti gba ami ẹyẹ Ballon D'or fun igba marun un ọtọọtọ. Ilu Milan lorilẹ-ede Italy lo wa nibi ti wọn ti fami ẹyẹ agbabọọlu to dara julọ ni idije liigi Serie A fun saa 2018-2019 daa lọla. Eyi ni igba akọkọ ti Messi yoo gba ami ẹyẹ Ballon D'or lati ọdun 2015, Ronaldo lo gbami ami ẹyẹ naa lọdun 2016 ati 2017, nigba ti Luka Modric Real Madrid gba a lọdun 2018. FUTA: Àwọn mẹ́jọ ló ṣíná ìyà fún Bolu ní FUTA Ọpọ lo gbagbọ pe Messi ni ami ẹyẹ t'ọdun yii tọ si lẹyin to gba goolu mọkanlelaadọta ninu ifẹsẹwọnsẹ aadọta to gba ni saa bọọlu 2018-19. Ballon D'or 2019: Ronaldo ló dáńtọ́ jùlọ (GOAT), bó tilẹ̀ jẹ́ pé Messi ló gb'àmì ẹ̀yẹ Ballon D'or Ija ilara ko le tan laelae, ajuwọn lọ ko ṣee wi lẹjọ, Virgil van Dijk to ṣe ipo keji ni Messi ni Eleduwa gbade ere bọọlu fun un. Van Dijk ni o yẹ kawọn tubọ maa gbaṣoba rabandẹ fun anjannu agbabọọlu ti wọn n pe ni Messi.",3 Ọ̀pẹ̀̀ 2019 +Chelsea àti Valencia pín gaàrí lọ́gbọọgba nílé Valencia," Oríṣun àwòrán, Getty Images Aileja lojude ile baba mi ko de ibi. Bẹẹ gan lọrọ ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea ṣe ri lẹyin ti wọn tẹyin ta ọmi alayo mejimeji pẹlu Valencia ninu idije UEFA Champions League lalẹ Ọjọru. Awọn ẹgbẹ agbabọọlu mejeeji kọkọ gbiyanju agbara wọn ṣugbọn ko sẹni to gbayo sawọn ẹnikeji fun iṣẹju mọkandinlogoji. Ṣugbọn Valencia lo kọkọ gbayo sawọn Chelsea lẹyin ti Carlos Soler jẹ goolu akọkọ nigba ti ifẹsẹwọnsẹ ọhun di ogoji iṣẹju. Amọ, Mateo Kovacic dayo naa pada lẹyin iṣẹju kan pere, eyi to mu ere bọọlu naa di ọmi alayo kọọkan. Lẹyin iṣẹju marun un ti ipele keji ifẹsẹwọnsẹ naa bẹrẹ ni Christian Pulisic fọba lee fun Chelsea ti ifẹsẹwọnsẹ si di ami ayo meji sẹyọkan fun Chelsea. Valencia lanfaani lati gbayo mii sawọn lẹyin ti rẹfiri fun wọn ni pẹnariti, ṣugbọn aṣọle Chelsea Kepa Arizabalaga mu pẹnariti ọhun. Gbogbọ igbiyanju Valencia lati ta ọmi ninu ere bọọlu ọhun, ja si ayọ nigba ti Daniel Wass tayo naa fi di 2-2.",27 Bélú 2019 +Unai Emery máa lọ! Àwọn olólùfẹ́ Arsenal ní kí Emery kọ̀wé fipò sílẹ̀," Oríṣun àwòrán, Twitter/Arsenal FC Ina ti jo dori koko bayii fun akọnimọọgba ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal, Unai Emery. Ọgọrọ awọn ololufẹ Arsenal ni wọn yabo oju opo ayelujara papaajulọ Twitter, nibi ti wọn ti sọ pe ki Emery kọwọ fipo rẹ silẹ tabi ki Arsenal juwe ile fun un. Agidi ni Arsenal fi gba ọmọ alayo meji si meji pẹlu ikọ agbabọọlu Southampton lopin ọsẹ to kọja ninu idije Premier League. Lẹyin ifẹsẹwọnsẹ naa lawọn ẹgbẹ alatilẹyin Arsenal kan sọ fun awọn alaṣẹ ikọ Arsenal pe ki wọm fọwọ osi juwe ile fun Emery. Ipo kẹjọ ni Arsenal wa bayii lori tabili idije Premier League eleyi to jẹ ki ọpọ alatilẹyin Arsenal maa kọminu. Ẹgbẹ naa ṣalaye pe awọn eeyan bi ọgọrun un mẹfa lo ti kọwọ bọwe pe ki Emery dagbere fun Arsenal. Bakan naa lọpọ eeyan loju opo Twitter n sọ pe o ti to asiko fun Emery lati fipo rẹ silẹ. Ọpọ lo n sọ pe kawọn alaṣẹ Arsenal gba Massimiliano Allegri tabi Mauricio Pochettino lati rọpo Emery gẹgẹ bi akọnimọọgba Arsenal. Ọmọ Yahoo tú àṣírí ara rẹ̀ fún, bí wọ́n ṣe ń ṣe é BBC Yorùbá",25 Bélú 2019 +Manchester City pàdí ọrẹ dà f'ogun ẹ̀yìn ja Chelsea," Oríṣun àwòrán, Getty Images Frank Lampard to jẹ akọnimọọgba Chelsea funra rẹ ti figba kan gba bọọlu fun Man City lẹyin to kuro ni Chelsea. Ami ayo meji si ẹyọkan ni Manchester City fi se agba fun ikọ Chelsea ninu Idije Premier League to n lọ lọwọ. Aguero jade lasiko ti ifẹsẹwọnsẹ naa n lọ lọwọ lẹyin ti o fi ara pa. N'Golo Kante lo kọkọ gba bọọlu wọle fun Chelsea, ki o to di wi pe De Bruyne ti ikọ Man City da imọ mọ ru, ti o si gba bọọlu wọ inu awọn. Oríṣun àwòrán, Getty Images Riyad Mahrez lo da ẹgbọ si ara Chelsea, ti o si fi ami ayo keji si inu awọn ti ifẹsẹwọnsẹ naa fi pari. Oni lonii jẹ, ẹ ni a bẹ lọwẹ lọrọ gbankọgbi ifẹsẹwọnsẹ Premier League toni. Idije yii yoo waye ni papa iṣere Etihad laarin Manchester City ati ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea nirọlẹ ọjọ Satide oni. Oríṣun àwòrán, Twitter/Manchester City Manchester City vs Chelsea: Ṣé kìnìhún Manchester City tó bú ramúramù kò ní pa Chelsea jẹ lónìí? Abuku oloronbo ni Liverpool fi kan Man City ninu ifẹsẹwọnsẹ ti wọn gba kẹyin ninu idije Premier League, ami ayo mẹta sodo ni Liverpool fi ṣẹwọn leegun ẹyin. Amọ, Chelsea fakọyọ ni ti wọn lẹyin ti fagba han Crystal Palace pẹlu ami ayo meji sodo. Ẹwẹ, Frank Lampard to jẹ akọnimọọgba Chelsea funra rẹ ti figba kan gba bọọlu fun Man City lẹyin to kuro ni Chelsea. Ni bayii, ipo kẹta ni Chelsea wa lori tabili Premier League, nigba ti Man City tẹle wọn ni ipo kẹrin. Ẹ gbẹ agbabọọlu Manchester City ti fidi rẹmi ninu ifẹsẹwọnsẹ mẹta ni saa yii, nigba ti Chelsea kuna ninu meji. Ami ayo mẹfa sodo ni Chelsea jẹ lọwọ Man City nigba ti wọn koju ara wọn kẹyin ni papa iṣere Etihad. Liverpool lo si wa loke tente, awọn nikan si ni ikọ agbabọọlu ti ko ti fidi rẹmi ninu ifẹsẹwọnsẹ kankan ni saa bọọlu yii. Money transfer: Òdíwọn iye owó tí èèyàn n fi rànṣẹ́ sílé ń dínkù púpọ̀ jù",23 Bélú 2019 +Jose Mourihno fakọ yọ pẹ̀lú bí Tottenham se na West Ham!," Oríṣun àwòrán, Getty Images Bí ẹ̀nìyàn bá gẹsin nínù Jose Monrinho kò lé è kọ̀sẹ̀ pẹ̀lú bí ikọ̀ Tottenham se fakọyọ. Ọpọ eniyan lo gboriyin fun akọnimọọgba tuntun Tottenham, Jose Mourinho pẹlu bi ikọ rẹ se na West Ham pẹlu ami ayo mẹta si meji. Son Heung-min lo kkọ fi bọọlu sinu awọn, lẹyin ti Dele Alli gba bọọlu fun un, ti o si wọ inu awọn. Ni se ni Jose n tọ soke sodo, ti inu re si n dun de di. Lucas Moura lo gba bọọlu keji wọnu awọn, nigbati Harry Kane si ran Serge Aurier lọwọ lati gba bọọlu naa wọ inu. Oríṣun àwòrán, Getty Images Michail Antonio ti ikọ West Ham ati Angelo ogbonna lo gba bọọlu wọle fun ikọ naa ti ayo fi pari si 3-2. Igba akọkọ ni yii ti akọnimọọgba naa yoo ma a tukọ ẹgbẹ agbabọọlu Tottenham lẹyin ti wọn le ni ikọ Chelsea ati Manchester United.",23 Bélú 2019 +Messi gọ̀ láti sọ fun akọ́nimọ̀ọ́gbá Brazil pé kó gbẹ́nu dákẹ́- Thiago Silva," Oríṣun àwòrán, Other Bo tilẹ jẹ pe Messi naa lo gba goolu kan ti ẹgbẹ agbabọọlu Argentina fi bori sawọn. Ki lo le mu ki agbabọọlu sọ fun akọnimọọgba pe ẹnu rẹ n run? Gbajugbaja agbabọọlu Barcelona to jẹ ọmọ Argentina lo sọ fun akọnimọọgba Brazil, Tite pe ko yee sọrọ mọ ninu ifẹsẹwọnsẹ ọlọrẹẹsọrẹẹ to waye laarin orilẹ-ede mejeeji lorilẹ-ede Saudi Arabia lọjọ Ẹti. Messi ati Tite tahun si ara wọn nigba ti ere bọọlu naa si n gbona girigiri, bo tilẹ jẹ pe Messi naa lo gba goolu kan ti ẹgbẹ agbabọọlu Argentina fi bori sawọn. Messi kan ṣadeede lọ sẹgbẹ kan lori papa nibi ti Tite wa, nibẹ lo ti fi ika sẹnu to si ni ''fẹẹmu'' fun akọnimọọgba ẹgbẹ agbabọọlu Brazil. Tite fun ra rẹ ṣalaye pe lootọọ loun ti n ṣaroye fun rẹfiiri pe nipa bi ifẹsẹwọnsẹ ṣe n lọ, ati pe oun ati Messi jọ ni gbolohun asọ nigba ti ipele akọkọ ere bọọlu pari. Akọnimọọgba Brazil ni o yẹ ki Messi gba kaadi ikilọ yẹlo, lẹyin naa lọ sọ pe ki oun gbẹnu dakẹ, bayii loun sọ fun un pe ko dakẹ ẹnu rẹ. Ninu ọrọ tiẹ, balogun ẹgbẹ agbabọọlu Brazil, Thiago Silva bu ẹnu ẹtẹ lu ihuwasi Messi si Tite. O ni iwa ti ko boju mu ni lati sọ pe ki agbalagba gbẹnu dakẹ. Silva fikun ọrọ rẹ pe alaṣeju ni Messi, oun nikan lo fẹ fọn feere, o fẹ dari ere bọọlu naa, bakan naa lo n ṣe ariyanjiyan pẹlu rẹfiri.",16 Bélú 2019 +Kí láwọn ohùn àmúyẹ tí kọmẹńtátọ̀ tó dáńtọ́ gbọ́dọ̀ ní?," Oríṣun àwòrán, Google Aworan Ernest Okonkwo ati awọn kọmẹntátọ̀ miran nibi ti wọn ti n pitu Lara akoko ti awọn ọmọ Naijiria maa n ṣafihan idunnu ni igba ti ikọ agbabọọlu Naijiria ba n jade sori papa ere bọọlu. Ninu ohun to maa n ṣe koriya fun wọn lasiko yi ni bi awọn agbabọọlu ti ṣe maa n tasẹ ati bi ẹni to n ṣalaye bi nnkan ṣe n lọ lori papa naa ba ṣe n pitu tiẹ naa. Latari eleyi,o jẹ ohun iyalẹnu fawọn ololufẹ ere boolu nigba ti afihan ati ọrọ alaye ta mọ si 'commentary' lede oyinbo ko lọ geere nigba ti Super Eagles Naijiria koju akẹ́gbẹ wọn lati Benin Republic. Rudurudu ati ailọ-deede eto naa lo n bi ibeere pe ṣe ileeṣẹ amohunmaworan Naijiria ko tilẹ ṣe igbaradi kankan ki wọn to bẹrẹ afihan ifẹsẹwọnsẹ naa ni?. Bakan naa lo mu iwoye wa ti a si fi ni ka beere pe ki lawọn ohun to yẹ ki kọmẹntatọ ni lamuye ki o to le e bọ si ori afẹfẹ pe ohun fẹ ṣalaye ifẹsọwọnsẹ to n lọ. Ki a ba le gbọ ọrọ yii ye daadaa ni ki a mu awọn gbajugbaja kọmẹntatọ ni Naijiria to dantọ ki a baa le mọ ohun ti wọn ṣe taraye fi gba wọn lọga nidi iṣẹ kọmẹntari. Bi wọn ba n porukọ akọni ninu awọn kọmẹntatọ ere bọọlu,yoo ṣoro ki a ma fi ida Ernest Okonkwo lalẹ gaara. Ọdun mọkandinlọgbọn ti o faye silẹ, niṣe ni awọn ọmọ Naijiria n ṣele de pẹlu itu to maa n pa pẹlu apejuwe to munadoko nipa ohun to n ṣẹlẹ lori papa. Oríṣun àwòrán, Google Kí láwọn ohùn àmúyẹ tí kọmẹńtátọ̀ tó dáńtọ́ gbọ́dọ̀ ní Awọn to mọ ọ nigba aye rẹ kan sara sii ti wọn si fun un ni orisirisi inagije to jọ mọ bi o ti ṣe maa n hun ọrọ lalai dena pẹnu. Lara awọn inagijẹ yi la ti ri ''Intercontinental Ballistic Missile Commentator,. Oríṣun àwòrán, Facebook/Yinka Craig Yinka Craig naa jẹ ogbontarigi kọmẹntátọ̀ ni Naijiria nigba aye rẹ Okonkwọ gẹgẹ bi ohun ti agbaọjẹ ere bọọlu ni Segun Odegbami ti ṣe sọ, a maa fun awọn agbabọọlu lorukọ ti eyi a si maa mu inu awọn to n fọkan ba ere naa lọ lori rẹdio dun. ''Dean of Defence'' ''Mathematical Odegbami'' ''Chairman Chrsitian Chukwu'' ati ''Elastic Elahor'' wa lara awọn orukọ to fi n ṣapejuwe awọn agbabọọlu lori papa. Oríṣun àwòrán, Google Ṣẹ ẹ ranti apejuwe ''Nigeria score Nigeria!'' to ṣe nigba ti Godwin Odiye fori gbe bọọlu wọnu awọn Naijiria lọdun 1977. Ti a ba n sọrọ ki eeyan dantọ, ọga ni Okonkwo ninu ṣiṣe alaye ohun to n lọ lori papa ere bọọlu Awọn kọmẹntatọ miran ninu itan Naijria ti wọn pegede ti wọn fi gbọrọ jẹka ni Àìsàn ìtọ̀ súgà kò túmọ̀ sí pé èèyàn ti gba ọjọ́ ikú- Dókítà Wilson Góòlù pọ̀ ní ìlú Madaka ṣùgbọ́n wọn kò ní ọ̀nà fún ọgọ́rùn ún ọdún Àwọn ọmọ Nàìjíríà bu ẹnu ẹ̀tẹ́ lu NTA lórí ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ ìdíje bọ́ọ̀lù Ilé ẹjọ́ ni agbábọ́ọ̀lù ọmọ Nàìjíríà, Dickson Etuhu jẹ́bi ẹ̀sùn títa ìdíje Sweden",14 Bélú 2019 +Àwọn ọmọ Nàìjíríà bu ẹnu ẹ̀tẹ́ lu NTA lórí ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ ìdíje bọ́ọ̀lù," Oríṣun àwòrán, @Ammar_sunkanmi Awọn ọmọ Naijiria bu ẹnu atẹ lu NTA loju opo Twitter pẹlu ami #ShameOnNTA Awọn ọmọ Naijiria ti fi aidunnu wọn han lori itakunn ayelujara lori bi ileeṣẹ amohunmaworan orilẹ-ede yii, NTA, ṣe ṣafihan ifẹsẹwọnṣẹ laarin ikọ Supper Eagles ati ti Benin lana. Awọn ọmọ Naijiria bu ẹnu ẹtẹ lu NTA lori bi kamẹra rẹ ko ṣe le yi sọtun ati sosi, ni abala kini ifẹsẹwọnṣe naa. Bẹẹ na ni wọn tun na ika abuku si ileeẹṣẹ ọhun lataari bi ko ṣe le ṣafihan awọn awọn ohun to ṣe pataki lẹẹkeji fun awọn onworan to wa nile. Bakan naa, wọn ni igbohunsafẹfẹ ti NTA ṣe lori ifẹsẹwọnṣe ri balabala, ti ko si ṣe e wo. Idi eyii lo mu ki awọn ọmọ Naijiria bu ẹnu ẹtẹ lu ileeṣẹ naa loju opo Twitter pẹlu ami #ShameOnNTA. Royal beere pe, ""Nigba wo ni ileeṣẹ NTA yoo ṣatunṣe si igbohunsafẹfẹ wọn?"" Obinna Nwosu ni ti ẹ ni, ileeṣẹ NTA ko ni idagbasoke kankan lati ogun ọdun sẹyin. World Diabetes Day: Ọdún kọkandinlogun ti mo ti wà lẹ́nu itọ ṣúgà nìyí Olajuwon sọ pe, oun yoo yan lati wo ifẹsẹwọnṣẹ lori ẹrọ asọrọmagbesi kaka ki oun wo lori ẹrọ NTA. Ẹ wo ohun tawọn ọmọ Naijiria mii n sọ loju opo Twitter. ""Aug 2018 ni ìgbìmọ̀ aláṣẹ APC ti ṣe ìpàdé kẹ́yìn, Oshiomole ti kùnà"" Ọ̀pọ̀ àwòrán rèé tó ń sàfihàn bí Ibadan se kún fún ẹ̀gbin àti òórùn Aeroplane House: Látọdún 1999 ni mo ti bẹ̀rẹ̀ kíkọ́ ilé yìí fún ìyàwó mi ọ̀wọ́n Bẹẹ, loju awọn miran, wọn ni o ṣeeṣe ko jẹ pe NTA ko tete mọ pe awọn maa gbe idije naa ki wọn le pese awọn nkan ti wọn nilo.",14 Bélú 2019 +"Koko iroyin: Lai Mohammed fèsì sí ọrọ Obasanjo, Ìjọ́ba ìpínlẹ̀ Ògùn kéde ìsinmi ní June 12"," Èyí ni àkójọpọ̀ àwọn ìròyìn tí tòní Lai Mohammed: Ọbasanjọ, bí ìwo bá ṣé réré, Ara kì yóò yà ọ? + Oríṣun àwòrán, Getty Images Ọbasanjọ ti ṣe nnkan ìtùfù sẹyin lo ṣe n kíyèsí ẹninkule rẹ̀ Ẹní jẹ fufu lára n fu lọ̀rọ̀ Ọbasanjọ. Èsì ọrọ ree láti ọdọ ìjọba Buhari sí Obasanjo to so pe Buhari n pète láti ka ẹsùn sí òun lọrùn lasiko yii. Mínísítà fún ètò ìròyìn,Alhaji Lai Muhammed, lo fèsì naa pada pé ''àhesọ ọ̀rọ̀ ni Ọbasanjọ n sọ, àti pé ìjọba Buhari kò ráàyè a n dìràn mọ́ni lẹ́sẹ̀'' Ọrọ náà jẹyọ nínú aàtẹ̀jáde kàn tó fí ṣọwọ́ s'awọn akọ̀ròyìn lọ́jọ́ Ẹtì nílùú Èkó. Ẹ ka ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ níbí June 12: Ògùn, Ọ̀yọ́ kéde ìsinmi lẹ́nu iṣẹ́ Oríṣun àwòrán, http://ogunstate.gov.ng Wọ́n ni ọjọ́ nàá yó le fún àwọn aráàlú ní ànfàání láti ṣe àjọyọ̀ ọjọ́ ìṣèjọba àwaarawa. Ìjọba ìpínlẹ̀ Ògùn ti kéde ọjọ́ kejìlá, oṣù Kẹfà, gkgẹ́ bí ọjọ́ ìsinmi lẹ́nu iṣẹ́. Èyí jẹyọ nínú àtẹ̀jáde kan tí akọ̀wé fún ìjọba ìpínlẹ̀ nàá, Taiwo Adeoluwa fọwọ́ sí. Nínú àtẹ̀jáde nàá tó tẹ ìwé ìròyìn Punch lọ́wọ́, wọ́n ni ọjọ́ nàá yó le fún àwọn aráàlú ní ànfàání láti ṣe àjọyọ̀ ọjọ́ ìṣèjọba àwaarawa. E ka ekunrere re ni bii 'Bóo rántí ikú Gáà kóo ṣòótọ́ ni ọ̀rọ̀ Abacha' 'Ọpọ̀ ẹ̀mí èèyàn ló bọ́ lọ́wọ́ Abacha láàrín 1993 sí 1998'",9 Òkùdu 2018 +"'Mourinho ṣetán láti gbaṣẹ́ Arsenal, tó bá ṣí sílẹ̀'"," Oríṣun àwòrán, Twitter/Express Sport Yoruba bọ wọn ni bi ohun ti a n ba n jẹ ba tan, ohun ti a kii jẹ naa lo ku. Iroyin to n tẹ wa lọwọ lati ilẹ Gẹẹsi lo n sọ pe akọnimọọgba Chelsea ati Manchester United nifẹ si ko gba iṣẹ akọnimọọgba ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal. Ọrọ yii lọpọ eeyan n gba bi ẹni n gba igba ọti lori ayelujara opo Twitter papaajulọ lati igba ti Arsenal ti ri iya he lọwọ Liverpool ninu idije Carabao Cup ni papa iṣere Anfield lalẹ Ọjọru. Iroyin sọ pe Mourinho n wa iṣẹ si ilẹ Gẹeṣi nitori nibẹ lo ti ṣaṣeyọri nibi to gba ife ẹyẹ idije Premier League nigba mẹta ọtọtọtọ. Ilẹ iroyin ESPN tiẹ sọ pe Mourinho ṣetan lati ṣe akọnimọọgba ikọ Arsenal ti wọn ti fọwọ osi juwe ile fun Unai Emery. Eleyi jẹ iyalẹnu fun ọpọlọpọ ololufẹ ere bọọlu papaajulọ idije Premier League nitori Mourinho sọrọ alufansa si Arsenal fun ọpọlọpọ ọdun. Mourinho ti kọ lati gba iṣẹ akọnimọọgba ni ẹgbẹ agbabọọlu Benfica ati ikọ agbabọọlu kan lorilẹede China. Bakan naa laagbọ pe o ṣeeṣe ki Mourinho pada si ikọ Real Madrid eleyi to ti tukọ rẹ ri tẹlẹ.",31 Ọ̀wàrà 2019 +Ole mórí bọ́! Manchester United tún wẹ̀wù ìyà fún Chelsea lẹ́ẹ̀kan síi," Oríṣun àwòrán, Getty Images Ẹgbẹ agbabọọboolu Manchester United ya ọpọ lẹnu lẹyin ti wọn fiya jẹ Chelsea mọle ninu idije Carabao Cup. Mracus Rashford lo kọkọ gbayo wọle lẹyin iṣẹju mẹẹdọgbọn ti wọn bẹrẹ ere bọọlu ọhun. Mchy Batshuayi dayo naa pada lai fọta pe. Amọ Rashford tun fọba lee fun Manchester United lẹyin to gbayo keji ti wọn fi jawe olubori wọle fun Man U. Àwọn ọmọ ológo Liverpool lé kúrò ní ìdíje Carabao Cup Yoruba bọ, wọn ni aileja lojude ile baba me ko de bi. Bayii ni ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal ṣe ya ọpọ ololufẹ ere bọọlu lẹnu lẹyin ti wọn fiya jẹ Liverpool mọle. Shkodran Mustafi lo kọkọ sẹesi gbayo sawọn Arsenal lẹyin iṣẹju mẹfa ti wọn bẹrẹ ere bọọlu ọhun. Amọ, Lucas Torreira dayo naa pada nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa di iṣẹju mókandinlogun. Oríṣun àwòrán, Getty Images Ẹlẹsẹ ayo, Gabriel Martinelli gba goolu meji sawọn fun Arsenal laarin iṣẹji mẹwaa, ni ere bọọlu ba di ami mẹti sẹyọkan. James Milner lo gbayo keji wọle fun Liverpool ki agbabọọlu Arsenal tẹlẹ Alex Oxlade Chamberlain ati Divock Origi to gbayo ẹlẹkẹta ati ẹlẹẹkẹrin sile Arsenal. Oríṣun àwòrán, Getty Images Ṣugbọn Arsenal lo pada jawe olubori nigbẹyin gbẹyin lẹyin ti Joseph Willock gba goolu karun un wọle fun Arsenal. Ọjọ́ ẹ̀san dé! Chelsea ṣetán láti gb'ẹ̀san 4-0 lára Manchester United Ọjọ n bọ ni Oluwa wi, ṣugbọn ọjọ ti ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea ati Manchester United yoo tun jọ ta kan-ungbọn ti de lalẹ Ọjọru. Ami ayo mẹrin sodo ni Manchester United fi ṣagba Chelsea nigba ti wọn kọkọ jọ waako ni ibẹrẹ saa bọọlu yii. Eyi ni igbakeji ti ẹgbẹ agbabọọlu mejeeji yoo koju ara wọn lati igba ti saa yii ti bẹrẹ. Ni papa iṣere Stamford Bridge ni ifẹsẹwọnsẹ toni yoo ti waye ninu idije ife Carabao Cup. Oríṣun àwòrán, Getty Images Lọdun 2012 lawọn mejeeji jọ pade kẹyin ninu idije yii, Chelsea lo jawe olubori pẹlu ami ayo marun un si mẹrin nigba ti ere bọọlu naa di womi ki n gba siọ. Chelsea n yeruku lala bayii, koda wọn jawe olubori ninu ifẹsẹwọnsẹ meje ti wọn kopa ninu rẹ kẹyin. Ipo kẹrin ni Chelsea wa lori tabili idije Premier League, nigba ti Man U wa ni ipo keje. Igba mẹrinlelọgọsan an ni Chelsea ati Manchester United ti jọ koju ara wọn, igba kẹfa si ree tawọn mejeeji yoo koju ara wọn ninu idije EFL. Chelsea jawe olubori lẹẹmẹwaa ninu ifẹsẹwọnsẹ mọkanla ti wọn kẹyin ninu idije EFL. Manchester United ni ti wọn jawe olubori ninu mẹfa ninu ifẹsẹwọnsẹ meje ninu idije EFL ti wọn gba pẹlu awọn ẹgbẹ agbabọọlu to n kopa ninu idije Premier League.",30 Ọ̀wàrà 2019 +Orí ìdúró ni mo ti wo ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ Nàìjíríà àti Hungary tán- Mínísítà," Oríṣun àwòrán, Twitter/NFF Ẹgbẹ agbabọọlu Naijiria ti ọjọ ori wọn ko ju ọdun mẹtadinlogun, the Golden Eaglets ya agbado ha si ọpọ lẹnu lẹyin ti wọn gbẹyẹ lọwọ ilẹ Hungary ninu idije ife ẹyẹ agbaye FIFA U-17 World Cup lorilẹede Brazil lalẹ ọjọ Satide. Koda minisita fun ere idaraya ati ọrọ ọdọ, Sunday Dare sọ pe lori iduro l'oun ti wo ifẹsẹwọnsẹ naa to fi pari nitori ẹru. Nnkan ko kọkọ ṣẹnu 're fawọn ọjẹwẹwẹ Naijiria lẹyin ti Gyorgy Komaromi gba bọọlu sawọn fun ikọ agbabọọlu Hungary lẹyin iṣẹju mẹta ti ere bọọlu naa bẹrẹ. Agbabọọlu Samson Tijani dayo naa pada nigba ti ifẹsẹwọnsẹ ọhun pe ogun iṣẹju. Amọ, Samuel Major tun fọba lee fun Hungary lẹyin iṣẹju mẹjọ ki Usman Ibrahim to dayo naa pada eleyi to sọ di ọmi alayo mejimeji. Oluwatimilehin Adeniyi lo fọba lee fun Naijiria nigba ti ere bọọlu ọhun ku iṣẹju mẹjọ ti yoo fi pari. Balogun Golden Eaglets, Tijani lo gba goolu ẹlẹẹkẹrin sawọn Hungary eleyi to jẹ ki Naijiria gbegba oroke pẹlu ami ayo mẹrin si meji. Ẹwẹ, minisita ere idaraya ni o da oun loju pe ikọ agbabọọlu Naijiria yoo tubọ fakọyọ ninu ifẹsẹwọnsẹ wọn toku. Minisita ṣalaye oun mọ pe awọn ọjẹwẹwẹ agbabọọlu Naijiria yoo fakọyọ ninu idije FIFA U-17 World nitori oun wo wọn nigba ti wọn n gbaradi niluu Abuja.",27 Ọ̀wàrà 2019 +Ìgbẹ́ àá f'éwé! Chelsea fẹ́ Ajax dànú bí abẹ̀bẹ̀ nílé wọ̀n," Oríṣun àwòrán, @Chelsea4Pidgin VAR ṣègbè lẹ́yìn Chelsea fogun ẹ̀yín ja Ajax mọ́lé Ifẹsẹwọnsẹ UEFA Champions League laarin ikọ Ajax ati Chelsea to waye lalẹ oni le koko bi oju ẹja, ṣugbọn ikọ Chelsea fẹ Ajax danu nile wọn. Ni igba ti idije naa wọ iṣeju mẹtalelọgbọn ni Quincy Promes sọ ayo kan wọle fun ikọ Ajax, ṣugbọn lẹyin isẹju die si ti wọn wo oju ẹrọ ni VAR ni rẹfiri wọgi le goolu ọhun. Ọ̀mì ni ikọ memeji gba ni ipari abala akọkọ ifẹsẹwọnsẹ ọhun. Gbogbo akitiyan Quincy Promes ninu abala keji ifẹsẹwọnsẹ naa lati sọ bọọlu sinu awọn ikọ Chelsea lo ja si pabo, ko to di pe wọn parọ rẹ. Ṣugbọn nigba ti o ku iṣeju mẹrin ki ifẹsẹwọnsẹ ọhun pari ni Michy Batshuayi fi ibinu sọ ami ayo kan sinu awọn ikọ Ajax. Oríṣun àwòrán, Getty Images Ẹgbẹ agbábọ́ọ̀lù Chelsea ya àgbàdo hà sí ikọ́ Ajax lẹnu lẹ́yìn tí wọ́n lù wọ́n mòlé Eyi mu ki akọnimọgba ikọ Ajax Erik ten Hag, parọ awọn ọmọ rẹ meji ni wara wara, ṣugbọn ẹpa ko boro mọ. Bo tilẹ jẹ pe akọnimọgba ikọ Chelsea naa parọ lara awọn ikilọ rẹ, ti wọn gbiyanju lati sọ ayo miiran sinu awọn. Lẹyin iṣẹju mẹrindinlọgọrun un ni ifẹsẹwọnsẹ naa pari ni ikọ Chelsea fẹ Ajax danu bi abẹbẹ pẹlu ami ayo kan si odo.",23 Ọ̀wàrà 2019 +Arsenal sì wà lọ́mọ ìkókó lẹ́yìn ọdún mẹ́wàá- Patrice Evra," Oríṣun àwòrán, Getty Images Ko si iyatọ kankan ninu ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal lati bii ọdun mẹwaa sẹyin, bakan naa ni si wa. Agbabọọlu ikọ Manchester United tẹlẹ ri, Patric Evra lo sọrọ yii lẹyin ti Sheffield United ṣina iya fun Arsenal lalẹ ọjọ Aje pẹlu ami ayo kan sodo ninu ifẹsẹwọnsẹ Premier League. Arsenal padanu anfaani lati bọ si ipo kẹta ninu idije Premier League lẹyin ti wọn rẹmi papa iṣere Bramall Lane. Evra ṣalaye pe ọmọ ikoko loun maa n pe wọn ni bii ọdun mẹwaa sẹyin nigba kugba tawọn ati Man U ba koju ara wọn. Bakan naa lo sọ pe akọnimọọgba Unai Emery ko tii mu iyatọ kankan to ba Arsenal lati igba to ti gori aleefa lẹyin ti Arsene Wenger kuro. Evra ni oun ko fi tabuku wọn, nigba ti oun sọ pe awọn agbabọọlu Arsenal n gbabọọlu bi ọmọ ọwọ, o ni otitọ loun n sọ. Oríṣun àwòrán, Getty Images Evra to jẹ ọmọ orilẹede Faranse fikun ọrọ rẹ pe otittọ ni wi pe Arsenal dun un wo loju ti wọn ba n gbabọọlu, amọ o ni wọn ko jọ ikọ agbabọọlu to le maa fakọyọ ninu ere bọọlu. O ni niṣe ninu oun maa n dun nigba kugba ti Man U ati Arsenal ba fẹ waako nitori oun mọ pe Man U yoo bori. Adilemu fun Man U tẹlẹ ni Sheffield United gan an lo yẹ ko jawe olubori ninu ifẹsẹwọnsẹ alẹ ọjọ Aje nitori awọn lo fakọyọ julọ.",22 Ọ̀wàrà 2019 +Man U kò jẹ́ kí Liverpool fakọyọ pẹ̀lú òmì ayò kan!," Oríṣun àwòrán, Inpho Marcus Rashford ló kọ́kọ́ gbá bọ́ọ́lù wọ inú àwọn fún Manchester United, kí Adam Lallana tó gbá bọ́ọ̀lù wọnú àwọ̀n fún Liverpool. Ọmi ayo kan naa ni Manchester United ati Liverpool gba ni idije Premier League to n lọ lọwọ. Eyi ko sẹyin bi ikọ Liverpool ko se le e fakọyọ gẹgẹ bi ikọ ti wọn ko tii na fun igba mejidinlogun ni idije Premier League. Marcus Rashford ti ikọ Manchester United lo koko gba bọọlu sinu awọn, ki saa kini ifẹsẹwọnsẹ naa. O ku isẹju marun un ki ifẹsẹwọnsẹ naa pari ni Adam Lallana ti ikọ Liverpool fi ọba le fun wọn, ti ifẹsẹwọnsẹ naa si pari si ọmi ayo kan(1-1).",20 Ọ̀wàrà 2019 +Abẹ̀ṣẹ́kùbíòjò Patrick Day dèrò ọ̀run lẹ́yìn tó gba ẹ̀ṣẹ́ s'órí!," Oríṣun àwòrán, Getty Images Patrick Day: Akẹ̀ṣẹ́ kan, Day dèrò ọ̀run lẹ́yìn tó gba ẹ̀ṣẹ́ s'órí Iku ogun nii pa akinkanju, iku odo nii pa omuwẹ. Abẹṣẹ-ku-ojo ọmọ ilẹ Amẹrika kan, Patrick Day ti dero ọrun lẹyin to fi ori ṣeeṣe nigba to ba Charles Conwell ja. Day to ku ni ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn dero ile iwosan lọjọ Satide to kọ ja, ko da ko le sọrọ mọ, bẹẹ ni ko mo ohun kankan mọ nitori. Ipele kẹwaa ija rẹ pẹlu Conwell eyi to waye niluu Chicago lo ti fidi rẹmi lẹyin ti ẹṣẹ ṣakoba fun un lori. Ọjọ mẹrin ni Day fi wa nile uwosan nibi ti ko ti le gbe apa, gbe ẹsẹ, ko to di pe o wa jẹ Ọlọrun nipe. Onigbọwọ Day, Lou DiBella lo kede iku rẹ nigba ti o wa pẹlu awọn ẹbi ati ọrẹ rẹ. DiBella ṣalaye ninu atẹjade kan to fi sita pe, oloogbe Day ko tiẹ nilo lati ja ẹṣẹ nitori o kawe, bẹẹ lo si ti ile ire jade, ati pe, o ni awọn ohun amuyẹ to le mu ṣe iṣẹ miiran yatọ si ẹṣẹ kikan. Oríṣun àwòrán, Getty Images Onigbọwọ Day, Lou DiBella lo kede iku rẹ nigba ti o wa pẹlu awọn ẹbi ati ọrẹ rẹ. DiBella ni Day pinu lati maa ja ẹṣẹ nitori ẹṣẹ kikan ni iṣẹ to yan laayo, ohun si ni o jẹ nnkan iwuri fun un. Ẹwẹ, Conwell ti wọn jọ ja naa kẹdun pẹlu ẹbi Day, o ni oun ko gbero iku sii nigba yawọn n ja. Conwell ṣalaye pe oun gbiyanju lati bori ninu ija naa ṣugbọn oun ko mọ pe iku ni yoo jasi fun alatako oun, Day. Day jawe olubori ninu ija mẹtadinlogun ninu mejilelogun to kopa ninu rẹ, o fidi rẹmi ninu mẹrin, o si ta ọmi ninu ija kan. Ọpọ lo n ṣedaro Patrick Day lori ayelujara, wọn kẹdun pẹlu ẹbi rẹ ninu ọrọ ti wọn fi sita.",17 Ọ̀wàrà 2019 +Òòṣà bóò le gbèmí...ọ̀mì lakitiyan Super Eagles pẹ̀lú Brazil jásí ni Singapore," Oríṣun àwòrán, Getty Images Ifẹsẹwọnsẹ ọlọọrẹsọọrẹ to waye laarin ikọ agbabọọlu Naijiria ati Brazil lo pari si ọmi. Ikọ Supper Eagles Nigeria lo kọkọ sọ bọọlu sinu awọn ilẹ Brazil, nigba ti Joe Aribo to n gba bọọlu fun Glasgow Rangers nilẹ Gẹẹsi ṣo ayo kan wọle, ni igabti idije naa wọ iṣẹju marundinlogoji. Sugbọn lẹyin ọpọlọ akitiyan ninu abala keji idije ọhun ni ikọ Brazil da bọọlu naa pada si awọn ikọ Naijiria, ni igba ti Casemiro to n gba bọọlu fun ikọ Real Madrid sọ ayo tiẹ wọle. Ọmi ti wọn ta yii tunmọ si pe, ikọ ilẹ Brazil ti kuna lati bori ninu idije mẹrin ti wọn ti gba sẹyin. Ẹgbẹ agbabọọlu Naijiria, Super Eagles ti ṣetan lati gbena woju ikọ agbabọọlu ilẹ Brazil lọjọ Aiku lorilẹede Singapore. Ikọ agbabọọlu Brazil ti kọkọ ta ọmi alayo kọọkan pẹlu Senegal l'Ọjọ ọsẹ to lọ nibu ifẹsẹwọnsẹ ọlọọrẹsọọrẹ. Ọdun 2003 ni Naijiria ati Brazil jọ koju ara wọn kẹyin ninu ere bọọlu ọlọọrẹsọọrẹ. Ni papa iṣere orilẹede Naijiria to wa l'Abuja ni Brazil ti lu Super Eagles lalu bolẹ pẹlu ami ayo mẹta sodo. Akọnimọọgba Supe Eagles Gernot Rohr ti sọ pe ẹgbẹ agbabọọlu Naijiria ti ṣetan lati jẹwọ ara wọn fun Brazil ninu ere bọọlu lorilẹede Singapore. Bakan naa, minisita fun ere idaraya ati idagbasoke ọrọọdun, Sundare Dare ni awọn agbabọọlu Naijiria fi da oun loju pe didun lọsan yoo so fun Naijiria ninu ifẹsẹwọnsẹ pẹlu Brazil. Minisita ṣalaye pe bo tilẹ jẹ wi pe ifẹsẹwọnsẹ ọlọọrẹsọọrẹ ni, awọn agbabọọlu Naijiria yoo fi taratara sii.",13 Ọ̀wàrà 2019 +Háà! Ole rugi oyin! Newcastle run Manchester United mọ́lẹ̀ jégéjégé," Oríṣun àwòrán, Getty Images Aṣe tẹni to de laari, ko si ẹni to mọ tẹni to n bọ. Bayii lọrọ ri nigba ti Wolves kọkọ na Manchester City mọle. Aṣe orogun wọn, Manchester United ti wọn jọ wa ni ilu kan naa yoo fidi rẹmi bi tawọn naa. Ẹgbẹ agbabọọlu Newcastle lo ṣina iya fun Man U ni tiwọn ni papa iṣere St. James Park nirọlẹ ọjọ Aiku ninu idije Premier League Matthew Longstaff lo gbayo naa wọle fun Newcastle nigba ti ifẹsẹwọnsẹ ọhun ku iṣẹju mejidinlogun ko pari. Oríṣun àwòrán, Getty Images Ọpọ lo ti n sọ pe asiko ti to lati le akọnimọọgba Ole Gunnar Soljskaer lọ lẹyin ti Man U ti n rakoro bi ọmọ ọwọ fun bi igba diẹ bayii. Guardiola kan ìjàngbọ̀n! Tamọtiye Wolves, Traore ta Man City pa mọ́lé Iya airo tẹlẹ ni ẹgbẹ agbabọọlu Wolves fi jẹ Manchester City ni papa iṣere Etihad lọjọ Aiku. Bi awada bi ere ni ifẹsẹwọnsẹ naa bẹrẹ eleyi ti ọpọ olololufẹ ere bọọlu si lero pe Man City ni yoo jawe olubori. Oríṣun àwòrán, Getty Images Amọ ọmi odo si odo ni wọn jọ gba ni abala akọkọ ere bọọlu ọhun lẹyin ti awọn mejeeji gbiyanju lati gba goolu sawọn ara wọn. Eleyi ni igbakeji ti ẹgbẹ agbabọọlu Man City yoo fidi rẹmi ninu idije Premier League ni saa yii lẹyin ti Norwich City ti kọkọ na wọn lai ro tẹlẹ bakan naa. Adama Traore lo gba goolu mejeeji sawọn fun Wolves Lampard ń dábírà! Àlùbolẹ̀ ni Chelsea lu Southampton mọ́lé Ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea ti bẹrẹ si ni yọ eruku lala bayii o, alubolẹ ni wọn lu Southampton mọle ninu idije Premier League lọjọ Aiku. Tamọtiye ti wọn n pe ni Tammy Abraham lo kọkọ ṣide iya lẹyin to gba goolu akọkọ sawọn fun Chelsea nigba ti ere bọọlu ọhun de iṣẹju mẹtadinlogun. Oríṣun àwòrán, Twitter/Premier League Ọkan lara awọn ọjẹwẹwẹ agbabọọlu Chelsea, Mason Mount lo gbayo ẹlẹẹkeji wọle fun Chelsea. Southanpton ta putu diẹ da ayo kan pada nibi ọgbọn iṣẹju, ṣugbọn Ngolo Kante fọba lee fun Chelsea pẹlu goolu kẹta. Mitchy Batshuayi lo gba goolu ẹkẹrin wọle fun Chelsea ti ifẹsẹwọnsẹ naa si pari si ami ayo mẹrin sẹyọkan.",6 Ọ̀wàrà 2019 +Tottenham tasẹ̀ àgẹ̀rẹ̀ bí Tacha fara káásá ìyà lọ́wọ́ Brighton," Oríṣun àwòrán, Getty Images Kaka ki ewe agbọn dẹ, niṣe lo n le koko sii. Kaka ko san fun ẹgbẹ agbabọọlu Tottenham, niṣe lo buru si o. Ẹgbẹ agbabọọlu Brighton & Hove Albion lo ṣe Tottenham bi ọṣẹ tii ṣoju ninu ifẹsẹwọnsẹ idije Premier League lọjọ Abamẹta. Ami ayo mẹta ọtọọtọ ni wọn Brighton fi ṣagba Tottenham eleyi to jẹ iyanlẹnu fun ọpọlọpọ awọn ololufẹ ere bọọlu. Balogun ati aṣọle ikọ Tottenham, Hugo Lloris lo kọkọ tasẹ agẹrẹ bi Tacha lo ba mu bọọlu bọ sinu awọn ara rẹ. Laipẹ ni aṣọle fọwọ ṣeeṣe debi pe wọn ni lati gbe lọ sile iwosan lati ori papa. Ṣugbọn bi iya nla ba gbeni sanlẹ, kekere a gori ẹni ni Brighton fi ṣe fun Tottenham lẹyin ti wọn fi ọba lee pẹlu goolu meji. Lẹyin ọ rẹyin, Brighton ṣina iya fun Tottenham pẹlu ami ayo mẹta sodo lairo tẹlẹ.",5 Ọ̀wàrà 2019 +Israel Adesanya fi ẹ̀ṣẹ́ mú ẹ̀jẹ̀ jáde nímú Whittaker láti gba àmì ẹ̀yẹ UFC," Oríṣun àwòrán, Getty Images Isreal Adesanya tó jẹ́ ẹni ọgbọ́n ọdún ló lu Robert Whittaker ní Melborne, Australia. Ọdun meji ati ija meje pere ni Afẹsẹkubiojo Isreal Adesanya to jẹ ọmọ orilẹede Naijiria ati Australia lo lati gba Ami Ẹyẹ UFC. Adesanya ti wọn n pe ni ""Last Stylebender"" lo gba Ami Ẹyẹ naa lẹyin to la Robert Whittaker mọlẹ, ni asekagba Idije UFC Middleweight Champion to waye ni Australia. Adesanya na ikeji rẹ pẹlu 3:33 ni iwaju awọn eniyan to to ẹgbẹrun lọna mẹtadinlọgọta ni papakọ ere idaraya naa. Lasiko to n sọrọ nipa aseyori rẹ, Adesanya ni ọpọ igba ni awọn eniyan ti ma n mu imu oun sẹjẹ, sugbọn ni bayii oun ti mu imu Whittaker naa sẹjẹ. Aseyori yii jẹ ko jẹ igba mejidinlogun (18-0) ti afẹsẹkubiojo Adesanya ti jawe olubori to si fi gba Ami Ẹyẹ UFC Middleweight Champion.",6 Ọ̀wàrà 2019 +Ó di agbábóòlù mẹta tí a ti pàdánù láàárín ọjọ meji - NFF," Oríṣun àwòrán, facebook Oloogbe Isaac Promise Ajọ ti o ri si ere boolu ni Naijiria ko dunnu rara si bi iku ojiji ti n pa awọn ọjẹ wẹwẹ agbaboolu lorilẹede yii. Ninu ọrọ rẹ, akọwe agba fun ere boolu lorilẹede yii, Dokita Mohammed Sanusi banujẹ lori iku Issac Promise. Issac Promise ni adari ojugba rẹ nigba idije awọn ọjẹwẹwẹ ti ọjọ ori wọn ko ju Ogun ọdun ati mẹtalelogun lọ. Akọwe agba lẹka ere bọọlu naa ni pe aipẹ yii ni ọkọ ayọkẹlẹ kan pa meji lara awọn agbabọọlu fun Ọlọpaa meji. Awọn meji naa ni wọn ku lairo tẹlẹ ni ilu Uyo, Olu Ilu Akwa Ibom ni ọjọ meji sẹyin, ki ti Issac Promise to tun ṣẹlẹ. Mohammed Samuel ni ọsẹ ibanujẹ ni ọsẹ naa jẹ fun Ajọ naa. O ṣapejuwe Isaac Promise gẹgẹ bi ẹni ti o ni iwa tutu ti o si mura siṣẹ. O tẹsiwaju pe titi di asiko ti iroyin yii jade, wọn ko i tii mọ orisun iku rẹ. O wa ni manigbagbe ni Promise yoo jẹ fun gbogbo eniyan. Promise ni o jẹ adari ikọ ọmọ Naijiria ninu idije ti ọjẹwẹwẹ ilẹ Afrika ni ọdun 2005 ni Orilẹ ede Benin. Bakan naa ni o tun kopa ninu ere idije ifese wọn sẹ ti FIFA ti ọjọ ori wọ ko ju Ogun kọ Promise ni o tun je adari ninu idije ti awọn ọjẹwẹwẹ ti ọjọ ori wọn ko ju mẹtalelogun lọ ni Beijing 2008. Ninu atẹjade ti ẹgbẹ agbaboolu rẹ Bold FC fi lede wọn ni Promise jade laye lẹyin ti o ti lo Ookanlelọgbọn lori eepẹ. Imam tó ṣí Mọ́ṣálásì fáwọn Krístẹ́nì sọ ìdí tí kò fi lè ta wọ́n nù",4 Ọ̀wàrà 2019 +Manchester United kò lèe ta pútú ní AZ Alkmaar," Oríṣun àwòrán, Getty Images Kikankikan ni olukọ atawọn agbabọọlu ẹbẹ agbabọọlu Manchester n pariwo lori papa iṣire ti wọn ti gba ifẹsẹwọnsẹ wọn pẹlu AZ Alkmaar ninu ifẹsẹwọnsẹ idije Europa. Ọmi ni Manchester United ta pẹlu AZ eleyi to mu ki Manchester United ṣi wa ni ipo keji ninu atẹ ipin L ninu idije naa ti Partizan belgrade si di ipo kini mu. Manchester United ni lati pari ifẹsẹwọnsẹ naa pẹlu agbabọọẹu mẹwa dipo mọkanla nitori ọkan lara awọn agbabọọlu rẹ, Jesse Lingard to fara pa to si ni lati fi ori papa silẹ ṣaaju opin ifẹsẹwọnsẹ naa. Pẹlu ifẹsẹwọnsẹ yii bayii, ami ayo mẹrin ni Manchester United ti ni ninu ifẹsẹwọnsẹ meji ti wọn ti gba. FC Astana ni wọn ba pade ninu ifẹsẹwọnsẹ wọn akọkọ ti wọn si bori.",3 Ọ̀wàrà 2019 +Ìwà pẹ̀lẹ́ àti iṣẹ́ takuntakun ló mú mi ṣàṣeyorí- Pryce," Oríṣun àwòrán, @BBCSport IAAF World Championships: Abiyamọ kan di lobìnrin tó leè sáré ""100 meters"" jùlọ l'àgbáyé Obinrin ọmọ ọdun mejilelogun kan lati orilẹ-ede Jamaica ti wọ inu iwe itan gẹgẹ bi obinrin to lee sare ori papa oniwọn ẹsẹ ọgọrun un julọ l'agbaye. Shelly-Ann Fraser-Pryce to jẹ ọlọmọ kan tun ni ẹni to dagba ju l'gbaye to gba ife ẹyẹ naa lẹyin to gba ife wura ni idije agbaye to n lọ lọwọ ni Doha, lorilẹ-ede Qatar. Dalemoṣu yii lo sa ere ori papa naa larin iṣẹju mẹwaa o le diẹ, lati gba ife ẹlẹẹkẹjọ iru rẹ ti yoo gba. Lẹyin to gba ife ẹyẹ naa tan, o ni inu oun dun gidigidi. O ṣalaye siwaju sii pe, aṣiri aṣeyọri oun ni iwa irẹlẹ ti oun ni ati bi oun ṣe mu iṣẹ oun lokunkundun. Bi o tilẹ jẹ pe ọpọlọpọ awọn ololufe ere ori papa ni ko yọju lati wo Shelly-Ann ni igba to n sa ere naa, o ni oun ko bikita rara. Ṣaaju akoko yii ni Shelly-Ann ti kopa ninu awọn idije agbaye miran bii; idije Olympic ti Beijin lọdun 2008, idije agbaye Berlin lọdun 2009, idije Olympic ti Londo lọdun 2012, ati bẹẹbẹẹ lọ. Nigeria Independence Day: Sé ẹ mọ̀ pé ọdún 1956 ló yẹ́ ká ti dòmìnira ṣùgbọ́n....",1 Ọ̀wàrà 2019 +Ìjà arọ méjì lálẹ́ òní ní pápá ìṣeré Old Trafford," Oríṣun àwòrán, Twitter/Premier League Manchester United vs Arsenal: Ta ni yóò borí nínú ìjà arọ méjì yìí? Ẹgbẹ agbabọọlu meji ti muṣemuṣe wọn ko da muṣemuṣe to, Manchester United ati Arsenal lo fẹ koju ara wọn lalẹ ọjọ Aje ni papa iṣere Old Trafford ninu idije English Premier League. Awọn ẹgbẹ agbabọọlu mejeeji ni wọn kọ lati ṣe iwuri fawọn ololufẹ lati igba ti saa bọọlu tuntun yii ti bẹrẹ. Ikọ Man U ni tiẹ ti fidi rẹmi nigba meji, bẹẹ ni wọn ta ọmi lẹẹmeji ninu ifẹsẹwọnsẹ mẹfa ti wọn gba ninu idije EPL ti saa yii. Ifẹsẹwọnsẹ meji pere ni Manchester UNited ti jawe olubori ninu ere bọọlu mẹfa ti wọn kopa ninu rẹ. Arsenal tun gbe pẹẹli diẹ ni ti wọn nitori ipo kẹjọ lawọn wa nigba ti Man U wa ni ipo kọkanla lori tabili idije EPL. Ninu ifẹsẹwọnsẹ mẹta ni Arsenal ti fakọyọ ninu meje ti wọn ti gba ni saa bọọlu yii. Arsenal fidi rẹmi ninu ifẹsẹwọnsẹ kan, bẹẹ ni ni wọn ta ọmi ninu ere bọọlu meji.",30 Owewe 2019 +"Ẹ̀yin baálé ilé, ẹ yé sá tẹ̀lé mi kiri mọ́!- Oshonaike"," Oríṣun àwòrán, Google Ẹ̀ yin baálé ilé, ẹ yé sátẹ̀lé mi kiri mọ́!- Oshonaike Agbabọọlu ẹlẹyin Table Tennis to ti gbami ẹyẹ nilẹ Afirika ri, Olufunke Oshonaike ti bu ẹnu ate lu bi awọn ọkunrin to ni iyawo sile ṣe n bere fun ibasepọ pẹlu oun. Olufunke to sọ eleyii lori oju opo Facebook rẹ, sọ wi pe oun ti sọ ifẹ fun igbeyawo nu, lẹyin ti ọpọlọpọ ọrọ ifẹ oun ti forisanpọn. Ninu ọrọ rẹ, Olufunke sọ wi pe awọn ọkunrin ti foju oun wina nitori ọpọlọpọ aisotitọ ati ododo ti wọn ti fi ba oun lo. O fi kun un wi pe, ọkọ ti oun fi silẹ, Kevin irabor lo fẹ ẹlomiran lẹyin ti awọn ṣe igbeyawo, ti oun si ti bimọ meji fun un. Bẹẹ lo kilọ fun awọn obinrin pe ki wọn ranti pe, ko si oun ti eniyan ṣe silẹ, ti ko ni ba. Arabinrin naa wa parọwa si awọn obinrin lati ye fẹ ọkọ ọlọkọ, ki idile lee gboro sii, nitori ewu ti o n fa ninu idile ko kere rara. Kí ni Yorùbá ń pe ọmọ tí wọ́n bí lẹ́yìn Àlàbá?",26 Owewe 2019 +"Messi fi Ronaldo, Van Dijk ṣe àkàsọ̀ dé ògo agbábọ́ọ̀lù tó pegedé jùlọ lágbayé"," Oríṣun àwòrán, Getty Images Ìròyìn tó ń tẹ̀ wa lọ́wọ́lọ́wọ́ ní wí pé wọn ti kede Lionel Messi gẹgẹ bii agbabọọlu FIFA to pegede julọ lagbaye. Messi to jẹ balogun ikọ orilẹede Argentina ati Barcelona n gba ami ẹyẹ naa fun igba kẹfa. Messi, Ronaldo ati Van Dijk ni awọn agbabọọẹu mẹta ti wọn yan fun ami ẹyẹ yii. Saaju ikede agbabọọlu to ku oju iwọn julọ lagbaye ni wọn ti kede olukọni ẹgbẹ agbabọọlu Liverpool, Jurgen Klopp ni wọn yan gẹgẹ bii olukọni to pegede julọ. Oríṣun àwòrán, Getty Images Awọn ami ẹyẹ miran ti wọn kede ni iwọnyii: 1.Allison Becker 1.Matthijs de Ligt 2.Sergio Ramos 3.Van Dijk 4.Marcelo Oríṣun àwòrán, Getty Images 1.Luca Modric 2.Frenkie de Jong 3.Eden hazard 1.Kylian Mbappé 2.Lionel Messi",23 Owewe 2019 +Sàkámàǹjeè! Arsenal gbẹ̀yìn gbé ru Aston villa," Oríṣun àwòrán, Getty Images Ori lo ko Arsenal yọ lọwọ Aston Vila ni idije Premiership to waye ni papa iṣire Emirates. Ilẹ kọkọ ṣe bi ẹni fẹ pooyi fun Arsenal ninu ifẹsẹwọnsẹ naa nigba ti John mcGinn gba bọọẹu wọle nitori aikiyesara awọn adilemu Arsenal to n woran lẹyin. Nicolas Pepe gba gbeelẹ koo gba sile, pẹnariti wọle lẹyin ti awọn agbabọọẹu Aston Villa gbe Gendouzi, agbabọọẹu Arsenal lulẹ ninu oju iwọn alapoti Aston villa ko jẹ ko tutu ti wọn tun ti fi gba omiran wọle. Lẹyin eyi ni Calum Chambers ati Aubameyang wa gba ayo kọọkan wọle lati bọ ẹwu itiju ti aston villa fẹ da ro Arsenal ni ibuba rẹ kuro. Pẹlu esi yii, ipo kẹrin ni Arsenal wa lori tabili liigi ilẹ Gẹẹsi bayii pẹlu ami mọkanla. Ọkan lara awọn agbabọọlu Arsenal, Ainsley Maitland -Niles gba kaadi pupa ti wọn si lee jade nitori ikọlu rẹ si agbabọọẹu Aston Villa kan.",22 Owewe 2019 +Liverpool jẹ Chelsea máye ni Stamford bridge," Oríṣun àwòrán, Getty Images Awọn agba bọ wọn ni bi ale iya ẹni ba ju baba ẹni lọ, baba laa pe. Bẹẹ lọrọ ri fun Chelsea nigba ti wọn gbalejo Liverpool ni ifẹsẹwọnsẹ kẹfa, saa idije liigi ti ọdun yii ni ilẹ Gẹẹsi. Trent Alexander-Arnold lo kọkọ gba goolu wọle fun Liverpool nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa wọ iṣẹju kẹrinla ki Roberto Firmino to dee lade funwọn. Amọṣa lẹyin ọpọlọpọ jija raburabu, Ngolo Kante da ẹyọ kan pada fun Chelsea. Gbogbo akitiyan atamatase Chelsea, Tammy Abraham lati yọ ikọ rẹ jade ninu ọfin Liverpool lo ja si pabo. Pẹlu esi yii, ifẹsẹwọnsẹ meji pere ni Chelsea ṣi bori ninu mẹfa ti wọn ti gba ninu liigi saa yi labẹ akoso olukọni wọn tuntun, Frank Lampard. Esi yii si n fi Liverpool silẹ loke tente tabili liigi ilẹ Gẹẹsi. Lẹyin ifẹsẹwọnsẹ mẹfa ti awọn ẹgbẹ agbabọọlu ti gba, Liverpool nikan ni ko tii padanu ifẹsẹwọnsẹ kankan bayii.",22 Owewe 2019 +"Ẹ máà wòran o, ọ̀bẹ ìyà tún ti ba Manchester United ní ìrù ìdí o"," Oríṣun àwòrán, Getty Images Ọwọ iya ba Manchester United ni ile Westham United ni ọjọ Aiku nibi idije Premiership ilẹ Gẹẹsi. Irinajo ti ko lọpẹ ninu ni olukọni iks Manchester United, Ole Gunner Solkjaer ko awọn agbabọọlu rẹ rin lọ si papa iṣire....to jẹ ibuba Westham united nibi ti wọn ti lu wọn ni goolu meji sodo. Oríṣun àwòrán, Getty Images Pẹlu Esi yii, o fihan pe ifẹsẹwọnsẹ meji pere ni Manchester united ṣi bori bayii ni mẹfa ti wọn gba bayii ni saa yii. Andriy Yarmolenko lo kọkọ gba goolu alakọkọ wọle fun Westham ki Aaron Cresswell to fọba lee nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa wọ iṣẹju kẹrinlelọgọrin. Lọwọ yii idi olukọni wọn n gbona bayii pẹlu ironu igbesẹ ti awọn alaṣẹ ẹgbẹ agbabọọlu naa lee gbe bi nnkan ko ba ṣe ẹnuure funwọn laipẹ.",22 Owewe 2019 +Ẹ wo àràmọ̀ǹdà ọmọ ọdún mọ́kànlá tó jẹ́ elégèé àrà tó dáńtọ́ jùlọ," Ọmọ ti yoo ba jẹ Aṣamu, kekere ni yoo ti maa jẹ ẹnu ṣamuṣamu. Chinonso Eche, tii se ọmọ ọdun mọkanla ree, to jẹ elege ara nilu Warri, ko si si elege to dabi rẹ. Lati ọmọ ọdun mẹjọ ni Chinonso ti bẹrẹ ege gige, to si fẹ dabi Messi, Ronaldo ati Okocha. O tun fẹ di ilumọọka agbabọọlu fun awọn gbajugbaja ẹgbẹ agbabọọlu agbaye bii Super Eagles ilk wa, Barcelona, Real madrid ati Chelsea. Ẹ wo fidio yii lati mọ iru ara ti Chinonso n fi bọọlu da nidi ege gige.",15 Owewe 2019 +Egbé agbábọọlù Super Eagles gbàgbé ohun eèlò wọn - Ọlajiire," Oríṣun àwòrán, @NFF Super Eagles kò rántí kó ohun eèlò ìgbábọọlu wọn dání. Agbẹ ti lọ soko idije bẹẹ ko ranti ọkọ ni ọrọ Super Eagles loni. Egbẹ agbabọọlu Super Eagles ti ilẹ Naijiria to lọ si orilẹ-ede Ukraine lati gba boolu ọlọrẹjọrẹ ninu eyi ti wọn ti gbagbe eroja wọn. Super Eagles ti wọn jẹ agbabọọlu àgbà fun ilẹ wa ni wọn ti gunlẹ si ilu Dnipro sugbọn ti wọn ko ranti ko awọn ohun eelo igba bọolu wọn dani. Abẹnugan fun eto are bọọlu fún Super Eagles, Ademọla Ọlajiire lo fi iroyin naa lede ni ọjọ lsinmi ọsẹ yii. O fi kun ọrọ rẹ pe awọn agbabọọlu mẹfa miran ni wọn tun n reti baagi ti ohun eelo wọn wa gẹgẹ bi igbaradi yoo ṣe bẹrẹ ni ọjọ Iṣẹgun ni pẹrẹwu. Wọn ni lẹyin ti ọkọ ofurufu to gbe wọn balẹ tan naa ni wọn rii pe ko si ẹru wọn kankan ninu ọkọ ofurufu ọhun Olori awọn ti wọn jọ kọwọ rin de ilu Dnipro, ni orile ede Ukraine, Dayọ Achor wi pe awón alaṣẹ ọkọ ofurufu Turkey yoo ṣe iranlọwọ to yẹ lati ko ẹru naa pada wa. Dayọ tẹsiwaju pe, asọye to muna doko ti wa laarin ajọ NFF ti ilẹ Naijiria ati alaṣẹ ileeṣẹ ọkọ ofurufu naa lati tete ko awọn ohun eelo naa pada de saaju ọjọ lsẹgun. Idije ọjọ Isẹgun yii lo maa bẹrẹ ni bii agogo meje abọ aṣaalẹ lori papa iṣere nla ti ilu Dnipro.",9 Owewe 2019 +Bianca júwe ilé fún Serena Williams nínú ìdíje l'America," Oríṣun àwòrán, Getty Images Bianca gba ami ẹyẹ mọ agba ọjẹ Serena lọwọ ni New York Idije to gbogo fun Bianca Andreescu naa waye ni Flushing Meadows ni New York laarin ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu kẹjọ si ọjọ kẹjọ, oṣu kẹsan an, ọdun 2019. Bianca Andreescu jẹ ọmọ ọdun mọkandinlogun lati orilẹ-ede Canada lo koju agbaọjẹ Serena Williams ọmọ ọdun mẹtadinlogoji naa ninu idije aṣekagba. 6-3; 7-5 ni wọn pada jọ gba ninu idije aṣekagba naa ni New York. Child Engineer: Olamide Odukọya nílò ìrànlọ́wọ́ láti lọ síléẹ̀kọ́ ìmọ̀ ẹ̀rọ Bianca fo fun ayọ, o ni: Odun yii ni àlá mi wa sí imuṣẹ. O ni: inu mi dun gidi, mo mọ oore nitori mo ti n tiraka tipẹ ti mo ti n woye ọjọ ti maa pade Serena Williams ninu idije. Serena ni gbajugbaja ti gbogbo wa n wo loke ninu ere idaraya yii. Si iyalẹnu gbogbo ero iworan to wa lori papa ni Bianca fidi Serena janle ti o si jẹ ki Serena padanu ife ẹyẹ yii lẹẹkẹrin bayii. Serena funra rẹ gboriyin fun ọdọmọde Bianca, o ni: Inu mi dun fun Bianca, o ṣiṣẹ bi ọmọ akin nitootọ ninu idije yii. Bianca jẹ ọmọ orilẹ-ede Canada. Oun ni ọdọmọde ẹni akọkọ ni Canada to maa gba ami ẹyẹ idije nla bọọlu ẹlẹyin ori tabili. Oríṣun àwòrán, EPA Bianca nigba to lulẹ ninu idijeẹ lọdun to kója. Oun ni ọdọmọde ti ko tii pe ogun ọdun akọkọ to maa gba goolu Grand slam lẹyin Maria Sharapova lọdun 2006. Oun lo tun kọkọ gba Akọkọ ṣe Slam lẹyin ọmọ Russia to gbaa lọdun 2004 ni Wimbledon Bianca jẹ ọdọmọde to ni igbooya ati ọkan akin ninu gbogbo idawọle rẹ, eyi to han ninu idije naa. Oríṣun àwòrán, Getty Images Mo ba oloriire yọ ni ọrọ naa pada ja si Andreescu ni ti ẹnikẹni ba sọ fun oun pe oun a koju Serena Williams ninu idije oun maa sọ pe ẹni naa ti ya were ni. Oun ni gbogbo aye n sọrọ nipa rẹ lori ayelujara lasiko yii pe ko si ohun ti ọdọmọde ko le ṣe yanju! Lọdun to lọ ni Bianca ja nibẹrẹ idije ti ko si si lara awọn igba akọkọ to ṣaaju ninu gbigba bọọlu ọhun. Awọn ara Romania ni obi Bianca jẹ. Nicu ni orukó baba rẹ nigba ti iya rẹ n jẹ Maria. Wọn lọ ṣe atipo ni orilẹ-ede Canada nibẹre ọdun 1990. Lati kekere ni Bianca ti n gba bọọlu ẹlẹyin ori tabili ni eyi to si ti gba ami ẹyẹ bii WTA Premier ni Indian Wells ati Toronto to si gba ẹbun owo rẹpẹte si. Bayii, Bianca n lọ ẹni karun un ni agbaye to si n lọ sile pẹlu ẹbun owo $3.85 miliọnu. Oríṣun àwòrán, AFP Mo di eti mi pa ni si ariwo orukọ Serena ki n to bori! Ẹkọ nla ti Bianca fẹ ki awọn ọdọ kọ ni pe ki wọn maa di eti wọn si ariwo ọja ati pe ki wọn ma bẹru ogbontarigi ti wọn ba fẹ koju lẹnu iṣẹ wọn. O ni oun di eti oun si ariwo ọja awọn eniyan ni bi awọn ero lori papa naa ṣe n pariwo orukọ Serena ki oun to le bori.",8 Owewe 2019 +Àwọn akọni Nàìjíríà padà sílé pẹ̀lú àmì ẹ̀yẹ 121 láti Morocco," Oríṣun àwòrán, @others Olajide Omotayo, ọkan lara awọn akóni to gbogo fun Naijiria ni Morocco Awọn akọni to lọ ṣoju Naijiria ninu idije African Games ti orilẹ-ede Morocco gbalejo ẹ ti de pada sile pẹlu ariwa ayọ. Ilu Abuja to jẹ olu ilu Naijiria ni wọn kọkọ fabọ sí lalẹ ọjọ Aiku. Ipo keji lapapọ ni wọn gbe ninu ẹlẹekejila idije ilẹ Adulawọ ọhun ni Rabat ni Morocco. Ọgbẹni Sunday Dare, minista fun ọrọ awọn ọdọ ati ere idaraya atawọn eekan mii nijọba lo wa ni papakọ ofurufu Nnamdi Azikwe lati ki wọn kaabọ sile. Minista ere idaraya gboriyin fun awọn akọni yii fun gbigbe ogo Naijiria ga ni Morocco. O ṣeleri fun wọn pe oun maa mojuto ipese igbeaye irọrun sii fun wọn lasiko yii paapaa lasiko igbaradi de idije. Orilẹ-ede Egypt to gba idije naa kẹyin naa lo tun bori ni tọdun yii ni eyi ti Naijiria ti gbe ipo keji lapapọ. Egypt ni goolu mọkandinlọgọrun, fadaka mẹrindinlọgọrun ati baba mọkandinlaadọrin nigba ti Naijiria ni apapọ mọkanlelọgọfa. South Africa, Algeria ati Morocco to gbalejo idije naa ni wọn jọ fi jẹ marun un loke tente atẹ idije tọdun yii. Ọjọ kọkandinlogun si ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu kẹjọ ni idije naa waye. Orilẹ-ede Ghana lo maa gbalejo ti ọdun 2023.",2 Owewe 2019 +"Ìjà orogún méjì ní London, Arsenal àti Tottenham ta ọ̀mì"," Oríṣun àwòrán, Getty Images Diẹ lo ku ki omi tẹyin wọ igbin Arsenal lẹnu loni nibi ifẹsẹwọnsẹ awọn ati orogun wọn ni ilu Londọn, iyẹn Tottenham. Tottenham ko fi ojuure wo Arsenal ninu ifẹsẹwọnsẹ naa pẹlu bi wọn ṣe side iya fun Arsenal ni iṣẹju kẹwa ifẹsẹwọnsẹ naa lati ẹsẹ Eriksen. Ogoji iṣẹju ni Harry Kane, balogun ikọ Tottenham ba tun gba ọkan si. Ẹgbé agbábóólù orílẹ-èdè Naìjíríà gba ẹbuǹ wúrà ilẹ Afrika Van Dijk gbadé UEFA mọ́ Messi àti Ronaldo lọ́wọ́ Liverpool kun Arsenal wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́ bí ẹran àsun 'lójúbọ' Anfield Ikú dóró! Agbábọ́ọ̀lù Super Falcons tẹ́lẹ̀, Chiejine jáde láyé lẹ́ni ọdún 36 Wo àwọn eléré ìdárayá mẹ́ta tí àjọ FIFA ti fòfin dè títí ayé Amọṣa, ṣe awọn agba bọ wọn ni bi ẹṣin ba da ni aa tuu gun ni. Ki ifẹsẹwọnsẹ naa to wọ isinmi fun saa akọkọ ni Lacazette, atamatase Arsenal da ọka pada ninu rẹ. Arsenal jẹwọ ọmọ ọkọ fun Tottenham ni abala ikeji ifẹsẹwọnsẹ naa ṣugbọn pẹlu gbogbo kirakita wọn, goolu kan ṣoṣo ti Aubameyang gba wọle nikan ni wọn ri dimu eyi to ko wọn yọ ninu itiju naa. Ori lo ko Tottenham pẹlu yọ lọwọ ogun atẹyinja ṣugbọn ṣa wọn sun iya ta lagba niluu London di ọjọ mii, ọjọọ re. Oríṣun àwòrán, Getty Images Bi ọrọ orogun adedigba ni ifẹsẹwọnsẹ laarin Arsenal ati Tottenham maa n jẹ nitori ifigagbaga awọn mejeeji lori mimọ tani alagbara ẹkun ariwa ilu London, eyi ti a ms si North London. Ireti ọpọ lori ifẹsẹwọnsẹ naa ko kuku ja sofo nitori bi ajere lo ṣe gbona janjan ṣugbọn lẹyin o rẹyin. Ninu awọn ẹgbẹ agbabọọlu mẹfa to maa n du ipo mẹrin akọkọ lori atẹ igbelewọn liigi ilẹ Gẹẹsi, iyẹn Manchester city, Liverpool, Arsenal, Manchester United, Chelsea ati Tottenham, Manchester city pẹlu Liverpool nikan lo bori ninu ifẹsẹwọnsẹ wọn lopin ọsẹ yii, ọmi ni Manchester United ati Chelsea ta ninu ifẹsẹwọnsẹ tiwọn to waye lọjọ satide.",1 Owewe 2019 +Ẹgbé agbábóólù orílẹ-èdè Naìjíríà gba ẹbuǹ wúrà ilẹ Afrika," Oríṣun àwòrán, FIFA.com Ikọ Falconets gbo ewuro soju ojugba won ti ile Cameroon Ẹgbẹ agbaboolu ọjẹ wéwé orilẹ-ede Naijiria ti ọjọ ori wọn ko ju ogun ọdun lọ ni wọn ti fi agba han ojugbaa wọn ti ilẹ Cameroon. Awọn agbaboolu yii kogoja lati gba ẹbun wura ti ilẹ Afrika lẹyin ọdun mejila ti wọn ti gba a gbẹyin. Bo tilẹ jẹ pe, ọmi ni awọn ẹgbẹ agbaboolu naa kọkọ gba ni ori papa Boubker Aamar ni ipele akọkọ ati ikeji ifẹsẹ wọn sẹ naa. Nigba ti adari eto lori papa pe fun idije ifẹsẹ-wọn- sẹ ojule si ojule ti o mu ki Naijiria gba amin ayo mẹta si meji si ile ojugba wọn. Ninu eyi ti o ti fun ẹgbẹ agbaboolu ti orilẹ ede yii ni anfaani lati fi ẹyin ojugba wọn gbolẹ Awọn ẹgbẹ agbabolu mejeeji ni wọn jọ figa gbaga lati jawe olubori ko to di wi pe ẹkọ ko soju mimu fun ikọ ti Cameroon. Nina ti ikọ ti orilẹ ede Naijiria na ojugba wọn yii fihan wi pe igba akọkọ re lati bii ọdun 2007 lẹyin ẹẹmarun ti wọn ti gbiyanju. Domestic Violence: Ìjà láàrin lọkọlaya sọ aya dèrò ọ̀run",30 Ògún 2019 +Van Dijk gbadé UEFA mọ́ Messi àti Ronaldo lọ́wọ́," Oríṣun àwòrán, Twitter/UEFA Adẹyinmu fun ẹgbẹ agbabọọlu Liverpool, Virgil Van Dijk lo gbami ẹyẹ agbabọọlu UEFA to pegede julọ ni saa bọọlu to lọ. Van Dijk fẹyin Cristiano Ronaldo ti Juventus ati Lionel Messi ikọ Barcelona gba lẹ gba ami ẹyẹ naa. Van Dijk wa lara awọn agbabọọlu to pegede nigba ti Liverpool na Tottenham pẹlu ami ayo meji sodo ninu ifẹsẹwọnsẹ aṣekagba idije UEFA Champions Laegue ti saa to lọ. Agbabọọlu Van Dijk to jẹ ọmọ orilẹde Netherlands lo ti n fakọyọ lati to ti darapọ ikọ Liverpool lati Southampton loṣu kinni ọdun 2018 fun pọun marunlelaadọrin(£75m). Agbabọọlu naa ki awọn akẹgbẹ rẹ atawọn ti wọn ran an lọwọ lati gbami ẹyẹ naa. O ni ti ko ba si awọn akẹgbẹ oun, ko lee ṣeeṣe fun oun lati pegede gbami ẹyẹ naa mọ Messi ati Ronaldo lọwọ. Ṣé Van Dijk lè borí Ronaldo àti Messi nínú ìdíje UEFA? Loni ni igbimọ adari ere bọọlu alafẹsẹgba UEFA yoo kede ẹlẹsẹ ayo tọdun yii nilẹ Yuroopu. Awọn akọni mẹta ni wọn jọ n du ami ẹyẹ yii: adiẹyin ẹgbẹ agbabọọlu Liverpool, Virgil Van Dijk, Cristiano Ronaldo ti Juventus ati Lionel Messi to n gba bọọlu fun Barcelona. Oríṣun àwòrán, Reserved getty image Ta ni yoo gba ami ẹyẹ yii laarin awọn akọni mẹta yii? Luka Modric lo yọ lara Ronaldo ati Messi lati gba ami ẹyẹ Ballon d'Or lọdun to kọja. Opo n lero pe o ṣeeṣe ki Van Dijk gbegba oroke mọ Messi ati Ronaldo lara lọdun yii. Lionel Messi ati Cristiano Ronaldo ni wọn ti n gba ami ẹyẹ yii mọ ara wọn lọwọ lati ọdun bii mẹwaa sẹyin. Lọdun 2011 ti wọn kọkọ yan ẹlẹsẹ ayo UEFA. Ronaldo ti gbaa ni ẹẹmẹta iyẹn ọdun 2014, 2016 àti 2017. Nigba ti Lionel Messi ti gba a lẹẹmeji lọdun 2011 ati 2015. Ronaldo lo ran Juventus lọwọ ti wọn fi bori ni Seria A nigba ti Messsi ran Barcelona lọwọ lati gba Liga. Oríṣun àwòrán, ""others ọmọ ju ọmọ lọ ninu idije bọọlu gbigba Laarin ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu keje, ọdun 2018 si ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu keje, ọdun 2019 ni esi abajade ifakọyọ awọn mejeeji ti fihan. Messi ti gba goolu mẹrinlelaadọta sáwọn nigba ti Ronaldo ti gba mejilọgbọn sawọn. Oríṣun àwòrán, Getty Images Ko si ẹni ti ogo ko le kan ninu ami ẹyẹ gbigba Van Dijk ló ti jé akọni pataki ni Liverpool lati igba to ti kuro ni Southampton nibi ti wọn ti bori Champions League ni saa to lọ. Bakan naa ni o ṣe iranwọ fun Manchester City lati gba Premier League. Van Dijk ni agbabọọlu adiẹyin mu akọkọ ti wọn yoo maa wo boya o le gba ami ẹyẹ naa. Van Dijk ti kopa ninu idije mọkandinlọgọta to si ti gba ọpọlọpọ goolu sawọn. Oun tun ni ẹlẹsẹ ayo Liverpool ati agbabọọlu to tii pẹ ju lagbaye (4,465). Oríṣun àwòrán, @others A ju ara wa lọ, ijakadi kọ ni idije de duro bayii Ilu Monarco lorilẹ-ede Faranse ni ikede ẹlẹsẹ ayo naa yoo ti waye.",29 Ògún 2019 +Liverpool kun Arsenal wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́ bí ẹran àsun 'lójúbọ' Anfield," Oríṣun àwòrán, Getty Images Idije Premier League Ajura wa lọ, ti ijakandi kọ o! Liverpool kọ ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal lẹkọ ti wọn ko le gbagbe ni papa iṣere Anfield lọjọ Abamẹta. A na sare ni Liverpool lu Arsenal ninu ifẹsẹwọnsẹ Premier League nirọlẹ ọjọ Satide. Ami ayo meji sodo ni wọn fi fẹyin Arsenal gbi lẹ ni Anfield. Adilemu, Joel Matip lo kọkọ fori kan bọọlu wọ le Arsenal, ki David Luiz to fa Mohamed Salah laṣọ nigba to fẹ gbayo sawọn, ni rẹfiri ba fọn feere pẹnariti. Salah ko beṣu bẹgba, niṣe lo gba pẹnariti naa wọ le, eleyi to mu Liverpool siwaju pẹlu ami ayo meji sodo. Oríṣun àwòrán, Getty Images Idije Premier League Laipẹ lai jina, Salah tun gbayo sawọn eleyi to jẹ ki Liverpool siwaju pẹlu ami ayo mẹta sodo ti Arsenal ko si ri ọkankan da pada. Amọ, Lucas Torreira gbiyanju lati dayo kan pada nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa ku iṣẹju marun un ko pari. Pierre-Emerick Aubameyang ati Nicolas Pepper to ṣẹṣẹ rọpo mọ Arsenal lanfaani lati gba goolu sawọn fun Arsenal, ṣugbọn wọn ko lo anfaani ti wọn ni.",24 Ògún 2019 +Ọwọ́ ba Ole! Crystal Palace pàkúta sí gaàrí Manchester United ní Old Trafford," Oríṣun àwòrán, Getty Images Ajẹtun iya ni Manchester United jẹ lọwọ ẹgbẹ agbabọọlu Crystal Palace lọjọ Abamẹta ninu idije Premier League. Crystal Palace lo kọkọ gba bọọlu sawọn ṣugbọn Manchester United dayo naa pada. Ṣugbọn ọrọ bẹyin yọ nigba ti Crystal Palace gbayo mii wọ le Man U nigba to ku diẹ ki ere bọọlu naa pari. Oríṣun àwòrán, Getty Images Idije Premier League Tamọtiye! Tammy ta Norwich pa mọ́ lé, bí Chelsea ti gbéra Lẹyin ọ rẹyin, ẹrin gba ẹkẹ akọnimọọgba Chelsea, Frank Lampard lẹyin ti ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea gbegba oroke fun igba akọkọ lati igba to ti gori aleefa gẹgẹ bi akọnimọọgba tuntun ni papa iṣere Stamford Bridge. Chelsea fẹyin Norwich City gba lẹ nile wọn ni Carrow Road lẹyin ti wọn ti ta ọmi kan ti wọn si jawe olubori ninu omiran ninu ifẹsẹwọnsẹ meji ti wọn ti gba lati igba ti idije Premier League ti bẹrẹ ni saa yii. Oríṣun àwòrán, Getty Images Idije Premier League Lẹyin iṣẹju mẹta pere ti wọn bẹrẹ ere bọọlu ọhun ni Tammy Abraham gba bọọlu sawọn fun Chelsea. Ṣugbọn Todd Cantwell dayo naa pada lẹyin iṣẹju mẹta mii lo ba di ọmi alayo kọọkan. Ọjẹwẹwẹ agbabọọlu Chelsea, Mason Mount gbayo wọ le eleyi ti Chelsea fi tun wa niwaju ṣugbọn ẹlẹsẹ ayo Teemu Pukki sọ ere bọọlu ọhun ọmi alayo mejimeji. Ẹlẹsẹ ayo Tammy Abraham lo gba mii wọ le fun Chelsea eleyi to jẹ ẹlẹẹkeji rẹ ninu ifẹsẹwọnsẹ naa. Lampard gbéra sọ!Chelsea run Norwich mọ́ lẹ̀ jégéjégé",24 Ògún 2019 +"Ikú dóró! Agbábọ́ọ̀lù Super Falcons tẹ́lẹ̀, Chiejine jáde láyé lẹ́ni ọdún 36"," Oríṣun àwòrán, Twitter/NFF Agbabọọlu Super Falcons tẹlẹ jade laye Iku doro, iku ṣeka, agbabọọlu Super Falcons Naijiria tẹlẹ ri, Ifeanyichukwu Chiejine ti jade laye lẹni ọdun mẹrindinlogoji. Ajọ to n ri si ere bọọlu ni Naijiria lo kede iku Chiejine loju opo Twitter wọn lọsan Ọjọbọ. NFF ṣalaye loju opo wọn pe agbabọọlu Naijiria tẹlẹ ri naa ku lẹyin aisan ranpẹ. Chiejine ṣoju Naijiria nigba mọkanlelọgọta, bẹẹ lo si gba goolu mẹẹdogun sawọn nigba aye rẹ. Chiejine ni balogun ẹgbẹ agbabọọlu obinrin Naijiria akọkọ tọjọ ori wọn ko ju ọdun mọkandinlogun lọ ninu idije ife ẹyẹ agbaye lọdun 2002. Oríṣun àwòrán, Twitter/NFF Iku pa agbabọọlu Super Falcons tẹlẹ NFF ṣalaye pe Ọjọru ọsẹ yii ni agbabọọlu naa dagbere faye.",22 Ògún 2019 +Buhari gbóṣùbà fún D'Tigress lẹ́yìn tí wọ́n lu Senegal gba ife AfroBasketWomen," Oríṣun àwòrán, Twitter/FIBA La ba gbe ife ẹyẹ lọ kuro ni Senegal! Aarẹ Muhammadu Buhari ti gboriyin fun awọn ikọ agbabọọlu alapẹrẹ Naijiria, D'Tigress pe wọn ku iṣẹ. Lọjọ Aiku, ọjọ kejidinlogun ni awọn agbabọọlu obinrin ọmọ Naijiria yii fakọyọ ti wọn tun gbe ife ẹyẹ Afrobasket lọ. Awọn naa ni wọn gba a lọdun 2017 ti wọn gbogo wale fun Naijiria. 60 -55 ni wọn fi fagbahan ikọ Senegal to gbalejo idije naa nibi ti o le ni ẹgbẹrun mẹẹdogun oluworan ti kopa. Aare Muhammadu Buhari to n tukọ orilẹ-ede Naijiria naa ti gboṣuba rabandẹ fawọn olu ọmọ wọnyii pe wọn gba ife ẹyẹ naa lẹẹkan sii. Otis Hughley to je akọnimọọgba ikọ awọn obinrin yii fi idunnu rẹ han lasiko to n ba BBC sọrọ. Oríṣun àwòrán, Getty Images A tun bori ni 2019 - Naijiria O ni inu oun dun pupọ pe idije bọọlu alapẹrẹ ti ni idagbasoke to yẹ laisko yii. O tun gboriyin fawọn agbabọọlu obinrin ti Naijiria ti o n kọ pe pe wọn fakọyọ daadaa. Ọpọ awọn ọmọ Naijiria lo ni iṣẹ takuntakun ni awọn obinrin n ṣe ninu ogo ere idaraya Naijiria lasiko yii. Wolii Arole",19 Ògún 2019 +Lampard wọ gàu! Chelsea tún ṣubú dàánù sọ́wọ́ Liverpool," Oríṣun àwòrán, Getty Images Pàá lẹ́ẹ̀kínní, pàá lẹ́ẹ̀kejì! Ṣé ojú Frank Lampard àtàwọn agbábọ́ọ̀lù Chelsea tí wọ́n ń gbá lọ́tùn ún lósì kò ní fọ́ báyìí? Ẹ̀yin ọmọ Chelsea kí ló ǹ ṣẹlẹ̀ gan an? Liverpool fi pẹnriti na Chelsea ninu idije UEFA Super Cup to waye niluu Istanbul lorilẹede Turkey. Ami ayo pẹnariti marun un si mẹrin ni wọn fi ṣagba Chelsea lẹyin ti wọn ti kọkọ ta ọmi alayo mejemeji. Igba keji ree ti Chelsea yoo fidi rẹmi laarin ọjọ mẹrin lẹyin ti Manchester United na wọn lọjọ Aiku ninuidije Premier League Chelsea láǹfààní láti t'ọ́mọlúábí wọn ṣe pẹ̀lú Liverpool lálẹ́ òní Iduro ko si ibẹrẹ ko si fun ẹni to gb'odo mi lọrọ ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea bayii, lẹyin ti wọn kabuku olorombo lọwọ Manchester United lọjọ Aiku to lọ ninu idije Premier League. Chelsea niṣẹ to pọ lati ṣe lalẹ lalẹ Ọjọbọ nigba ti wọn ba koju Liverpool ninu idije UEFA Super Cup. Oríṣun àwòrán, Getty Images Idije Super Cup Liverpool lo gba ife ẹyẹ UEFA Champions League ni saa bọọlu to lọ nilẹ Yuropu nigba ti Chelsea gba ife Europa League. Ọpọ lo ti bu ẹnu ẹtẹ lu Chelsea lẹyin ti Man U ka ayo mẹrin ọtọọtọ lewọn lọwọ ti wọn ko si le da ọkankan pada. Koda awọn miiran ni akọnimọọgba tuntun fun ikọ agbabọọlu Chelsea, Frank Lampard ko mọ iṣẹ, wọn ni ki wọn le lọ. Ṣugbọn Lampard ni awọn ṣetan fun ipenija idije Super Cup pẹlu Liverpool. Papa isẹre to wa niluu Istanbul lorilẹede Turkey ni ifẹsẹwọnsẹ yoo ti waye.",14 Ògún 2019 +Manchester United dáná sun Chelsea bi ẹràn àgbò iléyá," Oríṣun àwòrán, Getty Images Man United vs Chelsea: Man U fí han Chelsea pe ajá to wọlé ti ẹkun yóò fẹ̀jẹ̀ wẹ̀ Manchester Unite ti fàgbà han Chelsea pe ẹni o ṣe lásìkò tí wọ́n kọlu ara wan nínu ìfẹsẹ̀wọ́nṣe ti wọ́n fi ṣide premiere League sáà yìí, pẹ̀lú àmi ayò mẹ́rì si òdo Àmì ayò méjì ni Marcus Rashford fi sẹ ogun Frank Lampard nínú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ àkọ́kọ́ lẹ́yìn to gba iṣẹ́ akanimọ̀ọ́gbá Chelsea àti àwọn ọmọ ẹyìn rẹ̀ ní ìpele ìkíní àti ìkejì Wolii Arole Anthony Martial àti Daniel james náà ràn Red Devil lọ́wọ́ láti jáwe olúbori Chelsea ninu ìdíje tó dabi pé ó fẹ́ kó Chelsea lóyìí ojú. Oríṣun àwòrán, Getty Images Man United vs Chelsea: Man U fí han Chelsea pe ajá to wọlé ti ẹkun yóò fẹ̀jẹ̀ wẹ̀ Ìyàlẹ́nu ní abájáde ìfẹsẹwọnsẹ̀ ọ̀hun jẹ́ nítori ó jọ bi ẹni pé Chelsea yóò ṣe dáradár jú Manchester United lọ ní sáà àkọ́kọ́, bọ́ọ̀lù ṣe gbá àwsn pada ní ẹ̀ẹ̀mejì bi Emerson àti Tammy Abraham ṣe gbìyànjú tó. O jọ bi ẹní pe àwọn olólùfẹ́ Manchester United ko ni fi bẹ́ẹ̀ ba Chelsea kẹ́dùn bí ìdíje yìí ṣe jẹ èsì tó tíì dára júlọ ni old Trafford pẹ̀lú Chelsea láti ọdun 1965",11 Ògún 2019 +Samuel Okwaraji: Ó pé ọgbọ̀n ọdún tí lónìí ti akọni àgbábọ̀ọ̀lù papo dà," Oríṣun àwòrán, NFF Samuel Okwaraji: Ó pé ọgbọ̀n ọdún tí lónìí ti akọni àgbábọ̀ọ̀lù papo dà O ní ló pé ọgbọ̀n ọdún gbáko ti akọni agbábọ́ọ̀lù, olùfẹ́ orílẹ̀-èdè rẹ̀ kú lásìkò tó ń ṣe ojúṣe rẹ̀ fún orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. A bí Samuel Okwaraji ní ọdún 1964 sí ìdílé ọgbẹ́ni David Okwaraji àti Janet Okwaraji, ó sì lọ ilé ìwé WTC practicing ní Enugu fún iwé alákọbẹ̀rẹ̀ àti Ezeachi fún grammer, bákan náà ló lọ sí Federal Government College ni Orlu ni ìpínlẹ̀ Imo. Ó lọ sí fasiti ni Rome ni orilẹ̀-èdè Italy níbi to ti gba oye nínú ìmọ̀ òfin bàkàn náà lo tún gba oye ipele kejì sùgbọ́n kò lo èyí lẹ́yìn to pari ẹ̀kọ́ rẹ̀. Lásìkò tó ń ka iwé fún ìmọ̀ ofin oní pele kejì ló bẹ̀rẹ̀ si ni gbá bọ́ọ̀lù fún NK Dinamo Zagreb, VfB Stuttgart àti SSV Ulm 1846 níbi to ti fọmọ yọ ninu iṣẹ́ to yàn láàyò. Ọdún 1988 ni Samuel Okwaraji darapọ̀ mọ́ Green Eagles èyí to di Super Eagles lónìí, lásìkò African Nations Cup, o gbá bọ́ọ̀lù lásìkò yìí náà ní Morocco ti o sì gbá bọ́ọ̀lù sáwọ̀n láàrin isẹjú kan níbi ifsẹwọnsẹ pẹ̀lú Indomitable Lions ti Cameroon. Samuel Okwaraji gbá bọ́ọ̀lù ní Summer Olympics to wáye ni Seoul, South Korea, pẹ̀lú awọn bíi Samson Siasia, Rashidi Yekeni, Bright Omokaro, Wole Odegbami, Christain Obi, Jude Agada àti Henry Nwosu. Sùgbọ̀n ọ̀fọ̀ nla ṣe Nàìjíríà ní ọjọ́ kejìlá, oṣù kẹjọ, ọdún 1989 lásìkò ti Okwaraji pé ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n. Ó kú ikú àìtọ́jọ́ lóri pápá níbi to ti n gba bọ́ọ̀lù níwáju àwọn èrò ìwòràn tó lé ni ọgọ́rùn lọ́nà ogun ní pápá ìṣeré National Stadium, ní ìlú Eko. Ibẹ́ lo ti subú lulẹ̀ tó sì kú. Ìṣẹ́jú mẹ́tàlá ló kù ki ìfẹsẹ̀wọ́nsẹ̀ parí láàrín Nigeria ati Angola ní National Stadium ìpínlẹ̀ Eko èyí ti yóò mú wọọn pegede fún ife ẹ̀yẹ FIFA. Láti ọdún yìí ni Nigeria, ọlọ́dani àti àwọn ilé iṣẹ́ tí ń ṣe ǹkan máni gbàgbé láti ránti akọni to ti papodà yìí. Shiite: Ẹ̀mí àti ara wa kọ ohun tí ìjọba ń ṣe sìwa láti 2015 Babajide Raji Fashola tó jẹ́ gómìnà ìpínlẹ̀ Eko nígbà kan rí, mọ ere Okwaraji si ìwáju National Stadium láti maa ṣe ìránti rẹ̀ ńtori pé pápá iṣèré yìí náà ló ti kú. Oríṣun àwòrán, Lagos state Samuel Okwaraji: Kíni ẹ̀yín mọ nípa akọni yìí? Bí oní ṣe wá jẹ́ ọgbọ̀n ọdún gééré gé ti Samuel Okwaraji papo dà ajọ NFF náà ń selédè lẹ́yin rẹ̀. Oríṣun àwòrán, Nff Samuel Okwaraji: Ó pé ọgbọ̀n ọdún tí lónìí ti akọni àgbábọ̀ọ̀lù papo dà Ọ̀pọ̀ ọmọ Nàìjíríà ló ti ń ṣelédè lẹ́yìn Okwaraji bí wọ́n ṣe n ṣe ayájọ́ ọgbọ̀n ọdún to ti papo dà, sùgbọ́n wọ́n fi ẹdùn ọ̀kan wọ́n hàn pé, NFF àti ìjọba ko ti ṣe tó: Samuel Okwaraji: Ó pé ọgbọ̀n ọdún tí lónìí ti akọni àgbábọ̀ọ̀lù papo dà",12 Ògún 2019 +N jẹ Arsenal ò ti dà òkùtà sí Newcastle nígbá báyìí?," Oríṣun àwòrán, Getty Images Arsenal fi Newcastle sẹ̀sín, o dà òkùtà sí wan nígbá Ẹgbẹ́ agbábọọ̀lù Arsenal náà ti darapọ̀ mọ Machestger City, Liverpool àti Tottenham nínú ìdíje Premiere League tuntun sáà yìí to ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀. Arsenal náà jẹ́wọ́ ọmọ ọkọ bi wọn ṣe fi ojú Newcastle gbolẹ̀ nínú ìdíje àkọkọ ti wọ́n gba nínú òjò wẹ́liwẹ́li ní pápá St James lónìí Bótilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo rẹ̀ fẹ́ lọ jáí níbẹ̀rẹ̀ nítori gbogbo àwọn ọmọ agbabọọlu tuntun ti wọ́n kowo rà ló wà lóri ìjọko Mesut Ozil àti Sead Kolasinac, Unai Emery gan o fara lálẹ̀ ní gbogbo sáà àkọ́kọ́. Àṣẹ̀yìnwá àṣẹ̀yinbọ̀ Aubameyang ló gbá bọ́ọ̀lù sáwọn lẹ́yìn to gé Ainsley Maitland - Niles àti Martin Dubravka légèé tán. Oríṣun àwòrán, Getty Images Arsenal fi Newcastle sẹ̀sín, o dà òkùtà sí wan nígbá Nicholas Pepe àti Dani Ceballos o wulẹ̀ le ta pútu bótilẹ̀ jẹ pé Emery fún wọ́n ni ààyé láti fí orúkọ wan hàn níle aláró. Gbogbo ìgbìyànjú Newcastle láti gba ẹsan pàda, pabo ló jási oo Gbogbo àwọn ọmọ ti ikọ agbábọọlu Arsenal rà ni Chelsea naa kan ludo lónìí lái foya rárá, Alexandre Lacasete àti David Luis, bákan náà ni Pepe ti wọ́n rà láti France náà o gbẹ́yìn ninu ìdíje tònìí Ẹ̀wẹ̀, ẹnikan kò tẹ̀ fún ìkeji nínú ìfẹsẹwọnsẹ láàrin Leicester city àti Wolves.",11 Ògún 2019 +Ọ̀pọ̀ olólùfẹ́ eré bọ́ọ̀lù bẹnu ẹ̀tẹ̀ lu bí Iwobi àti Lukaku ṣe lọ," Oríṣun àwòrán, Arsenal FC Agbabọọlu Arsenal to jẹ ọmọ Naijiria, Alex Iwobi wa lara awọn agbabọọlu to darapọ mọ ẹgbẹ agbabọọlu miiran l'Ọjọbọ to jẹ gbedeke ọjọ ti ẹnikẹni le ra agbabọọlu tuntun ṣaaju saa bọọlu mii to bẹrẹ lonii ọjọ Ẹti nilẹ Gẹeṣi. Iwobi fọwọsi adehun ọdun marun un pẹlu ẹgbẹ agbabọọlu Everton lẹyin ti wọn san miliọnu mejidinlọgbọn owo pọun fun Arsenal. O tun wa ninu adehun pe Everton yoo pada fi miliọnu meje kun owo naa to ba ya. Akọnimọọgba Arsenal Unai Emery ni Iwobi ṣiṣẹ takuntakun nigba to fi wa pẹlu ikọ Arsenal. Emery ṣapejuwe Iwobi gẹgẹ bi awokọsẹ rere fawọn ọjẹwẹwẹ agbabọọlu, bẹẹ lo gbadura fun un wi pe yoo ṣoriire nibi to n lọ Bi Iwobi ṣe fi Arsenal silẹ lọ Everton jẹ ibanujẹ fun ọpọlọpọ ololufẹ rẹ, ko da aworan ẹni tomi n bọ loju rẹ lọpọ wọn ṣapejuwe bi ọrọ naa ṣe dun wọn to. Ohun to kọju sẹnikan, ẹyin lo kọ sẹlomiiran, nibi tawọn ti n sunkun pe Iwobi lọ, lawọn kan ti n yọ pe Iwobi kuro ni Arsenal. Awọn kan tiẹ nifẹ Iwobi ṣugbọn awọn ko fẹ wa lara awọn agbabọọlu Arsenal mọ. Igba kan n lọ, igba kan n bọ, bi Iwobi ṣe fi Arsenal silẹ bẹẹ naa ni David Luiz gbera pa lati Chelsea wa si Arsenal. Luiz kọwọ bọwe adehunọlọdun meji pẹlu Arsenal lẹyin ti Arsenal san miliọnu mẹjọ owo pọun. Lẹyin ọ rẹyin, ẹlẹsẹ ayo, Romelu Lukaku fi ẹgbẹ agbabọọlu silẹ lọ ikọ agbabọọlu Inter Milan. Lukaku wa lara awọn agbabọọlu ti Man U ko lo daadaa mọ ni saa bọọlu to lọ, Marcos Rashford lo maa n saa ba gba aye rẹ. Ẹwẹ, lọkunrin lobinrin lawọn ololufẹ Inter Milan tu jade lati ki Lukaku kaabọ si ikọ agbabọọlu wọn l'Ọjọbọ.",9 Ògún 2019 +Jesus gbá góòlù sáwọ̀n gba ife Community Shield fún Man City," Oríṣun àwòrán, Getty Images Ajura wa lọ tijankandi kọ o! Manchester City ṣina iya fun Liverpool lati gba ife ẹyẹ community Shield ni papa iṣere Wembley. Man City naa lo gba ife ẹyẹ Premier League Liverpool lọwọ ni saa bọọlu to lọ. Raheem Sterling lo kọkọ gbayo wọ le fu Man City ṣugbọn Joel Matip sayo naa pada, lo ba di ọmi alayo kọọkan. Wo mi ki n gba siọ ti wọn n pe ni pẹnariti ni wọn yanju rẹ. Oríṣun àwòrán, Twitter/Pep Team Manchester City lo papa jawe olubori lẹyin ti wọn gba pẹnariti wọ le ti Liverpool si le da mẹrin pada. Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Manchester City àti Liverpool ṣíde sáà bọ́ọ̀lù tuntun Saa bọọlu tuntun bẹrẹ lọjọ Aiku, ọjọ kẹrin, oṣu kẹjọ, Manchester City ti wọn gba ife ẹyẹ Premier League ni saa to lọ yoo ṣide saa tuntun pẹlu Liverpool tawọn gba ife ẹyẹ UEFA Champions League. Oríṣun àwòrán, Getty Images Saa bọọlu tuntun bẹrẹ Man City tun gba ife ẹyẹ FA, bẹẹ ni wọn ti Carabao Cup, awọn kan tiẹ sọ pe ife mẹrin ni wọn gba lẹyin ti wọn ṣina iya fun Chelsea ninu ifẹsẹwọnsẹ Community Shield ti saa bọọlu to lọ. Man City gba ife ẹyẹ Premier League pẹlu ami ayo mejidinlọgọrun un nigba ti Liverpool tẹle wọn pẹlu ami ayo mẹtadinlọgọrun. Asiko tun ti to lati bẹrẹ iwọ o ju mi, emi o ju ọ lẹẹkan si, aago mẹta ọsan ọjọ Aiku ni ifẹsẹwọnsẹ naa yoo bẹrẹ ni papa iṣere Wembley niluu London. Aṣole fun Manchester City Ederson ati agbabọọlu aaringbungbun Fernandinho ko ni le kopa ninu ere bọọlu naa, nitori o pẹ diẹ ki wọn to pada de lẹyin ti wọn ṣoju Brazil ninu idije Copa America, Claudio Bravo Bravo ni yoo dile mu fun Man City ninu ifẹsẹwọnsẹ ọhun. Oríṣun àwòrán, Getty Images Saa bọọlu tuntun bẹrẹ Bakan naa, Sadio Mane ko ni kopa ninu ifẹsẹwọnsẹ Community Shield nitori oun naa ṣẹṣẹ de lati idije AFCON 2019 nibi ti orilẹede rẹ, Senegal fidi rẹmi ninu aṣekagba idije naa. Igba akọkọ re e ti Liverpool yoo kopa ninu ifẹsẹwọnsẹ Community Shield lati ọdun 2006 nigba ti na Chelsea pẹlu ami ayo meji sẹyọkan. Eyi ni igba kejila ti Man City yoo kopa ninu Community Shield, wọn si ti gba ife naa lẹẹmarun un . Ayinla Kollington: ọ̀rẹ́ ni èmí àti Barrister kó tó jáde láyé Àìsàn jẹ́ kí àwọ̀ ara Amida dàbí ara ẹja",4 Ògún 2019 +Mo ṣe tán láti padà sórí pápá - Enyeama," Oríṣun àwòrán, Instagram/Vincent Enyeama Enyeama n gbaradi lati darapọ mọ ikọ agbabọọlu tuntun Aṣọle fun ẹgbẹ agbabọọlu Naijiria tẹlẹ ri, Vincent Enyeama ti ṣe tan lati pada sori papa lẹyi ti ko ṣoju ikọ agbabọọlu kankan fun ọdun meji. Enyeama wa pẹlu ikọ agbabọọlu ilẹ Faranse, Dijon nibi ti o ti n gbaradi fun ati pada sori papa. Ẹgbẹ agbabọọlu Dijon fun Enyeama laye lati wa pẹlu wọn di ipari oṣu yii. N100,000 Nairà mà ni Dino gbé dání lójú agbo, kò náwó yàlà-yòlò - Ayefele Lẹyin naa ni akọnimọọgba Stéphane Jobard yoo gbe igbesẹ bo ya Enyeama yoo dara pọ mọ ikọ Dijon. Ọdun 2017 ni aṣọle Enyeama ṣoju ikọ agbabọọlu kẹyin lẹyin to fi ẹgbẹ agbabọọlu Lille silẹ loṣu kẹjọ ọdun 2018. Oríṣun àwòrán, Instagram/Vincent Enyeama Enyeama n gbaradi lati darapọ mọ ikọ agbabọọlu tuntun Enyeama ṣoju ẹgbẹ agbabọọlu Naijiria ninu ifẹsẹwọnsẹ ọgọrun o le kan. Bakan naa lo mu 'le fun Naijiria ninu idije AFCON marun un ko to fi ikọ agbabọọlu Super Eagles silẹ. O wa lara ikọ agbabọọlu Naijiria to gba ife ẹyẹ AFCON 2013 lorilẹede South Africa.",27 Agẹmo 2019 +"Transfer Window: Pogba, Maguire, Bale, Neyman, báwo ni nkan ṣe ń lọ?"," Oríṣun àwòrán, Getty Images Akọnimọọgba ẹgbẹ agbabọọlu Liverpool, Jurgen Klopp ti ni ko si n to o jọ rara pe oun fẹ ẹ ra Gareth Bale Manchester United ti n gbaradi de lilọ Paul Pogba kuro lọdọ wọn. Wọn si ti fẹ ẹ fi ẹnu ko lori rira agbabọọlu orilẹ-ede Serbia, Sergel Milinkovic-Savic, ni aadọrin miliọnu Pọnun. (Mirror) Amọ ṣa, o ṣeeṣe ki Pogba o ṣi lo ọdun kan si i ni Old Trafford, eyi to le mu ifasẹyin ba rira ti wọn fẹ ra Milinkovic-Savic. (Express) Bakan naa ni o ṣeeṣe ko di dandan fun Manchester United lati wa ọgọrin miliọnu Pọnun ti wọn yoo fi ra agbabọọlu England, Harry Maguire lẹyin ti Eric Bailly fi orunkun ṣeṣe lasiko idije ọlọrẹsọrẹ pẹlu Tottenham ni Ọjọbọ. (Mirror) Akọnimọọgba ẹgbẹ agbabọọlu Liverpool, Jurgen Klopp ti ni ko si n to o jọ rara pe oun fẹ ẹ ra Gareth Bale lati ọwọ Real Madrid. O ni afojusun oun ni lati kọ ẹgbẹ agbọọlu to dantọ, kii kan ṣe lati ko eniyan jọ saa. (Independent) O dabi ẹni pe ko si bi agbabọọlu iwaju fun Juventus ati Portugal, Cristiano Ronaldo ṣe mọ idunna-dura a ṣe to, ko ni le fi ọrọ yi atamatase Paris St-Germain, Neyman lọkan pada lati darapọ mọ idije Serie A, nitori o da bi ẹni pe Neyman ti pinnu lati pada si Barcelona. (Star) Oríṣun àwòrán, Getty Images Barcelona lo wu Neyman ko pada si. Borossia Dortmund naa ti n duna-dura lati ra ọmọ orilẹede Brazil, Malcom ni miliọnu mejilelogoji Euro. (Goal) Akọnimọọgba Napoli, Carlo Ancelotti ni ọkan oun balẹ bi omi inu amu pe ẹgbẹ agbabọọlu oun ni yoo ra James Rodriguez lati ọwọ Real Madrid. (Marca) Everton naa ti sọ fun Crystal Palace pe awọn ṣetan lati san ọgọta miliọnu Pọun fun rira atamatase orilẹ-ede Turkey, Cenk Tosun ni igba kan naa pẹlu Wilfred Zaha. Amọ aya wọn ṣi n ja pe o ṣeesẹ ki Chelsea o ja a gba mọ wọn lọwọ. (Telegraph) Atamatase ni, Moussa Dembele naa yoo wa lara awọn to ṣeeṣe ki wọn o ta Romelu Lukaku. (Sky Sports) Ẹgbẹ agbabọọlu Wolves naa ti n ba Real Madrid sọrọ lati ra Jesus Vallejo fun saa kan, nigba ti Real Madrid naa ti n sunmọ bebe ati fẹnuko lati gba miliọnu mẹtadinlogun Pọnhun lọwọ AC Milan lati ra atamatase, ọmọ orilẹede Italy Patrick Cutrone. (Mail) Kayeefi: Facebook ni Wolii Arole Jesu fi tàn an wọ agbo, orí rẹ̀ ni wọ́n fi s'owó",26 Agẹmo 2019 +Abẹ̀ṣẹ́kùbíòjò dágbére fáyé lẹ́yìn ìjà rẹ," Oríṣun àwòrán, Getty Images Iku ogun lo pada pa akinkanju abẹṣẹkubiojo Maxim Iroyin ni kete ti wọn pari ija naa ni o ti hande pe Maxim ko le da rin kuro ni gbagede ija. Dadashev Maxim ọmọ Russia ni oun ati Subriel Matias jọ ja du bẹliti abẹṣẹkubiojo IBF light welterwiight. Buddy McGirt to n dari rẹ lo ni ki wọn fopin si ija naa ni ipele ikọkanla lọjọ Eti nigba ti Maxim ko lagbara mọ. Ni kete ti wọn lu aago yii ni wọn ti gbe Maxim lọ sile iwosan nitori ẹjẹ ti n dà ni agbari rẹ nibi ti wọn ti sare ṣiṣẹ abẹ fun un. Lẹyin iṣẹ abẹ yii ni ko pada ji mọ. Oríṣun àwòrán, Getty Images Lẹyin iṣẹ abẹ yii ni ko pada ji mọ. Ajọ to n mojuto ọrọ ẹṣẹ kikan ni orilẹ-ede Russia ni awọn ti bẹrẹ iṣẹ iwadii kikun lori iṣẹlẹ yii. Sekinat Quadri ọmọ ọdun meje ajẹsẹ to fẹ dabi Anthony Joshua Umar Kremlev to jẹ akọwe agba ajọ naa ni o dabi pe ejo iku Maxim fẹ lọwọ ninu. O ni Maxim jẹ ọkan lara awọn ọdọmọde abẹṣẹku bi ojo ti Russia n wo fun ọjọ iwaju rere. 'Mo ń ṣa ike jọ láti san owó ilé iwé ọmọ mẹ́ta' Akọwe agba naa ni ajọ naa maa ṣatilẹyin to yẹ fun ẹbi Maxim pẹlu owo ati pe awọn yoo ṣe iwadii naa bi o ti yẹ. O gba pe mimọ ootọ iṣẹlẹ yii yoo jẹ ki aato gidi wọ inu ere idaraya wọn gbogbo. Orilẹ-ede Amerika ni Dadashev n gbe to ti gba ami ẹyẹ mẹtala nibi ija mẹtala to ti bori sẹyin. Subriel Matias to jẹ ẹlẹṣẹ lati Puerto Rico lo ti na Maxim pupọ ni Maryland. Oríṣun àwòrán, others A ju ara wa lọ, ..... McGirt to jẹ atọna rẹ ni oun n ni ko dẹkun ija nigba ti oun rii pe ọrọ fẹ maa bẹyin yọ. Ajọ RBF ni Russia ni o n rẹ Dadashev sii nigba ti awọn oniṣegun oyinbo ni nkan ti ṣe ọpọlọ rẹ. Lọjọ Iṣẹgun ni Maxim wa gbẹmi mi nigba ti ọkan re kọ iṣẹ lẹyin iṣẹ abẹ ti wọn ti ṣe fun un. Chef Adefunkẹ: Òórùn ewé tí wọ́n n pọ́n ìrẹsì ọ̀fadà si jẹ́ adùn lọ́tọ̀",24 Agẹmo 2019 +Kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ Algeria là kìnìún Senegal mọ́ lẹ̀ lẹ́ẹ̀kejì gba ife AFCON," Oríṣun àwòrán, Getty Images Ikilọ kẹlẹgbẹ mẹgbẹ rẹ ni ẹgbẹ agbabọọlu Algeria fi ifẹsẹwọnsẹ aṣekagba idije AFCON 2019 ṣe fun ikọ Senegal lẹyin ti wọn rọ ojo iya le wọn lori lẹẹkeji ti wọn si gba ife ẹyẹ AFCON mọ wọn lọwọ. Lẹyin iṣẹju meji pere ti ere bọọlu naa bẹrẹ ni ọkan lara awọn agbabọọlu Algeria, Baghdad Bounedjah gba goolu aramọnda kan wọ le, eyi to mu Algeria siwaju. Bo tilẹ jẹ pe ogbontarigi adilemu fun Senegal, kalidou koulibaly ko lanfani lati kopa ninu ifẹsẹwọnsẹ ọhun nitori o ti gba kaadi olomi ọsan(yellow card) meji ninu ifẹsẹwọnsẹ mẹta, ikọ Senegal ṣi ja fitafita isbẹsibẹ. Ilumọọka agbabọọlu Liverpool, Sadio Mane ati awọn akẹgbẹ gbiyanju agbara wọn lori papa, ṣugbọn awọn agbabọọlu Algeria duro wamuwamu bi ologun ti wọn. Oríṣun àwòrán, Getty Images Igba keji ree ti Algeria yoo gba ife ẹyẹ AFCON lẹyin ti wọn gbaa fun igba akọkọ lọdun 1990. Bakan naa, igba keji ree ti ẹgbẹ agbabọọlu Senegal yoo gba ipo keji(fadaka) ninu idije AFCON lẹyin ti wọn kọkọ gbaa lọdun 2002 nigba ti wọn gbalejo idije naa. ",19 Agẹmo 2019 +Èyí tí mo ṣe tó! Mikel kéde ìfẹ̀hìntì fún Nàìjíríà," Oríṣun àwòrán, Instagram/John Obi Mikel Eyi ti mo ṣe to! Ọrọ yi ni balogun ẹgbẹ agbabọọlu ọkunrin Naijiria, John Mikel Obi sọ l'Ọjọbọ. Balogun Super Eagles, Mikel to fọrọ naa lede loju opo Instagram rẹ, sọ pe, asiko ti to fun oun lati fi ikọ agbabọọlu Naijiria silẹ. Mikel fi fọto ara rẹ soju opo Instagram, o sọ pe orilẹede Egypt loun ti bẹrẹ si soju Naijiria, nibẹ naa si ni oun pari rẹ si. O sọ pe ni Egypt lọdun 2006 loun ti ṣoju Naijiria ninu idije AFCON fun igba akọkọ, bakan naa ninu idije AFCON 2019 loun ti fi adagba rọ bọọlu gbigba fun Naijiria si. Mikel dupẹ lọwọ Naijiria fun anfani lati ṣoju orilẹede rẹ ninu oniruuru idije ere bọọlu. Oríṣun àwòrán, Instagram/John Obi Mikel Mikel ni oun gbe igbesẹ lati fi ẹgbẹ agbabọọlu Naijiria silẹ lati fun awọn ọjẹwẹwẹ agbabọọlu laaye. O ni ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles gbiyanju ninu idije AFCON 2019, lẹyin ti wọn gba ami ẹyẹ baba(Bronze) tii ṣe ipo kẹta. Naijiria na Tunisia pẹlu ami ayo kan sodo l'Ọjọru lati gba ipo kẹta.",18 Agẹmo 2019 +Ẹyẹ j’ẹyẹ lọ! Super Eagles f'ìyẹ́ bo Carthage Eagles Tunisia mọ́ 'lẹ̀," Oríṣun àwòrán, Getty Images Diẹ to ninu nnkan oni nnka, eyi lo difa fun ẹgbẹ agbabọọlu Naijiria, Super Eagles ti wọn ipo kẹta tawọn nnkan n pe ni golden bronze ninu idije AFCON 2019. Lẹyin iṣẹju mẹta pere ti wọn bẹrẹ ere bọọlu ọhun ni ẹlẹsẹ ayo, Odion Ighalo gba bọọlu sawọn eyi fun Naijiria lanfani lati siwaju ninu ifẹsẹwọnsẹ to kangun su aṣekagba. Oríṣun àwòrán, Getty Images Ighalo ti gba goolu marun un wọ le bayii lati igba ti idije AFCON 2019 ti bẹrẹ. O ṣeesẹ ko jẹ pe Ighalo lo maa gbami ẹyẹ agbabọọlu to gbayo sawọn julọ ninu idije AFCON 2019. Oríṣun àwòrán, Getty Images Ẹwẹ, akọnimọọgba ẹgbẹ agbabọọlu Naijiria, Gernot Rohr sọ ṣaaju ifẹsẹwọnsẹ alẹ Ọjọru pe lẹyin ere bọọlu pẹlu Tunisia l'oun yoo kede bo ya oun yoo tẹsiwaju pẹlu ikọ agbabọọlu Naijiria. AFCON 2019: Ìjà ẹlẹyẹ méjì láàrin Nàìjíríà àti Tunisia Ẹgbẹ agbabọọlu Naijiria ati ti orilẹede Tunisia yoo jọ ta kanungbọn lalẹ Ọjọru lati ja fun ipo kẹta ninu idije AFCON 2019 lorilẹede Egypt. O ku iṣẹju aaya ki ifẹsẹwọnsẹ to kangun si aṣekagba laarin Super Eagles ti Naijiria ati Algeria tan ni Riyad Mahraz gbayo keji wọ le Naijiria. Eleyi to jẹ ki Algeria fi Naijiria ṣatẹgun si ipele aṣekagba pẹlu ami ayo meji sẹyọ kan. Oríṣun àwòrán, CAF Eleyi to jẹ ki Algeria fi Naijiria ṣatẹgun si ipele aṣekagba pẹlu ami ayo meji sẹyọ kan. Ẹgbẹ agbabọọlu Tunisia kuna lati de ipele aṣekagba lẹyin ti Senegal fagba han wọn pẹlu ami ayo kan sodo. Igba akọkọ ree ti ẹgbẹ agbabọọlu Tunisia yoo de ipele to kangun si aṣekagba lati igba ti wọn ti gba ife ẹyẹ AFCON lọdun 2004 ti wọn gbalejo idije ọhun. AFCON 2019: Ki akọnimọọgba Naijira bá wọn sọ̀rọ̀ kóríyá Ọmi ni ikọ agbabọọlu Tunisia ta ninu ifẹsẹwọnsẹ mẹta ti wọn kọkọ gba, ki wọn to na Ghana pẹlu wo mi ki n gba siọ ni ipele ẹlẹni mẹrindinlogun. Oríṣun àwòrán, CAF Eleyi to jẹ ki Algeria fi Naijiria ṣatẹgun si ipele aṣekagba pẹlu ami ayo meji sẹyọ kan. Ṣugbọn wọn fakọyọ ni ipele ẹlẹni mẹjọ lẹyin ti wọn fiya jẹ Madagascar pẹlu ami ayo mẹta sodo. Ikọ Super Eagles jawe olubori ninu ifẹsẹwọnsẹ meji ti wọn kọkọ gba pẹlu Burundi ati Guinea ki Madagascar to fiya jẹ wọn lai ro tẹlẹ. Oríṣun àwòrán, CAF Naijiria fi Cameroon paa ni ipele ẹlẹni mẹrindinlogun pẹlu ami ayo mẹta si meji ki wọn to ṣeya fun South Africa ni ipele ẹlẹni mẹjọ. Algeria lo ṣẹ Naijiria leegun ẹyin ninu ifẹsẹwọnsẹ to kangun si aṣekagba. ",17 Agẹmo 2019 +Mahrez dá Super Eagles dùbúlẹ̀ lórí pápá oko tútù," Oríṣun àwòrán, Getty Images Super Eagles gbiyanju, ṣugbọn omi pọ ju ọka lọ, ami ayo meji ni Algeria fi ṣe wọn leegun ẹyin lalẹ ọjọ Aiku minu ifẹsẹwọnsẹ to kangun si aṣekagba ninu idije AFCON. Ṣiṣeṣisẹ ba adilemu, William Troost-Ekong, lo ba gba bọọlu sawọn Naijiria nigba ti ifẹsẹwọnsẹ ọhun de ogoji iṣẹju. Ṣugbọn ẹlẹsẹ ayo Odion Ighalo dayo naa pada ni abala keji ere bọọlu ọhun. Amọ, agbaọjẹ agbabọọlu Algeria, Riyad Mahrez ṣẹ ikọ agbabọọlu Naijiria leegun ẹyin lẹyin to gbayo keji wọ le fun Algeria ni iṣẹju ti ere bọọlu naa pari. Oríṣun àwòrán, Twitter/Super Eagles Naijiria fidi rẹmi Ni bayii, Naijiria yoo koju Tunisia l'Ọjọru lati ja fun ipo kẹta, nigba ti Algeria yoo ta kangbọn pẹlu Senegal ninu ifẹsẹwọnsẹ aṣekagba idije AFCON 2019. Ẹgbẹ agbabọọlu Naijiria, Super Eagles sọ pe awọn ti ṣetan lati jẹwọ ara awọn fun ikọ agbabọọlu South Africa ninu ifẹsẹwọnsẹ ipele ẹlẹni mẹjọ lalẹ Ọjọru. Ẹlẹsẹ ayo, Ahmed Musa ni awọn ko ni ja awọn ololufẹ awọn ọmọ Naijiria kulẹ nigba tawọn ba n koju Bafana Bafana. Oríṣun àwòrán, Reuters Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Nàìjíríà ti já ní AFCON Musa ni awọn mọ pe awọn ọmọ Naijiria fẹran ere bọọlu gan an, o ni awọn ti ṣetan lati pa wọn lẹrin. O ni awọn agbabọọlu Naijiria ko ro nnkan miiran bayii ju bi wọn yoo ṣe fiya jẹ South Africa lọ. Oríṣun àwòrán, Instagram/William Troost-Ekong Musa sọ pe awọn duro digbi fun ohun kohun ti Bafana Bafana ba fẹ gbe wa. Igba mẹrinla ni Naijiria ati South Africa ti pade ara wọn. Naijiria jawe olubori nigba mejila ọtọọtọ, ti South Africa si jawe olubori nigba kan.",10 Agẹmo 2019 +Kí ni Bode 'Thomas' ní ṣe pẹ̀lú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ Nàìjíríà àti South Africa?," Oríṣun àwòrán, GIUSEPPE CACACE Igbakiigba ti ọrọ ba ti pa Naijiria ati South Afrika pọ,bi igba pe wọn jọ fẹ doju ija kọ ara wọn ni o maa n jẹ. Lori papa ere bọọlu papa julọ, wọn kii fi oju ọrẹ wo ara wọn tabi ọmọ ilẹ adulawọ kanna. Awọn mejeeji fi ifigagbagba yi han nigba ti Naijiria ati South Afrika pade ninu idije AFCON 2019 Naijiria bori South Afrika pẹlu ami ayo meji sookan ti o si tumọ si pe wọn yoo tẹ siwaju lọ abala to kangun si aṣekagba. Loju opo Twitter ati Facebook, iroyin aṣeyọri Naijiria ti mu ki awọn ọmọ ile naa ati awọn akẹgbẹ wọn lati South Afrika ma fọrọwerọ. Nibi ọrọ yi ni awọn aṣa kan ti jẹyo eleyi ti o gba ori ayelujara kan. Ọmọ Yoruba to ba n gbe ilu Eko yoo ti gbọ orukọ Bode Thomas ri. Opopona kan nilu Eko lo n jẹ Bode Thomas lagbegbe Surulere amọ lẹyin ti Naijiria fi ẹyin South Afrika janlẹ, o gba itumọ miiran Oríṣun àwòrán, Google A ó jà fitafita láti ríi pé a ò já kulẹ̀ lónìí - Genort Rohr Lati oju opo Twitter, diẹ lara awọn itunmọ tuntun ti awọn eeyan fun orukọ yi re e: Lotitọ ati ododo, ọtọ ni nnkan ti olorin to kọrin rẹ jẹjẹ sọ ninu orin ti awọn ọmọ Naijiria yi itumọ rẹ pada si Bode Thomas. T'oun ti pe wọn mọ itunmọ rẹ, awọn ọmọ Naijiria ni ko kan awọn nitoripe asiko ree fawọn lati fi South Afrika ṣe yẹyẹ. Wilfred Ndidi: Mi ò fi dáa yín lójú pé a máà bórí o! Idẹyẹ si awọn ọmọ Naijiria lati ọwọ awọn eeyan South Afrika kan ko jẹ tuntun mọ. Amọ bayii ti Naijiria ti gbewuro soju South Afrika, nnkan ti yi pada ti awọn ọmọ Naijiria si ni asiko to bayi ki awọn naa ṣe idẹyẹ si sawọn ọmọ Naijiria. Samuel Chukwueze ẹlẹsẹ ayo to ge awọn ọmọ South Afrika lori papa ni wọn ni o n bawọn deye si South Afrika pada Ossai Joshua tilẹ ni Super Eagles fi aṣeyọri wọn ninu ifẹsẹwọnsẹ naa jẹ ogede South Afrika ni. Lakotan gbogbo awọn nkan ti awọn eeyan n sọ ko ju ere lọ irufẹ eleyi ti o ma n waye laarin awọn alatilẹyin ere boolu jakejado agbaye.",11 Agẹmo 2019 +Amuneke fipò sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí akọ́nimọ̀ọ́gbá Tanzania," Oríṣun àwòrán, Getty Images Emmanuel Ameneke Ẹgbẹ agbabọọlu orilẹede Tanzania, TFF fi aridaju han lọjọ aje pe Emmanuel Amuneke ti fi ipo rẹ silẹ gẹgẹ bi akọnimọọgba ẹgbẹ agbabọọlu orilẹede naa ni tubi nnubi. Eyi waye lẹyin ti Taifa Stars ti wọn ṣẹṣẹ kopa ninu idije ife ẹyẹ Nations Cup lati ọdun 1980 ko lee tẹsiwaju mọ ninu idije to n waye ni Egypt tori wọn ja kulẹ lẹẹmẹta. A ó jà fitafita láti ríi pé a ò já kulẹ̀ lónìí - Genort Rohr Ọdun 2018 ni wọn yan ọmọ ẹgbẹ agbabọọlu Naijiria tẹlẹri, Amuneke gẹgẹ bii akọnimọọgba ẹgbẹ agbabọọlu orilẹede Tanzania. Ati ẹgbẹ agbabọọlu ati akọnimọọgba wọn, Amuneke jọ tọwọ bọwe adehun lati fopin si iṣẹ rẹ gẹgẹ bi TFF ṣe fi si oju opo ayelujara wọn. Fulani Kidnapping: Owó púpọ̀ la san kí wọ́n tó fi mi sílẹ̀ Ọgbẹ naa ni awọn yoo yan akọnimọọgba kan na fun 'gba diẹ lẹyin ti awọn ba ṣe ipade pajawiri lọjọbọ ọsẹ oun si ni yoo dari awọn fun idije ife ẹyẹ African Nations Championship (CHAN) eyi ti wọn yoo bẹrẹ loṣu yii. Amuneke to tun ti jẹ agbabọọlu fun Barcelona ni igbakeji akọnimọọgba Naijiria nigba ti Naijiria jawe olubori ni ife ẹyẹ agbaye FIFA U- 17 fun igba kẹẹrin i UAE lọdun 2013. Lẹyin ọdun meji lo dari Naijiria lọ si idije FIFA U- 17 ẹlẹẹkarun un ni chile eyi to mu ki o gba igbega di akọnimọọgba fun ikọ Flying Eagles U- 20. Gẹgẹ bii agbabọọlu, Amuneke ko ṣee fọwọ rọ sẹyin ninu ikọ Super Eagles, oun lo jẹ goolu mejeji ni AFCON 1994 lorilẹede Tunisia nibi ti Naijiria ti fi ami ayo meji si ẹyọkan pẹlu Zambia gba ipo keji nilẹ Afirika.",8 Agẹmo 2019 +Sọ àsọtẹ́lẹ̀ orílẹ̀èdè tí yóò borí ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ t'òní, . Tomomewo Favour: olóṣèlú kìí ṣe ọ̀daràn tàbí alágbèrè,24 Òkùdu 2019 +"France Vs Nigeria: Super Falcons takú síbẹ̀, àmọ́ ẹ̀pa kò bóró mọ́"," Oríṣun àwòrán, FIFA.COM Awon omo Naijiria kan saara si ẹgbẹ agbaboolu obinrin Naijiria, Super Falcons lẹyin ti ikọ France bori wọn ninu idije ife ẹyẹ agbaye awọn obinrin pẹlu ami ayo kan si odo. Oju opo Twitter mì titi lẹyin ifẹsẹwonse naa pẹlu bi awon ololufẹ ikọ Super Eagles ṣe gboriyin fun ikọ Super Falcons nitori wọn gbiyanju lati se daradara ju ikọ France. Ikọ France ti di olori Group A bayii ninu idije ife ẹyẹ agbaye awọn obinrin, FIFA Women's World Cup lẹyin ti wo-mí-ngba-si-ọ ti adari ifẹṣẹwọnsẹ naa fun Wendie Renard lati gba ni ẹẹmeji. Super Falcons nilo ọmi ninu ifẹsẹwọnsẹ o kere tanalẹ oni lati tẹsiwaju ninu idije ife ẹyẹ agbaye to n lọ lọwọ lorilẹede France. Nnkan ko ṣẹnu fun ikọ agbabọọlu Naijiria ninu ifẹsẹwọnsẹ akọkọ ti wọn gba lẹyin ti Norway fiya jẹ wọn pẹlu ami ayo mẹta sodo. Ṣugbọn ẹgbẹ agbabọọlu Naijiria jẹwọ orukọ wọn gẹgẹ bi aṣaaju ikọ agbabọọlu obinrin lati ilẹ adulawọ lẹyin ti fagba han South Korea pẹlu ami ayo meji ninu ifẹsẹwọnsẹ keji ti wọn gba. Bo ti lẹ jẹ pe Super Falcons ja kulẹ ninu ifẹsẹwọbnṣẹ wọn pẹlu France, wọn ṣi ni anfani lati wa lara awọn ikọ mẹrindinlogun akọkọ ti wọn si tun le gbe ipo kẹta. Akọnimọọgba Super Falcons Thomas Dennerby gborinyin fun ikọ obinrin Naijiria naa. O ni akọni ni wọn, o si fi aidunu rẹ han wipe wọn fun France laaye lati gba wo-mí-ngba-si-ọ lẹẹmeji ọtọtọ. Akọnimọọgba Super Falcons, Thomas Dennerby sọ pe oun nigbagbọ pe Naijiria si le fakọyọ lalẹ oni bi wọn ti ṣe pẹlu South Korea. O fikun ọrọ rẹ pe yoo dara julọ ti Naijiria ba le fagba han France, nitori yoo fun wọn ni igboya lati koju ẹnikẹni ni ipele ẹlẹnimẹrindinlogun. Ami ayo mẹjọ sodo ni France fun Super Falcons ninu ere bọọlu ọlọọrẹsọọrẹ ti wọn jọ gba lọdun 2018. Ṣe Super Falcons le yi ero Afirika pada lori ere bọọlu awọn obinrin? Fun awọn agbabọọlu Naijiria, ife ẹyẹ agbaye awọn obinrin kọja ere bọọlu lasan. Oríṣun àwòrán, Twitter/NG_Super Falcons Ikọ Super Falcons nikan lẹgbẹ agbabọọlu ilẹ Afirika ti ko tii pa ikankan jẹ ninu gbogbo idije ife ẹyẹ agbaye to ti waye lati ọdun 1991 ti idije naa ti bẹrẹ. Ṣugbọn oniruuru iṣoro lo n koju awọn agbabọọlu obinrin lorilẹede Naijiria. Éégún tó wà nídí Yoruba Bollywood, Samo Baba f'ojú hàn o! Ọpọ eeyan ni ko ri ere bọọlu ni Naijiria gẹgẹ ere idaraya to yẹ ki obinrin maa ṣe. Ẹlẹsẹ ayo fun Naijiria to n gba bọọlu fun ikọ Barcelona, Asisat Oshoala sọ pe bakan naa lọmọ ṣori kaakiri gbogbo ilẹ Afirika. Iba Gani Adams: Bẹ́ẹ gbé màláíkà kan lọ sí Aso Rock, kò lè ṣàṣeyọrí Oshoola ni awọn agbabọọlu ni Afirika n gbiyanju lati yi ero ọpọ eeyan nilẹ Adulawọ pada pe obinrin ko wa fun ile idana nikan. Ninu idije ọdun 1999 ni Super Falcons ti rin jina julọ nigba ti wọn de ipele komẹsẹoyọ ẹlẹni mẹjọ. Iṣẹ pọ fun wọn lati ṣe nigba ti wọn ba koju France lalẹ ọjọ Aje. Oríṣun àwòrán, Getty Images Akẹgbẹ Oshoala, Francisca Ordega to n gba bọọlu fun ikọ Shanghai Shengli tiẹ sọ pe Naijiria niṣẹ to pọ lati ṣe lori ero awọn eeyan nipa ere bọọlu obinrin. Ordega ni mama oun sọ fun oun pe ko si ọkunrin to maa fẹ oun sile niwọn igba t'oun ba tẹsiwaju pẹlu bọọlu gbigba. Ṣugbọn o ni inu mama oun ti dun bayii nitori oun ti di araba ninu bọọlu gbigba. Ordega to jẹ ẹni ọdun marundinlọgbọn ti gba bọọlu lorilẹede Russia, Sweden, America, Australia, Spain ati China. Oríṣun àwòrán, Getty Images Francisca Ordega nigba to n gba bọọlu fun ikọ Sydney FC Ordega ranti bi France ṣe lu Naijiria ni alubami ni bii ọdun sẹyin, nitorinaa, ohun kan ṣoṣo to wa lọkan rẹ ni eṣan. Ordega ni ''awọn ko bẹru France,'' o ni ami ayo mẹjọ ti France ka lawọn kii ṣe ohun toju ko riri. O fikun ọrọ rẹ pe Germany ti na Naijiria ni 8-0 ri lọdun 2011 ṣugbọn wọn se e ki wọn to jẹ ẹ nigba tawọn mejeeji pade ninu idije ife ẹyẹ agbaye. Akẹgbẹ rẹ, Oshoala naa sọ pe ko le sẹeṣe ki France na Naijiria ni 8-0 lọdun 2018, ki wọn tun wa tun wọn na lalẹ ọjọ je.",17 Òkùdu 2019 diff --git a/BBC/bbc-yoruba.csv b/BBC/bbc-yoruba.csv new file mode 100644 index 000000000..f110884d8 --- /dev/null +++ b/BBC/bbc-yoruba.csv @@ -0,0 +1,167 @@ +ìṣẹ́jú kan bbc,ìsẹ̀lẹ̀ jákèjádò orílẹ̀èdè àgbáyé láàárín ìṣẹ́jú kan,ìṣẹ́jú 26 sẹ́yìn,àkójọpọ̀ ìsẹ̀lẹ̀ jákèjádò orílẹ̀èdè àgbáyé láàárín ìṣẹ́jú kan lórí bbc. +ṣé lóòtóͅ ni ilé ẹjóͅ pàsẹ kí peter obi má se ìpolongo ìdìbò ní lekki toll-gate?,"oríṣun àwòrán, peter obi/twitter ajọ awọn agbẹjọro fun oludije sipo aare legbe oselu labour party, peter obi ti ni ko si otitọ ninu iroyin pe ileẹjọ paṣẹ fun awọn lati ma se ipolongo ni lekki tollgate ni ipinle eko. ọjọ kini, oṣu kẹwaa ni ipolongo idibo naa yẹ ko waye. iroyin to n kaakiri ni pe ileẹjọ kan nipinlẹ eko paṣẹ fun ẹgbẹ ati awọn ololufẹ wọn lati maṣe korapọ si opopona lekki toll gate. ohun ti wọn le e ṣe nikan ni lati rin kọja nibẹ. o yẹ ko le ni miliọnu mẹrin awọn ọdọ ti yoo pejo po si ibi ipolongo idibo naa. amọ agbẹnusọ fun awọn agbejͅoro ẹgbẹ oṣelu labour ninu atẹjade ni kii ṣe ohun ti adajọ sọ niyẹn. o ni aṣẹ ẹgbẹ ni ki ẹgbẹ oṣelu labour ṣe iwọde ni agbegbe lekki, ikeja, surulere ati festac. bakan naa ni o ni ileẹjọ gba wọn laaye lati ṣe iwọde kọja nibẹ, amọ ko gbọdọ jẹ ibi apejọpọ won. awọn agbẹjọro bii mẹwaa, ti adedotun ajulo ṣe agbatẹru fun gbe ẹgbẹ oṣelu labour party lọ si ileẹjọ lori ẹsun pe wọn ko gbọdọ lọ lekki toll-gate fun iwode kankan. awọn agbẹjọro naa ni ẹgbẹ oṣelu labour party fẹ da omi alaafia ipinlẹ eko ru ni, eleyii ti yoo da wahala bii iwọde endsars silẹ. iwọde naa to yẹ ko waye ni ọjọ kini, oṣu kẹwaa ọdun 2022, amọ wọn tako eleyii. wọn ni oṣu kẹwaa, ọdun 2020 naa ni iṣẹlẹ endsars waye nigba naa lohun, ti o si fa rogbodiyan kaakiri orilẹede naijiria. gẹgẹbi atẹjade to wa ni ita ṣe sọ, adajọ wọgile ipe fun ki ipolongo ma waye ni ipinlẹ eko. bakan naa ni adajọ ni ko si otitọ kankan ninu iroyin pe ipolongo idibo naa yoo dabi ti endsars. o ni rogbodiyan bẹ silẹ nigba ti awọn ologun ṣekọlu si awọn afẹhọnuhan naa ni ogunjọ, oṣu kẹwaa, ọdun 2020. adajọ ni iwọde endsars ko ni nkankan ṣe pẹlu ipolongo idibo ẹgbẹ oṣelu ti wọn ni ẹtọ si labẹ ofin lati ṣe. ẹwẹ, ajọ eleto idibo ni naijiria, inec ti fun awọn ẹgbẹ oselu ni aṣẹ lati bẹrẹ ipolongo idibo ṣaaju eto idibo gbogboogbo ti yoo waye ni ọjọ karundinlọgbọn, oṣu keji, ọdun 2023.",29 owewe 2022,"egbẹ oṣelu labour ni ileejo gba ki ẹgbẹ oṣelu labour ṣe iwọde ni agbegbe lekki, ikeja, surulere ati festac." +ní yàjóyàjó ariwo sọ lórí fídíò olùkọ́ tó na akẹ́kọ̀ọ́ bí ẹran àìjẹ ní cameroun,"and we ll keep you signed in. sign in or register you need one to watch live tv on any channel or device, and bbc programmes on iplayer. it’s the law. nípasẹ̀ adedayo owolabi, funmi jokotade àti olubusola afolayan gbogbo àkókò tí a kọ jẹ́ ti uk ilé ẹjọ́ gíga ní kí oriade ní eko lọ sí ẹ̀wọ̀n ọdún 15 adajọ hakeem oshodi ti ile ẹjọ giga ni eko ti gbe idajọ kalẹ pe ki baalẹ shangisha, mutiu ogundare, fi aṣọ penpe roko ọba fọdun mẹẹdogun lori ẹsun pe o pete pero ijinigbe ara rẹ. iwa to hu yi gẹgẹ bi adajọ ṣe wi ṣakoba omi alaafia ilu. bakan naa ni ile ẹjọ tun ran ọkan lara awọn aburo rẹ adams mohammed naa lẹwọn. gẹgẹ bi awọn to gbe ẹjọ yi lọ siwaju ile ẹjọ ṣe wi wọn ni ọjọ karun un oṣu keje ọdun 2017 ni baalẹ pete yi. wọn ṣalaye pe ogundare jọwọ ara rẹ ki wọn baa le jiigbe lna ti da omialaafia ilu ru. koda wọn ni iyawo rẹ ati aburo rẹ lọwọ ninu fiimu ti wọn po pọ yi. toriu iwa to hu lọjọ naa lọhun, gomina ipinlẹ eko to wa lori aleefa akuinwumi ambode yọ nipo rẹ gẹgẹ bi balle shangisha. ninu idajọ ti adajọ oshodi gbe kalẹ, o ni ki ogundare lọ sẹwọn ọdun mẹwaa fun ẹsun akọkọ lallae si anfaani owo faaini. fun ẹsun keji o ni ko lọ sẹwọn ọdun kan pẹlu anfaani lati san owo faaini ẹgbẹrun lọna igba naira. akọrin takasufe raapu lorileede amẹrika coolio ti jade laye. akọrin yi ti ọpọ ranti fun orin rẹ gangsta s paradise dagbere fun duniya lẹni ọdun mọkandinlọgọta. ọrẹ rẹ ọlọjọ pipẹ jarez posey sọ fawọn akọroyin ni amẹrika pe awọn ba oku rẹ ni ilẹẹlẹ baluwe ile ọrẹ rẹ to wa ni los angeles. lati nkan bi ọdun 1980 ni coolio ti bẹrẹ iṣẹ orin ṣugbọn o fẹsẹ rinlẹnile agodo nigba to gbe orin gangsta paradise jade lọdun 1995. nkan to ṣokunfa iku rẹ gaan ko ti daju titi di akoko yi. amọ ọgbẹni posey to koko gbe iroyin iku rẹ jade sọ pe awọn oṣiṣẹ ilera s pe o ṣeese ki o jẹ pe ọkan rẹ ṣadede mu ina lọ(cardiac arrest) coolio,ti orukọ abisọ rẹ n jẹ artis leon ivey jr gba ami ẹyẹ grammy fun orin gangsta s paradise ti wọn si lo orin naa ninu fiimu dangerous minds nibi ti gbajugbaja oṣere tiata nii michelle pfeiffer ti kopa. orin yi jẹ orin tawọn eeyan fẹran lati maa gbọ koda o ti le ni eeyan biliọnu kan to ti gbọ loju opo spotify gẹgẹ bi wọn ṣe fi si oju opo wọn. nigba aye rẹ, coolio ṣiṣẹ akọrin yi fun nkan to le ni ogoji ọdun. laarin igba taa n wi yi, o gbe alibọọmu mẹjọ jade to si ami ẹyẹ american music award. bẹẹ naa ni o gba ami ẹyẹ mtv video music awards mẹta. awọn orin rẹ mi to gba ori afẹfẹ to gbe jade nigba naa ni fantastic voyage, rollin with my homies, 1, 2, 3, 4 (sumpin new), ati too hot. titi to fi jade laye, coolio ṣi n kọrin koda oun ati awọn akọrin aye atijọ mii bi vanilla ice ati young mc ṣi jọ kọrin papọ ni texas ni nkan bi ọjọ meloo kan ṣẹyin. snoop dog, mc hammer,ice cube ati vanilla ice ti n fi ọrọ ikẹdun iku rẹ ṣọwọ loju opo twitter. fidio arakunrin kan to din dundu iya fun awon akẹkọọ ilẹ ẹkọ kan lorilẹede cameroun ti da rugudu silẹ bayii lori ayelujara. fidio ọhun ti awọn eeyan ẹgbẹrun mejidinlaadọjọ (148,000) ti wo lori twitter ṣe afihan arakunrin kan to wọ kootu alawọ funfun kan, to n lo okun funfun lati na awọn akẹkọọ naa ti wọn da ikun delẹ ninu aṣọ ileẹkọ wọn. ko din ni akẹkọọ ọgbọn, ninu eyi ti awọn obinrin pẹlu wa ninu, ninu fidio naa. ni ọjọ iṣẹgun ni iṣẹlẹ yii ṣẹlẹ ni ileẹkọ aladani kan ni ilu yaoundé to jẹ olu ilu orilẹede cameroun. ọkan lara awọn oṣiṣẹ ileẹkọ naa ṣalaye fun bbc pe pipẹ ti awọn akẹkọọ naa pẹ de ileẹkọ lo ṣokunfa iya ti wọn jẹ. oludasilẹ ileẹkọ naa sọ fun bbc pe, minisita fun eto ẹkọ girama lorilẹede cameroun, nalova lyonga yoo ṣe abẹwo si ileẹkọ naa l’ọjọru nitori iṣẹlẹ naa. ọpọ lo ti bu ẹnu atẹ lu ohun to ṣẹlẹ naa lori ayelukara “a gbọdọ dẹkun iwa ipa lawọn ileẹkọ. aṣilo agbara niyi.” ni ọrọ ti eeyan kan sọ loju opo twitter “idi ti awọn aṣiwaju alasilo agbara ṣe pọ nilẹ afrika. a kii fẹ ba awọn aṣiwaju wi, koda bo ba jẹ pe ohun ti wọn n ṣe ba kudiẹ kaato” ni ọrọ ti ẹlomiran sọ loju opo twitter kan naa. ""we really need to stop school violence. it is abuse,"" one twitter use said. amọṣa awọn kan sọ pe, ni t awọn o, awọn ko ni ariwisi kankan si ohun to ṣẹlẹ naa. gẹgẹ bi eeyan kan lori twitter ṣe tun sọ, “wọn to ọrẹ si idi awa naa bi eleyii, o tubọ jẹ ki iwa ọmọluwabi, nini afojusun rere ati mimọ ohun to tọ ati eyi to yẹ wọ wa lara bi ẹwu ni.” ofin ko fi aye fifi iya jẹ akẹkọọ nileẹkọ silẹ lorilẹede cameroun, amọ o si n waye nibẹ. ṣaaju l’osu yii, olukọ kan gba iwe lọ rọkun nile fun igba diẹ lẹyin to na akẹkọọ ileẹkọ girama oniṣẹọwọ kan lẹkun gusu orilẹede naa debi pe o sese ninu oronro inu rẹ. minisita feto ẹkọ girama lorilẹede naa ni lati pe ipade apero apapọ lori iwa ipa lawọn ileẹkọ, eyi yoo si wayr laarin ogunjọ si ọjọ kẹtalelogun oṣu kejila nilu yaoundé ẹgbẹgbẹrun ọmọ ilẹ japan ti jade lati ṣe isin idagbere fun adari orilẹede naa tẹlẹ, shinzo abe ti wọn yinbọn pa. awọn onilẹ ati alejo to fi mọ awọn adari orilẹede ti wọn jẹ ọrẹ timọ-timọ pẹlu orilẹede japan ni wọn pejọ pọ si ibi ipejọpọ idaro naa. bio tilẹ jẹ pe awọn kan ko fi ara mọ bi wọn ṣe isinku rẹ ni isinku orilẹede( state burial). awọn ti ko faramọ mọ isinku naa ṣe ifẹhọnuhan lasiko ti isinku naa n lọ lọwọ. oṣu keje ni agbebọn kan yinbọn lu shinzo abe leemeji, to si gba ibẹ lọ opo aarẹͅ orileede japan papoda naa, akie abe lo wọ kimono dudu, to si n rin jẹlẹnkẹ pẹlu eeru ọkọ rẹ lọwọ ninu igo ti wọn fi n ṣe isinku. lẹyin naa lo gbe e si ori ipele ti wọn si aṣọ funfun bo pẹlu aworan olotu orilẹede naa tẹlẹri. shinzo abe to jẹ ẹni ọdun mẹtadinlaadọrin ki o to papoda ni wọn pa ni oṣu keje lẹyin ti wọn fi ibọn ti wọn ṣe ni abẹle yin ibọn lu ni ẹẹmeji, to si gba ibẹ lọ. iṣekupani naa jẹ iyalẹnu fun orilẹede japan nitori iru iṣẹlẹ naa ko i tii waye nibẹ ni ọpọlọpọ ọdun sẹyin. awọn ololufẹ rẹ naa kii fun ọpọlọpọ ọdun to fi jẹ aarẹ wọn, ti o si fun wọn ni ifọkanbalẹ ni gbogbo igba to fi wa ni ipo. amọ awọn ti ko faramọ iru isinku ti wọn ṣe fun un naa n ṣe ifẹhọnuhan wọn sunmọ ibi ti isinku naa ti n waye. o le ni kilomita ila ti awọn eniyan duro lati ṣe ẹyẹ ikẹyin fun sinzo abe. ileeṣẹ aarẹ lorileede naijiria ti fesi si iroyin to gbode pe aarẹ muhammadu buhari ti fọwọ si pe ki wọn yọ festus keyamo kuro nipo agbẹnusọ igbimọ ipolongo idibo bola ahmed tinubu sipo aarẹ naijiria. bola tinubu n dije labẹ ẹgbẹ oṣelu all progressives congress to jẹ ẹgbẹ aarẹ buhari. agbẹnusọ aarẹ garba shehu lo fidi ọrọ yi mulẹ loju opo rẹ ni twiter to si ni iroyin ofege gba a ni ọrọ yi jẹ. shehu sọ pe inu aarẹ buhari ati bola ahmed tinubu dun si iṣẹ ti keyamo n ṣe ni ipo rẹ gẹgẹ bi agbẹnusọ igbimọ ipolongo sipo aarẹtinubu. koda o sọ pe awokọṣe ni keyamo jẹ fawọn ẹgbẹ oṣelu mii nipa iṣẹ to n ṣe garba sheu wa fikun pe awọn mọ nipa ete tawọn kan n pa lati ṣi awọn olori ẹgbẹ apc lọna ki wọn baa le ṣakoba fun ipolongo ẹgbẹ naa fun ipo aarẹ. o rọ awọn ọmọ ẹgbẹ lati ma ṣe faaye gba ayederu iroyin ti awọn kan n gbe kaakiri nipa awọn olori wọn. ọgbẹni keyamo lo ṣe agbẹnusọ igbimọ ipolongo idibo aarẹ muhammadu buhari nigba to dije dupo ni saa keji rẹ lọdun 2019. awọn to n sọ pe buhari fẹ yọ keyamo a maa sọ pe niṣe lo n sọ ọrọ tabuku ijọba buhari ki o baa le gboriyin fun ipolongo ipo aarẹ bola tinubu. keyamo naa fun ara rẹ ti ṣaaju fesi si iroyin iyọni nipo rẹ ti ileeṣẹ iroyin kan ni naijiria gbe jade. esi naa wa loju opo rẹ ni twitter agbé́́bọn pa ènìyàn 12 niʹ ilé èͅkọ́ agbebon ti ṣina bolẹ ni ileẹkọ kan ni russia, to si pa eniyan mejila. awọn to farapa ninu iṣẹlẹ naa jẹ mọkanlelogun. awọn ọmọde meje lo wa ninu awọn to ṣe alaisi ninu iṣẹlẹ naa, ti gbogbo akẹkọọ to wa ni ileẹkọ naa si le ni ẹgbẹrun kan. iṣẹlẹ naa waye ni agbegbe izhevsk. loju ẹsẹ kan naa ni agbebọn naa yinbon pa ara rẹ. iwadii fihan pe ọmọ ileẹkọ naa tẹlẹri ni agbebọn naa. ileeṣẹ iroyin ni russia fi awọn fidio lede nibi ti awọn eniyan ti n paya . ti wọn si n sa asala fun ẹmi wọn. fọnran kan ṣafihan ẹjẹ ni ilẹ kilaasi ati oju ibọn lara ferese pẹlu awọn ọmọde ti wọn bẹrẹ mọlẹ pẹlu ifoya. ni apapọ, ogo wẹẹrẹ meje,agbalagba mẹfa ati awọn ẹsọ alaabo meji lo ba ikọlu agbebọn naa lọ. nibayii, ijọba ti paṣẹ ki wọn ko awọn akẹkọọ ati olukọ kuro nibẹ ni kiakia. bakan naa ni idaro ti bẹrẹ bayii titi di ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kẹsan an, ọdun 2022. obinrin kan, giorgia meloni, ti n mura lati di olootu ijọba akọkọ ni italy bayii bo ṣe n jawe olubori ninu eto idibo to n lọ lọwọ lorile­̣-ede naa. meloni sọ pe oun ko ni fa ori apakan fikan silẹ ninu iṣẹjọba oun lẹyin ibo naa. ninu awọn esi to ti n jade lọwọ, ibo tirẹ ti fi ida mẹrindilọgbọn ju ti ẹni to tẹle, enrico letta, lọ. lara awọn to n ṣatilẹyin fun meloni ni silvio berlusconi, to jẹ olootu ijọba orilẹ-ede naa nigba kan ri. to ba ni ida mẹrinlelogoji ibo naa, egbẹ rẹ ni yoo maa ṣakoso ile igbimọ aṣofi ilẹ naa. ẹwẹ, ọwọ aarẹ orilẹ-ede naa, sergio mattarella ni ẹni ti yoo di olootu ijọba ilẹ naa wa. lara awọn ohun ti meloni fi kede lasiko ipolongo ibo ni pe oun ko ni faye gba ibalopọ laarin akọ si akọ ati abo si abio. o tun sọ pe oun yoo gbogun ti awọn alakakiti ẹsin musulumi. lara awọn eto ti meloni ni ireti lati ṣe to ba de ori alefa ni fifopinsi bi awọn eeyan ṣe n wọ orilẹ-ede naa lọna aitọ pẹlu ọkọ oju omi lati orilẹ-ede libya, atawọn eto mii fun itura awọn araalu. àwòrán òkúta tó ṣààmì ibi tí òkú ọbabìnrin elizabeth wọlẹ̀ sí ti jáde sí gbangba, wo ìyè owó tí wàá ná fi wo o aafin buckingham nilẹ gẹ̀ẹ́sì ti ṣagbejade aworan àkọ́kọ́ okuta iyebiye to saami ibùsùn ikẹyin ọbabìnrin elizabeth ni windsor. nibayii, wọn ti gbe okuta isinku dudu naa sori ilẹ̀ ile ijọsin george iv memorial chapel níbi tí wọ́n sin òkú ọbabìnrin elizabeth sí lọ́jọ́ aje. wọn kọ orúkọ ará òkúta náà ní ìrántí ọbabìnrin, àwọn òbí rẹ̀ àti ọkọ rẹ̀ tó ti d olóògbé, duke ti edinburgh. eleyi lo rọpo okuta palaba ti wọn ṣe fún ọba george vi ati iya ọbabìnrin. nibayii, okuta tuntun naa ka bayii pé: ""george vi 1895-1952"" ati ""elizabeth 1900-2002"" ati pe ""elizabeth ii 1926-2022"" ati"" philip 1921-2021"". awọn ọba alaye mẹrin yii lo wa ni ilana ẹgbẹ́ awọn ""garter"" eyi to jẹ agba ju ni ilana awọn ẹniabuọláfún"" ni ilẹ̀ britain. awọn ọrọ idagbere to dara jọjọ àti ọpọlọpọ ododo lo yí okuta ara ọ̀tọ̀ naa ka ti wọn gbe sori ibi isinku ọbabìnrin elizabeth. bẹẹ si ni wọn fi ọwọ gbẹ ọrọ ati orúkọ sori rẹ pẹlu awọ dúdú belgium ko lee wa ni ibamu pẹlu ohun to wa nibẹ tẹlẹ̀. o ṣeéṣe ko jẹ pé àwọn araalu yoo lè san owó lati le wo okuta ara ọ̀tọ̀ yii ni kọọkan láti ọjọ ọjọbọ. iroyin ni iye owo ti agbalagba yoo san lati wọlé sibi to wa ni £28.50 lọ́jọ́ satide àti £26.50 làwọn ọjọ́ to ku. ẹgbẹ oṣelu all progressives congress, apc, ti sọ idi ti ko fi si orukọ igbakeji aarẹ, yemi osinbajo lara awọn ọmọ igbimọ ipolongo ibo fun bola tinubu. ọjọ satide ni ẹgbẹ naa gbe akọsilẹ orukọ awọn ọmọ igbimọ naa, ti yoo ṣa amojuto ipolongo ibo fun oludije si ipo aarẹ ninu ẹgbẹ naa, tinubu ati igbakeji rẹ, kashim shettima. orukọ eeyan 422 ni wọn fi sita, ninu eyi ti awọn oṣere naa wa ninu rẹ. lẹyin ti apc fi awọn orukọ naa sita si ni awuyewuye ti bẹrẹ, ti ọpọ si n beere pe kilode ti wọn ko fi osinbajo si. ṣugbọn ninu atẹjade to fi sita, minisita keji fun ọrọ oṣiṣẹ ni naijiria, festus keyamo, to tun jẹ agbẹnusọ fun igbimọ ipolongo naa, sọ pe aarẹ muhammadu buhari lo sọ pe wọn ko gbọdọ fi orukọ yemi osinbajo ati akọwe fun ijọba apapọ, boss mustapha sinu igbimọ naa “nitori pe wọn ni iṣẹ iṣejọba lati gbajumọ”. keyamo sọ pe ko bojumu ki gbogbo awọn olori ijọba fi iṣẹ wọn silẹ lai ṣe nitori ipolongo ibo fun ẹgbẹ. ọjọgbọn osinbajo naa dije ninu ibo abẹle ẹgbẹ oṣelu apc lati ṣoju wọn fun ipo aarẹ ninu eto idibo gbogbo gbo ọdun 2023, amọ o fidirẹmi. 2023 elections: tinubu ṣèpàdé pẹ̀lú ìgbìmọ̀ bíṣọ́ọ́bù ìjọ pẹntikósítà lẹ́kùn àríwá ipade alatilẹkunmọri se ti waye laarin oludije sipo aarẹ fun ẹgbẹ oselu apc, asiwaju bola ahmed tinubu ati igbimọ awọn bisọọbu ninu ijọ kristiẹni igbalode ta mọ si pentecostal, ẹkun ariwa naijiria. ilu abuja si ni ipade naa ti waye ni alẹ ọjọbọ ana, gẹgẹ bo se salaye loju opo twitter rẹ, @official_abat ipade naa si lo waye lasiko ti awọn eeyan kan tun n bu ẹnu atẹ lu bi ẹgbẹ oselu apc se fa tinubu ati igbakeji rẹ, shettima kalẹ, ti awọn mejeeji si jẹ musulumi. nibi ipade naa si ni tinubu ti salaye fun awọn asoju awọn bisọọbu naa, idi to se mu musulumi bii tiẹ gẹgẹ bii igbakeji. o salaye fun bisọọbu agba john praise ti ijọ dominican chapel, to ko awọn bisọọbu naa sodi pe igbesẹ naa kii se amọọmọ se oun. tinubu ni o di dandan ki oun yan shettima to jẹ musululmi lọna ati pese isejọba rere fun awọn ọmọ naijiria ti wọn ba dibo yan oun sipo aarẹ lọdun 2023. bakan naa tun ni tinubu ipade to waye laarin oun ati awọn igbimọ awọn bisọọbu naa se eso rere. sugbọn yoruba ni isọrọ ni igbesi, awọn naijria ti wa n fesi si ikede ti tinubu fi soju opo ayelujara rẹ naa. bi awọn eeyan kan se n kan saara si, ni awọn miran n sọko ọrọ si lori igbesẹ naa. awọn asofin kan ni naijiria ti bu ẹnu atẹ lu aarẹ muhammadu buhari lẹyin to ko nnkan bii ọgọrun un eeyan lọ sibi ipade ajọ agbaye to waye niluu new york, lorilẹ-ede amẹrika. awọn aṣofin naa ni, o jẹ ohun to buru jai pe aarẹ yoo ko iye eeyan to pọ to bẹẹ sọdi lọ silẹ amẹrika pẹlu owo iyebiye lasiko ti ara n ni eto ọrọ aje naijiria. lara awọn asọfin ọhun ni muhammad sani musa, to n ṣoju ẹkun ila oorun niger, lati ipinlẹ niger. asọfin naa ni oju gba oun ti fun aarẹ buhari ati awọn olubadamọran rẹ bi wọn ko ṣe dẹkun rẹ lati maṣe gbe igbesẹ naa. o ni “nigba ti mo ri iye eeyan to kọwọrin pẹlu aarẹ lori ẹrọ amohunmaworan, oju gba mi ti fun wọn.” “ọpọ araalu lo n pariwo ebi, koda, ijọba gan tun fẹ ya owo kun eto iṣuna, kilode ti a fi wa n fi obitibiti owo sọfo lati ko ọpọ ero tẹle aarẹ lọ irinajo?” sẹnetọ naa ni bii igba ti eeyan ba n fi owo ilu sọfo ni irinajo naa ri, nitori awọn eeyan bii ọgọrun naa ni ijọba yoo san owo ọkọ ofurufu wọn, yatọ si owo ile itura ati owo ounjẹ wọn. o pari ọrọ rẹ pe o yẹ ki ijọba maa ṣaanu awọn araalu, ko si maa din iye owo to n fi ṣofo ku. èyí lohun tí ààrẹ buhari à tàwọn olùdíje kọ̀ọ̀kan sọ níbi ìdìbò abẹ́nú apc buhari rọ gbogbo awọn oludije lati rii pe wọn ko sa fi ẹgbẹ oṣelu apc silẹ bi wọn ba padanu ibo abẹnu naa nitori pe omi ṣi n bẹ lamu fun ẹgbẹ oṣelu naa. o ni bi o ti lee wu ko ri, iṣọkan ẹgbẹ oṣelu apc ṣe koko. aarẹ buhari wa rọ awọn aṣojudibo lati dibo yan oludije to ni iṣọkan orilẹede naijiria lọkaan ti ko sii fi ilọsiwaju naijiria sere. èyí lohun tí ààrẹ buhari à tàwọn olùdíje kọ̀ọ̀kan sọ níbi ìdìbò abẹ́nú apc buhari rọ gbogbo awọn oludije lati rii pe wọn ko sa fi ẹgbẹ oṣelu apc silẹ bi wọn ba padanu ibo abẹnu naa nitori pe omi ṣi n bẹ lamu fun ẹgbẹ oṣelu naa. o ni bi o ti lee wu ko ri, iṣọkan ẹgbẹ oṣelu apc ṣe koko. aarẹ buhari wa rọ awọn aṣojudibo lati dibo yan oludije to ni iṣọkan orilẹede naijiria lọkaan ti ko sii fi ilọsiwaju naijiria sere. aarẹ gotabaya rajapaksa ti kọ iwe fi ipo rẹ sile gẹgẹ bi aarẹ lẹyin ti o fẹsẹ fẹẹ kuro lọ si orilẹ ede singapore latari bi awọn olugbe ilu ṣe fẹohunhan lori eto iṣejọba rẹ. igbagbo wa pe o fẹ kuro ni sri lanka ki o to kọ iwe fi ipo rẹ sile ni nitori ki ijọba tuntun ma baa fi ofin gbe e. ọwọngogo ounjẹ, epo bentiro ati awọn ohun miiran ni o ti nira lorilẹde naa. ni olu ilu colombo, pẹlu ijo ati ẹrin ayo ti awọn olufẹhonuhan fi n yọ nigbati wọn gbọ iroyin pe aarẹ ti kuro ninu ilu naa “inu wa dun pupo, a le ni isinmi bayi ki a to pada si igbesi aye wa,” viraga perera sọ fun bbc. “lọwọlọwọ bayi, o ti rẹ wa nitori bi a sẹ fehonuhan sugbọn wakati ti a wa yii, a ki ara wa ku oriire.” rajapaksa ti de si orilẹede singapore l ọjọbọ ana pẹlu iyawo ati olusọ abo meji. orilẹde singapore ti wa kede pe awọn ko fun aarẹ rajapaska ni anfani lati wa ni ilu wọn nitori orilẹ ede naa ko ki n fun awọn to ba sa kuro ni ilu wọn ni anfani lati wa ni singapore adele aarẹ lorilẹde sri lanka, ranil wickremesinghe ni ko ni di aarẹ fidihẹ latari bi wọn ko ṣe tii bura fun un. ranil wickremesinghe ni awọn aṣofin orilẹde naa ni ọgbọn ọjọ lati fi ase sii pe ko di aarẹ fidihẹ ni ṣe ni ọjọ ayo di ọjọ ibanujẹ fun arabinrin kan lẹyin ti ọlọpaa mẹrin fi ofin mu arabinrin fun ẹsun ole jija nigba ti igbeyawo re lọwọ lorilẹede uganda. lọjọ satide ọsẹ to kọja ni awọn ọlọpaa naa yawọ ibi ayẹyẹ igbeyawo, ti wọn si mu iyawo lo si agọ wọn ni mbararata, ni iwọ oorun uganda. arabinrin naa lo sun agọ naa mọjumọ, ti wọn si tu silẹ ni ọjọ keji. agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa , fred enanga, ninu atẹsita to fi sita, ni iwa ti awọn ọlọpaa maa wu ni o le gba isẹ lọwọ wọn, nitori nkan ti wọn ṣe ni ko ba ofin mu. o ni awọn ọlọpaa naa lo ṣe isẹ naa lai si ẹri, ti wọn ba ọjọ ayo jẹ fun arabinrin naaa enanga ni ọwọ ti tẹ ọkan lara awọn ọlọpaa naa, ti o siti wa ni ahamọ sugbọn awọn mẹta yooku ti fẹsẹ fẹ kuro ni agbegbe naa. bi isẹ ti arabinrin ti n sisẹ tẹlẹ lo fi ẹsun ole jija kan arabinrin naa, ti wọn si bẹ awọn ọlọpaa nisẹ lati lo mu arabinrin naa awọn eeyan ilu mariga nijọba ibilẹ bariga nipinlẹ niger ti n wa oku eeyan to to ẹẹdẹgbẹta nigba ti omi wọ iboji to wa nilu naa lọ. imaamu agba fun ilu mariga, alhaji alhassan na ibi lo fi idi isẹlẹ naa mulẹ fun bbc ljọru. ""ẹkun omi naa ba iboji ti wọn sin oku eeyan bii ẹẹdẹgbẹjọ si amọ oku ẹgbrun kan pere la tun sin pada si iboji naa nigba ti ẹkun omi naa fa"". o fikun pe awọn tun ti n wa awọn oku ẹẹdẹgbẹta to sọnu amọ awọn ro pe omi ti wọ wọn lọ ni. amọ ihuwasi awọn awakusa to wa ni agbegbe ti itẹ oku naa wa, lo n kọ imaamu ọhun lominu. gẹgẹ bo se wi, iru isẹlẹ bayii ko waye ri lati ọgọta ọdun sẹyin. ogbontarigi agbabọọlu ọmọ naijiria to fi orile-ede austria ṣe ibugbe, david olatukunbo alaba, ti kọ awọn ile igbọnsẹ fun awọn ara ilu remo, nipinlẹ ogun. ọmọ orile-ede naijiria ni awọn obi alaba, sugbọn ilu vienna ni austria ni wọn bi si. oun naa kii si fi pamọ pe ọmọ naijiria ni oun. ọjọ satide, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu kẹsàn-án, ọdun 2022, ni wọn ṣe ifilọlẹ awọn ile igbọnsẹ naa ni ọjà kara tó wa ni ogere-remo. alaba ni oun kọ ile igbọnsẹ naa gẹgẹ bi ara ọna lati ṣe atilẹyin fun akitiyan isejọba muhammadu buhari lati fòpin si bi awọn araalu kan ṣe n yagbẹ ni gba ngba. alaga àjọ to n mojuto ọrọ àwọn ọmọ naijiria nilẹ okeere, abike dabiri-erewa lo kede igbeṣẹ alaba. o sọ ninu atẹjade kan lori twitter rẹ pe oun dupẹ pupọ lọwọ àjọ alaanu david alaba foundation, fun kíkọ àwọn ile igbọnsẹ naa. "" david tun ti n ṣe eto lati kọ ibudo ikọṣẹ fun bọọlu gbigba ni naijiria."" ẹgbẹ agbabọọlu real madrid ni david alaba n gba bọọlu fun lọwọlọwọ. ọwọ́ ọlọ́pàá hisbah zamfara tẹ arákùnrin àti arábìnrin tó ní ìbálòpọ̀ ní ìta gáréèjì awọn oṣiṣẹ ọlọpaa ẹsin hisbah to wa ni ipinlẹ zamfara ti fi panpẹ ofin mu arakunrin kan ati obinrin kan tawọn mejeeji sọ itiju nu ti wọn si bẹrẹ si ni ṣe ibalopọ nitagbangba. ni gareeji ọkọ to wa ni gusua olu ilu ipinlẹ zamfara ni wọn ti kawọn mọ nidi iwa ailojuti yi. ileeṣẹ iroyin pr.nigeria to jabọ iṣẹlẹ yi ni awọn mejeeji ko bikita bawọn ero ṣe n wo wọn ni ita gbangba fiiili kan to wa lẹgbẹ gareeji ọkọ naa. awọn oṣiṣẹ awakọ ati ero to ri wọn nidi iwa yi lo tara kesi awọn oṣiṣẹ hisbah ki wọn to sare wa lati gbe wọn kuro nibẹ. oṣiṣẹ hisbah kan to ba prnigeria sọrọ sọ pe awọn oniṣekuṣe meji yi ko bẹru pe awọn eeyan n wo awọn ti wọn si tẹsiwaju pẹlu iwa buruku yi titi tawọn hisbah fi wa gbe wọn kuro nibẹ. o sọ pe ọkunrin ati obinrin yi ti n leri laarin awọn lori ẹni to jẹ alailojuti julọ laarin wọn. awọn mejeeji n leri si ara wọn nibẹ si ni wọn ti ni kawọn dan ara wọn wo lati mọ ẹni ti jẹ alailojuti laarin wọn ileri ti wọn n ṣe si ara wọn yi ni wọn ba de bi pe wọn bọ ara wọn si ihoho ti wọn si ni kawọn wo ẹni ti yoo laya lati ni ibalopọ ni ita gbangba. ileeṣẹ iroyin prnigeria ni oṣiṣẹ to ba awọn sọrọ ṣugbọn to ni ki wọn fi orukọ bo ohun laṣiri ni awọn oṣiṣẹ hisbah ti wọ awọn mejeeji lọ siwaju ileẹjọ sharia to wa ni kankuri,zamfara. hisbah ti ko wọn lọ si ileẹjọ sharia ti a si lero pe wọn dajọ wọn ni ilana sharia yala fun ẹsun agbere tabi panṣaga nitori iwa ti wọn hu tako ofin ẹsin islaamu ati aṣa awọn eeyan ipinlẹ yi agbere labẹ ofin ni ibalopọ ti ko lẹtọ laarin awọn ti kii ṣe lọkọlaya. panṣaga leleyi to jẹ ibalopọ lọna aitọ laarin awọn to ni iyawo tabi ọkọ ti wọn tun wa n ba ẹlomiran ni ibalopọ aitọ. ẹgbẹ awọn akẹkọọ lorilẹede naijiria, nan ti ni awọn yoo da lilọ bibọ duro ni papakọ ofurufu lorilẹede naijiria ti ijọba ko ba fi opin si iyanṣelodi ti ẹgbẹ olukọ asuu gunle. eyi ko ṣẹyin iyanṣelọdi to ti wọ oṣu meje bayii lori bi ijọba ko ṣe mu adehun to ṣe pẹlu awọn olukọ ṣe. ati aisan owo osu fun wọn ni gbogbo igba ti wọn fi yan iṣẹ lodi. ẹgbẹ nan naa to ṣe ipade ni opin ọṣẹ nipinlẹ ondo bu ẹnu atẹ lu bi ijọba apapọ ko ṣe naani awọn olukọ ati eto ẹkọ paapaa ni naijiria. ‘’ni bayii, a ko bẹbẹ mọ, ko si eto ẹkọ, ko si lilọ bibọ kaakiri orilẹede naijiria’’ bakan naa ni awọn akẹkọọ naa ni ayọ ni igbese wọn lati ti awọn opopona kaakiri naijiria. ‘’bẹrẹ lati ọjọ aje, ọjọ kọkandinlogun, ọdun 2022 ni a o bẹrẹ ifẹhọnuhan miran. ‘’a o ri pe ko si ọkọ ofurufu kankan lati ilẹ okeere to balẹ si naijiria abi eleyii ti yoo jade.’’ ‘’aarẹ buhari gbọdọ san gbogbo owo awọn olukọ to jẹ wọn nitori o ti su wa ki a ba wọn sọrọ ti wọn kọ’’ ‘’a ko ni gba ki awọn akẹkọọ joko si ile nigba ti awọn oloṣelu n ran ọmọ wọn lọ si oke okun. ‘’#occupytheairports yoo bẹrẹ ni ọjọ aje, ki gbogbo agbaye le mọ ohun ti a n la kọja ni orilẹede naijiria.’’ ni igbesẹ to ṣafihan ibọwọ ti ọba charles ni to si ti n fihan tipẹ fun awọn oniruuru ẹsin, iṣẹlẹ kan waye lonii nibi ti o ti pade awọn adari ẹsin eyi ti wọ̀n si sun akoko rẹ siwaju ni bii wakati kan lati faaye gba adari ẹsin chief rabbi ephraim mirvis ko lee tete kuro lati lọ bẹrẹ isin ti wọn n pe ni shabbat. aṣayan lara ọrọ ti ọba ba awọn aṣoju ẹsin naa sọ nirọlẹ oni fihan pe o ti n fi ifẹ han tipẹ pe oun jẹ oludaabobo oniruuru ẹsin. “mo ti maa n saba ro britain gẹgẹ bi ilu to ju ilu lọ,” ọba sọ bẹẹ. “iyẹn si ti sun mi de ibi nini imọ kikun pe dida ni agbara ẹni tun ni iṣẹ ṣiṣe tirẹ... lati da abo bo oniruuru ero ati igbagbọ awọn eniyan orilẹede wa, to fi mọ didaabo bo aaye to wa fun igbagbọ ati iṣẹ isin rẹ”. awọn ọjọgbọn ninu sin islam ti sọ nipa bi ọba charles ṣe ka quaran, bakan naa ni awọn adari ẹsin juu ti sọ nipa ijinlẹ ati iduro pipẹ rẹ ifẹ to ni si igbagbọ wọn, oun ati iyawo rẹ , olori tuntun ti fi igba kan ri lọ ba awọn ẹlẹsin hindu sin ọlọrun wọn nibi eto adura bakan naa lo si tun ti kan sara si awọn ẹsin sikhism, buddhism atawọn oniruuru ẹya ẹsin kristẹni. bo tilẹ jẹ pe oriṣiriṣi ni ero ati iwoye awọn eniyan laarin awọn ọdun 1990s nipa ẹsin to n ṣe pato, lasiko ikede rẹ lasiko ikede rẹ, ibura rẹ ko yipada rara gẹgẹ bi “oludaabo boo oniruuru ẹsin” to si tun ti sọrọ nipa bi igbagbọ rẹ ṣe tun jinlẹ ninu ẹsin ijọ ti ilẹ gẹẹsi.",,"ko din ni akẹkọọ ọgbọn, ninu eyi ti awọn obinrin pẹlu wa ninu, ninu fidio naa." +kí ni àwọn fijilanté ń fi ak47 ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fún? akeredolu fún ìjọba àpapọ̀ lésì,"oríṣun àwòrán, screenshot gómínà ìpínlẹ̀ ondo, rotimi akeredolu ti ní òun kò ní ye pariwo àyàfi tí ààbò tó gbópọn bá wà fún àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ òun àti ilẹ̀ yorùbá lápapọ̀. akeredolu nínú àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ rẹ̀, richard olatunde fi síta ní ìpinnu ààrẹ láti dènà àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò tí kìí ṣe ti ìjọba àpapọ̀ láti má lo ìbọn ìgbàlódé kò dára tó ó ní àtẹ̀jáde tí agbẹnusọ rẹ̀ garba shehu fi síta pé àwọn kò ní fi ààyè gba àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò yàtọ̀ sí ti ìjọba láti lo àwọn ohun ìjà ìgbàlódé kò sí ní ìbámu pẹ̀lú ìpèníjà ààbò tó ń bá nàìjíríà fínra lọ́wọ́ yìí. ó fi kun pé gbogbo àwíjàre tí shehu ń sọ lórí ìdí tí àwọn fijilanté katsina tí wọ́n ń ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú ak47 ṣùgbọ́n tí ìjọba àpapọ̀ kọ̀ láti gba ẹ̀ṣọ́ amotekun láti ṣe bẹ́ẹ̀ kìí ṣe ohun tó ṣe é gbọ́ sétí. gómìnà akeredolu ní ìròyìn tí iléeṣẹ́ tvc fi síta ṣàfihàn ibi tí àwọn fijilanté katsina ti ń ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú ìbọn ak47 lọ́wọ́ àti pé tí kò bá ṣe wí pé wọ́n fẹ́ lò ó, kí ni wọ́n ń ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú rẹ̀ sí. bákan náà ló ìbéèrè tí òun ń bèèrè ni pé ṣe àwọn fijilanté náà yóò dá ìbọn náà padà lẹ́yìn tí wọ́n bá ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tán àti pé to ló buwọ́lùú fún wọn láti fi kẹ́kọ̀ọ́? ó tẹ̀síwájú pé láti ìgbà tí ìròyìn ọ̀hún ti gbòde, ìjọba ìpínlẹ̀ katsina kò jìyàn gbogbo ẹ̀sùn tí òun fi kàn wọ́n, tí òun kò sì mọ ìdí tó fi jẹ́ pé garba shehu wa sọ ara rẹ̀ di agbẹnusọ ìpínlẹ̀ katsina. akeredolu tẹnumọ pé òun tí òun ń jà fún ni pé gbogbo àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò tó bá wà ní ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kan gbọ́dọ̀ ní àǹfàní láti máa lo àwọn ìbọn ìgbàlódé èyí tọ jẹ́ wí pé ohun ni àwọn ọ̀daràn ń lò láti máa fi ṣiṣẹ́ ibi wọn. ó fi kun pé ọwọ́ lásán kò ṣèé kojú àwọn oníṣẹ́ ibi tí wọ́n ń ṣàkóbá fún ààbò nàìjíríà àti pé ìjọba ní ojúṣe láti dá ààbò tó péye bo àwọn ará ìlú láì sí tàbítàbí kankan nínú. ó ṣàlàyé pé òun ti jẹ́jẹ̀ẹ́ pé gbogbo ọ̀nà ni òun ma gbà láti dá ààbò bo ẹ̀mí àti dúkìá àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ òun. nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí ìdásílẹ̀ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀, akeredolu ní ẹnu gbogbo àwọn gómìnà ìpínlẹ̀ ló kò lórí ìpinnu náà àti pé àwọn lọ́balọ́ba ẹkùn àríwá náà kí wọn lẹ́yìn. ó ní ohun tó kù ni kí ìjọba àpapọ̀ náà gbọ ìpè àwọn kò sí fọwọ́ sí ìdásílẹ̀ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀. ó tẹ̀síwájú pé àsìkò yìí gan ló yẹ ki ìjọba kojú gbogbo àwọn ọ̀daràn tó ń da omi àláfíà ìlú láàmú nítorí ènìyàn kò le máa ṣe nǹkankan náà ní gbogbo ìgbà kó wá máa retí èsì tàbí àbájáde tó yàtọ̀. oríṣun àwòrán, aketi/buhari ṣaájú ni a ti mú ìròyìn wá fún-un yí pé ijọba apapọ naijiria ti sọ pe oun ko fun ipinlẹ kankan ni naijria lagbara lati ra ohun ija oloro funra rẹ fun eto abo. aarẹ muhammadu buhari lo sọ ọrọ naa ninu atẹjade kan loju opo twitter ijọba apapọ naijiria. atẹjade ọhun ni ọọfisi aarẹ fi lede lẹyin ọsẹ kan ti gomina ipinlẹ ondo, rotimi akeredolu, kede pe oun yoo ra ibọn fun ẹṣọ alaabo amotekun. bakan naa ni ko tii ju ọjọ kan ti eeyan bii ẹẹdẹgbẹrin darapọ mọ ikọ naa l’ondo. ninu atẹjade naa to fi si oju opo twitter ileeṣẹ aarẹ lọjọ iṣẹgun, ijọba apapọ sọ pe oun ko fun ijọba ipinlẹ kankan laṣẹ lati ra ohun ija oloro fun ikọ abo abẹle rẹ, yala ipinlẹ katsina ni o tabi ipinlẹ mii ni naijiria.” “labẹ iṣejọba yii, a ti jẹ ko ye gbogbo araalu pe ko si ẹnikẹni to laṣẹ lati gbe ibọn ak-47, ẹni to ba si ni irufẹ ibọn naa lọwọ gbọdọ jọwọ rẹ fun ijọba.” “labẹ ofin, ọọfisi ileeṣẹ to n ri si eto abo, nsa, nikan lo le fun ẹnikẹni laṣẹ lati lo ohun ija oloro, iyẹn lẹyin to ba ti kọkọ gba aṣẹ lati ọọfisi aarẹ.” ijọba apapọ ni lodi soi ohun ti akeredolu sọ pe awọn ẹṣọ abẹle ipinlẹ katsina n gbe ibọn ak-47, ṣe ni awọn eeyan naa lo ibọn ọhun lati ṣe idanilẹkọọ lasiko eto kan, kii ṣe pe wọn fẹ maa lo. ẹwẹ, ṣaaju ni gomina ipinlẹ ondo, rotimi akeredolu ti kọkọ sọ pe ijọba apapọ n ṣe ojuṣaju laarin awọn ipinlẹ to jọba le lori. o ni oun ri fidio ibi ti awọn ẹṣọ abẹle ipinlẹ katsina ti n gbe ibọn ak-47, bẹẹ ijọba apapọ kọ ki awọn gomina ilẹ yoruba ra irufẹ ibọn kan naa fun ikọ amotekun. aketi ni “a fẹ ki gbogbo araalu mọ pe, ko si bi ọbọ ṣe ṣ’ori ti inaki naa ko ṣe o.” “ijọba ipinlẹ ondo ti ṣetan bayii, gẹgẹ bii ojuṣe rẹ labẹ ofin, lati ra ibọn fun abo awọn eeyan rẹ.” “igbesẹ yii ṣe pataki, paapaa lasiko yii ti awọn agbesumọmi n ra ibọn bo ṣe wu wọn.” o pari ọrọ rẹ pe “ijọba ipinlẹ yii ko ni la oju rẹ silẹ ki awọn agbesumọmi maa pa awọn eeyan wa ni ipakuta lai wa nnkan ṣe si.” “a o daabo bo awọn eeyan wa.”",28 owewe 2022,akeredolu nínú àtẹ̀jáde kan richard olatunde fi síta ní ìpinnu ààrẹ láti dènà àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò tí kìí ṣe ti ìjọba àpapọ̀ láti má lo ìbọn ìgbàlódé kò dára tó. +amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ tẹ̀lẹ̀ fún gómìnà ìpínlẹ̀ ogun di èrò ẹ̀wọ̀n ní us fún jìbìtì,"oríṣun àwòrán, abidemi rufai/facebook ile ẹjọ kan ni orilẹ-ede america, ti ju amugbalẹgbẹ nigba kan fun gomina ipinlẹ ogun, abidemi rufai si ẹwọn ọdun marun-un. akọsilẹ ẹsun ti wọn fi kan rufai fihan pe ni ọdun 2017, o jí akọsilẹ nipa ọmọ orilẹ-ede america to le ni ẹgbẹrun lọna ogún, to si fi beere fun owo to le miliọnu meji dọla lọwọ ijọba. nkan ti ọgbẹni rufai sọ fun ijọba ni pe oun yoo fi ṣe owo itunu fun awọn eeyan naa. o si le ni ẹgbẹrun lọna ẹgbẹta dọla ti ileeṣẹ ijọba kọọkan to da si ọrọ naa san fun. yatọ si ti ọdun 2017, o tun beere fun owo iranwọ lọwọ ijọba lasiko ajakalẹ aarun covid-19, ti wọn si san owo to to 350,763 dọla si awọn apo asunwọn to wa ni abẹ akoso rufai. awọn alaṣẹ sọ pe rufai lo akọsilẹ ati aworan eeyan to le ni ọgọrun nilu washington, lati beere fun iranlọwọ owo ti ijọba fun awọn ti ajakalẹ aarun covid-19 gba iṣẹ lọwọ wọn. bẹẹ naa lo tun sẹ ni awọn ilu bi hawaii, wyoming, massachusetts, montana, new york, ati pennsylvania. niṣe lo fi imeeli ọtọọtọ fi iwe ẹ̀bẹ̀ ranṣẹ, ki wọn o ma ba mọ pe ẹnikan pere lo n kọ gbogbo rẹ. awọn apo asunwọn ori ayelujara si lo fi gba owo naa. koda, wọn ni o fi owo naa ranṣẹ diẹdiẹ si adirẹsi awọn mọlẹbi rẹ to n gbe ni new york ati jamaica ati apo asunwọn miran to jẹ tiẹ nilẹ america. agbẹjro ijọba to rojọ tako o, cindy chang, sọ pe eeyan 238 to nilo iranlọwọ, ni rufai fi iwa jibiti rẹ ba aye wọn jẹ. lati oṣu karun-un, ọdun 2021 ni rufai ti wa ni ahamọ awọn agbofinro nigba ti ọwọ tẹ ẹ ni papakọ ọkọ ofurufu jfk ni new york.",28 owewe 2022,amugbalẹgbẹ gomina dapo abiodun di ero ẹwọn ni america +"a kò tako tinubu, kó ṣàá má díwa lọ́wọ́ ìpolongo yoruba nation - akintoye","ẹgbẹ ilana ọmọ oodua sọrọ lori ṣiṣe atilẹyin fun tinubu olori ẹgbẹ to n polongo fun idasilẹ orilẹ-ede oduduwa, ọjọgbọn banji akintoye, ti sọ pe awọn ko nii ti tori pe ọmọ yoruba kankan n dije fun ipo aarẹ, jawọ ninu ijijagbara awọn. ọjọgbọn akintoye sọ ọrọ naa ninu ifọrọwanilẹnu wo kan pẹlu bbc. o sọ eyi ni idahun si ibeere pe ṣe ẹgbẹ naa yoo ṣe atilẹyin fun bola tinubu, ọkan lara awọn ọmọ yoruba to n dije fun ipo aarẹ lọdun 2023. akintoye ni, kii ṣe nkan to buru pe ọmọ yoruba n dije, ni wọn igba ti awọn ṣi wa ni naijiria, o ni amọ tiẹ ko nii di awọn lọwọ ipolongo, bẹẹ ni awọn ko nii fi ipolongo di i lọwọ. o ṣalaye pe awọn to fẹ orilẹ-ede oduduwa lo pọ ju laarin awọn ọmọ yoruba, ""nitori naa, a ko nii dakẹ. ""a ti ba ipolongo wa de ipele to ga julọ, eyi to jẹ fifi to awọn awujọ agbaye to le gba orilẹ-ede wa fun wa, leti. ọrọ ti akintoye sọ waye lasiko ti awọn ọmọ yoruba kan ninu afenifere sọ pe oludije lati ẹya igbo, peter obi ni awọn ṣe atilẹyin fun. amọ awọn kan lara wọn tun sọ pe tinubu ni awọn n ba lọ.",28 owewe 2022,"akintoye ni, kii ṣe nkan to buru pe ọmọ yoruba n dije, ni wọn igba ti awọn ṣi wa ni naijiria." +"àwọn jàǹdùkú pa ọ̀gá ọlọ́pàá dco, afurasí kan, ṣá dpo àti ìǹsìpẹ́kítọ̀ ládàá","oríṣun àwòrán, screenshot iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ oyo ti sọ àrídájú rẹ̀ wí pé dandan ni kí àwọn fìyà tó tọ́ jẹ àwọn tó ṣekúpa ọ̀gá ọlọ́pàá ní ìlú iganna, ìjọba ìbílẹ̀ iwajowa ní alẹ́ ọjọ́ ìṣẹ́gun ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n, oṣù kẹsàn-án. nínú àtẹ̀jáde tí agbẹnusọ ọlọ́pàá oyo, adewale osifeso gbé jáde ló ti ṣàlàyé ohun tó ṣẹlẹ̀ gangan níbẹ̀. kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá oyo, adebowale williams tó fajúro sí ìkọlù tí àwọn agbébọn kan ṣe sí àwọn ọlọ́pàá níbi tí dco àti ọkùnrin kan ti pàdánù ẹ̀mí wọn ní àwọn méjì mìíràn náà farapa. williams ní àwọn méjì tó farapa ọ̀hún ti wà ní ilé ìwòsàn ìjọba kan níbi tí wọ́n ti ń gba ìtọ́jú lọ́wọ́. ó ní ìwádìí àwọn ṣàfihàn wí pé àwọn ọlọ́pàá ọ̀hún ń ṣe iṣẹ́ wọn, gẹ́gẹ́ bí òfin láti máa ṣàyẹ̀wò àwọn ọ̀kadà tí kò bá ní nọ́mbà ìdánimọ̀ lójúnà àti dín ìwà ọ̀daràn kù. kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá ní wí pé ojúṣe àwọn ọlọ́pàá yìí ni wọ́n ń ṣe lọ́wọ́ ní òpópónà elejoka-igangan kí àwọn jàǹdùkú náà tó ṣe ìkọlù sí wọn. ó ṣàlàyé pé ìkọlù yìí lọ ṣokùnfà ikú ọ̀gá ọlọ́pàá tó ń mójútó ìwà ọ̀daràn (divisional crime officer, dco) àti ọkùnrin kan tó wà ní àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá nígbà tí wọ́n ń jà fitafita láti rí wí pé àwọn ọ̀daràn náà kò ráyè wọ àgọ́ ọlọ́pàá iganna. bákan náà ló ní dpo àgọ́ ọlọ́pàá náà àti ìǹsìpẹ́kítọ̀ kan tún fara gbọgbẹ́ àdá èyí tí àwọn ọ̀daràn náà fi ṣá wọn tí wọ́n sì ti wà ní ilé ìwòsàn báyìí níbi tí wọ́n ti ń gba ìtọ́jú lọ́wọ́. àtẹ̀jáde náà fi kun pé kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá ti wá ní kí ẹ̀ka tó ń mójútó ìwádìí ìwà ọ̀daràn bẹ̀rẹ̀ ìwádìí ní kíákíá láti lè tètè fojú àwọn aṣebi náà hàn. bákan náà ló ní àwọn ti náwọ́ gán àwọn kan lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà. oríṣun àwòrán, screenshot àwọn agbébọn ti tún ṣe ìkọlù sí igangan, ìjọba ìbílẹ̀ ibarapa ní ìpínlẹ̀ oyo. ìròyìn tó tẹ bbc news yorùbá lọ́wọ́ ní àgọ́ ọlọ́pàá ìlú igangan ni àwọn agbébọn náà ṣe ìkọlù sí tí wọ́ sì pa ọ̀gá ọlọ́pàá dco. bákan náà ni wọ́n tún pa afurasí kan tó wà ní àhámọ́ àgọ́ ọlọ́pàá náà. ní alẹ́ ọjọ́ ìṣẹ́gun, ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n oṣù kẹsàn-án ni ìkọlù náà wáyé. bákan náà ni ìròyìn ní dpo, ìǹsìpẹ́kítọ̀ ti iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ọ̀hún náà fara gbọta. agbẹnusọ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ oyo, adewale osifeso fìdí ìròyìn náà múlẹ̀ fún bbc ní òwúrọ̀ ọjọ́rú. osifeso ní ìwádìí ti bẹ̀rẹ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ náà tí àwọn yóò sì fi ohun tí àwọn bá bábọ̀ léde. ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìròyìn ń bọ̀ láìpẹ́.",28 owewe 2022,"nínú àtẹ̀jáde tí agbẹnusọ ọlọ́pàá oyo, adewale osifeso gbé jáde ló ti ṣàlàyé ohun tó ṣẹlẹ̀ gangan ní iganna níbi tí ìkọlù náà ti wáyé." +"irú àìsàn wo ló n ṣe baba ijesha, tó fi nílò ìtọ́jú pàjáwìrì lọ́gbà ẹ̀wọ̀n?","oríṣun àwòrán, thewill nigeria oṣere tiata yoruba to wa lọgba ẹwọn niluu eko lori ẹsun pe o ba ọmọde ṣe aṣemaṣe, olanrewaju james, ti ọpọ mọ si baba ijesha, ti ke gbajare pe aisan buburu kan n ba oun finra n inu ahamọ to wa bayii. eyii lo mu ki oṣere naa ke si awọn ọmọ naijiria lati ṣe iranlọwọ fun oun. ninu ifọrọwerọ pẹlu bbc yoruba, akẹgbẹ rẹ, yomi fabiyi sọ pe lootọ ni apanilẹrin naa n ṣaisan ninu ahamọ, o si nilo itọju ni kankan. yomi fabiyi ni “ootọ ni pe baba ijesha n ṣaisan, aarẹ yẹn ti wa lara wọn ko to di pe wọn lọ sinu ahamọ.” “lẹnu igba ti mo ba wọn sọrọ bii ọsẹ to kọja, bi wọn ṣe n dun... mo ni ki wọn lọ si ile iwosan to wa ninu ibẹ nitori emi ni igbagbọ pe o yẹ ki wọn lẹtọtọọ si itoọju.” “boya nigba ti wọn lọ, wọn ko ri itọju to peye nibẹ ni wọn ṣe ke gbajare sita, amọ ootọ ni pe agara da wọn.” fabiyi sọ pe eyii to ju ninu aisan naa ko ṣẹyin ikọlu ti awọn kan ṣe si oṣere naa ninu ile princess nigba ti wọn kọkọ fẹsun biba ọmọde lopọ kan an. o ni “eyii to jẹ olori ibẹ ni ibi ti wọn ni wọn ti la igi mọ awọn lori ninu ile princess.” gẹgẹ bii ohun ti fabiyi sọ, o ni baba ijesha sọ pe wọn la igi mọ oun lori nile princess nigba ti wọn fẹsun kan oun, ori naa lo si n yọ lẹnu. fabiyi pari ọrọ rẹ pe, ọkan lara awọn aburo baba ijesha to jẹ dọkita ti n gbiyanju lati yọju si ọgba ẹwọn lati ba awọn alaṣẹ ọrọ lori ipo ilera rẹ ati ọna abayọ. ọjọ karun un, oṣu keje, ọdun 2022 yii ni ile ẹjọ ran baba ijesha lẹwọn lẹyin to jẹbi mẹrin ninu ẹsun mẹfa ti wọn fi kan, eyii to ni ṣe pẹlu ṣiṣe aṣemaṣe pẹlu ọmọde.",28 owewe 2022,"ninu ifọrọwerọ pẹlu bbc yoruba, akẹgbẹ rẹ, yomi fabiyi sọ pe lootọ ni apanilẹrin naa n ṣaisan ninu ahamọ, o si nilo itọju ni kankan." +ikú yá ju ẹ̀sín lọ ni mo ṣe dáná sun ara mi,"oríṣun àwòrán, punch.ng ní ọjọ́ ẹtì, ọjọ́ kẹtàlélógún, oṣù kẹsàn-án ni ìròyìn ọkùnrin kan tó fẹ́ gba ẹ̀mí ara rẹ̀ gba ìgboro. orúkọ ọkùnrin náà muritala afolabi tó jẹ́ ẹni ọgbọ̀n ọdún. ìròyìn ní ọkùnrin náà ṣàdédé gbé epo bẹntiróòlù tó sì dáà sí gbogbo ara rẹ̀ kó tó ṣáná si ara rẹ̀. èyí ló mú kí bbc news yorùbá kàn sí ọkùnrin náà ní ilé ìwòsàn tó wà ní ìlú iree ní ìpínlẹ̀ osun láti fìdí ohun tó ṣẹlẹ̀ gangan múlẹ̀. nígbà tó ń ṣàlàyé ohun tó mu ṣe ìpinu láti pa ara rẹ̀, afolabi ní nígbà tí òun jókòó tí òun ro ìgbésí ayé òun ló mú kí òun pinnu pé ikú yá ju ẹ̀sín lọ. tí kò bá ti si ọjà báyìí ni gbogbo nǹkan máa ń sú mi afolabi tó ní iṣẹ́ àwọn tó máa ń fẹ́ táyà ni òun ń ṣe ṣàlàyé tí òun bá ti wà ní ṣọ́ọ̀bù tí alájé kò sì wá ni ìrònú òun máa ń pọ̀ si tó sì máa ń fa èròkerò sí òun lọ́kàn. ó ní ìdí nìyí tí òun fi lọ ra epo bẹntiróòlù tí òun sì lọ sí inú igbó kan láti lọ dáná sun ara òun. “fúnra mi náà ni mo lọ ra epo ní ilé epo, kìí ṣe àárín ìgboro ni mo ti ṣe é, inú igbó kan báyìí ni mo lọ.” “mo wá da epo náà sára, tí mo sì ṣáná si.” afolabi ṣàlàyé pé àwọn ènìyàn tó rí òun níbi tí òun ti ń jóná ni wọ́n sáré dìgbàdìgbà láti dóòlà ẹ̀mí òun. ó ní àwọn ènìyàn náà ló sáré pa iná náà kí wọ́n tó gbé òun lọ sí ilé ìwòsàn. afolabi ní kìí ṣe wí pé òun jẹ ènìyàn lówó tàbí wà nínú okùn gbèsè kan, ó ní ìyàwó tí ọlọ́run jogún fún òun ni àgbélèbú tó ń da ìgbésí ayé òun láàmú. ó ní èpè ni ìyàwó òun máa ń gbé òun ṣẹ́ ní ojoojúmọ́. ó ṣàlàyé pé ní kété ti àwọn bá ti jí ní òwùrọ́ báyìí ni ìyàwó òun yóò ti gbégbá èpè bọnu tí kò sì ní fi ọ̀kan pe méjì fún òun. “tí mo bá ki káàárọ̀ báyìí, èpè ló ma fi dámi lóhùn.” “nínú oṣù keje náà ni a fẹ́ ara wa àmọ́ èpè ló fi ń bámi gbé láti ìgbà tó ti kó wọlé mi kódà a ò tíì bímọ kankan.” “tí mo bá sọ̀rọ̀ ẹyọ̀kan, èpè mẹ́wàá ló ma fi dámi lóhùn, ó sì ti mọ lára.” afolabi tẹ̀síwájú pé nítorí èpè tí ìyàwó máa ń gbé òun ṣẹ́ ló ṣokùnfà tí òun kìí fí sunlé ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà. bákan náà ló ní òun ti lọ fi sun àwọn mọ̀lẹ́bí ṣùgbọ́n kò sí ìyàtọ̀ kankan. nígbà tí akọ̀ròyìn bbc yorùbá ń bèèrè lọ́wọ́ afolabi wí pé kí ló dé tí kò fi fọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ àwọn ènìyàn kó tó gbèrò láti gbẹ̀mí lọ́rùn ara rẹ̀, ó ní òun ṣe bẹ́ẹ̀. ó ní gbogbo àwọn tí òun sọ fún ni wọ́n gba òun nímọ̀ràn láti má ṣe bẹ́ẹ̀. “nígbà tí mo fẹ́ lọ ṣe gangan mi ò sọ fún ẹnìkankan mọ́.” ó fi kun pé ara òun ti ń balẹ̀ tí òun sì ti ń rí ìtọ́jú gbà ní ilé ìwòsàn tí òun wà. oríṣun àwòrán, bola bamigbola/punch ọkunrin ẹni ọgbọn ọdun kan, muritala afolabi ti farapa lẹyin to dana sun ara rẹ nipinlẹ osun. amọ awọn eeyan kan tete doola rẹ, ti wọn si gbe digbadigba lọ sile iwosan kan niluu iree, nibi to ti n gba itọju. nigba to n ba ileeṣẹ iroyin abẹle punch sọrọ lori ibusun aisan to wa,gni afolabi ni oun gbe igbesẹ lati pa ara oun nitori bi iyawo oun ko ṣe fi oun ni ọkan balẹ. gẹgẹ bii oun to sọ, inu oṣu keje, ọdun 2022 ni wọn ṣe igbeyawo, amọ ojojumọ ni iyawo rẹ naa maa n gbe ṣepe, to si ma n sọ awọn ọrọ kobakungbe si. o ni “mo kan pinnu lati fopin si gbogbo rẹ naa ni.” “mo lọ sile epo, mo ra epo bẹtiro, mo si lọ sinu igbo to wa ni ẹyin ile ẹkọ baptist high school, ni iree, lati dana sun ara mi.” “mo ronu nipa gbogbo ohun ti mo n la kọja, mo si pinnu lati pa ara mi. “ko si owo lọwọ mi, iyawo mi si maa n gbe mi ṣepe lojojumọ lo jẹ ki n sọ ireti nu, bẹẹ, inu oṣu keje ọdun yii ni a ṣe igbeyawo.” o tẹsiwaju pe “lẹyin ti mo dana si ara mi tan lawọn eeyan kan sara wa sibi ti mo wa lati doola mi, ti wọn si gbe mi wa sile iwosan yii.” nigba ti awọn akọroyin kan si iyawo ọkunrin ọhun, ifedolapo, o ni irọ ni pe oun maa n gbe ṣepe. obinrin naa ni “mi o mọ eredi to ṣe lọ dana sun ara rẹ.” “emi ni iyawo rẹ lootọ amọ mi o tii bi ọmọ fun.” a ṣi n gbiyanju lati ba tọkọtaya naa, ati ẹbi wọn sọrọ. ẹ tẹti leko. ti ẹ ko ba gbagbe, inu ọdun yii naa ni obinrin kan, ifeoluwa bamidele, dana sun ọkọ rẹ lori ẹsun pe oloogbe naa n yan ale nipinlẹ osun yii kan naa. iroyin ni afurasi naa tan ẹrọ amunawa ‘generator’ lasiko to dana sun ọkọ rẹ bamidele lori ibusun ki ariwo ẹrọ naa ma ba jẹ ki awọn eeyan gbọ igbe rẹ lati doola ẹmi rẹ. amọ lẹyinorẹyin ti iroyin kan ifeoluwa lara pe ọkọ rẹ bamidele ti ku, ti awọn agbofinro si n wa kiri, loun naa ba gbe oogun jẹ, to si gba ibẹ jẹ ọlọrun nipe.",26 owewe 2022,afolabi ní nígbà tí òun jókòó tí òun ro ìgbésí ayé òun ló mú kí òun pinnu pé ikú yá ju ẹ̀sín lọ. +"‘èmi kọ́ ni mo ń jí ènìyàn gbé, tèmi ni láti fi ilé wọn hàn","oríṣun àwòrán, the nation arakunrin afurasi ajinigbe, lyon ewa ti ṣalaye ipa ti o ma n ko lasiko ijinigbe. lyon ni ọwọ tẹ lẹyin ti ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ bayelsa ni awọn ti mu ogbontagiri ajinigbe to n da ipinlẹ naa ru, ti ọwọ si tẹ wọn lasiko ti wọn ji ọga banki gbe ni yenagoa. ọga banki ti wọn jigbe naa ti orukọ rẹ n jẹ danjuma emeije lo jẹ ọga rẹ tẹlẹ. oríṣun àwòrán, the nation lyon ewa ninu ọrọ rẹ lasiko ifọrọwerọ pẹlu awọn akọroyin ni oun ki n ṣe ajinigbe, ile awọn ti wọn ba fẹ jigbe nikan ni oun maa n ṣafihan rẹ. amọ o ni lootọ ni oun gba 3.5 million naira lasiko ijinigbe nitori oun darukọ rẹ ati ibi to n gbe fun wọn. emi ko lo ji wọn gbe, ile wọn nikan ni mo fihan ’ ’ a n wa ọkọ lo ni mo si sọ fun wọn pe ile ọga mi tẹlẹ niyii, lobatan ’ amọ ọkan lara afurasi to jẹ olubaṣiṣẹpọ rẹ ti orukọ rẹ n jẹ emma ni ko si otitọ kankan ninu ọrọ ti lyon sọ nitori awọn jọ ṣiṣẹ pọ ni. koda owo tirẹ lo poju. bawo ni ẹni ti ko mọ nkankan nipa rẹ fi gba owo gọbọi? ’oun gan an lo sọfun wa pe ki a lo gbe ọga oun tẹlẹ nitori o yọ oun lẹnu iṣẹ, nitori ọlọla ni. oríṣun àwòrán, getty images ileeṣẹ ọlọpaa ti mu afurasi ogbontarigi ajinigbe kan to ma n fi ọlá rẹ ṣe fọri-fọri lori ayelujara. oṣiṣẹ ile ifowopamọ ni ọpọ eeyan mọ john lyon si, to si ma n gba awọn eeyan ni imọran lati jara mọ isẹ ni gbogbo igba to ba fi aworan tabi fidio si ori ayelujara. agbẹnusọ ọlọpaa nipinlẹ bayelsa, asimi butswat, sọ fun bbc pe ilu abuja ni ọwọ ti tẹ ọgbẹni lyon, ṣugbọn wọn ti gbe e wa si ipinlẹ bayelsa fun iwadii. ko din ni iṣẹlẹ ijinigbe mẹwaa, ti wọn fi gba owo nipinlẹ bayelsa, ti ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe ko ṣẹyin ikọ ajinigbe lyon. amọ, oun kọ ni olori ikọ naa. lati opin ọsẹ ni fidio kan to ṣafihan afurasi naa ti wa ni ori ayelujara, ninu eyi ti wọn ti fi ṣẹkẹṣẹkẹ de e lọwọ. botilẹ jẹ pe ọgbẹni lyon ko tii jẹwọ ni gbangba, a ri ninu fidio naa ni ahamọ ọlọpaa, to si n tọrọ aforijin lẹyin ti ọwọ tẹ ẹ. ọpọlọpọ ọmọ naijiria lo si ti n fi iyalẹnu han lori bi ọwọ ṣe tẹ ẹ, ti awọn kan si n ṣapejuwe afurasi naa gẹgẹ bi ẹni to lawọ, to ma n fun awọn eeyan ni ẹ̀bùn.",26 owewe 2022,"lyon ewa ninu ọrọ rẹ lasiko ifọrọwerọ pẹlu awọn akọroyin ni oun ki n ṣe ajinigbe, ile awọn ti wọn ba fẹ jigbe nikan ni oun maa n ṣafihan rẹ." +bí ọkọ mi ṣe jẹ́ alága labour party kò dá ṣíṣe ìpolongo tèmi fún tinubu dúró - foluke daramola,"oríṣun àwòrán, instagram gbajugbaja oṣerebinrin ni naijiria, foluke daramola ti ni ipo ti ọkọ rẹ dimu ninu ẹgbẹ oṣelu labour party ko lee pa oun lara, pẹlu bi wọn ṣe yan oun kun igbimọ ipolongo fun oludije sipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu apc, ahmed tinubu. foluke daramola fi ero rẹ lede ni oju opo instagram rẹ,lẹyin to ni ahẹsọ nipe ọkọ oun ṣiṣẹ fun tinubu ni ẹgbẹ oṣelu labour. daramola ni igbagbọ oun ni pe ki ọkọ ati iyawo wa ninu ẹgbẹ oṣelu ọtọọtọ ko ba nkankan jẹ, ti ko si yẹ ko fa wahala abi aigbọraẹniye. laipẹ yii ni wọn yan daramola gẹgẹ bi ọkan lara awọn igbimọ ipolongo fun tinubu ninu ẹgbe oṣelu apc. amọ ọkọ rẹ , ezekiel kayode salako ni alaga ẹgbẹ oṣelu ‘labour party’ ni ipinlẹ eko, to si jẹ alatilẹyin fun oludije sipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu ‘labour party’, peter obi. oríṣun àwòrán, instagram ninu ọrọ rẹ, daramola ni ko si iyọnu nitori ọkọ oun mọ pe oun ni ifẹ ẹgbẹ oṣelu apc denudenu , ti ko si ni si iyọnu. ‘ahesọ lasan ni pe ọkọ mi n ṣiṣẹ fun apc ni ipo alaga ẹgbẹ oṣelu labour party, denudenu ni ọkọ mi duro ti peter obi, ti kosi si mimi kan to le mii.’’ ‘awọn to mọ ọkọ mi mọ wi pe kii ṣe ọgagun ninu ile, o faye gba ki iyawo rẹ naa sọrọ, to si bọwọ fun ero rẹ pẹlu.’’ ‘eyi mu ki o ni igbagbọ ninu ero mi lati darapọͅ mọ ẹgbẹ oṣelu apc, ti ko si tako mi’’ ’ere iṣẹ takntakun ti mo ṣe ninu ẹgbẹ oṣelu apc ni ipo tuntun ti wọn fi mi si nitori ti ọmọ ba ṣiṣẹ dara dara, a o tun fi iṣẹ miran da lọ. ẹ o ranti pe a ti mu iroyin wa pe bi ipalẹmọ eto idibo aarẹ ti n kanlẹkun dẹẹdẹ, ẹgbẹ oṣelu all progressives congress ti gbe orukọ awọn ti yoo wa lara igbimọ ipolongo ipo aarẹ wọn jade. ni ọjọ abamẹta ni wọn gbe orukọ awọn eeyan irinwo le mejilelogun naa jade ti eleyi si ti n mu kawọn ọmọ naijiria maa sọ ero ọkan wọn nipa rẹ. bawọn kan ṣe n sọrọ nipa awọn ti orukọ wọn ko si nibẹ bi igbakeji aarẹ yemi osinbajo ati akọwe ijọba apapọ boss mustapha to fi mọ minisista feto ibaraẹnisọrọ tẹlẹ to si jẹ eekan ninu ẹgbẹ apc ni ipinlẹ oyo, bayo shittu, bẹẹ lawọn mii n ṣe ayẹwo finifini orukọ inu iwe naa ti wọn gbe jade. bo ti lẹ jẹ wi pe ẹgbẹ apc ti jade lati ṣalaye idi ti orukọ bii ti igbakeji aarẹ ko ṣe si nibẹ, eleyi ti awa fẹ ṣe agbeyẹwo rẹ ninu awọn orukọ yii lorukọ awọn oṣere tiata ti wọn pada wa gbe orukọ wọn jade ninu igbimọ ipolongo naa. oríṣun àwòrán, officialasiwajubat/ ni meni meji, a ri awọn orukọ oṣere tiata yoruba to jẹ gbajumọ ti araalu si mọ wọn daada. ṣaaju ki wọn to gbe orukọ yii jade lati rii tawọn oṣere wọnyi ti n ṣe fọnran fidio atilẹyin fun bola tinubu ti wọn a si maa foju han pe awọn duro lẹyin rẹ bi ike. lara awọn oṣere tiata ti wọn gbe orukọ wọn sita la ti ri: wọn fi awọn oṣere yii sabẹ akoso ẹka awọn amuludun. akọwe igbimọ lẹka amuludun ni jide kosoko jẹ ni ipinlẹ eko nigba ti saheed balogun si jẹ igbakeji agbẹnusọ ni eko. yatọ si awọn ti o jẹ osẹre tiata ati amuludun lati iwọ oorun guusu, wọn yan awọn miran naa lati apa ariwa ati ila oorun guusu naijiria bi zack orji, sani idris moda nuhu abdullahi ni kano ati awọn miran. oríṣun àwòrán, apcprescc2022 labẹ oṣelu awarawa awọn ẹgbẹ oṣelu a maa ṣe akitiyan lati wa ọna ti araalu yoo fi dibo yan awọn aṣoju ẹgbẹ wọn dipo ti ẹgbẹ miran. ninu ọna ti ofin faaye gbawọn ni ṣiṣe ipolongo idibo bi asiko ibo ba ṣe n sunmọ bọ. ni naijiria, awọn to n dije dupo aarẹ paapa a maa farabalẹ ṣe akojọ orukọ awọn ti yoo di ipo orisirisi mu labẹ eto ipolongo ti o si ṣe pe orukọ yi yoo ṣafihan bi ẹgbẹ naa ba ṣe tagba de kaakiri naijiria. bi wọn ṣe n mu awọn oloṣelu, bẹẹ ni wọn a maa mu awọn mii to ṣe pe wọn ni ipa kan tabi omiran ti wọn yoo ko lara eto ipolongo yii. ni gbogbo igba ti idibo paapa ti aarẹ ba ṣe n sunmọ si si ni awọn araalu maa n foju sọna lati wo awọn ti ẹgbẹ kọọkan yoo yan sipo labẹ igbimọ ipolongo yi. a ko ri akọsilẹ ninu iwe ofin ẹgbẹ oṣelu all progressives congress to sọ boya wọn yoo san owo fun awọn ọmọ igbimọ ipolongo aarẹ tabi wọn ko ni san an fun wọn. eyi taa mọ ni pe loore koore ni awọn igbimọ ẹgbẹ a maa yan igbimọ mii ki wọn baa le tẹsiwaju pẹlu eto ẹgbẹ wọn. ninu awọn igbimọ to maa n waye loore koore ni ti ipolongo idibo yi jẹ. labẹ ofin, ẹgbẹ funrarẹ, a maa ri owo lati ọna meloo kan bi owo ti awọn ọmọ ẹgbẹ ba da fun iṣakoso ẹgbẹ osẹlu, eyi ti ijọba ba fun wọn, eyi ti wọn ba ri lati idokoowo ti ẹgbẹ ba ṣe tabi nipa yiya owo ti igbimọ alaṣẹ ẹgbẹ ba buwọlu. leyi ti awọn ẹgbẹ maa n sọ fun awọn to ba fẹ ṣe iru iṣẹ yii, wọn a maa sọ fun wọn pe ifarajin lo jẹ ati pe bi wọn ba debi ṣe aṣeyọri tan, gbogbo onikaluku to kopa lati gbe ẹgbẹ de ipo naa ni yoo jẹ ninu mudunmudun to ba wa labẹ iṣejọba wọn.",25 owewe 2022,laipẹ yii ni wọn yan daramola gẹgẹ bi ọkan lara awọn igbimọ ipolongo fun tinubu ninu ẹgbe oṣelu apc. +"ìpolongo ìbò 2023 gbéra sọ, wo nkan tí àwọn olùdíje kò gbọdọ̀ ṣe","oríṣun àwòrán, others oni, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu kẹsan-an, ọdun 2022, ni eto ipolongo ibo fun awọn ẹgbẹ osẹlu bẹrẹ, ni imurasilẹ fun idibo gbogbo gbo ọdun 2023. ipolongo ibo naa yoo waye fun oṣu maarun-un gbako titi si oṣu keji ọdun 2023, ti idibo yoo waye. igba akọkọ niyii ti eto ipolongo ṣaaju ọjọ idibo, wọ oṣu maarun-un ninu itan idibo ni naijiria. ṣaaju asiko yii, kii ju bi oṣu mẹta lọ. bi oludije kọọkan ati ẹgbẹ oṣelu wọn yoo ṣe ma a lọ kaakiri lati fa awọn oludibo loju mọra, ajọ inec ti fi awọn ilana ti wọn gbọdọ tẹle sita. awọn ilana ati ofin naa ko yọ awọn alatilẹyin wọn naa silẹ. awọn ilana naa lo wa ni ibamu pẹlu ofin idibo ọdun 2022. bẹrẹ lati ọjọ kejidinlọgbọn oṣu kẹsan an ọdun 2022, awọn ẹgbẹ oṣelu at’awọn ololufẹ wọn yoo lanfani ati bẹrẹ ipolongo ita gbangba fun idibo to n bọ lọdun 2023 lorilẹede naijiria. lati le rii daju pe gbogbo nnkan lọ ni mẹlọmẹlọ, ajọ eleto idibo lorilẹede naijiria, inec ti ṣalaye gbogbo ofin makan ti awọn oludije, ẹgbẹ oṣelu won, at’awọn ololufẹ wọn gbodo tẹle. igba akọkọ si niyi latigba ti naijiria ti n seto idibo, ti wọn yoo maa la aadọjọ ọjọ tabi oṣu marun un silẹ fun ipolongo ibo ni ibamu pẹlu abala kẹrinlelaadọrun iwe ofin idibo tọdu. 2022. abala yii tun laa kalẹ pe gbogbo eto ipolongo gbọdọ pari nigba to ba ku wakati mẹrinlelogun si ọjọ ibo gangan. abala naa ṣalaye pe ẹgbẹ oṣelu tabi ololufẹ rẹ yoowu to ba dagunla gbedeke wakati mẹrinlelogun si ọjọ yiilati dẹkun ipolongo ibo wọn yoo san owo itanranto to ẹgbẹrun lọna ẹdẹgbẹta naira. bo ba si jẹ ileeṣẹ iroyin lo tapa si ofin yii, miliọnu kan naira lowo itanran rẹ yatọ si ofin to de akoko ipolongo, ki lawọn ohun miran to yẹ k’awọn eeyan mọ niyii. ko gbọdọ ṣi ọrọ alufansa tabi eebu gẹgẹ bi abala ikejilelogun iwe ofin idibonaiiria tọdun 2022 ṣe sọ. ko gbọdọ si ilo ọrọ to lee fa wahala, rukerudo tabi yanponyanri lasiko ipolongo ibo naa. oríṣun àwòrán, getty images awọn agbegbe kan wa ti ofin ko tilẹ fi aye rẹ silẹ fun ẹnikẹni lati ṣe ipolongo idibo tabi ipade ipolongo ita gbangba. ipin kẹta abala kẹtalelaadorun iwe ofin idibo naijiria ṣalaye pe tokan sí awọn agbegbe naa gẹgẹ bí ile ijọsin, agọ ọlọpaa atawon ọfiisi ijọba gbogbo. gbogbo ẹgbẹ oṣelu lo lẹtọ lati seto ipolongo ibo ofin naa fun gbogbo ẹgbẹ oṣelu at’awọn oludije wọn ni anfani lati seto ipongo nigbakugba to ba wu wọn. o lodi si ofin idibo naijiria fun ẹnikẹni tabi ẹgbẹkẹgbẹ lati kọlu ẹgbẹ oṣelu kankan tabi eto ati ilana ti wọn sinmi le. nitori eyi, ko gbọdọ si ẹgbẹ oṣelu tabi oludije kankan to gbọdọ lo egungun fun ipolongo idibo. bakanna lo tako ofin lati ko awọn agbero tabi januku jọ lati kọ wọn, tabi ko ohun ija oloro le wọn lọwọ nitori oṣelu. awọn alamojuto ibo ni agbekalẹ ijiya to yẹ fun ẹgbẹ oṣelu yoowu tabi oludije yoowu to ba tẹ oju ofin mọlẹ nipa did awọn miran lọwọ siseto ipolongo wọn nirọwọrọsẹ. owo itanran milionu kan naira tabi fi ẹwọn oṣu mejila oludije to ba ṣe eyi yoo fi jora. bo ba si jẹ ẹgbẹ oseluni, miliọnu meji naira ni fun igba akọkọ, milionu kan naira ni yoo maa san lẹyin eyi. bo ba si jẹ pe nṣe lonitọhun n ṣe agbodegba fun iwa itapasofin yii, ẹẹdẹg ẹta ẹgbẹrun naira ni yoo fi jora tabi ẹwọn ọdun meta tabi mejeeji gan. bi o ba lo iwa ipalati fi mu ki eeyan kan ti ẹgbẹ oṣelu kan lẹyin, ẹsẹ nla leyi labẹ ofin idibo naijiria, bi o ba jẹ oludije kan ni tabi ọpọ eeyan ni, miliọnu kan naira ni ọwọ itanran wọn. bi o ba wa jẹ egbe oṣelu lo ṣe eyi, miliọnu meji naira ni owo itanran rẹ, bi won ba si tun sẹ ẹṣẹ yii, okare ọrọ abo jeyo labẹ iwe ofin idibo naijiria, ọdun 2022. gbogbo ẹgbẹ oṣelu lo l’asẹ ati ẹtọ si abo agbofin. bẹẹni awọn kọmiṣọna olopaa fun ipinlẹ kọọkan ati olu ilu nàìjíríà lo sí gbọdọ fun won. ipin keji abala ofin naa sọ pe agbofinro ti wọn ko ba ran lọ si ibudo ipolongo ibi ko gbọdọ si ni sakani ibẹ. bakanna ni ipin kẹta abala kọkanlelaadọrun iwe ofin idibo naijiria tun fa awọn ọlọpaa at’awọn agbofinro yoku leti pe, bi o ti wu ki agbara ti awọn abala iwe ofin mirqn fun wọn ṣe le pọ to, ojuṣe kan ṣoṣo tí wọn ni nibudo ipolongo ni kiwon o mojuto alaafia nibẹ. ko si oludije tabi ẹgbẹ oṣelu to laṣẹ lati lo dukua ilu – ninu eyi ti ileeṣẹ iroyin wa, fun anfani ara rẹ laifun awọn oludije miran niru a fani bẹẹ. gbogbo awon ileesẹ iroyin ti ijọba ati aladani gbọdọ ya iye akoko tabi aye kan naa si ọtọ fun gbogbo oludije tabi ẹgbẹ oṣelu niwọn igba ti wọn ba ti san owo to yẹ ki wọn san. bi ileeṣẹ iroyin kan ba tapa si ofin yii, owo itanran miliọnu meji ni yoo san fun ìgbà àkọkọ. to ba run tapa si ofin tii lẹyin eyi, miliọnu marun un naira ni yoo maa san. awọn lọgalọga nileese iroyin bẹẹ yoo si tun fi miliọnu kan nairan owo itanran jura tabi ẹwọn oṣu mẹfa. lakotan, ofin yii ko fi aye silẹ fun ẹnikẹni tabi ẹgbẹ oṣelu kankan lati fi ẹsin, ẹya tabi ohun ẹya kan polongo tako ẹgbẹ oṣelu kankan. bi o ba jẹ eeyan kan lo rufin yii, owo itanran miliọnu kan naira ni tabi ẹwọn oṣu mejila, o si lee fi mejeeji jora.",27 owewe 2022,wo àwọn ohun tí ẹgbẹ́ òṣèlú àti àwọn olólùfẹ́ wọn lè ṣe àti èyí tí wọn kò lè ṣe lásìkò ìpolongo ìbò 2023 +"adájọ́ pàṣẹ́ kí lastma sàn n750,000 fún awakọ tí wọn gbà n20,000 lọ́wọ́ rẹ","oríṣun àwòrán, followlastma ile ẹjọ giga nipinlẹ eko ti dajọ wipe ki ajọ to n mojuto irinna ọkọ loju popo ni ipinlẹ eko,lastma ko laṣẹ lati ni ki awakọ ti wọn fura si pe o tapa sofin san owo itanran lalae gbaṣẹ lọwọ ile ẹjọ. adajọ olalekan oresanya lo gbe idajọ yi kalẹ lasiko to n gbẹjọ ti awakọ kan,aliyu toyin lawal gbe wa sile ẹjọ nibi to ti pe agbẹjọro agba nipinlẹ eko,ijọba eko ati ajọ lastma lẹjọ. ninu iwe ipẹjọ, lawal beere lọwọ adajọ pe ki wọn kede pe iwa to lodi sofin ni lastma hu nigba ti wọn ṣe idiwọ fun loju popo, ti wọn fipa wọ ọkọ rẹ lọ ti wọn si fi ọkọ naa si ahamọ lọdọ wọn. bẹẹ lo sọ pe ki adajọ kede pe iwa ti ko bofin mu ni lastma hu nigba ti wọn gba owo itanran ẹgbẹrun lọna ogun naira ati ẹgbẹrun mẹwaa naira lowo pe wọn wọ ọkọ rẹ lọ. lawal ṣalaye fun ile ẹjọ pe wọn gbe igbesẹ yi lalae gbaṣẹ ile ẹjọ ti eleyi si tako ẹtọ rẹ gẹgẹ bi ẹdamọniyan to lẹtọ lati rin nibi to wu. lati oṣu kọkanla ọdun 2021 ni awọn oṣiṣẹ lastma ti gba ọkọ agbẹjọro yi ni tipa ti wọn si ti bẹrẹ si ni fa ọrọ naa. ninu nkan ti arakunrin lawal beere pe ki ile ẹjọ ṣe fun oun ni ki wọn paṣẹ ki lastma, ijọba ipinlẹ eko ati agbẹjọro agba ipinlẹ naa san owo gba ma binu miliọnu marun un fun oun. adajọ gbọ ẹjọ yi lootọ to si ni oun yoo gba gbogbo ibeere ti lawal gbe wa siwaju ile ẹjọ. awọn nkan wọnyi ni pe ki lastma da owo itanran n20,000.00 ti wọn gba pada, ki wọn da owo ti wọn gba pe awọn fi wọ ọkọ rẹ,n10,000.00 ati pe ki wọn si san owo gba ma binu fun agbẹjọro yi. oríṣun àwòrán, temilola kofoworola sobola ninu nkan ti adajọ wo to ṣe koko ti awọn araalu mi le jẹ anfaani nibẹ ni pe lastma ko gba iwe aṣẹ lọdọ ile ẹjọ ki wọn to fidi ọrọ mulẹ lọwọ ara wọn pe arakunrin naa jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an. gẹgẹ bi adajọ olalekan oresanya ṣe wi, ko si ẹri aridaju ti lastma mu wa lati le fi kin iwa ti wọn hu yi lẹyin labẹ ofin. mo gbe idajọ kalẹ pe gbigba owo itanran ati owo ti lastma gba pe awọn fi wọ ọkọ olupẹjọ yi lalae gba iwe aṣẹ lọdọ ileẹjọ tokajuẹ jẹ ohun tolodi si ofin ti ko si fẹsẹ mulẹ.tori naa ki wọn san owo itanran ti wọn gba pada fun arakunrin to pẹjọ o tẹsiwaju pe ki wọn san owo gba ma binu ẹgbẹrun lọna ọta leni ẹẹdẹgbẹrin naira n750,000 tori pe wọn tapa si ẹtọ rẹ gẹgẹ bi ẹdamọniyan. adajọ fi kun ọrọ rẹ pe ko si ẹri ninu iwe ofin to de iṣakoso irina loju popi to fun wọn laṣẹ lati kọdi ẹtọ araalu lati le lọ ki wọn si bọ lalae si idiwọ. awọn ileeṣẹ ijọba ko gbọdọ hu iwa to lodi si ti yoosi tapa si ẹtọ araalu eleyi ti iwe ofin naijiria fidi rẹ mulẹ fun wọn bakan naa ni adajọ sọ pe lastma wọ ọkọ ti nkankan ko ṣe loju popo ti ẹni to ni ọkọ ko si foju tabi iwa han wipe oun ko ṣetan lati jọwọ ọkọ naa fun wọn. lori ọrọ owo itanran ti lastma paṣẹ ti wọn si gba lọwọ awakọ naa, adajọ sọ pe lastma lo da nikan fẹsun kan arakunrin naa ti wọn si da ẹjọ koda wọn tungbe ijiya kalẹ lalae fun ni anfaani awijare niwaju ileẹjọ. adajọ ṣalaye pe lẹyin agbeyẹwo finifin ohun ti ofin lastma sọ ni abala 27 (1) b, c, d ati e, awọn ko ri ibi to ti sọ pe lastma le gba owo itanran lọwọ awakọ, lai gbe onitọhun lọsi iwaju ileẹjọ. idajọ yi jẹ eleyi ti ọpọ ọmọ naijiria ni paapa awọn awakọ nipinlẹ eko ti ri gẹgẹ bi ohun to fi idajọ odoo mulẹ. lọpọ igba ni awọn araalu ti n sọ pe gale gale lastma pọ ati pe wọn a maa ṣe ofin to wu wọn nipa mimu awakọ ati gbigba owo itanran lọwọ wọn. lastma ko ti fesi si idajọ yi, a ko si mọ boya wọn yoo pẹjọ kotẹmilọrunlori rẹ.",26 owewe 2022,lati oṣu kọkanla ọdun 2021 ni awọn oṣiṣẹ lastma ti gba ọkọ agbẹjọro yi ni tipa ti wọn si ti bẹrẹ si ni fa ọrọ naa. +ndlea dáná sun egbògi olóró tó lé ọgọ́rùn-ún bílíọ̀nù náírà,"àjọ tó ń gbógunti lílo egbògi olóró ní orílẹ̀ èdè nàìjíríà, ndlea ti dáná sun egbògi olóró tó lé ní ọgọ́rùn-ún bílíọ̀nù náírà. ní agbègbè badagry ní ìpínlẹ̀ eko ni wọ́n ti dáná sun àwọn egbògi olóró náà èyí tí wọ́n jáwọ ibi tí wọ́n ń kówọn sí ní ikorodu lọ́sẹ̀ tó kọjá. ndlea ní ìgbà akọ́kọ́ nìyí tí àwọn yóò ṣe àwárí egbògi olóró tí ó pọ̀ tó báyìí láti ìgbà tí iṣẹ́ wọn ti bẹ̀rẹ̀. wọ́n ní ilé ẹjọ́ gíga ìjọba àpapọ̀ tó wà ní ìpínlẹ̀ eko ló fún àwọn ní àṣẹ láti dáná sun egbògi olóró náà. nínú tọ́ọ̀nù 1.8 èyí tí wọ́n rí mú níbi iṣẹ́ náà, wọ́n ní búlọ̀kù 1,828 ni àwọn dáná sun tí àwọn sì fi ìyókù pamọ́ láti fi ṣẹjọ́ pẹ̀lú àwọn afurasí tí wọ́n mú nígbà tí wọ́n yawọ ilé náà. àwọn afurasí ọ̀hún náà tẹ̀lé àjọ ndlea lọ sí ibi tí wọ́n ti lọ sun egbògi olóró ní ibereko badagry tí wọ́n sì tọwọ́bọ ìwé pé kí ndlea dáná sun àwọn egbògi náà. àjọ náà ní gbogbo dúkìá tí àwọn afurasí náà bá fi owó egbògi olóró kójọ ni àwọn yóò gbà pátápátá. buba marwa tó jẹ́ olórí àjọ ndlea ṣàlàyé pé láàárín ogún oṣù sí àsìkò yìí ọkọ̀ 249 ni àwọn ti gbà lọ́wọ́ àwọn tó ń gbé egbògi olóró tí àwọn sì tún ti dí akoto owó 600 ní àwọn ilé ìfowópamọ́. marwa tún fi kun pé kò dín afurasí 2904 tó ti fojú ba ilé ẹjọ́ lórí ẹ̀sùn gbígbé agbògi olóró. ṣaaju ni a ti mu iroyin wa pe ajọ tó ń gbógun tí lilo oògùn olóró lorilẹede naijiria, ndlea ti jawọ ibi ti wọ ti awọn oloogun oloro gbe oogun oloro to le ni ọgọrun biliọnu naira (n194, 775,000,000) pamọ si. eyi jẹ igba akọkọ ni itan igbogun ti oogun oloro lorilẹede naijiria ti ọwọ yoo tẹ awọn ologun oloro lọgọọrọ lẹẹkan naa. agbegbe kan ni ikorodu ni wọn ti ri oogun oloro naa to le ni ẹgbẹrun kilo. o kere tan awọn to ni oogun oloro yii ni awọn ọtẹlẹmuyẹ naa fi panpẹ mu ni ẹyọ kọọkan kaakiri ilu eko. ọmọ orilẹede miran wa lara awọn olori awọn oloogun ọrọ mẹrin ti wọn ri mu ni ilu eko. awọn wọnyii ni ajọ to n gbogun ti oogun oloro, ndlea ni awọn ti n wa lati ọdun 2018 nitori wọn pẹlu ẹgbẹ awọn oloogun oloro lagbaye. ọjọ isinmi, ọjọ kejidinlogun ati ọjọ aje, ọjọ kọkandinlogun ni wọn ṣiṣẹ ọtẹlẹmuyẹ to ṣafihan awọn oloogun oloro naa. iwadii fihan pe wọn fẹ ko oogun oloro naa lọ si ilẹ yuroopu, asia nibi ti wọn ti fẹ ta a fun awọn olubara wọn ni oke okun. ninu baagi mẹwaa ti wọn n di ẹru si ni wọn gbe oogun oloro ọhun si to fi mọ garawa mẹtala. ajọ ndlea gboriyin fun awọn oṣiṣẹ wọn to ri pe wọn ri ẹyin awọn to n hu iwa ibajẹ lawujọ yii. bakn naa ni wọn gboriyin fun ikọ to n gbogun ti lilo oogun oloro lorilẹede amẹrika (us-dea). ninu ọrọ rẹ, alaga ajọ ndlea ni naijria, mohammed buba marwa ni awọn oloogun oloro yoo ma ranti ọjọ yii titi ayeraye wọn. marwa fikun un pe eyi yoo jẹ ẹkọ fun wọn lati jawọ ninu ṣiṣe ibajẹ ati pe igba ti yipada, aṣiri wọn ko si bo mọ.",19 owewe 2022,"alága ndlea, buba marwa ṣàlàyé pé láàárín ogún oṣù sí àsìkò yìí ọkọ̀ 249 ni àwọn ti gbà lọ́wọ́ àwọn tó ń gbé egbògi olóró." +àwọn tó fẹ́ kí ààrẹ wá láti ariwa ní 2023 fẹ́ mú gbogbo wa ní ọ̀bọ ni – satguru maharaj,"sat guru maharaj sọ̀rọ̀ lórí ètò ìdìbò ọdún 2023 oludari ijọ one love foundation, satguru maharaj, ti sọ pe ẹkun gusu naijiria ni ipo aarẹ kan lọdun 2023. ninu ifrọwanilẹnuwo kan to ṣe pẹlu bbc, maharaj sọ pe awọn eeyan ẹkun ariwa ti ṣe aarẹ fun saa meji, eyi to tumọ si pe gusu lo yẹ ko tun bọ si gẹgẹ bi aṣa ni naijriia. maharaj ni oun rọ gbogbo ọmọ naijiria lati jade lọ dibo, amọ wọn gbọdọ mọ ẹni to yẹ lati dibo fun. “ko bojumu bi awọn to n du ipo aarẹ ṣe pọ, niṣe lo yẹ ki ipo naa bọ si gusu, ti aarẹ to ba wọle yoo si yan igbakeji rẹ lati ariwa.” o sọ pe eyi wa ni ibamu pẹlu aṣa ni naijria pe ki ipo aarẹ ma a lọ yika awọn ẹ̀kùn to wa.",27 owewe 2022,"satguru maharaj sọrọ lori eto idibo 2023, o ni gusu naijiria lo tọ si." +ẹ má ṣe àṣìṣe láti dìbò yan àwọn apààyàn lọ́dún 2023 – jonathan,"oríṣun àwòrán, @gejonathan aarẹ naijiria tẹlẹ, goodluck jonathan ti kilọ fun awọn araalu lati maṣe dibo yan awọn apaayan ninu eto idibo gbogbogbo ti yoo waye lọdun 2023. jonathan lo sọ ọrọ naa niluu uyo nibi isin idupẹ ọdun marundinlogoji ti wọn da ipinlẹ naa silẹ. o ni “lọdun 2023, ẹ ma ṣe aṣiṣe lati dibo yan awọn apaayan sori ipo.” “awọn ti wọn n ko ibọn, ọbẹ atawọ ohun ija oloro mii nitori oṣelu, ọta araalu ni wọn jẹ.” “ẹni to ba gbẹmi eeyan lati de ipo oṣelu yoo tẹsiwaju lati maa gbẹmi eeyan lati di ipo naa mu ni.” “ẹri daju pe lati ile igbimọ aṣofin ipinlẹ, titi de ile igbimọ aṣofin aaab ati gomina, e dibo yan ẹni to tọ ni ipinlẹ akwa ibom.” aarẹ ana ọhun gboriyin fun gomina ipinlẹ naa, udom emmanuel, fun akitiyan rẹ lati mu idagbasoke ba ipinlẹ naa. jonathan sọ pe emmanuel ti ṣe daadaa lati mu igba itura de ba awọn eeya ipinlẹ rẹ lati ọdun meje to ti wa lori alefa. o ni bo ti tilẹ jẹ pe oṣiṣẹ banki ni gomina ọhun tẹlẹ, ti ọpọ eeyah si lero pe ko ni ṣe daadaa gẹgẹ gomina, amọ o jọ awọn ti ko gbagbọ ninu rẹ loju. lẹyin naa lo dupẹ lọwọ igbimọ ijọba ipinlẹ ọhun fun atilẹyin wọn fun gomina naa, eyii to mu ko ṣe aṣeyọri.",26 owewe 2022,jonathan lo sọ ọrọ naa niluu uyo nibi isin idupẹ ọdun marundinlogoji ti wọn da ipinlẹ naa silẹ. +àwọn ajagunfẹ̀yìntì ṣe ìfẹ̀hónúhàn lórí owó oṣù àti àjẹmọ́nú wọn,"àwọn ajagunfẹ̀yìntì kaakiri orilẹ ede naijiria ti bẹrẹ ifẹhonuhan ni ẹnu ọna ilé isẹ ọmọ ogun orilẹ ede naijiria iyẹn ship house to wa niluu abuja. ohun ti wọn n ṣe ifẹhonuhan le lori ni bi awọn alakoso ile-isẹ ọmọ ogun se kọ̀ lati san owó eto aabo ti ijọba apapọ ni ki wọn san wọn. ètò ifẹhonuhan naa lo bẹrẹ ni deede aago mẹjọ owurọ ọjọ aje, ọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu kẹsan-an, bi o tilẹ jẹ pe ojo fẹ di ifẹhonuhan ọhun lọwọ, sibẹ awọn ajagunfẹyinti ọhun fi aake kọri lati duro si ẹnu ọna ile-isẹ ọmọ ogun. wọn pinnu wi pe ti awọn ko ba ri owó awọn gba, àwọn ko ni fi ẹnu ọna ile-isẹ ologun naa silẹ. pupọ ninu awọn ajagunfẹ̀yìntì naa ni wọn gbe ìbùsùn lọ́wọ́ ,ohun ìdáná ati awọn àkọlé orisirisi lọwọ́. lara awọn ohun ti wọn kọ si akọle ọhun ni ""ẹ se atunse si eto owo osu ti ẹ ń san, ki aparo kan maa ṣe ga ju omiran lọ."" ni osu kiini ọdun yii ni awọn ajagunfẹ̀yìntì naa ti kọkọ ṣe ifẹhonuhan ni ile-isẹ to n mojuto eto inawo niluu abuja latari owó osu mẹrinlelogun ti ijọba apapọ ko san fun wọn. agbẹnusọ fun awọn ajagunfẹ̀yìntì ọhun, abiodun durowaiye-herberts sọ pe awọn ti setan lati sún si ile-iṣẹ ajọ ọmọ ogun titi ti wọn yoo fi dawọn lohun. o tẹsiwaju pe awọn ni aya , ọmọ ati awọn opó fun awọn ti wọn padanu ẹ̀mí wọn loju ogun lasiko ti wọn n ba awọn ikọ boko hraam wọya ijakadi. wọn wa rọ minisita fún eto aabo, bashir magashi lati san ajẹmọnu owo naa eyi ti aarẹ muhammadu buhari ti fọwọsi lati san fún wọn .",26 owewe 2022,"wọn pinnu wi pe ti awọn ko ba ri owó awọn gba, àwọn ko ni fi ẹnu ọna ile-isẹ ologun naa silẹ." +"adigunjalè wọ ilé aubameyang, wọ́n lùú, wọ́n tún kó dúkìá rẹ̀","oríṣun àwòrán, getty images awọn adigunjale ji awọn nkan olowo iyebiye ko lọ nile agbabọọlu barcelona, pierre-emerick aubameyang, ni owurọ ọjọ aje. awọn alaṣẹ ẹgbẹ agbabọọlu naa sọ pe ọkunrin mẹrin to di ihamọra nkan ija oloro lo wọ ile agbabọọlu naa, ti wọn si fi ipa mu lati ṣi ilẹkun ibi to n ko awọn nkan olowo iyebiye pamọ si. nibẹ ni wọn ti ko awọn ẹṣọ ara to ko sibẹ lọ. iroyin sọ pe awọn adigunjale naa dunkooko mọ aubameyang ati iyawo rẹ. bakan naa ni iroyin naa sọ pe wọn lu u lasiko ikọlu naa. igba akọkọ kọ niyii ti adigunjale wọ ile awọn agbabọọlu ni orilẹ-ede spain. eyi to ṣẹlẹ yii si ni igba keji ti wọn wọ ile aubameyang ni castelldefels laarin oṣu meji pere. ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe igba akọkọ waye nigba ti agbabọọlu naa ati idile rẹ ko si nile. awọn agbabọọlu barcelona miran ti ole ti wọ ile wọn ni gerard pique, ansu fati, jordi alba, samuel umtiti ati coutinho.",29 ògún 2022,"awọn adigunjale tun wọ ile agbabọọlu barcelona, aubameyang fun igba keji." +ta ni bournemouth ṣẹ̀ tí liverpool fi di ẹrù ìyà 9-0 rù wọ́n?,"oríṣun àwòrán, getty images ẹgbẹ agbabọọlu liverpool tayọ ni ifẹsẹwọnsẹ wọn pẹlu bournemouth pẹlu goolu mẹsan si odo. ifẹwọnsẹ akọkọ ti liverpool yoo bori ni saa liigi 2022/2023 niyi lẹyin ti wọn ti gba ifẹsẹwọnsẹ mẹta ṣiwaju. goolu mẹsan si odo ni goolu to pọju ninu ifẹsẹwọnsẹ kan ṣoṣo lati igba ti liigi premiership ilẹ gẹẹsi ti bẹrẹ lọgbọn ọdun sẹyin. bi o tilẹ jẹ wi pe ṣaju ifẹsẹwọnsẹ naa, akọnimọọgba liverpool, jurgen klopp ṣalaye pe ibẹrẹ wọn ko tii ri bi awọn ṣe fẹ lẹyin ti wọn gbe ta ọmi meji ki manchester united to na wọn lọjọ aje ni papa iṣire old trafford. oríṣun àwòrán, getty images manchester united lo kọkọ na ikọ agbabọọlu miran pẹlu goolu mẹsan an si odo nigba ti wọn koju ipswich lọdun 1995 ati southampton lọdun to kọja. bakan naa ni leicester city na southampton ni mẹsan si odo lọdun 2019. oríṣun àwòrán, getty images diaz gba meji wọle ni iṣẹju kẹta ati ikarundinlaadọrun, firmino pẹlu gba meji wọle nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa wọ iṣẹju kọkanlelọgbọn ati ikejilelọgọta. elliot (iṣẹju kẹfa), alexander-arnold (iṣẹju kejidinlọgbọn), van dijk (iṣẹju karundinlaadọta), freitas gouveia carvalho (iṣẹju ọgọrin). bakan naa ni aṣiṣe de ba mepham, agbabọọlu bournemouth to gba bọọlu si ile ara rẹ.",27 ògún 2022,liverpool ni ẹgbẹ agbabọọlu kẹta ti yoo na alatako rẹ ni goolu mẹsan si odo lati igba ti idije premiership ti bẹrẹ lorilẹede england. +omijé gbojú anthony joshua lẹ́yìn tó lulẹ̀ níwájú oleksandr usyk lẹ́ẹ̀kejì,"oríṣun àwòrán, getty images niṣe lomije n bọ loju gbajumọ akanṣẹgbayi ọmọ orilẹede england, anthony joshua lẹyin to padanu ifẹsẹwọnsẹ ẹṣẹ kikan laarin oun ati oleksandr usyk lọjọ satide mọ ọjọ aiku. bo tilẹ jẹ pe onka awọn alamojuto ifẹsẹwọnsẹ ẹṣẹ kikan naa lo fun usyk ni bẹliti igbanu ẹyẹ olubori nilu jeddah lorilẹede saudi arabia, joshua ṣalaye nigba ti wọn bii lere ọrọ pe, “inu n bimi gidi gan an ni, o dun mi de isalẹ ọkan mi” lẹyin to sọ eyi tan, joshua fọwọ boju rẹ o si mi kanlẹ. o ni awọn, “ipenija kan ti mo n koju n ni ipa lara mi ṣugbọn n ko ni jẹ ki ijakulẹ ija naa gbe mi ṣubu bi o tilẹ jẹ pe yoo nira diẹ” joshua ti gba ami ẹyẹ goolu ẹṣẹ kikan ni idije olympics lọdun 2012 nilu london. lẹyin eyi lo bori awọn ija nejilelogun to kọkọ ja gẹgẹ bi akanṣẹjẹun. anthony joshua ti padanu mẹta ninu awọn ija marun to ja gbẹyin bayii, igba keji si niyi ni tẹlentẹle ti yoo lulẹ niwaju usyk ọmọ orilẹede ukraine. kamaru usman pẹlu lilẹ ni idije ijakadi igbalode ufc 278. kamaru usman padanu idije ijakadi igbalode ufc 278 ni ipele welterweight to wa.",21 ògún 2022,"anthony joshua ti padanu mẹta ninu awọn ija marun to ja gbẹyin bayii, igba keji si niyi ni tẹlentẹle ti yoo lulẹ niwaju usyk ọmọ orilẹede ukraine." +"ẹ má bú ọkọ́ mi mọ́, bàbá tobi kò jẹ́bí bó ṣé dáná sún aṣọ èrè ṣíṣá ọmọ rẹ - ìyá amusan","oríṣun àwòrán, tobi amusan iya to bi tobi amusan ti o di ilumọọka lagbaye ati akọni ori ọdan ti ko si ẹlẹgbẹ rẹ, iyafin amusan ti sọrọ lori ọrọ kan ti ọmọ rẹ sọ. tobi lo sọ fun ẹka ere idaraya bbc pe baba oun maa n dana sun asọ ere idaraya oun ni lasiko ti oun n gbaradi, nitori iwe lo fẹ ki oun gbajumọ. amọ nigba ti oun naa n ba bbc yoruba sọrọ, iya tobi amusan ni ki awọn ọmọ naijiria maṣe bu ẹnu atẹlu baba ọmọ oun. o ni awọn eeyan n bu ọkọ oun lẹyin ti tobi ni baba oun maa n dana sun asọ ati bata oun nitori pe oun fẹ maa sare ori ọdan. tobi amusan lẹyin ti o gba ami ẹyẹ agbaye nidi ere sisa onimita ọgọrun, salaye pe ọpọlọpọ igba ni mama oun ma parọ fun baba oun pe oun lọ sí ṣọọṣì. amọ to si jẹ pe oun lọ se igbaradi fun ere sísa ni. iyafin amusan wa sọ fun bbc yoruba pe ara ọmọ lo ta baba tobi nitori fura tobi lo ni oun fẹ di dokita. mama tobi ni ojuse awọn si ni lati tọ tobi sọna, ko le kọkọ moju to ẹkọ rẹ, ko si yago fun ere sisa. “agbabọọlu ni baba tobi, ẹmi iya rẹ gan mo ma n sa ere, fun idi eyi, baba tobi fẹ ko gba jumọ eto ẹko rẹ lo fi gbe igbesẹ naa. sugbọn o ni ibi ti ọlọrun ba ni eeyan yoo de, yoo de ibẹ lasẹ eledumare.” iyafin amusan ni lati ile iwe alakọbẹrẹ ni tobi amusan ti bẹrẹ si n ma sare, ki o to lọ si oke okun. o tẹsiwaju pe, bi ọrọ naijiria ṣe ba ni lẹru wa lara idi ti baba tobi fi gbe igbesẹ naa, ti o si rọ awọn eeyan lati mase bu ẹnu atẹ lu igbese wọn. “ile iwe jẹ ọkan googi to sọ ọmọ mi di ilu mọka.” “lati ile ẹkọ alakọbẹrẹ ni ọmọ mi ti n sare, titi ti o fi lọ ka iwe ni oke okun, to fi wa ri anfani lati sare fun naijiria. iyafin amusan wa rọ awọn obi ati alagbatọ lati maṣe dẹkun nidi sise atilẹyin fun awọn ọmọ wọn, gẹgẹ bi o ṣe ṣe fun tobi. sugbọn o ni ki wọn ri daju pe wọn ran awọn ọmọ naa lọ si ile iwe fun ẹkọ to peye.” “pẹlu ọlọrun, awọn ọmọ le de ibi ti wọn fẹ, a gbọdọ gbaruku ti wọn pẹlu adura, a gbọdọ ran wọn lọ si ile iwe.” oríṣun àwòrán, getty images tobi amusan ti di ilumọọka lagbaye ati akọni ori ọdan ti ko si ẹlẹgbẹ rẹ nidi ere sisa onimita ọgọrun. laipẹ yii si ni okiki rẹ kan pe o ti laluyọ nidi ere sisa, to si ti gba ami ẹyẹ agbaye nidi ere idaraya naa. ọmọ naijiria ni tobi amusan, o wa lati iran yoruba, to si gbe ogo orilẹede yii ga. nigba to n ba ẹka ere idaraya bbc sọrọ, tobi amusan salaye awọn akoko to lo ni naijiria ati ibasepọ pẹlu ẹbi rẹ. tobi, tii se ẹni ọdun mẹẹdọgbọn lo salaye pe ọpọ ipenija lo dide si oun nitori ere sisa ti oun yan laayo naa. tobi sọ fun bbc pe awọn obi oun ko gba gbẹrẹ rara, ti wọn si mu iwa ọmọluabi lọkunkundun. o ni ẹkọ iwe nikan ni wọn fẹ ki awọn ọmọ wọn dojukọ, ati pe gẹgẹ bii obinrin, wọn ro pe oun ti n si ẹsẹ gbe, ti oun ko si ni afojusun to dara. oríṣun àwòrán, getty images nigba to n salaye iru atilẹyin to ri gba lati ọdọ iya rẹ, tobi amusan ni iya oun ni oju inu, to si ti ri awn ohun ti oun ko ri nipa ọjọ ọla oun. “mama mi ro pe o yẹ ki awọn fun mi ni aaye lati se oun to wu ọkan mi, to si maa n fa mi leti lati mase ja oun kulẹ ninu igbẹkẹle ti oun ni ninu mi. mama mi yoo sọ fun baba mi pe ipade ẹgbẹ akọrin ni mo lọ ni sọọsi wa nigba kiigba ti mo ba yọ jade nile, tabi ko sọ fun pe mo lọ sibi eto ariyanjiyan akẹkọọ ta n pe ni debate. gbogbo asiko yii, mo ti lọ sibi idije ere sisani awn ipinlẹ miran. bi gbogbo rẹ si se bẹrẹ ree. ni ọjọ kan, baba mi yari, to si koro oju si mi nigba ti asiri tu pe mo n lọ sa ere ori ọdan ni. o jo gbogbo awọn asọ ere sisa mi. o wa sọ fun mama mi pe iyẹn ni ko jẹigba ikẹyin ti oun yoo foju kan mi ni ibudo ere idaraya.” amọ bi o tilẹ jẹ pe baba rẹ ko ni igbẹkẹle tabi igbagbọ ninu ere sisa to yan laayo, sibẹ tobi amusan ni igbagbọ pupọ ati igbẹkẹle ninu ara rẹ, eyi to mu ko moke ninu ere sisa. oríṣun àwòrán, getty images oríṣun àwòrán, twitter aarẹ muhammadu buhari ti darapọ mọ ẹgbẹẹgbẹrun awọn ọmọ naijiria lagbaye lati ki arabinrin tobi amusan ku oriire. iyen lẹyin to gba ami ẹyẹ wura fun naijiria ninu idije world athletics championships ti ọdun 2022. amusan to jẹ ẹni ọdun marunlelogun naa lo ṣe ohun ti enikan o ṣeri lasiko to di ọmọ naijiria akọkọ lati gba wura ni idije championship ninu ọrọ aarẹ buhari, o kii pe o ku oriire to si mu iwuri ba orin orilẹede naijiria , ti wọn kọ lati sami si ami ẹyẹ wura to gba naa. aarẹ buhari ni iṣẹtakuntakun to ṣe naa mu ayọ ati idunnu ba awọn ọmọ naijiria, eleyii to mu wọn gbagbọ wi pe ko si ohun to ṣoro lati ṣe pẹlu igbagbọ. o fikun un pe aseyori re yoo jẹ moriya fun awọn ọmọde to n bọ ni ẹyin rẹ lati mọ daju pe ẹni to ba ṣiṣẹ takuntakun yoo ri ere rẹ. bakan naa ni gomina ipinlẹ eko, bajide sanwo-olu ni itan amusan jẹ itan naijiria, eleyii to fi daju pe ti awọn ọmọ naijiria ba gbagbọ ninu ara wọn, ko si ohunkohun to lee ṣoro ṣe fun wọn. o ni arabinrin naa kọ awọn ọmọ naijiria lati ṣiṣẹ ki wọn si mọ pe ere n bẹ fun oniṣẹ. ninu ọrọ tirẹ, gomina ipinlẹ ogun to pe arabinrin naa ni ọmọ oun ti oun yan ni nkan bii osu diẹ ṣẹyin lati ṣe moriya fun iṣẹ to yan laayo. amusan to jẹ ọmọ ipinlẹ ogun ni gomina abiodun ba yọ ayọ to si ni gbogbo awọn ọmọ ipinlẹ ogun wa ni ẹyin rẹ. gbajugbaja elere idaraya, usain bolt naa ki ku oriire to si ni aṣeyọri rẹ lamilaaka, to si wu ni lori. ninu ọrọ idupẹ rẹ, amusan ni ohun ni awọn eniyan ma n lo ọrọ o ku diẹ fun nitori igba mẹta ọtọọtọ ni ohun ti ṣe ipo kẹrin, ki o to di pe oun gba ade wura naa. amusan lo kọkọ fakọyọ ninu idije to kangun si aṣekagba (semi-finals) lẹyin to gba jawe olubori ni iṣeju aaya (12:12 seconds) lẹyin eyi lo wa fọbale ni aṣekagba idije naa nibi to ti wa jawe olubori to si da ẹni akọkọ lati orilẹede naijiria ti yoo gbegba oroke ni idije championships ni agbaye. lẹyin to pegede tan, o gba okẹ marun un dọla owo ilẹ okeere ati ẹgbẹrun aadọrin dọla fun jija we olubori to si gba ami ẹyẹ wura. apapọ owo to gba ti wọn ba yii si owo orilẹede naijiria yoo le ni aadọrin miliọnu naira. oríṣun àwòrán, afp ṣaaju asiko yi, ọpọ le ma mọ nipa elere ori ọdan tobilola amusan ṣugbọn pẹlu ara to da nibi idije c0mmonwealth to n lọ lọwọ, ọpọ lo n kan sara si arabinrin ọmọ naijiria yi. ninu idije elere sisare fo igi taa mọ si hurdles lo ti fi ounjẹ fẹgbẹ to si gbawo bọ nigba to kopa ninu abala to kangun si aṣekagba. ko fi mọ ni eleyi nikan nigba to tẹsiwaju ni abala aṣekagba to si gba ami ẹyẹ wura ninu idije naa. pẹlu itu to pa, oun ni ẹni to sa are lasiko to kere julọ ni isọri awọn obinrin. ni onka iṣẹju, iṣẹju mejila ati iṣẹju aaya mejila(12.12 secs) lo fi gba ife ẹyẹ naa. ẹni ọdun marundinlọgbọn yi fi itan lelẹ nipa pe o la akoko ti ọmọ orileede amẹrika nii kendra harrison ti ṣaaju fi lelẹ gẹgẹ bi ẹni to sare julọ ni isọri ere hurles 100m fawọn obinrin. akoko ti harrison jẹ 12.20 lọdun 2016 lo si fi lelẹ. ninu aṣekagba idije ti wn sa lorileede amẹrika yi, harrison ṣe ipo keji lẹyin amusan ninu abala to kangun si aṣekagba. wakati meji lẹyin igba to fi ẹyin harrison lulẹ ni amusan tẹsiwaju lọ gba ami ẹyẹ goolu ninu aṣekagbga idije naa. koda o tun sare ju ti 12.12 to sa ni abala to kangun si aṣekagba ṣugbọn nitori atẹgun to pọ lasiko ere naa, wọn ko kọ 12.06s toi sa silẹ fun. fọnran fidio ibi ti omije ti n jabọ loju arabinrin tobilola jẹ nkan ti ọpọ ti n sọrọ rẹ ni naijiria loju opo ayelujara. niṣe ni tobi n yọ omi loju nigba ti wọn n kọrin orileede naijiria fun tobi gẹgẹ bi ẹni to jaweolubori. eyi mu ki ọpọ ọmọ naijiria kan saara si ki wn si ni akikanju lo jẹ to si tun gbe ogo naijiria ga. wọn bi tobilola amusan ni ilu ijẹbu ode lọdun 1997 to si kẹkọ jade nileẹkọ girama our lady of apostles secondary school, ijebu-ode. ọmọ yoruba atata yi tẹsiwaju lọ si fasiti university of texas, el paso. ninu awọn ami ẹyẹ to ti gba sẹyin tẹlẹ ni eyi to gba lọdun 2018 ni ilẹ afrika ati nibi idije commonwealth. bakan naa lo tun jaweolubori nibi idije diamond league ni zurich lọdun 2021 nibi idije elere ori ọdan ni abala 100 metres hurdles.",25 agẹmo 2022,"agbábọ́ọ̀lù ní bàbá tobi, èmi ìya rẹ̀ náà ń sáré, ọlọ́run ló gbógo fún wa - mama amusan" +"tobi ní òun kò ní jẹ́ asáré ojú títì lásán, mo sì ń tì í lẹ́yìn - alàgbà amusan","oríṣun àwòrán, getty images awọn obi oluwatobiloba amusan, to jẹ elere ori ọdan ọmọ naijiria, ti n jo yagini yojo pẹlu bi ọmọ wọn ṣe gbegba oroke ninu idije igi fifo 100m hurdles. nibi idije commonwealth games ni akikanju obinrin yii ti fi itan lelẹ gẹgẹ bi ẹni to yara sa ere naa julọ ni isọri awọn obinrin. o fi akoko tuntun 12.30 lelẹ lati fi gba ami ẹyẹ wura lorukọ naijiria lowurọ ọjọ aiku. ṣaaju lo ti kọkọ gba ami ẹyẹ rẹ akọkọ nibi abala to kangun si aṣekagba idije elere igi fifo 100 metres hurdles lọjọ aiku. awọn obi rẹ, arakunrin ati arabirin amusan sọ fun bbc pe awọn ko ti gbagbe ayọ ati idunnu tawọn mọ nigba ti tobi gba ami ẹyẹ wura. bakan naa lo si tun fi itan lelẹ nibi idije world athletics championships to waye ni eugen usa. nibẹ lo ti fi itan lelẹ gẹgẹ bi ọmọ naijria akọkọ ti yoo gba ami ẹyẹ wura nibi idije naa. baba tobi sọ iriri rẹ lalẹ ọjọ ti tobi gba ami ẹyẹ nibi idije world chamìonship. o sọ fun bbc pe oun ko sun daada lalẹ naa nitori pe oun fẹ wo tobi lasiko ti yoo sare lori amohunmaworan. baba amusan tẹsiwaju pe nigba ti tobi kopa nibi idije world championship, mo sọ pe mo gbọdọ darun mọju lati wo isesi rẹ lori ọdan. oorun diẹ bẹrẹ si ni kun mi nitori akoko wa yatọ si ti ilu to ti n kopa nibi idije naa. gẹgẹ bi obi, bi ọmọ rẹ ba ṣe oriire, idunnu rẹ ko ni lopin, a kọrin, a jo, a fọpẹ fun ọlọrun. inu wa dun pupọ kii se ọjọ ti eeyan ba gun, lo n kan ọrun, lẹyin igbesẹ akọkọ, mo ti n sọ fun awn ohun to yẹ ko se atawọn ohun ti ko yẹ ko se. koda, tobi sọ fun mi pe laelae, oun ko ni jẹ asare oju titi lasan, lati igba naa ni mo ti n se atilẹyin fun. mo si nigbagbọ ninu rẹ pe lọjọ kan, yoo di ohun eelo to se iyebiye lagbo ere idaraya. lootọ ni ala mi pada wa sẹ lori rẹ, eyi to dun mọ mi ninu, ogo si ni fun oluwa nitori kii se mimọọse wa. o fikun pe oun ko mọ pe iru ọjọ bayii yoo waye, ti ogo tobi yoo tan bi ti irawọ. baba tobi sọ pe kii ṣe mimọ ṣe awọn bi kii ṣe pe ọlọrun lo gbogo fun ọmọ awọn.",8 ògún 2022,"awọn obi akikanju elere ori ọdan, tobi amusan, ba bbc sọrọ nipa bi inu wọn ṣe dun to lori aṣeyọri ọmọ wọn." +láéláé! naijiria kọ́ ló kàn láti gbàlejò afrcia cup of nations ti 2025,"oríṣun àwòrán, getty images adari ajọ elerebọọlu ni naijiria, amaju pinnick ti sọ pe ajọ elereebọlu ilẹ afrika ti ni orilẹede naijiria ko lee gbalejo idije african cup of nations ni ọdun 2025. pinnick fi eyi lede ni ọjọ iṣẹgun pe igbiyanju wọn lati gbalejo idije afcon 2025 ti bọ si pabo. o ni ajọ caf ni orilẹede guinea ni awọn ti gbe igbalejo naa fun un, ti ko si si ohun to tii yipada. ohun ti naijria n fẹ ni lati jijọ gbalejo idije naa pẹlu orilẹede benin republic paapaa aṣekagba idije naa. orilẹede guinea ti wọn gbe idije naa fun lo n koju ijọba ologun lọwọlọwọ lẹyin ti ikọ ologun lorilẹede naa gba iṣakoso ni ọdun to kọja. eyi ti fa ki awọn eniyan ma a bẹru nipa eto aabo lorilẹede naa lasiko idije afcon naa ni ọdun 2025. amo ọkan lara awọn ọga agba caf to ba awọn oniroyin sọrọ ni ko si ohun to ti yipada nitori guinea ni akọsilẹ wa pe yoo gbalejo idije naa. oríṣun àwòrán, getty images ọdun 2019 ni orilẹede guinea gba lati gbalejo idije afcon 2025 lẹyin ti ajọ caf naa ṣe agbeyẹwo idije afcon fun ọdun 2019, 2021 ati ọdun 2023. nibayii, idije to yẹ ko waye ni ọdun 2023 ni wọn ti gbe lọ si ọdun 2024 nitori asiko oojo. bakan naa ni naijiria to n gbiyanju lati gbalejo ti ọdun 2025 naa n koju eto aabo to dẹnukọlẹ, ti ko si agbegbe ti aabo to ye kooro wa.",29 agẹmo 2022,caf yarí lórí ọ̀rọ̀ ẹni tó máa gbàlejò afcon 2025 pé naijiria kọ́ ló kàn láti gbàlejò afrcia cup of nations +"àlàyé lórí adijat adenike olarinoye, ọmọ nàìjíríà tó gba góòlù àkọ́kọ́ ní ìdíje commonwealth birmingham 2022","oríṣun àwòrán, getty images aderinola gbe irin ọmọ naijiria to kopa ni idije irin gbigbe, weightlifting oni iwọn 55kg, adijat adenikẹ ọlarinoye ti gba goolu akọkọ fun orilẹede naijiria nibi idije ere idaraya commonwealth games to n lọ lọwọ nilu birmingham, lorilẹede england. iwọn irin ti apapọ rẹ jẹ iwọn kilogiramu mẹtalenigba, 203kg ni ọlarinoye gbe lati gba ami ẹyẹ goolu ni idije irin gbigbe oni iwọn kilogiramu marundinlọgọta, 55kg. ni ẹka iringbigbe yii to jẹ snatch, iwọn mejilelaadọrun kilogiramu, 92kg lo gbe, iwọn kilogiramu mọkanlalaadọfa, 111kg lo gbe ni ipele claen and jerk, ti apapọ gbogbo rẹ fi ku si iwọn kilogiramu mẹtalenigba, 203kg. agberingbayi lati orilẹede india, bindyarani devi sorokhaniban lo gba ami ẹyẹ fadaka ti agberinjẹun ọmọ orilẹede england, fraer morrow gba ami ẹyẹ baba. ariwo ayọ nla lo sọ ni ibudo ifiniwọsi awọn ikọ elere idaraya naijiria nibi idije ere idaraya naa lẹyin ti ọgbogbo awọn agberin yoku ti naijiria ko lọ sibi idije ere idaraya commonwealth games naa kuna lati kogoja. ireti ọpọ ọmọ naijiria bayii ni pe awọn elere sisa ti naijiria ko lọ sibi idije ere idaraya naa yoo ta biọ̀biọ nigba ti asiko ba to fun awọn idije ere sisa gbogbo. oríṣun àwòrán, screenshot aworan atẹ igbelewọn irin gbigbe onikiliogiramu 55kg ọmọ ọdun mejilelogun ni adijat adenikẹ ọlarinoye gẹgẹ bi akọsilẹ to wa lọwọ awọn alakoso ere idaraya commonwealth games loju opo itakun agbaye birmingham 2022 . ni ọjọ kẹrinla oṣu keje ọdun 1999 ni wọn bii lẹkun iwọ oorun gusu orilẹede naijiria. ṣaaju akoko yii, ami ẹyẹ mẹta ọtọọtọ ni ọlarinoye gba fun naijiria nibi idije ere idaraya ilẹ adulawọ, african games to waye lorilẹede morocco ni ọdun 2019 . oríṣun àwòrán, getty images aderinola gbe irin lasiko idije ere idaraya naa, o gba goolu kan ni idije irin gbigbe oni iwọn kilogiramu marundinlọgọta, 55kg ki o to tun lọ gba ami ẹyẹ goolu miran ni ipele clean-jerk ti idije irin gbigbe oni iwọn kilogiramu marundinlọgọta, 55kg. bakan naa lo tun gba ami ẹyẹ fadaka ni idije ere idaraya naa. bakan naa ni ọlarinoye tun gba ami ẹyẹ goolu ni idije agbaye fun irin gbigbe, international weightlifting federation world championship, to waye ni ilu tashkent lorilẹede uzbekistan ọdun 2021.",31 agẹmo 2022,ireti ọpọ ọmọ naijiria bayii ni pe awọn elere sisa ti naijiria ko lọ sibi idije ere idaraya naa yoo ta biọ̀biọ nigba ti asiko ba to fun awọn idije ere sisa gbogbo. +ká má a jí owó ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àti ìwé yíyí ló da ààrin èmi àti ‘speaker’ ogun rú,"ká má a jí owó ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àti ìwé yíyí ló da à[rin èmi àti ‘speaker’ rú awuyewuye to n waye laarin olori ile igbimọ aṣofin ipinlẹ ogun, olakunle oluomo ati igbakeji rẹ, oludare kadiri, ko ti dopin. ọjọ kinni, oṣu kẹsan-an, ọdun 2022, ni ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ ni najiria, efcc, mu olori ile aṣofin naa fun ẹsun kiko owo ilu jẹ. ọwọ tẹ ẹ ni papakọ ọkọ ofurufu murtala muhammed nilu eko. wọn fi ẹsun kan ọgbẹni oluomo ati awọn aṣofin mii, pe wọn yí iwe, wọn si tun ṣe mago-mago iwe akọsilẹ owo ile aṣofin naa. o lo ọjọ diẹ ni ahamọ ajọ naa, ki wọn to o pada yọnda rẹ, botilẹ jẹ pe iwadii ṣi n lọ lori ẹsun naa. diẹ lara awọn ọmọ ile aṣofin naa, to fi mọ olori ile funra rẹ si lo gbagbọ pe, ti wọn si fi ẹsun kan igbakjei pe oun lo ditẹ pẹlu efcc lati parọ ole mọ ọgbẹni oluomo. lẹyin ọrọ naa ni awọn ọmọ ile aṣofin ati olori wọn, paṣẹ fun igbakeji rẹ ati aṣofin mii pe awọn da wọn duro fun igba diẹ. ninu ọrọ to ba bbc sọ, igbakeji ile aṣofin naa, ọgbẹni oludare kadiri, sọ pe olori ile fi orukọ oun fọwọ si awọn iwe owo kan to to ọgọrun miliọnu naira ti oun ko mọ nipa rẹ. bakan naa lo sọ pe awọn igbesẹ olori ile naa le sọ oun di eero ẹwọn lọjọ iwaju ni oun ṣe kesi efcc. ṣugbọn ninu ọrọ rẹ, aṣofin oluomo to jẹ olori ile sọ pe fifi ẹjọ sun efcc tako ofin ihuwasi awọn aṣofin.",26 owewe 2022,olori ile aṣofin ipinlẹ ogun ati igbakeji rẹ ṣalaye nkan to da arin wọn ru ti ile ko fi tooro +wo ọmọ nàíjíríà tó ń gbèjà ilẹ̀ baba rẹ̀ lọ́wọ́ àbùkù àti ìkórira pẹ̀lú ìjìnlẹ̀ ọ̀rọ̀ ẹnu,"deji ige: bí mo kúrò nílé, ọkàn mi kò kúrò, tá bá tún ilé ṣe, ọjọ́ iwájú kò ní dárí jìn wá owe yoruba kan lo ni nibi ti n pa ọ wa, ni n o gba ọ wa nitori eeyan meji kii binu iyọ lọja, bi eeyan kan ba tu, eeyan kan yoo. bi o tilẹ jẹ pe ọpọ ọmọ naijiria lo n wa bi wọn yoo se sa kuro lorilede yii, paapaa awọn ọdọ amọ ọkunrin kan ree, to ni afori-afọrun, naijiria ni oun yoo duro ti. deji ige nii se onkọwe ati akewi, to si n lo ijinlẹ ede yoruba ati gẹẹsi lati tako iwa abuku ati ikorira ti ọpọ ọmọ naijiria n hu silẹ baba wọn. nigba to n ba bbc yorùbá sọ̀rọ̀, deji ige salaye idi to se n gbe igbesẹ yii, to se n fi ijinlẹ ede tun oruk ati ayanmọ naijiria se nile ati lẹyin odi. gẹgẹ bi ige ti wi, bi oun tilẹ kuro ni naijiria, ko seese lati ko gbogbo ẹbi oun tabi ọkan oun kuro nitori tiwa n tiwa, akisa ni ti aatan. ninu alaye rẹ, deji ige ni isẹ ologun lo kọkọ wu oun lati se ni aarọ ọjọ aye oun, ti oun si gbiyanju nigba mẹrin ọtọọtọ amọ ti wọn ko gba oun si isẹ ologun. o ni idi ree ti oun se mu gege ikọwe oun lati maa se awọn akọsilẹ ọpọ isẹlẹ to n waye lorilẹede yii, boya ire abi ibi. ige ni lati ipasẹ eyi ni oun ti bẹrẹ si ni sọrọ kaakiri agbaye, boya lori redio ni tabi mohunmaworan, ti ohunsi tun n fi ewi gba a lẹgbẹ. “ebi lo n ba ọpọ eeyan finra ni naijiria, ti ọwọn gogo epo si ti di ọmọ naijiria, ojoojumọ lawọn olukọ fasiti n dasẹ silẹ, tawọn osisẹ ilera si n sa kuro lorilede yii.” mo n ri awọn isẹlẹ to n waye ni agbegbe mi, idi ree ti ẹnu mi ko fi le dakẹ si ọpọ awọn aidaa to n waye naa. amọ ti mo ba ri ohun to dara nipa naijiria, ko yẹ ki n dakẹ nitori ba se n ri aidaa, naa la n ri awọn ohun to dara.” o salaye pe oun gbọgbọ pe akọsilẹ oun ni lati di gbajumọ asọrọgbayi nitori oun ko lero pe isẹ miran wa, ti ko ba gbe oun de ibi ti oun de lonii yii. “ọrọ naijiria jẹ mi logun, tori ko sibi to dabi ile”",23 owewe 2022,"deji ige ni oun ko le fi ọrọ naijiria sere tori ko sibi to dabi ile fun oun, to si ni ta ba tun ile se, ọjọ iwaju ko ni dari jin wa." +"""mo gba ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ lọ sí amẹ́ríkà láì lówó lọ́wọ́ tàbí mọ èèyàn pàtàkì""","ìrírí àgbà: oladele awobuluyi ní nàíjíríà yóò jìyà báwọn dókítà ṣe ń yọ lọ sókè òkun yoruba ni iriri lo n jẹ agba, ohun ti agbalagba ba si ri lori ijoko rẹ, bi ọmọde ba gun ori igi, o le maa ri. idi ree ti bbc yoruba fi n tọ awọn agba awujọ lọ lati bu mu ninu omi ọgbọn wọn lati ipasẹ iriri ti wọn ti ri nile aye, ni abala eto iriri agba ta n mu wa fun yin ni ọsọọsẹ. iriri yii naa si ni wọn yoo fi gba awọn ọdọ nimọran to le tọ wọn sọna lati se ile aye wọn, ki wọn maa ba si ẹsẹ gbe. yoruba naa lo sa ni agba kii wa lọja, ki ori ọmọde wọ. ọjọgbọn oladele awobuluyi, tii se akọsẹmọsẹ olukọ agba ni ẹka ẹkọ ede, onkọwe ati agba awujọ lo ba bbc yoruba sọrọ ni abala iriri agba lọsẹ yii. lasiko ifọrọwerọ naa si ni agba awujọ ọhun ti mẹnuba awọn anfaani ti orilẹede naijiria se fun nigba ewe rẹ ati ọna to gba sanjọ pada fun orilẹede yii. amọ ka to sọrọ nipa ifọrọwerọ to waye, ẹ jẹ ka mọ diẹ nipa baba agba ọjọgbọn oladele awobuluyi, ta ni ọjọgbọn oladele awobuluyi? ọmọ bibi ilu okeagbe nijọba ibilẹ iwọ oorun ariwa akoko ni ọjọgbọn oladele awobuluyi. ọjọ kẹtadinlogun osu keje ọdun 1937 si lo dele aye lẹyin ti iya rẹ ti bi ọpọ abiku. o ni awọn akẹẹgbẹ oun tawọn dijọ n sere lo se iwuri fun oun lati lọ forukọ silẹ nile ẹkọ bi o tilẹ jẹ pe o to ọdun kan lẹyin igba na, ko to le bẹrẹ ẹkọ kikọ. idi ni pe wọn ni ọwọ rẹ ko to eti nigba naa, ti wọn si ni ko pada lọ sile lati lọ dagba diẹ si, ko to wa bẹrẹ ile ẹkọ. nigba to n salaye awọn ọna ti orilede naijiria fi gbe larugẹ lati goke agba, awobuluyi ni ọdun 1959 ni oun ri ẹkọ ọfẹ ijọba apapọ gba lati lọ kawe ni amẹrika. “mo se ọdun meji ati aabọ ni colorado, ki n to wa lọ si columbia nilu new york lati kawe gboye si ninu ede latin. ijọba apapọ lo ran mi lọ, mo si bẹbẹ pe ki wọn fun mi ni ọdun meji si, ki n le ni iriri isẹ olukọ nile ẹkọ giga. ijọba gba fun mi, mo si pada sile lọdun 1969.’ awobuluyi ni oun ko mọ ẹnikẹni ri, ti ijọba apapọ to fun oun ni ẹkọ ọfẹ lati lọ kawe. o ni agbẹ ni awọn obi oun, oore nla si ni ijọba se oun. “n ko tiẹ sopo pe mo fẹ duro silu oyinbo, mo mọ pe ijọba se mi loore, mo si gbọdọ pada wa sile, lati wa se ẹlomiran loore pẹlu imọ ti mo ni. ko tiẹ ro mi lara rara lati sọ pe mo fẹ pada wa sile nitori pe ile ni abọ sinmi oko, a si tun ni ero lati wa tun orilẹede wa se. kii se emi nikan lo pada wa sile, gbogbo awa ti ijba ran lọ soke okun, la pada wa. amọ bi ilu wa se ri bayii, lo n mu kawọn to ba lọ soke okun fi aake kọri, lati mase pada wa sile mọ.” nigba to n salaye pe oun ko se laalaa, ki oun to ri isẹ se, ọjọgbọn oladele awobuluyi fikun pe awọn ileesẹ to fẹ fun awọn nisẹ, maa n duro, ki awọn pari ile kọ ni. “ko ba jẹ ileesẹ ijọba ni eeyan fẹ ba sisẹ ni tabi ti aladani, ka to pari idanwo, ni wọn yoo ti maa wa fi ọrọ wa wa lẹnu wo. o nilo lati mọ ẹnikẹni ri, ko to fun ọ nisẹ, to ba ti pegede ninu ifọrọwerọ pẹlu wọn.” ọjọgbọn awobuluyi tun woye pe inu oun ko dun si bi awọn dokita wa se n sa lọ soke okun. o ni yoo nira fun naijiria lati gberi nitori awọn to yẹ ko maa fi orilẹede yii yangan, lo n sa lọ yẹn. bakan naa lo ni a maa jiya si bi ọpọ awọn dokita naa se n sa kuro nilẹ naijiria nitori pe yoo se akoba fun ẹka ilera wa. o wa rọ ijọba apapọ lati tete mọ pe ojuse oun ni lati setọju awọn ọmọ orilẹede yii nitori eyi nikan lo le dẹkun ba se n sa lọ soke okun. nigba to n foju abuku wo awọn obi ti ko fẹ ki awọn ọmọ wọn maa sọ ede abinibi, paapaa yoruba, awobuluyi ni itanjẹ gbaa ni iwa yii. o ni wọn kan n tan ara wọn jẹ ni nitori awọn isẹ to labuku ni wọn yoo pada se loke okun ti wọn ba sa lọ. o wa dupẹ lọwọ ọlọrun fun imọ nipa ede yoruba to yan laayo, ti ọlọrun si tete fi ọna han oun. o ni lẹni ọdun marundinlaadọrun, oun si n kọ iwe jade, ti oun si n ronu nipa ohun tuntun ti oun le mu jade nipa ede yoruba lojoojumọ.",22 owewe 2022,"ni abala eto iriri agba wa, ọ̀jọ̀gbọ́n oladele awobuluyi gba awọn ọdọ to n ya lọ soke okun nimọran ati idi to fi yẹ ka pawọpọ gbe ilẹ wa larugẹ." +ohun tí ojú mí rí rèé lẹ́nu ìrínàjò lọ sí yúróòpù,"arakunrin ike nnebule sọ iriri rẹ nigba ti o gbiyanju lati lọ si ilẹ yuroopu ọmọ naijiria kan, ike nnaebue ti sọ iriri rẹ nigba to gbiyanju lati rin irinajo lọ si ilẹ yuroopu. ike anaebue ni oun gbiyanju ni nkan bi ọdun mẹrindinlọgbọn ṣẹyin pẹlu awọn ọrẹ oun mẹta. o ni awọn tẹ ọkọ leti lọ si ilu benin lati rin irinajo lọ si oke okun. erongba wa ni lati sọda lati ila oorun ilẹ afrika lọ si togo, burkina faso, mali ati mauritania to fi mọ morocco. nibẹ la gba de yuroopu paapaa spain, nibi ti wọn ti sọ fun wa pe ẹnikẹni to ba fẹ ṣe iṣẹ, yoo ri iṣẹ ṣe. ohun ti wọn sọ fun wa ni pe ẹnikẹni to ba wa iṣẹ yoo ri iṣẹ, emi si fẹ ṣiṣẹ eze ni ọpọlọpọ awọn to n rin irinajo yii ni wọn ma n yi orukọ wọn pada, ki wọn ba le ri ọrọ sọ, ti awọn eniyan ba beere ni ọwọ wọn. eze ni junior ni orukọ ti oun yan laayo nitori awọn ko le ṣẹẹṣẹ ma a ṣalaye ara awọn fun awọn eniyan. ọkan lara awọn to ba eze sọrọ ninu fidio naa ni james ni orukọ oun ati wi pe oun fẹ igbe aye irọrun ni oun ṣe fẹ rin irinajọ lọ si ilẹ miran. ọpọlọpọ nkan lo ma n ṣẹlẹ si wọn ni oju ọna, igba miran wọn ma n na wọn, ti wọn ma n ja wọn lole tabi ki wọn tilẹ ta ẹya ara wọn. bakan naa ni awọn obinrin sọ iriri wọn bi wọn ṣe ma n fi ipa ba wọn lọpọ ti wọn ba n rin irinajo wọn lọ si ilẹ yuroopu. obinrin to sọ iriri rẹ ni awọn eniyan fẹ lati pada si ile amọ itiju ni kii jẹ ki wọn pada. o ni ti awọn miran a si ma tọrọ lati jẹun, tabi fi ko owo jọ lati ra ọkọ oju omi ti yoo gbe wọn lọ si ilẹ yuroopu. ọjọ kan la fi rin irinajo de morocco amọ aja awọn ọlọpaa bẹrẹ si ni le wa. a kọkọ fẹ salọ, amọ a duro nitori ki aja naa ma ba bu wa jẹ titi awọn ọlọpaa fi de ibẹ. lẹyin naa ni awọn ọlọpaa naa da wa pada lọ si ile. bi o tilẹ jẹ pe eze pada si ile lẹyin to kọ ẹkọ imọ nipa gbejade sinima ni gambia, ọpọlọpọ awọn eniyan ni ko pada de ile mọ.",21 owewe 2022,"ike naebue sọ fun bbc pe ọpọ nnkan lo maa n ṣẹlẹ si awọn arinrina ajo silẹ yuroopu loju ọna, wọn maa n na wọn, ja wọn lole tabi ta ẹya ara wọn." +"""babaláwo ní n kò ṣe lò làwọn tó fẹ́ fi mí ṣòògùn owó fi dá mi padà""","osun honourable father: ""babaláwó rí àmìn ọ̀run lọ́wọ́ mi, ní ẹni ọ̀wọ̀, ẹran ọ̀hun ni mí laipẹ la mu iroyin wa fun yin pe họnọrebu kofoworola babajide ti ọpọ eeyan mọ si akọgun nilu ede, to tun jẹ olori ọmọ ẹgbẹ oselu to kere ju nile asofin ipinlẹ osun kede pe oun ti ri baba oun tawọn n wa. idi ree ti bbc yoruba fi gba ilu ede lọ lati lọ gbọ tẹnu baba naa nipa ọna to gba bọ ni akata awọn to ji gbe salọ. nigba to n ba bbc yoruba sọrọ, alagba mudasiru lawal naa ni ori lo ko oun yọ lọwọ wọn. o ni ọkada ni wọn fi gbe oun kuro nile oun nilu ede, ti wọn si gbe oun lọ sile babalawo kan. o ni erongba wn ni lati fi oun se oogun owo amọ ti ẹlẹda oun ko jẹ. alagba lawal tẹsiwaju pe babalawo ti wọn gbe oun de ọdọ rẹ beere lọwọ ifa boya ẹran to se lo fun oogun owo ni oun. amọ o ni se ni ifa yari, ti babalawo naa si beere pe orisa wo ni wọn n bọ ninu idile awọn. “mo sọ fun wọn pe awa ko ni orisa amọ wọn maa n bọ sango ninu idile iyawo mi. babalawo naa ni abajọ, to si tun ri amin ọrun kan ni ara oun, to si beere pe ki lo wa fun. mo si sọ fun pe lati ọrun ni oun ti mu amin naa wa, o wa sọ fun awọn to gbe mi wa pe ẹran ọwọ ni mi, ti n ko si se lo fun oogun owo. o tun fikun pe ti awọn to gbe mi wa ko ba fẹ ki sangho pa awọn, yoo dara ki wọn tete gbe oun pada sibi ti wọn ti gbe oun. charles agbako: n kò le yàgbẹ́ tàbí tọ̀, ara ń ni mí saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe bàbá asofin adewunmi kofoworola babajide, tii se olori ọmọ ẹgbẹ oselu to kere julọ nilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ osun, alagba muftau lawal, ti pada wale. bẹẹ ba gbagbe, ọmọ rẹ, asofin koforola naa lo ń ṣojú ẹkun idibo àríwá ede, lo pariwo pe oun ko ri baba oun mọ lasiko laasigbo oselu to waye nilu ede laipẹ yii. lasiko rogbodiyan naa si ni wọn jo ile ti asofin kofoworola kọ fun baba rẹ naa, ti wọn ko si ri oku tabi aaye baba naa nigba naa. amọ iroyin kan ti asofin kofoworola fi soju opo facebook rẹ lọjọ ẹti to kọja ti salaye pe baba oun ti de. ""awọn ọlọpaa lo pe mi lori foonu pe wọn ti ri baba mi nilu lokoja nipinlẹ kogi, ti wọn si ti n seto bi yoo se pada wa sile. bi inu mi tilẹ dun pe wọn ti ri baba mi amọ inu mi ko dun si awọn iriri ti ko dara to seese ko ni ni akata awọn eeyan to ji gbe naa. mo wa dupẹ pupọ lọwọ gbogbo awọn eeyan to duro ti mi lasiko isoro naa, mo si lero pe baba mi ko ni ni irora nipa ilera rẹ nitori awọn ohun to ti la kọja naa."" alagba lawal wa salaye lori iriri rẹ fawọn akọroyin lẹyin to ti akata awọn ajinigbe de, eyi ti ọmọ rẹ fi soju opo facebook rẹ. ó ní ṣàdédé ni òun rí tí àwọn kan gbé ọ̀kadà wá bá òun ní ẹnu ọ̀nà ilé òun tí wọ́n sì ń dúnkokò mọ́ òun pé òun máa pa òun tí òun kò bá pàdé wọn. + + ""iwájú ilé ni mo wà ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà tí mò ṣàdédé rí àwọn ènìyàn tí wọ́n ya wọ ilé mi lórí ọ̀kadà."" + + ""lẹ́sẹ̀ kan náà ni àwọn ọmọ tí wọ́n wà níwájú ilé tí wọ́n ń ṣeré kọ́kọ́ sá dànù."" + + ""àwọn ajínigbé náà wá ń sọ fún ara wọn pé kí àwọn yìbọn fún mi tàbí kí wọ́n jó mi ní ààyè."" + + ó ní lẹ́yìn tí àwọn yẹn lọ tán ni àwọn mìíràn tún dé pẹ̀lú ọ̀kadà tí wọ́n sì ní kí n gun orí ọ̀kadà. ""mo bèrè wí pé níbo ni wọ́n ń gbé mi lọ, tí ọ̀kan nínú wọn sì fún mi lésì wí pé àwọn ń gbé mi lọ sí ọ̀dọ̀ ọmọ mi, akogun."" + + ""nítorí ọjọ́ orí mi, ojú mi kò ríran dada mọ́, ṣùgbọ́n nígbà tó ṣe díẹ̀ mo ri wí pé ọ̀nà ilesa ni wọ́n ń gbé mi lọ."" + + ""nígbà tó tún ṣe díẹ̀ ni mo tún bèrè wí pé níbo ni wọ́n ń gbé mi lọ ṣùgbọ́n wọ́n fèsì wí pé tí mo bá tún bèrè ọ̀rọ̀ kankan lọ́wọ́ àwọn, àwọn ma pa mí síbẹ̀."" + + ""ilẹ̀ ti ń ṣú ní gbogbo ìgbà tí à ń sọ yìí tí wọ́n sì ń sáré gidigidi lórí eré mi ò sì le rí nǹkankan mọ́."" + + alagba lawal tẹ̀síwájú pé nígbà tó ṣe díẹ̀, àwọn dé ilé kan tí babaláwo wà nínú rẹ̀ tó sì ń dífá. alagba lawal ní díẹ̀ ló kù kí wọ́n fi òun ṣe oògùn owó ni ahamọ ti oun wa. ó ní lẹ́yìn tó pọfọ̀ ló bèèrè lọ́wọ́ òun pé ṣé òun ní òrìṣà kankan tí wọ́n ń bọ ní ìdílé àwọn tí òun sì fún lésì pé rárá ṣùgbọ́n àwọn ìyàwó òun máa ń bọ ṣàǹgó. + + ó fi kun pé ìgbà náà ni babaláwo náà pe àwọn tí wọ́n gbé òun wá pé kí wọ́n wá gbé òun padà nítorí òun kò ṣé lò. + + ó ṣàlàyé pé àwọn tó gbé òun lọ sí ọ̀dọ̀ babaláwo náà kò padà wá fún bí ọ̀sẹ̀ mélòó kan tí wọ́n tó wá gbé òun ní ọ̀sẹ̀ tó kọjá. + + ó ní nígbà tí wọ́n wá gbé òun ní àárín òru ni wọ́n gbé òun sínú ọkọ̀ kan tó gbé òun lọ sí ìlú lokoja. + alagba lawal fi kun pé nígbà tí òun dé lokoja ni òun lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá láti lọ fi ọ̀rọ̀ náà tó wọn létí tí wọ́n sì kan sí àwọn ènìyàn òun ní ìpínlẹ̀ osun. + + ""nígbà tí mo dé osun, kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá gba ọ̀rọ̀ lẹ́nu mi to sì ṣèlérí láti wá ìdí ọ̀rọ̀ náà láti mọ àwọn tó ṣiṣẹ́ náà kí òun tó padà sí ìlú ede."" baba agba naa ní ọlọ́pàá ló fún òun ní bàtà tí òun wọ̀ padà sí osun nítorí aṣọ kan tí òun wọ̀ ló wà ní ọrùn òun. + + alagba lawal wá rọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá láti fojú àwọn aṣebi tí wọ́n ṣiṣẹ́ náà hàn. + ẹ ó rántí pé nínú oṣù kẹjọ ọdún yìí ni ni wọn fi ẹsun kan olórí ọmọ ẹgbẹ oselu to kéré jùlọ ní ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ osun, kofoworola babajide awọn ọmọ ẹgbẹ oselu pdp ni wọọdu kan nilu ede ni o ń fi ọlọ́pàá dúnkokò mọ́ àwọn níbi ìpàdé ẹgbẹ́ wọn kàn to waye nilu naa. nígbà ti ọ̀rọ̀ náà ṣẹlẹ̀, ènìyàn méjì ni ọta ìbọn pa, abideen ati kafayat olalekan, ti awọn mejeeji si wa latinu ẹbi kan soso. + + ẹ̀wẹ̀, babajide jiyàn gbogbo ẹ̀sùn náà wí pé àwọn kan lọ sí ilé bàbá òun, tí wọ́n jó ibẹ̀ níná, kí wọ́n tó jí gbé.",18 owewe 2022,"ede crisis: baba akogun ni babaláwó rí àmìn ọ̀run lọ́wọ́ òun, ó ní ẹni ọ̀wọ̀ àti ẹran ọ̀hun ni òun tí kò ṣe fi ṣe owó torí ìjà ṣàngó" +"a kò fẹ́ ki bàbá charles olumo jẹ ìrora kú, ìnira àìsàn wọn pọ̀ - aya ọmọ agbako","charles agbako: n kò le yàgbẹ́ tàbí tọ̀, ara ń ni mí laipẹ yii la mu iroyin wa fun yin pe ojojo n se ogun baba agba lagbo tiata, charles olumo, ti ọpọ eeyan mọ si agbako. agbako, tii se odu, ti kii se aimọ fun ologbo lagbo tiata lede yoruba lo ti dubulẹ aisan naa lati bii osu mẹta sẹyin. ninu fidio yii ni agbako funra rẹ ati aya ọmọ rẹ, olamide ti ba bbc yoruba sọrọ nipa ipo inira ti agba osere tiata naa n la kọja. gẹgẹ bi agbako ti wi, ọkunrin ni oun fi n gbe inira naa, ti awn dokita si sọ pe oun nilo lati maa lo oogun oore koore, lati mu inira naa ku. baba agbako ni owo to le diẹ ni igba naira ni dokita sọ pe oun nilo lati maa ra oogun naa lati igba de igba nitori oun ko le se isẹ abẹ mọ. agbako wa n bẹbẹ fun iranwọ awọn ololufẹ rẹ, ki inira naa le dinku. nigba oun naa n ba bbc yoruba sọrọ ninu fidio yii, olamide, tii se aya ọmọ baba naa kaanu pupọ nipa ipo inira ti baba ọkọ rẹ wa. olamide ni “baba agbako ti n sọ pe ti oun yoo ba ku, ki oun kuku ku nitori inira naa pọ amọ a ko gbadura pe ki baba naa ku sinu irora yii.” o ni lootọ ni agbako se isẹ abẹ amọ ko jẹ ki egbo naa jinna to tun fi bẹrẹ isẹ tiata pada eyi to mu ki aisan naa gbodi lọ lara rẹ.",20 owewe 2022,fídíò rèé níbi tí charles olumo agbako àti aya ọmọ rẹ̀ tí ń ṣàlàyé ìnira ńlá tí àgbà òṣèré náà ń là kọjá àti ìdí tó ṣe nílò òògùn lóòrè-kóòòrè láti mú kí ara rẹ̀ le. +"wo ọkùnrin tó ní ìpèníjà ara, tó tún ń jà fún ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn","blind human right activist: temitope oyejobi ní ọ̀sán ayé òun ni ìyọnu ojú náà bẹ̀rẹ̀ adura ti ọpọ eeyan ma n se ni pe ki oluwa ma gba ode ọsan lọwọ wa amọ to ba ti sẹlẹ, irẹwẹsi lo maa n ko ba ọpọ eeyan. amọ eyi ko ri bẹẹ fun ọkunrin kan to ni ipenija oju amọ to n fi ailera naa ja fun ẹtọ ọmọniyan. temitope olujinmi oyejobi to ni ipenija oju naa, ba bbc yoruba sọrọ lori idi to se n ja fun ẹtọ ọmọniyan. bakan naa ni diẹ lara awọn eeyan ti oyejobi ti ja fun ba bbc sọrọ lori ọna ti ẹni to ni ipenija oju naa n gba ran ilu lọwọ. koda, agbẹnusọ fun ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ ogun, abimbola oyeyemi gan gbe ọrọ awọn eeyan yii lẹsẹ. o si salaye fun bbc nipa bii ọkunrin to ni ipenija oju naa se maa n paara agọ ọlọpaa lati gbeja awọn araalu. nigba to n salaye bi ipenija oju rẹ se bẹrẹ, oyejọbi ni kii se pe bi wn se bi oun pẹlu ipenija oju ree amọ ọsan gangan aye oun ni isẹlẹ naa waye. o ni ọdun 2012 lo bẹrẹ, ti oun si ti gbe iyawo, ti oun si wa mọto lọ silu eko lati lọ ra ọja amọ ti oun ko le wa mọto naa pada wa sile mọ nitori pe oun ko riran. oyejobi ni dokita salaye fun oun pe aisan oju glaucoma lo n yọ oun lẹnu lati bii ọdun mẹrin, ti oun ko si fura. o ni aisan anaa lo fọ oju oun naa patapata. nigba to n salaye ohun to sun de idi sise ijijagbara fawọn araalu, oyejobi ni iku baba oun lo faa ti oun fi gbe igbesẹ naa. “baba mi ku ninu ijamba mọto lọna sagamu si ijebu ode, tawọn ọlọpaa si mu ọkunrin kan pe oun lo wa mọto naa. ọkunrin naa si n pariwo pe oun ko mọ ohunkohun nipa isẹlẹ naa nitori pe mọto ti oun fi n sisẹ ti bajẹ, ti oun ko si wa ọkọ lọjọ ti ijamba naa waye. wọn fi ọkunrin naa si ahamọ ọgba ẹwọn laarin ọdun 2009 si 2013, ki oun to lọ gba silẹ, pe ki wọn fi silẹ, ko maa lọ. oyejobi ni lati akoko yii ni oun ti n ja fun ẹtọ awọn eeyan ti iya ba n jẹ. o yẹ ka gbe oriyin fun akanda ẹda to n ran ẹlomiran lọwọ - agbẹnusọ ọlọpa l‘ogun ọpọ awọn eeyan to ba bbc yoruba sọrọ nipa oniruuru iranwọ ti oyejobi ti se fun wọn lo kan saara si pe akọrin nii se. koda, wọn se alaye ọpọ iranwọ to ti se ati isẹ akin rẹ. fun iyalẹnu, koda, agbẹnusọ fun ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ ogun gan, abimbola oyeyemi kọrin rere ki akanda ẹda naa, ẹni to n gbe ija onija lai fi ti ipenija oju to ni se. oyeyemi salaye pe ileesẹ ọlpaa ogun mọ oyejobi bii isana ẹlẹẹta, to si maa n wa si ileesẹ ọlọpaa ni oore-koore lati wa gbeja ẹlomiran. “oyejobi maa n ba ọrọ araalu wa, tabi ko wa fi ẹjọ ọlọpa to ma huwa si araalu lọna ti ko yẹ wa, o si maa n gbọ alaye ta ba se. o yẹ ka le maa gbe iru eeyan bayii larugẹ nitori pe ko fi ailera to n se han, o maa n se ojuse rẹ laarin ilu ni. ọpọ eeyan to ni ipenija ara bii tiẹ ni wn maa n tọrọ agbe loju popo amọ oyejobi ko jẹ ki ipo to wa ko irẹwẹsi ba a.”",19 owewe 2022,"bbc yoruba ba ọkunrin kan to ni ipenija oju, temitope olujinmi oyejobi to tun n jija gbara afawọn araalu sọrọ ati idi to se gunle igbesẹ bẹẹ." +"fídíò, mo ti tá búrẹ́dì rí kí n tó padà lu àlùyọ àwàdà àti ọ̀rọ̀ ìṣítí- mr success adẹ́rinpoṣónú, duration 8,42",emi ti n ri ara mi bii pastor - mr success hassan abayomi adesanya ṣalaya ohun to bi orukọ mr success ti o n jẹ to fi rọpo orukọ ọti oosa to kọkọ n lo. bakan naa lo ṣorọ nipa irinajo aye rẹ ati ohun ti oju ri ko to de ibi to de lonii. kini mr success tun sọ? hassan adesanya menuba ibi ati idagbasoke rẹ lati agbegbe itoko nilu abeokuta nipinle ogun ni iwo oorun guusu naijiria ni eyi to bi ede egba to fi n se awada. o sọ nipa bo ṣe wu oun lati maa gba bọọlu ko to di pe ẹsẹ oun kan ki o to tun ero rẹ pa. mr success sọ iriri ati imisi to fi n se ọrọ iṣiti fun awọn eeyan rẹ. o menuba ipa ti awọn ọrọ imọran yii ti ko ninu awọn eeyan.,16 owewe 2022,"bbc wa aderinposonu to n sọrọ ìsítí fún àwọn eeyan kan, o sọrọ ilẹ kun." +"fídíò, mi kìí mu ìgbó, sìgá, ọ̀tí rárá, ọmọ jẹ́jẹ́ ní mi- ose ose ọmọ banke, duration 7,02","awọn agba tí a bá níwájú ló se ọbẹ̀ sílẹ̀ ti àwa òṣèré ìsinyi n gbé ka ina- soji taiwo gbajugbaja osere ni, soji taiwo ti ọpọ maa n pe ni o se, o se, omo banke gbalejo bbc yoruba lalejo. soji taiwo to saaba maa n ko ipa ọmọ ita ninu ere oniṣe ṣalaye fun bbc pe olorin ni baba oun, yomi taiwo to jẹ elere juju, eyi to fihan pe ile ni oun ti ba iṣẹ yii. o menuba ohun to bi orukọ rẹ ose , ose ọmọ bankẹ. bawo ni soji taiwo se bẹrẹ ere oniṣe? soji taiwo salaye ni kikun ere onise alhaji ajileye to gbe oun sita ati ipa ti oun ko nibẹ pẹlu iya gbonkan. o gba awọn ọdọ to fi maa ṣere oniṣe ni imoran lati gbe igbesẹ to yẹ o tun mẹnuba awọn ipenija ti o koju lẹni iṣẹ yii ki o to de ibi ti oun ti de. soji taiwo salaye kikun nipa irinajo rẹ lati ibẹrẹ di isinyi.",15 owewe 2022,gbajugbaja osere soji taiwo ṣalaye bi oruko ose ose ọmọ banke ṣe waye ati nipa irinajo re fun bbc. +agbébọn kan pa èèyàn 17 nílé ẹkọ́ alákọ̀bẹ̀rẹ̀ ní russia,"oríṣun àwòrán, reuters ko din ni eeyan mẹtadinlogun ti ọkunrin agbebọn kan pa nile ẹkọ kan ni orilẹ-ede russia lọjọ aje. iroyin sọ pe eeyan mẹrinlelogun lo tun fi ara pa, ti akẹkọọ mọkanla si wa lara awọn to ku nile ẹkọ naa to wa nilu izhevsk. awọn alaṣẹ sọ pe agbebọn naa pa ara rẹ sibi ikọlu naa, ti oun funra rẹ si jẹ akẹkọọ nibẹ nigba to wa lọmọde. awọn fidio to wa lori ayelujara sihan bi awọn eeyan ṣe n sa kijokijo ninu ile ti ikọlu ti waye, ati ni ayika ibẹ. fidio miran tun fihan bi ẹjẹ ṣe kun ilẹ yaara ikẹkọ kan, pẹlu bi awọn ọmọde ṣe sapamọ si abẹ tabili ikọwe wọn. ọmọde mọkanla ati agbalagba mẹrin ni agbebọn naa pa, lara awọ̀n ti oṣiṣẹ alaabo meji ati olukọ meji wa. ni bayii, wọn ti ko awọn akẹkọọ ati awọn olukọ wọn kuro nile ẹkọ naa. iroyin sọ pe agbebọn naa, ti wọn pe orukọ rẹ ni artem kazantsev ni wọn bi ni ọdun 1988, to si ṣe ikọlu naa pẹlu ibọn ilewọ ‘pistol’ meji. oríṣun àwòrán, shutterstock awọn ọmọ ilẹ okeere ti lanfaani bayii lati di ọmọ onilu lorilẹ-ede russia laarin ọdun kan pere. ọjọ satide ni aarẹ vladimir putin kede pe ọmọ ilẹ okeere yoowu to ba gba lati fọwọ si adehun iṣẹ ọdun kan pẹlu ileeṣẹ ologun orilẹede russia, lati kopa ninu ogun ni ukraine, le kọwe lati di ọmọ onilu. ṣaaju ikede yii, ẹni ti yoo ba ni anfani lati di ọmọ orilẹ-ede naa gbọdọ ti gbe nibẹ fun ọdun marun-un. bakan naa ni putin tun paṣẹ pe ẹwọn ọdun mẹwaa ni ki wọn o ju ọmọ ogun to ba kọ̀ lati ja ni ukraine, tabi gbiyanju lati sa kuro nibi iṣẹ ologun. ikede naa waye lẹyin ọjọ diẹ ti putin kede pe awọn yoo fa ẹgbẹrun lọna ọọdunrun ọkunrin wọ ileeṣẹ ologun lati ja ni ukraine. lati igba naa si ni iwọde ati ifẹhonu han ti n waye jakejado orilẹ-ede ọhun. o si ti to ẹgbẹrun kan eeyan ti awọn agbofinro ti mu lara awọn oluwọde. ẹwẹ, iroyin sọ pe ni kiakia si ni wọn pin fọọmu fun diẹ lara awọn ti wọn mu lọjọ satide, ti wọn si tun paṣẹ pe ki awọn oṣiṣẹ alaabo ko wọn lọ si ibudo ti wọn o ti pin wọn si oju ogun. ijọba ni igbesẹ fifi ipa mu awọn araalu lọ si oju ogun, ko tako ofin. oríṣun àwòrán, getty images awọn ofin tuntun yii mu ki ọpọ onwoye gbagbọ pe o ṣafihan pe awọn ọmọ ogun russia ti dinku pupọ. ṣugbọn ṣa, bi awọn kan ṣe n fi ẹhonu han, ni awọn ọdọ kan ti n sa kuro ni russia nitori ki wọn ma baa fa wọn wọ ogun jija, ti wọn si n salọ si awọn orilẹ-ede to mule ti wọn bii finland ati latvia. awọn alaṣẹ agbegbe ni russia sọ pe ko din ni ẹgbẹrun meji aabọ ọkọ to n gbiyanju lati jade nilu. ṣugbọn ṣawọn ni ‘ayederu iroyin’ ni pe awọn eeyan n fi ilu silẹ nitori ki wọn o ma baa darapọ mọ ileeṣẹ ologun. oṣu keji, ọdun 2022, ni russia bẹrẹ ogun pẹlu ukraine",25 owewe 2022,"ọkunrin agbebọn kan kọlu ile ẹkọ ni russia, o pa eeyan mẹtadinlogun" +wo àwọn òṣèré tó bá ìpèníjà kídìnrín fínra,"oríṣun àwòrán, screenshot àrùn tí kò gbọ́ oògùn kí ọlọ́run má fi ṣe wá ni àdúrà tí kìí wọ́n lẹ́nu àwọn ènìyàn. ní òde òní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ló ń kojú ìpèníjà ìlera kan tàbí òmíràn. lára àìsàn tó ń gba omijé lójú ọ̀pọ̀ ènìyàn tó sì ń ṣe àkóbá fún ẹ̀yà ara ni àìsàn kídìnrín jẹ́. àwọn onímọ̀ ìlera nínú ìwádìí wọn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn tó wà ní ìdùbúlẹ̀ àìsàn ní àwọn ilé ìwòsàn ńlá ní nàìjíríà ló jẹ́ wí pé àìsàn tó jẹ mọ́ kídìnrín ló ń yọ wọ́n lẹ́nu. lára àwọn ohun tí wọ́n ní ó máa ń fa àìsàn kídìnrín ni omi tí kò dára, èéfí, mímú egbògi olóró àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. wọ́n ní kò sí ẹni tí àìsàn yìí kò le bá jà, ìbáà ṣe ọmọdé tàbí àgbàlalgbà. bákan náà ni àìsàn ọ̀hún kò dá olówó mọ̀ yàtọ̀ sí tálákà, ọlọ́lá tàbí bọ̀rọ̀kìní. wọ́n ní àwọn mìíràn máa ń yè é tí wọ́n bá tètè mọ̀ tí àwọn mìíràn sì máa ń ba lọ tó bá ti pẹ́ lára ju bó ṣe yẹ lọ. ọ̀pọ̀ àwọn gbajúmọ̀ òṣèré yálà nídìí iṣẹ́ orin tàbí tíátà náà ló ti lùgbàdì àìsàn búburú yìí. lára àwọn gbajúmọ̀ tó ti ní àìsàn yìí nìyí: oríṣun àwòrán, dejo tunfulu/instagram ní ọjọ́ kìíní oṣù kẹrin ọdún 2022 ni ariwo ẹkún sọ ní agbo òṣèré tíátà yorùbá nígbà tí títán débá gbajúgbajà adẹ́rìnínpòṣónú tíátà adekunle adetokunbo tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ mọ̀ sí dejo tunfulu. bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn kò mọ̀ wí pé òṣèré náà ń kojú àìlera kó tó di pé ọlọ́jọ́ dé, wọ́n ní òṣère náà ti ń bá àìsàn kídìnrín fínra fún ìgbà díẹ̀ kó tó mú ẹ̀mí rẹ̀ lọ. ọ̀rẹ́ dejo tó bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ ní ó ti pẹ́ tí dejo ti ṣàlàyé ìpèníjà ìlera rẹ̀ fún òun ṣùgbọ́n òun kò mọ̀ bóyá ó sọ fún àwọn ẹbí àti ará rẹ̀. ó ní ọ̀pọ̀ ìgbà ló máa ń sọ fún òun tó bá fẹ́ lọ ra ògùn rẹ̀. ilé ìwòsàn ìjọba tí dejo kú sí náà ní agbègbè ikorodu nínú àtẹ̀jáde kan tí wọ́n dfi síta lẹ́yìn tí dejo dágbére fáyé ní ọ̀pọ̀ ẹ̀ya ara dejo ni kò ti ṣiṣẹ́ bó ti yẹ kí ọlọ́jọ́ tó dé àti pé “immunosuppression” ló ṣekúpa á. àtẹ̀jáde náà ni wọ́n fi fèsì sí ìròyìn pé àwọn fi ìlera dejo falẹ̀ lo ṣokùnfà ikú rẹ̀. oríṣun àwòrán, screenshot nínú oṣù kẹrin, ọdún 2017 ni gbajúgbajà òṣèré samuel adesanya tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ mọ̀ sí pásítọ̀ ajidara gba èkuru jẹ lọ́wọ́ ẹbọra. àìsàn kídìnrín ni wọ́n ní ó bá fínra títí ọlọ́jọ́ fi dé. ìyáwó rẹ̀, atinuke adesanya tó fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ ní ilé ìwòsàn kan ló kú sí ní ìlú abeokuta níbi tó ti ń gba ìtọ́jú. ó kú ọjọ́ méjì tí adesanya papòdà ní àwọn ẹbí ké gbàǹjarè pé àwọn nílò mílíọ̀nù méjìlá láti san gbogbo gbèsè tí wọ́n jẹ kalẹ̀ ní ilé ìwòsán tó ti ń gba ìtọ́jú. oríṣun àwòrán, eedris abdulkareem/instagram gbajúmọ̀ olórin tàkasúfèé ni eedris abdulkareem tó gbajúmọ̀ fún orin “nàìjíríà jàgàjágá” àti “mr lecturer.” ní nǹkan bí oṣù díẹ̀ sẹ́yìn ni eedris abdulkareem kéde pé òun ní àìsàn kídìnrín tí òun sì ti ń gba ìtọ́jú ní ilé ìwòsàn kan ní ìpínlẹ̀ eko. nínú oṣù kẹjọ ọdún 2022 ní abdulkareem tún fi àtẹ̀jáde kan léde tó ti ń dúpẹ́ lọ́wọ́ ìyàwó rẹ̀ fún bí ó ṣe fún òun ní ẹyọ̀kan nínú kídìnrín tirẹ̀ àti pé iṣẹ́ abẹ tí àwọn ṣe yọrí sáyọ̀. ní ọjọ́ kejìlélógún oṣù kẹsàn-án ló fi ìròyìn sójú òpó instagram rẹ̀ wí pé òun ti padà sílé tí òun sì wà ní àláfíà ara. oríṣun àwòrán, screenshot tí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa bí ẹ̀ka orin tàkasúfèé ní nàìjíríà ṣe ti gòkè àgbà lónìí láì dárúkọ babatunde okungbowa tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí ojb jezreel kò ì tíì pé. jezreel tó gbajúmọ̀ fún ṣíṣe ìlù sí àwọn orin ló ṣe olóòtú orin african queen tí 2face kọ, ìyàwó àsìkò, kiss me again àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. ọdún mẹ́rin ló fi bá àìsàn kídìnrín fínra kí ikú tó dá ẹ̀mí rẹ̀ légbodò ní ọdún 2016. bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìyàwó rẹ̀, mabel fun ní kídìnrín kan ṣùgbọ́n kò ru àìsàn náà là tó sì papòdà lẹ́yìn ọdún mẹ́ta tí wọ́n ṣiṣẹ́ abẹ náà.",24 owewe 2022,"lára àwọn ohun tí wọ́n ní ó máa ń fa àìsàn kídìnrín ni omi tí kò dára, èéfí, mímú egbògi olóró àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ." +efcc mú òṣìṣẹ́ ìjọba kwara tó fún ọmọ ijọ́ 23 ní ayédèrú iṣẹ́,"oríṣun àwòrán, efcc kele ti gbe arabinrin kan ti ajọ to n gbogun ti iwa jẹgudujẹra ni naijiria efcc sọ pe o n lu awọn eeyan ni jibiti nipa fifun awọn to n wa iṣẹ ni ayederu iwe igbanisiṣẹ. orukọ arabinrin naa gẹgẹ bi ajọ efcc ti ṣe gbe sita ninu atẹjade kan ni oyawoye r. olajumoke fafemi. wọn lawọn ti wọ lọ siwaju ile ẹjọ giga to wa ni ilorin lori ẹsun onigun mẹrin to da lori iwa jibiti nipa igbanisiṣẹ ati eto awọn alalaaji. o kere tan awọn eeyan mẹtalelogun lo ti pin iwe igbanisiṣẹ fun to si gba owo lọwọ wọn ni ipinlẹ kwara. gbogbo wọn si jẹ ọmọ ile ijọsin ti wọn lawọn n wa iṣẹ. efcc ṣalaye pe oṣiṣẹ ileeṣẹ ijọba to n risi ọrọ eto inawo ni ẹni ọdun mẹtalelaadọta naa jẹ. gẹgẹ bi alaye ti wọn ṣe, awọn ọmọ ile ijọsin christ apostolic church to wa ni offa lo fi na ẹburu gba owo lọwọ wọn lori irọ pe oun yoo ba wọn wa iṣẹ. o ni iṣẹ yi yoo jẹ iṣẹ pẹlu ijọba ipinlẹ kwara tabi ko si jẹ pẹlu ijọba apapọ. iwadii wa fihan pe fafemi fun awọn eeyan mẹtalelogun yi pata ni iwe igbanisiṣẹ. o kọ sinu rẹ pe ijọba ipinlẹ kwara ati ijọba apapọ ti fun n ni iṣẹ koda o fi iye owo oṣu ati ipo ti wọn gba wọn si, sinu lẹta wọn efcc ko ṣalaye dedee iye owo to gba ati boya awọn ti gba owo naa pada lọwọ arabinrin naa.",28 owewe 2022,arabinrin ẹni ọdun 53 yi pin iwe igbanisiṣẹ fawọn ọmọ ile ijọsin koda o kọ iye owo ti wọn yoo gba lowo oṣu sibẹ. +ààrẹ buhari kan sáárá sí ọọni ife lórí ipa rẹ̀ sí ìṣọ̀kan nàìjíríà,"ṣaaju ni a ti mu iroyin wa fun yin in pe ọọni fẹ bẹrẹ igbele ọlọjọ meje ni eyi to n bẹrẹ ayẹyẹ ọdun ọlọ́jọ́ níbi ti yóò ti bẹ àwọn alálẹ̀ lọ́wẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ nàìjíríà. ní báyìí ayẹyẹ ọdún ọlọ́jọ́ ti kásẹ̀ nílẹ́ tí ọọni sì ti jáde padà lẹ́yìn ìgbélé ọjọ́ méje. ẹ̀wẹ̀, ààrẹ muhammadu buhari ti kan sáárá sí ọọni ile ife, ọọni enitan ogunwusi ojaja keji fún ipa ribiribi tó ń kó sí ríri dájú pé àláfíà ń jọba ní agbègbè rẹ̀. ààrẹ buhari, ẹni tí mínísítà fọ́rọ̀ abẹ́lé, rauf aregbesola ṣojú fún níbi ayẹyẹ ọdún ọlọ́jọ́ ti 2022 ní ètò ààbò ní nàìjíríà ti kọjá ohun tí ẹnìkan tàbí ìjọba le dá ṣe. ó ní níbi tí nàìjíríà dé dúró báyìí, gbogbo ènìyàn gbọ́dọ̀ máa wà ní ojú lalákàn fi ń ṣọrí kí wọ́n yé dá gbogbo rẹ̀ dá àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò nìkan. “ìjọba máa gbìyànjú láti ṣe ipá tirẹ̀ láti dá ààbò bo àwọn ará ìlú, bẹ́ẹ̀ náà ló yẹ kí àwọn ènìyàn máa ran àwọn òṣìṣẹ́ ààbò lọ́wọ́ kí iṣẹ́ wọn le jẹ́ àṣeyọrí.” “gbogbo àwọn ìwà kò tọ́ àti ìrìn tí kò bá mọ́ ti ẹ́ ba kẹ́fin ní àdágbò yin ló yẹ kí ẹ máa fi tó ìjọba léti.” ààrẹ ní òun gbóríyàn fún ọọni fún ipa takuntakun tí ọọni láti wá ojútùú sí ìpéníjà ààbò tó ń bá nàìjíríà fínra lásìkò yìí. nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa ọdún ọlọ́jọ́, ààrẹ ní láyé àtijọ́ ọdún ọlọ́jọ́ àti àwọn ayẹyẹ mìíràn nílẹ̀ yorùbá jẹ́ àsìkò tí wọ́n máa ń fi èrè oko wọn han aráyé. ó ní yàtọ̀ sí wẹ̀jẹmẹ̀mu tó máa ń wáyé láwọn àsìkò náà, iṣẹ́ àgbẹ̀ tó jẹ́ iṣẹ́ kan gbòógì tí yorùbá kò fọwọ́ yẹpẹrẹ mú máa ń jẹ́ lájọrí ohun tí àwọn ayẹyẹ náà máa ń dálé lórí. ó fi kun pé yóò jẹ́ ìdùnnú àti ohun ìwúrí fún òun tí àwọn ènìyàn bá le padà sóko bí ti ayé àtijọ́ tí ọdún ọlọ́jọ́ yóò sì máa jẹ́ ayẹyẹ tí àwọn àgbẹ̀ ti ń ṣàfihàn èrè oko wọn. nígbà tó ń sọ̀rọ̀, ọọni ogunwusi kọminú lórí àwọn ìpèníjà tó ń bá nàìjíríà fínra pàápàá lórí ọrọ̀ ajé àti ètò ààbò. ọọni ní ohun ìbànújẹ́ ló máa ń jẹ́ fun òun nígbà tí òun bá ń kà ìròyìn nípa bí ètò ààbò ṣe ti fẹ́ pín nàìjíríà sí yẹ́lẹyẹ̀lẹ. ó ní gbogbo ọ̀rọ̀ ẹnì kọ̀ọ̀kan ní orílẹ̀ èdè nàìjíríà kò kọjá bí nàìjíríà yóò ṣe pín lọ. ó wá sọ àrídájú rẹ̀ pé òun kò ní yẹ̀bá nídìí ríri dájú pé ìṣọ̀kan nàìjíríà dúró ṣinṣin nípasẹ̀ lílo àṣà àti ìnàjú láti fi gbogbo ẹ̀yà mọ́ra. ọọni tẹ̀síwájú pé ọdún ọlọ́jọ́ jẹ́ ọ̀nà kan tí òun ní èròńgbà láti fi mú ìṣọ̀kan dúró láàárín gbogbo ènìyàn. ó fi kun pé gbogbo agbára òun ni òun yóò sà láti ri pé ìpìlẹ̀ rere tí àwọn ara ìgbà nnì fi lélẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àrólé oduduwa, kò parẹ́ rárá. oríṣun àwòrán, facebook ooni tilu ile ife, ọba adeyeye enitan ogunwusi ti kuro ni aafin rẹ lati lọ da nikan wa, ko le bawọn alalẹ sọrọ, bi ọdun ọlọ́jọ́ ṣe n sunmọ tosi. igbele adura naa ti ooni yoo se fun ọjọ meje, lo jẹ ara igbesẹ to maa n waye saaju ọdun ọlọjọ́ naa, eyi to maa n waye ni ọdọọdun. nígbà tó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ lasiko tó ń kúrò ní ààfin ile-oodua, ooni ní bí òpin yóò ṣe dé bá ìyanṣẹ́lódì tí asuu gùnlé, wà lára àdúrà tí òun yóò máa bá olódùmarè sọ. ọọni ní bí àgbọ́yé yóò ṣe wà láàárín ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì, asuu àti ìjọba àpapọ̀ wà lára ohun tí òun yóò máa bẹ àwọn alálẹ̀ lọ́wẹ̀, sí bí òun ṣe ń bẹ̀rẹ̀ ìgbélé ṣaájú ọdún ọlọ́jọ́. ooni ní òun máa fi àkókò ìgbélé náà bá ọlọ́run sọ̀rọ̀ lórí gbogbo ìpèníjà tó ń bá orílẹ̀ èdè nàìjíríà pàápàá bí ètò ìdìbò gbogbogboò ṣe ń kan ilẹ̀kùn gbọ̀ngbọ̀n. ó ṣàlàyé pé ìjọba àpapọ̀, ní kíákíá gbọ́dọ̀ wá ọ̀nà láti fòpin sí ìyanṣẹ́lódì tó ń lọ náà bí wọn kò bá fẹ́ rí ìbínú àwọn ọ̀dọ́ nàìjíríà. ó ní àwọn ọ̀dọ́ ti ń bínú gidi lọ́wọ́ yìí tí ènìyàn kò sì le rí wọn báwí nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ oṣù ni wọ́n ti fi wà nílé láì ṣe ohunkóhun. ""asuu àti ìjọba àpapọ̀ láti fẹnukò kí wọ́n fòpin sí ìyanṣẹ́lódì nítorí kò sí ẹni tó máa rí àwọn ọ̀dọ́ mú tí wọ́n bá bínú tán. oríṣun àwòrán, facebook ọọni fi kun pé ìbínú àwọn ọ̀dọ́ ti ń fojú hàn nípa bí wọ́n ṣe ti bẹ̀rẹ̀ sí ní dí ọ̀nà mọ́ àwọn ọlọ́kọ̀ ní àwọn òpópónà àti pápá kọ̀ òfurufú. ó ní èyí túmọ̀ sí pé wọ́n ti sún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ohun kan ògiri ló fa ìgbésẹ̀ wọn yìí. ó ní lásìkò ìgbanisíṣẹ́ ojajamore tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe ìfilọ́lẹ̀ rẹ̀, ọọni ní àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí kò tíì parí ẹ̀kọ́ wọn ni àwọn tó forúkọ sílẹ̀ jùlọ. ọba alayé ọ̀hún ní ohun tó túmọ̀ sí ni pé ilé ti sú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí ilé-ẹ̀kọ́ wọn ń yanṣẹ́lódì lọ́wọ́. ó ní ìyanṣẹ́lódì asuu ti ṣàkóbá lọ́pọ̀lọpọ̀ tí ìjọba sì gbọdọ̀ tètè mójúto ní kíákíá. àrólé oòduà ní ètò ìdìbò ọdún tó ń bọ̀ tún jẹ́ ohun tí òun yóò máa gbàdúrà lé lórí kó le lọ ní ìrọ́wọ́rọsẹ̀ kí àláfíà le jọba ní orílẹ̀ èdè yìí. ó fi ìdánilójú hàn wí pé gbogbo àdúrà tí òun bá ṣe náà ni yóò gbà nítorí kò sí ìgbà tí òun képe ọlọ́run lásìkò ìgbélé náà tí àdúrà òun kìí gbá. ní ọdọọdún ni ọdún ọlọ́jọ́ máa ń wáyé ní ìlú ile ife láti ṣàmì ayẹyẹ ọjọ́ tí ọlọ́run dá ilé ayé. lára àwọn ohun tí yóò wáyé níbi ayẹyẹ ti ọdún yìí ni ilagun, ojo owode, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.",20 owewe 2022,ààrẹ ní òun gbóríyàn fún ọọni fún ipa takuntakun tí ọọni láti wá ojútùú sí ìpéníjà ààbò tó ń bá nàìjíríà fínra lásìkò yìí. +"asuu gbà ilé-ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn lọ, ìjọba fọnmú pé kó kọ́kọ́ padà sẹ́nu iṣẹ́ ná","oríṣun àwòrán, @fkeyamo fakinfa laarin ijọba apapọ naijiria ati ẹgbẹ oṣiṣẹ fasiti naijiria ti gba ọna miran yọ bayii. eyi ko si ṣẹyin bi ẹgbẹ naa ṣe wọ ijọba lọ si ile ẹjọ kotẹmilọrun ni itako idajọ to ni ki wọn wọle pada sẹnu iṣẹ. wọn ni idajọ ti ile ẹjọ to n risi ọrọ laarin oṣiṣẹ ati agbanisiṣẹ gbe kalẹ ni abuja ko ba awọn lara mu. bẹẹ naa ni ẹgbẹ oṣiṣẹ fidi rẹ mulẹ pe adajọ to gbe idajọ yi kalẹ kuna nipa idajọ to gbe kalẹ nitori ko agbẹjọro agba to n ṣẹjọ lorukọ asuu femi falana ni awọn rawọ ẹbẹ si ile ẹjọ kotẹmilọrun to wa ni abuja lati yi idajọ ti o wa nilẹ pada.. idajọ taa n wi yi leleyi ti ile ẹjọ to n risi ọrọ laarin oṣiṣẹ ati agbanisiṣẹ gbe kalẹ pe ki awọn olukọ pada siṣẹ ki wọn si maa kọ awọn akẹkọọ. adajọ polycarp hamman lo gbe idajọ yi kalẹ lọjọru to kọja to si ni ki wọn dawọ iyanṣẹlodi duro titi di igba ti ile ẹjọ yoo fi gbọ ẹjọ mii lori ọrọ yi. o ti le ni oṣu meje bayii ti asuu ti faake kọri pẹlu iyanṣlodi ti ijọba apapọ si wọ wọn lọ ile ẹjọ nigba ti idunadura fori ṣanpọn. ki ni esi ijọba si ọrọ yi lati rin jina jina ni esi ijọba apapọ to n waye lori ọrọ bi asuu ṣe gba ile ẹjọ kotẹmilọrun lọ. minisita fọrọ oṣiṣẹ chris ngige lo si n dawọn lohun lori ọrọ yii pẹlu amọran pe ki wọn bọwọ fun idajọ ile ẹjọ, ki wọn si pada sẹnu iṣẹ. o fesi yi lasiko to n dahun ibeere lọwọ awọn akọroyin ni ilu new york l amẹrika nibi ti ipade apero ajọ isọkan agbaye ti n waye. oríṣun àwòrán, @senchrisngige o ni emi kii ṣe asuu ṣugbọn agbọye ofin ni pe ti idajọ ile ẹjọ kan ba wa nilẹ, ohun to tọ ni pe ki eeyan tẹle idajọ yi ṣaaju ko to lọ si ile ẹjọ kotẹmilọrun tori naa ohun taa lero pe o yẹ ki wọn ṣe ni ki wọn kọkọ pada si kilaasi nigige fi kun pe pipada si kilaasi ko tunmọ si pe awọn ko ni tẹsiwaju idunadura. o ni gbogbo ọna lawọn yoo maa fi ṣe idunadura ọhun. ẹgbẹ oṣiṣẹ fasiti ni naijiria lawọn n ja ki ijọba ṣe imuṣẹ adehun kan ti wọn buwọlu pẹlu ẹgbẹ olukọ fasiti ni ọdun 2009 ati awọn nkan miran. ọkan lara igbegidina ti ko jẹ ki ọrọ ni iyanju ni fifẹnu ko lori ọna ti wọn yoo fi san owo olukọ. ijọba sọ pe ippis lawọn yoo lo amọ ẹgbẹ olukọ ni awọn fẹ ki wọn lo oju ọna mii eleyi tawọn gbe kalẹ ti orukọ rẹ n jẹ university transparency accountability solution (utas). die ree ninu awọn ohun ti ẹgbẹ olukọ lawọn n ja fun ti eleyi to ku si wa ninu iwe adehun ti wọn lawọn fẹ ki ijọba gbera n lẹ ki wọn ṣe amuṣẹ rẹ.",24 owewe 2022,igbeṣẹ asuu lati pe ẹjọ́ kotẹmilọrun lo n waye lẹyin ti ile ẹjọ to n gbọ aawọ nipa ọrọ oṣiṣẹ ati agbaniṣiṣẹ sọ pe ki wọn pada sẹnu iṣẹ. +"nàíjíríà méjì ló wà, kí yorùbá gba òmìnira lọ̀nà àbáyọ - akintoye","adari ẹgbẹ ilana omo oodua, ọjọgbọn banji akintoye ti sọ pe ki naijiria pin nikan ni ọna abayọ si rukerudo to n waye kaakiri, paapaa lori eto abo to mẹhẹ. ọrọ yii lo jade lẹyin ọjọ kan ti gomina ipinlẹ ondo, oluwarotimi akeredolu kede pe ijọba oun yoo ra ibọn fun ikọ amotekun fun aabo awọn araalu. atẹjade kan ti akintoye fi ṣọwọ si bbc yoruba lati ọwọ agbẹnusọ ẹgbẹ ilana omo oodua, maxwell adeleye lo sisọ loju eleyi. ak intoyeni ko si irọ kankan ninu gbogbo ohun ti akeredolu sọ nipa ojuṣaju to n waye ni naijiria. o ni otitọ ni akeredolu sọ pe naijiria meji lo wa, apa kan fun awọn alẹnulọrọ, ati ida keji rẹ fun awọn ti wọn n tẹ ẹtọ wọn loju mọlẹ. akintoye sọ pe awọn ẹya kan ko ni imọ nipa bo ṣe yẹ ki wọn maa dari naijiria lo n jẹ ki oniruru laasigbo maa waye, asiko si ti to lati yago fun wọn. ọjọgbọn naa ṣalaye pe ọna abayọ kan ṣoṣo si rogbodiyan to n waye ni naijiiria, paapaa oniruru ifẹmiṣofo, ni ki naijiria pin. o ni “o yẹ ki gbogbo wa joko ki a si jiroro lori bi ọjọ ọla wa yoo ṣe ri gẹgẹ orilẹ-ede.” “o si yẹ ki a fẹnuko pe a fẹ pinya, ki a si jiroro lori bi a o ṣe wa ni alaafia pẹlu ara wa lẹyin ti a ba pin tan lai si ogun tabi ọtẹ.” “ko si angẹli kankan lati ọrun to le mu iṣọkan wa ni naijiria mọ bayii.” “awọn ọmọ iya wa ti wọn fẹ dije du ipo oṣelu, ọrọ wọn ye mi, nitori inu naijiria naa ni a ṣi wa amọ ọna odi ni wọn n gbe ọrọ naa gba.” “ohun to yẹ ki wọn ṣe ni ki wọn ba awọn eeyan wọn sọrọ lori bi a ṣe maa gba ominiri wa, ki a si ni orilẹ-ede eyii ti kii ṣe ara naijiria.” ohun ti akeredolu sọ saaju ree nipa amulo ilana ofin meji tijọba apapọ n se: oríṣun àwòrán, @thesignalng ijọba ipinlẹ ondo ti sọ pe oun ti ṣetan lati ra ohun ija oloro, paapaa ibọn ak-47 fun aabo awọn eeyan oun. gomina rotimi akeredolu lo sọ ọrọ naa ninu atẹjade kan to fi lede loju opo twitter ati facebook rẹ. aketi sọ pe ko ṣeeṣe ki orilẹ-ede jẹ ọkan ṣoṣo, ko si maa fi ofin ọtọtọ ba awọn eeyan rẹ lo. ọrọ yii lo n jade lẹyin ti ijọba apapọ kọ lati gba ikọ alabo amotekun laaye lati maa lo ohun ija oloro. akeredolu sọ pe oun ti ri fidio kan nibi ti ijọba apapọ ti fun ikọ alaabo ipinlẹ katsina laṣẹ, lati maa lo ibọn ak-47. amọ o ni o kọ jalẹ pe ki ikọ amotekun naa ma lo ibọn. o ni “pe ikọ alaabo ipinlẹ katsina le maa lo ibọn ak-47, ti ikọ alaabo amotekun ko si le ṣe bẹẹ, tumọ si pe ofin ọtọtọ ni a n lo lorilẹ-ede yii.” akeredolu sọ pe igbesẹ naa n tumọ si pe ijọba apapọ n ṣe ojuṣaju laarin awọn ipinlẹ to jọba le lori. aketi ni “a fẹ ki gbogbo araalu mọ pe, ko si bi ọbọ ṣe ṣ’ori ti inaki naa ko ṣe o.” “ijọba ipinlẹ ondo ti ṣetan bayii, gẹgẹ bii ojuṣe rẹ labẹ ofin, lati ra ibọn fun abo awọn eeyan rẹ.” “igbesẹ yii ṣe pataki, paapaa lasiko yii ti awọn agbesumọmi n ra ibọn bo ṣe wu wọn.” o pari ọrọ rẹ pe “ijọba ipinlẹ yii ko ni la oju rẹ silẹ ki awọn agbesumọmi maa pa awọn eeyan wa ni ipakuta lai wa nnkan ṣe si.” “a o daabo bo awọn eeyan wa.” oríṣun àwòrán, rotimi akeredolu",22 owewe 2022,banji akintoye kín akeredolu lẹ́yìn lórí àmúlò oríṣìí ìlànà méjì tíjọba àpapọ̀ ń lò láàrin àwọn ìpínlẹ̀. +amotekun àtàwọn ẹsọ àláàbò míì kò ní kópa nínú ìpolongo ìbò - ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá,"ọga fun ileeṣẹ ọlọpaa ni naijiria, usman alkali baba ti pasẹ pe ki wọn fi ofin de lilo ikọ ẹsọ alaabo amọtekun, esn ati awọn ẹsọ alaabo miiran to jẹ ti ipinlẹ fun iponlogo ti yoo bẹrẹ lọsẹ to n bọ. baba sọ eleyi nibi ipade kan to ṣe pẹlu awọm adari ileeṣẹ ọlọpaa niluu abuja. o salaye pe ipinu lati fi ofin de awọn ẹsọ alaabo naa lo wa lati ri pe eto idibo lọdun 2023 lọ ni alaafia kaakiri naijiria. o wa pasẹ fun awọn kọmisana ọlọpaa lati tẹlẹ ofin naa, ki wọn si ri pe awọn iponlogo ibo awọn ẹgbẹ oṣelu tẹle ilana ti ileeṣẹ ọlọpaa gbe kalẹ. o ni ki awọn kọmisana naa ṣe isẹ wọn bo ṣe yẹ pẹlu ofin ilana ileeṣẹ ọlọpaa tọdun 2022. bakan naa lo ni ki wọn ri pe eto iponlogo naa ko fa rogbodiyan kaakiri oriléede naijiria. “a fi da awọn ọmọ loju pe sisọ ẹmio ati dujia wọn lo jẹ wa logun pupọ. “eto idibo lọdun 2023 ni yoo jẹ bi idanwo fun wa sugbọn o da mi loju pe ileeṣẹ ọlọpaa orilẹede naijiria koju osuwọn lati ri pe eto idibo naa lọ ni irọwọrọsẹ. “a fi ọkan yin balẹ nitori ileeṣẹ ọlọpaa ni ifẹ awọn ọmọ orilẹede naijiria lọkan. “nipa bi a ṣe fẹ mu awọn nkan yi wa si imusẹ ni a fifi ofin de lilo awọn ẹsọ amọtẹkun ati awọn ẹsọ alaabo yooku nitori ofin ko gba wọn laye lati kopa ninu ẹto idibo. oríṣun àwòrán, ogun police ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ ogun ni awọn ti fi panpẹ ọlọpaa mu ọkunrin marun fun ẹsun ole jija ni ipinlẹ ogun. ileeṣẹ ọlọpaa darukọ awọn afurasi adigunjale naa gẹgẹ bi umar haruna, abbah yahaya, muritala umar, wale fadeyi ati segun olofinmade. ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ ogun ni ọwọ tẹ awọn afurasi naa nigba ti awọn gba ipe pajawiri ni agọ ọlọpaa sango ni oru ganjọ. ipe pajawiri naa lo ki awọn ọ̀lopaa naa gbera lọ si ileeṣẹ naa ti wọn ti n ta awọn engini ọkọ. wọn ni awọn adigunjale naa le ni eeyan mẹwaa pẹlu ọkọ mitsubishi tì wọn gbe naa. kete ti wọn ri awọn ọlọpaa naa ni wọn salọ amọ ti wọn ri marun un gbamu ninu wọn. lara awọn ti wọn ri mu naa ni wọn sọ pe adari eto aabo ni ileeṣẹ naa tẹlẹ lo ran wa wa. adari ẹka aabo naa ni wọn yọ ni iṣẹ ni nkan bi oṣu mẹta ṣẹyin. bakan naa ni ileeṣẹ ọlọ̀paa ni iwadii ti bẹrẹ ni kikun lori iṣẹlẹ naa, ti wọn si ti bẹrẹ si ni wa adari eleto aabo naa.",22 owewe 2022,ọga agba ọlọpaa ni naijiria ti pasẹ fawọn kọmisana ọlọpaa lawọn ipinlẹ pe ki wọn ri pe iponlogo ibo tẹle ilana ti ileeṣẹ ọlọpaa gbe kalẹ. +‘’ohun tí tinubu fẹ́ fúnmi nìyíí ká ní mo darapọ̀ mọ́ apc...’’,"oríṣun àwòrán, others gomina ipinlẹ rivers, nyesom wike ti ni oludije sipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu apc, asiwaju bola tinubu fi ipo ṣenatọ lọ oun nigba ti wọn pade ni london laipẹ yii. lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ lori aigbọraẹniye lẹgbẹ oṣelu pdp lọ sọ bẹẹ. gẹgẹ bi ọrọ rẹ, tinubu fi tikẹẹti ile aṣofin agba lọ oun, amọ o ni idi ti oun fi dije du ipo aarẹ ni wipe oun fẹ ipo naa, kii ṣe sẹnetọ tabi igbakeji rẹ. ‘’mi o kii ṣe awọn ẹlomiran to ra tikẹẹti ṣẹnatọ pẹlu ipo aarẹ.’’ ‘’nitori naa ni mo ṣe kọ jalẹ fun tinubu nigba to fi ipo ṣẹnetọ lọ mi ti mo ni mi o fẹ.’’ oríṣun àwòrán, others gomina ipinlẹ rivers nyesom wike ti ni oun ko ko ọrọ oun jẹ lori ki alaga ẹgbẹ, iyorchia ayu kọ iwe fi ipo silẹ. o ni bakan naa ni ko si ẹnikẹni ninu ẹgbẹ naa to le e yọ oun ni ipo. ‘’bio tilẹ jẹpe ko si ẹni to gaju ẹgbẹ lọ, ẹ yọ mi ni ipo ki ẹ wa mọ bi mo ṣe jẹ.’’ ‘’ko si bi pdp ṣe le di ipo aarẹ mu ni naijiria lai jẹ pẹ wọn fi ti ipinlẹ river ṣe.’’ ‘’bakan naa ni ko lee si ipo aarẹ lai si ipinlẹ eko, kano ati rivers nibẹ, ko lee ṣeeṣe.’’ eyi n wayẹ lẹyin ti wike ati awọn iṣọgbe rẹ yọ ara wọn kuro ninu ikọ ipolongo fun atiku ni ọdun 2023. wike ni ẹgbẹ oṣelu pdp ko ṣe to nipa yiyi ẹni ti yoo dije du ipo lọ si ẹkun to kan. o bu ẹnu atẹ lu bo ṣe jẹ ariwa orilẹede naijiria nikan ni oludije ti n wa lati ọdunbọdun ṣẹyin. o ni wọn ro wi pe nitori ẹya ariwa pọ, ohun gbogbo gbọdọ lọ si agbegbe wọn, eleyii ti wike ni ko boju mu rara. ‘’nitori naa ẹgbẹ oṣelu pdp gbọdọ gbọ ohun ti a n sọ, ti alaga ẹgbẹ ba fẹran ẹgbẹ, ki o fi ipo silẹ.’’ ‘’adehun ni pe ti aarẹ ba ti wa lati ariwa naijiria, alaga ẹgbẹ yoo fi ipo silẹ fun guusu lati dari ẹgbẹ oṣelu pdp.’’ oríṣun àwòrán, others ẹgbẹ oṣelu pdp ni ipinlẹ oyo ti bu ẹnu atẹ lu ẹgbẹ oṣelu pdp ni ipinlẹ ondo, ogun ati ekiti lori ọrọ ti wọn sọ lati tabuku gomina ipinlẹ oyo makinde. laipẹ ni makinde fi iroyin lede pe ki alaga ẹgbẹ oṣelu pdp kọ iwe fi ipo silẹ fun ẹni ti yoo wa lati guusu di ipo naa mu. amọ ẹgbẹ oṣelu pdp fi iroyin lede pe ẹka ẹgbẹ ni ipinlẹ ondo, ekiti ati ogun ti ṣatilẹyin fun ayu lati di ipo rẹ mu. ẹka ẹgbẹ naa ni oyo ni eyi ko bojumu rara nitori makinde ni aṣẹ ju gbogbo awọn to ku lọ nitori oun nikan ni gomina ni ilẹ yoruba lati ẹgbẹ oṣelu pdp. nitori naa wọn ke si wọn ki wọn ti ọwọ ọmọ wọn bọ aṣọ, ki ayu si kọ iwe fi ipo silẹ ni kiakia, ki ẹgbẹ oṣelu pdp le tooro.",23 owewe 2022,lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ lori aigbọraẹniye lẹgbẹ oṣelu pdp lọ sọ bẹẹ. +"""màá kán apá àti ẹsẹ̀ mi, kí n le bọ́ lọ́wọ́ putin tó ń fi tipá mú wa lọ sójú ogun""","oríṣun àwòrán, getty images awọn ọmọ orilẹede russia ti bẹrẹ si ni sa kuro lorilẹede naa lẹyin ti ijọba kede afikun awọn ọmọ ogun lati lọ koju orilẹede ukraine. ogunlọgọ awọn eeyan russia si ti balẹ si awọn agbegbe igberiko lati igba ti aarẹ vladimir putin ti se ikede naa. koda, ijọba yoo ṣe idanilẹkọ fun awọn eeyan toto ẹgbẹrun lọna ọọdunrun lati lọ koju orilẹede ukraine. pupọ ninu awọn ọkunrin to wa ni ọjọ ori to le darapọ mọ awọn ologun, ni wọn ti bẹrẹ lati ma sa kuro ni agbegbe wọn, ki wn maa baa kopa ninu ogun naa. ọkunrin kan ti ko darukọ rẹ, sọ fun bbc pe kete bi aarẹ putin ti gbe ikede naa jade, ni oun ti mu iwe irinna oun. o ni ti oun ko si idi ẹru kankan dani nitori ọjọ ori oun wa lara awọn ti wọn le ran lọ si oju ogun. awọn osojumikoro to wa nibi isẹlẹ naa ni ọpọlọpọ ọkọ ayọkẹlẹ lo ti wọ awọn igberiko, ti sukẹrẹ fakẹrẹ si gba gbogbo ojo opopona. fọnran kan safihan bi awọn awakọ ṣe n fi ọkọ silẹ nitori bi ọna ṣe di pa. orilẹede georgia ni orilẹede kan to sunmọ ilẹ russian, ti awọn eeyan si ti sa lọ sibẹ lai nilo iwe irinna. finland naa wa lara awọn orilẹede ti ọpọ wọn salọ sugbọn wọn nilo iwe irinna lati wọ orilẹede naa. awọn agbegbe yoku to tun mule ti russia ni istanbul, belgrade tabi dubia. awọn ilu wọnyi ni wọn ti fi owo kun owo tikẹẹti wọn ni kete ti aarẹ putin ṣe ikede naa. minisita to wa feto irina lorilẹede germany, nancy faeser, ni orilẹede naa ti ṣetan lati tẹwọ gba awọn ọmọ russia to ba sa wa si ilu wọn. sugbọn orilẹede lithuania, latvia, estonia ati czech republic ni awọn ko ni fun awọn awọn ọmọ russia ni anfani lati wọ ilu awọn. ọkunrin kan ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn, to jẹ akẹkọọ ati olukọ ni wọn ti pe lati wa darapọ mọ ikọ ologun naa. ọkunrin naa ti ko darukọ rẹ fun ileeṣẹ bbc, sọ pe ni kete ti aarẹ putin pari ikede ni awọn meji kan sabẹwo si oun. o ni wọn si fun ni iwe kan lati tọwọ bọ gẹgẹ bi ọmọ ologun. o ni oun ro pe awọn to ba ni iriri nipa ogun ni wọn maa ransẹ si lati wa ja ogun ukraine sugbọn eyi ko ri bẹẹ. ikede naa lo ti fa ọpọlọpọ ifẹhonuhan ni olu ilu russia, moscow ati st peterburg, ti wọn si ti mu eeyan to ju ẹgbẹrun kan lọ si ahamọ. iroyin ni pupọ lara awọn to wa ni ahamọ ni awọn to ti tọwọ bọwe lati lọ soju ile russia. aarẹ orilẹede ukraine, volodymyr zelensky ti rọ awọn eeyan russia lati maṣe gba lati darapọ mọ ikọ ologun lati koju ukraine. o ni pupọ awọn eeyan ti ba ogun naa lọ. “ẹ fẹ si? rara? ẹ fẹhonuhan, ẹ salọ tabi ki ẹ farayin kalẹ fun awọn ologun russia.”",23 owewe 2022,"minisita to wa feto irina lorilẹede germany, nancy faeser, ni orilẹede naa ti ṣetan lati tẹwọ gba awọn ọmọ russia to ba sa wa si ilu wọn." +"""buhari, àwọn olùkọ́, ọ̀gá àgbà fásitì kò gbọdọ̀ gbowó oṣù mọ́ torí ìyanṣẹ́lódì asuu""","oríṣun àwòrán, house_ngr/instagram akẹkọọ fasiti kan, soohemba aker, ti sọ fun ile ẹjọ giga niluu abuja pe ko pa lasẹ lati da owo osu aarẹ ati awọn osisẹ agba miiran labẹ ijọba duro. akẹkọọ- binrin naa, to jẹ akẹkọọ imọ ofin ni fasiti ipinlẹ benue ni o ṣe koko pe ki ileẹjọ da owo oṣu awọn olori duro, lati ofisi aarẹ lọ si ile gbimọ asọfin. aker ni gbogbo awọn minisita, ọga agba fasiti, akọwe ijọba, asofin ati ẹgbẹ asuu ni ko lẹtọ si owo oṣu ti wọn n gba, akẹkọọ naa, ninu iwe ipẹjọ, fhc/abj/cs/1684/2022, ti agbẹjọro rẹ, ckukwuma machukwu ume gbe kalẹ ni iyẹnsẹlodi ti ẹgbẹ asuu gun le, n ṣe ọpọlọpọ akoba fun oun ati awọn akẹkọọ mii. o ni erongba oun ati awọn akẹgbẹ oun lati pari eto ẹkọ lọdun 2022 ni ko le wa si imusẹ mọ nitori iyansẹlodi ti asuu gunle. aker ni o ti han gbangba pe owo ti oun san fun saa tuntun ni ile ẹkọ oun ni ko wulo mọ, ti ẹgbẹ asuu ko ba le pada si ẹnu isẹ wọn. aker ni oun soju gbogbo akẹkọọ naijiria ti iyansẹlodi si ti ṣe ọpọlọpọ ijamba fun awọn kaakiri orilẹede naijiria. awọn olujẹjọ ti wọn fiwe pe ni ijọba apapọ, ẹgbẹ asuu, aarẹ ile igbimọ asofin, agbẹnugan ile gbimọ asofin kekere, awọn agbẹjọro agba ati minisita eto idajọ. ni afikun, awọn olujẹjọ yoku ni agbẹjọro agba fun ipinlẹ kọọkan, olootu fasiti ti ilẹ abuja, gomina abia, faac, rmafc ati umar faruk. ipẹjọ naa ni wọn ko ti ri adajọ ti yoo lewaju rẹ. oríṣun àwòrán, asuu ẹgbẹ awọn olukọ ni fasiti lorilẹede naijiria, asuu, ti ni idajọ ti ileẹjọ to n gbọ aawọ osisẹ ati agbanisisẹ gbe kalẹ, ko le tu irun kankan lara oun. lọjọru ni ileẹjọ naa ni pe ki wọn fi opin si iyansẹlodi ti wọn gun le lati ninu oṣu keji ọdun yii. amọ asuu ni idajọ naa ni ko tẹ awọn lọrun, ti awọn si ti setan lati wọ ijọba apapọ lọ ileẹjọ kotẹmilọrun. alaga ẹgbẹ naa niluu abuja, dokita kasim umar lo kede bẹẹ nigba to fesi si idajọ ti ile ẹjọ gbe kalẹ. umar ni awọn igbimọ alasẹ ẹgbẹ asuu yoo ṣe ipade loni lati mọ ọna ti wọn gbe gba pẹlu ileẹjọ ko tẹmilọrun. agbẹjọro ẹgbẹ naa, femi falana naa ti fidi rẹ mulẹ pe ẹgbẹ asuu ti gbaradi lati wọ ijọba apapọ rele ile ẹjọ kotẹmolọrun. falana ni ẹjọ naa lawọn yoo pe lati tako idajọ ti ileẹjọ to n gbọ aawọ osisẹ ati agbanisisẹ gbe kalẹ lana. bakan naa, olootu fasiti ti ilu abuja, ọjọgbọn ahmed modibbo muhammed ti gba ijọba apapọ ni imọran lati fi suuru ba awọn ẹgbẹ olukọ fasiti ṣe. modeiboo ni asẹ ileẹjọ ko le tan rogbodiyan to wa laarin ijọba apapọ ati ẹgbẹ olukọ fasiti naa. o wa rọ awọn igun mejeeji lati ṣe suuru, ki wọn si fi aye gba ibaraẹnisọrọ ni itubi-nubi lori ọna abayo si iyansẹlodi naa. o tẹsiwaju pe ibaraẹnisọrọ ni itubi-nubi nikan lo le tan gbogbo rogbodiyan naa. oríṣun àwòrán, screenshot ileẹjọ to n gbọ aawọ osisẹ ati agbanisisẹ ti palasẹ fun ẹgbẹ olukọ fasiti lọrilẹede naijiria, asuu pe ko fi opin si iyansẹlodi to gun le. nigba to n gbe idajọ kalẹ lori ẹjọ ti ijọba apapọ gbe wa si ile ẹjọ naa, adajọ polycrap hamman fi ofin de asuu lati mase tẹsiwaju pẹlu bo se n wosẹ niran. hamman ni titi ti igbẹjọ naa yoo fi wa sopin, asuu gbọdọ maa sisẹ lọ. adajọ hamman tun ni ki wọn da ẹjọ naa pada si ọdọ adajọ agba lati yan adajọ tuntun fun igbẹjọ naa. adajọ naa ni iyanṣelodi asuu ti ṣe ọpọlọpọ akoba fun awọn akẹkọọ lorilẹede naijiria. o ni oun gbe idajọ naa kalẹ nitori ihuwasi asuu ni ko jẹ ki ọpọlọpọ awọn akẹkọọ, ti ko lagbara lati lọ sile ẹkọ adani, mase ni anfaani lati kawe. agbẹjọro ijọba, james igwe ninu ọrọ rẹ rọ ileẹjọ lati pasẹ fun asuu pe ko bẹrẹ isẹ lẹsẹkẹsẹ, ki igbẹjọ naa to wa sopin. o ni ọrọ yii ti fa ọpọlọpọ ifasẹyin ba ilọsiwaju naijiria nitori bí awọn akẹkọọ ṣe wa nile latinu oṣu kejì. laipẹ yii ni ẹgbẹ awọn olukọ fasiti, asuu kede pe awọn ti ṣe adehun tuntun pẹlu awọn asofin apapọ naijiria. awọn ikọ adari ile igbimọ asofin apapọ lo lewaju ipade oni wakati mẹrin, to bi adehun tuntun naa, eyi to waye ni ile gbimọ asofin niluu abuja lọjọ isẹgun. adehun naa lo nilo ibuwọlu aarẹ muhammadu buhari, ẹni to rin irinajo lati kopa nibi ijokoo ajọ isọkan agbaye niluu new york. emmanuel osodeke lo lewaju fun ẹgbẹ awọn olukọ fasiti, ti minista fun eto ẹkọ, goodluck opiah si lewaju fun ijọba apapọ nibi ipade naa.",21 owewe 2022,soohemba aker ni erongba oun atawọn akẹgbẹ oun lati pari eto ẹkọ lọdun 2022 ni ko le wa si imusẹ mọ nitori iyansẹlodi asuu. +"wo irin, ọ̀kọ̀, ìbọn àti àdá tí ogedengbe agbogungboro fi ń jagun àti àga tó fi ń wo ọ̀tá","ogedemgbe agbogungboro: kó tó lọ sójú ogun, ojú rẹ̀ yóò pọ́n bíi ẹ̀jẹ̀ ti a ba n sọrọ itan ilẹ ijesa ati yoruba lapapọ, itan naa ko le pari lai sọ ipa ribiribi ti akọni ọkunrin kan, ogedengbe agbogungboro ko lati gba ilu naa ati ilẹ yoruba silẹ lọwọ ogun. + ni aye atijọ, ọkan lara awọn alagbara ti okiki wọn kan pupọ ni akọni ọkunrin naa, to si n ba awọn ologun olokiki bii basọrun oluyole nilẹ ibadan ta kangbọn. + ọdun 1910 si ni ogedengbe agbogungboro jade laye eyi to ti pe ọdún mejilelaadọfa (112) bayii. ni ipari osu keje ọdun 2022, ni awọn idile ogedengbe agbogungboro se iranti ọdun mejilelaadọfa naa ti akọni to sẹdasil wọn jade laye. + idi si ree ti bbc yoruba fi gba ilu ilesa lọ, lati wo bi ayẹyẹ iranti naa se waye, ka si wo awọn ohun manigbagbe ti ogedengbe agbogungboro se fun il ijesa ati yoruba lapapọ. nigba to n salaye bi wọn se bi ogedengbe agbogungboro fun bbc yoruba, oluọdẹ ilu owode-itori, oloye ojo elijah ni ifa ti kede saaju nigba ti iya ogedengbe loyun rẹ pe wọn ko gbọdọ bi ọwọ naa sile baba rẹ. o ni ile iya rẹ ni itori ni ki wọn bi ogedengbe agbogungboro si nitori pe akọni ọmọ ni. o si le ni ẹni ọdun mtadinlogun ki ogedengbe agbogungboro to maa bẹr si jagun nigba ti ogun bẹrẹ lagbegbe naa. agbara to ni yii si lo ni o fi gba ilẹ ijesha silẹ ati il yoruba lapapọ lọwọ ogun. oríṣun àwòrán, ogedemgbe agbogungboro children nigba to n ba bbc yoruba sọrọ, ọkan lara awọn arọmọdọmọ ogedengbe agbogungboro, ọmọọba tayo ogedengbe salaye igbe aye baba nla rẹ naa fun wa. ọmọọba ogedengbe ni owode itori gan ni ilu ogedengbe agbogungboro, itori ija ẹkẹ to maa n ja ni wọn se sọ ni ogedemgbe. orisarayibi gan ni orukọ ogedengbe agbogungboro amọ nitori pe o maa n gbe eeyan ni ogedengbe lati la onitọun mọlẹ lasiko ija ẹkẹ ni wọn fi sọ ni inagijẹ naa. o fikun pe ọdun mtadinlogun ni akọni naa ti n jija ẹkọ, to si maa n bori ọpọ akọni ọkunrin ninu ija naa eyi to mu ki okiki rẹ pọ kaakiri il ijesa nigba naa. oju rẹ yoo pn bii ẹjẹ, yoo si gbe kaun si ẹrẹkẹ kọọkan eyi to fi maa ro awọn oogun rẹ lagbara bii igba ti eeyan ba n saaji batiri. ọkan ijesa si bal pe awọn ni ogedengbe agbogungboro lati doju kọ ogun yowu ti wọn ba gbe ti awọn.” lasiko ayẹyẹ iranti naa ni awọn arọmọdọmọ ogedengbe agbogungboro se afihan awọn eroja ti akọni naa lo nigba to wa loke eepẹ. lara awọn eroja ijagun ogedengbe agbogungboro ta fi oju ri ni irin, ibọn, ọkọ, ada ati aga to fi maa n joko lati wo awọn ọta lati orere nigba ti ogun ba n bọ. “ibọn danku ti baba n lo ree, ko to di pe oyinbo ko ibọn ak47 de, bo si se n jagun niwaju, ni yoo tun maa jagun bọ ni ẹyin. ori aga yii naa si lo maa n joko si lati ri awọn ọta to n gbe ogun bọ lati ọkankan nitori ori oke ni ile rẹ wa. ogedengbe agbogungboro jagun ni ibadan, igbajọ, kii si se ilesa nikan lo ti jagun amọ idi ogun kiriji lo pari ogun jija si. awọn idile ogedengbe agbogungboro tun sọ fun bbc yoruba pe akọni naa lo maa n fi ọwọ ara rẹ se oogun abẹnu gọngọ to maa n lo lati jagun. wọn ni ko ni babalawo to maa n ba se oogun gẹgẹ bii awọn akọni miran. bakan naa lo ni awọn iyawo kankan kii ba ogedengbe agbogungboro gbe amọ wọn n gbe ni agboole rẹ to wa ni adugbo anaye nilu ilesa. sugbọn wọn ni inu oko mọlẹbi naa to wa ni itori ni baba naa n gbe. bakan naa ni wọn sọ fun bbc yoruba pe akọni ọkunrin yii tun ni nnkan se pẹlu adugbo ibeju-lekki. wọn ni ọkunrin naa sisẹ ribiribi nibẹ, ti wọn ko si le gbagbe rẹ titi di oni yii. ipari ogun kiriji ati iku ogedengbe agbogungboro lọdun 1910: nipari, a ri gbọ pe ogedengbe agbogungboro fi ogun jija si yin ogun kiriji. dun 1886 si ni ogedengbe agbogungboro fi ọwọ bọ iwe adehun pẹlu awọn oyinbo amunisin ati ilu ibadan pe ogun naa ti wa sopin. koda awọn ọmọ ogedengbe agbogungboro gan tun de ibudo ti wọn ti tọwọ bọ iwe adehun lati fi opin si ogun kiriji nilu imesi-ile eyi ti bbc yoruba naa ko gbẹyin nibẹ. awọn ọmọ ogedengbe agbogungboro wa seleri pe awọn yoo tun ile baba naa kọ si ti igbalode ko le jẹ ibudo tawọn arinrinajo afẹ yoo maa peju si.",6 owewe 2022,"bbc yorùbá wà níbi ìrántí ọdún kejìléláàdọ́fà tí ogedengbe agbogungboro kú, a rí ọ̀pọ̀ ohun èèlò akọni náà, táwọn ọmọ rẹ̀ sì ṣe àlàyé ìgbé ayé rẹ̀ fún wa." +baba ijesha lulẹ̀ nílé ẹjọ́ fún ìgbà kejì,"ile ẹjọ to n gbọ ẹsun ifipabanilopọ niluu eko ti kọ lati gba beeli oṣere tiata yoruba, james olanrewaju omiyinka, ti ọpọ mọ si baba ijesha, ṣaaju ki wọn to bẹrẹ igbẹjọ kotẹmilọrun rẹ. adajọ oluwatoyin taiwo da ipe fun beeli naa nu nitori baba ijesha ko ni awọn amuyẹ to tọ lati kunju oṣuwọn fun beeli naa. nigba to n dajọ lori beeli ọhun, adajọ sọ pe baba ijesha gbọdọ ṣe afihan awọn eredi pataki ti wọn fi gbọdọ fun ni beeli naa, eyii ti ko ṣe. o tun ni ko si ẹri pe ọdaran naa ti pe ẹjọ kotẹmilọrun tabi ẹri kankan pe ile ẹjọ yoo fi ẹjọ kotẹmilọrun rẹ falẹ. gẹgẹ bii iwe ti agbẹjọro rẹ kọ siwaju adajọ, oṣere naa n fẹ ki ile ẹjọ fun oun ni beeli ki oun ma lọ sile lọna ati le pe ẹjọ kotẹmilọrun tako idajọ ẹwọn ọdun marun run ti wọn da fun. ojọ kẹwaa, oṣu kẹjọ, ọdun 2022 yii ni agbẹjọro rẹ, gabriel olabiran, sọ fun ile ẹjọ pe awọn ti pe igbejọ fun beeli ọdaran naa, ṣaaju ipẹjọ kotẹmilọrun. to n tumọ si pe, baba ijesha n fẹ ki wọn fun oun ni beeli ki oun le kuro ninu ọgba ẹwọn lati maa gba ile lọ sile ẹjọ fun igbejọ kotẹmilọrun, kaka ko maa ti inu ọgba ẹwọn lọ sile ẹjọ ọhun fun igbẹjọ kotẹmilọrun naa. igbesẹ yii lo wa ni ibamu pẹlu abala kẹfa iwe ofin orilẹ-ede naijiria ti wọn kọ lọdun 1999, ati afikun rẹ ni abala kọkanlelaadọta to waye nile ẹjọ giga kan nilu eko. olabiran ni awọn gbe ọrọ naa lọ siwaju ile ẹjọ adajọ oluwatoyin taiwo lẹyin to ṣoro fun awọn lati gba ọjọ ipẹjọ nile ẹjọ kotẹmilọrun. amọ agbeọjọro ijọba, yusuf sule tako igbesẹ naa pẹlu ipẹjọ tirẹ pe ko si eredi kankan ti ile ẹjọ fi gbọdọ fun baba ijesha ni beeli titi ti igbẹjọ kotẹmilọrun rẹ yoo fi bẹrẹ. ọjọ kẹrinla, oṣu keje, ọdun 2022 yii ni ile ẹjọ to n gbọ ẹsun ifipanilopọ yii ṣedajọ ẹwọn ọdun maru un fun baba ijesha, lẹyin to jẹbi mẹrin ninu ẹsun mẹfa ti wọn kan an, eyii to ni ṣe pẹlu ṣiṣe aṣemaṣe pẹlu ọmọde ti ọjọ ori rẹ ko tii to mejidinlogun. ninu ifọrọwerọ pẹlu bbc yoruba lẹyin ti ile ẹjọ kọ lati gba beeli ọdaran naa, agbẹjọro rẹ, gbariel olabiran sọ pe oun ṣi ni ireti pe onibara oun yoo bọ ninu ọgba ẹwọn to wa. o ni “ẹjọ ti a pe ni pe ki ile ẹjọ tu silẹ ko maa wa lati ile fun igbẹjọ kotẹmilọrun rẹ, amọ ile ko gba aba wa wọlẹ.” “a ti pe ẹjọ nile ẹjọ kotẹmilọrun nile ẹjọ giga, a dẹ mọ wi pe a ni awọn ohun ti ẹjọ wa to fẹsẹ mulẹ ti a fi mọ pe wọn maa fun wa ni ohun ti a n fẹ.”",22 owewe 2022,baba ijesha n fẹ ki wọn fun oun ni beeli ki oun le kuro ninu ọgba ẹwọn lati maa gba ile lọ sile ẹjọ fun igbejọ kotẹmilọrun. +"wo àwọn ọmọ yorùbá tó ń díje sípò ààrẹ, ilé aṣòfin àtàwọn obìnrin olùdíje","oríṣun àwòrán, screenshot àjọ tó ń rí sí ètò ìdìbò ní orílẹ̀ èdè nàìjíríà, inec ti fi orúkọ àwọn olùdíje sípò òṣèlú tó jẹ́ ti ìjọba àpapọ̀ léde. nínú àtẹ̀jáde kan tí inec fi sórí ayélujára twitter rẹ̀, ni wọ́n ṣe àgbéjáde orúkọ àwọn olùdíje sípò ààrẹ, igbá-kejì ààrẹ, àti ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àpapọ̀ nínú ẹgbẹ́ òṣèlú kọ̀ọ̀kan. inec ní èyí wà ní ìbámu pẹ̀lú ìwé òfin eto ìdìbò ọdún 2022. wọ́n ní àwọn tí àwọn fi orúkọ wọn síta náà ni ẹgbẹ́ òṣèlú wọn tẹ̀lé ìlànà tó tọ́ lásìkò tí wọ́n ṣe ìdìbò abẹ́nú. àtẹ̀jáde náà tí agbẹnusọ inec, festus okoye fi léde ní orúkọ àwọn tó lẹ́tọ̀ọ́ láti díje nìyí. o fikun pe kò sí àyípadà kankan tó lè wáyé lórí rẹ̀ mọ́ àyàfi tí ọ̀kan nínú àwọn olùdíje náà bá ṣe aláìsí. okoye ní gbogbo ẹgbẹ́ òṣèlú méjìdínlógún tí inec fọwọ́ sí ni wọ́n fi olùdíje sípò ààrẹ kalẹ̀. bákan náà ló ní àwọn olùdíje 1,101 lọ ń díje fún ipò sẹ́nétọ̀ tí àwọn tó ń díje sípò ilé ìgbìmọ̀ aṣojúṣòfin sì jẹ́ 3,122. oríṣun àwòrán, inec/twitter oríṣun àwòrán, inec/twitter oríṣun àwòrán, inec/twitter nínú àwọn méjìdínlógún tí inec gbé orúkọ wọn jáde pé wọ́n ń wá ipò ààrẹ márùn-ún nínú wọn lọ jẹ́ ọmọ yorùbá. àwọn náà ni: oríṣun àwòrán, yelesowore/instagram sowore omoyele stephen ló ń díje lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú african action congress, aac. ọmọ bíbí ìlú ese-odo ní ìpínlẹ̀ ondo ni sowore. ọdún 1971 sì ni wọ́n bi. sowore jẹ́ ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn, òun sì ni olùdásílẹ̀ iléeṣẹ́ ìròyìn sahara reporter. ìgbà ìkejì rèé tó ń díje sípò ààrẹ nàìjíríà. ní ọdún 2019 ló kọ́kọ́ díje tó sì fìdí rẹmi sọ́wọ́ ààrẹ muhammadu buhari. oríṣun àwòrán, bola tinubu/facebook asiwaju bola ahmed tinubu náà jẹ́ ọ̀kan lára olùdíje sípò ààrẹ nàìjíríà lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú all progressives congress, apc. gbajúgbajà olóṣèlú ni tinubu ní orílẹ̀ èdè nàìjíríà bó ṣe jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olùdásílẹ̀ àti adarí àpapọ̀ ẹgbẹ́ òṣèlú apc. ní ọdún 1952 ni wọn bí tinubu ní ìpínlẹ̀ eko. bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé tinubu ṣe gómìnà ìpínlẹ̀ eko fún sáà méjì, láàárín ọdún 1999 sí 2007, ìgbà àkọ́kọ́ rèé tó ń wá ipò ààrẹ nàìjíríà. ọmọ bíbí ìpínlẹ̀ ogun ni adenuga sunday oluwafemi tó ń díje lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú boot party, bp. ọmọ ọdún méjìdínláàdọ́ta ni adenuga tó sì jẹ́ ògbóǹtarigì oníṣòwò. ìgbà àkọ́kọ́ nìyí tó ń díje fún ipò ààrẹ nàìjíríà. oríṣun àwòrán, kola abiola/facebook ọmọ bíbí olóògbé m. k. o. abiola ni kola abiola tó ń díje sípò ààrẹ nàìjíríà lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú peoples redemption party, prp. ọdún 1962 ni wọ́n bí kola abiola tó sì ti pé ọgọ́ta ọdún báyìí. ìgbà àkọ́kọ́ tó ń díje sípò ààrẹ nàìjíríà nìyí. oríṣun àwòrán, adebayo adewole/facebook ọmọ bíbí ìlú ondo ní ìpínlẹ̀ ondo ni adebayo adewole ebenezer tó sì jẹ́ ọmọ àádọ́ta ọdún. agbẹjọ́rò ni adewole adebayo tó sì tún jẹ́ olùdásílẹ̀ iléeṣẹ́ amóhùnmáwòrán kaftan tv. lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú social democratic party, sdp ló ti ń díje. ìgbà àkọ́kọ́ nìyí tí yóò gbé gbá láti du ipò ààrẹ nàìjíríà. gẹ́gẹ́ bí àtẹ̀jáde tí inec fi síta ṣe sọ àwọn obìnrin 381 lọ ń wá ipò òṣèlú sí àwọn ipò ijoba àpapọ̀. nínú àwọn 381 yìí, ẹnìkan péré ló ń wá ipò igbakeji ààrẹ, ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àpapọ̀ ni àwọn yòókù ń gbèrò láti lọ. lati ilẹ̀ yorùbá, awọn ogún ló ń díje sípò sẹ́nétọ̀ tí àwọn àádọ́rin sì ń wá ipò sí ilé ìgbìmọ̀ aṣojúṣòfin.",22 owewe 2022,inec ní àwọn tí àwọn fi orúkọ wọn síta náà ni ẹgbẹ́ òṣèlú wọn tẹ̀lé ìlànà tó tọ́ lásìkò tí wọ́n ṣe ìdìbò abẹ́nú. +"asuu àtàwọn aṣòfin ṣàdéhùn tí yóò fòpin sí ìyanṣẹ́lódì, buhari ló kù kó buwọ́lù ú","oríṣun àwòrán, nass ẹgbẹ awọn olukọ fasiti, asuu ti ṣe adehun tuntun pẹlu ijọba apapọ naijiria. awọn ikọ adari ile igbimọ asofin apapọ lo lewaju ipade oni wakati mẹrin to bi adehun tuntun naa to waye ni ile gbimọ asofin to wa niluu abuja lọjọ isẹgun. adehun naa lo nilo ibuwọlu aarẹ muhammadu buhari, ẹni to rin irinajo lati kopa nibi ijokoo ajọ isọkan agbaye niluu new york. emmanuel osodeke lo lewaju fun ẹgbẹ awọn olukọ fasiti ti minista fun eto ẹkọ, goodluck opiah si lewaju fun ijọba apapọ nibi ipade naa. lẹyin ipade naa, adari ile igbimọ aṣofin kekere, femi gbajabiamila, to tun jẹ alaga fun ipade naa kede pe ipade naa bi awọn adehun tuntun sugbọn ko sọ ipo ti adehun tuntun naa dirọ mọ. o ni awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin yoo ṣe agbekalẹ awọn adehun naa fun aarẹ buhari, to ba pada de si orilẹede naijiria. “ọna meje ni asuu fi ṣe agbekalẹ wọn, to si ti fi ẹnu ko lori awọn nkankan lẹyin ti a jọ wo awọn ọna naa. “lẹyin eleyi, awọn adari ile igbimọ aṣofin yoo duro ki aarẹ buhari pada si orilẹede naijiria lati ibi ipade ajọ isọkan agbaye. a ṣe awọn agbekalẹ fun aarẹ, ti a si ni ireti pe aarẹ yoo fara mọ awọn adehun naa, pẹlu eleyi, mo ni igbagbọ pe ọrọ naa yoo tete ri iyanju.” nigba ti o sọrọ nibi ipade naa, aarẹ ajọ asuu, emmanuel osodeke ni ọrọ ko ni pẹ ti wọn ma fi iyanju rẹ. “a ti ri ilọsiwaju latara ipade, ti a si duro de nkan ti wọn yoo fi ransẹ si wa lati fi ba awọn ọmọ ẹgbẹ sọrọ. a ni ireti pe ko ni pẹ ti ọrọ iyansẹlodi yoo fi di ohun igbgagbe.” oríṣun àwòrán, others ẹgbẹ awọn akẹkọọ lorilẹede naijiria, nan ti balẹ si papakọ ofurufu to wa ni ipinlẹ eko, ti wọn si da lilọ bibọ duro saaju bi ijọba ṣe kuna lati fi opin si iyanṣelodi ti ẹgbẹ olukọ asuu gunle. ifẹhonuhan naa ko ṣẹyin iyanṣelọdi to ti wọ oṣu meje bayii lori bi ijọba ko ṣe mu adehun to ṣe pẹlu awọn olukọ ṣe. ati aisan owo oṣu fun wọn ni gbogbo igba ti wọn fi yan iṣẹ lodi ogunlọgọ awọn akẹẹkọ lo ti balẹ si agbegbe naa lati bẹrẹ ifẹhonuhan naa ọsẹ to kọja ni ẹgbẹ nan ṣe ipade nipinlẹ ondo, ti wọn si bu ẹnu atẹ lu bi ijọba apapọ ko ṣe naani awọn olukọ ati eto ẹkọ paapaa ni naijiria. oríṣun àwòrán, others oríṣun àwòrán, others nibi ipade naa ni wọn ti kede pe awọn yoo bẹrẹ ifẹhonuhan kaaliri papakọ ofurufu lorilẹede naijiria. ‘’bẹrẹ lati ọjọ aje, ọjọ kọkandinlogun, ọdun 2022 ni a o bẹrẹ ifẹhọnuhan miran. ‘’a o ri pe ko si ọkọ ofurufu kankan lati ilẹ okeere to balẹ si naijiria abi eleyii ti yoo jade.’’ ‘’aarẹ buhari gbọdọ san gbogbo owo awọn olukọ to jẹ wọn nitori o ti su wa ki a ba wọn sọrọ ti wọn kọ’’ ‘’a ko ni gba ki awọn akẹkọọ joko si ile nigba ti awọn oloṣelu n ran ọmọ wọn lọ si oke okun. ‘’#occupytheairports yoo bẹrẹ ni ọjọ aje, ki gbogbo agbaye le mọ ohun ti a n la kọja ni orilẹede naijiria.’",19 owewe 2022,àdéhùn tó rinlẹ̀ wáyé níbi ìpadé asuu àtàwọn aṣòfin lọ́nà àti fòpin sí ìyanṣẹ́lódì àwọn olùkọ́ fásitì. +ṣé lóòótọ́ ni pé nurtw eko ń gba ₦500 lọ́wọ́ àwọn oníkẹ̀kẹ́ fún ìpolongo tinubu?,"ní àná ọjọ́ ìṣẹ́gun ogúnjọ́ oṣù kẹsàn-án ni fídíò kan gba orí ayélujára, èyí tó ṣàfihàn bí àwọn kan ṣe ń sọ fún awakọ̀ kẹ̀kẹ́ márúwá kan láti san ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta náírà. ohun tí wọ́n ní owó náà wà fún ni rira tíkẹ́ẹ̀tì kan tí wọ́n yóò lẹ̀ mọ́ ara kẹ̀kẹ́ náà láti lè máa polongo fun olùdíje sípò ààrẹ lábẹ́ àsíá ẹgbẹ òṣèlú apc, bola ahmed tinubu. ní agbègbè alagbado, ìpínlẹ̀ eko ni fidio naa ní ìṣẹ̀lẹ̀ ọhun tí wáyé. nínú fídíò náà ni òṣìṣẹ́ ẹgbẹ awakọti pọn ní dandan pe kí awakọ̀ náà gba tíkẹ́ẹ̀tì yii tó sì fẹ́ lẹ tíkẹ́ẹ̀tì náà mọ́ ara ọkọ̀ náà ní dandan. àmọ́ awakọ̀ márúwá náà fárígá wí pé òun kò ní gba tíkẹ́ẹ̀tì yìí, tó sì ní kí òṣìṣẹ́ union yọ́ kúrò lára kẹ̀kẹ́ òun. ọ̀rọ̀ ọ̀hún ló ṣe bẹ́ẹ̀ fa awuyewuye láàárín àwọn méjèèjì, ti àwọn èrò si pe le awọn mejeeji lori loju titi. èyí sì mú kí àwọn ènìyàn da ẹnu bo òṣìṣẹ́ union náà wí pé ìwà kò tọ́ ni wọ́n ń hù lórí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí. fídíò náà ti wá gba orí ayélujára kan, eyi tó sì ti ń fa awuyewuye. ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn sì ń fi ẹ̀sùn kan alága àwọn ọlọ́kọ̀ ní ìpínlẹ̀ eko, musliu akinsanya, tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí mc oluomo wí pé òun ló wà nídìí títa tíkẹ́ẹ̀tì náà. oríṣun àwòrán, mc oluomo/instagram lẹ́yìn tí fídíò náà gba orí ayélujára ni mc oluomo fi àtẹ̀jáde kan léde lórí instagram rẹ̀ láti fi wẹ ara rẹ̀ mọ́ wí pé òun kò mọ nǹkankan nípa tíkẹ́ẹ̀tì náà. mc ní ó jẹ́ ohun ìyàlẹ́nu fún òun wí pé àwọn kan ń fi orí tíkẹ́ẹ̀tì àti fídíò náà sọ òun àti gbígba owó fún ìpolongo ibo ààrẹ fún tinubu. ó là á mọ́lẹ̀ wí pé òun kò ní nǹkan ṣe pẹ̀lú tíkẹ́ẹ̀tì tàbí títà rẹ̀ àti pé inú òun yóò dùn tí àwọn ènìyàn bá le fi ibi tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti waye gangan han òun láti ṣe ìwádìí ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́. ó ní gbogbo àwọn nǹkan tó bá le kó ìpalára bá iṣẹ́ àti àwọn ènìyàn àwọn ni òun máa ń sá fún nítorí náà àwọn kò lè dédé gbé ìnáwó kan dìde fún àwọn ènìyàn láì bá wọn sọ tẹ́lẹ̀. mc tẹ̀síwájú pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ló ti ń gbèrò láti náwó tó pọ̀ rẹpẹtẹ sídìí ìpolongo tinubu tí irú owó bẹ́ẹ̀ kò sì ní wá láti ọ́fíìsì òun. bákan náà ló ní tó bá ti di àsìkò ìpolongo ìbò báyìí onírúurú ìròyìn ẹlẹ́jẹ̀ ni àwọn ènìyàn máa ń gbé kiri láti fi ṣàkóbá fún ẹlòmíràn. ó wà rọ àwọn ènìyàn láti kọtí ọ̀gbọ̀in sí ìròyìn ẹlẹ́jẹ̀ yìí nítorí irọ́ pátápátá ló wà nìdí ẹ. bẹ́ẹ̀ náà ló rọ àwọn olóṣèlú láti yé fi irọ́ kún ohun gbogbo tí wọ́n bá ń ṣe lásìkò yìí àti pé kí wọ́n yàgò nìdí dídárúkọ òun sí ọ̀rọ̀ òṣèlú wọn",21 owewe 2022,"ní agbègbè alagbado, ìpínlẹ̀ eko ní ìṣẹ̀lẹ̀ náà tí wáyé." +"ìyá ìbejì twinz love sá bá ọkọ míì lọ sí ibadan, ó bímọ kùnrin síbẹ̀ ló fa ìpínyà wa - baba ibeji","twinx love dad: ìyá ìbejì kúrò nílé fún oṣù méjì láì sọ ibi tó ń lọ, kò fi mí lọ́kàn balẹ̀ yoruba ni eti to ba gbọ alọ, lo yẹ ko gbọ abọ. bẹẹ ba gbagbe, laipẹ yii ni bbc yoruba mu fidio kan wa fun yin nipa ifọrọwerọ wa pẹlu obinrin kan, arabinrin adeyinka oladimeji. oun si lo bi ibeji adẹrinposonu ti orukọ wọn n jẹ doyin ati moyin oladimeji, ti wọn jẹ twinz love lori ayelujara. ninu ifọrọwerọ naa si ni mama ibeji ti salaye awọ ilakọja to ni lasiko to n tọju awọn ọmọ naa, bi ọkọ rẹ se ni ko gbe awọn ọmọ naa silẹ niwaju ile olowo kan ati bi baba ibeji naa se salọ kuro nile ti wọn n gbe. lẹyin ọsẹ meji ta gbe fidio naa sita, ni baba awọn ibeji yii kan si bbc yoruba lati sọ alaye tiẹ lori awọn ẹsun ti iya ibeji fi kan an. amọ yoruba ni agbọ ẹjọ ẹnikan da, agba osika ni nitori o yẹ ka wadi ohun gbogbo daju, ka si di eyi tii se otitọ mu. pasitọ sunday oladimeji, to jẹ baba ibeji sọ fun bbc yoruba pe osu february 1998 ni awọn pade ara awọn nilu akure, ni adugbo ti awọn mejeeji dijọ n gbe, ti awọn si se ayẹyẹ mọmi n mọ ọ nilana idana tilẹ yoruba lẹyin osu mẹrin. baba ibeji, tii se ọmọ bibi ilu ila orangun amọ to ti di ojisẹ ọlọrun bayii nilu akure fikun pe lẹyin osu kan ti wọn se idana iyawo ni adeyinka loyun, to si fi bi ibeji obinrin meji. o ni ọgbọnjọ osu kẹta march ọdun 1999 ni obinrin naa bi awọn ibeji yii, ti awọn si se isọmọ lorukọ, sọọsi iya arẹmọ si ni awọn n lọ nigba naa. baba ibeji ni ọpọ eeyan pupọ lo peju sibi ayẹyẹ isọmọlorukọ awọn ibeji naa nitori se ni ẹnu n ya gbogbo eeyan pe oun oladimeji bi meji. oríṣun àwòrán, sunday oladimeji nigba to n salaye iru ajọsepọ to wa laarin oun ati iya ibeji ati iru ẹni to jẹ, oladimeji ni eeyan lile ni iya ibeji naa ati pe onijagidijagan ni. o ni kii gbọ, kii gba ni adeyinka, ti ko si pe osu mẹrin ti awọn bi ibeji, ti mama onile fi ni ki awọn ko kuro ninu ile naa. “mama onile naa wa laye bayii o, o ni ka kuro nile tori wahala iyawo mi ti pọ ju, yara meji ninu ile kọjusimi ki n kọjusiọ si la n gbe. bi awọn tẹnanti yoku ta jọ n gbe ile ba n ja, iyawo mi ni yoo fi ọlọpaa mu wọn, yoo ti wọn mọle, ibi ti wahala yẹ ti bẹrẹ niyẹn. bi wọn ba n ja, yoo fi tiẹ si, idi si ree ta fi kuro ninu ile mama naa, ta si tun lọ gba ile miran.” oríṣun àwòrán, sunday oladimeji oladimeji tẹsiwaju pe onisẹ ọwọ atọkọse panel beater ni oun amọ iya ibeji ko sisẹ kankan nigba naa. o ni nigba ti awọn ibeji pe osu mẹjọ pere lọdun 2000 ni mama wọn ti n gbe awọn ọmọ naa si ibudo itọju ọmọde, ta mọ si day care. oladimeji ni iyawo oun jade lọ fun ọjọ meje lai pada wale, to si ko awọn ọmọ silẹ nigba to ni oun fẹ lọ si ile ẹkọ gbogbonse poly offa. baba ibeji ni asiko yii ni mama oun wa bẹ awọn wo, nigba ti wọn si duro bii ọjọ meji si mẹta, wọn ko ri iya ibeji, to si de ni ọjọ keje to ti kuro nile. “ni kete to de, ko dahun ibeere ti mo n bi pe ibo lo lọ, amọ se lo tun wọ sokoto, to tun jade nile, ti ko si tun pada wa sile wa sun. nigba ti mama mi si ri bi mo ti n se wahala, wọn ba ko awọn ibeji lọ sile wọn ni ila.” baba ibeji tẹsiwaju pe nigba ti iya ibeji pada sile, o n bẹbẹ ni titi ti oun fi sọ fun mama oun pe ki wọn ko ọmọ fun. o ni lẹyin eyi, iyawo oun le jade lọ lati aarọ titi di alẹ tabi ko ma wale fun odidi ọjọ mẹta. “lọjọ kan ta n mura lati lọ si sọọsi lọjọ sunday lọdun 2021, ni iya ibeji ni oun tun fẹ lọ si irin ajo, bo se lọ, ti a ko ri mọ niyẹn fun osu meji. lẹyin osu meji, nigba ti wahala itọju wọn pọ fun mi, mo ko awọn ọmọ lọ sọdọ mama mi. a se ibadan lo lọ, o ti ni oju tuntun ni ibadan, ohun to fi de ibadan di oni niyẹn, mo ro pe o lọ haaya ile sibẹ ni. nigba to pada de, o lọ si ila lati lọ beere ọmọ rẹ, amọ mo ni wọn ko gbọdọ ko ọmọ fun. a maa n pade nile ẹkọ awọn ọmọ, yoo wa lati ibadan, emi yoo wa lati ila, a si dijọ n tọju awọn ọmọ yii. sugbọn ko ni asiko pe ko duro tọju awọn ọmọ yii fun isẹju kan.” oríṣun àwòrán, sunday oladimeji sunday oladimeji ni nigba to ya, wọn pe awọn mejeeji lati ba wọn pari ija, ti wọn si bi oun pe se oun si le fẹ iytawo oun pada, ti oun si ni oun yoo fẹ. asiko yii naa ni wọn sọ pe kawọn se igbeyawo nitori mọmi n mọọ lasan ni awọn se tẹlẹ, to fi ko wa sile. “ase mo n tan ara mi jẹ ni, o de lọjọ naa, o ni ka ko ọmọ wa si akure, ọkan kan ati osu mẹta si ni awọn ọmọ lo lọdọ mama mi. o maa n lọ si ibadan ni osoosu, nigba to ya mo ni ko maa ko bọ wa si akure, ibi ti ija ti bẹrẹ niyẹn. nigba to di 2005, oladimeji ni iya ibeji tun sọ fun oun pe oun fẹ rinrin ajo, ti oun si ni ko le lọ, amọ nigba ti oun jade lọ, iya ibeji ti ko awọn ọmọ rẹ lọ. “lẹyin ọsẹ meji, o wa sile, o fọ ilẹkun si meji, o si ko gbogbo ẹsọ ile lọ. mo si pinnu pe ko maa lọ, nitori o ti n fooro ẹmi mi ju. nigba to di 2007, o wa si akure nile ẹgbọn rẹ, wọn si pe mi amọ se lo n sepe fun mi, n ko fọhun tori epe rẹ ko le mọ mi. ẹgbọn rẹ ba wa pari rẹ, mo si fa mọra.’” sunday oladimeji ni lasiko ti wọn ba awọn pari ija tan, ni iya ibeji gbe ọmọkunrin kan lọwọ, to si n fun ni ọyan. “mo wa bi i pe ta lo ni ọmọ, to si ni oun ti fẹ ọkọ miran, mo si sọ fun pe sebi oun ni oun n duro de lati ọjọ yii, ti oun ko fi fẹ iyawo miran? funra ara rẹ lo sọ fun mi pe ki n lọ fẹ iyawo miran, to si ni ki n maa fi owo ransẹ si oun fun itọju awọn ọmọ. igba yii ni mo sọ pe ko ba mi ko awọn ọmọ amọ o ni rara, mo si ni ko jẹ ki ohunkohun ti mo ba fun maa tẹ lọrun.” oríṣun àwòrán, sunday oladimeji baba ibeji ni oun n san owo si akanti iya ibeji amọ epe lo n fi ransẹ si oun pe owo naa kere. lati igba naa si lo ti pa foonu, igbakuugba ta ba si pe e, epe lo maa n sẹ fun gbogbo wa. iya ibeji mọ pe n ko sọnu, o mọ ibi to le wa mi si, o wu lo ko awọn ọmọ sa fun mi.” baba ibeji wa sẹ lori ọrọ ti iya ibeji sọ pe oun wi fun pe kawọn gbe ibeji lọ sile ọmọ alainiya. o ni ko si oun to jọ bẹẹ rara, irọ lasan ni to si salaye pe epe to n sẹ fun awọn lo mu ki oun fisilẹ. “odidi ọdun mẹwa ni wahala iya ibeji fi wa lara mi, mo si sa fun ẹmi mi, kii se pe mo fẹ tọrọ owo lọwọ rẹ, ni mo se sọrọ yii sita. bi kii ba se ohun ti ẹyin bbc kọ pe ẹ wa mi, ẹ ko ri mi, lo mu ki n wa sọ tẹnu mi. ọlọrun sisẹ agbara rẹ ninu aye mi, mo ti ni sọọsi temi, ọlọrun si n jẹwọ agbara rẹ.” nigba ti bbc yoruba beere lọwọ baba ibeji pe se o setan lati fa awọn ọmọ rẹ mọra pada, o ni o wu oun ki ifẹ pada bọ sipo, ti iya wọn ba fẹ ko pada. “iya ko jẹ mi amọ to ba fẹ ki awọn ọmọ yẹn ri mi, deede, to ba si ni ko ni ri bẹẹ, ko buru. eleyi to ba ti wu ni ko se, sebi oun ni agbara wa lọwọ rẹ, ko dẹ si nnkan ta le se si. ti mo ba ri wọn, inu mi yoo dun, ayọ mi ni wọn, ayọ mi wọle niyẹn.” iya àwọn aderinposonu ìbejì tí ọ̀pọ̀ mọ sì twinz love ṣàlàyé ìrìnàjò rẹ pẹlu awọn ọmọ rẹ",8 owewe 2022,"bàbá ìbejì bá bbc yorùbá sọ̀rọ̀ láti ṣàlàyé ohun tó fa ìpínyà láàrin rẹ̀ àti ìyá ìbejì, èyí tí kò jẹ́ kó bèèrè ìbejì fọ́jọ́ pípẹ́." +"àwọn olùdíje, òjísẹ́ ọlọ́run gbàdúrà nínú òjò ṣáájú ìbò 2023","oríṣun àwòrán, others bi igbaradi ṣe n sunmọ lori idibo lọdun 2023, awọn oludije si oniruuru ipo labẹ asia ẹgbẹ oṣelu pdp ni ipinlẹ ogun ti bẹrẹ akanṣe adura fun aseyori ẹgbẹ oṣelu naa. awọn ojisẹ ọlọrun kaakiri gbogbo ẹsin peju si ọọfisi ẹgbẹ oṣelu pdp niluu abeokuta lọjọ aje. nibẹ ni wọn si ti gbadura si ọlọrun fun awọn ti yoo ma rin irinajo fun iponlogo ati aseyọri nibi eto idibo naa. lẹnu akanṣe adura ọhun ni ojo ti bẹrẹ, ti awọn ojisẹ ọlọrun ati awọn oludije si kọ lati kuro ninu ojo, ti wọn kẹnu bọ adura fun ẹgbẹ pdp naa. ẹgbẹ oṣelu pdp ni awọn gbe adura naa kalẹ lati beere fun aabo ọlọrun ati lati gbogun ti gbogbo erongba buburu ti ẹgbẹ alatako gbero si ẹgbẹ oṣelu naa. ninu ọrọ rẹ, oludije sipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu pdp, ladi adebutu ni gbogbo ọna ni ẹgbẹ oṣelu pdp n gba lati se aseyori ninu idibo ọdun 2023 pẹlu atilẹyin ara ati ẹmi. oludije sipo gomina naa wa gbadura aseyọri fun gbogbo ọmọ ẹgbẹ oṣelu naa to n kopa ninu eto idibo, lati ori aaarẹ si igbimọ aṣofin. o ni ọpọ igba ni ọrọ eto idibo ko ni jẹ ki oun ri oorun sun, ti oun si ti pinnu pe oun ko ni dẹkun lati ma ṣe ohun to tọ fun idagbasoke ipinlẹ oyo. oríṣun àwòrán, others adebutu tẹsiwaju pe kii ṣe nitori owo ni oun fẹ fi jẹ gomina ipinlẹ ogun sugbọn lati ri pe awọn eeyan ipinlẹ naa ko jiya rara, ki ipinlẹ naa si ni ilọsiwaju. akọwe ẹgbẹ oṣelu pdp , dokita sunday solarin ni ẹgbẹ oṣelu naa nilo adura lati ti fi gbogun ti erongba awọn alatako, ti wọn fẹ da eto alaafia ẹgbẹ oṣelu naa ru. folarin ni akanṣe adura naa lo jẹ akọkọ iru ẹ, ti awọn igun obinrin ẹgbẹ oṣelu naa gbe kalẹ. woli kan lorilẹede uganda to ti wọ gau lori ẹsun ifiyajẹni ati ijinigbe ti wọn fi kan-an. woli naa, kintu dennis ti ile ijọsin hoima empowerment church international ni a ri ninu fidio, nibi to ti n fi ẹgba naa awọn ọmọ ijọ rẹ. ileeṣẹ ọlọpaa ti wa fi panpẹ ọba mu oun ati awọn ọmọ ijọ rẹ mẹrin lẹyin ti awọn eniyan fi aidunnu wọn han nipa fidio naa. ohun to ṣe ni pe o paṣe fun awọn oṣiṣẹ ni ṣọọṣi rẹ lati jade si ita, ki wọn si maa na awọn ọmọ ijọ naa tabi ki wọn ma wa si ile ijọsin rẹ mọ. ni gbogbo asiko yii ni awọn eniyan n wo bi o ṣe n na awọn oṣiṣẹ ijọ rẹ naa. amọ ninu ọrọ rẹ, woli kintu ni bi jesu ṣe ṣe fun awọn to n na ọja ninu ṣọọṣi tabi tẹmpili ni oun se fun awọn ọmọ alaigbọran ijọ oun. bakan naa ni ijọba fẹsun un kan pe ijọ rẹ ko gba iwe aṣẹ kankan, ko to bẹrẹ rẹ. iwadii fihan pe ẹgba mẹta lo wa ninu ile ijọsin naa, ti wọn fi n na awọn eniyan. wọn ti fi wolii naa atawọn mẹrin yoku si ahamọ ọlọpaa titi di jọ keje, oṣu kẹsan, ọdun 2022. ọpọlọpọ ijọ lo wa ni uganda, ti ko si ẹnikẹni to n yẹ wọn ni ọwọ wo.",18 owewe 2022,pdp ni oun gbe adura naa kalẹ lati beere aabo ọlọrun ati lati gbogun ti erongba buburu ẹgbẹ alatako. +pásítọ̀ wọ gàù lórí ẹ̀sùn ìjínigbé àti ìṣekúpa nọ́ọ̀sì’,"oríṣun àwòrán, georgina asor botchwey ileeṣẹ ọlọpaa orilẹ-ede ghana ti fi ṣikun ofin mu pasitọ kan ti wọn fẹsun kan pe o ji ọdọbinrin akẹkọọ nọọsi kan gbe. bakan naa, wọn tun fi ẹsun apaniyan kan-an tori bi wọn lo se gbẹmi obinrin naa lagbegbe mankessim. awọn ọlọpaa ti wu oku obirin naa bayii nibi ti pasitọ naa ati ẹni ti wọn jọ ṣiṣẹ laabi ọhun, sin oloogbe naa si. ni bayii, wọn ti n wa afurasi keji to n ba pasitọ naa ṣiṣẹ, iyẹn oloye kan, nana clarke. o ti to ọsẹ kan ti oloogbe-binrin ọhun, georgina asor botchwey ti di awati ti wọn si ti n wa kiri. iroyin ni ṣe ni akẹkọọ naa lọ ṣe ifọrọwanilẹnuwo kan nile ẹkọ ankaful nursing training school, nibi ti wọn ti n kọ awọn eeyan lẹkọọ nọọsi. lati igba naa, ko si ẹnikẹni to gbọ ohunkohun nipa rẹ, bẹẹ si ni ẹrọ ibaraẹnisọrọ rẹ ko wọle. idi ree ti awọn mọlẹbi atawọn ọrẹ rẹ bẹrẹ si n ke gbajare lori ayelujara. asiko ti iwadii bẹrẹ ni ọlọpaa ni awọn fura si pasitọ naa, lẹyin iwadii wọn, o si jẹwọ pe lootọ ni oun lọwọ ninu iku obinrin ọhun. ẹwẹ, awọn eeyan lagbegbe ti iṣẹlẹ naa ti waye ti ke si ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa ni ghana lati wa ojutu si oniruru iṣẹlẹ iṣekupani to n waye nibẹ. aṣofin to n ṣoju agbegbe ọhun, cephas arthur sọ pe “igba karun un ree ti irufẹ nnnkan bayii yoo waye ninu ọdun yii nikan ṣoṣo. mo si fẹ ki awọn ọlọpaa fi imu pasitọ naa ati oloye ti wọn jọ ṣiṣẹ papọ danrin.” wọn ti gbe oku oloogbe ọhun lọ sile iwosan cape coast teaching hospital bayii fun ayẹwo ati iwadii ni kikun.",24 owewe 2022,"iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ti n wa afurasi keji to n ba pasitọ naa ṣiṣẹ, iyẹn oloye kan, nana clarke." +"""mo fipá bá ọmọbìnrin mi lòpọ̀ nínú yàrá kan tí èmi, aya àti ọmọ mẹ́fà ń gbé""","oríṣun àwòrán, @ogunpoliceng ọwọ ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ ogun ti ba baba kan, olusẹgun oluwole tii se ẹni ọdun mẹrindinlaadọta fun ẹsun pe o fi tipa ba ọmọdebinrin rẹ lopọ. ikede kan ti ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ ogun fisita loju opo twitter rẹ lo sisọ loju eleyi pẹlu afikun pe agbebe amolaso nilu abeokuta ni isẹlẹ naa ti waye. gẹgẹ bi ileesẹ ọlọpaa ogun ti wi, ọmọdebinrin naa lo mu ẹjọ baba rẹ tọ agọ ọlọpaa ibara lọ lati fi ipalara ti oluwole se han wọn. ọmọdebinrin naa, tii se ẹni ọdun mẹtadinlogun, ni baba rẹ fipa ba lopọ lasiko to n sun lọwọ ninu ile oniyara kan ti wọn n gbe ni deede aago mọkanla abọ. ọmọ naa ni “nigba ti baba mi ri pe awọn eeyan yoku ti sun lọ fọnfọn, se ni wọn sadede ki mi lapa lojiji, ti wọn si fipa ba mi ni ajọsepọ. wọn wa n dunkooko mọ mi pe ti n ko ba gba, ki awọn ba mi lopọ, awọn yoo pa mi ni.” ileesẹ ọlọpaa ni, ni kete ti ẹsun naa to awọn leti, ni ọga ọlọpaa ibara, bernard egbondiya nawọ gan afurasi ọhun. nigba ti wọn wa fi ọrọ wa oluwole lẹnu wo, oluwole, to bi ọmọ mẹfa, wa n bẹbẹ fun idarijin lọwọ awọn ọlọpaa. oluwole ni “n ko tiẹ mọ ohun to ta le mi, ti mo fi hu iwa yii, ti mo si fipa ba ọmọ mi lopọ.” wayi o, kọmisana ọlọpaa nipinlẹ ogun, lanre bankole ti wa pasẹ pe ki wọn mu afurasi naa lọ si ẹka ileesẹ ọlọpaa to wa fun iwa ọdaran fun iwadii to yẹ. o ni lẹyin iwadii ẹka naa, ni ki wọn gbe oluwole lọ sile ẹjọ, ko le gba idajọ to yẹ lọdọ ijọba. bakan naa lo ni ki wọn tete mu ọmọdebirin naa lọfun itọju nmile iwosan. oríṣun àwòrán, osun police awọn ẹgbẹ ọdẹ ibilẹ ni ilu ede ni ipinlẹ osun ti kede pe ọwọ awọn ti tẹ ọkunrin kan, ẹni ọdun mejidinlọgbọn, ismail adewuyi. ẹsun ti wọn fi kan afurasi naa ni pe o ṣe ji ori ati ifun oku ọmọbinrin kan ni itẹ oku awọn musulumi to wa ni oke yidi, niluu ede. adewuyi, ẹni ti wọn ba ọpọlọpọ ogun lara rẹ, lo ṣe ikọlu si itẹ oku naa ni owurọ ọjọ satide, to si wu oku naa sita lati bẹ ori ati lati ko ifun rẹ. wọn ni kete ti o fẹ kuro ni itẹ oku naa lo bọ sọwọ ọkan lara awọn ọdẹ agbegbe naa, ni dede ago kan orun. agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, yemisi opalola ni ọwọ ti tẹ okunrin oniṣegun naa, ti iwadi si ti bẹrẹ lori iṣẹlẹ naa. opadola ni “lowurọ ọjọ satide, ni bi iṣẹju diẹ kọja ago kan, ni ọwọ ọkan lara ẹgbẹ ọdẹ tẹ adewuyi ismail lati oke ola, agbagudu ni ede. wọn si mu wa si agọ ọlọpaa pẹlu ori ọmọbinrin kan to ji gbe ati awọn ifun pẹlu. “afurasi naa ti wa agọ wa, ti iwadi si ti ibẹrẹ lori iṣẹlẹ naa.” oríṣun àwòrán, others ikọ itẹmuyẹ to n risi ọrọ pajawiri, rapid response squad (rrs) ti fi panpẹ ọba mu awọn ọdọlangba meji fun ẹsun ifipabanilopọ nipinlẹ eko. ọmọbinrin ẹni ọdun mọkanlelogun to jẹ alajota ni awọn ti wọn n fi ẹsun kan pe wọn n fi ipa balopọ ni inu ọkọ nissan ni agbegbe alausa ni ikeja, eko. awọn ti wọn fẹsun kan naa ni solomon barry ati omega bright, ti wọn jẹ ẹni ọdun mẹtadinlogoji ati ẹni ọdun mejidinlogoji. agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ eko, benjamin hundeyin ninu atẹjade ni wọn fi idi ọrọ naa mulẹ. o ni awọn oṣiṣẹ naa wa lẹnu iṣẹ ni wọn ri i pe wọn wa ọkọ naa gunlẹ ninu nissan naa, ki wọn to ri ohun to n ṣẹlẹ ninu ọkọ naa. ‘’nigba ti awọn oṣiṣẹ naa de ibẹ ni wọn ri i pe obinrin naa ko mi mọ, ti ko si gbo ohun ti awọn ọlọpaa n sọ.’’ ‘’lẹyin naa ni wọn gbe lọ si olu ileeṣẹ wọn fun iwosan to si ji pada.’’ bakan naa ni iwadii fihan pe agbegbe ile itaja ikeja shopping mall, alausa ni wọn ti gbe obinrin naa to si gba pe ki wọn gbe oun kaakiri, ki wọn to lọ si ile itura. ileeṣẹ rrs naa ni wọn ti gbe iṣẹlẹ naa lọ si ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to n ṣewadii ọrọ obinrin.",17 owewe 2022,osun suspected rapist: bàbá fipá bá ọmọ rẹ̀ lòpọ̀ nínú yàrá kan ṣoṣo tí ìdílé rẹ̀ ń gbé. +iléẹjọ́ tí rán ọlọ́pàá tó ṣekúpa kolade johnson lọ sí ẹ̀wọ̀n igbere,"oríṣun àwòrán, getty images/styles kolade johnson ileẹjọ ti ran osisẹ ileeṣẹ ọlọpaa nigba kan ri, olalekan ogunyemi lọ si ẹwọn gbere. idajọ naa lo waye lẹyin ọdun mẹta ti wọn fi ẹsun kan-an pe o pa ololufẹ ere bọọlu kan, kolade johnson. adajọ adenike coker, ti ile ẹjọ giga ipinlẹ eko lo gbe idajọ naa kalẹ lọjọbọ pe ki ọlọpaa naa wa ni atimọle ayeraye. johnson lo padanu ẹmi rẹ lẹyin ti ikọ ọlọpaa to n gbogun ti idigunjale, sars ṣe ikọlu si agbegbe mangoro ni ipinlẹ eko. wọn yinbọn fun johnson ni isalẹ ikun, to si gba ibẹ ku. awọn aladugbo ti ọrọ naa ṣoju wọn ni idije bọọlu alafẹsẹgba laarin liverpool ati tottenham ni oloogbe ọhun wa wo nile olounjẹ adugbo, ki ọlọjọ to de. wọn ni awọn sars naa ti pinnu lati gba ẹjẹ eeyan ninu ọrọ ẹnu wọn bi wọn ṣe de adugbo naa tẹlẹ. koda wọn ni oju ara nkan ọmọkunrin kolade ni ibọn ikẹta ti ọlọpàa sars naa yin ti baa ko to ku ki wọn to gbee de ilé iwosan ninu idajọ rẹ, adajọ adenike coker ni olujẹjọ jẹbi ẹsun ti wọn fi kan, fun idi eyi, ko ma lọ igbesi aye rẹ yoku ni ọgba ẹwọn. o tẹsiwaju pe olalekan mọmọ ṣekupa ọmọdekunrin nani oríṣun àwòrán, twitter ń ṣe ni ọ̀rọ̀ dàbí eré orí ìtàgé ní ilé ìjọsìn kan lánàá ọjọ́ àìkú, ọjọ́ kejìdínlógún oṣù kẹsàn-án ọdún 2022 nígbà tí àwọn elégún yawọ ilé ìjọsìn náà. awọn olùjọsìn ń sá àsálà fún ẹ̀mí ara wọn nígbà tí àwọn eégún náà yabò wọ́n, tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ní na ọmọdé àti àgbà. lásìkò tí ìsìn ń lọ lọ́wọ́ ni àwọn eégún náà yawọ ilé ìjọsìn náà tó wà ní ìlú shikal, ìjọba ìbílẹ̀ langtang, ìpínlẹ̀ plateau tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ní na gbogbo àwọn olùjọsìn. bákan náà ni ìròyìn ní yàtọ̀ sí wí pé wọ́n na àwọn olùjọ́sìn, àwọn dukia ìjọ náà ni àwọn eégún náà tún bàjẹ́. ẹgbẹ́ ọmọlẹ́yìn krìsìtẹ́nì (can) ti ẹ̀ka ìpínlẹ̀ plateau ní àwọn àwọn ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí sí ohun tó ṣokùnfà ìdí tí àwọn elégún náà ṣe gbé irúfẹ́ ìgbésẹ̀ yìí. alága ẹgbẹ́ can ìpínlẹ̀ plateau, ẹni ọ̀wọ̀ polycarp lubo, nígbà tó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ ní ohun ìyàlẹ́nu ńlá ni ìròyìn náà jẹ́. o ni iwa títẹ ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn lójú ni pẹ̀lú. ẹni ọ̀wọ̀ lubo ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ilé ìjọsìn tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé kò ì tíì fi isẹlẹ naa tó àwọn létí àmọ́ àwọn ti bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ láti wá fìn-ín ìdí kókò ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún. ""bí mo ṣe rí fídíò náà lórí ayélujára, ọkàn mi gba ọgbẹ́, tó sì ká mi lára gidi gan."" ""mi ò tíì lè sọ pé òótọ́ tàbí irọ́ ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà àmọ́ ohun tó dájú ni pé a ò ní kawọ́ lẹ́ràn, a máa wádìí ohun tó ṣẹlẹ̀ gangan."" lubo fi kun pé láti agbègbè náà ni akọ̀wé ẹgbẹ́ can ìpínlẹ̀ náà ti wá, tí òun sì ti pè é láti ṣèwádìí ilé ìjọsìn tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé, kó sì jábọ̀ fún òun. ó fi kun pé ní kété tí àwọn bá ti ṣèwádìí tí àwọn sì mọ ohun tó ṣẹlẹ̀, ni àwọn yóò fi ìròyìn léde. oríṣun àwòrán, twitter",20 owewe 2022,"adajọ adenike coker ni ọlọpaa naa jẹbi ẹsun ti wọn fi kan-an, to si ni ko lọ lo igbesi aye rẹ yoku lọgba ẹwọn." +èèyàn mẹsan an pàdánù ẹ̀mi wọn nínú ìwọ́de tako hijab ní iran,"oríṣun àwòrán, twitter ifẹhonuhan to bẹ silẹ lẹyin iku obinrin kan ti gbẹmi eeyan mẹsan-an miiran lorilẹede iran. obinrin to ku naa ni awọn agbofinro ti mọle nitori o tapa si ofin to rọ mọ lilo ibori lorilẹede naa. obinrin naa si lo padanu ẹmi rẹ lẹyin to lo ọjọ mẹta nile wosan. lara awọn to ti ba iṣẹlẹ naa lọ ni ọmọ ọdun mẹrindinlogun kan , ẹni ti awọn agbofinro yinbọn lu, nigba ti wọn ṣe ikọlu si awọn olufẹhonuhan. orisirisi fọnran lori ayelujara ṣe afihan bi awọn obinrin to n ṣe ifẹhonuhan ṣe ju anamọ soke, lẹyin ti wọn dana sun awọn ibori wọn. fọnran naa ṣe afihan bi wọn ṣe pariwo pe “a ki n ṣe anamọ, a fẹ itusilẹ ati ibaradọgba akọ ati abo"" ninu ọrọ rẹ niwaju ajọ isọkan agbaye, aarẹ joe biden ti orilẹede amẹrika ni awọn wa lẹyin awọn obinrin to n fi ẹhonu han naa ni iran nitori wọn ja fun ẹtọ wọn ni. o sọrọ yii ni kete ti aarẹ iran, ebrahim raisi ni ki ajọ agbaye kọ eti ikun si ipe awọn obinrin naa to n ja fun ẹtọ wọn. oríṣun àwòrán, twitter ọpọ awọn obinrin lo lewaju ifẹhonuhan ni iran, ti wọn si n dana sun ibori wọn, ‘hijab’, lẹyin ti ọkan lara wọn to tapa si ofin ‘hijab’ padanu ẹmi rẹ. ifẹhonuhan naa lo ti gbalẹ fun ọjọ marun un bayi, to si ti tan kalẹ kaakiri orilẹede naa. mahsa amini, obinrin kan ti awọn ọlọpa fi ẹsun kan pe o tapa si ofin to de lilo ibori si lo padanu ẹmi rẹ ni ile wosan lọjọ ẹti. amini yii lo ku lẹyin to ti wa ni ẹsẹkan aye ẹsẹkan ọrun (coma) nile iwosan fun ọjọ mẹta. ni sari, ẹkun ariwa ilẹ tehran, ogunlọgọ awọn obinrin lo tu sita, ti wọn si bẹrẹ si ni dana sun ‘hijab’ wọn lati fẹhonu han. amini ni ọwọ awọn ọlọpaa to n risi igbọran araalu tẹ ni olu ilu orilẹede naa lọsẹ to kọja. wọn si fi ẹsun kan pe o tapa si ofin to rọ mọ pe ki obinrin gbọdọ fi nkan bo ori, apa ati ẹsẹ wọn. iroyin naa ni awọn ọlọpaa na obinrin naa, to si daku, eyi to mu ko wa ni koma fun ọjọ mẹta. asoju ajọ united nation to ri ija fun ẹto ọmọniyan, nada al-nashif, ni iwadi awọn safihan pe awọn ọlọpaa naa fi kumọ naa amina. o ni ti wọn si tun gba ori rẹ mọ ọkan lara ọkọ wọn. awọn ọlọpaa ni awọn ko fi iya jẹ obinrin naa ati pe o kan sadede ni ijakulẹ ọkan rẹ. mọlẹbi amina ni ilera rẹ wa ni alaafia, ti ko si nkan to mu rara. amini, ẹni ọdun mejilelogun wa lati kurdistan ni ẹkun iwọ orun orilẹede iran. agbegbe yii si ni eeyan mẹta ti padanu ẹmi wọn lọjọ aje nigba ti ọlọpaa sina bolẹ fun awọn olufẹhonuhan. ọkan lara awọn amugbalẹgbẹ adari ayatollah ali khamenei, ti orilẹede iran sabẹwo si idile ọmọbinrin, to si ṣe ileri pe ẹlẹsẹ kan ko ni lọ la jiya lori iṣẹlẹ naa. mp jalal rasidi koochi wa bu ẹnu atẹlu ihuwasi awọn agbofinro, to si ni wọn kan ko ba awọn araalu si ni lorilẹede iran. oríṣun àwòrán, mọlẹbi mahsa amini lẹyin ti ẹsin islam ri ayipada lọdun 1979, awọn alasẹ lorilẹede iran gbe ofin kalẹ lori asọ wiwọ awọn obinrin. wọn ni wọn gbọdọ bo ori wọn, wọn ko si gbọdọ wọ asọ to fun mọra ju ni awujọ. ẹka ọlọpaa to ri si igbọran ""gasht-e ershad"", ni wọn gbe isẹ naa le lọwọ lati ri pe awọn obinrin tẹle ofin naa. awọn ọlọpaa ni asẹ lati da obinrin duro lati wo boya o tẹle ofin ati irufẹ asọ ti wọn ba wọ sara. ijiya ẹsẹ fun ẹni toba tapa si ofin naa ni, owo itanran, lilọ sọgba ẹwọn ati ẹgba jijẹ. lọdun 2014., awọn obinrin bẹrẹ lati ma ṣe afihan awọn aworan ati fọnran ara wọn ni awujọ nibi ti wọn ti n tapa si ofin naa lati fi ṣe ifẹhonuhan lori ayelujara. ifẹhonuhan naa ni wọn pe ni ""my stealthy freedom"". lara awọn ifẹhonuhan ti ọpọlọpọ awọn obinrin miran ti se lori lilo ibori ni wọn pe akori rẹ ni ""white wednesdays"" ati ""girls of revolution street"".",21 owewe 2022,iran hijab protest: èrò ààrẹ iran yàtọ̀ sí ti amẹ́ríkà níbi ìpàdé un lórí àwọn obìnrin tó ń ṣe ìwọ́de ní iran. +"""ife ń ti ṣọ́ọ̀ṣì bọ̀, mo tàn-án wọ ṣọ́ọ̀ṣì wa, mo fipá ba lòpọ̀, fun lọ́rùn pa""","oríṣun àwòrán, oyo state police command ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ oyo ti ṣafihan afurasi ẹni ogun ọdun kan, to si ti sọ bi oun ṣe fipa ba ọmọdebinrin kan lopọ, ko to pa a sinu ile ijọsin kan ni ibadan. adugbo olodo ni arakunrin kolade tosin ṣalaye fawọn agbofinro pe oun pa arabinrin naa si, tori pe o fun oun ni ayederu passwọọdi foonu to wa lọwọ rẹ. nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ ni olu ileeṣẹ ọlọpaa ladugbo eleyele ni ibadan, o ni ọbẹ loun lo lati fi dẹru ba arabinrin naa, ki oun to hu iwa aburu yi. afurasi yii ṣalaye fawọn akọroyin lasiko afihan rẹ naa, nipa ọna to gba hu iwa aburu yi. gẹgẹ bo ṣe wi, lọjọ kẹtadinlogun oṣu kẹsan 2022 ni mo lọ si ile ni nkan bi ago kan ọsan, lẹyin ti mo parọ fun ọga mi pe mo fẹ lọ ṣe igá. ọga mii si ni ki n ma pẹ pada o tẹsiwaju pe mo mu kọkọrọ ile ijọsin lẹyin ti mo de ile tori maami ni wọn maa n tun ile ijọsin ṣe. nigba ti mo de ile ijọsin, mo ko gbogbo aga si ẹgbẹ kan mo si n ṣọ igba ti ifeoluwa yoo kọja. bo ṣe kọja ni mo sọ fun pe ko ran mi lọwọ lati to awọn aga, ki o to maa lọ si ile ijọsin tiẹ. lẹyin igba naa ni afurasi yii sọ pe oun fa ọbẹ yọ si ifeoluwa, ""ti mo si sọ fun pe ko ma ṣe pariwo sita mo fẹ gba foonu ọwọ rẹ ṣugbọn o bẹrẹ si ni lọ ọbẹ mọ mi lọwọ. nibẹ lo ti ṣubu to si fi ori gbalẹ nigba to fẹ́ salọ. kolade ṣalaye siwaju fawọn akọroyin bo ti ṣe fipa ba ifeoluwa lopọ nigba ti o ri pe ko lagbara lati salọ. nigba ti ko lagbara mọ, mo fi ipa ba lopọ. mo gba foonu rẹ mo si sọ fun pe ko fun mi ni pasiwọọdu rẹ. ayederu pasiwọdu lo gbe le mi lọwọ. nigba ti mo ri bẹẹ ni mo fi wa fun lọrun pa kọmiṣana ọlọpaa ni ipinlẹ oyo, adebowale williams sọ pe awọn agbofinro ni agọ ọlọpaa iyana-offa ni wọn fi to leti pe ifeoluwa ti dawati. gẹgẹ bo ṣe wi, ẹni ọdun mẹtadinlogun naa kuro ni ile ijọsin ni nkan bi ago mẹrin, ko si pada dele. kọmiṣana sọ pe iwadii ibẹrẹ, awọn fihan pe wọn ri oku arabinrin yii lẹgbẹ ile ẹkọ bibeeli lagbegbe olodo. o ni ẹjẹ wa loju ara rẹ ti apẹrẹ si wa wipe o ja fita ki o to pada gbẹmi mi. adebowale williams fi kun pe wọn ti gbe ọrọ naa lọ si ẹka ọtẹlẹmuyẹ ileeṣẹ ọlọpaa, nibi ti iwadii yoo ti maa tẹsiwaju.",21 owewe 2022,"iléeṣẹ́ olọ́pàá sọ pé wọ́n bá òkú ifeoluwa lẹ́bàá ilé ìjọ́sìn kan, tí ìwádìí sì tú àṣírí ẹni tó pa á." +"aráàlù fọnmú lórí pásítọ̀ tó ń gbẹ̀bí, pèsè ‘omi ayẹta’ fọ́mọ ìjọ","oríṣun àwòrán, peter michonza/facebook ọpọlọpọ awuyewuye lo ti n waye lori pasitọ ijọ new jerusalem deliverance ministry, peter michonza ni ijọba ibilẹ okene ni ipinlẹ kogi. ẹsun ti wọn fi kan pasitọ naa ni pe o n funra ara rẹ gbẹbi awọn alaboyun ninu ijọ rẹ lai gba aṣẹ ijọba. awọn to fi ẹsun kan an nipe awọn obinrin miran ti jẹ oku latari igbẹbi ti pasitọ naa n ṣe. okiki pasitọ naa lo kan kaakiri ayelujara lẹyin ti fidio ibi to ti n gbẹbi awọn obinrin jade soju opo ayelujara facebook rẹ. bakan naa ni pasitọ yii tun n fun awọn eniyan ni omi to pe ni ayẹta ‘’bullet proof water’’ fawọn ọmọ ijọ rẹ. awọn eniyan tun bu ẹnu atẹ lu pasitọ peter michonza nigba to ṣe ifẹhonu han nipinlẹ kogi. ifẹhonuhan naa lo wa lati fi aidunnu rẹ han lori gbajugbaja olori r kelly, ti wọn fi si sọgba ẹwọn lori ẹsun ṣiṣe aitọ pẹlu ọmọde. awọn fidio to wa ni oju opo facebook pasitọ peter michonza safihan ibi to ti n gbẹbi, to tun n se ‘’iwosan’’ ti a ko lee fi idi rẹ mulẹ. amọ bi awọn kan ṣe n tako, ni awọn miran n gboriyin fun ni oju opo naa. bakan naa ni oju opo facebook rẹ sapejuwe rẹ gẹ gẹ bi ‘’peter, ọmọ to n ṣoju baba rẹ ni aye.’’ iwadii ni iṣẹ orin kikọ ati fiimu ṣiṣeni pasitọ peter michonza n ṣe tẹlẹ, ki o to bẹrẹ ile ijọsin rẹ. oríṣun àwòrán, peter michonza/facebook oludamọran pataki fun gomina ipinlẹ kogi lori agbelarugẹ agbegbe, suleiman adinoyi sọ iriri rẹ nigba ti o de ile ijọsin naa. o ni oun lọ sibẹ nigba ti mọlẹbi oun kan n rọbi ni ile ijọsin naa, ti wọn si fi to oun leti. ‘’nigba ti mo de ibẹ , mi o le sọ boya pasitọ ni amọ o da mi loju pe kii ṣe dokita, o kan n fi ẹmi awọn alaboyun we ewu ni.’’ oríṣun àwòrán, peter michonza/facebook adinoyi tẹsiwaju pe ""bi mo ṣe de ibẹ ni mo beere ẹni to jẹ adari ni ṣọọṣi naa amọ wọn ko fẹ ko yọju si mi , igba ti mo da wahala silẹ nibẹ ni o to yọju’’ bi o ṣe de ibẹ ni awọn eniyan doju bolẹ, ti wọn si n pe ni baba wọn ati olugbala wọn. mo beere lọwọ rẹ pe ṣe dokita ni abi pasitọ, to si dahun pe oun kii se dokita amọ ile ọlọrun ni, ti oun si n ṣe ohun ti eniyan ko le ṣe. mo sọ fun pe mo wa gbe ibatan mi to wa nibẹ ni amọ o kọ jalẹ pe ọkọ ati iyawo ti buwọlu pe ki o wa ni ikawọ oun. nigba ti mo yari ni mo wọ ibi ti ibatan mi wa, nibi to ti n jẹ irora amọ o yari pe oun ko ni tẹle mi’’ lẹyin ọpọlọpọ ẹbẹ lo gba lati tẹle mi, amọ nigba ti a de ile iwosan ni dokita ni ọmọ inu rẹ ti ku’’ oríṣun àwòrán, peter michonza/facebook alaga ijọba ibilẹ okene, abdulrazaq muhammad ti paṣẹ fun awọn eleto aabo lati ṣewadii ile ijọsin pasitọ peter michonza. ninu atẹjade ti wọn fi lede ni wọn ni iwadii ti bẹrẹ ni pẹrẹwu lori pasitọ naa ati gbogbo ohun to n ṣe ninu ile ijọsin rẹ. alaga naa dupẹ lọwọ awọn eniyan to pariwo sita nipa iṣe pasitọ naa. o si fi da awọn eniyan loju pe gbogbo rẹ ni awọn yoo tu sita nigba ti iwadii ba pari. bakan naa ni wọn ti kesi ajọ to n ri ọrọ ọmọlẹyin kristi ni naijiria, can lati sabojuto ohun ti pasitọ naa n gbe ṣe ni ipinlẹ kogi.",20 owewe 2022,alaga ijọba ibilẹ okene ti paṣẹ fun awọn eleto aabo lati ṣewadii ile ijọsin pasitọ peter michonza. +"falana sọ̀kò ọ̀rọ̀ sì agbẹnusọ ọlọ́pàá tó ní aráàlù kò le gbẹ̀san, bí ọlọ́pàá bá gbá a létí","oríṣun àwòrán, others gbajugbaja agbẹjọro to n ja fun ẹtọ ọmọniyan, femi falana ti bu ẹnu atẹlu lu ọrọ kan ti agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, olumuyiwa adejobi sọ lori ayelujara lori bi awọn ọmọ orilẹede naijiria kan ṣe ṣe ikọlu si awọn ọlọpaa. adejobi ni ọlọpaa to ba wa ninu asọ idanimọ rẹ ni ẹtọ lati gba oju ẹnikẹni, ti ko si yẹ ki ẹnikẹni le ṣe ikọlu ọlọpaa. o tẹsiwaju pe arifin, abuku ati tita ẹrẹ si orilẹede naijiria ni ki awọn ọmọ orilẹede naijiria maa gbiyanju lati ṣe ikọlu si ọlọpaa. “ti ọlọpaa to ba wa ninu asọ idanimọ rẹ ba gba oju araalu, ẹni naa ko ni anfani lati gba ẹsan. si ṣe ikọlu si ọlọpaa ni o da bi pe eeyan ṣe ikọlu su orilẹede naijiria. “abuku yii ki n ṣe ti ọlọpaa nikan sugbọn gbogbo orilẹede naijiria. “o lo di ofin, ti o si sapejuwe ẹni to ba ṣe bẹẹ gẹgẹ bi ọdaran.” oríṣun àwòrán, @princemoye1 nigba ti yoo fesi si ọrọ naa, femi falana ni si ṣe ikọlu si ọmọ orilẹede naijiria labẹ ofin ni ijiya ọdun mẹẹdọgbọn ni ọgba ẹwọn, ti ko si yọ ileeṣẹ ọlọpaa silẹ. falana ni labẹ ofin ọdaran lọdun 2015 ati ti ileeṣẹ ọlọpaa ti ọdun 2020, ko fi aye gba ọlọpaa tabi awọn agbofinro yoowu lati ṣe ikọlu si ẹnikẹni. “koda ẹni ti ile ẹjọ ko ti da lẹbi ni anfani si ofin yii, awọn ko gbọdọ fi iya jẹ ẹnikẹni ni ọna aitọ. “ninu iwe ofin orilẹede naijiria, ẹni to ba ti jẹ ọmọ orilẹede yii ni wọn ni anfani si ẹtọ ọmọniyan, wọn ko si gbọdọ fi iya jẹ wọn ni ọna aitọ “ijiya fun ẹnikẹni ti wọn ba ba iwa ibajẹ naa lọwọ rẹ ni yoo fi ẹwọn ọdun mẹẹdọgbọn gbara tabi ko san owo itanran.” falana wa rọ awọn ọmọ orilẹede naijiria lati dẹkun sise ikọlu si awọn ọlọpaa nitori ohun naa ni ijiya tiẹ labẹ ofin. o ni ọdun mẹta ni ẹnikẹni to ba se ikọlu si ọlọpaa labẹ ofin.",19 owewe 2022,amofin femi falana ti bu ẹnu atẹlu lu ọrọ kan ti agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa sọ lori pe ọmọ naijiria ko gbọdọ gbẹsan bi ọlọpaa ba gba wọn leti. +evans rí ẹ̀wọ̀n ọdún mọ́kànlélógún hé fún ẹ̀sùn ìjínigbé,"ile ẹjọ giga nipinlẹ eko ti ran ajinigbe, chukwudumeme onwuamadike, ti ọpọ mọ si evans lọ si ẹwọn ọdun mọkanlelogun. bakan naa ni amugbalẹgbe rẹ, victor aduba yoo se ẹwọn iye ọdun kan naa pẹlu evans fun bi wọn ṣe ji okunrin kan ti orukọ rẹ jẹ sylvanus hafia gbe pamọ. adajọ oluwatoyin taiwo lo gbe igbẹjọ naa kalẹ niluu eko loni ọjọ aje, ọjọ kọkandinlogun, oṣu kẹsan an ọdun 2022. ọwọ tẹ awọn ajinigbe naa lọdun 2014 ni agbegbe kara ni amuwo odofin niluu eko lẹyin ti wọn ji hafia gbe. awọn ajinigbe naa tun beere owo itusilẹ milọnu mẹji dọla, owo ilẹ okeere. awọn olujẹjọ mejeeji naa lo sọ fun ilẹẹjọ giga ipinlẹ eko pe awọn ko jẹbi ẹsun mẹrin ti wọn fi kan wọn. nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, adajọ taiwo ni igbẹjọ naa ni yoo jẹ ẹkọ fun awọn yooku to lọwọ ninu iwa ajinigbe ni naijiria. blind human right activist: temitope oyejobi ní ọ̀sán ayé òun ni ìyọnu ojú náà bẹ̀rẹ̀ saaju ni ọwọ sinkun ọlọpa ti tẹ evans ati amugbalẹgbẹ rẹ fun ẹsun ijinigbe lọjọ kẹwa osu kẹfa ọdun 2017. lẹyin atotonu ikọ olupẹjọ ati olujẹjọ, ni adajọ hekeem oshodi tileẹjọ giga ipinlẹ eko ti sọ evans ati amugbalẹgbẹ naa sẹwọn gbere. ọjọ kejilelogun osu keji ọdun 2022 si ni idajọ naa waye, idi si ree ti evans se pe ẹjọ kotẹmilọrun lori idajọ naa. nibayii, adajọ ti wa ni ki evans ati amugbalẹgb rẹ lọ lo ọdun mọkanlelogun lọgba ẹwọn, dipo ẹwọn gbere ti ile ẹjọ akọkọ kọkọ da fun wn.",19 owewe 2022,adajọ taiwo ni igbẹjọ naa ni yoo jẹ ẹkọ fun awọn yooku to n lọwọ ninu iwa ajinigbe ni naijiria. +ìjọba ya èèyàn 100 sọ́tọ̀ ní ghana tórí àrùn pọ̀jẹ̀-pọ̀jẹ̀ marburg,"ijọba orilẹede ghana ti fi eeyan bii ọgọrun si ipamọ lẹyin tawọn osisẹ eleto ilera fidi rẹ mulẹ pe eeyan meji ti ko kokoro arun iba asekupani marburg awọn alasẹ orilẹede naa ni eeyan meji ti ku sile iwosan lẹkun guusu ashanti lẹyin ti wọn ko kokoro arun iba pọ̀jẹ̀-pọ̀jẹ̀ naa, eyi to fi ara jọ arun ebola. amọ ẹyẹ adan ni iwadii sọ pe o n se okunfa iba buruku yii, tawọn alasẹ si ti n laago ikilọ pe ki wọn takete sawọn iho ti awọn ẹyẹ yii lugọ si. isẹlẹ iba pọjẹ-pọjẹ to bẹ silẹ lorilẹede ghana yii ni isẹlẹ keji ti yoo waye lawọn orilede to wa lẹkun iwọ oorun afirika. bẹẹ ba gbagbe, a mu iroyin wa fun yin ni ọdun to kọja pe arun iba pọjẹpọjẹ marburg bẹ silẹ lorilẹede guine.",18 agẹmo 2022,"isẹlẹ iba pọjẹ-pọjẹ to bẹ silẹ ni ghana yii ni isẹlẹ keji ti yoo waye lẹyin ti guinea, lawọn orilẹede to wa lẹkun iwọ oorun afirika." +"ooru àmújù ń peléke si nílẹ̀ yúróòpù, gbogbo ìlú gbóná janjan","àwọn orílẹ̀ èdè ní ẹkùn ìwọ̀ oòrùn ilẹ̀ yúróòpù ti ń gbóná tayọ ààlà bí afẹ́fẹ́ gbígbóná ṣe ń wọ́ lọ sí ẹkùn árìwá. wọ́n ti ṣèkìlọ̀ fún àwọn ènìyàn orílẹ̀ èdè france àti united kingdom láti múrá digbí de ooru tí yóò mú. ẹkùn árìwá spain ní òhun ti ń gbóná tayọ bí òdiwọ̀n ojú ọjọ́ rẹ̀ ṣe ti wọ 43c báyìí. iná ńlá ti bẹ́ sílẹ̀ ní àwọn apá ibì kan ní france, portugal, spain àti greece ní èyí tó ti ń mú kí àwọn ènìyàn sá kúrò nílé wọn. orílẹ̀ èdè britain ni ìrètí wà pé ooru tí yóò mú níbẹ̀ lónìí yóò lágbára ju ti àtẹ̀yìnwá lọ gẹ́gẹ́ bí àwọn onímọ̀ ṣe sọ àti pé france yóò gbóná gidi gan. ènìyàn méjì ló ti pàdánù ẹ̀mí wọn lẹ́kùn zamora ní ìwọ̀ oòrùn árìwá spain sọ́wọ́ iná tí wọ́n si ti ṣe ìdádúró ọkọ̀ ojú irin ní wíwọ̀ nítorí ọ̀nà tí yóò gbà súnmọ́ iná púpọ̀. obìnrin kan àti ọkọ̀ rẹ̀ náà pàdánù ẹ̀mí nígbà tí wọ́n fẹ́ sa kúrò ní ilé wọn nítorí bí iná tó ń fa ooru púpọ̀ ní portugal. ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn ló ti sá kúrò ní ilé wọn ní orílẹ̀ èdè yìí. bákan náà ọ̀pọ̀ ẹranko ni wọ́n ti kó kúrò ní ibùgbé wọn. oríṣun àwòrán, getty images awọn onimọ nipa bi oju ọjọ se ri nilẹ united kingdom ti kede pe oju ọjọ yoo mooru pupọ nil naa, ti odiwọn boju ọjọ se ri yoo si jẹ 41c. ileesẹ to n tọpinpin bi oju ọjọ se ri ti wa fi ewe ọmọ mọ awọn olugbe ilẹ gẹẹsi leti pe ilẹ naa yoo gbona janjan lonii ọjọ aje ati ni ọla ọjọ isẹgun. bakan naa ni wọn kede pe oju ọjọ naa yoo mooru pupọ bẹrẹ lati ilu london titi de york ati manchester. odiwọn 38.7c ni oju ọjọ to tii gbona julọ nilẹ uk eyi to waye lọdun 2019. ikede yii si ni wọn tun fi n sekilọ fun gbogbo awọn agbegbe to wa nilẹ gẹẹsi, wales ati scotland pe oju ọjọ yoo mooru pupọ lagbegbe tiwọn naa. oríṣun àwòrán, getty images nibayii, o ti foju han pe ilu london ni yoo jẹ ọkan lara awọn agbegbe to mooru julọ lagbaye nitori bi odiwọn oju ọjọ rẹ se gbona ju agbegbe sahara ati caribbean lọ. bakan naa ni awọn onimọ nipa oju ọjọ tun ti sọ asọtẹlẹ pe ilu london ju ilu dakhla lagbegbe iwọ oorun sahara lọ eyi ti odiwọn oju ọjọ rẹ jẹ 24c. awọn agbegbe miran ti london yoo tun mooru julọ ni nassau to wa lagbegbe bahamas to jẹ 32c, kingston nilẹ jamaica to jẹ 33c, malaga lorilede spain to jẹ 28c ati athens ni greece tii se 35c. saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe awọn panápaná ti ń ṣiṣẹ́ takuntakun láti fòpin sí iná ńlá tó ṣẹ́yọ nítorí ooru tó ń bá wọn fínra ní orílẹ̀èdè portugal, spain àti apá kan france. ní ẹkùn àríwá portugal, awakọ òfurufú kan pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ nígbà tí ọkọ̀ òfurufú tó fi ń fi omi pa iná náà já lulẹ̀ ní foz coa lẹ́bàá ẹnubodè spain. kò dín ní ẹgbẹ̀rún méjìlá ènìyàn ló ti sa kúrò ní agbègbè gironde ní france bí iná tó lágbára ṣe ń báwọn fínra níbẹ̀ náà. ní gúúsù spain, lẹ́gbẹ̀ẹ́ costa del sol àwọn ènìyàn tó ti sá kúrò níbẹ̀ ti tó 2,300 nítorí bí iná tó lágbára ṣe ń yawọ orí òkè mijas. ashley baker, ọmọ orílẹ̀èdè britain tó ń gbé ní mijas sọ fún bbc pé ọwọ́jà iná náà pọ̀ gan ní ọjọ́ ẹtì tó sì ń yàbọ̀ sí ọ̀nà ọ̀dọ̀ òun ṣùgbọ́n tí ìjì líle bá òun le lọ. baker ní àwọn ọkọ̀ òfurufú ti ń sọ àwọn ohun èlò ìpaná sí agbègbè náà tí wọ́n sì ń bu omi ọ̀sà láti pa á. ""kò dín ní ogójì ilé tó wà ní agbègbè wa tí gbogbo ènìyàn sì wà ní inú fu, àyà fu báyìí. karyn tó ń gbé ní teste-de-buch ní ẹkùn ìwọ̀ oòrùn gúúsù france sọ fún àwọn akọ̀ròyìn wí pé òun kò tíì rí irú iná bẹ́ẹ̀ rí. àwọn ènìyàn ń fi ilé wọn sílẹ̀ bíi ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá àwọn ènìyàn ló ti fi ibùgbé wọn sílẹ̀ tí ohun tí wọ́n rí mú kúrò kò ju aṣọ tó wà ní ọrùn wọn lọ. nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, manon jacquart ní ọjọ̀rú ni òun kúrò ní ibùdó tí òun ti ń ṣiṣẹ́ tí òun sì ti dèrò teste-de-buch ní france. jacquart ní òun ń gbìyànjú láti mú ọkàn òun le ṣùgbọ́n ẹ̀rù ń ba òun nítorí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ náà. láti ọjọ́ ìṣẹ́gun ni gbogbo ìlú ti ń gbóná janjan ní portugal àti spain. àwọn tó ti ku ní orílẹ̀ èdè méjéèjì ti lé ní 300. bákan náà ni ìjọba italy ti kéde pé nǹkan kò rọgbọ ní agbègbè po valley. ní ẹkún àríwá morocco, àwọn ènìyàn ti ń fi ìlú sílẹ̀ nítorí bí iná ṣe ti gba larache, ouezzane, taza àti tetouan. ìlú kan parun tán ní agbègbè ksar el kebir sọ́wọ́ tí ènìyàn kan sì ti pàdánù ẹ̀mí rẹ̀.",19 agẹmo 2022,"awọn onimọ nipa bi oju ọjọ se ri ti wa kede pe ooru pupọ yoo wa ni uk, france, spain, greece àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ." +who kéde ìkìlọ pàjáwìrì jakèjadò àgbáyé lórí ààrùn monkey pox,"oríṣun àwòrán, getty images ajọ ilera lagbaye who ti fi ikede pajawiri sita lori aarun monkey pox lagbaye. ikede yi si ni eleyi to gajulọ ti ajọ naa le fi sita ko si sẹyin bi aarun naa ṣe kale kako lagbaye. ikede yi ti wọn sọ di mimọ lẹyin ipade ẹlẹẹkeji igbimọ pajawiri aarun naa sọ pe eeyan ẹgbẹrun mẹrindinlogun lo tilugbadi monkey pox lorileede marundinlọgọrin lagbaye. ọga agba who dokita tedros adhanom ghebreyesus lo sọ bẹẹ. nibi ọrọ de duro who sọ pe eeyan marun un ni o padanu ẹmi wọn latara arun yi. ni bayi, awọn arun to ni iru ikede pajawiri yi lagbaye ko ju meji lọ, coronavirus ati igbiyanju lati mu opin ba aisan rọpa rọsẹ lagbaye taa mọ si polio. dokita tedros ni igbimọ pajawiri naa ko ti ribi fẹnuko boya ki wọn ka aarun monkey pox gẹgẹ bi aarun ti ajakalẹ rẹ kaakiri agbaye. ko fi gbogbo ara ye wọn bi itankalẹ aarun yi ṣe n gbalẹ gẹgẹ bi dokita tedros ti ṣe sọ. o ni ayẹwo taa ṣe fihan pe ewu itankalẹ yi ko kọja agbara kaakiri agbaye ayafi lawọnn agbegbe ilẹ yuroopu nibi ti ewu yi ti lagbara ju a ko ni ẹri pe aarun yi le tankalẹ jakejado agbaye a ko si le sọ pe yoo ṣakoba fun lilọ bibọ awọn eeyan lagbaye nitori eleyi ko kọja agbarta lasiko yi o kere tan who ti kede pe wọn ri eeyan mejilelaadọrin to ti lugbadi aarun yi ni yuroopu,amẹrika,canada,australia. wọn si ti se iwadii eeyan mejidinlọgbọn ti wọn furasi pe o lugbadi aarun yi lawọn orileede mejila ti monkeypox kii saba ran kaakiri. sugbọn sa, awọn onimọ ni eleyi kii se bi ajakalẹ covid-19 ati pe awọn ni ikapa lori ajakalẹ yi. monkeypox jẹ aarun ti kokoro aifojuri monkeypox le sokunfa rẹ. o yatọ si kokoro aifojuri smallpox sugbọn oun ko buru to arun igbona smallpox . lagbegbe aarin gbungbun ilẹ afrika lo wọpọ si ati iwọ oorun ilẹ afrika ni paapa lawọn agbegbe ti igbo kijikiji wa. ni orileede dr congo lawọn ibi ti igbo kijikiji wa, wọn ti kede pe o leni eeyan 1,200 to ti ko aarun yi lọdun yi nikan. wọn ni akọsilẹ eeyan mẹtadinlọgbọn to ku laarin ọjọ kini osu kaarun 2022 gẹgẹ bi who se sọ. amọ lọwọ lọwọ bayi, awọn ilẹ yuroopu lo wa ninu ewu julọ lọwọ arun yi bayi lagbaye.",23 agẹmo 2022,monkeypox jẹ aarun ti kokoro aifojuri monkeypox le sokunfa rẹ.o yatọ si kokoro aifojuri smallpox sugbọn oun ko buru to arun igbona smallpox . +sri lanka yan ààrẹ tuntun lẹ́yìn tí ààrẹ tẹ́lẹ̀ sálọ lásìkò ìwọ́de aráàlú,"awọn asofin orilẹede sri lanka ti yan olootu ijọba, ranil wickremesinghe gẹgẹ bii aarẹ tuntun fun orilẹede naa. wickremesinghe yii ni yoo maa koju isẹ bi yoo se mu orilẹede naa kuro ninu ọfin ọrọ aje to dagun, eyi to jin si. igbesẹ naa lo waye lẹyin ifẹhonu han alagbara to waye lati ọdọ araalu fun ọpọlọpọ osu. aarẹ tẹlẹ ni ilẹ sri lanka, gotabaya rajapaksa si ti sa kuro lorilẹede naa lọsẹ to kọja. orilẹede maldives lo kọkọ morile, ko to rekọja lọ si singapore lẹyin ti ẹgbẹlẹgbẹ araalu jade sita lati se iwọde. awọn olufẹhonuhan naa lo ya wọ ilegbe aarẹ, atawọn ileesẹ ijọba miran, ti wọn si n beere pe ki aarẹ kọwe fipo silẹ. bakan naa ni wọn n beere pe ki wickremesinghe, ti wọn yan sipo olootu ijọba losu karun ọdun yii, kọwe fipo rẹ silẹ. awọn oluwọde naa lo jo ile adani aarẹ, ti wọn si tun lọ ka mọ ọọfisi to n lo bii olootu ijọba, eyi to wa ni colombo lati se iwọde tako ilana isejọba rẹ. amọ awọn oluwọde naa ni o di dandan ki olootu ijọba naa lọ lẹyn ti aarẹ gotabaya rajapaksa kọwe fipo silẹ. ipenija nla ni olootu ijọba naa n koju lati ọdọ dullas alahapperuma, tii se asofin kan lati inu ẹgbẹ to n se isejọba lọwọ amọ ti ẹgbẹ alatako gboogi nilẹ naa, n se atilẹyin fun lati di aarẹ. aarẹ wickremesinghe ni yoo pari saa isejọba rajapaksa, eyi ti yoo wa sopin losu kọkanla ọdun 2024. orilede sri lanka lo ti jẹ gbese pupọ, to si tun n koju ọwọn gogo ounjẹ, epo bẹntirolu atawọn ohun eelo amayedẹrun miran.",20 agẹmo 2022,"aarẹ tuntun, wickremesinghe ni yoo pari saa isejọba aarẹ tẹlẹ, rajapaksa, eyi ti yoo wa sopin losu kọkanla ọdun 2024." +wo ohun tó yẹ ko mọ̀ nípa àrùn pọ̀jẹ̀-pọ̀jẹ̀ marburg tó ń yára ṣekú pani,"bi ajakalẹ arun coronavirus to ba ilẹ afirika finra se n palẹmọ kuro, arun mii ti wọn n pe ni marburg, tun wọle de. awọn oṣiṣẹ eleto ilera lorilẹede guinea ti fidi rẹ mulẹ pe arun margurg ti gba orilẹede naa wọ apa iwọ oorun afirika. l.ọwọlọwọ bayii, ijọba orilẹede ghana ti fi eeyan bii ọgọrun si ipamọ lẹyin tawọn osisẹ eleto ilera fidi rẹ mulẹ pe eeyan meji ti ko kokoro arun iba asekupani marburg yii. idi ree ti bbc yoruba fi se akọjọpọ koko pataki to jẹ kẹ mọ ni[pa arun asekupan marburg, ohun to n faa, ami idamọ rẹ ati ibi to ti sẹ wa. oríṣun àwòrán, getty images ilu kekere kan ti wọn n pe ni marburg to wa ni orilẹede west germany ni wọn ti kọkọ kẹẹfin arun asekupani naa ldun 1967. awọn eeyan to kọkọ fori sọta arun yii ni wọn jẹ osisẹ ileesẹ nla kan to n se abẹrẹ ajẹsara nilu marburg naa. akọsilẹ ni lasiko ti awọn osisẹ naa n sisẹ lọwọ, ni wọn se alabapade ẹjẹ tabi isan lati ara awọn ọbọ to wa lati agbegbe ila oorun afirika. awọn ọbọ naa si ni wọn ni wọn ti ni arun asekupani kan to fara pẹ arun ebola. lẹyin o rẹyin, eeyan mejilelọgbọn lo ko arun naa laarin awn osisẹ yii, ti meje si dagbere faye laarin wọn. wọn ni ẹbi kan naa ni arun marburg ati ebola to ti ṣọṣẹ sẹyin l afirika jẹ, amọ arun margurg tete maa n tan kalẹ bi ina inu ọyẹ. ajọ eleto ilera lagbaaye, who ni kokoro arun yii ko ṣe wo loju rara nitori bi o ti maa n ṣọṣẹ. arun marburg ni a gbọ pe o maa n ran awọn eeyan lati ara ẹyẹ adan to n jẹ eso. arun marburg yii, to ti ran eeyan to le ni ogoje sọrun lorilẹede angola lo ni awọn ami idamọ ta gbọdọ tete fiyesi. arun yii si ni iwadi sọ pe o wọpọ lara ẹyẹ adan ati oniruuru ọbọ bii aaya, inaki, lanbẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ. lara awọn ami idamọ arun marburg ni ori fifọ, iba, otutu, ara riro, egbo ni ọna ọfun ati ki ara maa rẹ eeyan. awọn ami idamọ yoku ni igbẹ gbuuru, eebi ati inu rirun. bakan naa ni awọn eeyan miran to ba ni arun marburg ni oju wọn maa n pọn bii ẹjẹ,ti wọn yoo si maa se esuke. koda, iwadi imọ ijinlẹ nipa arun naa ni o seese ki ẹni to ni arun marburg maa pọ ẹjẹ sinu tabi sita. lọwọ bayii, ko tii si abẹrẹ ajẹsara to le dena arun naa. oríṣun àwòrán, getty images ọdun 1975 ni arun marburg tun sẹyọ nilẹ afirka, lorilẹede kenya nigba ti ọkunrin kan dero ile iwosan pẹlu awọn arun naa to suyọ lara rẹ. se lo ni arun iba, ẹyin riro, ti ko si le mi daada, to si tun n pọ ẹjẹ eyi to mu ko ku laarin makati mẹfa ti arun naa mu. lẹyin ọjọ kẹsan ti alaisan naa ku, ni dokita to se itọju rẹ naa bẹrẹ aisan to fara pẹ arun marburg yii bi o tilẹ jẹ pe ori ko yọ ni tiẹ. arun marburg maa n ran lati eeyan kan si ẹlomiran nipa omi ara bii oogun, itọ tabi ikun. arun yii maa n fa ailera to lagbara, iba, koda o maa n jẹ ki ẹjẹ jade lara ẹlomiran. ayẹwo ẹjọ ti wọn ṣe fun ẹnikan to ku nile iwosan lorilẹede guinea fihan pe arun marburg lo ṣekupa ẹni naa. dokita ajọ who kan, matshidiso moeti ṣalaye pe arun marburg lagbara lati tan kalẹ kaakiri debi to jina. iwadii n lọ lọwọ lati mọ awọn eeyan ti ẹni ti arun marburg yii ni ibaṣepọ pẹlu ki o to dagbere faye. ijọba orilẹede guinea ti ṣe itaniji awọn ilana ati dẹkun ebola nibẹ lati le koju arun marburg.",18 agẹmo 2022,"ajọ eleto ilera lagbaaye, who ni kokoro arun marburg ko ṣe wo loju rara nitori bi o ti maa n ṣọṣẹ." +tea àti omi iyọ̀ ni èròjà tí orílẹ̀-èdè yìí fí n kojú ààrùn covid-19,"oríṣun àwòrán, epa oṣiṣẹ ijọba to n fin oogun apa kokoro si ara ọkọ ni pyongyang orileede north korea n koju ajakalẹ aarun covid-19 pẹlu bi ọpọ eeyan ko se gba abẹrẹ ajẹsara ti wọn ko si lanfaani oogun to n koju aarun yi. ni ibẹrẹ ọdun 2020 ni orileede naa ti ibode rẹ lati le dena kawọn eeyan ko aarun naa wọ ilẹ wọn. titi di asiko yi, awọn olori ilẹ naa ti lawọn ko fẹ iranwọ lati ọdọ araata. bẹẹ naa ni ileeṣẹ iroyin ilẹ naa ti daba kawọn eeyan maa lo oogun ibilẹ fi koju nkan ti wọn pe ni iba wo awọn nkan ti wọn da laba faraalu lati fi koju aarun covid-19. fun awọn to ba rẹ gidi gaan,ileeṣẹ iwe iroyin ilẹ naa rodong simnun daba pe ki wọn lo omi gbona pẹlu ginger,oyin tabi nkan mii. oríṣun àwòrán, getty images lootọ mimu nkan gbigbona le dẹkun awọn apẹrẹ covid-19 bi ikọ ọfun didun to si le jẹ ki omi pada si ara eeyan to ba ti padanu omi ara. ginger naa ati ewe kan ti wọn n pe orukọ rẹ ni willow leaf naa a maa di inira ku lara. ṣugbọn wọn kii ṣe oogun itọju aarun yi ileeṣẹ iroyin ilẹ naa ba awọn tọkọtaya kan to da lilo omi ti wọn da iyọ sinu rẹ laarọ ati lalẹ. tori naa wọn tifi ẹgbẹgbrun tọọnuiyọ ranṣẹ si pyonyang lati fi peelo oogun gẹgẹ bi ileeṣẹ iroyin ilẹ naa ṣe jabọ awọn iwadii kan fi han pe bi eeyan ba gbo omi iyọ jigi lọna ọfun eleyi le koju kokoro aifojuri to ba n fa ọfikin. amọ ko si ẹri to fihan pe eleyi le dẹwọ itankalẹ covid-19. oríṣun àwòrán, reuters omi ọsẹ abufọnu le pa awọn kokoro gẹgẹ bo ṣe fihan ninu laabu nigba ti wn fi ṣe iwadii kan. amọ eleyi ko daju pe yoo le koju kokoro yi lara awọn eeyan. awọn eeyan maa n ko aarun covid-19 nipa fifa atẹgun wọ imu wọn tabi ẹnu.tori naa gbigbo omi jigi le koju ọna kan ṣoṣo. ti kokoro yi ba si ti wọle, niṣe lo maa n rẹsi ni ti yoo si wọ inu awọn ẹya ara mii nibi ti gbigbo omi jigi lẹnu lo le de ileeṣ iroyin ilẹ naa tun sọ pe kawọn eeyan maa lo oogun ara riro bi ibuprofen ati oogun apa kokoro bi amoxicillin ati awọn miran. oríṣun àwòrán, getty images ibuprofen ati paracetamol le mu ki ara to n gbona walẹ ti a si tun maa koju awọn apẹrẹ mii bi ori fifọ ati ọfun didun. amọ wọn ko le mu kokoro covid-19 kuro tabi ki wọn kọdi idagbasoke rẹ. oogun to n pa kokoro wa fun awọn kokoro bakiteria kii se fun awọn kokoro virọọsi.",20 èbibi 2022,"bi itankalẹ aarun yi ṣe n peleke si, ileeṣẹ iroyin lorileede naa ti n rọ awọn eeyan lati lo oogun ibilẹ fi koju rẹ." +u.s. yóò máa fún àwọn ọmo nàìjíríà kan ní físà ìwé ìrìnnà láì ṣe ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò,"oríṣun àwòrán, getty images àjọ ilẹ̀ amẹrika ní àwọn ń ṣe àyípadà sí ètò fífúnni ní visa lójúnà à ti ṣe ìrànwọ́ fún àwọn tí kò ní èròǹgbá láti máa gbe ilẹ̀ amẹrika láti máa ṣe sí ìwé ìrìnnà wọn láì ní ṣe ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò mọ́. ní inú oṣù kejì ní ètò tuntun yìí yóò bẹ̀rẹ̀ ní ìpínlẹ̀ eko kí wọn tó tarí rẹ̀ sí abuja. ṣaájú àkókò yìí, àwọn tó bá fẹ́ gba ìwé ìrìnnà lọ sí amẹrika máa ń nílò láti yọjú sí embassy ní abuja tàbí ilé iṣẹ́ àjọ náà ní ìpínlẹ̀ eko fún ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò. ìyàtọ̀ yóò wà báyìí? gẹ́gẹ́ bí àtẹ̀jáde tí àjọ ilẹ̀ amẹrika fi síta, iye ènìyàn tó ma le jẹ àǹfàní ètò yìí ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ kò ní tó nǹkan ṣùgbọ́n tí èyí yóò yí padà tí ètò náà bá ti dé abuja. àjọ náà ní ènìyàn kan nínú mọ̀lẹ́bí ní yóò wá fi àwọn ìwé ẹ̀rí wọn lélẹ̀, àwọn ọmọdé kò nílò láti wá. alhaji shanko bákan náà ni wọ́n ní ó ṣeéṣe kí ìgbésẹ̀ náà máa gbà tó oṣù méjì báyìí ṣùgbọ́n ìrètí wà pé kò ní máa ju ọ̀sẹ̀ pérete lọ tó báyá. bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n sọ pé ẹni náà kò ní le gba àwọn ìwé náà padà àyàfi tí gbogbo ètò bá parí. eba ta ni ó le jẹ àǹfàní yìí? àwọn tó le ṣe àtúnṣe sí ìwé ìrìnnà wọn láì ṣe ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò ní àwọn tó ń fẹ́ b1/b2, f, m, j (àwọn akadá nìkan) h, l or c1/d tí wọ́n sì gbọdọ̀ ní àwọn nǹkan wọ̀nyìí : - nàìjíríà ni wọ́n ti gbọdọ̀ kọ́kọ́ fun ni visa lákọ̀kọ́. - èyí ó ń bèèrè fún gbọ́dọ̀ jẹ́ nǹkan kan náà pẹ̀lú èyí ó ti gbà tẹ́lẹ̀. olùdíje gómìnà apc -tí ọjọ́ bá ti lọ lórí visa náà láàárín oṣù 24 tábi tí ó bá ku oṣù mẹ́ta tí ọjọ́ yóò lọ lórí rẹ̀. - tí o ba ní pásípọ̀ọ̀tì t fún gbogbo ìgbà tí o lo visa náà àti ìgbà tí ó fẹ́ fi lò ó. - tí wọn kò bá tí ì mú ẹ fún ẹ̀ṣẹ̀ kankan ní amẹrika rí, kódà bí wọ́n bá yááfì rẹ. - tí o kò bá ti ṣiṣẹ́ láì ní àṣẹ ilẹ̀ amẹrika tàbí lò jù ìgbà tí wọ́n fún ọ lọ. ogun king killing: baálẹ̀ agodo ní ààrin ẹ̀gẹ́ ni òun sùn mọ́jú, tí òun kò sì rí aya, ọmọ ìgbésẹ̀ tí ènìyàn yóò tẹ̀lẹ́: ènìyàn yóò kọ́kọ́ san owó fún ètò visa náà lórí ẹ̀rọ ayélujúra tàbí sí ilé ìfowópamọ́ ṣaájú kí wọ́n ó tó bèrè fún visa. ẹni tí ó bá ní gbogbo àwọb nǹkan tó nílò wọ̀nyìí yóò lọ sórí ẹ̀rọ ayélujúra us láti ṣe àwọn ìgbésẹ̀ tó kàn.",1 èrèlè 2022,wo àwọn tó le jẹ ànàfàní físà ìwé ìrìnnà láì ṣe ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò naa. +bí ọ̀rọ̀ ṣe bẹ̀rẹ̀ sí ní dàrú ní naijiria rèé ...,"aarẹ akọkọ fun ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ nlc sọ bí ọ̀rọ̀ ṣe bẹ̀rẹ̀ sí ní dàrú ní naijiria aarẹ akọkọ fun ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ lapapọ lorilẹede naijiria, ọgbẹni hassan adebayo sunmọnu ti sọ bi eto ọrọ aje orilẹede naijiria ṣe wọ wa lati ibẹrẹ. ọgbẹni sunmọnu lasiko ifọrọwerọ pẹlu ileeṣẹ bbc news yoruba ni ikọ ologun to gba ijọba ni naijiria lo ba ọrọ aje naijiria. ninu ọrọ rẹ, o ni eto iṣejọba naijiria ki awọn ologun to gbajọba fi aye silẹ ni awọn ipinlẹ fun idagbasoke eto ọrọ aje wọn amọ o ni kete ti awọn ologun gbajọba ni wọn kede pe ohun gbogbo to niiṣe pẹlu eto ẹkọ, ilera ati ọrọ aje ti da ti ijọba apapọ. bakan naa lo ni ijọba ologun to sọ ipinlẹ mẹta da ipinlẹ mejidinlogun ni wọn bẹrẹ si ni fi owo naijiria tọju awọn oloṣelu. ẹkunrẹrẹ fidio naa wa nibi.",wákàtí kan sẹ́yìn,"aarẹ akọkọ fun ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ lapapọ lorilẹede naijiria, ọgbẹni hassan adebayo sunmọnu ti sọ bi eto ọrọ aje orilẹede naijiria ṣe wọ wa lati ibẹrẹ." +ní yàjóyàjó ìró ìbọn tó n dun lákọ-lákọ nílé ààrẹ dá ìpayà sílẹ̀ ní burkina faso,"and we ll keep you signed in. sign in or register you need one to watch live tv on any channel or device, and bbc programmes on iplayer. it’s the law. nípasẹ̀ adedayo owolabi, funmi jokotade àti olubusola afolayan gbogbo àkókò tí a kọ jẹ́ ti uk lakọlakọ ni iro ibọn n dun nitosi ibudo ọmọ ogun kan nilu ouagadougou, lorilẹ-ede burkina faso ni owurọ ọjọ ẹti. ileeṣẹ agbohunsafẹfẹ orilẹ-ede naa, la radiodiffusion télévision du burkina, si ti dawọ igbohunsafẹfẹ duro. iroyin yii jade lẹyin ti ọpọ ọmọ ogun ti ku nileeṣẹ ọmọ ogun orilẹ-ede naa lati ọsẹ diẹ sẹyin. inu iporuru ọkan si ni awọn olugbe orilẹ-ede naa wa bayii pẹlu bi iro ibọn ṣe n dun lati baraaki ologun ti baba sy to wa ni olu ilu orilẹ-ede naa, ouagadougou. ileeṣẹ iroyin afp sọ pe ibọn n dun ni ile aarẹ, ati olu ileeṣẹ ologun to ditẹ gbajọba to waye laipẹ yii. gbogbo awọn opopona nla to wa nilu naa si ni awọn ọmọ ogun ti di pa. lọwọlọwọ, a ko tii le sọ ẹni to paṣẹ kiko awọn ọmọ ogun si aarin ilu ati ile aarẹ. amọ nkan to daju ni pe lọjọ aje nikan ṣoṣo, oku ọmọ ogun mọkanla ati ti aadọta araalu ni wọn ri ni ilu djibo, lẹyin ti awọn kan dena de awọn ologun. oṣu kinni, ọdun yii ni ọgagun paul-henri sandaogo damiba ditẹ gbajọba, pẹlu ileri pe oun yoo fi opin si igbesunmọmi awọn alakatakiti ẹsin islam to bẹrẹ lọdun 2015. ṣugbọn titi si akoko yii, rogbodiyan ko tii dawọ duro nibẹ. ilé ẹjọ́ gíga ní kí oriade ní eko lọ sí ẹ̀wọ̀n ọdún 15 adajọ hakeem oshodi ti ile ẹjọ giga ni eko ti gbe idajọ kalẹ pe ki baalẹ shangisha, mutiu ogundare, fi aṣọ penpe roko ọba fọdun mẹẹdogun lori ẹsun pe o pete pero ijinigbe ara rẹ. iwa to hu yi gẹgẹ bi adajọ ṣe wi ṣakoba omi alaafia ilu. bakan naa ni ile ẹjọ tun ran ọkan lara awọn aburo rẹ adams mohammed naa lẹwọn. gẹgẹ bi awọn to gbe ẹjọ yi lọ siwaju ile ẹjọ ṣe wi wọn ni ọjọ karun un oṣu keje ọdun 2017 ni baalẹ pete yi. wọn ṣalaye pe ogundare jọwọ ara rẹ ki wọn baa le jiigbe lna ti da omialaafia ilu ru. koda wọn ni iyawo rẹ ati aburo rẹ lọwọ ninu fiimu ti wọn po pọ yi. toriu iwa to hu lọjọ naa lọhun, gomina ipinlẹ eko to wa lori aleefa akuinwumi ambode yọ nipo rẹ gẹgẹ bi balle shangisha. ninu idajọ ti adajọ oshodi gbe kalẹ, o ni ki ogundare lọ sẹwọn ọdun mẹwaa fun ẹsun akọkọ lallae si anfaani owo faaini. fun ẹsun keji o ni ko lọ sẹwọn ọdun kan pẹlu anfaani lati san owo faaini ẹgbẹrun lọna igba naira. akọrin takasufe raapu lorileede amẹrika coolio ti jade laye. akọrin yi ti ọpọ ranti fun orin rẹ gangsta s paradise dagbere fun duniya lẹni ọdun mọkandinlọgọta. ọrẹ rẹ ọlọjọ pipẹ jarez posey sọ fawọn akọroyin ni amẹrika pe awọn ba oku rẹ ni ilẹẹlẹ baluwe ile ọrẹ rẹ to wa ni los angeles. lati nkan bi ọdun 1980 ni coolio ti bẹrẹ iṣẹ orin ṣugbọn o fẹsẹ rinlẹnile agodo nigba to gbe orin gangsta paradise jade lọdun 1995. nkan to ṣokunfa iku rẹ gaan ko ti daju titi di akoko yi. amọ ọgbẹni posey to koko gbe iroyin iku rẹ jade sọ pe awọn oṣiṣẹ ilera s pe o ṣeese ki o jẹ pe ọkan rẹ ṣadede mu ina lọ(cardiac arrest) coolio,ti orukọ abisọ rẹ n jẹ artis leon ivey jr gba ami ẹyẹ grammy fun orin gangsta s paradise ti wọn si lo orin naa ninu fiimu dangerous minds nibi ti gbajugbaja oṣere tiata nii michelle pfeiffer ti kopa. orin yi jẹ orin tawọn eeyan fẹran lati maa gbọ koda o ti le ni eeyan biliọnu kan to ti gbọ loju opo spotify gẹgẹ bi wọn ṣe fi si oju opo wọn. nigba aye rẹ, coolio ṣiṣẹ akọrin yi fun nkan to le ni ogoji ọdun. laarin igba taa n wi yi, o gbe alibọọmu mẹjọ jade to si ami ẹyẹ american music award. bẹẹ naa ni o gba ami ẹyẹ mtv video music awards mẹta. awọn orin rẹ mi to gba ori afẹfẹ to gbe jade nigba naa ni fantastic voyage, rollin with my homies, 1, 2, 3, 4 (sumpin new), ati too hot. titi to fi jade laye, coolio ṣi n kọrin koda oun ati awọn akọrin aye atijọ mii bi vanilla ice ati young mc ṣi jọ kọrin papọ ni texas ni nkan bi ọjọ meloo kan ṣẹyin. snoop dog, mc hammer,ice cube ati vanilla ice ti n fi ọrọ ikẹdun iku rẹ ṣọwọ loju opo twitter. fidio arakunrin kan to din dundu iya fun awon akẹkọọ ilẹ ẹkọ kan lorilẹede cameroun ti da rugudu silẹ bayii lori ayelujara. fidio ọhun ti awọn eeyan ẹgbẹrun mejidinlaadọjọ (148,000) ti wo lori twitter ṣe afihan arakunrin kan to wọ kootu alawọ funfun kan, to n lo okun funfun lati na awọn akẹkọọ naa ti wọn da ikun delẹ ninu aṣọ ileẹkọ wọn. ko din ni akẹkọọ ọgbọn, ninu eyi ti awọn obinrin pẹlu wa ninu, ninu fidio naa. ni ọjọ iṣẹgun ni iṣẹlẹ yii ṣẹlẹ ni ileẹkọ aladani kan ni ilu yaoundé to jẹ olu ilu orilẹede cameroun. ọkan lara awọn oṣiṣẹ ileẹkọ naa ṣalaye fun bbc pe pipẹ ti awọn akẹkọọ naa pẹ de ileẹkọ lo ṣokunfa iya ti wọn jẹ. oludasilẹ ileẹkọ naa sọ fun bbc pe, minisita fun eto ẹkọ girama lorilẹede cameroun, nalova lyonga yoo ṣe abẹwo si ileẹkọ naa l’ọjọru nitori iṣẹlẹ naa. ọpọ lo ti bu ẹnu atẹ lu ohun to ṣẹlẹ naa lori ayelukara “a gbọdọ dẹkun iwa ipa lawọn ileẹkọ. aṣilo agbara niyi.” ni ọrọ ti eeyan kan sọ loju opo twitter “idi ti awọn aṣiwaju alasilo agbara ṣe pọ nilẹ afrika. a kii fẹ ba awọn aṣiwaju wi, koda bo ba jẹ pe ohun ti wọn n ṣe ba kudiẹ kaato” ni ọrọ ti ẹlomiran sọ loju opo twitter kan naa. ""we really need to stop school violence. it is abuse,"" one twitter use said. amọṣa awọn kan sọ pe, ni t awọn o, awọn ko ni ariwisi kankan si ohun to ṣẹlẹ naa. gẹgẹ bi eeyan kan lori twitter ṣe tun sọ, “wọn to ọrẹ si idi awa naa bi eleyii, o tubọ jẹ ki iwa ọmọluwabi, nini afojusun rere ati mimọ ohun to tọ ati eyi to yẹ wọ wa lara bi ẹwu ni.” ofin ko fi aye fifi iya jẹ akẹkọọ nileẹkọ silẹ lorilẹede cameroun, amọ o si n waye nibẹ. ṣaaju l’osu yii, olukọ kan gba iwe lọ rọkun nile fun igba diẹ lẹyin to na akẹkọọ ileẹkọ girama oniṣẹọwọ kan lẹkun gusu orilẹede naa debi pe o sese ninu oronro inu rẹ. minisita feto ẹkọ girama lorilẹede naa ni lati pe ipade apero apapọ lori iwa ipa lawọn ileẹkọ, eyi yoo si wayr laarin ogunjọ si ọjọ kẹtalelogun oṣu kejila nilu yaoundé ẹgb gb run ọmọ il japan ti jade lati ṣe isin idagbere fun adari oril ede naa t l , shinzo abe ti wọn yinbọn pa. awọn onil ati alejo to fi mọ awọn adari oril ede ti wọn j ọr timọ-timọ p lu oril ede japan ni wọn pejọ pọ si ibi ipejọpọ idaro naa. bio til j pe awọn kan ko fi ara mọ bi wọn ṣe isinku r ni isinku oril ede( state burial). awọn ti ko faramọ mọ isinku naa ṣe if họnuhan lasiko ti isinku naa n lọ lọwọ. oṣu keje ni agbebọn kan yinbọn lu shinzo abe leemeji, to si gba ib lọ opo aar ͅ orileede japan papoda naa, akie abe lo wọ kimono dudu, to si n rin j l nk p lu eeru ọkọ r lọwọ ninu igo ti wọn fi n ṣe isinku. l yin naa lo gbe e si ori ipele ti wọn si aṣọ funfun bo p lu aworan olotu oril ede naa t l ri. shinzo abe to j ni ọdun m tadinlaadọrin ki o to papoda ni wọn pa ni oṣu keje l yin ti wọn fi ibọn ti wọn ṣe ni ab le yin ibọn lu ni meji, to si gba ib lọ. iṣekupani naa j iyal nu fun oril ede japan nitori iru iṣ l naa ko i tii waye nib ni ọpọlọpọ ọdun s yin. awọn ololuf r naa kii fun ọpọlọpọ ọdun to fi j aar wọn, ti o si fun wọn ni ifọkanbal ni gbogbo igba to fi wa ni ipo. amọ awọn ti ko faramọ iru isinku ti wọn ṣe fun un naa n ṣe if họnuhan wọn sunmọ ibi ti isinku naa ti n waye. o le ni kilomita ila ti awọn eniyan duro lati ṣe y ik yin fun sinzo abe. ileeṣẹ aarẹ lorileede naijiria ti fesi si iroyin to gbode pe aarẹ muhammadu buhari ti fọwọ si pe ki wọn yọ festus keyamo kuro nipo agbẹnusọ igbimọ ipolongo idibo bola ahmed tinubu sipo aarẹ naijiria. bola tinubu n dije labẹ ẹgbẹ oṣelu all progressives congress to jẹ ẹgbẹ aarẹ buhari. agbẹnusọ aarẹ garba shehu lo fidi ọrọ yi mulẹ loju opo rẹ ni twiter to si ni iroyin ofege gba a ni ọrọ yi jẹ. shehu sọ pe inu aarẹ buhari ati bola ahmed tinubu dun si iṣẹ ti keyamo n ṣe ni ipo rẹ gẹgẹ bi agbẹnusọ igbimọ ipolongo sipo aarẹtinubu. koda o sọ pe awokọṣe ni keyamo jẹ fawọn ẹgbẹ oṣelu mii nipa iṣẹ to n ṣe garba sheu wa fikun pe awọn mọ nipa ete tawọn kan n pa lati ṣi awọn olori ẹgbẹ apc lọna ki wọn baa le ṣakoba fun ipolongo ẹgbẹ naa fun ipo aarẹ. o rọ awọn ọmọ ẹgbẹ lati ma ṣe faaye gba ayederu iroyin ti awọn kan n gbe kaakiri nipa awọn olori wọn. ọgbẹni keyamo lo ṣe agbẹnusọ igbimọ ipolongo idibo aarẹ muhammadu buhari nigba to dije dupo ni saa keji rẹ lọdun 2019. awọn to n sọ pe buhari fẹ yọ keyamo a maa sọ pe niṣe lo n sọ ọrọ tabuku ijọba buhari ki o baa le gboriyin fun ipolongo ipo aarẹ bola tinubu. keyamo naa fun ara rẹ ti ṣaaju fesi si iroyin iyọni nipo rẹ ti ileeṣẹ iroyin kan ni naijiria gbe jade. esi naa wa loju opo rẹ ni twitter agbé́́bọn pa ènìyàn 12 niʹ ilé èͅkọ́ agbebon ti ṣina bol ni ile kọ kan ni russia, to si pa eniyan mejila. awọn to farapa ninu iṣ l naa j mọkanlelogun. awọn ọmọde meje lo wa ninu awọn to ṣe alaisi ninu iṣ l naa, ti gbogbo ak kọọ to wa ni ile kọ naa si le ni gb run kan. iṣ l naa waye ni agbegbe izhevsk. loju s kan naa ni agbebọn naa yinbon pa ara r . iwadii fihan pe ọmọ ile kọ naa t l ri ni agbebọn naa. ileeṣ iroyin ni russia fi awọn fidio lede nibi ti awọn eniyan ti n paya . ti wọn si n sa asala fun mi wọn. fọnran kan ṣafihan j ni il kilaasi ati oju ibọn lara ferese p lu awọn ọmọde ti wọn b r mọl p lu ifoya. ni apapọ, ogo w r meje,agbalagba m fa ati awọn sọ alaabo meji lo ba ikọlu agbebọn naa lọ. nibayii, ijọba ti paṣ ki wọn ko awọn ak kọọ ati olukọ kuro nib ni kiakia. bakan naa ni idaro ti b r bayii titi di ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu k san an, ọdun 2022. obinrin kan, giorgia meloni, ti n mura lati di olootu ijọba akọkọ ni italy bayii bo ṣe n jawe olubori ninu eto idibo to n lọ lọwọ lorile­̣-ede naa. meloni sọ pe oun ko ni fa ori apakan fikan silẹ ninu iṣẹjọba oun lẹyin ibo naa. ninu awọn esi to ti n jade lọwọ, ibo tirẹ ti fi ida mẹrindilọgbọn ju ti ẹni to tẹle, enrico letta, lọ. lara awọn to n ṣatilẹyin fun meloni ni silvio berlusconi, to jẹ olootu ijọba orilẹ-ede naa nigba kan ri. to ba ni ida mẹrinlelogoji ibo naa, egbẹ rẹ ni yoo maa ṣakoso ile igbimọ aṣofi ilẹ naa. ẹwẹ, ọwọ aarẹ orilẹ-ede naa, sergio mattarella ni ẹni ti yoo di olootu ijọba ilẹ naa wa. lara awọn ohun ti meloni fi kede lasiko ipolongo ibo ni pe oun ko ni faye gba ibalopọ laarin akọ si akọ ati abo si abio. o tun sọ pe oun yoo gbogun ti awọn alakakiti ẹsin musulumi. lara awọn eto ti meloni ni ireti lati ṣe to ba de ori alefa ni fifopinsi bi awọn eeyan ṣe n wọ orilẹ-ede naa lọna aitọ pẹlu ọkọ oju omi lati orilẹ-ede libya, atawọn eto mii fun itura awọn araalu. àwòrán òkúta tó ṣààmì ibi tí òkú ọbabìnrin elizabeth wọlẹ̀ sí ti jáde sí gbangba, wo ìyè owó tí wàá ná fi wo o aafin buckingham nilẹ gẹ̀ẹ́sì ti ṣagbejade aworan àkọ́kọ́ okuta iyebiye to saami ibùsùn ikẹyin ọbabìnrin elizabeth ni windsor. nibayii, wọn ti gbe okuta isinku dudu naa sori ilẹ̀ ile ijọsin george iv memorial chapel níbi tí wọ́n sin òkú ọbabìnrin elizabeth sí lọ́jọ́ aje. wọn kọ orúkọ ará òkúta náà ní ìrántí ọbabìnrin, àwọn òbí rẹ̀ àti ọkọ rẹ̀ tó ti d olóògbé, duke ti edinburgh. eleyi lo rọpo okuta palaba ti wọn ṣe fún ọba george vi ati iya ọbabìnrin. nibayii, okuta tuntun naa ka bayii pé: ""george vi 1895-1952"" ati ""elizabeth 1900-2002"" ati pe ""elizabeth ii 1926-2022"" ati"" philip 1921-2021"". awọn ọba alaye mẹrin yii lo wa ni ilana ẹgbẹ́ awọn ""garter"" eyi to jẹ agba ju ni ilana awọn ẹniabuọláfún"" ni ilẹ̀ britain. awọn ọrọ idagbere to dara jọjọ àti ọpọlọpọ ododo lo yí okuta ara ọ̀tọ̀ naa ka ti wọn gbe sori ibi isinku ọbabìnrin elizabeth. bẹẹ si ni wọn fi ọwọ gbẹ ọrọ ati orúkọ sori rẹ pẹlu awọ dúdú belgium ko lee wa ni ibamu pẹlu ohun to wa nibẹ tẹlẹ̀. o ṣeéṣe ko jẹ pé àwọn araalu yoo lè san owó lati le wo okuta ara ọ̀tọ̀ yii ni kọọkan láti ọjọ ọjọbọ. iroyin ni iye owo ti agbalagba yoo san lati wọlé sibi to wa ni £28.50 lọ́jọ́ satide àti £26.50 làwọn ọjọ́ to ku. ẹgbẹ oṣelu all progressives congress, apc, ti sọ idi ti ko fi si orukọ igbakeji aarẹ, yemi osinbajo lara awọn ọmọ igbimọ ipolongo ibo fun bola tinubu. ọjọ satide ni ẹgbẹ naa gbe akọsilẹ orukọ awọn ọmọ igbimọ naa, ti yoo ṣa amojuto ipolongo ibo fun oludije si ipo aarẹ ninu ẹgbẹ naa, tinubu ati igbakeji rẹ, kashim shettima. orukọ eeyan 422 ni wọn fi sita, ninu eyi ti awọn oṣere naa wa ninu rẹ. lẹyin ti apc fi awọn orukọ naa sita si ni awuyewuye ti bẹrẹ, ti ọpọ si n beere pe kilode ti wọn ko fi osinbajo si. ṣugbọn ninu atẹjade to fi sita, minisita keji fun ọrọ oṣiṣẹ ni naijiria, festus keyamo, to tun jẹ agbẹnusọ fun igbimọ ipolongo naa, sọ pe aarẹ muhammadu buhari lo sọ pe wọn ko gbọdọ fi orukọ yemi osinbajo ati akọwe fun ijọba apapọ, boss mustapha sinu igbimọ naa “nitori pe wọn ni iṣẹ iṣejọba lati gbajumọ”. keyamo sọ pe ko bojumu ki gbogbo awọn olori ijọba fi iṣẹ wọn silẹ lai ṣe nitori ipolongo ibo fun ẹgbẹ. ọjọgbọn osinbajo naa dije ninu ibo abẹle ẹgbẹ oṣelu apc lati ṣoju wọn fun ipo aarẹ ninu eto idibo gbogbo gbo ọdun 2023, amọ o fidirẹmi. 2023 elections: tinubu ṣèpàdé pẹ̀lú ìgbìmọ̀ bíṣọ́ọ́bù ìjọ pẹntikósítà lẹ́kùn àríwá ipade alatilẹkunmọri se ti waye laarin oludije sipo aarẹ fun ẹgbẹ oselu apc, asiwaju bola ahmed tinubu ati igbimọ awọn bisọọbu ninu ijọ kristiẹni igbalode ta mọ si pentecostal, ẹkun ariwa naijiria. ilu abuja si ni ipade naa ti waye ni alẹ ọjọbọ ana, gẹgẹ bo se salaye loju opo twitter rẹ, @official_abat ipade naa si lo waye lasiko ti awọn eeyan kan tun n bu ẹnu atẹ lu bi ẹgbẹ oselu apc se fa tinubu ati igbakeji rẹ, shettima kalẹ, ti awọn mejeeji si jẹ musulumi. nibi ipade naa si ni tinubu ti salaye fun awọn asoju awọn bisọọbu naa, idi to se mu musulumi bii tiẹ gẹgẹ bii igbakeji. o salaye fun bisọọbu agba john praise ti ijọ dominican chapel, to ko awọn bisọọbu naa sodi pe igbesẹ naa kii se amọọmọ se oun. tinubu ni o di dandan ki oun yan shettima to jẹ musululmi lọna ati pese isejọba rere fun awọn ọmọ naijiria ti wọn ba dibo yan oun sipo aarẹ lọdun 2023. bakan naa tun ni tinubu ipade to waye laarin oun ati awọn igbimọ awọn bisọọbu naa se eso rere. sugbọn yoruba ni isọrọ ni igbesi, awọn naijria ti wa n fesi si ikede ti tinubu fi soju opo ayelujara rẹ naa. bi awọn eeyan kan se n kan saara si, ni awọn miran n sọko ọrọ si lori igbesẹ naa. awọn asofin kan ni naijiria ti bu ẹnu atẹ lu aarẹ muhammadu buhari lẹyin to ko nnkan bii ọgọrun un eeyan lọ sibi ipade ajọ agbaye to waye niluu new york, lorilẹ-ede amẹrika. awọn aṣofin naa ni, o jẹ ohun to buru jai pe aarẹ yoo ko iye eeyan to pọ to bẹẹ sọdi lọ silẹ amẹrika pẹlu owo iyebiye lasiko ti ara n ni eto ọrọ aje naijiria. lara awọn asọfin ọhun ni muhammad sani musa, to n ṣoju ẹkun ila oorun niger, lati ipinlẹ niger. asọfin naa ni oju gba oun ti fun aarẹ buhari ati awọn olubadamọran rẹ bi wọn ko ṣe dẹkun rẹ lati maṣe gbe igbesẹ naa. o ni “nigba ti mo ri iye eeyan to kọwọrin pẹlu aarẹ lori ẹrọ amohunmaworan, oju gba mi ti fun wọn.” “ọpọ araalu lo n pariwo ebi, koda, ijọba gan tun fẹ ya owo kun eto iṣuna, kilode ti a fi wa n fi obitibiti owo sọfo lati ko ọpọ ero tẹle aarẹ lọ irinajo?” sẹnetọ naa ni bii igba ti eeyan ba n fi owo ilu sọfo ni irinajo naa ri, nitori awọn eeyan bii ọgọrun naa ni ijọba yoo san owo ọkọ ofurufu wọn, yatọ si owo ile itura ati owo ounjẹ wọn. o pari ọrọ rẹ pe o yẹ ki ijọba maa ṣaanu awọn araalu, ko si maa din iye owo to n fi ṣofo ku. èyí lohun tí ààrẹ buhari à tàwọn olùdíje kọ̀ọ̀kan sọ níbi ìdìbò abẹ́nú apc buhari rọ gbogbo awọn oludije lati rii pe wọn ko sa fi ẹgbẹ oṣelu apc silẹ bi wọn ba padanu ibo abẹnu naa nitori pe omi ṣi n bẹ lamu fun ẹgbẹ oṣelu naa. o ni bi o ti lee wu ko ri, iṣọkan ẹgbẹ oṣelu apc ṣe koko. aarẹ buhari wa rọ awọn aṣojudibo lati dibo yan oludije to ni iṣọkan orilẹede naijiria lọkaan ti ko sii fi ilọsiwaju naijiria sere. èyí lohun tí ààrẹ buhari à tàwọn olùdíje kọ̀ọ̀kan sọ níbi ìdìbò abẹ́nú apc buhari rọ gbogbo awọn oludije lati rii pe wọn ko sa fi ẹgbẹ oṣelu apc silẹ bi wọn ba padanu ibo abẹnu naa nitori pe omi ṣi n bẹ lamu fun ẹgbẹ oṣelu naa. o ni bi o ti lee wu ko ri, iṣọkan ẹgbẹ oṣelu apc ṣe koko. aarẹ buhari wa rọ awọn aṣojudibo lati dibo yan oludije to ni iṣọkan orilẹede naijiria lọkaan ti ko sii fi ilọsiwaju naijiria sere. aarẹ gotabaya rajapaksa ti kọ iwe fi ipo rẹ sile gẹgẹ bi aarẹ lẹyin ti o fẹsẹ fẹẹ kuro lọ si orilẹ ede singapore latari bi awọn olugbe ilu ṣe fẹohunhan lori eto iṣejọba rẹ. igbagbo wa pe o fẹ kuro ni sri lanka ki o to kọ iwe fi ipo rẹ sile ni nitori ki ijọba tuntun ma baa fi ofin gbe e. ọwọngogo ounjẹ, epo bentiro ati awọn ohun miiran ni o ti nira lorilẹde naa. ni olu ilu colombo, pẹlu ijo ati ẹrin ayo ti awọn olufẹhonuhan fi n yọ nigbati wọn gbọ iroyin pe aarẹ ti kuro ninu ilu naa “inu wa dun pupo, a le ni isinmi bayi ki a to pada si igbesi aye wa,” viraga perera sọ fun bbc. “lọwọlọwọ bayi, o ti rẹ wa nitori bi a sẹ fehonuhan sugbọn wakati ti a wa yii, a ki ara wa ku oriire.” rajapaksa ti de si orilẹede singapore l ọjọbọ ana pẹlu iyawo ati olusọ abo meji. orilẹde singapore ti wa kede pe awọn ko fun aarẹ rajapaska ni anfani lati wa ni ilu wọn nitori orilẹ ede naa ko ki n fun awọn to ba sa kuro ni ilu wọn ni anfani lati wa ni singapore adele aarẹ lorilẹde sri lanka, ranil wickremesinghe ni ko ni di aarẹ fidihẹ latari bi wọn ko ṣe tii bura fun un. ranil wickremesinghe ni awọn aṣofin orilẹde naa ni ọgbọn ọjọ lati fi ase sii pe ko di aarẹ fidihẹ ni ṣe ni ọjọ ayo di ọjọ ibanujẹ fun arabinrin kan lẹyin ti ọlọpaa mẹrin fi ofin mu arabinrin fun ẹsun ole jija nigba ti igbeyawo re lọwọ lorilẹede uganda. lọjọ satide ọsẹ to kọja ni awọn ọlọpaa naa yawọ ibi ayẹyẹ igbeyawo, ti wọn si mu iyawo lo si agọ wọn ni mbararata, ni iwọ oorun uganda. arabinrin naa lo sun agọ naa mọjumọ, ti wọn si tu silẹ ni ọjọ keji. agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa , fred enanga, ninu atẹsita to fi sita, ni iwa ti awọn ọlọpaa maa wu ni o le gba isẹ lọwọ wọn, nitori nkan ti wọn ṣe ni ko ba ofin mu. o ni awọn ọlọpaa naa lo ṣe isẹ naa lai si ẹri, ti wọn ba ọjọ ayo jẹ fun arabinrin naaa enanga ni ọwọ ti tẹ ọkan lara awọn ọlọpaa naa, ti o siti wa ni ahamọ sugbọn awọn mẹta yooku ti fẹsẹ fẹ kuro ni agbegbe naa. bi isẹ ti arabinrin ti n sisẹ tẹlẹ lo fi ẹsun ole jija kan arabinrin naa, ti wọn si bẹ awọn ọlọpaa nisẹ lati lo mu arabinrin naa awọn eeyan ilu mariga nijọba ibilẹ bariga nipinlẹ niger ti n wa oku eeyan to to ẹẹdẹgbẹta nigba ti omi wọ iboji to wa nilu naa lọ. imaamu agba fun ilu mariga, alhaji alhassan na ibi lo fi idi isẹlẹ naa mulẹ fun bbc ljọru. ""ẹkun omi naa ba iboji ti wọn sin oku eeyan bii ẹẹdẹgbẹjọ si amọ oku ẹgbrun kan pere la tun sin pada si iboji naa nigba ti ẹkun omi naa fa"". o fikun pe awọn tun ti n wa awọn oku ẹẹdẹgbẹta to sọnu amọ awọn ro pe omi ti wọ wọn lọ ni. amọ ihuwasi awọn awakusa to wa ni agbegbe ti itẹ oku naa wa, lo n kọ imaamu ọhun lominu. gẹgẹ bo se wi, iru isẹlẹ bayii ko waye ri lati ọgọta ọdun sẹyin. ogbontarigi agbabọọlu ọmọ naijiria to fi orile-ede austria ṣe ibugbe, david olatukunbo alaba, ti kọ awọn ile igbọnsẹ fun awọn ara ilu remo, nipinlẹ ogun. ọmọ orile-ede naijiria ni awọn obi alaba, sugbọn ilu vienna ni austria ni wọn bi si. oun naa kii si fi pamọ pe ọmọ naijiria ni oun. ọjọ satide, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu kẹsàn-án, ọdun 2022, ni wọn ṣe ifilọlẹ awọn ile igbọnsẹ naa ni ọjà kara tó wa ni ogere-remo. alaba ni oun kọ ile igbọnsẹ naa gẹgẹ bi ara ọna lati ṣe atilẹyin fun akitiyan isejọba muhammadu buhari lati fòpin si bi awọn araalu kan ṣe n yagbẹ ni gba ngba. alaga àjọ to n mojuto ọrọ àwọn ọmọ naijiria nilẹ okeere, abike dabiri-erewa lo kede igbeṣẹ alaba. o sọ ninu atẹjade kan lori twitter rẹ pe oun dupẹ pupọ lọwọ àjọ alaanu david alaba foundation, fun kíkọ àwọn ile igbọnsẹ naa. "" david tun ti n ṣe eto lati kọ ibudo ikọṣẹ fun bọọlu gbigba ni naijiria."" ẹgbẹ agbabọọlu real madrid ni david alaba n gba bọọlu fun lọwọlọwọ. ọwọ́ ọlọ́pàá hisbah zamfara tẹ arákùnrin àti arábìnrin tó ní ìbálòpọ̀ ní ìta gáréèjì awọn oṣiṣẹ ọlọpaa ẹsin hisbah to wa ni ipinlẹ zamfara ti fi panpẹ ofin mu arakunrin kan ati obinrin kan tawọn mejeeji sọ itiju nu ti wọn si bẹrẹ si ni ṣe ibalopọ nitagbangba. ni gareeji ọkọ to wa ni gusua olu ilu ipinlẹ zamfara ni wọn ti kawọn mọ nidi iwa ailojuti yi. ileeṣẹ iroyin pr.nigeria to jabọ iṣẹlẹ yi ni awọn mejeeji ko bikita bawọn ero ṣe n wo wọn ni ita gbangba fiiili kan to wa lẹgbẹ gareeji ọkọ naa. awọn oṣiṣẹ awakọ ati ero to ri wọn nidi iwa yi lo tara kesi awọn oṣiṣẹ hisbah ki wọn to sare wa lati gbe wọn kuro nibẹ. oṣiṣẹ hisbah kan to ba prnigeria sọrọ sọ pe awọn oniṣekuṣe meji yi ko bẹru pe awọn eeyan n wo awọn ti wọn si tẹsiwaju pẹlu iwa buruku yi titi tawọn hisbah fi wa gbe wọn kuro nibẹ. o sọ pe ọkunrin ati obinrin yi ti n leri laarin awọn lori ẹni to jẹ alailojuti julọ laarin wọn. awọn mejeeji n leri si ara wọn nibẹ si ni wọn ti ni kawọn dan ara wọn wo lati mọ ẹni ti jẹ alailojuti laarin wọn ileri ti wọn n ṣe si ara wọn yi ni wọn ba de bi pe wọn bọ ara wọn si ihoho ti wọn si ni kawọn wo ẹni ti yoo laya lati ni ibalopọ ni ita gbangba. ileeṣẹ iroyin prnigeria ni oṣiṣẹ to ba awọn sọrọ ṣugbọn to ni ki wọn fi orukọ bo ohun laṣiri ni awọn oṣiṣẹ hisbah ti wọ awọn mejeeji lọ siwaju ileẹjọ sharia to wa ni kankuri,zamfara. hisbah ti ko wọn lọ si ileẹjọ sharia ti a si lero pe wọn dajọ wọn ni ilana sharia yala fun ẹsun agbere tabi panṣaga nitori iwa ti wọn hu tako ofin ẹsin islaamu ati aṣa awọn eeyan ipinlẹ yi agbere labẹ ofin ni ibalopọ ti ko lẹtọ laarin awọn ti kii ṣe lọkọlaya. panṣaga leleyi to jẹ ibalopọ lọna aitọ laarin awọn to ni iyawo tabi ọkọ ti wọn tun wa n ba ẹlomiran ni ibalopọ aitọ. ẹgbẹ awọn akẹkọọ lorilẹede naijiria, nan ti ni awọn yoo da lilọ bibọ duro ni papakọ ofurufu lorilẹede naijiria ti ijọba ko ba fi opin si iyanṣelodi ti ẹgbẹ olukọ asuu gunle. eyi ko ṣẹyin iyanṣelọdi to ti wọ oṣu meje bayii lori bi ijọba ko ṣe mu adehun to ṣe pẹlu awọn olukọ ṣe. ati aisan owo osu fun wọn ni gbogbo igba ti wọn fi yan iṣẹ lodi. ẹgbẹ nan naa to ṣe ipade ni opin ọṣẹ nipinlẹ ondo bu ẹnu atẹ lu bi ijọba apapọ ko ṣe naani awọn olukọ ati eto ẹkọ paapaa ni naijiria. ‘’ni bayii, a ko bẹbẹ mọ, ko si eto ẹkọ, ko si lilọ bibọ kaakiri orilẹede naijiria’’ bakan naa ni awọn akẹkọọ naa ni ayọ ni igbese wọn lati ti awọn opopona kaakiri naijiria. ‘’bẹrẹ lati ọjọ aje, ọjọ kọkandinlogun, ọdun 2022 ni a o bẹrẹ ifẹhọnuhan miran. ‘’a o ri pe ko si ọkọ ofurufu kankan lati ilẹ okeere to balẹ si naijiria abi eleyii ti yoo jade.’’ ‘’aarẹ buhari gbọdọ san gbogbo owo awọn olukọ to jẹ wọn nitori o ti su wa ki a ba wọn sọrọ ti wọn kọ’’ ‘’a ko ni gba ki awọn akẹkọọ joko si ile nigba ti awọn oloṣelu n ran ọmọ wọn lọ si oke okun.",,lati bi ọsẹ diẹ ni awọn agbebọn ti n pa awọn ọmọ ogun orilẹ-ede naa +ìṣẹ̀lẹ̀ tó ṣẹlẹ̀ sí ọmọ mi ló wú mi lórí láti bẹ̀rẹ̀ ṣíṣe àgbélẹ̀rọ ẹsẹ̀ àti ọwọ́ fún àwọn ọmọ tí kò le rìn,"oríṣun àwòrán, crystal chigbu “nigba ti a bii, ko ni egungun lẹsẹ eyi si jẹ ipenija nla fun emi ati ọkọ mi crystal chigbu lo ṣalaye yii lori ọrọ ọmọ rẹ ti wọn bi laisi egungun ẹsẹ. “nigba ti wọn sọ fun mi pe wọn maa ge ẹsẹ ọmọ mi ni, mo kọkọ sare jade, mo sa lọ patapata. beulah ni akọbi ọmọ mi. mi o gbọ iru nnkan bayii ri. ko si ninu iran mi."" crystal joko sọrọ pẹlu bbc pidgin lori bi igbe aye ẹbi oun ati ẹbi rẹ ṣe yipadayipada nipasẹ iriri rẹ ati ti ọmọ rẹ ti wọn pada ge lẹsẹ ti ko wa lee rin mọ. “ṣaaju akoko yii, mi o tii ri eeyan ti wọn bi pẹlu nnkan bayii ri laye mi tabi ti wọn ge lẹsẹ. mo maa n ri awọn to ni ọwọ kan tabi ẹsẹ kan loju popo ṣugbọn nko tilẹ roo ripe o lee wa pada kan emi naa. o fi mi logbologbo. mo bi ọlọrun leere ẹṣẹ mi.” oríṣun àwòrán, crystal chigbu ni awujọ to jẹ pe awọn eeyan ti maa n da si ọrọ ti ko ye wọn pẹlu idẹyẹsi awọn akanda lọpọlọpọ, crystal sọrọ lori ipenija to koju lori ọrọ ọmọ rẹ. o sọ pe nigba ti wọn ge ẹsẹ ọmọ oun obinrin, ọpọ eeyan lo n sọ ọ kaakiri pe eṣẹ awọn lo pọ si ọlọrun lo fimu ki ọlọrun gbe iru ipenija bẹẹ ko wọn loju. “ki wọn to fun ọmọ mi ni agbelẹrọ ẹsẹ eyi to fi n rin kaakiri bayii ti awọn kan si maa n beere idi ti awọn ṣi fi maa n gbe ọmọ to ti dagba bayii kiri. wọn ni a kan fẹ ba a jẹ ni. ọpọ igba ni mi o si ki n mọ esi ti maa fun wọn.” oríṣun àwòrán, crystal chigbu crystal sọ pe lọjọ akọkọ ti oun ri ọmọ oun to duro funra rẹ lẹyin ti wọn fi agbelẹrọ ẹsẹ si ẹsẹ rẹ, omije bọ loju oun. “o wọ aṣọ ileẹkọ rẹ, o duro pẹlu ẹsẹ ti wọn ṣefun un naa , ni mo ba bẹrẹ si nii sunkun ti mo si tun n rẹrin papọ lẹsẹ kan naa nitori pe inira leyi jẹ fun oun ati ọkọ oun. eyi ni crystal so eyi gan lo wu oun lori lati ṣe iranwọ fun awon omode to wa ni ipo kan naa ṣugbọn ti awọn naa nkoju ohun ti oun pẹlu koju oríṣun àwòrán, crystal chigbu ajọ iranwọ kan to n pese aloku agbelẹrọ ẹsẹ at’awọn ohun irinna mirqn fawọn ọmọde ti ọjọ ori wọn ko ju odun mejidinlogun lọ ni crystal chigbu gbe kalẹ bayii. ọmọ rẹ obinrin ti won bi laini egungun ẹsẹ lo bi agbekalẹ ajọ iranwọ yii. “a rii pe awọn ọmọ kan naa wa ti wọn bi wọn bee naa tabi ti wọn ni ijamba to ge ẹsẹ wọn tabi ọwọ wọn. mo bẹrẹ si nii ba awọn obi wọn sọrọ lati mọ ọna ati mu aye dẹrun fun wọn.” crystal ni oun pinnu lati fi iṣẹ oojọ oun silẹ lati gbaju mọ riran awọn ọmọ ti wọn ge ọwọ tabi ẹsẹ wọn lọwọ nitoripe o n mu inu oun dun. “ inu mi maa n dun lati ri pe awọn ọmọde miran ti n ni ẹsẹ lati fi rin. ona ti a n gba ṣe agbelẹrọ ẹsẹ naa da lori rironu lori ohun ti yoo ṣe ọmọde ti a fẹ lo o fun lanfani.” o ni awọn ni awọn akọṣẹmọṣẹ to mọ nipa rẹ lati rii daju pe awọn agbelẹrọ ẹsẹ ti wọn ba ṣe naa yoo duro deede fun awọn ọmọ to fẹ lo o. “nigba ti awọn ọmọde naa ba ti ye ẹsẹ naa wo, a o gbiyanju lilo rẹ lati rii daju pe o ṣe rẹgi pẹlu wọn. o le maa jẹ ọwọ tabi ẹsẹ ti wọn ni tẹlẹ, ṣugbọn nigba tí ọmọ naa ba rin, ẹ o mọ boya nnkan kan ku diẹ kaaro lara rẹ.” o salaye siwaju sii pe awọn ọmọ miran n si lee gba bọọlu, sare tabi ṣe awọn ohun miran pẹlu agbelẹrọ ẹsẹ tiwọn. oríṣun àwòrán, crystal chigbu crystal chigbu ṣalaye pe ọmọ to ba n lo agbelẹrọ ẹsẹ tabi ọwọ si le e gbe igbe aye irọrun ti yoo si gbadun aye rẹ gẹgẹ bi iriri toin ṣe lọ. o ni ọmọ oun ṣi n luwẹ, gun kẹkẹ at’awọn ere idaraya miran. “a ti ri lara awọn ọmọ ti a ti ṣe iranwọ fun ti wọn ti sọ pe awọn fẹ di dokita, amofin ati bẹẹbẹ lọ lọjọ iwaju lai f’ọkan si pe ipenija wọn lee di ala ọjọ ọla wọn lọwọ. gẹgẹ bi ọrọ ti crystal chigbu sọ fun bbc, o ti le ni ọọdunrun awọn ọmọ to ti ran lọwọ pẹlu agbelẹrọ ẹsẹ tabi ọwọ lati igba ti ajọ iranwọ to gbe kalẹ ti bẹrẹ. o tun fi kun un pe igba miran wa ti oun maa n fẹ kọkọ ran awọn ọmọ to ti de ọjọ ori ati lọ sile iwe , ati lati wo bi ipenija awọn miran ṣe ta koko si ki oun to lati lee mọ ọmọ ti oun yoo kọkọ ran lọwọ. oríṣun àwòrán, crystal ghigbu fun ọmọde kan lati lee lo agbelẹrọ ọwọ tabi ẹsẹ ri won n pe ni ‘prosthetic’ yoo nii ṣe pẹlu ohun ti wọn fẹ ṣe. agbelẹrọ ọwọ tabi ẹsẹ yii jẹ arọpo fun awọn ẹya ara wọn kan ti wọn padanu yala nipasẹ ijamba ni tabi gige e kuro igbesẹ akọkọ ni fun awọn obi tabi alagbatọ ọmọ bẹẹ lati joko sọrọ pẹlu awọn ri yoo pese agbelẹrọ ẹya ara yii lati lee mọ ohun gan ni pato ti ọmọ wọn fẹ lo o fun lari le mọ eyi to se rẹgi fun un ni lilo. fun apẹrẹ: bi ọmọ ba ni ẹsẹ mejje, ohun elo agbelẹrọ ti wọn nilo yoo wa fun ati lee rin. ohun miran ti wọn tun ni lati kiyesi ni ọjọ ori wọn. irufẹ awọn ohun elo agbelẹrọ ẹsẹ tabi ọwọ ti wọn nilo tun nii. ṣe pẹlu ọjọ ori wọn. awọn agbelẹrọ ẹsẹ tabi ọwọ maa n ran awọn akanda ọmọ lati tubọ fi irọrun gbe igbe aye wọn amọṣa yoo gba wọn lakoko diẹ lati mọọ lo daadaa. nitori naa wọn yoo nilo ayẹwo atigbadegba, ati boya atunṣe diẹ lawọn ibi kan tabi omiran lati jẹ ko dun un lo, ko si tun wulo fun wọn daadaa.",30 owewe 2022,crystal joko sọrọ pẹlu bbc pidgin lori bi igbe aye ẹbi oun ati ẹbi rẹ ṣe yipadayipada nipasẹ iriri rẹ ati ti ọmọ rẹ ti wọn pada ge lẹsẹ ti ko wa lee rin mọ. +"ọmọ ọdún mẹ́wàá dàwátì, wọ́n bá òkú rẹ̀ nínú gọ́tà ní ibadan","gbogbo abiyamọ ayé a ò ní fojú sunkún ọmọ. níṣe ni ọkàn òbí àwọn ayoola daniel gbọgbẹ́ bí wọ́n ṣe bá òkú ọmọ wọn, ọmọ ọdún mẹ́wàá nínú gọ́tà kan tí kò jìnà sí ilé tí wọ́n ń gbé ní agbègbè wakajaye ní ìlú ibadan. nígbà tí bbc news yorùbá kàn sí àwọn òbí ayoola láti gbọ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ọmọ wọn, bàbá rẹ̀ ní ọjọ́ ajé ni ayoola ṣàdédé di àwátì. micheal ayoola tó jẹ́ bàbá daniel ayoola ní aago méjì ní ayoola ni máa ń dé láti ilé ẹ̀kọ́ ṣùgbọ́n ó jẹ́ ohun ìyàlẹ́nu fún àwọn nígbà tí àwọn kò rí ọmọ àwọn kó dé lásìkò. ó ní èyí ló mú kí òun àti ìyá ọmọ náà kó ẹsẹ̀ sọ́nà láti gba ilé ẹ̀kọ́ wakajaye community school lọ láti mọ ìdí tí ọmọ àwọn kò fi tíì délé lásìkò tó máa ń délé. micheal ṣàlàyé pé láti ọjọ́ ajé náà ni àwọn ti bẹ̀rẹ̀ sí ní wá kó tó di wí pá àwọn ènìyàn kan wá sọ fún àwọn wí pé wọ́n ti rí ọmọ náà ní ẹ̀gbẹ́ ilé àwọn. ó ní àmọ́ òkú ọmọ ni àwọn rí nígbà tí àwọn máa fi dé ibẹ̀. micheal tẹ̀síwájú pé ohun ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún àwọn nígbà tí òun bá òkú ọmọ òun nínú gọ́tà tí àwọn ti ri nítorí gbogbo ibẹ̀ ni àwọn ti wá ṣíwájú. ó fi kun pé yàtọ̀ sí ilé iṣẹ́ rédíò, gbogbo ilé ilẹ̀ àti odò tó wà ní agbègbè àwọn ni àwọn ti wá ọmọ náà dé láti ọjọ́ ajé tí àwọn kò rí nílé. “àwọn ará àdúgbò ló pè mí wí pé wọ́n rí òkú ọmọ mi nínú gọ́tà kan ní ẹ̀gbẹ́ ilé wá.” “nígbà tí mo débẹ̀, ó yàmilẹ́nu pé ọmọ ọdún mẹ́wàá le gba ibẹ̀ nítorí ibẹ̀ ṣe tóóró gan.” yàtọ̀ sí daniel ayoola, ọmọ ọdún mẹ́sàn-án mìíràn, muhiba kareem tó jẹ́ ọmọ ilé ẹ̀kọ́ wakajaye community school náà tún ti di àwátì ní àná ọjọ́bọ̀, ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n, oṣù kẹsàn-án. ìyá muhiba, kemi kareem òun kò ri kí ọmọ òun náà padà sílé lẹ́yìn tó jáde nílé ẹ̀kọ́. kemi ní láti àná ọ̀hún ni òun ti ń wá ọmọ òun ṣùgbọ́n tí òun kò ì tíì gbúròó rẹ̀ rárá. kemi ṣàlàyé pé màmá àgbà tí muhiba ń gbé ọ̀dọ̀ rẹ̀ ní wakajaye ló pe òun pé àwọn kò rí ọmọ òun mọ́. ó ní lẹ́sẹ̀ kan ni òun kúrò ní oje tí òun ń gbé tá àwọn sì ti bẹ̀rẹ̀ sí ní wá ọmọ náà ṣùgbọ́n àwọn kò ì tíì rí àpadàbọ̀ rẹ̀ títí di àsìkò tí a fi ń kó ìròyìn yìí jọ. ó fi kun pé nígbà tí òun dé ilé ẹ̀kọ́ àwọn ọmọ náà ní òwúrọ̀ ọjọ́ ẹtì, ohun tí wọ́n sọ fún òun ni pé àwọn kò ri láti àná tí wọ́n ti kúrò ní ilé ẹ̀kọ́. ó ní òun ti lọ fi ẹjọ́ sùn ní àgọ́ ọlọ́pàá monatan. nígbà tí ikọ̀ ìròyìn bbc yorùbá kàn sí ilé ẹ̀kọ́ wakajaye ní nǹkan bí ago mẹ́wàá òwúrọ̀ yìí, kò sí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kankan ní ilé ẹ̀kọ́ náà mọ́. bákan náà ni àwọn olùkọ́ tó fi mọ́ olùkọ́ àgbà kò sí níbẹ̀ nítorí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ náà. gbogbo ìgbìyàn jú bbc yorùbá láti kan sì agbẹnusọ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ oyo láti gbọ́ tẹnu rẹ̀ lórí àwọn ìròyìn yìí ló já sí pàbó.",30 owewe 2022,micheal ayoola tó jẹ́ bàbá daniel ayoola ní aago méjì ní ayoola ni máa ń dé láti ilé ẹ̀kọ́ ṣùgbọ́n ó jẹ́ ohun ìyàlẹ́nu fún àwọn nígbà tí àwọn kò rí ọmọ àwọn kó dé lásìkò. +pdp gbọn dotun babayemi yọ nínú ẹgbẹ́ bí jìga,"oríṣun àwòrán, screenshot ẹgbẹ́ òṣèlú peoples democratic party, pdp tẹ̀ka ìpínlẹ̀ osun ní àwọn ti lé dotun babayemi kúrò nínú ẹgbẹ́ náà. lẹ́yìn tí ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ ní orílẹ̀ èdè nàìjíríà dájọ́ pé ademola adeleke ni ojúlówó olùdíje sípò gómìnà ẹgbẹ́ náà níbi ètò ìdìbò abẹ́nú tó wáyé lọ́jọ́ kẹrìndínlógún oṣù keje. dotun babayemi ló ti ṣaájú gba ilé ẹjọ́ lọ wí pé kí ilé ẹjọ́ wọ́gilé ètò ìdìbò abẹ́nú tó gbé ademola adeleke wọlé gẹ́gẹ́ bí olùdíje pdp kí wọ́n sì kéde òun bíi ẹni tó gbégbá orókè níbi ètò ìdìbò náà. àtẹ̀jáde kan tí adelé alága pdp osun, adekunle akindele fi síta lọ́jọ́bọ̀ ní dotun babayemi kìí ṣe ọmọ ẹgbẹ́ àwọn mọ́ fún ìgbésẹ̀ tó gbé náà. akindele ní babayemi kò lẹ́tọ̀ọ́ kankan mọ́ báyìí láti dá sí ọ̀rọ̀ tó bá jẹmọ́ ti ẹgbẹ́ òṣèlú pdp. bákan náà ló kan sáárá sí ilé ẹjọ́ fún ìdájọ́ náà wí pé àwọn ti ń ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ìdájọ́ ilé ẹjọ́. ó ní ẹnikẹ́ni tó bá ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú dotun babayemi ni àwọn yóò tún fẹ̀sùn kàn wí pé ó ń ṣekuṣẹyẹ pẹ̀lú ẹgbẹ́ tí yóò sì kojú ìjìyà tó péye. à ti pé gbogbo àwọn tó bá ń ṣojú méjì nínú ẹgbẹ́ ni àwọn yóò gbọ̀n dànù ni àwọn máa gbọ̀n dánú láì wẹ̀yìn wò. oríṣun àwòrán, instagram ẹ ó rantí pé a mú ìròyìn wá fún-un yín ní àná wí pé ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ ní nàìjíríà ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé gómínà tí wọ́n dìbò yàn ní ìpínlẹ̀ osun, ademola adeleke ni ojúlówó olùdíje ẹgbẹ́ òṣèlú peoples democratic party, pdp. nínú ìdájọ́ ìgbìmọ̀ ẹlẹ́ni márùn-ún tí ilé ẹjọ́ náà gbé kalẹ̀ lọ́jọ́bọ̀ ní ẹjọ́ tí dotun babayemi pè wí pé òun ni ojúlówó olùdíje tí ẹgbẹ́ pdp yàn níbi ètò ìdìbò abẹ́nú ẹgbẹ́ náà tó wáyé lọ́jọ́ kẹrìndínlógún oṣù keje kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀. wọ́n ní ọjọ́ mẹ́rìnlá tí ilé ẹjọ́ là kalẹ̀ kí ẹni tí ìdájọ́ ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn ní láti fi gbé ẹjọ́ wọn wá sí ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ ti kọjá kí dotun babayemi tó gbé ẹjọ́ rẹ̀ wá. oríṣun àwòrán, screenshot ìgbìmọ̀ tó ń gbọ́ ẹ̀hónú ìbò ìpínlẹ̀ osun ti sún ìgbẹ́jọ́ síwájú di ọjọ́ kẹrin, oṣù kẹwàá. èyí wáyé láti fún àjọ tó ń rí sí ètò ìdìbò nàìjíríà, inec, gómìnà tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dìbò yàn, ademola adeleke àti ẹgbẹ́ òṣèlú peoples democratic party, pdp láti ṣara jọ lórí ìgbẹ́jọ́ ọ̀hún. nígbà tí ìgbẹ́jọ́ yóò bẹ̀rẹ̀ lónìí, ọjọ́ ajé ọjọ́ kẹrìndínlógún, oṣù kẹsàn-án, agbẹjọ́rò ẹgbẹ́ òṣèlú all progressives congress, apc ọ̀jọ̀gbọ́n kayode olatoke ní àwọn ti ṣetán tí àwọn sì ti wà ní digbí fún ìgbẹ́jọ́ náà. olatoke ní àwọn ti buwọ́lu fọ́ọ̀mù tf008 láti tẹ̀síwájú ìgbẹ́jọ́ náà. àmọ́ agbẹjọ́rò àjọ inec, ben ananaba ní òun kò ì tíì lè tẹ̀síwájú lórí ìgbẹ́jọ́ náà nítorí wọn ṣẹ̀ṣẹ̀ fi ìwé ìpẹ̀jọ́ ránṣẹ́ sí òun ní òwúrọ̀ òní ni. ananaba ní òun ṣì ní ọjọ́ méje láti fi fèsì sí ìpẹ̀jọ́ náà nítorí náà kí ilé ẹjọ́ fún òun láyè si. bákan náà ni agbẹjọ́rò adeleke, bamidele abolarin àti agbẹjórò pdp, nathaniel oke náà bèèrè fún ìsúnsíwájú ìgbẹ́jọ́ ọ̀hún. wọ́n ní kí ilé ẹjọ́ fún àwọn ní ọjọ́ méje láti fèsì sí àwọn ẹ̀sùn náà àti láti gbáradì. nígbà tó ń gbé ìgbẹ́jọ́ rẹ̀ kalẹ̀, alága ìgbìmọ̀ náà, adájọ́ tertsea kume wá sún ìgbẹ́jọ́ náà sí ọjọ́ kẹrin, oṣù kẹwàá. nígbà tó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀, agbẹjọ́rò ẹgbẹ́ òṣèlú apc, ọ̀jọ̀gbọ́n olatoke ní ìgbésẹ̀ tí adájọ́ náà gbé kìí ṣe ohun tó burú nítorí àwọn tó yẹ kí wọ́n jẹ́jọ́ ní àwọn ṣẹ̀ṣẹ̀ ń rí ìwé ìpẹ̀jọ́ gbà ni. oríṣun àwòrán, screenshot onírúurú awuyewuye ló ń jẹ jáde lẹ́yìn ètò ìdìbò sípò gómìnà ìpínlẹ̀ osun níbi tí sẹ́nétọ̀ ademola adeleke ti ẹgbẹ́ òṣèlú pdp ti jáwé olúborí. lára ohun tó wáyé lẹ́yìn ìdìbò náà ni pé gómìnà tó wà lórí ipò gboyega oyetola, tó tún jẹ́ olùdíje lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú apc kọ èsì ìdìbò náà. lẹ́yìn náà ni ẹgbẹ́ òṣèlú apc àti gómìnà oyetola wọ sẹ́nétọ̀ adeleke àti ẹgbẹ́ òṣèlú pdp lọ síwájú ìgbìmọ̀ tó ń gbọ́ ẹ̀hónú ìbò lórí èsì ìdìbò náà. lára àwọn ẹ̀sùn tí gómìnà oyetola fi kàn ni wí pé ìbò dídì wáyé ní àwọn ibùdó ìdìbò 750 ju iye ìdìbò tó yẹ kó wáyé láti ibẹ̀ lọ. ẹ̀wẹ̀, lẹ́nu ọjọ́ mẹ́ta yìí ni ìròyìn tún gba ìgboro pé gómìnà tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dìbò yàn náà, sẹ́nétọ̀ adeleke náà fọwọ́ si pé àlékún ìbò wáyé ní àwọn ibùdó náà. èyí ló mú bbc news yorùbá kàn sí gómìnà tuntun náà láti gbọ́ látẹnu rẹ̀ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ gan-an. gómìnà tuntun tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dìbò yàn ní ìpínlẹ̀ osun, ademola adeleke ti wá sọ̀rọ̀ lórí ìròyìn pé àwọn àlékún ìdìbò wáyé ní àwọn ibùdó ìdìbò kan ju bó ṣe yẹ lọ. adeleke ní dípò ibùdó 750 tí ẹgbẹ́ òṣèlú apc àti gómìnà gboyega oyetola ń gbé kiri pé àwọn èsì ìbò tó wáyé níbẹ̀ pọ̀ ju iye tó yẹ kó jẹ́ lọ. ó ní ibùdó mẹ́fà ni irúfẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ ti wáyé. agbẹnusọ adeleke, olawale rasheed tó bá bbc yorùbá sọ̀rọ̀ ṣàlàyé pé ìròyìn náà ló mú kí àwọn gbé àtẹ̀jáde kan síta lọ́jọ́ àìkú, ọjọ́ kejìdínlógún oṣù kẹsàn-án ọdún 2022. o ni atẹjade naa lo wa láti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé irọ́ pátá gbáà ni ìròyìn náà. rasheed ní lóòótọ́ ni àwọn ṣe àyẹ̀wọ̀ àwọn èsì ìbò tí àwọn ènìyàn dì lẹ́yìn tí gómìnà oyetola àti apc gbé àwọn lọ sí ilé ẹjọ́. ó ní ohun tí àwọn ṣàwárí ni pé dípò ibùdó ìdìbò 750 tí apc ní àwọn kùdìẹ̀kudiẹ ti wáyé, ibùdó ìdìbò mẹ́fà ni àwọn àlékún náà ti wáyé. ó fi kun pé àwọn ẹ̀rí wà tó lè fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé irọ́ pátápátá ní gbogbo ohun tí oyetola ń sọ, tí ó sì hàn sílé ẹjọ́ pé sẹ́nétọ̀ adeleke fìdí oyetola janlẹ̀ níbi ètò ìdìbò náà. rasheed sọ pé àwọn ìwé ẹ̀rí akọsilẹ esi ibo tí kò pé ni ẹgbẹ́ òṣèlú apc kó síwájú ilé ẹjọ́. o ni èyí tó lòdì sí ohun tó wà nínú ẹ̀rọ bvas àti fọ́ọ̀mù ec8a tó jẹ́ ojúlówó àwọn ẹ̀rọ tí wọ́n lò lásìkò ìdìbò náà. ó tẹ̀síwájú pé àwọn gbà wí pé lóòótọ́ ni àwọn èsì ìbò kan pọ̀ju iye ènìyàn tó yẹ kó lẹ́tọ̀ọ́ láti dìbò ní àwọn ibùdó ìdìbò mẹ́fà. àmọ́ ó ní kìí se ibùdó 750 ni irú rẹ̀ tí wáyé gẹ́gẹ́ bí ìròyìn tí oyetola àti apc ń gbé kiri. ó fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àṣìṣe ẹ̀rọ bvas ló fa ìṣẹ̀lẹ̀ náà àti pé ìbò ibùdó náà kò le ṣàkóbá fún èsì ìdìbò adeleke tí wọ́n bá yọ ọ́ kúrò nínú èsì ìbò tó gbé adeleke wọlé. bákannáà lo ní kò yẹ kí gómìnà oyetola àti ẹgbẹ́ òṣèlú apc máa lọ sọ̀rọ̀ sórí ayélujára àti àwọn iléeṣẹ́ ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ lórí ìdìbò náà lẹ́yìn tí ẹjọ́ ti wà nílé ẹjọ́. ó wá rọ̀ wọ́n láti gba ilé ẹjọ́ láyè láti ṣe iṣẹ́ rẹ̀ bó ṣe tó àti bó ṣe yẹ.",19 owewe 2022,akindele ní babayemi kò lẹ́tọ̀ọ́ kankan mọ́ báyìí láti dá sí ọ̀rọ̀ tó bá jẹmọ́ ti ẹgbẹ́ òṣèlú pdp. +kílódé tí ìgbẹ́jọ́ kò fi wáyé lórí ẹ̀bẹ̀ adedoyin láti lọ tọ́jú ara rẹ̀?,"oríṣun àwòrán, others igbẹjọ iku timothy adegoke to yẹ ko waye ni ọjọ ẹti foriṣanpọn. eyi ko ṣẹyin bi awọn agbofinro ko ṣe gbe awọn afurasi to n jẹjọ ipaniyan naa. nibi igbẹjọ to yẹ ko waye lonii, ni oludasilẹ ile itura hilton resorts hotel, ile-ife, rahman adedoyin, yẹ ko ti mọ boya ile ẹjọ yoo gba beeli rẹ nitori ilera ara rẹ. agbejoro olùjẹ̀jọ́ rọ ile-ejọ ṣáájú lati bere fún ìwé ipo ilera ogbeni adedoyin ti o ni awọn ailera diẹ ni ọgbà ẹwọn ti o wa. ṣugbọn agbẹjọro naa paapaa ko yọju sile ẹjọ lọjọ ẹti. abejoro fatima adeshina to n soju ẹbi oloogbe adegoke nikan lo wa. bakan naa ni agbẹjọro ọkan lara awọn afurasi naa, to jẹ oun gan-an ni afurasi akọkọ, naa wa sile ẹjọ. agbejoro awọn prison naa wa ni ile ẹjọ bakanna. adajo adepele ojo ti wa sun ẹjọ naa di ọjọ kẹwa, oṣu kẹwaa, ọdún 2022 lati fun àwọn agbejoro timothy adegoke ni aaye lati ko awijare wọn jọ lori idi ti ile ẹjọ naa ko gbọdọ fi fun adedoyin ni beeli. oni, ọgbọn ọjọ, oṣu kẹsan an, ọdun 2022, ni igbẹjọ rahman adedoyin yoo tun tẹsiwaju niluu osogbo. ohun ti igbẹjọ oni yoo da le lori ko ṣẹyin ẹbẹ adedoyin pe ki ile ẹjọ fun oun laafani lati lọ tọju ara oun. afurasi ọhun atawọn mẹfa mii, ti wọn jẹ oṣiṣẹ rẹ nile itura hilton, eyii to wa niluu ile ife ni wọn n jẹjọ niwaju adajọ lori ẹsun pe wọn lọwọ ninu iku timothy adegoke, to jẹ akẹkọọ fasiti ile ife, oau. ko pẹ ti igbẹjọ naa bẹrẹ ti awọn agbẹjọro adedoyin ti n bẹ ile ẹjọ pe ki wọn fun ni beeli nitori aisan kan to n ba finra. gẹgẹ bii awijare wọn, itọju ti afurasi naa n gba lọgba ẹwọn to wa ko koju oṣuwọn to, wọn si n fẹ lati gba beeli rẹ, ko le lọ ṣetọju ara rẹ nigba ti ẹjọ naa yo si maa tẹsiwaju. lara awọn agbẹjọro to dantọ to n sọju mọlẹbi oloogbe naa ni agbẹjọro agba naijiria, o tun jẹ ajafẹtọ ọmọniyan femi falana. ẹ ó rántí pé àjọ ọlọ́pàá ti kọkọ wọ́ ẹni tó ni ilé ìtura hilton náà, dókítà ramon adedoyin àti àwọn mẹ́fà mìíràn lọ sí ilé ẹjọ́ gíga kan nílùú abuja lórí ikú timothy adegoke tó kú sí ilé ìtura náà lọ́jọ́ kẹfà, oṣù kọkànlá, ọdún 2021. lẹ́yìn èyí ni wọ́n gbé ẹjọ́ náà lọ sí ilé ẹjọ́ gíga ìlú osogbo, ìpínlẹ̀ osun, lẹ́yìn tí wọ́n pé fùn gbígbé ẹjọ́ náà lọ sí ìpínlẹ̀ náà nítorí níbẹ̀ ni ìṣẹ̀lẹ̀ láabi náà ti wáyé. lára ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn adedoyin ni sínsin òkú adegoke lọ́nà àìtọ́, pípa ẹ̀rí ìwé owó tí timothy adegoke fi san owó rẹ́ àti yíyọ ẹ̀rọ ayàwòrán (cctv) ilé ìtura náà rẹ́ lójúnà àti pa àwọn ohun tí kò bá jẹ́ ohun ẹ̀rí rẹ́. ẹ̀sùn ìpànìyàn, ìlẹ̀dí-àpòpọ̀, àti àwọn ẹ̀sùn mìíràn ni wọ́n fi kan àwọn mẹ́fà tó ku.",30 owewe 2022,ohun ti igbẹjọ oni yẹ ko da le lori ni ẹbẹ adedoyin pe ki ile ẹjọ fun oun laafani lati lọ tọju ara oun. +"ó lé ní 1,500 ọmọdé tí mo ti fi èdè yorùbá kọ́ ní software development lọ́fẹ̀ẹ́","ẹ wo ọdọmọkunrin to n fi ede yoruba kọ awọn ọmọde ni imọ ijinlẹ kọmputa yoruba ni ẹyin lo n di akukọ . bẹẹ ni ọrọ ri fun ọdọmọkunrin kan, abass oyeyemi to n fi ede yoruba kọ awọn ọmọde ni imọ ijinlẹ kọmputa ti wọn n pe ni software development . ọgbẹni oyeyemi ṣe idasilẹ ile ẹkọ kan, eyi to pe ni teki site, nibi ti oun ati awọn ọrẹ rẹ kan ti n lọ kaakiri ilu lati kọ awọn ọmọde. o ni oun da ile ẹkọ imọ ayelujara naa silẹ, nitori ki awọn ọmọ naa ma ba ya iyakuya, tabi gbọ ẹkọ odi to le mu wọn wọ iṣẹ jibiti ori ayelujara ati awọn iwa buruku miran to le ba ọjọ iwaju wọn jẹ. oyeyemi ṣalaye fun bbc pe ikọ oun ti si awọn ilu kaakiri ilẹ yoruba, ti wọn si ti kọ ọmọ to le ni ẹgbẹrun kan aabọ. ""lootọ ede gẹẹsi ni imọ kọmputa, amọ a kiyesi pe awọn ọmọ to wa ni igberiko ni a n kọ. nitori ki ẹkọ naa le tete ye wọn la ṣe n lo ede abinibi.",30 owewe 2022,ọdọkunrin kan ti ba bbc sọrọ nipa bo ṣe n fi ede yoruba kọ awọn ọmọde ni imọ kọmputa +owó ilé là pé owó táa fún àwọn ọmọ ìgbìmọ̀ amúṣẹ́yá kìí ṣé mẹ́numọ́- pdp,"oríṣun àwòrán, official peoples democratic party (pdp) nigeria igbimọ amuṣẹya ẹgbẹ oṣelu peoples democratic party, pdp ti ṣalaye idi ti ẹgbẹ fi fun awọn ọmọ igbimọ amuṣẹya ẹgbẹ naa ni owo to le ni ọgọrun miliọnu naira. + ninu atẹjade ti wọn fi sita,wọn ni owo tawọn fun awọn ọmọ ẹgbẹ yi kii ṣe owo mẹnumọ bi kii ṣe pe owo ile lawọn san fun wọn. + wọn ni owo yi wa ni ibamu pẹlu ilana ẹgbẹ eyi to faaye gba ki wọn san owo ile awọn ọmọ igbimọ amuṣẹya ati awọn oṣiṣẹ ẹgbẹ miran. + esi ti wọn tori rẹ mu alaye yi wa ko ṣẹyin iroyin to gbode pe owo mẹnumọ ni wọn san fawọn ọmọ ẹgbẹ yi ki wọn baa ma sọrọ soke lori owo fọọmu to le ni biliọnu mẹẹdogun ti wọn ṣapapin rẹ. gẹgẹ baa ṣe ri ka ninu atẹjade ti debo ologunagba,akọwe ipolongo ẹgbẹ fi sita lorukọ igbimọ amuṣẹya, pdp ko san owo kankan fawọn ọmọ igbimọ amuṣẹya lowo abẹtẹlẹ abi tori nkan mii + o fi kun pe a ṣe ayẹwo finifin kaa to san owo ile yi ati pe o wa ni ibamu pẹlu ajẹmnu ati ẹt mii fawọn ọmọ ẹgbẹ ati eekan inu ẹgbẹ + akọwe ipolongo ẹgbẹ yi tẹsiwaju pe iroyin kan ti ileeṣẹ iwe iroyin kan gbe jade lo da wahala sil nipa pe o gbe ayederu iroyin jade. + iroyin ofege ti ileeṣẹ iroyin yi gbe jade pe owo abẹtẹlẹ ni owo ile taa san fawọn ọmọ igbimọ amuṣẹya ẹgbẹ wa jẹ oríṣun àwòrán, arapaja oladejo taofeek wahala abẹnu to n koju ẹgbẹ oṣelu peoples democratic party ni naijiria ti gba ọna mii yọ pẹlu bi iroyin ṣe gbode pe awọn ọmọ ẹgbẹ kan ti ṣe apapin owo fọọmu ti wọn gba lọwọ awọn oludije sipo. awọn ọmọ igbimọ amuṣẹya kan ninu ẹgbẹ pdp lo da owo naa to le ni ọgọrun miliọnu naira pada ti ṣe ti n da owo pada si akoto ẹgbẹ. ko tan sibẹ, wọn tun fi lẹta pẹlu owo ti wọn da pada ti wọn si ṣalaye sinu rẹ pe awọn ko mọ nipa owo ti o wa lati ọdọ akapo ẹgbẹ tori naa awọn fẹ da owo naa pada. kaakiri oju opo ayelujara lawọn ọmọ ẹgbẹ pdp bi ambassador taofeek arapaja to jẹ igbakeji alaga apapọ ni iwọ oorun guusu naijiira ati alaga fagbegbe iwọ oorun guusu naijiria olasoji adagunodo ti n ṣafihan iwe ti wọn fi da owo pada. ninu iwe ti arapaja kọ si alaga ẹgbẹ naa, iyorchia ayu, o ni iroyin to gbode pe awọn ọmọ igbimọ amuṣẹya ti ba wọn pin ninu owo to to biliọnu mẹẹdogun owo fọọmu lo mu ki oun lo yẹ apo aka-n-ti oun wo. o ni lẹyin ti oun wo iye to wọle si akoto owo oun, loun wa ri wi pe wọn san miliọnu mẹrindinlọgbọn naira kan wọle lati ọdọ akapo owo ẹgbẹ. o fi lẹta to fi sita yi sọ fun ẹgbẹ wi pe oun ti da owo naa pada. lẹta rẹ yi ko fi taratara yatọ si eyi tawọn ọmọ igbimọ amuṣẹya ẹgbẹ naa mii fi ṣalaye bawọn ko ṣe mọ nipa obitibiti owo yi ati pe ariwo to pọ lode wi pe awọn ti gbadọde lo mu kawọn da owo naa pada. oríṣun àwòrán, olusoji adagunodo a ko le sọ pato boya iroyin ati ẹsun ajẹbanuyi yoo tunbọ fawọn to fẹ ki alaga ẹgbẹ iyorchia kuro nipo lagbara si. laipẹ yii ni awọn ọmọ ẹgbẹ naa kan bi gomina ipinlẹ rivers nyesom wike ati seyi makinde ti oyo, ti n sọ pe ko yẹ ki iyorchia ayu ṣi wa lori ipo alaga ẹgbẹ. koda, awọn gomina naa ati awọn kan ko yọju sibi ifilọlẹ ipolongo ibo aatiku abubakar to waye l ọjọru. a ko mọ boya eyi niṣe pẹlu ipinu wọn pe ayafi ki iyorchia ayu kuro lori ipo gẹgẹ bi alaga. amọ ṣa bayi ti wọn ti n da owo pada, o ṣeeṣe ki o jẹ pe ibẹrẹ ọna ti wọn yoo fi yẹ aga nidi iyorchia ayu ni wọnfẹ gunle yi. bi iwadii ba lọ to bọ, o ṣeeṣe ki wọn ni kiayu wa ṣalaye idi to fi ni ki wọn san aduru owo yi sakoto awọn ọmọ igbimọ amuṣẹya ẹgbẹ.",30 owewe 2022,awọn ọmọ igbimọ amuṣẹya gbogbo ti wọn ti da owo pada sọ pe awọn ṣe bẹ nigba ti ariwo pọ wi pe awọn ti gbabọde fawọn to ṣe apapin biliọnu mẹẹdogun owo fọọmu. +àwọn tó pa bamise nínú brt ba ojú ara àbúrò mi jẹ́ yánkan-yànkan,"oríṣun àwòrán, bamise ayanwola ẹgbọn ọdọbirin ti wọn ni awakọ brt ṣekupa l’eko, iyẹn oluwabamise ayanwola, ti sọ fun ile ẹjọ to n gbọ ẹsun naa pe wọn ti ba oju ara oloogbe naa jẹ lasiko ti awọn ọlọpaa yoo fi ṣawari oku rẹ. + ibatan rẹ ọhun, abegunde ayanwola lo sọ ọrọ naa lasiko to wa jẹri niwaju ile ẹjọ tako awakọ brt ti wọn ni o pa ọdọbirin naa, andrew nice ominikoron. + andrew nice yii ni wọn fẹsun kan pe o ba oloogbe naa lopọ pẹlu ipa, to tun gba ẹmi rẹ lẹyin naa. + o tun n koju ẹsun ibalopọ ero ọkọ mii, iyẹn maryjane odezelu. + + o ni ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu keji, ọdun 2022 yii ni bamise kuro nile lati ṣabẹwo si ọkan lara awọn ẹgbọn rẹ, amọ ko de ibi to n lọ, eyii lo mu ki wọn bẹrẹ si n wa. ọkan lara awọn ọrẹ bamise lo ṣalaye fun awọn mọlẹbi rẹ pe o n ba oun sọrọ jolu opo whatsapp pe oun wọ inu ọkọ ero btr, amọ pe ẹru n ba oun ninu ọkọ ero naa nitori awọn nnkan ti oun fura si lẹyin ti gbogbo awọn ero ọkọ naa ti sọto si ku oun nikan sinu rẹ pẹlu awakọ. abegunde ṣalaye pe bamise ati ọrẹ rẹ ọhun fi ohun ranṣẹ si ara wọn lori whatsapp, eredi ree ti ileeṣẹ ọlọpaa fi lọ ṣe ọfintoto bi oloogbe naa ṣe rin ni ileeṣẹ to n bojuto brt l’eko. o fi kun pe ileeṣẹ brt bere aṣẹ lati ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ki wọn to fun awọn laṣẹ lati wo aworan ori cctv inu brt naa. gẹgẹ bii ohun ti abegunde sọ, awọn ọlọpaa fi ọwọ yẹpẹrẹ mu ọrọ naa, eyii to mu ki a wọn kọ lẹta si ọọfisi ileeṣẹ to n ṣakoso brt l’eko, lamata ati ile igbimọ aṣofin ipinlẹ ọhun. o ni lẹyin oniruru igbinyaju ni wọn ri oku aburo oun nile igbokusi kan lọjọ keje, oṣu kẹta, lẹyin ti ẹnikan dari awọn si agọ ọlọpaa to wa ni ebute ero. nigba ti agbẹjọro afurasi bere lọwọ ẹgbọn bamise ohun to n gbiyanju lati sọ nigba to sọ pe wọn ti ba oju ara oloogbe naa jẹ. pẹlu omije loju, o ni “’virgin’ ni ọmọ naa, ti awọn ọkunrin bii meji si mẹta si ba lopọ, ṣe ẹ fẹ ki n maa ṣalaye bi oju ara rẹ sẹ ri ni? rara o! mi o le ṣalaye.” ṣaaju ni agbẹjọro afurasi, ọgbẹni omotubora tọrọ afọriji lọwọ adajọ pe oun pẹ de ile ẹjọ naa ni ijoko to waye kẹyin, o ni sunkẹrẹ-fakerẹ ọkọ to maa n waye lagbegbe ikorodu lo ṣokunfa rẹ. adajọ sherifat sonaike wa fun lesi pe oun ti fun ẹlomiran ni ipo rẹ. o kere tan, agbẹjọro naa ti kuna lati yọju si ijoko marun un ọtọtọ. adajọ sọ fun pe irufẹ iwa bẹẹ tumọ si pe ko bọwọ fun ile ẹjọ, lẹyin naa lo sun igbẹjọ naa si ọjọ karundinlọgbọn ati ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu kẹwa, ọdun 2022.",30 owewe 2022,"ẹgbọn bamise ayanwola, ọmọbinrin ti wọn fi ẹsun kan pe wọn fi ipa balopọ ninu brt jẹri nile ẹjọ" +"atiku, obi, tinubu t’ọwọ́ bọ ìwé àdéhùn àlàáfíà fún ìbò 2023","oríṣun àwòrán, twitter awọn oludije fun ipo aarẹ lasiko idibo apapọ ọdun 2023 lorilẹede naijiria ti tọwọ bọ iwe adehun alaafia, pẹlu ileri ati rii daju pe eto ipolongo ibo wọn ko mu wahala tabi rogbodiyan dani rara. bakan naa ni wọn tun fohun ṣọkan lati tẹle ilakalẹ ofin idibo ni naijiria ṣaaju, lasiko ati lẹyin idibo naa ki eto gbogbo lee lọ nirọwọrọsẹ. ninu ọrọ to sọ ranṣẹ sibi ayẹyẹ naa ninu akasilẹ fọnran fidio kan, nibi ayẹyẹ naa, aarẹ orilẹede naijiria, muhammadu buhari rọ awọn oludije lati rii pe ọrọ nipa koko ohun ti wọn fẹ gbe ṣe ni wọn n gbe leke lasiko ipolongo wọn dipo ikọlu, ọrọ alufansa ati ọrọ aitọ to lee da wahala silẹ. aarẹ buhari tun rọ wọn lati yago fun iroyin ofege lasiko ti wọn ba n polongo ibo wọn. aarẹ buhari ko dije ni ibo to n bọ nitori saa keji ti ofin fi aye rẹ silẹ lo n lo lọ lọwọ. olori ijoba ologun lorilẹede naijiria nigba kan ri, ọgagunfẹyinti abdusalami abubakar lo gbe ero naa kalẹ pẹlu atilẹyin awọn aṣiwaju ẹsin ni naijiria bii biṣọbu agba ijọ aguda lẹkun sokoto, mathew hassan kukah ati olori ẹsin musulumi ni naijiria, , sultan sa’ad abubakar kẹta tilu sokoto oríṣun àwòrán, twitter oríṣun àwòrán, twitter ọgagunfẹyinti abdusalami ni awọn oloṣelu gbọdọ ni oye pe “idibo kii ṣe ogun jija”, nitoei naa ki wọn yago fun awọn ọrọ to le fa yanpọnyanrin. lara awọn oludije to wa nibẹ ni atiku abubakar ti pdp, peter obi ti labour, rabiu kwankwaso ti nnpp. kashim shettima to jẹ igbakeji oludije ti apc, lo soju fun bola tinubu. l’ọjọru ni ipolongo ibo bẹrẹ lorilẹede naijiria fun eto idibo apapọ tiyoo waye loṣu keji ọdun 2023. lọdun 2015 ni eto yii bẹrẹ nitori iriri awọn wahala to waye lẹyin idibo lorilẹede naijiria lọdun 2011 eyi to gbẹmi ọgọrọ eeyan lọdun naa.",29 owewe 2022,"bakan naa ni wọn tun fohun ṣọkan lati tẹle ilakalẹ ofin idibo ni naijiria ṣaaju, lasiko ati lẹyin idibo naa ki eto gbogbo le lọ nirọwọrọsẹ." +méjì lára àwọn tó pa àbúrò mi ti kọ́kọ́ wá mu ọtí ní hotel rẹ̀ lọ́sàn-án,"oríṣun àwòrán, caleb owolabi ẹ̀gbọ́n oniṣowo kan ti awọn ajinigbe pa nilu ogbomoso sọrọ lori iku rẹ ẹni to jẹ ẹgbọn oniṣowo kan to jẹ ọmọ naijiria, ṣugbọn to n gbe nilẹ america, ayorinde owolabi, ti sọrọ lori iku rẹ. ninu oṣu kẹfa, ọdun 2022, ni awọn ajinigbe pa ọkunrin naa ati akẹkọọ fasiti lautech kan nilu ogbomoso. iroyin sọ pe ninu ile itura ọgbẹni owolabi ni wọn ti ji oun ati akẹkọọ lautech naa, racheal opadele to jẹ oṣiṣẹ nibẹ gbe. wọn pa awọn mejeeji lẹyin ti wọn gba owo itusilẹ lọwọ ẹbi wọn. ninu ọrọ to sọ fun bbc, ẹgbọn oloogbe ayorinde owolabi, alagba caleb owolabi sọ pe meji lara awọn to pa aburo oun ati oṣiṣẹ rẹ naa, ti kọkọ wa a mu ọti nile itura rẹ. o ni ""nkan to jẹ ka mọ ẹya ti wọn ti wa ni pe meji lara wọn ti kọkọ wa mu ọti nile itura naa lọsan, koda wọn sọ pe awọn fẹ ẹ gba yaara. ""ọmọbinrin ti wọn gbe pẹlu aburo mi, rachael, lo ta ọti fun wọn, boya nitori ẹ ni wọn ṣe ji oun naa gbe."" alagba caleb ṣalaye pe ọgọrun miliọnu naira ni wọn kọkọ beere fun, amọ awọn ko miliọnu marun-un lọ lẹyin ọjọ kẹrin ti wọn gbe wọn. o ni ẹni to gbe owo naa lọ ṣalaye pe bi wọn ṣe gba owo naa, ni wọn bẹrẹ si sọ ede ti oun ko gbọ. lẹyin naa si ni wọn bẹrẹ si yinbọn mọ awọn to wa ni ahamọ wọn, ẹni to gbe owo lọ, ati ọlọkada to gbe e lọ. ẹni to gbe owo lọ nikan ni ko kú ninu awọn mẹrẹẹrin. oloogbe owolabi ti n gbe nilẹ america lati ọdun 1986, to si ma n wa sile lati wo awọn eeyan rẹ ati awọn okowo to n ṣe ni naijiria. botilẹ jẹ pe ẹbi oloogbe fi ẹsun kan pe awọn eeyan kan lati ẹya fulani lo ṣe iṣẹ ibi naa, ileeṣẹ ọlọpaa ko fidi eyi mulẹ. bakan naa ni wọn ko tii ri afurasi kankan mu lori iṣẹlẹ ọhun.",29 owewe 2022,ẹ̀gbọ́n oniṣowo kan ti awọn ajinigbe pa nilu ogbomoso sọrọ lori iku rẹ +ìjọba ti ṣọ́ọ̀ṣì tí wọ́n ti n ta omi ayẹta ìbọn fun àwọn olùjọ́sìn ní kogi,"ijọba ipinlẹ kogi ti ti ile ijọsin kan pa fun ẹsun pe alufaa ijọ naa n ta omi ayẹta fun awọn ọmọ ijọ. ọjọ aje ni wọn gbe ilẹkun ile ijọsin naa, new jerusalem deliverance ministry lẹyin ti gomina yahaya bello paṣẹ rẹ pasitọ ijọ naa, peter adeiza tun ṣi ileewosan lai gba aṣẹ lọwọ ijọba lati ọdun 2008. igbagbọ wa pe ọpọ eeyan lo ti padanu ẹmi wọn nitori ilana ti wọn n gba ṣe itọju wọn. awọn ileeṣẹ iroyin abẹle jabọ pe, yatọ si pe wọn n ṣe itọju aisan, ati igbẹbi alaboyun nibẹ, wọn tun n lo ṣọọṣi naa fun itọju aarun ọpọlọ, ti wọn si so ọpọ wọn pẹlu ṣẹkẹṣẹkẹ. ijọba sọ pe alufaa adeiza n lu awọn ọmọ ijọ rẹ ni jibiti nipa ti ta omi kan fun wọn, ‘ti ko ni i jẹ ki ọta ibọn ko ran wọn’. awọn ọmọ ijọ naa kan sọ fun awọn akọroyin pe lootọ ni baba wọn ninu oluwa ọhun n fun awọn ni iwosan lori oriṣiriṣi aisan ati aarun. oludamọran lori aabo fun ijọba ipinlẹ kogi, jerry omodara, sọ pe awọn ọlọpaa ati dss ti kọkọ mu pasitọ naa nigba kan, lati tọpinpin nkan to n ṣẹlẹ ninu ṣọọṣi naa. omodara sọ pe awọn ni ẹri to to lati fihan nile ẹjọ pe iṣeṣi pasitọ naa tako ilana ẹsin ati iṣegun oyinbo. o ṣalaye pe laipẹ ni wọn o gbe e lọ sile ẹjọ.",29 owewe 2022,ijọba ipinlẹ kogi ti ile ijọsin kan pa nitori ilana wọn tako ofin +mọ̀ síi nípa olaolu martins ọ̀kan lára olùdásílẹ̀ ilé oúnjẹ bukka hut tó ṣáláìsí,"oríṣun àwòrán, olaolu-martins ile ounjẹ igbalode to gbale gba oko ni ipinlẹ eko bukka hut ti kede iku ọkan lara awọn oludasilẹ rẹ, olaolu martins. gẹgẹ bi atẹjade ti wọn fi sita lọjọ iṣẹgun, arakunrin martins jade laye ṣugbọn wọn ko sọ ohun to ṣokunfa iku rẹ. ẹni ti wọn jọ da ileeṣẹ ounjẹ igbalode naa silẹ to si jẹ oludari ileeṣẹ naa lọwọ bayi rasheed jaiyeola lo buwọlu atẹjade yi lorukọ ileeṣẹ wọn. ibeere ti o gba ẹnu ọpọ ọmọ naijiria ati awọn to jẹ alabara ileeṣẹ ile ounjẹ naa bayi wa ni pe iru eeyan wo ni laolu martins to jade laye yi. laolu martins jẹ ẹni ọdun marundinlaadọta nigba to jade laye. lati ibẹrẹ pẹpẹ igbesi aye rẹ lo ti jẹ akikanju eeyan to ja fafa lẹnu iṣẹ. gẹgẹ bi ohun taa ri ka nipa rẹ, ileeṣẹ ayẹwe owo wo taa mọ si price water. loju opo rẹ to wa ni linkedin la ti ri iroyin yi nipa rẹ. fasiti ilu eko unilag lo ti kawe gboye to si tun ṣiṣẹ papọ pẹlu ileeṣẹ stanbic ibtc laarin ọdun 2000-2005. o kuro nibẹ lọ si shell nigeria ki o to wa lọ si nigeria international securities limited to jẹ oludasilẹ nibẹ lati ọdun 2008 titi di igba to jade laye. awọn mọlẹbi rẹ naa ti fi atẹjade sita ni ikede iku ọmọ wọn. ninu rẹ, wọn ni ki awọn eeyan gbaruku ti mọlẹbi paapa iyawo, awọn ọmọ, obi ati awọn ọmọ iya rẹ lasiko yi. wọn ni ikede mii nipa eto isinku rẹ yoo maa waye laipẹ. loju opo ayelujara lawọn to jẹ ọrẹ ati alabaṣe rẹ ti n daro oniṣowo pataki to jade laye yi.",29 owewe 2022,olokoowo to jẹ gbajugbaja ni olaolu martins jẹ nigba aye rẹ. +ọ̀pọ̀ èèyàn kìí fẹ́ kí ọmọ wọn fẹ́ àwa akéwì nítorí wọ́n rò pé oníranù ni wá,àwọn òbí mi kọ́kọ́ lérò pé ìranù ni mó fẹ́ má a fi oríkì ṣe,28 owewe 2022,"ọmọbinrin to kawe, amọ aṣa yorugba gbigbe larugẹ lo fi n ṣiṣẹ ṣe." +ṣé lóòtọ́ ni wọ́n fipá bá ọmọ ọdún mẹ́wàá tí wọ́n rí òkú rẹ̀ ní ayobo l eko lòpọ̀?,"ileeṣẹ ọlọpaa ti sọrọ lori oku ọmọdebinrin kan ti wọn deede ri ni agbegbe ayobo nipinlẹ eko. alukoro ọlọpaa nipinlẹ naa, benjamin hundeyin sọ fun bbc pe lootọ ni awọn ri oku naa ṣugbọn iwadii n tẹsiwaju lati fidi ohun to ṣokunfa iku ọmọde naa mulẹ. ṣaaju ni oṣerebinrin tiata yoruba, to tun jẹ adẹrinposonu, damilola adekoya ti ọpọ eeyan mọ si princess ti kọkọ gbe ọrọ yi soju opo ayelujara to si ni wọn fipa ba ọmọde naa lo pọ ni. o darukọ ọmọde naa to si ni iya to bi ọmọ naa ti lọ si agọ ọlọpaa to wa ni ayobo ṣugbọn wọn ko jẹ ki o foju ri oku ọmọ rẹ. ninu fọnran fidio to fi si oju opo instagram rẹ, princess kesi alukoro ọlọpaa ni ipinlẹ eko taa ba sọrọ pe ko tete wa nkan ṣe si ọrọ yi. bẹẹ la ri arabinrin kan ti o pe ara rẹ ni iya ọmọde naa. o ṣalaye fun princess ninu fidio naa pe wọn fipa ba ọmọ rẹ lo pọ ni ati pe wọn pa ọmọdebinrin ẹni ọmọ odun mẹwaa yi. amọ ọgbẹni hundeyin sọ pe awọn ko le sọ boya ifipabanilopọ waye ṣugbọn ṣa awọn ri oku ọmọdebinrinkan ati pe awọn ti n ṣe iwadii lori ohun to ṣokunfa iku rẹ. o ni kete tawọn ba pari iwadii ni awọn yoo fi to awọn akọroyin leti bi iṣẹlẹ naa ṣe waye. gẹgẹ bi a ti ṣe sọ saaju, alukoro ọlọpaa benjamin hundeyin sọ pe awọn ti mu awọn afurasi kan ṣugbọn ko darukọ iye wọn. amọ loju opo princess to fi fidio si, eeyan kan ti orukọ rẹ n jẹ @hrh king adedamola o loju opo instagram sọ pe oun wa ni agọ ọlọpaa ti wọn gbe ẹjọ yi lọ ati pe ole ni eeyan mẹrinla ti wọn ti mu lori ọrọ yi. o ni bi apẹrẹ awọn onile ladugbo,obinrin olori ile ijọsin kana ti awọn ọmọ ile ijọsin wa lara awọn ti wọn mu wọn si ti gbe eeyan mẹfa ninu wọn lọ si panti",27 owewe 2022,ileeṣẹ ọlọpaa ti mu afurasi lori oku ọmọde kan ti wọn ri ni eko. +ìwọde forí ṣọ́npọ́n! wo ohun tó ṣẹ́lẹ̀ níbi “4 million man march” àwọn alatilẹyin peter obi l’eko,"awọn alatilẹyin oludije sipo aarẹ ninu ẹgbẹ oṣelu labour, peter obi, ti wọn maa n pe ara wọn ni ""obidient"" ti ṣe iwọde niluu eko. ṣaaju ni wọn ti kọkọ kede pe miliọnu mẹrin eeyan lawọn n reti nibi iwọde naa, ati pe iloro lekki toll gate ni iwọde naa yoo ti waye. amọ lẹyin ikede naa ni ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ eko sọ pe awọn ko ni gba ki iwọde kankan waye ni lekki toll gate. ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ ileeṣẹ naa, benjamin hundeyin fi lede, o ni “o ṣe pataki lati jẹ ki awọn araalu mọ pe a ko ni gba ki iwọde kankan waye ni lekki toll gate.” “ile ẹjọ ti paṣẹ pe ki ẹnikẹni maṣe ṣe iwọde kankan ni toll gate ọhun.” “eyii jẹ ọna lati pa ẹmi ati dukia awọn eeyan mọ.” lasiko ti ikọ ileeṣẹ iroyin bbc ṣabẹwo si ẹnu iloro lekki toll gate naa, wamu-wamu ni awọn ọlọpaa duro digbi sibẹ pẹlu ibọn lọwọ wọn. a ko foju ganni oluwọde kankan ni toll gate naa, ayafi awọn ọlọpaa to wa nibẹ. amọ ṣa, lara awọn eeyan naa ṣe iwọde lawọn agbegbe mii ni lekki, wọn tun ṣe iwọde ni surulere, ikeja ati festac. ti ẹ ko ba gbagbe, inu oṣu kẹwaa, ọdun 2020 ni iwọde endsars bẹrẹ, ki iwọde naa to gbọna mii yọ ni iloro lekki toll gate yii logunjọ oṣu kan naa, nini ọpọ ẹmi ti sọnu. lati asiko naa wa ni ijọba ipinlẹ eko ti kọ ki ẹnikẹmi maa ṣe iwọde ni iloro naa.",1 ọ̀wàrà 2022,amọ lẹyin ikede naa ni ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ eko sọ pe awọn ko ni gba ki iwọde kankan waye ni lekki toll gate. +mo tọrọ àforíjì fún ìyà àti ìṣẹ́ tó ń bá àwọn ọmọ naijiria fínra - aisha buhari,"oríṣun àwòrán, others iyawo aarẹ orilẹede naijiria, aisha buhari ti tọrọ aforiji lọwọ awọn ọmọ niajiria fun iya ati iṣẹ to n ba awọn ọmọ naijiria finra labẹ iṣejọba aarẹ buhari. iyawo aarẹ naa sọ ọrọ yii lati ṣe ayẹyẹ ayajọ ọjọ ominira orilẹede niajiria fun ọdun 2022 lasiko to n sọrọ ni ilu abuja. aisha buhari ni bi o tilẹ jẹpe ijọba aarẹ buhari ko munadoko to bo ti yẹ, ohun fi asiko yii tọrọ aforiji lọwọ awọn eniyan lati dariji awọn. o rọ awọn ọmọ naijiria lati ṣiṣẹ pọ ki orilẹede naijiria le lọ siwaju. ‘’ gbogbo wa lo ri bi owo naijiria ṣe dẹnukọlẹ, ti ko si si owo jaburata fun awọn araalu, eleyii to mu ki iṣoro de ba eto ẹkọ, ilera ati igbayegbadun awọn eniyan ni naijiria.’’ ‘’eleyii kọ mi lominu, ti mo si tọrọ aforiji lọwọ awọn araalu.’’ ‘’mo rọ awọn eniyan lati gbadura fun eto idibo ti yoo waye ni ọdun to n bọ, ki alaafia le jọba kaakiri orilẹede naijiria.’’ bakan naa lo ni ki opin le de ba ọrọ eto aabo to dẹnukọlẹ ni naijiria, awọn araalu gbọdọ fi ọwọ so wọpọ pẹlu ileeṣẹ ọmọogun naijiria. iyawo aarẹ tun gboriyin fun awọn ẹṣọ fun bi wọn ṣe n sa gbogbo ipa wọn lati ri pe opin de ba igbesunmọmi ni naijiria. aisha buhari fikun un pe ileeṣẹ iyawo aarẹ n gbiyanju lati pese ounjẹ ati iṣẹ fun awọn araalu, paapaa awọn obinrin ki iṣẹ le dinku. bakan naa lo ni ijọba gbọdọ mu ọrọ iṣẹ agbẹ ni ọkunkun dun, ki ebi ati iṣẹ le dikun ni naijiria.",1 ọ̀wàrà 2022,"aisha buhari ni ijọba gbọdọ mu ọrọ iṣẹ agbẹ ni ọkunkun dun, ki ebi ati iṣẹ le dikun ni naijiria." +ìdí tí oyetola kò fi ní àṣẹ láti díje gẹ́gẹ́ bií gómìnà ní osun rèé – iléẹjọ gíga,"oríṣun àwòrán, others ileẹjọ giga ni ilu abuja ti ni gomina isiaka oyetola ati igbakeji rẹ, benedict alabi ko laṣẹ labẹ ofin lati dije du ipo gomina ni ipinlẹ osun. ileẹjọ ni igbesẹ naa ko ṣẹyin bi gomina ipinlẹ yobe, mai mala buni to tun di ipo alaga ẹgbẹ oṣelu apc ṣe buwọlu idije wọn. ileẹjọ ni eyi tako ofin orilẹede naijiria nitori labẹ ofin buni kuna lati di ipo meji mu. ni ọjọ keje, osu kẹrin, ọdun 2022 ni arakunrin ogunwumiju (san) fi ẹsun kan ẹgbẹ oṣelu apc nipa iyansipo gomina ipinlẹ osun, isiaka oyetola gẹgẹ bi oludije sipo gomina nipinlẹ naa, ti alaga ẹgbẹ buwọ lu. agbẹjọrọ naa ni alaga ẹgbẹ ko lee di ipo meji mu labẹ abala ofin 285(14) (c), ti ọdun 1999. amọ awọn agbẹjọro gomina naa ti muyiwa atoyebi san ṣe adari fun ni ko si ohun to buru ninu ohun ti buni ṣe nitori o ni ẹtọ ni abẹ abala ofin 183. amọ adajọ ni iyansipo oyetola ko lẹṣẹ nilẹ nitori buni di ipo gomina ipinlẹ yobe mu, to si tun di ipo alaga ẹgbẹ oṣelu apc mu. ninu ọrọ rẹ, gomina ipinlẹ osun, adegboyega oyetola ti sọ fun awọn eniyan rẹ lati fi ọkan balẹ nitori mimi kan ko lee mi awọn. eyi ko ṣẹyin aṣẹ ileẹjọ giga ni ilu abuja to ni ko ni aṣẹ lati dije dupo gomina ni saa keji. oyetola ni awọn n gba ileẹjọ kotẹmilọrun lọ fun agbeyẹwọ idajọ ọhun. o ni gbogbo igbiyanju awọn alatako ni lati doju igbẹjọ to n lọ lọwọ ni ile ẹjọ to n gbẹjọ lori idibo bolẹ.",1 ọ̀wàrà 2022,"gomina ipinlẹ osun, adegboyega oyetola ti sọ fun awọn eniyan rẹ lati fi ọkan balẹ nitori awọn n lọ ile ẹjọ kotẹmilọrun." +pencom kéde bo ṣé lè mú nínú owó ìfẹ̀hìntì rẹ̀ fí sàn owó láti fí rà ilé,"oríṣun àwòrán, federalmortgagebank ajọ to n risi ọrọ owo ifẹhinti awọn oṣiṣẹ ni naijiria (pencom) kede laipẹ yi pe awọn ti gbe eto kalẹ ti oṣiṣẹ le fi mu ninu owo ifẹhinti rẹ fi san owo asansilẹ ile to ba fẹ ra. gẹgẹ baa ṣe gbọ, ifayegba yii wa ni ibamu pẹlu ofin to de atunto ilana owo ifẹhinti labẹ ofin to de eto owo ifẹyinti naijiria(section 89 (2) of the pension reform act 2014 iroyin yii jẹ ohun idunnu fun awọn oṣiṣẹ yala lẹka ijọba tabi aladani to n fi owo ifẹhinti pamọ to si tun n gbero lati da ile ara tiẹ ni. amọ ṣa pencom gbe awọn ilana kan kalẹ ti eeyan gbọdọ tẹle ko to le jẹ anfaani yii. atupalẹ awọn ilana yii ati ohun ti oṣiṣẹ to n ko owo ifẹhinti pamọ sọdọ pencom le ṣe ni akori apilẹkọ yii. oríṣun àwòrán, federalmortgagebank pataki julọ, ẹni to ba fẹ jẹ anfaani yi nikan lo le kọwe beere fun anfaani yi. wọn ko le ba oṣiṣẹ to n da owo ifẹhinti ṣe eto yii lorukọ rẹ. irufẹ ẹni to ba tẹle eto yi yoo kan si ileeṣẹ to n ṣeto owo ifẹhinti rẹ fun alaye ẹkunrẹrẹ. ileeṣẹ to n gba owo ifẹhinti rẹ taa n pe ni pfa yii yoo tẹ akọsilẹ dede iye owo to wa ni akoto ikowo ifẹhinti rẹ pamọ si. too ba ti gba eleyi tan, ri pe o pada si ọdọ ileeṣẹ to n ṣeto ẹyawokọle,gba lẹta ti wọn fifẹ ta ile naa fun ẹ,ri pe o ṣe ayẹwo daada lati faaye gba wọn lati mọ pe ida 25% nikan ni o le yọ ninu owo ifẹhinti lati fikun owo ile. ida 75% to ku , ibomiran lo ti ma wa iyẹn. too ba ti ri iwe ti ileeṣẹ to fẹ ta ile buwọlu, eleyi ni o ma mu lọ si ileeṣẹ to n ko owo ifẹhinti rẹ pamọ ti o si le tẹsiwaju lati gba ida 25% to nilo. oríṣun àwòrán, national pension commission ninu alaye ti pencom ṣe, owo to pọju ti eeyan le gba to ba fẹ ya owo fi kun owo ti yoo fi ra ile ko le ju ida marundinlọgbọn yii lọ. owo ko baa pọgaan ninu akoto rẹ, ko le gba ju iye yi lọ ati pe ti owo naa ko ba to lati le fun ẹni yi lanfaani lati san ida 25% ninu owo apapọ to ba fẹ fi ra ile yi, ileeṣẹ rsa le wo ọna mii lati fi ri owo yi ti eleyi ba wa si ni. alaye to wa lori eleyi yii ni pe ti eeyan ba ti kọkọ gba ida mẹẹdọgbọn kan lasiko ti iṣẹ bọ lọwọ rẹ, o tun le pada wa gba ida mẹẹdọgbọn mii ninu iye owo to n fi si akoto ifowo ifẹhinti rẹ si. ki o to le gba owo yi, o gbọdọ buwọlu iwe nibi ti yoo ti ṣalaye pe oun ti kọkọ gba ida mẹẹdọgbọn kan ṣaaju ṣugbọn bayi ti oun ti ri iṣẹ pada, oun fẹ gba iye owo yii lẹẹkan si lati le fi ra ile. yoo jẹ ajọmọ laarin ẹni to n da owo ati rsa rẹ pe owo ti wọn ba fun yii yoo kuro ninu gbogbo owo ti yoo gba ti o ba pada fẹhinti lẹnu iṣẹ. owo to ba wa ninu akoto ẹni to fẹ jẹ anfaani yi ko ṣe dandan ko to dede iye owo ti awọn to fẹ ta ile n beere. fun apẹrẹ, ti o ba fẹ ra ile ti wọn si pe iye rẹ ni miliọnu mẹwaa naira. ti o ba san ida 25% owo yi yoo maa ku si n2.5m. to ba wa ṣe wi pe iye to wa ninu akoto owo rẹ ko ju n1.5 miliọnu lọ, o lanfaani lati wa miliọnu kan to ku nibo miran ko wa paapọ pẹlu eleyi ti o wa ninu akoto rẹ lati fi jẹ ko to n2.5m to nilo. tọkọtaya le jijọ pa owo to ba wa ninu akoto ifowo ifẹhinti wọn pamọ lati le jẹ anfaani yi ti wọn ba fẹ ra ile. amọ bi o ba ku nkan bi ọdun mẹta tabi meji ti eeyan yoo fi fẹhinti lẹnu iṣẹ, ko ni lanfaanilati gba owo ida 25% taa n wi yii. lakotan, ẹni to ba fẹ jẹ anfaani yii nilati ṣe ayẹwo iroyin rẹ to kọ sọdọ rsa rẹ ki gbogbo nkan baa le lọ letoleto.",1 ọ̀wàrà 2022,ṣaaju asiko yi ọpọ to n fi owo ifẹhinti pamọ ni ko lanfaani lati mu ninu rẹ fi gbọ bukata bi ile kikọ. +wo ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa àrùn ebola àti bí o ṣe lè dáàbò bo ara rẹ lọ́wọ́ àrùn náà,"oríṣun àwòrán, afp ajọ to n gbogun ti ajakalẹ aarun ni africa, cdc, ti sọ pe oun ti n ṣeto lati jiroro pẹlu awọn ileeṣẹ apoogun oyinbo, to ti ṣe abẹrẹ ajẹsara to ṣe e ṣe ko koju ẹda aarun ebola tuntun, sudan strain. oludari ajọ cdc, dokita ouma ogwell, sọ ni ọjọbọ pe ti awọn ba fi ṣe aṣeyọri lori igbesẹ naa, ni kiakia ni awọn yoo bẹrẹ lilo abẹrẹ naa fun itọju pajawiri ni uganda. lọwọlọwọ, o ti pe eeyan mọkanlelọgbọn to ni ẹda aarun ebola, sudan strain naa, ti mẹfa lara wọn si ti ku ni uganda. ileeṣẹ eto ilera orilẹ-ede naa sọ pe ẹsẹ kan aye, ẹsẹ kan ọrun ni ọkan lara awọn oṣiṣẹ ilera to ko aarun naa wa bayii. ebola jẹ arun buburu kan to maa n mu iba lọwọ, pẹlu ara riro. yoo maa rẹ ẹni to ba ni arun naa, bẹẹ si ni irufẹ ẹni bẹẹ, ọna ọfun yoo maa dun un. ti arun ọhun ba ti wọ eeyan lara, irufẹ ẹni bẹẹ yoo maa bi, bẹẹ si ni yoo maa ya igbẹ gburu. nigba miran ẹwẹ, ẹjẹ le maa jade lara ẹni to ba ni arun ebola. ara ẹranko to ti ni arun naa tẹlẹ lo ti maa n ran eeyan, amọ ara ẹran igbẹ ti awọn eeyan n jẹ ni arun ọhun sodo si julọ. lati ibẹ lọ o le ran awọn ẹlomiran nipasẹ omi ara bii ẹjẹ, itọ́, eebi, atọ ọṃkunrin tabi ti obinrin, igbọnsẹ ati ooru. iwadii ijinlẹ ti fi han pe arun ọhun ṣi le wa ninu atọ ọkunrin lẹyin to ba ti gbawosan tan. ọna kan gboogi lati daabo bo ara ẹni lọwọ ebola ni lati ṣọra fun ẹni to ba ti ni arun naa lara. maṣe bọwọ pẹlu ẹni to ba ni arun naa rara, fifọ ọwọ ẹni pẹlu omi ati ọṣẹ naa ṣe pataki. awọn oṣiṣẹ eto ilera gbọdọ wọn aṣọ atawọn ohun idaabo bo ara ẹni miran ti wọn ba fẹ ṣe itọju alaarun ebola.",30 owewe 2022,"lọwọlọwọ, o ti pe eeyan mọkanlelọgbọn to ni ẹda aarun ebola, sudan strain naa, ti mẹfa lara wọn si ti ku ni uganda." +"táńkà agbépo gbiná ní kogi, ẹ̀mí èèyàn 20 ba lọ","oríṣun àwòrán, others ko din ni ogun eeyan to jona guruguru lasiko ti ọkọ agbepo kan gbina nipinlẹ kogi. iroyin sọ pe ọkọ agbepo naa to gbe bẹtiro, ṣubu lulẹ lori afara odo maboro nilu ankpa, nijọba ankpa, nipinlẹ kogi, lẹyin ti awakọ naa sọ ijanu ọkọ nitori bureeki to da isẹ silẹ lojiji. isẹlẹ naa waye lẹyin ọsẹ diẹ ti awọn adigunjale yabo awọn banki kan nipinlẹ naa, ti wọn si pa awọn araalu. awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn sọ fun awọn akọroyin pe ni nkan bi aago mẹta aabọ ọsan ọjọru ni ijamba ọkọ naa waye. wọn ni pupọ ninu awọn to ku, ni wọn jona kọja dida mọ. “bakan naa ni ọkọ tẹ awọn kan pa, ti ẹya ara wọn si fọn kaakiri oju popo. oludari ajọ ẹṣọ ojupopo, frsc, nipinlẹ kogi, stephen dawulung, sọ fun iwe iroyin daily trust pe awọn ko tii le sọ iye eeyan to ku. ọgbẹni dawulung sọ pe ọkọ agbepo naa, bọọsi kan ati ọkọ ayọkẹlẹ mẹta, to fi mọ ọkada mẹta, lo kagbako ijamba naa. oríṣun àwòrán, others bakan naa ni agbẹnusọ gómìnà ìpínlẹ̀ kogi, onogwu muhammed sọ fun bbc pe nígbà tí ìjánu ọkọ naa bajẹ lo wọ aarin ero lọ to si ṣokunfa iku ọpọ eniyan. mohammed ni ọpọ dukia awọn eniyan lo run sinu ijamba naa. o ni ijọba ti bẹrẹ igbesẹ lati ran awọn eniyan agbegbe ankpa lọwọ lori adanu ti iṣẹlẹ naa da si wọn lọrun. awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn tun ṣalaye pe niṣe ni ọkọ agbepo naa n gun awọn ọkọ miiran mọlẹ to si pa ọpọlọpọ eniyan. nnkan bi ọsẹ mẹta sẹyin ni awọn adigunjale yawọ awọn ile ifowopamọ kan àti agọ ọlọpaa ni ilu ankpa ọhun ti wọn si ṣekupa ọpọlọpọ eniyan nibẹ.",29 owewe 2022,awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn sọ fun awọn akọroyin pe ni nkan bi aago mẹta aabọ ọsan ọjọru ni ijamba ọkọ naa waye. +"fídíò, njẹ́ ẹ ṣì nífẹ̀ẹ́ kíka ẹ̀jẹ́ orílẹ̀èdè nàìjíríà? ẹ gbọ́ bí àwọn ọ̀dọ́ ṣe fèsì, duration 1,52","se iwọ le ka orin ogo ilẹ wa gangan? àsía aláwọ̀ ewéko àti funfun, orin ògó ilẹ̀ wa àti ẹ̀jẹ́ orilẹ-ede wà lára àwọn àmì ìdánimọ̀ ọmọ naijiria. lọdun 1960 ninu oṣu kẹwaa ni naijiria gba ominira kuro lọwọ ijọba amunisin ti ilẹ gẹẹsi ǹ jẹ́ o mọ àwọn èèyaǹ wọ̀nyí tó jà fún òmìnira nàìjíríà?. àsía aláwọ̀ ewé àti funfun, orin ògó ilẹ̀ wa àti ẹ̀jẹ́ orilẹ-ede wà lára àwọn àmì ìdánimọ̀ ọmọ naijiria. lẹyin eyi ni a kọ awọn orin ogo ilẹ wa ati ẹ̀jẹ́ fun orilẹ-ede ni eyi ti gbogbo ọmọ naijiria maa n ka nibi eto akanṣe ati nile iwe. ṣaaju ni minista fun ifitonileti, lai mohammed fẹ̀sùn kan àwọn ènìyàn naijiria pé ọ̀pọ̀ wọn ni kò orin ògò àti ẹ̀jẹ́ orílẹ̀-èdè wa! mo ṣe ileri fun orilẹ-ede mi naijiria ni ila akọkọ ninu ẹ̀jẹ́ naa to ṣe idanimọ ati imọsilara pe naijiria yii, ti gbogbo wa ni. lati jẹ olododo ati olotitọ eniyan ẹni ti o ṣee fi ọkan tan naa tun jẹ awọn amuyẹ to le mu idagbasoke ba naijiria ti gbogbo wa ba mu ileri yii ṣẹ. ẹ jẹ ki gbogbo wa lọ tun orin ogo naijira ati ẹjẹ yii kọ lede abinibi wa, ki a si fi gbolohun inu rẹ kọ awọn ewe iwoyi ki ọjọ iwaju naijiria le dun ju bayii lọ.",1 ọ̀wàrà 2022,"minista fún ìfitóniléti ni nàìjíríà,lai mohammed fẹ̀sùn kan àwọn ènìyàn naijiria pé ọ̀pọ̀ wọn ni kò mọ orin ògò àti ẹ̀jẹ́ orílẹ̀-èdè wa!" +náírà mẹ́rin ni owó tí a kọ́kọ́ pa nídìí àwàdà ṣíṣẹ - ẹ̀rẹ̀kẹ́niṣọ́ọ̀bù àti alájẹjù,"ẹ̀rẹ̀kẹ́niṣọ́ọ̀bù ní láti kékeré ni òun ti fẹ́ràn láti máa dáàpárá. gbajúgbajà àwọn adẹ́rìnínpòṣónú, adeyeye adebanjo ati timothy agboola tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí alájẹjù àti ẹ̀rẹ̀kẹ́niṣọ́ọ̀bù ti ṣàlàyé bí wọ́n ṣe bẹ̀rẹ̀ ìrìàjò wọn nídìí àwàdà ṣíṣe. wọ́n ní ìlú zaria ni àwọn ti jọ ń bá ìrìnàjò bọ̀ kí àwọn tó tún pàdé ní ìlú ilesha nígbà tí àwọn padà sí ìlú bàbá àwọn. ẹ̀rẹ̀kẹ́niṣọ́ọ̀bù ní láti kékeré ni òun ti fẹ́ràn láti máa dáàpárá tí àwọn ènìyàn máa ń sọ wí pé bàba sàlá ló yẹ kí òun máa tẹ̀lé. “nítorí pé ẹnu mi dùn gan, àwọn àgbàlagbà ló máa ń bámi ṣọ̀rẹ́ ní ìluú zaria.” “ìdí nìyí tí àwọn onítíátà fi fàmí mọ́ra.” alajeju ní nítorí àṣèjù máa ń pọ̀ nínú àwọn nǹkan tí òun bá ń ṣe ni wọ́n ṣe máa ń pe òun ní alajeju kìí ṣe wí pé òun máa ń jẹun jù.",29 owewe 2022,ẹ̀rẹ̀kẹ́niṣọ́ọ̀bù ní láti kékeré ni òun ti fẹ́ràn láti máa dáàpárá tí àwọn ènìyàn máa ń sọ wí pé bàba sàlá ló yẹ kí òun máa tẹ̀lé. +ọ̀pọ̀ èèyàn yínmú sí ọ̀rọ̀ buhari ní àyájọ́ òmìnira,"oríṣun àwòrán, screenshot awọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ oselu alatako ati awọn ọmọ naijiria kan ti n yinmu si ọrọ ti aarẹ muhammadu buhari sọ lọjọ ayajọ ominira naijiria. lara awọn ẹgbẹ oselu alatako naa la ti ri ẹgbẹ oselu labour ati pdp ti wọn yọ suti ete si ọrọ aarẹ, eyi to ni ijọba oun ti se ọpọ aseyọri lori aleefa. bẹẹba gbagbe, aarẹ muhammadu buhari lo kede ninu ọrọ to bawọn ọmọ naijiria sọ ni ayajọ ominira pe bi eeyan ko ba yin oun, oun yoo yin ara oun nidi awọn aseyọri ti oun ti se. aarẹ ni ijọba oun ti se gudugudu meje ati ya ya mẹfa nidi gbigbogun ti iwa ajẹbanu ati sise wo ilu basubasu, ipese ilera to poju owo atawọn nnkan miran. amọ nigba to n sọ ero rẹ lori ikede aarẹ buhari naa, agbẹnusọ fun ẹgbẹ oselu pdp, debo ologunagba ni ofuuftu fẹẹtẹ, aasa ti ko ni kaun ninu, ni ọrọ aarẹ naa. pdp ni kawọn ọmọ naijiria se agbeyẹwo awọn isẹlẹ to n waye lati fi se odiwọn ohun ti buhari sọ nitori ẹni ti yoo sa purọ, nii sọ pe ẹlẹri oun wa ni ọrun. pdp ni se a le sọ pe orilẹede naijiria ti ni aabo to pegede si lati ọdun 2015 ti aarẹ buhari ti gba ijọba ni abi aabo n buru si? ẹgbẹ oselu alatako naa ni yoo dara ki aarẹ buhari jẹ ki eto idibo to n bọ lọ gaaraga bo se yẹ nitori awọn ọmọ naijiria ko le se suuru mọ lati ri ẹyin isejọba buhari lọdun 2023. nigba to n ba iwe iroyin punch sọrọ, aarẹ tẹlẹ fun ẹgbẹ to n ja fẹtọ ọmọniyan, malachy ugwumadu salaye pe ofo ọjọ keji ọja ni awọn ileri ti aarẹ buhari se ko to dori aleefa. malachy ni ki ijọba buhari to gba ọpa asẹ lọdun 2015, ọpọ ileri to se ni ko tii mu wa si imusẹ, koda, ko mu ẹyọ kan sẹ ninu rẹ. amọ o ni yatọ si eyi, ohun ti awọn ọmọ naijiria ri ni pe owo ọpọ eroja n lọ soke, eto aabo mẹhẹ, ti iwa ajẹbanu si di tọrọ fọn kale. nigba toun naa n se agbeyẹwo ọrọ ti buhari sọ lati ki awọn ọmọ naijiria ku ayajọ ominira, alaga ẹgbẹ oselu alatako apga, victor oye ni irọ nla ni. oye ni aarẹ kan n mu omulomu ni nitori ohun to n waye lorilede naijiria yatọ gedegede si awọn aseyọri ti aarẹ mẹnuba. amọ o yan pe ireti ti awọn ọmọ naijiria n foju sun bayii ni pe ki aarẹ mu ileri rẹ to kede laipẹ yii sẹ pe oun yoo rẹyin awọn agbebọn, ti yoo ba fi di osu kejila ọdun 2022. lero tiẹ, oludije fun ipo aarẹ labẹ ẹgbẹ oselu aac, omoyele sowore ni buhari ko mọ ohunkohun to n waye ni naijiria. “ọpọ igba ni oun ti maa n kede pe orilẹede miran tabi aye mii ni aarẹ buhari n gbe, ti ko si mọ nnkan kan to n sẹlẹ lorilẹede yii.” oríṣun àwòrán, presidency aarẹ buhari ti tun paa laṣẹ fun awọn adari ile ẹkọ giga fasiti pe ki wọn ni kawọn olukọ pada si kilaasi kiakia. aarẹ n sọ eyi lara ọrọ to sọ ni owurọ ayajọ ọjọ ominira orilẹede naijiria to si ni oun ni imọlara iya to n jẹ awọn ọmọ naijiria. ""mo ni lati jẹwọ fun yin pe iṣe ti idena ṣe n wa fun ilọsiwaju lawọn ile ẹkọ giga wa n dun mi lara gidi gan mo si n lo anfani ọjọ ominira yii lati tun tẹnu mọ pipe fun ki awọn ọmọ ẹgbẹ academic staff union of universities (asuu) pada si kilaasi nigba ti a si n fi da wọn loju pe ojutuu yoo wa fun ọrọ to n ka wọn lara laarin ohun to wa nilẹ"". aarẹ buhari ni iṣejọba yii n ri ilọsiwaju ninu kikoju awọn ọrọ yii to ti wa nilẹ fun o le ni ọdun mọkanla o si ni ijọba apapọ yoo tẹ́iwaju lati ṣakojọ labẹle ati lẹyin odi lati ya owo lu ẹka eto ẹkọ ""ki awọn ọmọ waa lee kẹkọ yanju ati mimọ oniruuru iṣẹ ọwọ tori ẹkọ ni atọna akọkọ fun idagbasoke ọrọ aje ati ipese iṣẹ."" oríṣun àwòrán, google aarẹ buhari ni oun jẹjẹ oun si muu ṣẹ pẹ̀lu ifarajin lati mu ọgọrun miliọnu ọmọ naijiria kuro ninu ìṣẹ́ laarin ọdun mẹwa. + gẹgẹ bi awọn eeyan agbaye ṣe n ki orilẹede naijiria ku oriire lonii ayajọ ọjọ ominira orilẹede naa, aarẹ muhamadu buhari ti fi ọrọ rẹ ṣe ajimuna fawọn ọmọ naijiria. + ninu ọrọ naa ti atupalẹ kikọ rẹ hande latọwọ olugbaninimọran aarẹ lori iroyin ati ọrọ to kan araalu, femi adesina lori ayelujara, aarẹ buhari ni pẹlu ọkan ọpẹ si ọlọrun loun fi n ba awọn ọmọ naijiria sọrọ tori oun lo fun oun lanfani ati ṣe adari lori orilẹede nla yii ni asiko ipenija. + “tori mo mọ pe eyi ni yoo jẹ ọrọ ikẹyin mi fun ọjọ ominira gẹgẹ bi aarẹ yin, mo n ba ọgọọrọ ọmọ naijiria to gbagbọ ninu mi sọrọ ti wọn si gbaruku ti mi ninu bi mo ṣe n dari orilẹede yii ti gbogbo araalu ti ni anfani kan naa lati ṣe aṣeyọri ti wọn fẹ”. + oríṣun àwòrán, google aarẹ buhari ni iwuri lo jẹ fun oun pe itan oun ninu itan naijiria kii ṣe aṣiri kankan, akitiyan rẹ, ijakulẹ ati aṣeyọri rẹ lati di aarẹ ti ọpọlọpọ dibo yan lọdun 2015. + “nigba naa, bo tilẹ jẹ pe mo sọọ pe oke to wa niwaju mii yi ga ju ṣugbọn mo ṣe ipinu lati mu igbega ba ọrọ aje, koju iwa ajẹbanu ati koju ija si iṣoro aabo eyi si tun gba agbara sii pẹ̀lu ifarajin mi lati mu ọgọrun miliọnu ọmọ naijiria kuro ninu ìṣẹ́ laarin ọdun mẹwa”. + aarẹ ni tori pe awọn mọ iṣẹ to wa niwaju awọn, a wa akoko lati farabalẹ kojumọ ṣiṣe atunto ọrọ aje nipa wiwa ọna abayọ to dara lawọn apa ibi to ṣe koko ni ipele ijọba apapọ ati awọn ipele kekeke. + aarẹ ni lara awọn ibi ti ijọba oun ti ni ilọsiwaju ni gbigba iwa jẹgudujẹra danu eyi to ti rapala wọ gbogbo kọlọfin ibi idagbasoke orilẹede. + “a ro ileeṣẹ to koju iwa jẹgudujẹra lagbara lati lee koju iwa yii bẹẹ si ni a tun rii pe atilẹyin wa fun wọn labẹnu eyi to mu iṣẹ ya lati ri ọpọlọpọ owo gọbọi ti awọn eeyan ti ko pamọ si awọn orilẹede mii gba pada”. aarẹ ni igbesẹ yii ṣi n tẹsiwaju awọn ko si ni sinmi. + aarẹ buhari ni ohun ti ijọba oun ṣe lati le koju iṣoro aabo ni iṣẹ adọgbọnṣe ti awọn ṣe to mu adinku ba igbesunmọmi ni awọn apaa ila ooru-ariwa, awọn ajijagbara niger delta, ija ẹlẹyamẹya ati wahala ẹsin lawọn igun kọọkan ni naijiria to fi mọ awọn iṣoro mii to n dun mọhuru mọ orilẹede naijiria. “akitiyan wa lati ṣe atunto ọrọ aje farahan ninu ipenija ifasẹyin gboogi meji to fi naijria lakalaka”. ẹwẹ, aarẹ sọ oniruuru idamu ti naijiria ti foju ri ni ti ọrọ aje to si tun sọ igbesẹ ti wọn gbe fun apẹẹrẹ mimu idiwọ ọlọdun pipẹ kuro lọna awọn to wu lati wa dokoowo ni ẹka po rọbi ati afẹfẹ gaasi eyi to si hande ninu fifọwọ si abala ofin ileeṣẹ ipọnpo ti ọdun 2021. + + lara awọn koko mii ti aarẹ buhari mẹnu pe ijọba oun ti ṣe aṣeyọri ni: + + ẹka eto ọgbin + okoowo kekeke ati eto ẹyawo + imọ ẹrọ ibaraẹnisọrọ eyi ti yoo ran pipa owo ilẹ okere wọle. + aarẹ tun sọ pe bi awọn ṣe n pa ina iṣoro aabo to doju kọ naijiria lati ọjọ pipẹ ni awọn mii to tun ṣajoji si orilẹede yii bẹrẹ si ni yọju paapaa bii ijinigbe, fifiyajẹni, pipa awọn alaiṣẹ, janduku to si ni gbogbo eyi ni awọn oṣiṣẹ alaabo n koju. + “mo ni imọlara iya ti awọn ọmọ naijiria n la kọja mo si n fi daa yin loju pe ai kaarẹ yin ati suuru yin ko ni ja si asan tori ijọba yii yoo tun fi agbara kun agbara lati doju kọ gbogbo ipenija yii.”",1 ọ̀wàrà 2022,ẹgbẹ oselu pdp wa n beere pe se a le sọ pe naijiria ni aabo to pegede si lati ọdun 2015 ti aarẹ buhari ti gba ijọba ni abi aabo n buru si? +àṣírí àwọn ọkùnrin tó ń fi abẹ́rẹ́ pọ́ ikùn ọmọdé síta torí agbe ṣíṣe tú,"oríṣun àwòrán, @benhundeyin orisirisi ọgbọn ti awọn onisẹ ibi n da lati gba owo loju popo lo ti n tu sọwọ awọn agbofinro bayii. ọpọ igba si ni a maa n ri awọn eeyan to n fi awọn ewe tọrọ owo pe wọn ni arun kan tabi omiran lara. amọ ilẹ ti mọ ba afurasi ọdaran kan lara wọn, ti ọwọ ileesẹ ọlọpaa eko si ti tẹ kẹ, se bi irọ ba lọ titi fun ogun ọdun, ọjọ kan soso ni otitọ yoo ba. ikede kan ti agbẹnusọ fun ileesẹ ọlọpaa fi soju opo ayelujara twitter rẹ, ti sisọ loju rẹ pe ọwọ oun ti tẹ eeyan mẹrin to n fi awọn ọmọ kekeke tọrọ agbe loju popo. gẹgẹ bi benjamin hundeyin ti wi, kii se pe awọn afurasi naa n fi awọn ọmọde naa, ti wọn to mẹrin se agbe nikan, n se lo tun gun wọn ni abẹrẹ oogun kan. abẹrẹ oogun naa ni yoo jẹ ki ikun awọn ọmọde naa wu gbẹndu bii iku alarun, ti yoo si ta sita ringindin bii ẹni to ni arun olokelẹ. hundeyin, to fi ikede naa sita lọjọ abamẹta salaye pe se ni awọn ọkunrin onisẹ ibi naa maa n ko awọn ọmọ ọhun lati abule wa si ilu nla nla lati wa fi wọn se agbe. o tun salaye pe lẹyin ti wọn ba ko awọn ọmọde naa de aarin igboro, ni wọn yoo wa dokita onisegun oyinbo kan, ti yoo ba wọn gun awọn ọmọde ọhun ni abẹrẹ. oríṣun àwòrán, @benhundeyin “abẹrẹ yii ni yoo jẹ ki ikun wọn wu sita rogodo, ti wọn yoo si maa fi wọn gba owo loju popo pe awọn ọmọ naa n se aisan. aanu yoo se awọn eeyan to ba n wo awọn ọmọ naa, ti wọn yoo si maa dawo jọ fun wọn lati fi se itọju wọn. amọ ikun yii yoo pada lọ silẹ lẹyin wakati diẹ, ti wọn ba ti sisẹ agbe wọn tan.” agbẹnusọ fun ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ eko wa rọ awọn obi lati maa se akiyesi iru awọn eeyan ti wọn ba n ko ọmọ wọn fun tabi fi wọn sọ. oríṣun àwòrán, @benhundeyin oríṣun àwòrán, screenshot iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ oyo ti sọ àrídájú rẹ̀ wí pé dandan ni kí àwọn fìyà tó tọ́ jẹ àwọn tó ṣekúpa ọ̀gá ọlọ́pàá ní ìlú iganna, ìjọba ìbílẹ̀ iwajowa ní alẹ́ ọjọ́ ìṣẹ́gun ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n, oṣù kẹsàn-án. nínú àtẹ̀jáde tí agbẹnusọ ọlọ́pàá oyo, adewale osifeso gbé jáde ló ti ṣàlàyé ohun tó ṣẹlẹ̀ gangan níbẹ̀. kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá oyo, adebowale williams tó fajúro sí ìkọlù tí àwọn agbébọn kan ṣe sí àwọn ọlọ́pàá níbi tí dco àti ọkùnrin kan ti pàdánù ẹ̀mí wọn ní àwọn méjì mìíràn náà farapa. williams ní àwọn méjì tó farapa ọ̀hún ti wà ní ilé ìwòsàn ìjọba kan níbi tí wọ́n ti ń gba ìtọ́jú lọ́wọ́. ó ní ìwádìí àwọn ṣàfihàn wí pé àwọn ọlọ́pàá ọ̀hún ń ṣe iṣẹ́ wọn, gẹ́gẹ́ bí òfin láti máa ṣàyẹ̀wò àwọn ọ̀kadà tí kò bá ní nọ́mbà ìdánimọ̀ lójúnà àti dín ìwà ọ̀daràn kù. kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá ní wí pé ojúṣe àwọn ọlọ́pàá yìí ni wọ́n ń ṣe lọ́wọ́ ní òpópónà elejoka-igangan kí àwọn jàǹdùkú náà tó ṣe ìkọlù sí wọn. ó ṣàlàyé pé ìkọlù yìí lọ ṣokùnfà ikú ọ̀gá ọlọ́pàá tó ń mójútó ìwà ọ̀daràn (divisional crime officer, dco) àti ọkùnrin kan tó wà ní àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá nígbà tí wọ́n ń jà fitafita láti rí wí pé àwọn ọ̀daràn náà kò ráyè wọ àgọ́ ọlọ́pàá iganna. bákan náà ló ní dpo àgọ́ ọlọ́pàá náà àti ìǹsìpẹ́kítọ̀ kan tún fara gbọgbẹ́ àdá èyí tí àwọn ọ̀daràn náà fi ṣá wọn tí wọ́n sì ti wà ní ilé ìwòsàn báyìí níbi tí wọ́n ti ń gba ìtọ́jú lọ́wọ́. àtẹ̀jáde náà fi kun pé kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá ti wá ní kí ẹ̀ka tó ń mójútó ìwádìí ìwà ọ̀daràn bẹ̀rẹ̀ ìwádìí ní kíákíá láti lè tètè fojú àwọn aṣebi náà hàn. bákan náà ló ní àwọn ti náwọ́ gán àwọn kan lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà. oríṣun àwòrán, screenshot àwọn agbébọn ti tún ṣe ìkọlù sí igangan, ìjọba ìbílẹ̀ ibarapa ní ìpínlẹ̀ oyo. ìròyìn tó tẹ bbc news yorùbá lọ́wọ́ ní àgọ́ ọlọ́pàá ìlú igangan ni àwọn agbébọn náà ṣe ìkọlù sí tí wọ́ sì pa ọ̀gá ọlọ́pàá dco. bákan náà ni wọ́n tún pa afurasí kan tó wà ní àhámọ́ àgọ́ ọlọ́pàá náà. ní alẹ́ ọjọ́ ìṣẹ́gun, ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n oṣù kẹsàn-án ni ìkọlù náà wáyé. bákan náà ni ìròyìn ní dpo, ìǹsìpẹ́kítọ̀ ti iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ọ̀hún náà fara gbọta. agbẹnusọ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ oyo, adewale osifeso fìdí ìròyìn náà múlẹ̀ fún bbc ní òwúrọ̀ ọjọ́rú. osifeso ní ìwádìí ti bẹ̀rẹ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ náà tí àwọn yóò sì fi ohun tí àwọn bá bábọ̀ léde. ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìròyìn ń bọ̀ láìpẹ́.",28 owewe 2022,wo báwọn ọkùnrin ṣe ń gún ọmọdé ní abẹ́rẹ́ òògùn láti fi wọ́n ṣe agbe lójú pópó. +ní yàjóyàjó àwa ò ní jìròrò pẹ̀lú àwọn tó ń jó lórí egungun ara èèyàn àyàfi ... – ukraine,"and we ll keep you signed in. sign in or register you need one to watch live tv on any channel or device, and bbc programmes on iplayer. it’s the law. nípasẹ̀ adedayo owolabi, funmi jokotade àti olubusola afolayan gbogbo àkókò tí a kọ jẹ́ ti uk olugbaninimọran kan fun aarẹ́ ukraine ti kọ lati fọwọ si ipe latọdọ aarẹ orilẹede russia, vladmir putin pe ki ilu kyiv pada si ijoko didunaa dura – o ni ko si koko kankan ninu jijomi toro ọrọ pẹlu “awọn ti wọn n jo lori egungun awọn eeyan.” ninu atẹjade kan ti mykhailo podolyak fi sita ni o ti sọ pe didunadura ko lee ṣeeṣe ayafi pẹlu “aarẹ tuntun ti russia” – to si n tẹnu mọ ọrọ kan lara eyi ti ọga rẹ, volodymyr zelenzky sọ. bakan naa ni ọjọ ẹti, aarẹ putin rọ ukraine pe “ki wọn jawọ titani danu ki wọn si pada sori ijiroro” gẹgẹ bo ṣe kede pe russia n gbero ati fipa gbajọba ẹkun bii mẹrin ti wọn to ti baba wa ni sakani wọn. aarẹ amẹrika, joe biden ti kilọ fun orilẹede russia pe united states ko ni foya rara pẹlu bi aarẹ vladimir putin ṣe kede pe awọn yoo fi tipatipa gba ẹkun bii mẹrin to wa ni ukraine. ni ọjọ ẹti ni aarẹ putin sọ ọrọ idunkokomọni pe awọn yoo lo awọn nkan ijagun nla-nla lati dabo bo awọn agbegbe naa. o ni “titi lai ni wọn yoo jẹ ara russia” – amọṣa ukraine ṣeleri lati tu wọn silẹ. adari ẹgbẹri nato, jens stoltenberg sọ pe ọwọ ti russia fẹ gbe yii lo jẹ eyi to lee bu bẹntiroo sinu ina rogbodiyan yii lati igba ti ogun ti bẹrẹ. ninu ọrọ kan to sọ ni moscow, adari russia sọ pe awọn araalu to wa ni apa guusu ukraine bii donetsk ati luhansk to fi mọ kherson ati zaporizhzhia ni iha guusu lo ti pohun pọ pe awọn yoo wa pẹlu awọn eeyan awọn, ilẹ iya wọn”. ẹwẹ, aarẹ biden sọ pe ọrọ aarẹ putin kan jẹ lati ta si awọn eeyan iha iwọ oorun. o ni “ni ọsẹ to kọja, ọgbẹni putin sọ pe orilẹede oun ni oniruuru nkan ijagun to si fẹ lo gbogbo ọna to ba ni lati ja”. torinaa, aarẹ biden fọhun pe ọrọ akẹgbẹ rẹ ti russia jẹ ọrọ to buu jai to si lee dẹru bani amọfi kun un pe “awọn ko ni bẹru”. “amẹrika atawọn alabaṣe rẹ ko ni foya rara”. o n sọ eyi ni gbangba nile aarẹ to n na ika sinu ẹrọ ayaworan pe “iwọ gaan ni mo n bawi pe awọn ko bẹru. “amẹrika ti gbara di digbi pẹlu awọn nato alabaṣe wa, lati daabo bo gbogbo ala nato. ṣe lo tun tẹnu mọọ pe “ọgbẹni putin, ma ṣi mi gbọ o, mo tun sọ pe gbogbo àlà.” lakọlakọ ni iro ibọn n dun nitosi ibudo ọmọ ogun kan nilu ouagadougou, lorilẹ-ede burkina faso ni owurọ ọjọ ẹti. ileeṣẹ agbohunsafẹfẹ orilẹ-ede naa, la radiodiffusion télévision du burkina, si ti dawọ igbohunsafẹfẹ duro. iroyin yii jade lẹyin ti ọpọ ọmọ ogun ti ku nileeṣẹ ọmọ ogun orilẹ-ede naa lati ọsẹ diẹ sẹyin. inu iporuru ọkan si ni awọn olugbe orilẹ-ede naa wa bayii pẹlu bi iro ibọn ṣe n dun lati baraaki ologun ti baba sy to wa ni olu ilu orilẹ-ede naa, ouagadougou. ileeṣẹ iroyin afp sọ pe ibọn n dun ni ile aarẹ, ati olu ileeṣẹ ologun to ditẹ gbajọba to waye laipẹ yii. gbogbo awọn opopona nla to wa nilu naa si ni awọn ọmọ ogun ti di pa. lọwọlọwọ, a ko tii le sọ ẹni to paṣẹ kiko awọn ọmọ ogun si aarin ilu ati ile aarẹ. amọ nkan to daju ni pe lọjọ aje nikan ṣoṣo, oku ọmọ ogun mọkanla ati ti aadọta araalu ni wọn ri ni ilu djibo, lẹyin ti awọn kan dena de awọn ologun. oṣu kinni, ọdun yii ni ọgagun paul-henri sandaogo damiba ditẹ gbajọba, pẹlu ileri pe oun yoo fi opin si igbesunmọmi awọn alakatakiti ẹsin islam to bẹrẹ lọdun 2015. ṣugbọn titi si akoko yii, rogbodiyan ko tii dawọ duro nibẹ. ilé ẹjọ́ gíga ní kí oriade ní eko lọ sí ẹ̀wọ̀n ọdún 15 adajọ hakeem oshodi ti ile ẹjọ giga ni eko ti gbe idajọ kalẹ pe ki baalẹ shangisha, mutiu ogundare, fi aṣọ penpe roko ọba fọdun mẹẹdogun lori ẹsun pe o pete pero ijinigbe ara rẹ. iwa to hu yi gẹgẹ bi adajọ ṣe wi ṣakoba omi alaafia ilu. bakan naa ni ile ẹjọ tun ran ọkan lara awọn aburo rẹ adams mohammed naa lẹwọn. gẹgẹ bi awọn to gbe ẹjọ yi lọ siwaju ile ẹjọ ṣe wi wọn ni ọjọ karun un oṣu keje ọdun 2017 ni baalẹ pete yi. wọn ṣalaye pe ogundare jọwọ ara rẹ ki wọn baa le jiigbe lna ti da omialaafia ilu ru. koda wọn ni iyawo rẹ ati aburo rẹ lọwọ ninu fiimu ti wọn po pọ yi. toriu iwa to hu lọjọ naa lọhun, gomina ipinlẹ eko to wa lori aleefa akuinwumi ambode yọ nipo rẹ gẹgẹ bi balle shangisha. ninu idajọ ti adajọ oshodi gbe kalẹ, o ni ki ogundare lọ sẹwọn ọdun mẹwaa fun ẹsun akọkọ lallae si anfaani owo faaini. fun ẹsun keji o ni ko lọ sẹwọn ọdun kan pẹlu anfaani lati san owo faaini ẹgbẹrun lọna igba naira. akọrin takasufe raapu lorileede amẹrika coolio ti jade laye. akọrin yi ti ọpọ ranti fun orin rẹ gangsta s paradise dagbere fun duniya lẹni ọdun mọkandinlọgọta. ọrẹ rẹ ọlọjọ pipẹ jarez posey sọ fawọn akọroyin ni amẹrika pe awọn ba oku rẹ ni ilẹẹlẹ baluwe ile ọrẹ rẹ to wa ni los angeles. lati nkan bi ọdun 1980 ni coolio ti bẹrẹ iṣẹ orin ṣugbọn o fẹsẹ rinlẹnile agodo nigba to gbe orin gangsta paradise jade lọdun 1995. nkan to ṣokunfa iku rẹ gaan ko ti daju titi di akoko yi. amọ ọgbẹni posey to koko gbe iroyin iku rẹ jade sọ pe awọn oṣiṣẹ ilera s pe o ṣeese ki o jẹ pe ọkan rẹ ṣadede mu ina lọ(cardiac arrest) coolio,ti orukọ abisọ rẹ n jẹ artis leon ivey jr gba ami ẹyẹ grammy fun orin gangsta s paradise ti wọn si lo orin naa ninu fiimu dangerous minds nibi ti gbajugbaja oṣere tiata nii michelle pfeiffer ti kopa. orin yi jẹ orin tawọn eeyan fẹran lati maa gbọ koda o ti le ni eeyan biliọnu kan to ti gbọ loju opo spotify gẹgẹ bi wọn ṣe fi si oju opo wọn. nigba aye rẹ, coolio ṣiṣẹ akọrin yi fun nkan to le ni ogoji ọdun. laarin igba taa n wi yi, o gbe alibọọmu mẹjọ jade to si ami ẹyẹ american music award. bẹẹ naa ni o gba ami ẹyẹ mtv video music awards mẹta. awọn orin rẹ mi to gba ori afẹfẹ to gbe jade nigba naa ni fantastic voyage, rollin with my homies, 1, 2, 3, 4 (sumpin new), ati too hot. titi to fi jade laye, coolio ṣi n kọrin koda oun ati awọn akọrin aye atijọ mii bi vanilla ice ati young mc ṣi jọ kọrin papọ ni texas ni nkan bi ọjọ meloo kan ṣẹyin. snoop dog, mc hammer,ice cube ati vanilla ice ti n fi ọrọ ikẹdun iku rẹ ṣọwọ loju opo twitter. fidio arakunrin kan to din dundu iya fun awon akẹkọọ ilẹ ẹkọ kan lorilẹede cameroun ti da rugudu silẹ bayii lori ayelujara. fidio ọhun ti awọn eeyan ẹgbẹrun mejidinlaadọjọ (148,000) ti wo lori twitter ṣe afihan arakunrin kan to wọ kootu alawọ funfun kan, to n lo okun funfun lati na awọn akẹkọọ naa ti wọn da ikun delẹ ninu aṣọ ileẹkọ wọn. ko din ni akẹkọọ ọgbọn, ninu eyi ti awọn obinrin pẹlu wa ninu, ninu fidio naa. ni ọjọ iṣẹgun ni iṣẹlẹ yii ṣẹlẹ ni ileẹkọ aladani kan ni ilu yaoundé to jẹ olu ilu orilẹede cameroun. ọkan lara awọn oṣiṣẹ ileẹkọ naa ṣalaye fun bbc pe pipẹ ti awọn akẹkọọ naa pẹ de ileẹkọ lo ṣokunfa iya ti wọn jẹ. oludasilẹ ileẹkọ naa sọ fun bbc pe, minisita fun eto ẹkọ girama lorilẹede cameroun, nalova lyonga yoo ṣe abẹwo si ileẹkọ naa l’ọjọru nitori iṣẹlẹ naa. ọpọ lo ti bu ẹnu atẹ lu ohun to ṣẹlẹ naa lori ayelukara “a gbọdọ dẹkun iwa ipa lawọn ileẹkọ. aṣilo agbara niyi.” ni ọrọ ti eeyan kan sọ loju opo twitter “idi ti awọn aṣiwaju alasilo agbara ṣe pọ nilẹ afrika. a kii fẹ ba awọn aṣiwaju wi, koda bo ba jẹ pe ohun ti wọn n ṣe ba kudiẹ kaato” ni ọrọ ti ẹlomiran sọ loju opo twitter kan naa. ""we really need to stop school violence. it is abuse,"" one twitter use said. amọṣa awọn kan sọ pe, ni t awọn o, awọn ko ni ariwisi kankan si ohun to ṣẹlẹ naa. gẹgẹ bi eeyan kan lori twitter ṣe tun sọ, “wọn to ọrẹ si idi awa naa bi eleyii, o tubọ jẹ ki iwa ọmọluwabi, nini afojusun rere ati mimọ ohun to tọ ati eyi to yẹ wọ wa lara bi ẹwu ni.” ofin ko fi aye fifi iya jẹ akẹkọọ nileẹkọ silẹ lorilẹede cameroun, amọ o si n waye nibẹ. ṣaaju l’osu yii, olukọ kan gba iwe lọ rọkun nile fun igba diẹ lẹyin to na akẹkọọ ileẹkọ girama oniṣẹọwọ kan lẹkun gusu orilẹede naa debi pe o sese ninu oronro inu rẹ. minisita feto ẹkọ girama lorilẹede naa ni lati pe ipade apero apapọ lori iwa ipa lawọn ileẹkọ, eyi yoo si wayr laarin ogunjọ si ọjọ kẹtalelogun oṣu kejila nilu yaoundé ẹgbẹgbẹrun ọmọ ilẹ japan ti jade lati ṣe isin idagbere fun adari orilẹede naa tẹlẹ, shinzo abe ti wọn yinbọn pa. awọn onilẹ ati alejo to fi mọ awọn adari orilẹede ti wọn jẹ ọrẹ timọ-timọ pẹlu orilẹede japan ni wọn pejọ pọ si ibi ipejọpọ idaro naa. bio tilẹ jẹ pe awọn kan ko fi ara mọ bi wọn ṣe isinku rẹ ni isinku orilẹede( state burial). awọn ti ko faramọ mọ isinku naa ṣe ifẹhọnuhan lasiko ti isinku naa n lọ lọwọ. oṣu keje ni agbebọn kan yinbọn lu shinzo abe leemeji, to si gba ibẹ lọ opo aarẹͅ orileede japan papoda naa, akie abe lo wọ kimono dudu, to si n rin jẹlẹnkẹ pẹlu eeru ọkọ rẹ lọwọ ninu igo ti wọn fi n ṣe isinku. lẹyin naa lo gbe e si ori ipele ti wọn si aṣọ funfun bo pẹlu aworan olotu orilẹede naa tẹlẹri. shinzo abe to jẹ ẹni ọdun mẹtadinlaadọrin ki o to papoda ni wọn pa ni oṣu keje lẹyin ti wọn fi ibọn ti wọn ṣe ni abẹle yin ibọn lu ni ẹẹmeji, to si gba ibẹ lọ. iṣekupani naa jẹ iyalẹnu fun orilẹede japan nitori iru iṣẹlẹ naa ko i tii waye nibẹ ni ọpọlọpọ ọdun sẹyin. awọn ololufẹ rẹ naa kii fun ọpọlọpọ ọdun to fi jẹ aarẹ wọn, ti o si fun wọn ni ifọkanbalẹ ni gbogbo igba to fi wa ni ipo. amọ awọn ti ko faramọ iru isinku ti wọn ṣe fun un naa n ṣe ifẹhọnuhan wọn sunmọ ibi ti isinku naa ti n waye. o le ni kilomita ila ti awọn eniyan duro lati ṣe ẹyẹ ikẹyin fun sinzo abe. ileeṣẹ aarẹ lorileede naijiria ti fesi si iroyin to gbode pe aarẹ muhammadu buhari ti fọwọ si pe ki wọn yọ festus keyamo kuro nipo agbẹnusọ igbimọ ipolongo idibo bola ahmed tinubu sipo aarẹ naijiria. bola tinubu n dije labẹ ẹgbẹ oṣelu all progressives congress to jẹ ẹgbẹ aarẹ buhari. agbẹnusọ aarẹ garba shehu lo fidi ọrọ yi mulẹ loju opo rẹ ni twiter to si ni iroyin ofege gba a ni ọrọ yi jẹ. shehu sọ pe inu aarẹ buhari ati bola ahmed tinubu dun si iṣẹ ti keyamo n ṣe ni ipo rẹ gẹgẹ bi agbẹnusọ igbimọ ipolongo sipo aarẹtinubu. koda o sọ pe awokọṣe ni keyamo jẹ fawọn ẹgbẹ oṣelu mii nipa iṣẹ to n ṣe garba sheu wa fikun pe awọn mọ nipa ete tawọn kan n pa lati ṣi awọn olori ẹgbẹ apc lọna ki wọn baa le ṣakoba fun ipolongo ẹgbẹ naa fun ipo aarẹ. o rọ awọn ọmọ ẹgbẹ lati ma ṣe faaye gba ayederu iroyin ti awọn kan n gbe kaakiri nipa awọn olori wọn. ọgbẹni keyamo lo ṣe agbẹnusọ igbimọ ipolongo idibo aarẹ muhammadu buhari nigba to dije dupo ni saa keji rẹ lọdun 2019. awọn to n sọ pe buhari fẹ yọ keyamo a maa sọ pe niṣe lo n sọ ọrọ tabuku ijọba buhari ki o baa le gboriyin fun ipolongo ipo aarẹ bola tinubu. keyamo naa fun ara rẹ ti ṣaaju fesi si iroyin iyọni nipo rẹ ti ileeṣẹ iroyin kan ni naijiria gbe jade. esi naa wa loju opo rẹ ni twitter agbé́́bọn pa ènìyàn 12 niʹ ilé èͅkọ́ agbebon ti ṣina bolẹ ni ileẹkọ kan ni russia, to si pa eniyan mejila. awọn to farapa ninu iṣẹlẹ naa jẹ mọkanlelogun. awọn ọmọde meje lo wa ninu awọn to ṣe alaisi ninu iṣẹlẹ naa, ti gbogbo akẹkọọ to wa ni ileẹkọ naa si le ni ẹgbẹrun kan. iṣẹlẹ naa waye ni agbegbe izhevsk. loju ẹsẹ kan naa ni agbebọn naa yinbon pa ara rẹ. iwadii fihan pe ọmọ ileẹkọ naa tẹlẹri ni agbebọn naa. ileeṣẹ iroyin ni russia fi awọn fidio lede nibi ti awọn eniyan ti n paya . ti wọn si n sa asala fun ẹmi wọn. fọnran kan ṣafihan ẹjẹ ni ilẹ kilaasi ati oju ibọn lara ferese pẹlu awọn ọmọde ti wọn bẹrẹ mọlẹ pẹlu ifoya. ni apapọ, ogo wẹẹrẹ meje,agbalagba mẹfa ati awọn ẹsọ alaabo meji lo ba ikọlu agbebọn naa lọ. nibayii, ijọba ti paṣẹ ki wọn ko awọn akẹkọọ ati olukọ kuro nibẹ ni kiakia. bakan naa ni idaro ti bẹrẹ bayii titi di ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kẹsan an, ọdun 2022. obinrin kan, giorgia meloni, ti n mura lati di olootu ijọba akọkọ ni italy bayii bo ṣe n jawe olubori ninu eto idibo to n lọ lọwọ lorile­̣-ede naa. meloni sọ pe oun ko ni fa ori apakan fikan silẹ ninu iṣẹjọba oun lẹyin ibo naa. ninu awọn esi to ti n jade lọwọ, ibo tirẹ ti fi ida mẹrindilọgbọn ju ti ẹni to tẹle, enrico letta, lọ. lara awọn to n ṣatilẹyin fun meloni ni silvio berlusconi, to jẹ olootu ijọba orilẹ-ede naa nigba kan ri. to ba ni ida mẹrinlelogoji ibo naa, egbẹ rẹ ni yoo maa ṣakoso ile igbimọ aṣofi ilẹ naa. ẹwẹ, ọwọ aarẹ orilẹ-ede naa, sergio mattarella ni ẹni ti yoo di olootu ijọba ilẹ naa wa. lara awọn ohun ti meloni fi kede lasiko ipolongo ibo ni pe oun ko ni faye gba ibalopọ laarin akọ si akọ ati abo si abio. o tun sọ pe oun yoo gbogun ti awọn alakakiti ẹsin musulumi. lara awọn eto ti meloni ni ireti lati ṣe to ba de ori alefa ni fifopinsi bi awọn eeyan ṣe n wọ orilẹ-ede naa lọna aitọ pẹlu ọkọ oju omi lati orilẹ-ede libya, atawọn eto mii fun itura awọn araalu. àwòrán òkúta tó ṣààmì ibi tí òkú ọbabìnrin elizabeth wọlẹ̀ sí ti jáde sí gbangba, wo ìyè owó tí wàá ná fi wo o aafin buckingham nilẹ gẹ̀ẹ́sì ti ṣagbejade aworan àkọ́kọ́ okuta iyebiye to saami ibùsùn ikẹyin ọbabìnrin elizabeth ni windsor. nibayii, wọn ti gbe okuta isinku dudu naa sori ilẹ̀ ile ijọsin george iv memorial chapel níbi tí wọ́n sin òkú ọbabìnrin elizabeth sí lọ́jọ́ aje. wọn kọ orúkọ ará òkúta náà ní ìrántí ọbabìnrin, àwọn òbí rẹ̀ àti ọkọ rẹ̀ tó ti d olóògbé, duke ti edinburgh. eleyi lo rọpo okuta palaba ti wọn ṣe fún ọba george vi ati iya ọbabìnrin. nibayii, okuta tuntun naa ka bayii pé: ""george vi 1895-1952"" ati ""elizabeth 1900-2002"" ati pe ""elizabeth ii 1926-2022"" ati"" philip 1921-2021"". awọn ọba alaye mẹrin yii lo wa ni ilana ẹgbẹ́ awọn ""garter"" eyi to jẹ agba ju ni ilana awọn ẹniabuọláfún"" ni ilẹ̀ britain. awọn ọrọ idagbere to dara jọjọ àti ọpọlọpọ ododo lo yí okuta ara ọ̀tọ̀ naa ka ti wọn gbe sori ibi isinku ọbabìnrin elizabeth. bẹẹ si ni wọn fi ọwọ gbẹ ọrọ ati orúkọ sori rẹ pẹlu awọ dúdú belgium ko lee wa ni ibamu pẹlu ohun to wa nibẹ tẹlẹ̀. o ṣeéṣe ko jẹ pé àwọn araalu yoo lè san owó lati le wo okuta ara ọ̀tọ̀ yii ni kọọkan láti ọjọ ọjọbọ. iroyin ni iye owo ti agbalagba yoo san lati wọlé sibi to wa ni £28.50 lọ́jọ́ satide àti £26.50 làwọn ọjọ́ to ku. ẹgbẹ oṣelu all progressives congress, apc, ti sọ idi ti ko fi si orukọ igbakeji aarẹ, yemi osinbajo lara awọn ọmọ igbimọ ipolongo ibo fun bola tinubu. ọjọ satide ni ẹgbẹ naa gbe akọsilẹ orukọ awọn ọmọ igbimọ naa, ti yoo ṣa amojuto ipolongo ibo fun oludije si ipo aarẹ ninu ẹgbẹ naa, tinubu ati igbakeji rẹ, kashim shettima. orukọ eeyan 422 ni wọn fi sita, ninu eyi ti awọn oṣere naa wa ninu rẹ. lẹyin ti apc fi awọn orukọ naa sita si ni awuyewuye ti bẹrẹ, ti ọpọ si n beere pe kilode ti wọn ko fi osinbajo si. ṣugbọn ninu atẹjade to fi sita, minisita keji fun ọrọ oṣiṣẹ ni naijiria, festus keyamo, to tun jẹ agbẹnusọ fun igbimọ ipolongo naa, sọ pe aarẹ muhammadu buhari lo sọ pe wọn ko gbọdọ fi orukọ yemi osinbajo ati akọwe fun ijọba apapọ, boss mustapha sinu igbimọ naa “nitori pe wọn ni iṣẹ iṣejọba lati gbajumọ”. keyamo sọ pe ko bojumu ki gbogbo awọn olori ijọba fi iṣẹ wọn silẹ lai ṣe nitori ipolongo ibo fun ẹgbẹ. ọjọgbọn osinbajo naa dije ninu ibo abẹle ẹgbẹ oṣelu apc lati ṣoju wọn fun ipo aarẹ ninu eto idibo gbogbo gbo ọdun 2023, amọ o fidirẹmi. 2023 elections: tinubu ṣèpàdé pẹ̀lú ìgbìmọ̀ bíṣọ́ọ́bù ìjọ pẹntikósítà lẹ́kùn àríwá ipade alatilẹkunmọri se ti waye laarin oludije sipo aarẹ fun ẹgbẹ oselu apc, asiwaju bola ahmed tinubu ati igbimọ awọn bisọọbu ninu ijọ kristiẹni igbalode ta mọ si pentecostal, ẹkun ariwa naijiria. ilu abuja si ni ipade naa ti waye ni alẹ ọjọbọ ana, gẹgẹ bo se salaye loju opo twitter rẹ, @official_abat ipade naa si lo waye lasiko ti awọn eeyan kan tun n bu ẹnu atẹ lu bi ẹgbẹ oselu apc se fa tinubu ati igbakeji rẹ, shettima kalẹ, ti awọn mejeeji si jẹ musulumi. nibi ipade naa si ni tinubu ti salaye fun awọn asoju awọn bisọọbu naa, idi to se mu musulumi bii tiẹ gẹgẹ bii igbakeji. o salaye fun bisọọbu agba john praise ti ijọ dominican chapel, to ko awọn bisọọbu naa sodi pe igbesẹ naa kii se amọọmọ se oun. tinubu ni o di dandan ki oun yan shettima to jẹ musululmi lọna ati pese isejọba rere fun awọn ọmọ naijiria ti wọn ba dibo yan oun sipo aarẹ lọdun 2023. bakan naa tun ni tinubu ipade to waye laarin oun ati awọn igbimọ awọn bisọọbu naa se eso rere. sugbọn yoruba ni isọrọ ni igbesi, awọn naijria ti wa n fesi si ikede ti tinubu fi soju opo ayelujara rẹ naa. bi awọn eeyan kan se n kan saara si, ni awọn miran n sọko ọrọ si lori igbesẹ naa. awọn asofin kan ni naijiria ti bu ẹnu atẹ lu aarẹ muhammadu buhari lẹyin to ko nnkan bii ọgọrun un eeyan lọ sibi ipade ajọ agbaye to waye niluu new york, lorilẹ-ede amẹrika. awọn aṣofin naa ni, o jẹ ohun to buru jai pe aarẹ yoo ko iye eeyan to pọ to bẹẹ sọdi lọ silẹ amẹrika pẹlu owo iyebiye lasiko ti ara n ni eto ọrọ aje naijiria. lara awọn asọfin ọhun ni muhammad sani musa, to n ṣoju ẹkun ila oorun niger, lati ipinlẹ niger. asọfin naa ni oju gba oun ti fun aarẹ buhari ati awọn olubadamọran rẹ bi wọn ko ṣe dẹkun rẹ lati maṣe gbe igbesẹ naa. o ni “nigba ti mo ri iye eeyan to kọwọrin pẹlu aarẹ lori ẹrọ amohunmaworan, oju gba mi ti fun wọn.” “ọpọ araalu lo n pariwo ebi, koda, ijọba gan tun fẹ ya owo kun eto iṣuna, kilode ti a fi wa n fi obitibiti owo sọfo lati ko ọpọ ero tẹle aarẹ lọ irinajo?” sẹnetọ naa ni bii igba ti eeyan ba n fi owo ilu sọfo ni irinajo naa ri, nitori awọn eeyan bii ọgọrun naa ni ijọba yoo san owo ọkọ ofurufu wọn, yatọ si owo ile itura ati owo ounjẹ wọn. o pari ọrọ rẹ pe o yẹ ki ijọba maa ṣaanu awọn araalu, ko si maa din iye owo to n fi ṣofo ku. èyí lohun tí ààrẹ buhari à tàwọn olùdíje kọ̀ọ̀kan sọ níbi ìdìbò abẹ́nú apc buhari rọ gbogbo awọn oludije lati rii pe wọn ko sa fi ẹgbẹ oṣelu apc silẹ bi wọn ba padanu ibo abẹnu naa nitori pe omi ṣi n bẹ lamu fun ẹgbẹ oṣelu naa. o ni bi o ti lee wu ko ri, iṣọkan ẹgbẹ oṣelu apc ṣe koko. aarẹ buhari wa rọ awọn aṣojudibo lati dibo yan oludije to ni iṣọkan orilẹede naijiria lọkaan ti ko sii fi ilọsiwaju naijiria sere. èyí lohun tí ààrẹ buhari à tàwọn olùdíje kọ̀ọ̀kan sọ níbi ìdìbò abẹ́nú apc buhari rọ gbogbo awọn oludije lati rii pe wọn ko sa fi ẹgbẹ oṣelu apc silẹ bi wọn ba padanu ibo abẹnu naa nitori pe omi ṣi n bẹ lamu fun ẹgbẹ oṣelu naa. o ni bi o ti lee wu ko ri, iṣọkan ẹgbẹ oṣelu apc ṣe koko. aarẹ buhari wa rọ awọn aṣojudibo lati dibo yan oludije to ni iṣọkan orilẹede naijiria lọkaan ti ko sii fi ilọsiwaju naijiria sere. aarẹ gotabaya rajapaksa ti kọ iwe fi ipo rẹ sile gẹgẹ bi aarẹ lẹyin ti o fẹsẹ fẹẹ kuro lọ si orilẹ ede singapore latari bi awọn olugbe ilu ṣe fẹohunhan lori eto iṣejọba rẹ. igbagbo wa pe o fẹ kuro ni sri lanka ki o to kọ iwe fi ipo rẹ sile ni nitori ki ijọba tuntun ma baa fi ofin gbe e. ọwọngogo ounjẹ, epo bentiro ati awọn ohun miiran ni o ti nira lorilẹde naa. ni olu ilu colombo, pẹlu ijo ati ẹrin ayo ti awọn olufẹhonuhan fi n yọ nigbati wọn gbọ iroyin pe aarẹ ti kuro ninu ilu naa “inu wa dun pupo, a le ni isinmi bayi ki a to pada si igbesi aye wa,” viraga perera sọ fun bbc. “lọwọlọwọ bayi, o ti rẹ wa nitori bi a sẹ fehonuhan sugbọn wakati ti a wa yii, a ki ara wa ku oriire.” rajapaksa ti de si orilẹede singapore l ọjọbọ ana pẹlu iyawo ati olusọ abo meji. orilẹde singapore ti wa kede pe awọn ko fun aarẹ rajapaska ni anfani lati wa ni ilu wọn nitori orilẹ ede naa ko ki n fun awọn to ba sa kuro ni ilu wọn ni anfani lati wa ni singapore adele aarẹ lorilẹde sri lanka, ranil wickremesinghe ni ko ni di aarẹ fidihẹ latari bi wọn ko ṣe tii bura fun un. ranil wickremesinghe ni awọn aṣofin orilẹde naa ni ọgbọn ọjọ lati fi ase sii pe ko di aarẹ fidihẹ ni ṣe ni ọjọ ayo di ọjọ ibanujẹ fun arabinrin kan lẹyin ti ọlọpaa mẹrin fi ofin mu arabinrin fun ẹsun ole jija nigba ti igbeyawo re lọwọ lorilẹede uganda. lọjọ satide ọsẹ to kọja ni awọn ọlọpaa naa yawọ ibi ayẹyẹ igbeyawo, ti wọn si mu iyawo lo si agọ wọn ni mbararata, ni iwọ oorun uganda. arabinrin naa lo sun agọ naa mọjumọ, ti wọn si tu silẹ ni ọjọ keji. agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa , fred enanga, ninu atẹsita to fi sita, ni iwa ti awọn ọlọpaa maa wu ni o le gba isẹ lọwọ wọn, nitori nkan ti wọn ṣe ni ko ba ofin mu. o ni awọn ọlọpaa naa lo ṣe isẹ naa lai si ẹri, ti wọn ba ọjọ ayo jẹ fun arabinrin naaa enanga ni ọwọ ti tẹ ọkan lara awọn ọlọpaa naa, ti o siti wa ni ahamọ sugbọn awọn mẹta yooku ti fẹsẹ fẹ kuro ni agbegbe naa. bi isẹ ti arabinrin ti n sisẹ tẹlẹ lo fi ẹsun ole jija kan arabinrin naa, ti wọn si bẹ awọn ọlọpaa nisẹ lati lo mu arabinrin naa awọn eeyan ilu mariga nijọba ibilẹ bariga nipinlẹ niger ti n wa oku eeyan to to ẹẹdẹgbẹta nigba ti omi wọ iboji to wa nilu naa lọ. imaamu agba fun ilu mariga, alhaji alhassan na ibi lo fi idi isẹlẹ naa mulẹ fun bbc ljọru. ""ẹkun omi naa ba iboji ti wọn sin oku eeyan bii ẹẹdẹgbẹjọ si amọ oku ẹgbrun kan pere la tun sin pada si iboji naa nigba ti ẹkun omi naa fa"". o fikun pe awọn tun ti n wa awọn oku ẹẹdẹgbẹta to sọnu amọ awọn ro pe omi ti wọ wọn lọ ni. amọ ihuwasi awọn awakusa to wa ni agbegbe ti itẹ oku naa wa, lo n kọ imaamu ọhun lominu. gẹgẹ bo se wi, iru isẹlẹ bayii ko waye ri lati ọgọta ọdun sẹyin. ogbontarigi agbabọọlu ọmọ naijiria to fi orile-ede austria ṣe ibugbe, david olatukunbo alaba, ti kọ awọn ile igbọnsẹ fun awọn ara ilu remo, nipinlẹ ogun. ọmọ orile-ede naijiria ni awọn obi alaba, sugbọn ilu vienna ni austria ni wọn bi si. oun naa kii si fi pamọ pe ọmọ naijiria ni oun. ọjọ satide, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu kẹsàn-án, ọdun 2022, ni wọn ṣe ifilọlẹ awọn ile igbọnsẹ naa ni ọjà kara tó wa ni ogere-remo. alaba ni oun kọ ile igbọnsẹ naa gẹgẹ bi ara ọna lati ṣe atilẹyin fun akitiyan isejọba muhammadu buhari lati fòpin si bi awọn araalu kan ṣe n yagbẹ ni gba ngba. alaga àjọ to n mojuto ọrọ àwọn ọmọ naijiria nilẹ okeere, abike dabiri-erewa lo kede igbeṣẹ alaba. o sọ ninu atẹjade kan lori twitter rẹ pe oun dupẹ pupọ lọwọ àjọ alaanu david alaba foundation, fun kíkọ àwọn ile igbọnsẹ naa. "" david tun ti n ṣe eto lati kọ ibudo ikọṣẹ fun bọọlu gbigba ni naijiria.""",,bayii ni aarẹ joe biden ṣe daa pada fun aarẹ putin lori ọrọ ibẹru ti fi ranṣẹ si awọn ara ukraine. +lóòtọ̀ ni òṣìṣéͅ 21 kú ní fásitì calabar láàrín oṣù méje tí asuu bẹ̀rẹ̀ ìyanṣéͅlódì,"oríṣun àwòrán, others o kere tan awọn olukọ fasiti to le ni ogun ti padanu ẹmi wọn ni fasiti calabar laarin oṣu meje ti ẹgbẹ oṣiṣẹ asuu ti bẹrẹ iyanṣẹlodi. oṣu keji, ọdun 2022 ni ẹgbẹ oṣiṣẹ asuu bẹrẹ iyanṣẹlodi lori ẹsun pe ijọba apapọͅ kọ lati mu adehun ṣe pẹlu awọn olukọ . bakan naa ni wọn bẹrẹ atunṣe ni awọn fasiti kaakiri orilẹede naijiria. amọ ijọba kan an ni ipa fun wọn lati pada si ileẹkọ ki wọn to le san owo oṣu fun wọn. ijọba n ṣamulo ofin pe ẹnikẹni ti ko ba ṣiṣẹ ko ni gba owo osu. laipẹ yii ni iroyin gbode pe o kere tan ọjọgbọn ati ọmọwe to le ni ogun ti gbẹmi mi laarin oṣu meje. alaga ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ fasiti ni calabar, john edor lasiko to n ba bbc sọrọ ni lootọ ni awọn olukọ agba fasiti naa jade laye. ‘’amọͅ awọͅn ọjọgbọn, ọmọwe bii mẹwaa ni awọn to jẹ ọmọ ẹgbẹ asuu, awọn yoku jẹ oṣiṣẹ fasiti ti kii ṣe olukọ.’’ ‘’airi ounjẹ jẹ, itọju to peye nitori wọn ko san owo oṣu awọn oṣiṣẹ yii jẹ ọkan lara ohun to ṣekupa wọn.’’ ‘’ o ṣoro lati sọ wi pe iyanṣẹlodi asuu lo fa iku wọn, amọ nigba ti wọn ko ba gba owo oṣu, ko si bi wọn ṣe maa tọju ara wọn.’’ ‘’bakan naa ni ijọba gbọdọ gbọ ohun ti a n sọ, owo oṣu wa kii sẹ titi wọn, awọn ko ni wọn ni owo ilu, nitori naa ko bojumu ki wọn sọ wi pe olukọ ti ko ba ṣiṣẹ, ko ni gba owo osu.’’ ninu ọͅrọͅ rẹͅ, agbẹͅnusọͅ oṣiṣẹͅ asuu naa ni iya n jẹ awọn olukọ lati igba ti iyanṣẹlodi yii ti bẹrẹ, nitori ijọba kọ lati san owo oṣu wọn. o ni iru ifiyajẹni ti a ko ri iru rẹ ri ni ki wọn maṣe san owo oṣu oṣiṣẹ fun oṣu meje gbako. ‘’ọpọlọpọ awọn olukọ wọn yii ni wọn n tọrọ jẹ, ti wọn kesi ẹbi ati ara lati ran wọn lọwọ.’’ ‘’nkan ti ijọba ṣe ko bojumu rara nitori awọn kọ ni wọn ni owo ilu, ti wọn fi wa n fi iya jẹ awọn eniyan lọna aitọ, lai bikita. laipẹ yii ni ileẹjọ to n risi ọrọ karakata paṣẹ fun awọn oṣiṣẹ fasiti lati pada si ẹnu isẹ lẹyin osu meje , amọ ẹgbẹ oṣiṣẹ naa yari kanlẹ pe afi ti ijọba ba san owo osu awọn lasiko iyanṣẹlodi ọhun.",29 owewe 2022,"agbẹͅnusọͅ oṣiṣẹͅ asuu naa ni iya n jẹ awọn olukọ lati igba ti iyanṣẹlodi yii ti bẹrẹ, nitori ijọba kọ lati san owo oṣu wọn." +"kò rọrùn rárá láti dàgbà ní agbègbè bíi mushin, àànú ọlọ́hun ló sọ mi di agbábọ́ọ̀lù super falcons - rasheedat ajibade","rasheedat ajibade wafcon 2022: tí m bá wo bí mo ṣe bẹ̀rẹ̀ ní mushin táwọn ẹgbẹ́ mi ń máà m ṣaaaju ifsẹwọnsẹ ti yoo waye laarin awọn agbabọọlu obinrin orilẹede naijiria ati cameroon lonii ni papa isere stade mohamed v stadium ni casablanca lẹyin ti wọn lu awọn agbabọọlu burundi lalubami lọjọ aiku to kọja, bbc yoruba mu iroyin nipa igbaradi awọn ẹgbẹ agbabọọlu ti naijiria wa. ọkan lara wọn to jẹ agbabọọlu aarin to si jẹ ọmọ yoruba, rasheedat ajibade kẹnu bọ ọrọ nipa ibẹrẹpẹpẹ rẹ ni agbegbe mushi ni ipinlẹ eko, naijiria.",14 agẹmo 2022, +"ẹ ṣọ́ra, monkeypox tún lè dàbí àjàkálẹ̀ ààrùn bíi coronavirus ní àgbáyé - who","oríṣun àwòrán, wikipedia ajọ to n gbogun ti ajakalẹ aarun lorilẹede naijiria ti fi lede pe eniyan mejilelọgta lo ti lugbadi arun naa lorilẹede naijiria. ajọ ncdc fi eleyii lede ninu atẹjade nipa monkeypox ti wọn fi sita ni ọjọ iṣẹgun. ajọ ncdc ni lati osu kini ọdun 2022 yii si oṣu kẹfa ọdun naa, ni wọn ti fi lede pe ipinlẹ mejidinlogun ni awọn eniyan ti ni arun naa ni naijiria to fi mọ ilu abuja. bakan naa ni atẹjade naa fi lede pe eniyan mẹrinlenigba ni afihan wa pe o ṣeeṣe ki wọn ti lugbadi aarun naa ni naijiria. ọkunrin mẹrinlelogoji ati obinrin mejidinlogun lo ti lugbadi arun naa ni ilu mọkandinlogun. lara wọn ni eniyan mẹwaa ti lugbadi aarun naa ni ipinlẹ eko, eniyan kan ni ipinlẹ ọyọ, ondo ati ogun. awọn ipinlẹ to tun ni ni adamawa (6), bayelsa (5), delta (5), rivers (5), cross river (4), edo (4), fct (4), plateau (4), nasarawa (3), kano (2), imo (2), taraba (2), abia (1), katsina (1), niger (1). bakan naa ni ẹni ogoji ọdun ti gbẹmi ni latari arun monkeypox naa. ajọ eleto ilera lagbaye, who ti kilọ pe ti awọn orilẹede ko ba ṣọra, arun monkeypox le dabi ajakalẹ arun coronavirus lagbaye aṣoju wọn lorilẹede naijiria, dr. walter mulombo lo ṣọ bẹẹ nibi ipade pẹlu awọn akọroyin ti wọn pe akọle rẹ ni; “monkeypox spread, infodemic & public health response in nigeria,”. dr. walter mulombo ni ti awọn orilẹede lagbaye ko ba ni abẹrẹ ajẹsara to gbooro lati koju aarun naa pe o sẹeṣẹ ko tankalẹ. bakan naa ni o fikun un pe abẹrẹ ajẹsara ti wọn fi n tọju ẹni to ni aarun smallpox ti awọn orilẹede lagbaye nlo, eleyii ti ko wọpọ ni ilẹ afrika. iwadii fihan pe o ṣeeṣe ko je awọn eku ni wọn n ṣe atakalẹ aarun naa ti ohun wa lati ara ẹranko si eniyan.",29 òkùdu 2022, +olóṣèlú bẹ̀rẹ̀ àpárá tórí ọ̀pọ̀ olùwọ́de lẹ́yìn peter obi,"agbẹnusọ fun ikọ ipolongo idibo fun atiku abubakar, tii se oludije fun ipo aarẹ lẹgbẹ osẹlu pdp, daniel bwala ti fi ero rẹ lede lori iwọde to waye ni awọn olu ilu kaakiri orilẹede naijiria fun oludije lẹgbẹ oṣelu labour party, peter obi. ninu ọrọ to fi si oju opo twitter rẹ, bwala ni iwọde to waye ni awọn ilu naa, paapaa ni ilu kaduna fihan pe ina ẹgbẹ oṣelu apc n jo ajorẹyin ni. awọn alatilẹyin obi ti wọn n pe ni obidient ni wọn ṣe iwọde oni miliọnu kan eeyan kaakiri awọn olu ilu ni naijiria lati ṣe ayajọ ọjọ ominira naijiria ni ọjọ kini, osu kẹwaa, ọdun 2022. amọ bwala lasiko to n sọrọ nipa bi awọn ero naa ṣe pọ to ni atiku lo jẹ ki obi di ilu mọọka, eleyii ti o ni o ṣafihan pe apc ti n fidi rẹmi. bwala ni ""eleyii kii se ẹgbẹ oselu pdp, labour ni o, ti awọn eniyan si n wọ tẹle wọn bayii.’’ eyi fihan pe adari nla ni atiku abubakar nitori o gbagbọ ninu ẹya igbo, ti o si jẹ ki obi di ilu mọọka. bakan naa ni bwala fihan pe atiku ti fidi rẹ mulẹ pe lẹyin oun, ẹya igbo ni yoo di ipo aarẹ mu ni naijiria. bakan naa lo fikun un pe o da oun loju pe obi ti gba iṣakoso iha guusu orilẹede naijiria, ti apc nipinlẹ eko ko si lagbara to bi wọn ṣe ro. amọ ninu ọrọ rẹ, reno omokri ti ni obi ko le wọle gẹgẹ bi aarẹ ni ọdun 2023, awọn eniyan kan n tẹle lasan ni. omokri fi ero rẹ yii lede loju opo twitter rẹ lasiko to n sọrọ nipa iwọde ‘’obidient’’ ọhun. o ni obi gan an ni yoo ran tinubu lọwọ lati ri pe o bori ninu idibo sipo aarẹ ni ọdun 2023. reno omokri ni aarin atiku ati tinubu ni ijakadi fun ipo aarẹ ọdun 2023 wa. o ni ẹbun keresimesi to wa saaju ọdun ọhun ni obi jẹ fun tinubu nitori awọn eniyan yoo dibo fun lọgọọrọ. amọ o gboriyin fun obi to ko ẹgbẹgbẹrun awọn eniyan jọ, ti wọn si tu yaya jade lati ṣe atilẹyin fun",ìṣẹ́jú 31 sẹ́yìn,"reno omokri ni peter obi ko le wọle gẹgẹ bi aarẹ ni ọdun 2023, awọn eniyan kan n tẹle lasan ni." +"buhari, ìhàlẹ̀ lásán ni ìdúnkòkò rẹ̀, a kò padà sí kíláàsì – asuu yarí","oríṣun àwòrán, others ẹgbẹ awọn olukọ fasiti ni naijiria, asuu ti seleri pe iyanṣẹlodi yoo tẹsiwaju titi ti ijọba yoo fi wa ọna abayọ si ọrọ yii. aarẹ ẹgbẹ asuu, emmanuel osodeke lo sọ bẹẹ lẹyin ti aarẹ buhari kesi ẹgbẹ naa lati fopin si iyanṣẹlodi wọn , ki wọn si pada si ẹnu iṣẹ wọn. amọ̀ osodeke, ninu lẹta to kọ sawọn olukọ, ni awọn ko ni da idunkoko ijọba lohun ayafi ti wọn ba dahun si ibeere wọn, ki wọn si san owo oṣu awọn oṣiṣẹ. bakan naa lo ni awọn ko tapa si aṣẹ ileẹjọ to ni ki awọn wọle pada nitori awọn ti gba ileẹjọ kotẹmilọrun lọ. o ni nitori awọn ti lọ si ileẹjọ kotẹmilọrun naa, awọn le boju wẹyin mọ lori iyanṣelodi naa. ‘’iyanṣelodi yii ti fẹrẹ pe oṣu mẹjọ, ti mo si dupẹ lọwọ awọn oṣiṣẹ ti wọn ko wẹyin bi o tilẹ jẹpẹ ijọba kọ lati san owo oṣu fun wa mọ.’’ ‘’a ti fi ye ijọba pe awa kii ṣe atẹmẹrẹ ti wọn le ṣe baṣubaṣu tabi ti wọn le dunkoko mọ.’’ ‘’eleyii ti mu ki eso rere maa jade, ti ijọba si n gbiyanju lati ba wa sọrọ.’’ laarin ọṣẹ meji, a ti jijoro pẹlu adari ile aṣojuṣofin, femi gbajabiamila. igbagbọ wa si ni pe aarẹ buhari yoo da wa lohun ni kiakia ti wọn ba ti gbe adehun naa de ọdọ rẹ. bakan naa lo fikun un pe inu awọn ko dun pe awọn akẹkọọ wa ni ile lai ṣe nkankan. ẹgbẹ asuu wa rọ gbogbo awọn ti ọrọ kan lati sa ipa wọn lati fi opin si iyanṣelodi naa lai fi iya jẹ awọn olukọ bakan naa. oríṣun àwòrán, others wayi o, ẹgbẹ awọn akẹkọọ ni fasiti ipinlẹ nasarawa, keffi (nsuk) ti kesi awọn akẹkọọ lati gbọ aṣẹ adari fasiti pe ki wọn pada si ileẹkọ. aarẹ ikọ awọn akẹkọọ fasiti nasarawa, naajim gbfwi fi ero wọn lede ni ilu keffi. lẹyin ti awọn alaṣẹ ileẹkọ naa fi atẹjade sita ni ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu kẹsan an pe ki awọn akẹkọọ pada si ileẹkọ nitori kilasi yoo bẹrẹ pada ni kiakia. eyi lo mu ki ẹgbẹ awọn akẹkọọ naa rọ awọn akẹkọọ lati pada si ileẹkọ lati bẹrẹ eto ẹkọ wọn pada. bakan naa ni wọn kesi ẹgbẹ asuu lapapọ lati maṣe tapa si igbeṣẹ wọn nitori awọn nifẹ lati pada si ẹnu ẹkọ wọn. amọ alaga ẹgbẹ asuu ni fasiti nasarawa, ọmọwe samuel alu ti bu ẹnu atẹ lu aṣẹ fasiti ọhun pe ki awọn akẹkọọ wọle pada. alu ni ko si ohun to jọ bẹ ẹ nitori awọn olukọ ko ni wọle pada ayafi ti ijọba ba pari iyanṣelodi naa, ti wọn si san owo oṣu wọn.",wákàtí 4 sẹ́yìn,amọ awọn alaṣẹ fasiti ipinlẹ nasarawa ti paṣẹ fun awọn akẹkọọ lati pada si ileẹkọ. +"ibi tí yorùbá ńfẹ́ kọ́ ni adebanjo kọjú sí, ẹ̀yìn tinubu ni afenifere tò sí -wale oshun","oríṣun àwòrán, others aṣiwaju ẹgbẹ ọmọbibi ilẹ yoruba, afenifere renewal group, ọgbẹni olawalu oshun, ti sọ pe bọla tinubu lawọn n ṣe atilẹyin fun, kii ṣe peter obi ti ẹgbẹ oṣelu labour party. ṣaaju ni olori afenifere, oloye ayo adebanjo sọ nibi eto kan lọjọ aje pe obi ni ẹgbẹ naa n tilẹyin. ọgbẹni oshun sọ fun bbc pe ohun ti ẹgbẹ afẹnifẹre renewal group duro ti ni ifẹ ọmọ yoruba nile ati lẹyin odi, ti o si da awon loju pe ohun to ọgọrọ ọmọ yoruba n fẹ naa ni ki ọmọ yoruba to kun oju oṣuwọn o wọle sipo aarẹ. o ni kii ṣe pe ẹgbẹ naa ko ni igbagbọ ninu iṣọkan naijiria, ati wi pe boya awọn eeyan lati ẹya miran ko ni jade. “ohun to fa ipinnu wa lati duro ti ọmọ yoruba laarin awọn to n dije bayii ko ju wi pe, oun lo kun oju oṣuwọn julọ ninu gbogbo oludije fun ipo aarẹ. ọgbẹni oshun ni bola tinubu, ni awọn rii pe yoo lee yanju awọn ipenija ti o n doju kọ ọmọ naijiria, leyi ti awọn si ti n fọnrere rẹ ṣaaju akoko yii. ọrọ ti afẹnifere sọ yii n fidi ohun ti agbẹnusọ fun ileeṣẹ ipolongo ibo bola tinubu, bayọ ọnanuga sọ pe ọrọ ara oloye adebanjọ lo n sọkii ṣe ohun ti ẹgbẹ afẹnifẹre n fe. oríṣun àwòrán, other asiwaju ẹgbẹ yoruba kan ti a mọ si afẹnifẹre, oloye ayọ adebanjọ ti ṣalaye idi ti ẹgbẹ naa ko fi fẹ ti oludije ẹgbẹ oṣelu apc, bola ahmed tinubu tabi ti pdp atiku abubakar lẹyin fun ibo aarẹ naijiria ti yoo waye lọdun 2023. asiwaju ẹgbẹ afẹnifẹre, oloye ayọ adebanjọ ṣalaye nibi apero kan to ṣe pẹl’awọn akọroyin pe iṣọkan ati ilana aparo kan ko ga ju ọkan lọ pẹlu idajọ ododo lti ẹgbẹ naa duro fun lo mu ko pinnu eyi. adebanjọ n fi apero naa fesi si ọrọ ti ileeṣẹ ipolongo idibo aarẹ fun bola ahmed tinubu fi sita laipẹ yii ni ninu eyi to ti sọ ọ di mimọ pe iṣẹ ara oloye adebanjọ lo n jẹ o ko jẹ iṣẹ ọmọ yoruba lori peter obi to gbe ka ori. + oludari eto ipolongo fun ileesẹ ipolongo ibo fun bola tinubu, bayọ ọnanuga ṣalaye bu ẹnu atẹ lu bi ayọ adebanjọ ṣe n ṣe atilẹyin fun peter obi ti ẹgbẹ oṣelu labour. + onanuga kọ ọ si oju opo facebook rẹ pe lootọ adebanjọ lẹtọ si fifi atilẹyin rẹ han fun oludije yoowu to ba wu u ṣugbọn iṣẹ ara rẹ lo n jẹ, ko yẹ ko wa maa lọ ifẹ ara rẹ mọ ẹgbẹ afẹnifẹre lẹsẹ pe oun ti oun n fẹ naa ni ẹgbẹ ọhun pẹlu nfẹ. + adebanjọ to fesi si eyi ṣalaye iwa aisi irẹjẹ ni afẹnifẹre n fẹ to fi gbe ijoko joko si ẹyin peter obi gẹgẹ bi oludije to fẹ ti lẹyin. + o fi kun pe ilana iṣejọba apapọ tootọ ti oyinbo n pe ni federalism ni afẹnifẹre n fẹ. + + ayọ adebanjọ ni lootọ ọpọ awọn aṣiwaju ilẹ yoruba lo ti kọminu lori igbesẹ naa sugbọn ti oun ti la ọrọ naa ye ti oun si ti jẹ ki wọn mọ pe ilana ẹni kan kii jẹ ki ilẹ fẹ ti action group ti awolowo da silẹ laye ọjọun duro le lori lawọn ṣi n tẹlẹ.",27 owewe 2022, +àgbàrá òjò wú òkú tó lé ní 500 jáde ní ìpínlẹ̀ niger,"oríṣun àwòrán, nema ọkan lara awọn afara odo ti ojo bajẹ ko din ni ẹgbẹrun kan aabọ iboji oku, ti agbara ojo bajẹ ni ilẹ isinku kan nilu mariga, nipinlẹ niger. bakan naa lo tun wọ́ iboji to le ni ẹẹdẹgbẹta lọ. omiyale bẹrẹ lẹyin ti ojo nla ti n rọ fun ọpọlọpọ ọjọ ni agbegbe naa. imaamu ilu naa, alhassan musa na’ibi, sọ fun bbc pe iru iṣẹlẹ alagbara bẹẹ ko waye ri ni ilẹ isinku naa lati bi ẹẹdẹgbẹta(500) ọdun ti wọn ti kọ ọ. bakan naa ni imaamu sọ pe awọn ti tun oku bi ẹgbẹrun kan to ti jẹra sin. bo tilẹ jẹ pe iroyin sọ pe iboji oku naa sun mọ odò kan, awọn olugbe agbegbe ọhun sọ pe awọn to n wa kusa goolu nitosi ilẹ isinku ọhun lo mu ki iṣẹlẹ naa buru to bẹẹ nitori pe “ilẹ ibẹ ko l’agbara mọ’. ẹkun omi naa ni eyi to buru ju ti ipinlẹ niger koju lati bi ọdun mẹwaa. lati ibẹrẹ oṣu keje, ko din ni ọọdunrun eeyan to ti ku nitori ẹkun omi, ti ọpọ to ju ẹgbẹrun lọna ọgọrun eeyan si di alainile lori tabi sa asala kuro nilu wọn. awọn onimọ nipa oju ọjọ sọ pe ọpọ ẹkun omi ni yoo tun waye nitori awọn ojo nla ti yoo tun rọ.",25 owewe 2022, +wo ìgbé ayé àwọn obìnrin ní iran kí ìjìjàgbara islam tó dé,"oríṣun àwòrán, paolo koch/gamma-rapho via getty images ọdun 1979 ni ijijagbara ẹsin islam waye ni iran, eyii to mu ọpọ ayipada ba igbe aye awọn obinrin orilẹ-ede naa. ọna kan gboogi ti iyipada naa ti farahan ni bi wọn ṣe n mura. ṣaaju lẹyin ọdun 1930, ni ijọba ilẹ naa ti kọkọ fofin de ibori fun awọn obinrin, awọn ọlọpaa si maa n fi agidi yọ ibori lori awọn obinrin ọhun laarin igboro. amọ lẹyin ọdun 1980, ẹsin musulumi gbilẹ lorilẹ-ede iran to bẹẹ ti ijọba ẹlẹsin musulumi naa kan nipa fun gbogbo obinrin lati maa lo ijaabu. oríṣun àwòrán, a. abbas / magnum photos awọn oibinrin fasiti tehran lọdun 1977: awọn mọlẹbi kan ko gba ki awọn ọmọ wọn obinrin maa lọ sile ẹkọ, amọ ijọba ṣe ilaniyọyẹ fun wọn nipa afaani to wa ninu ẹkọ. oríṣun àwòrán, bruno barbey / magnum photos awọn obinrin to n na ọja lọdun 1976: ọpọ eeyan lo n lo ijaabu lọdun 1976 amọ ko pọn dandan, bẹẹ si ni awọn obinrin kan yan lati maa ṣi irun wọn silẹ. lara awọn aṣọ ti wọn maa n wọ lọdun naa ṣaaju islam ni ‘jeans,’ yẹri ti ko de orokun, atawọn aṣọ penpe miran. oríṣun àwòrán, bruno barbey / magnum photo faaji ita gbangba lọjọ jimoh ni 1976: ọpọ awọn eeyan iran lo fẹran ati maa ṣe faaji ni iwaju ile wọn ati leti okun lai bo ori wọn. ọjọ ẹti jẹ opin ọsẹ ni iran, wọn si maa n lo ọjọ ẹti naa lati gbadun ara wọn. oríṣun àwòrán, a. abbas / magnum photos ṣọọbu ti wọn ti n ṣe irun ni yọyọ ni 1976: awọran yii jẹ iru eyii ti eeyan ko le ri mọ bayii ni iran, amọ eyii ko tumọ si pe ko si awọn aṣerun ni yọyọ mọ lorilẹ-ede naa. oríṣun àwòrán, bruno barbey / magnum photos obinrin to n rin laarin igboro lọdun 1976: bo tilẹ jẹ pe o lodi si ofin lati da obinrin duro laarin igboro ni iran, irufẹ aworan yii, to n ṣafihan yẹti ati atike obinrin to sọwọn bayii lorilẹ-ede ọhun. oríṣun àwòrán, getty images awọn obinrin to n ṣe ifẹhonuhan lodi si ijaabu lọdun 1979: lẹyin ti adari ijọba tuntun, ayatollah ruhollah khomeini gori alefa tan lo kede pe gbogbo obinrin gbọdọ maa wọ ijaabu. ọjọ kẹjọ, oṣu kẹta ọdun naa lawọn ibinrin tu sita lati ṣe iwọde tako aṣẹ tuntun naa. oríṣun àwòrán, getty images awọn mọlẹbi to n lọ gbadura ni mọṣalaṣi ni 1980: ofin ẹsin islam tuntun ko gba awọn obinrin ati ọkunrin lati joko papọ lasiko adura ninu mọṣalaṣi. obinrin ko si gbọdọ jade lai si ọkọ rẹ tabi ọkunrin ti yoo daabo bo lẹgbẹ rẹ. oríṣun àwòrán, behrouz mehri/afp/getty images awọn obinrin to n rin laarin igboro ni 2005: kii ṣe gbogbo awọn obinrin iran lo n wọ aṣọ ti yoo bo gbogbo ara wọn, amọ dandan ni ibori. oríṣun àwòrán, getty images ibori leti okun lọdun 2005: ofin ko gba awọn obinrin iran laaye lati wẹ leti okun pẹlu aṣọ to ṣi ara wọn silẹ. bẹẹ si ni ọkunrin ati obinrin ko gbọdọ wẹ ninu odo kan lasiko kan naa. oríṣun àwòrán, getty images iwọde fun atilẹyin ijaabu lọdun 2006: lẹyin nnkan bii ọdun marundinlọgbọn ti islam gbilẹ ni iran, awọn obinrin ṣe iwọde ninu eyii ti wọn ti fẹsun kan ijọba pe kọ fi ẹsẹ ofin to kan ijaabu nipa mulẹ bo ṣe yẹ. oríṣun àwòrán, behrouz mehri/afp/getty images awọn obinrin to n wo bọọlu lọdun 2008: bo tilẹ jẹ pe wọn ko ni ki awọn obinrin ma wo bọọlu ni iran, amọ ọpọ igba ni wọn ki n gba wọn laaye lati wọ inu papa iṣere lọna ati wo bọọlu ọhun.",wákàtí 2 sẹ́yìn,ọna kan gboogi ti iyipada to ba awọn obinrin iran fi farahan ni bi wọn ṣe n mura lode oni saaju ọdun 1979. +"wo àwọn èèyàn tó ná ọ̀pọ̀ owó, ṣe iṣẹ́ abẹ bíi igba láti di ẹranko","oríṣun àwòrán, getty images/daily mail uk awọn onimọ ijinlẹ gbagbọ pe nnkan ẹyọ kan ko le maa wu eeyan ni gbogbo igba, idi ree ti eeyan fi maa n jẹ oniruru ounjẹ lojojumọ. bakan naa ni awọn eeyan maa n paarọ aṣọ, bata, ile tabi adugbo ti wọn n gbe, awọn mii ẹwẹ a maa paarọ ololufẹ wọn ti wọn a si sọ pe ko rọrun lati maa jẹ ounjẹ kan naa ni gbogbo igba. amọ n jẹ o ṣeeṣe ki eeyan paarọ bi awọ, ẹya ara tabi irisi rẹ ṣe ri? ibeere nla leyi jẹ, ibeere yii kan naa lo si sokunfa bawọn eeyan mẹrin wọnyi, ti wọn ni wọn ko nifẹ si bi ẹya ara wọn ṣe ri, se tun ara wọn da. amọ abamọ nla ni eyi jẹ fun wọn, to si jẹ pe ẹtẹ lo ba de fun awọn kan ninu wọn ni ikẹyin. bbc yoruba wa se akojọpọ eeyan mẹrin pere ninu awọn eeyan to tun ara wọn da yatọ si bi ẹlẹda se da wọn. oríṣun àwòrán, getty images dennis avner, ti apele rẹ n jẹ ‘stalking cat’ ni wọn bi niluu michigan, nilẹ amẹrika, lọdun 1958. o ṣe iṣẹ abẹ nigba mẹrinla lati yi irisi rẹ pada si ti ẹkun, eyii to mu ko gba ami ẹyẹ agbaye fun ẹni to ṣiṣẹ abẹ julọ lọna ati da bii ẹranko. avner kọkọ ṣiṣẹ ologun ofurufu fun ọdun diẹ ko to kuro nibẹ lọdun 1981, ko pẹ lẹyin naa to bẹrẹ si n ya ‘tatoo’ si ara, ko fi le da bii ẹkun. ọdun 2012 ni wọn ri oku rẹ ninu gareji rẹ lẹyin ọsẹ kan to ti jade laye, iroyin ni ṣe lo pa ara rẹ. oríṣun àwòrán, tiamat legion medusa richard hernandez ni orukọ abisọ ọkunrin naa, oṣiṣẹ ile ifowopamọ si ni ní ibẹrẹ ayẹ rẹ. ṣaaju ni awọn obi rẹ ti kọkọ pinya, ti ko si gbe lọdọ eyikeyi ninu awọn mejeji, eyi to mu ko maa lo ọpọ akoko ninu igbo pẹlu awọn ẹranko afayafa. gẹgẹ bii ohun to sọ, ọpọ akoko to maa n lo ninu igbo yii mu ko fẹran ejo pupọ, eyii to mu ko ya ọpọ tattoo ati iṣẹ abẹ lati da bii ejo. ọkunrin naa to n fi ilu los angeles ṣe ibugbe, na owo ti iye to £61,000 lati da bii ejo. lẹyin to di gbajumọ tan, o ṣiṣẹ abẹ lati sọ ara rẹ di obinrin, o si kede pe oun yoo ge nnkan ọmọkunrin oun sọnu. ni bayii , tiamat ti lugbadi arun kogboogun hiv, amọ o ṣi n ba iṣẹ abẹ rẹ lati di ejo lọ. richard hernandez si ti kede pe iṣẹ abẹ naa yoo pari titi ọdun 2025. oríṣun àwòrán, pixee fox - the living cartoon obinrin ẹni ọdun mẹtalelọgbọn naa ti ṣiṣẹ abẹ nigba igba, o si ti na owo ti iye rẹ to £500,000 fun awọn iṣẹ abẹ naa. ohun ti obinrin naa ṣe ni pe o yọ egungun ẹgbẹ rẹ mẹfa, ki bebere idi rẹ le kere lọna ati farajọ ‘cartoon.’ oríṣun àwòrán, @renmusb1 iṣẹ agbẹjọro ni obinrin yii n ṣe, o si tun jẹ oniṣowo pẹlu. ọdun 1967 ni wọn bi niluu guadalajara, ni mexico. nnkan to mu ki irawọ obinrin naa tan, ko ṣẹyin awọn iṣẹ abẹ to ṣe atawọn tattoo to ya si ara rẹ lati yi ara rẹ pada. o ni oun gbe igbesẹ naa lọna ati ṣe itaniji fun awọn eeyan lodi si iwa ipa si awọn obinrin ninu ile.",wákàtí 5 sẹ́yìn,"bbc yorùbá ṣe àkójọpọ̀ ìtàn ayé àti ìgbẹ̀yìn àwọn èèyàn tó ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ abẹ tó lé ní igba, ná àìmọye owó láti di ẹranko."